O Mà Lè Borí Ìrẹ̀wẹ̀sì!
ỌLỌGBỌ́N ọkùnrin kan kọ̀wé nígbà kan pé: “Ìwọ ha ti jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ ní ọjọ́ wàhálà bí? Agbára rẹ yóò kéré jọjọ.” (Òwe 24:10) Tóo bá ti rẹ̀wẹ̀sì rí, ó ṣeé ṣe kóo fara mọ́ gbólóhùn yẹn.
Kò sẹ́ni tí kò lè rẹ̀wẹ̀sì. Ìrẹ̀wẹ̀sì tó mọ níwọ̀n lè dorí ẹni kodò fún bí ọjọ́ kan tàbí méjì kí ó sì lọ. Àmọ́ tó bá di pè ìbínú tàbí ìmí ẹ̀dùn wọ̀ ọ́, ìṣòro náà lè máà tètè kúrò nílẹ̀. Àwọn Kristẹni kan tí wọ́n ti jẹ́ olóòótọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún ti di ẹni tí ìbànújẹ́ mú dorí kodò débi pé wọn ò tiẹ̀ lọ sípàdé mọ́, wọn ò sì kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá mọ́.
Tóo bá rí i pé o fẹ́ rẹ̀wẹ̀sì, má sọ̀rètí nù! Àwọn ìránṣẹ́ olóòótọ́ ayé ọjọ́un borí ìrẹ̀wẹ̀sì, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀.
Nígbà Táwọn Ẹlòmíràn Bá Mú Ọ Bínú
O kò lè retí pé kò ní sẹ́ni tó máa sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí ọ tàbí tó máa ṣe ohun tó lè múnú bí ọ. Àmọ́, o lè pinnu pé o ò ní jẹ́ kí àìpé àwọn ẹlòmíràn nípa lórí iṣẹ́ ìsìn rẹ sí Jèhófà. Bí ẹnì kan bá ti mú ọ bínú, gbígbé ọ̀nà tí Hánà, ìyá Sámúẹ́lì, gbà borí ipò kan tó kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá a yẹ̀ wò lè ràn ọ́ lọ́wọ́.
Ọmọ ń wu Hánà bí gan-an, ṣùgbọ́n ó yàgàn. Pẹ̀nínà, ìyàwó kejì tọ́kọ rẹ̀ fẹ́ ti bí àwọn ọmọkùnrin àtàwọn ọmọbìnrin fún un. Dípò kí Pẹ̀nínà máa káàánú Hánà, orogún ló kà á sí, ìwà tó sì ń hù sí i burú débi pé Hánà “máa ń sunkún, kò sì ní jẹun.”—1 Sámúẹ́lì 1:2, 4-7.
Lọ́jọ́ kan, Hánà lọ gbàdúrà nínú àgọ́ ìjọsìn. Élì, àlùfáà àgbà ní Ísírẹ́lì, kíyè sí i pé ètè rẹ̀ ń mì. Níwọ̀n bí Élì kò ti mọ̀ pé àdúrà ni Hánà ń gbà, ó ti gbà pé ọtí ló mu yó. Ó béèrè pé: “Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò fi máa ṣe bí ọ̀mùtípara? Mú wáìnì rẹ kúrò lára rẹ.” (1 Sámúẹ́lì 1:12-14) Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo bí ọ̀rọ̀ yẹn ṣé máa rí lára Hánà? Nítorí àtirí ìṣírí gbà ló ṣe wá sínú àgọ́ ìjọsìn. Kò retí pé ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin tí wọ́n bọ̀wọ̀ fún jù lọ ní Ísírẹ́lì lè ṣe báyẹn fẹ̀sùn èké kan òun!
Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá Hánà pátápátá. Ó lè fi àgọ́ ìjọsìn náà sílẹ̀ lójú ẹsẹ̀, kó sì búra pé òun kò tún ní fẹsẹ̀ kan ibẹ̀ mọ́ níwọ̀n ìgbà tí Élì bá ṣì ń sìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà níbẹ̀. Àmọ́, Hánà mọrírì àjọṣe tó ní pẹ̀lú Jèhófà gidigidi. Ó mọ̀ pé inú Jèhófà kò ní dùn bí òun bá ṣe bẹ́ẹ̀. Ibùdó ìjọsìn mímọ́ gaara ni àgọ́ ìjọsìn yẹn. Jèhófà ti fi orúkọ ara rẹ̀ síbẹ̀. Bó sì ti wù kí Élì jẹ́ aláìpé tó, òun ni aṣojú tí Jèhófà yàn.
Ọ̀nà oníwà-bí-Ọlọ́run tí Hánà gbà dáhùn ẹ̀sùn tí Élì fi kàn án yẹn jẹ́ àpẹẹrẹ gidi fún wa lónìí. Kò fara mọ́ ẹ̀sùn èké tó fi kàn án o, àmọ́ ó dáhùn lọ́nà tó fi ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ hàn. Ó fèsì pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́, olúwa mi! Obìnrin tí a ni ẹ̀mí rẹ̀ lára dé góńgó ni èmi; èmi kò sì mu wáìnì àti ọtí tí ń pani, ṣùgbọ́n mo ń tú ọkàn mi síta níwájú Jèhófà. Má ka ẹrúbìnrin rẹ sí obìnrin aláìdára fún ohunkóhun, nítorí láti inú ọ̀pọ̀ yanturu ìdàníyàn mi àti ìbìnújẹ́ mi ni mo ti ń sọ̀rọ̀ títí di ìsinsìnyí.”—1 Sámúẹ́lì 1:15, 16.
Ǹjẹ́ Hánà ṣàlàyé ara rẹ̀? Dájúdájú, ó ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n, ó bá Élì sọ̀rọ̀ lọ́nà tó mọ́gbọ́n dání, kò sọ pé òun máa fìbínú sọ̀rọ̀ sí i nítorí ẹ̀sùn èké tó fi kan òun. Élì náà wá dá a lóhùn lọ́nà pẹ̀lẹ́tù, ó ní: “Máa lọ ní àlàáfíà, kí Ọlọ́run Ísírẹ́lì sì yọ̀ǹda ìtọrọ tí o ṣe lọ́dọ̀ rẹ̀.” Gbàrà tí wọ́n yanjú ọ̀rọ̀ náà tán ni Hánà “bẹ̀rẹ̀ sí bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó sì jẹun, ìdàníyàn fún ara ẹni kò sì hàn lójú rẹ̀ mọ́.”—1 Sámúẹ́lì 1:17, 18.
Kí la rí kọ́ nínú ìtàn yìí? Hánà tètè yanjú èdè àìyedè náà, ṣùgbọ́n ó ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ kí àjọṣe tó dára wà láàárín òun pẹ̀lú Jèhófà àti Élì. Ẹ ò rí i pé ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó gbámúṣé àti ọgbọ́n lè jẹ́ kí a má sọ ìṣòro kékeré di ńlá!
A gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ká tó lè yanjú aáwọ̀ tó wà láàárín àwa àtàwọn ẹlòmíràn, ó di dandan kí àwa méjèèjì lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ká sì ṣeé tẹ̀ síhìn-ín sọ́hùn-ún. Bí onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ kan kò bá fẹ́ fara mọ́ ìsapá tóo ń ṣe láti yanjú aáwọ̀ kan, o lè ní láti fi ọ̀ràn náà lé Jèhófà lọ́wọ́, kí o fọkàn balẹ̀ pé yóò yanjú rẹ̀ ní àkókò tó bá tọ́ lójú rẹ̀, àti ní ọ̀nà tó fẹ́.
Ṣé Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn Lo Pàdánù?
Àwọn kan ti sorí kọ́ nítorí pé wọ́n ní láti fi àǹfààní kan tí wọ́n ń gbé gẹ̀gẹ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run sílẹ̀. Wọ́n ń gbádùn bí wọ́n ṣe ń lo ara fún àwọn arákùnrin wọn, nígbà tí wọ́n sì pàdánù àǹfààní yẹn, wọ́n ronú pé àwọn kò wúlò fún Jèhófà tàbí ètò àjọ rẹ̀ mọ́. Bó bá jẹ́ pé ohun tóo ń rò nìyẹn, o lè lóye ohun tó fà á tóo bá gbé àpẹẹrẹ òǹkọ̀wé Bíbélì nì, Máàkù, tó tún ń jẹ́ Jòhánù Máàkù yẹ̀ wò.—Ìṣe 12:12.
Máàkù tẹ̀ lé Pọ́ọ̀lù àti Bánábà lọ sí ìrìn àjò míṣọ́nnárì wọn àkọ́kọ́, àmọ́ nígbà tó bá wọn dé ọ̀nà, ó já wọn sílẹ̀, ó sì padà sí Jerúsálẹ́mù. (Ìṣe 13:13) Lẹ́yìn ìyẹn, Bánábà tún fẹ́ kí Máàkù bá wọn lọ sí ìrìn àjò mìíràn. Àmọ́, Bíbélì sọ pé: “Pọ́ọ̀lù kò ronú pé ó bẹ́tọ̀ọ́ mu láti mú ẹni yìí dání pẹ̀lú wọn, nítorí pé ó fi wọ́n sílẹ̀ láti Panfílíà, kò sì bá wọn lọ sẹ́nu iṣẹ́.” Bánábà kọ̀ délẹ̀. Ìtàn náà sọ pé: “Látàrí èyí, ìbújáde ìbínú mímúná wáyé, tí ó fi jẹ́ pé wọ́n pínyà kúrò lọ́dọ̀ ara wọn; Bánábà mú Máàkù dání, ó sì ṣíkọ̀ lọ sí Kípírù. Pọ́ọ̀lù yan Sílà, ó sì lọ.”—Ìṣe 15:36-40.
Ọkàn Máàkù ti ní láti gbọgbẹ́ gan-an nígbà tó rí i pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tí wọ́n bọ̀wọ̀ fún gidigidi kò fẹ́ bá òun rìn àti pé awuyewuye tí wọ́n ń ṣe nípa bóyá òun tóótun tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́ ti dá wàhálà sílẹ̀ láàárín Pọ́ọ̀lù àti Bánábà. Àmọ́ ìtàn náà kò parí síbẹ̀ o.
Pọ́ọ̀lù òun Sílà ṣì nílò ẹni tó máa bá wọn rin ìrìn àjò. Nígbà tí wọ́n dé Lísírà, wọ́n rí ẹnì kan fi dípò Máàkù, ìyẹn ni ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tímótì. Wàyí o, ó lè jẹ́ pé kò tíì ju bí ọdún méjì sí mẹ́ta tí Tímótì ṣe batisí nígbà tí wọ́n yàn án. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, Máàkù ti ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ Kristẹni látìgbà tó ti bẹ̀rẹ̀—àní tipẹ́tipẹ́ ṣáájú Pọ́ọ̀lù alára. Síbẹ̀, Tímótì ni wọ́n fún ní àǹfààní ẹrù iṣẹ́ náà.—Ìṣe 16:1-3.
Kí ni Máàkù ṣe nígbà tó rí i pé wọ́n ti fi ẹni tó kéré sí òun, tí kò sì fí bẹ́ẹ̀ nírìírí rọ́pò òun? Bíbélì kò sọ ohun tó ṣe fún wa. Ṣùgbọ́n, ó fi hàn pé Máàkù ń bá a lọ gẹ́gẹ́ bí ògbóṣáṣá nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ó lo àwọn àǹfààní tó ṣí sílẹ̀ fún un dáadáa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò láǹfààní láti bá Pọ́ọ̀lù àti Sílà ṣíṣẹ́, síbẹ̀ ó ṣeé ṣe fún un láti bá Bánábà lọ sí Kípírọ́sì, tó jẹ́ àdúgbò Bánábà. Máàkù tún bá Pétérù ṣiṣẹ́ pọ̀ ní Bábílónì. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ó láǹfààní láti bá Pọ́ọ̀lù—àti Tímótì—ṣiṣẹ́ ní Róòmù. (Kólósè 1:1; 4:10; 1 Pétérù 5:13) Nígbà tó yá, a tiẹ̀ mí sí Máàkù láti kọ ọ̀kan lára àwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin!
Ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n kan wà nínú gbogbo èyí. Máàkù kò jẹ́ kí àǹfààní tóun pàdánù ba òun lọ́kàn jẹ́ débi tí kò fi ní mọyì àwọn àǹfààní tó ṣì wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ̀. Máàkù jẹ́ kí ọwọ́ òun dí nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, Jèhófà sì bù kún un.
Nítorí náà, tóo bá pàdánù àǹfààní kan, má ṣe rẹ̀wẹ̀sì. Tóo bá ní ẹ̀mí tó dáa, tóo sì jẹ́ kí ọwọ́ rẹ dí, àwọn àǹfààní mìíràn lè yọjú. Ohun púpọ̀ ló wà láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa.—1 Kọ́ríńtì 15:58.
Ìránṣẹ́ Kan Tó Jẹ́ Olóòótọ́ Rẹ̀wẹ̀sì
Kò rọrùn láti máa ja ìjà líle fún ìgbàgbọ́. O lè rẹ̀wẹ̀sì nígbà mìíràn. Lẹ́yìn ìyẹn, o tún lè wá máa dá ara rẹ̀ lẹ́bi pé o tiẹ̀ rẹ̀wẹ̀sì, kóo parí èrò sí pé kò yẹ kí olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní irú èrò yẹn. Ronú nípa Èlíjà, ọ̀kan lára àwọn wòlíì tó tayọ jù lọ ní Ísírẹ́lì.
Nígbà tí Jésíbẹ́lì Ayaba Ísírẹ́lì, ẹni tó gba wèrè mọ́ ìjọsìn Báálì, gbọ́ pé Èlíjà ti pa àwọn wòlíì Báálì, ó búra pé òun máa pa á ṣáá ni. Èlíjà ti kojú àwọn ọ̀tá tó burú ju Jésíbẹ́lì tẹ́lẹ̀, àmọ́ lójijì ó bẹ̀rẹ̀ sí rẹ̀wẹ̀sì débi pé ikú wá ń wù ú. (1 Àwọn Ọba 19:1-4) Báwo nìyẹn ṣe lè ṣẹlẹ̀? Ó ti gbàgbé nǹkan kan ni.
Èlíjà ti gbàgbé láti wo Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Orísun okun rẹ̀. Ta ló fún Èlíjà lágbára láti jí òkú dìde àti láti kojú àwọn wòlíì Báálì? Jèhófà ni. Dájúdájú, Jèhófà lè fún un lágbára láti kojú ìrunú Jésíbẹ́lì Ayaba.—1 Àwọn Ọba 17:17-24; 18:21-40; 2 Kọ́ríńtì 4:7.
Kò sẹ́ni tí ìgbẹ́kẹ̀lé tó ní nínú Jèhófà kò lè mì fúngbà díẹ̀. Bíi ti Èlíjà, àwọn ìgbà mìíràn wà tóo lè fẹ́ fi ojú tèèyàn wo àwọn ìṣòro kan dípò kí o fi “ọgbọ́n tí ó wá láti òkè” yanjú rẹ̀. (Jákọ́bù 3:17) Bó ti wù kó rí, Jèhófà kò kọ Èlíjà sílẹ̀ nítorí fífà tó fà sẹ́yìn fúngbà díẹ̀ yìí.
Èlíjà sá lọ sí Bíá-Ṣébà, ó sì tibẹ̀ forí lé aginjù, níbi tó rò pé ẹnikẹ́ni kò ti lè rí òun. Àmọ́ Jèhófà rí i. Ó rán áńgẹ́lì kan pé kó lọ tù ú nínú. Áńgẹ́lì náà rí i dájú pé Èlíjà rí àkàrà gbígbóná fẹlifẹli jẹ, ó sì rí omi tí ń tuni lára mu. Lẹ́yìn tí Èlíjà sinmi dáadáa tán, áńgẹ́lì náà sọ pé kó tẹsẹ̀ bọ ìrìn àjò tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọ̀ọ́dúnrún kìlómítà lọ sí Òkè Hórébù, níbi tí Jèhófà yóò ti túbọ̀ fún un lókun.—1 Àwọn Ọba 19:5-8.
Ní Òkè Hórébù, Èlíjà rí gudugudu méje tí agbára Jèhófà ṣe, èyí sì fún ìgbàgbọ́ rẹ̀ lókun. Lẹ́yìn náà, pẹ̀lú ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, ohùn rírẹlẹ̀, Jèhófà mú un dá a lójú pé kò dá nìkan wà. Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ̀, àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin [7,000] arákùnrin rẹ̀ náà wà pẹ̀lú rẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Èlíjà kò mọ̀ wọ́n. Níkẹyìn, Jèhófà yan iṣẹ́ fún un láti ṣe. Kò ta Èlíjà nù pé kì í ṣe wòlíì òun mọ́!—1 Àwọn Ọba 19:11-18.
Ìrànlọ́wọ́ Wà Lárọ̀ọ́wọ́tó
Tóo bá ní ìrẹ̀wẹ̀sì díẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, o lè rí i pé ara yóò tù ọ́ tóo bá sinmi dáadáa tàbí tóo bá jẹ oúnjẹ kan tó ń fára lókun. Nathan H. Knorr, ẹni tó sìn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà títí ó fi kú ní 1977, sọ nígbà kan rí pé àwọn ìṣòrò ńlá sábà máa ń dà bíi pé kò ju kékeré mọ́ lẹ́yìn téèyàn bá ti sùn dáadáa lóru. Àmọ́ ṣá o, tó bá wá di pé ìṣòro náà kọ̀ tí kò fẹ́ lọ, oorun lásán lè máà tó láti yanjú rẹ̀—wàá nílò ìrànlọ́wọ́ láti gbógun ti ìrẹ̀wẹ̀sì nígbà yẹn.
Jèhófà rán áńgẹ́lì kan láti fún Èlíjà lókun. Lóde òní, Ọlọ́run ń pèsè ìṣírí nípasẹ̀ àwọn alàgbà àti àwọn Kristẹni mìíràn tó dàgbà dénú. Ní ti tòótọ́, àwọn alàgbà lè “dà bí ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù.” (Aísáyà 32:1, 2) Àmọ́ tóo bá fẹ́ rí ìṣírí gbà látọ̀dọ̀ wọn, ó lè di dandan fún ọ láti lo ìdánúṣe. Bí Èlíjà ṣe rẹ̀wẹ̀sì tó yẹn, ó rin ìrìn àjò lọ sí Òkè Hórébù láti gba ìtọ́ni lọ́dọ̀ Jèhófà. A ń rí àwọn ìtọ́ni afúnnilókun gba nípasẹ̀ ìjọ Kristẹni.
Nígbà táa bá gba ìrànwọ́, táa sì fi tìgboyàtìgboyà kojú àwọn àdánwò, irú bíi kí ọkàn ẹni gbọgbẹ́ tàbí kéèyàn pàdánù àwọn àǹfààní kan, ńṣe la ń fi hàn pé ìhà ọ̀dọ̀ Jèhófà la wà nínú ọ̀ràn pàtàkì kan. Ọ̀ràn wo? Sátánì ṣe àwáwí pé kìkì nítorí ire tara wọn làwọn èèyàn ṣe ń sin Jèhófà. Sátánì kò sọ pé a kò ní sin Ọlọ́run nígbà tí gbogbo nǹkan bá ń lọ déédéé fún wa, àmọ́ ó sọ pé a kò ní sin Ọlọ́run mọ́ nígbà táa bá kó sínú ìṣòro. (Jóòbù, orí kìíní àti ìkejì) Bí a bá ń bá iṣẹ́ ìsìn Jèhófà nìṣó láìka ìrẹ̀wẹ̀sì èyíkéyìí táa lè ní sí, a óò lè ṣèrànwọ́ láti já Èṣù nírọ́ ẹ̀sùn ìbanilórúkọjẹ́ tó fi kàn Ọlọ́run.—Òwe 27:11.
Hánà, Máàkù, àti Èlíjà ní àwọn ìṣòrò tó bà wọ́n nínú jẹ́ fúngbà díẹ̀. Àmọ́, wọ́n borí àwọn ìṣòro wọn, wọ́n si gbé ìgbésí ayé tó nítumọ̀. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, ìwọ náà lè borí ìrẹ̀wẹ̀sì!