Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì
12 Ní àkókò yẹn, Ọba Hẹ́rọ́dù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe inúnibíni sí àwọn kan nínú ìjọ.+ 2 Ó fi idà+ pa Jémíìsì arákùnrin Jòhánù.+ 3 Nígbà tó rí i pé ó dùn mọ́ àwọn Júù nínú, ó tún lọ mú Pétérù. (Èyí ṣẹlẹ̀ nígbà àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú.)+ 4 Ó gbá a mú, ó fi í sẹ́wọ̀n,+ ó sì fi í sábẹ́ ọ̀wọ́ mẹ́rin àwọn oníṣẹ́ àṣegbà tí ọ̀wọ́ kọ̀ọ̀kan ní ọmọ ogun mẹ́rin-mẹ́rin láti máa ṣọ́ ọ, ó ní in lọ́kàn láti mú un wá síwájú* àwọn èèyàn náà lẹ́yìn Ìrékọjá. 5 Nítorí náà, wọ́n fi Pétérù sínú ẹ̀wọ̀n, àmọ́ ìjọ ń gbàdúrà kíkankíkan sí Ọlọ́run nítorí rẹ̀.+
6 Nígbà tó kù díẹ̀ kí Hẹ́rọ́dù mú un jáde, ní òru yẹn, Pétérù ń sùn tòun ti ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ méjì tí wọ́n fi dè é, ó wà láàárín ọmọ ogun méjì, àwọn ẹ̀ṣọ́ tó wà lẹ́nu ilẹ̀kùn sì ń ṣọ́ ilé ẹ̀wọ̀n náà. 7 Àmọ́ wò ó! Áńgẹ́lì Jèhófà* dúró síbẹ̀,+ ìmọ́lẹ̀ kan sì tàn nínú yàrá ẹ̀wọ̀n náà. Ó gbá Pétérù pẹ́pẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́, ó jí i, ó sọ pé: “Dìde kíákíá!” Àwọn ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ náà sì bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.+ 8 Áńgẹ́lì náà sọ fún un pé: “Wọ aṣọ rẹ,* kí o sì wọ bàtà rẹ.” Ó ṣe bẹ́ẹ̀. Níkẹyìn, ó sọ fún un pé: “Gbé aṣọ àwọ̀lékè rẹ wọ̀, kí o sì máa tẹ̀ lé mi.” 9 Ó jáde, ó sì ń tẹ̀ lé e, àmọ́ kò mọ̀ pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ látọwọ́ áńgẹ́lì náà jẹ́ ohun gidi. Àní, ṣe ló rò pé òun ń rí ìran. 10 Wọ́n kọjá ẹ̀ṣọ́ ológun kìíní àti èkejì, wọ́n dé ẹnubodè onírin tó wọnú ìlú náà, ó sì fúnra rẹ̀ ṣí fún wọn. Lẹ́yìn tí wọ́n jáde, wọ́n gba ojú ọ̀nà kan lọ, áńgẹ́lì náà sì kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. 11 Bí Pétérù ṣe wá mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ó sọ pé: “Ní báyìí, mo ti mọ̀ dájú pé Jèhófà* ló rán áńgẹ́lì rẹ̀ láti gbà mí lọ́wọ́ Hẹ́rọ́dù àti lọ́wọ́ gbogbo ohun tí àwọn Júù ń retí pé kó ṣẹlẹ̀.”+
12 Lẹ́yìn tó ti mọ ohun tó ṣẹlẹ̀, ó lọ sí ilé Màríà ìyá Jòhánù tí wọ́n ń pè ní Máàkù,+ níbi tí àwọn díẹ̀ kóra jọ sí, tí wọ́n ń gbàdúrà. 13 Nígbà tó kan ilẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà àbáwọlé, ìránṣẹ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Ródà wá dá a lóhùn. 14 Nígbà tó mọ̀ pé ohùn Pétérù ni, inú rẹ̀ dùn débi pé kò ṣí ilẹ̀kùn náà, àmọ́ ó sáré wọlé, ó sì sọ fún wọn pé Pétérù ló wà lẹ́nu ọ̀nà. 15 Wọ́n sọ fún un pé: “Orí rẹ dà rú.” Àmọ́, ó ń tẹnu mọ́ ọn pé òun ni. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Áńgẹ́lì rẹ̀ ni.” 16 Ṣùgbọ́n Pétérù ò kúrò níbẹ̀, ó ń kan ilẹ̀kùn. Nígbà tí wọ́n ṣílẹ̀kùn, wọ́n rí i, ẹnu sì yà wọ́n. 17 Àmọ́, ó fọwọ́ sọ fún wọn pé kí wọ́n dákẹ́, ó sì sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ bí Jèhófà* ṣe mú un jáde kúrò nínú ẹ̀wọ̀n, ó sọ pé: “Ẹ sọ àwọn nǹkan yìí fún Jémíìsì+ àti àwọn ará.” Lẹ́yìn náà, ó jáde, ó sì rin ìrìn àjò lọ sí ibòmíì.
18 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, arukutu sọ láàárín àwọn ọmọ ogun lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pétérù. 19 Hẹ́rọ́dù fara balẹ̀ wá a, nígbà tí kò rí i, ó da ìbéèrè bo àwọn ẹ̀ṣọ́ náà, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n lọ fìyà jẹ wọ́n;+ ó lọ láti Jùdíà sí Kesaríà, ó sì lo àkókò díẹ̀ níbẹ̀.
20 Inú ń bí i gidigidi* sí àwọn èèyàn Tírè àti Sídónì. Nítorí náà, wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú èrò tó ṣọ̀kan. Lẹ́yìn tí wọ́n sì ti yí Bílásítù tó ń bójú tó ohun tó ń lọ nínú ilé ọba* lérò pa dà, wọ́n bẹ̀bẹ̀ fún àlàáfíà, nítorí ilẹ̀ ọba ló ń pèsè oúnjẹ fún ilẹ̀ wọn. 21 Lọ́jọ́ pàtàkì kan, Hẹ́rọ́dù gbé aṣọ ìgúnwà wọ̀, ó jókòó sórí ìjókòó ìdájọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àsọyé fún gbogbo wọn. 22 Ni àwọn èèyàn tó pé jọ bá bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe pé: “Ohùn ọlọ́run ni, kì í ṣe ti èèyàn!” 23 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, áńgẹ́lì Jèhófà* kọ lù ú, nítorí kò fi ògo fún Ọlọ́run, ìdin* jẹ ẹ́, ó sì kú.
24 Àmọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà* ń gbilẹ̀, ó sì ń tàn kálẹ̀.+
25 Ní ti Bánábà+ àti Sọ́ọ̀lù, lẹ́yìn tí wọ́n ti parí gbogbo iṣẹ́ ìrànwọ́ tí wọ́n ń ṣe ní Jerúsálẹ́mù,+ wọ́n pa dà, wọ́n sì mú Jòhánù+ tí wọ́n tún ń pè ní Máàkù dání.