Ìbùkún Làwọn Àgbàlagbà Jẹ́ Fáwọn Ọ̀dọ́
“Àní títí di ọjọ́ ogbó àti orí ewú, Ọlọ́run, má fi mí sílẹ̀, títí èmi yóò fi lè sọ nípa apá rẹ fún ìran náà, fún gbogbo àwọn tí ń bọ̀, nípa agbára ńlá rẹ.”—SÁÀMÙ 71:18.
1, 2. Ohun wo ló yẹ káwọn àgbàlagbà tó jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run mọ̀, kí la sì fẹ́ gbé yẹ̀ wò báyìí?
ALÀGBÀ kan ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà lọ sọ́dọ̀ arákùnrin àgbàlagbà kan tó jẹ́ ẹni àmì òróró, ó sì kí i pé, “Ẹ ń lẹ́ o bàbá, ṣé àjíǹde ara ń jẹ́?” Arákùnrin náà fèsì pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo lè sáré, mo lè tọ, mo sì lè fò sókè,” ó tiẹ̀ gbìyànjú láti fara ṣàpèjúwe ohun tó ń sọ yẹn. Ó wá fi kún un pé, “Àmọ́, mi o lè fò bí ẹyẹ.” Ohun tó ń sọ yé alàgbà tó ń bá sọ̀rọ̀. Ohun tó ń sọ ni pé, ‘Tayọ̀tayọ̀ ni mo fi ń ṣe àwọn ohun tí mo lè ṣe, àmọ́, mi ò lè ṣe ohun tágbára mi ò gbé.’ Alàgbà tó lọ sọ́dọ̀ bàbá náà ti lé lẹ́ni ọgọ́rin ọdún báyìí, inú rẹ̀ sì máa ń dùn nígbà tó bá ń rántí bí arákùnrin yẹn ṣe máa ń pani lẹ́rìn-ín tó sì tún jẹ́ adúróṣinṣin.
2 Tí àgbàlagbà kan bá hùwà lọ́nà tó fi hàn pé ó ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, ìyẹn lè nípa tó lágbára lórí àwọn mìíràn. Àmọ́ ṣá o, pé ẹnì kan dàgbà lọ́jọ́ orí kò túmọ̀ sí pé ẹni náà á ṣàdédé ní ọgbọ́n àti irú àwọn ànímọ́ tí Kristi ní. (Oníwàásù 4:13) Bíbélì sọ pé: “Orí ewú jẹ́ adé ẹwà nígbà tí a bá rí i ní ọ̀nà òdodo.” (Òwe 16:31) Tó o bá ti dàgbà lọ́jọ́ orí, ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwọn ọ̀rọ̀ tó ò ń sọ àtàwọn ìṣe rẹ lè nípa tó dára lórí àwọn ẹlòmíràn? Wo àwọn àpẹẹrẹ bíi mélòó kan nínú Bíbélì tó jẹ́ ká rí i báwọn àgbàlagbà ṣe jẹ́ ojúlówó ìbùkún fáwọn ọ̀dọ́.
Ìgbàgbọ́ Nóà Ṣàǹfààní Gan-An
3. Báwo ni ìṣòtítọ́ Nóà ṣe nípa lórí gbogbo àwọn tó wà láàyè nísinsìnyí?
3 Ìgbàgbọ́ àti ìdúróṣinṣin Nóà ṣàǹfààní gan-an, kódà ó ṣì ń ṣàǹfààní dòní olónìí. Nóà ti ń sún mọ́ ẹni ẹgbẹ̀ta ọdún nígbà tó kan ọkọ̀ áàkì, tó kó àwọn ẹranko sínú rẹ̀, tó sì wàásù fáwọn èèyàn. (Jẹ́nẹ́sísì 7:6; 2 Pétérù 2:5) Nítorí pé Nóà bẹ̀rù Ọlọ́run, òun àti ìdílé rẹ̀ la Ìkún-omi já, ó si di baba ńlá fún gbogbo èèyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé lónìí. Lóòótọ́, àkókò tí ẹ̀mí àwọn èèyàn máa ń gùn gan-an ni Nóà gbé láyé. Síbẹ̀, ó jẹ olóòótọ́ sí Ọlọ́run títí dìgbà tó darúgbó kùjọ́kùjọ́, ìyẹn sì yọrí sáwọn ìbùkún àrà ọ̀tọ̀ kan. Lọ́nà wo?
4. Ọ̀nà wo ni ìdúróṣinṣin Nóà gbà ń ṣe àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láǹfààní lónìí?
4 Nóà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹni ẹgbẹ̀rin ọdún nígbà tí Nímírọ́dù bẹ̀rẹ̀ sí í kọ Ilé Gogoro Bábélì. Ohun tí Nímírọ́dù ń ṣe yìí sì ta ko àṣẹ tí Jèhófà pa pé káwọn èèyàn “kún ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 9:1; 11:1-9) Àmọ́ Nóà ò lọ́wọ́ sí ọ̀tẹ̀ Nímírọ́dù. Nípa báyìí, ó ṣeé ṣe kí èdè tirẹ̀ má yí padà nígbà tí Ọlọ́run da èdè àwọn ọlọ̀tẹ̀ èèyàn yẹn rú. Ó yẹ kí gbogbo àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run, yálà a jẹ́ ọmọdé tàbí àgbàlagbà, fara wé ìgbàgbọ́ Nóà àti ìdúróṣinṣin rẹ̀. Kì í ṣe ìgbà tó di arúgbó nìkan ló fi àwọn ànímọ́ yìí hàn, ó ṣe bẹ́ẹ̀ jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀.—Hébérù 11:7.
Ipa Tí Ábúráhámù Ní Lórí Ìdílé Rẹ̀
5, 6. (a) Kí ni Jèhófà sọ pé kí Ábúráhámù ṣe nígbà tó wà lẹ́ni ọdún márùndínlọ́gọ́rin? (b) Kí ni Ábúráhámù ṣe nígbà tí Ọlọ́run pa àṣẹ yìí fún un?
5 Ipa tí àwọn àgbàlagbà lè ní lórí ìgbàgbọ́ àwọn tó wà nínú ìdílé wọn la rí nínú ìgbésí ayé àwọn baba ńlá tó gbé ayé lẹ́yìn Nóà. Ábúráhámù ti tó ẹni nǹkan bí ọdún márùndínlọ́gọ́rin nígbà tí Ọlọ́run sọ fún un pé: “Bá ọ̀nà rẹ lọ kúrò ní ilẹ̀ rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ àti kúrò ní ilé baba rẹ sí ilẹ̀ tí èmi yóò fi hàn ọ́; èmi yóò sì mú orílẹ̀-èdè ńlá jáde lára rẹ, èmi yóò sì bù kún ọ.”—Jẹ́nẹ́sísì 12:1, 2.
6 Ìwọ fojú inú wò ó ná, ká ní wọ́n sọ fún ọ pé kó o fi ilé rẹ sílẹ̀, kó o fáwọn ọ̀rẹ́ rẹ sílẹ̀, kó o kúrò nílùú tí wọ́n ti bí ọ, kó o fi gbogbo àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ sílẹ̀, kó o wá forí lé orílẹ̀-èdè tí o kò mọ̀. Ohun tí Ọlọ́run ní kí Ábúráhámù ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn. Ó sì “lọ gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti sọ fún un,” bó ṣe dẹni tó ń gbénú àgọ́ ní gbogbo ìyókù ìgbésí ayé rẹ̀ nìyẹn, tó sì ń ṣí kiri gẹ́gẹ́ bí àjèjì nílẹ̀ Kénáánì. (Jẹ́nẹ́sísì 12:4; Hébérù 11:8, 9) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ti sọ pé Ábúráhámù yóò di “orílẹ̀-èdè ńlá,” síbẹ̀ ó ti kú tipẹ́ kó tó di pé àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ di púpọ̀. Sárà, ìyàwó rẹ̀ ò bí ju ọmọ kan ṣoṣo fún un, ìyẹn Ísákì, ẹ̀yìn ìgbà tí Ábúráhámù sì ti ṣe àtìpó ní ilẹ̀ ìlérí fún ọdún márùndínlọ́gbọ̀n ni ìyàwó rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ bí ọmọ náà. (Jẹ́nẹ́sísì 21:2, 5) Síbẹ̀, Ábúráhámù ò jẹ́ kí irú ìgbésí ayé yẹn sú òun kó sì padà síbi tó ti wá. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tó lágbára gan-an àti ìfaradà nìyẹn jẹ́ fún wa!
7. Ipa wo ni ìfaradà Ábúráhámù ní lórí Ísákì ọmọ rẹ̀, kí sì nìyẹn yọrí sí fún ìràn èèyàn?
7 Ìfaradà Ábúráhámù yìí ní ipa tó lágbára gan-an lórí Ísákì ọmọ rẹ̀. Ísákì fi gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀, ìyẹn ọgọ́sàn-án ọdún, jẹ́ àtìpó nílẹ̀ Kénáánì. Ìgbàgbọ́ tí Ísákì ní nínú ìlérí Ọlọ́run ló jẹ́ kó ní ìfaradà, àwọn òbí rẹ̀ tó jẹ́ àgbàlagbà ló sì gbin ìgbàgbọ́ yìí sí i lọ́kàn. Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà fúnra rẹ̀ wá sọ nígbà tó yá tún jẹ́ kí ìgbàgbọ́ yìí túbọ̀ jinlẹ̀ sí i lọ́kàn rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 26:2-5) Ìdúróṣinṣin Ísákì kó ipa pàtàkì gan-an nínú ìmúṣẹ ìlérí Jèhófà, pé “irú ọmọ” kan tí a ó tipasẹ̀ rẹ̀ bù kún gbogbo ayé yóò wá látinú ìdílé Ábúráhámù. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn, Jésù Kristi, tó jẹ́ olórí “irú-ọmọ” náà ṣí ọ̀nà sílẹ̀ kí gbogbo àwọn tó fi hàn pé àwọn nígbàgbọ́ nínú rẹ̀ lè padà bá Ọlọ́run rẹ́ kí wọ́n sì ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Gálátíà 3:16; Jòhánù 3:16.
8. Báwo ni Jékọ́bù ṣe fi hàn pé ìgbàgbọ́ òun lágbára, kí sì ni àbájáde rẹ̀?
8 Ísákì náà ran Jékọ́bù ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ láti nígbàgbọ́ tó lágbára, èyí tó jẹ́ kí Jékọ́bù lè jẹ́ olóòótọ́ títí dọjọ́ ogbó rẹ̀. Ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún ni Jékọ́bù nígbà tó bá áńgẹ́lì kan jà ní gbogbo òru kó bàa lè rí ìbùkún gbà. (Jẹ́nẹ́sísì 32:24-28) Kó tó di pé Jékọ́bù kú lẹ́ni ọdún mẹ́tàdínláàádọ́jọ [147], ó sapá láti súre fún àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjìlá lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fún un. (Jẹ́nẹ́sísì 47:28) Àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ, èyí tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 49:1-28 sì rí bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, kódà wọ́n ṣì ń nímùúṣẹ di bá a ti ń sọ̀rọ̀ yìí.
9. Kí la lè sọ nípa bí àwọn àgbàlagbà tí wọ́n jẹ́ ẹni tẹ̀mí ṣe máa ń nípa lórí ìdílé wọn?
9 Láìsí àní-àní, àwọn arúgbó tó jẹ́ olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run lè ní ipa tó dára gan-an lórí àwọn tó wà nínú ìdílé wọn. Ìtọ́ni inú Ìwé Mímọ́, pa pọ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n àti àpẹẹrẹ ẹni kàn tó ní ìfaradà lè ran ọ̀dọ́ kan lọ́wọ́ gan-an láti jẹ́ ẹni tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára bó ti ń dàgbà. (Òwe 22:6) Àwọn àgbàlagbà ò gbọ́dọ̀ fojú kéré ipa rere tí wọ́n lè ní lórí ìdílé wọn.
Àwọn Àgbàlagbà Lè Nípa Lórí Àwọn Tí Wọ́n Jọ Ń Jọ́sìn
10. Kí ni Jósẹ́fù ‘pa láṣẹ nípa àwọn egungun rẹ̀,’ ipa wo nìyẹn sì ní lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?
10 Àwọn àgbàlagbà tún lè ní ipa rere lórí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́. Nígbà tí Jósẹ́fù ọmọ Jékọ́bù ti di arúgbó, ó ṣe ohun kan wẹ́rẹ́ tó fi hàn pé ó nígbàgbọ́, ìyẹn sì nípa tó lágbára lórí ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn olùjọsìn tòótọ́ tó gbé ayé lẹ́yìn rẹ̀. Ẹni àádọ́fà ọdún ni nígbà tó “pa àṣẹ nípa àwọn egungun rẹ̀,” pé nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá máa kúrò nílẹ̀ Íjíbítì níkẹyìn, kí wọ́n kó egungun òun dání lọ. (Hébérù 11:22; Jẹ́nẹ́sísì 50:25) Àṣẹ tó pa yẹn túbọ̀ fi àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́kàn balẹ̀ ní gbogbo ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n fi jẹ́ ẹrú lẹ́yìn ikú Jósẹ́fù, wọ́n mọ̀ dájú pé ìdáǹdè àwọn ń bọ̀.
11. Ipa wo ló ṣeé ṣe kí Mósè tó jẹ́ arúgbó ní lórí Jóṣúà?
11 Ọ̀kan lára àwọn tó rí ìṣírí gbà látinú ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ tí Jósẹ́fù sọ yẹn ni Mósè. Nígbà tí Mósè wà lẹ́ni ọgọ́rin ọdún, ó láǹfààní láti kó egungun Jósẹ́fù kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì. (Ẹ́kísódù 13:19) Àkókò yẹn ló mọ Jóṣúà tó kéré sí i lọ́jọ́ orí. Ogójì ọdún gbáko lẹ́yìn ìyẹn ni Jóṣúà fi jẹ́ ìránṣẹ́ fún Mósè. (Númérì 11:28) Ó tẹ̀ lé Mósè dé Òkè Sínáì, ó sì dúró de Mósè títí tó fi sọ kalẹ́ láti orí òkè tó ti lọ gba àwọn wàláà Gbólóhùn Ẹ̀rí. (Ẹ́kísódù 24:12-18; 32:15-17) Ẹ ò rí i pé ìmọ̀ràn àti ọgbọ́n tí Mósè tó jẹ́ arúgbó tó sì tún nírìírí gan-an ti ní láti fún Jóṣúà á ga lọ́lá!
12. Báwo ni Jóṣúà ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ tó dára fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀?
12 Jóṣúà náà tún jẹ́ ìṣírí fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní gbogbo ìgbà tó fi wà láàyè. Ìwé Àwọn Onídàájọ́ 2:7 sọ fún wa pé: “Àwọn ènìyàn náà sì ń bá a lọ láti sin Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ Jóṣúà àti ní gbogbo ọjọ́ àwọn àgbà ọkùnrin tí ọjọ́ wọ́n gùn ré kọjá ti Jóṣúà, tí wọ́n sì ti rí gbogbo iṣẹ́ ńlá Jèhófà tí ó ṣe fún Ísírẹ́lì.” Àmọ́, lẹ́yìn tí Jóṣúà àtàwọn àgbà ọkùnrin yòókù kú tán, odindi ọ̀ọ́dúnrún ọdún gbáko làwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi wà láìmọ èyí tí wọ́n máa yàn nínú ìjọsìn tòótọ́ àti ìjọsìn èké, títí fi di ìgbà ayé wòlíì Sámúẹ́lì.
Sámúẹ́lì “Ṣiṣẹ́ Òdodo Yọrí”
13. Kí ni Sámúẹ́lì ṣe láti ‘ṣe iṣẹ́ òdodo yọrí’?
13 Bíbélì ò sọ bí Sámúẹ́lì ṣe dàgbà tó nígbà tó kú, àmọ́ àwọn ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín ọdún méjìlélọ́gọ́rùn-ún [102] ló wà nínú ìwé Sámúẹ́lì Kìíní, èyí tó pọ̀ jù lọ lára wọn ló sì ṣojú Sámúẹ́lì. Ohun tá a kà nínú Hébérù 11:32, 33 ni pé, àwọn onídàájọ́ àtàwọn wòlíì tó jẹ́ adúróṣinṣin “ṣiṣẹ́ òdodo yọrí.” Dájúdájú, Sámúẹ́lì ní ipa tó dára lórí àwọn kan nígbà ayé rẹ̀, tó mú káwọn èèyàn náà yẹra fún ìwà àìtọ́. (1 Sámúẹ́lì 7:2-4) Báwo ló ṣe ṣe é? Ó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà ní gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀. (1 Sámúẹ́lì 12:2-5) Kò bẹ̀rù láti fún àwọn èèyàn nímọ̀ràn tó lágbára, kódà ó fún ọba pàápàá. (1 Sámúẹ́lì 15:16-29) Yàtọ̀ síyẹn, lẹ́yìn tí Sámúẹ́lì ti ‘darúgbó tó sì ti hewú,’ ó fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ nípa bó ṣe máa ń gbàdúrà fáwọn ẹlòmíràn. Ó sọ pé ó jẹ́ ohun tí “kò ṣeé ronú kàn . . . láti ṣẹ̀ sí Jèhófà nípa ṣíṣíwọ́ láti gbàdúrà” fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì bíi tirẹ̀.—1 Sámúẹ́lì 12:2, 23.
14, 15. Báwo làwọn àgbàlagbà òde òní ṣe lè fara wé Sámúẹ́lì nínú ọ̀ràn àdúrà gbígbà?
14 Gbogbo èyí jẹ́ ká rí ọ̀nà pàtàkì kan táwọn àgbàlagbà lè gbà ní ipa tó dára lórí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àìlera tàbí àwọn ipò mìíràn lè fa ìṣòro fáwọn tó ti dàgbà lọ́jọ́ orí, síbẹ̀ wọ́n lè gbàdúrà fáwọn mìíràn. Ẹ̀yin àgbàlagbà, ǹjẹ́ ẹ mọ bí àwọn àdúrà yín ṣe ṣàǹfààní fún ìjọ tó? Nítorí ìgbàgbọ́ tẹ́ ẹ ní nínú ẹ̀jẹ̀ Jésù tó ta sílẹ̀, ẹ wà ní ipò ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Jèhófà, ìfaradà yín sì ti mú kẹ́ ẹ ní ‘ojúlówó’ ìgbàgbọ́ “tí a ti dán wò.” (Jákọ́bù 1:3; 1 Pétérù 1:7) Ẹ má ṣe gbàgbé láé pé: “Ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ olódodo, nígbà tí ó bá wà lẹ́nu iṣẹ́, ní ipá púpọ̀.”—Jákọ́bù 5:16.
15 A nílò àwọn àdúrà tí ẹ̀ ń gbà láti ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ Ìjọba Jèhófà. Àwọn kan lára àwọn arákùnrin wa wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n nítorí pé wọn ò dá sí ọ̀ràn ìṣèlú tàbí ogun. Àjálù ti bá àwọn kan, àwọn kan sì wà níbi táwọn ogun ńlá tàbí ogun abẹ́lé ti ń jà. Bẹ́ẹ̀ làwọn kan tún wà nínú ìjọ tiwa gan-an tí wọ́n ń kojú ìdẹwò tàbí àtakò. (Mátíù 10:35, 36) Àwọn tó ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù àtàwọn ìjọ kárí ayé tún nílò àdúrà tẹ́ ẹ̀ ń gbà fún wọn nígbà gbogbo. (Éfésù 6:18, 19; Kólósè 4:2, 3) Ì bá mà dára o, ká ní o lè máa dárúkọ àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ onígbàgbọ́ nígbà tó o bá ń gbàdúrà, bí Epafírásì ti ṣe!—Kólósè 4:12.
Bí Àwọn Àgbàlagbà Ṣe Lè Kọ́ Ìran Tó Ń Bọ̀
16, 17. Àsọtẹ́lẹ̀ wo ló wà nínú Sáàmù 71:18, ọ̀nà wo lèyí sì ti gbà nímùúṣẹ?
16 Àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ lára àwọn “agbo kékeré,” ìyẹn àwọn tí Ọlọ́run pè sí ọ̀run, ti pèsè ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó ṣe pàtàkì gan-an fáwọn tó ń bá wọn kẹ́gbẹ́, ìyẹn àwọn “àgùntàn mìíràn” tí wọ́n nírètí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé. (Lúùkù 12:32; Jòhánù 10:16) Àsọtẹ́lẹ̀ èyí wà nínú Sáàmù 71:18, tó kà pé: “Àní títí di ọjọ́ ogbó àti orí ewú, Ọlọ́run, má fi mí sílẹ̀, títí èmi yóò fi lè sọ nípa apá rẹ fún ìran náà, fún gbogbo àwọn tí ń bọ̀, nípa agbára ńlá rẹ.” Ó wu àwọn tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn láti túbọ̀ dá àwọn àgùntàn mìíràn tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè bójú tó ọ̀pọ̀ nǹkan, kó tó di pé àwọn ẹni àmì òróró wọ̀nyí fi wọ́n sílẹ̀ lọ sọ́run láti dẹni tí Ọlọ́run ṣe lógo pẹ̀lú Jésù Kristi.
17 Ìlànà tí Sáàmù 71:18 sọ nípa dídá “àwọn tí ń bọ̀” lẹ́kọ̀ọ́ la tún lè lò fún àwọn àgùntàn mìíràn tí wọ́n ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ látọ̀dọ̀ àwọn tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn. Jèhófà ti fún àwọn tó dàgbà láǹfààní láti jẹ́rìí nípa òun fáwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń wá sínú ìjọsìn tòótọ́ báyìí. (Jóẹ́lì 1:2, 3) Àwọn àgùntàn mìíràn gbà pé Ọlọ́run bù kún àwọn nítorí àwọn ohun tí wọ́n ti rí kọ́ lọ́dọ̀ àwọn ẹni àmì òróró. Èyí sì tún ń mú káwọn àgùntàn mìíràn máa fi ẹ̀kọ́ inú Ìwé Mímọ́ kọ́ àwọn mìíràn tó fẹ́ sin Jèhófà.—Ìṣípayá 7:9, 10.
18, 19. (a) Àwọn ohun ṣíṣeyebíye wo ni ọ̀pọ̀ àgbàlagbà tó jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà lè sọ fún wa? (b) Kí ló yẹ kó dá àwọn àgbàlagbà tó jẹ́ Kristẹni lójú?
18 Àwọn àgbàlagbà tó jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà, yálà àwọn ẹni àmì òróró tàbí àwọn àgùntàn mìíràn, mọ àwọn ohun pàtàkì tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn. Àwọn díẹ̀ ṣì wà láàyè lára àwọn tó rí “Photo-Drama of Creation” [Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá] nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ fi hàn. Àwọn kan ṣì wà tí wọ́n mọ àwọn arákùnrin tó ń mú ipò iwájú, ìyẹn àwọn tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n lọ́dún 1918. Àwọn kan kópa nínú àwọn ìwàásù tí wọ́n máa ń gbé jáde ní iléeṣẹ́ rédíò Watchtower, ìyẹn WBBR. Ọ̀pọ̀ lè sọ nípa àkókò táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbé ọ̀ràn nípa òmìnira ẹ̀sìn lọ sílé ẹjọ́ láwọn kóòtù gíga jù lọ. Kódà àwọn kan ò fi ìjọsìn tòótọ́ sílẹ̀ nígbà tí wọ́n wà lábẹ́ ìjọba bóofẹ́ bóokọ̀. Dájúdájú, àwọn àgbàlagbà lè sọ nípa bá a ṣe túbọ̀ ń lóye òtítọ́ sí i bí Ọlọ́run ṣe ń ṣí i payá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká jàǹfààní látinú ọ̀pọ̀ ìrírí táwọn àgbàlagbà ní yìí.—Diutarónómì 32:7.
19 Bíbélì rọ àwọn Kristẹni tó jẹ́ àgbàlagbà pé kí wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ rere fáwọn ọ̀dọ́. (Títù 2:2-4) Ó ṣeé ṣe kó o má tíì mọ ipa tí ìfaradà rẹ, àdúrà rẹ, àti ìmọ̀ràn rẹ ń ní lórí àwọn mìíràn báyìí. Kò dájú pé Nóà, Ábúráhámù, Jósẹ́fù, Mósè, àtàwọn yòókù mọ ipa tí ìṣòtítọ́ wọn ní lórí àwọn ìran tó dé lẹ́yìn wọn. Síbẹ̀, àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ àti ìṣòtítọ́ wọn ní ipa tó lágbára gan-an, bẹ́ẹ̀ ni àpẹẹrẹ tirẹ̀ náà yóò ṣe àwọn ọ̀dọ̀ láǹfààní.
20. Àwọn ìbùkún wo ló ń dúró de àwọn tí kò bá jẹ́ kí ìrètí wọn yingin rárá?
20 Yálà o la “ìpọ́njú ńlá” já tàbí o padà wà láàyè nípasẹ̀ àjíǹde, o ò rí i pé ìdùnnú ńlá ló máa jẹ́ láti gbádùn “ìyè tòótọ́”! (Mátíù 24:21; 1 Tímótì 6:19) Fojú inú wo bí nǹkan ṣe máa rí lákòókò Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, nígbà tí Jèhófà yóò mú kí àwọn arúgbó padà di ọ̀dọ́. Dípò kí ara wa máa di hẹ́gẹhẹ̀gẹ, bá a bá ṣe ń jí lójoojúmọ́ la ó máa rí i pé ara wa ń le sí i. Agbára wa á máa pọ̀ sí i, ojú wa á ríran kedere, a ó máa gbọ́rọ̀ dáadáa, a ó sì máa lẹ́wà sí i! (Jóòbù 33:25; Aísáyà 35:5, 6) Àwọn tí Ọlọ́run bù kún láti gbé nínú ayé tuntun rẹ̀ kò ní darúgbó, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n máa wà láàyè títí láé. (Aísáyà 65:22) Nítorí náà, kí gbogbo wa má ṣe jẹ́ kí ìrètí wa yingin rárá, ká sì máa bá a lọ ní fífi gbogbo ọkàn wa sin Jèhófà. Ká jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà yóò mú gbogbo àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ àti pé ohun tó máa ṣe yóò pọ̀ gan-an ju ohunkóhun tá a lè máa retí.—Sáàmù 37:4; 145:16.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Báwo ni ìdúróṣinṣin Nóà tó jẹ́ arúgbó ṣe yọrí sí ìbùkún fún gbogbo aráyé?
• Ipa wo ni ìgbàgbọ́ àwọn baba ńlá ayé ọjọ́un ní lórí àwọn àtọmọdọ́mọ wọn?
• Nígbà tí Jósẹ́fù, Mósè, Jóṣúà, àti Sámúẹ́lì di arúgbó, báwo ni wọ́n ṣe fún àwọn tí wọ́n jọ ń jọ́sìn Ọlọ́run lókun?
• Ogún wo làwọn àgbàlagbà lè fi sílẹ̀ fáwọn ọ̀dọ́?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ìfaradà Ábúráhámù ní ipa tó lágbára gan-an lórí Ísákì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n látọ̀dọ̀ Mósè jẹ́ ìṣírí fún Jóṣúà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Àdúrà táwọn àgbàlagbà bá ń gbà nítorí àwọn ẹlòmíràn lè ṣèrànwọ́ gan-an
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Àwọn ọ̀dọ́ máa ń jàǹfààní gan-an nípa títẹ́tí sí àwọn àgbàlagbà tó jẹ́ olóòótọ́