A Ha Lè Gbẹ́kẹ̀ Lé Ìwé Yìí Bí?
“Mo túbọ̀ ṣàwárí àwọn ẹ̀rí dídánilójú ti ìjójúlówó nínú Bíbélì ju ti ìtàn [ayé] èyíkéyìí mìíràn.”—Alàgbà Isaac Newton, ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí ó jẹ́ olókìkí.1
ǸJẸ́ ìwé yìí—Bíbélì—ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé bí? Ó ha tọ́ka sí àwọn ènìyàn tí wọ́n gbé láyé ní ti gidi, àwọn ibi tí ó wà ní tòótọ́, àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ lóòótọ́ bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí ẹ̀rí wà pé àwọn òǹkọ̀wé tí wọ́n jẹ́ afẹ̀sọ̀-ṣe-nǹkan tí wọ́n sì jẹ́ aláìlábòsí ni ó kọ ọ́. Ẹ̀rí wà. Ọ̀pọ̀ nínú rẹ̀ ni a ti rí nínú ilẹ̀ tí wọ́n rì mọ́, kódà púpọ̀ sí i ju ìwọ̀nyí wà nínú ìwé náà fúnra rẹ̀.
Wíwú Ẹ̀rí Jáde
Àwárí àwọn ohun èlò ìgbàanì tí wọ́n wà ní rírìmọ́lẹ̀ ní àwọn ilẹ̀ tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ti ṣètìlẹ́yìn fún ìpéye Bíbélì ní ti ìtàn àti ní ti àwòrán ojú ilẹ̀. Ṣàgbéyẹ̀wò kìkì mélòó kan lára ẹ̀rí tí àwọn awalẹ̀pìtàn ti wú jáde.
Dáfídì, ọ̀dọ́ olùṣọ́ àgùntàn onígboyà tí ó di ọba Ísírẹ́lì, ni àwọn olùka Bíbélì mọ̀ dáadáa. Orúkọ rẹ̀ fara hàn ní 1,138 ìgbà nínú Bíbélì, gbólóhùn náà “Ilé Dáfídì”—tí ó sábà máa ń tọ́ka sí ìlà ìdílé rẹ̀ tí ń jọba—sì fara hàn ní ìgbà 25. (1 Sámúẹ́lì 16:13; 20:16) Àmọ́, títí di àìpẹ́ yìí, kò sí ẹ̀rí tí ó dájú pé Dáfídì wà yàtọ̀ sí ti inú Bíbélì. Ṣé ẹni àròsọ kan lásán ni Dáfídì jẹ́ ni?
Ní 1993, àwùjọ àwọn awalẹ̀pìtàn kan, tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Avraham Biran jẹ́ aṣáájú wọn, ṣe àwárí yíyanilẹ́nu kan, tí a ròyìn rẹ̀ nínú ìwé agbéròyìnjáde Israel Exploration Journal. Ní ibi tí òkìtì ìgbàanì kan tí a ń pè ní Tel Dan wà ní ìhà àríwá Ísírẹ́lì, wọ́n wú akọ òkúta kan jáde. Àwọn ọ̀rọ̀ bí “Ilé Dáfídì” àti “Ọba Ísírẹ́lì” ni a gbẹ́ sára òkúta náà.2 Àkọlé náà, tí a ṣírò ọjọ́ orí rẹ̀ lọ dé ọ̀rúndún kẹsàn án ṣáájú Sànmánì Tiwa ni a sọ pé ó jẹ́ ara ohun ìrántí ìṣẹ́gun tí àwọn ará Árámù—àwọn ọ̀tá Ísírẹ́lì tí ń gbé níhà ìlà oòrùn—gbé nàró. Èé ṣe tí àkọlé ìgbàanì yí fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀?
Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ kan nínú ìwé àtìgbàdégbà Biblical Archaeology Review tí a gbé karí ìròyìn kan láti ọwọ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n Biran àti ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ Ọ̀jọ̀gbọ́n Joseph Naveh, sọ pé: “Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí a óò rí orúkọ náà, Dáfídì, nínú èyíkéyìí nínú àkọlé ìgbàanì yàtọ̀ sí ti inú Bíbélì.”3a Ohun mìíràn tún wà tí ó gba àfiyèsí nínú àkọlé náà. Gbólóhùn náà, “Ilé Dáfídì,” ni a kọ ní ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo. Ọ̀jọ̀gbọ́n Anson Rainey tí ó jẹ́ ògbógi nínú ọ̀ràn nípa èdè ṣàlàyé pé: “Ohun àfipín ọ̀rọ̀ . . . ni a sábà máa ń yọ sílẹ̀, pàápàá bí àkànpọ̀ náà bá jẹ́ orúkọ ẹni tàbí ti ohun kan tí a mọ̀ dáadáa. Dájúdájú, ‘Ilé Dáfídì’ jẹ́ irú orúkọ bẹ́ẹ̀ tí a ń lò nínú ọ̀ràn ìṣèlú àti ti àwòrán ilẹ̀ ní ìdajì ọ̀rúndún kẹsàn án ṣáájú Sànmánì Tiwa.”5 Nítorí náà, Ọba Dáfídì àti ìlà ìdílé rẹ̀ tí ń jọba ní ó dájú pé a mọ̀ dáadáa ní ayé ìgbàanì.
Nínéfè—ìlú títóbilọ́lá ti Ásíríà tí a mẹ́nu kàn nínú Bíbélì—ha wà ní tòótọ́ bí? Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kọkàndínlógún, àwọn aṣelámèyítọ́ Bíbélì kan kọ̀ láti gbà gbọ́ pé ó rí bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n ní 1849, Alàgbà Austen Henry Layard wú àwókù ààfin Ọba Senakéríbù jáde ní Kuyunjik, ibi tí ó jẹ́ apá kan Nínéfè ìgbàanì. Àwọn aṣelámèyítọ́ ni a tipa báyìí pa lẹ́nu mọ́ lórí kókó yẹn. Ṣùgbọ́n àwọn àwókù wọ̀nyí ní púpọ̀ sí i láti sọ. Lára àwọn ògiri ìyẹ̀wù kan tí a pa mọ́ dáadáa ni àfihàn kan wà tí ń fi hàn bí wọ́n ṣe gba ìlú kan tí a dáàbò bò dáadáa, pẹ̀lú àwọn òǹdè tí a ń tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ lọ́ síwájú ọba kan tí ó gbé sùnmọ̀mí wá bá wọn. Lókè ọba náà ni a kọ àkọlé yìí sí pé: “Senakéríbù, ọba ayé, ọba Ásíríà, ó jókòó sórí ìtẹ́ nîmedu tí ó sì ń ṣàyẹ̀wò àwọn ìkógun (tí a kó) láti Lákíṣì (La-ki-su).”6
Àfihàn àti àkọlé yìí, tí a lè rí ní Ibi Ìkóhun-Ìṣẹ̀ǹbáyé-Sí ti Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa bí Senakéríbù ṣe gba ìlú Júdà náà, Lákíṣì, tí a kọ sínú 2 Àwọn Ọba 18:13, 14. Ní ṣíṣàlàyé lórí ìjẹ́pàtàkì àwárí náà, Layard kọ̀wé pé: “Ta ni ì bá gbà gbọ́ pé a lè rí tàbí pé ó ṣeé ṣe, ṣáájú kí àwọn àwárí wọ̀nyí tó wáyé, pé lábẹ́ òkìtì ilẹ̀ tàbí ti pàǹtí tí ó sàmì sí ibi tí Nínéfè wà, a ó lè rí ìtàn nípa àwọn ogun tí ó wáyé láàárín Hesekáyà [ọba Júdà] àti Senakéríbù, tí a kọ ní ìgbà tí wọ́n wáyé gan-an láti ọwọ́ Senakéríbù fúnra rẹ̀, tí ó sì ń jẹ́rìí sí kúlẹ̀kúlẹ̀ inú àkọsílẹ̀ Bíbélì pàápàá?”7
Àwọn awalẹ̀pìtàn ti wú ọ̀pọ̀ ohun àfipìtàn míràn jáde—ohun èlò amọ̀, àwókù àwọn ilé, àwọn wàláà amọ̀, àwọn ẹyọ owó, àwọn àkọsílẹ̀, àwọn ohun ìrántí, àti àwọn àkọlé—tí ń jẹ́rìí sí ìpéye Bíbélì. Àwọn awalẹ̀ ti walẹ̀ kúrò lórí ìlú àwọn ará Kálídíà náà, Úrì, ìkóríta fún ìṣòwò àti ìsìn níbi tí Ábúráhámù gbé.8 (Jẹ́nẹ́sísì 11:27-31) Ìwé Ìtàn Nábónídọ́sì, tí wọ́n wú jáde ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, ṣàpèjúwe bí Bábílónì ṣe ṣubú sọ́wọ́ Kírúsì Ńlá ní ọdún 539 ṣáájú Sànmánì Tiwa, ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí a sọ nínú Dáníẹ́lì orí 5.9 Àkọlé kan (àfọ́kù èyí tí a pa mọ́ sí Ibi Ìkóhun-Ìṣẹ̀ǹbáyé-Sí ti Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì) tí a rí ní ẹnu ọ̀nà rìbìtì kan ní Tẹsalóníkà ìgbàanì, ní orúkọ àwọn alákòóso ìlú tí a ṣàpèjúwe wọn gẹ́gẹ́ bíi “politarch,” ọ̀rọ̀ kan tí kò sí nínú àwọn ìwé olókìkí àtijọ́ tí a kọ ní èdè Gírí ìkì ṣùgbọ́n tí Lúùkù, òǹkọ̀wé Bíbélì náà, lò.10 (Ìṣe 17:6, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé, NW ) Ìpéye Lúùkù ni a wá tipa èyí dá láre—gẹ́gẹ́ bí ó tí ṣe jẹ́ nínú ọ̀ràn ti àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ mìíràn.—Fi wé Lúùkù 1:3.
Àmọ́ ṣáá o, àwọn awalẹ̀pìtàn kì í fìgbà gbogbo fohùn ṣọ̀kan, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti fífohùnṣọ̀kan pẹ̀lú Bíbélì. Pẹ̀lú ìyẹn náà, Bíbélì ní àwọn ẹ̀rí alágbára nínú ara rẹ̀ pé ó jẹ́ ìwé kan tí a lè gbẹ́kẹ̀ lé.
A Kọ Ọ́ Láìṣàbòsí
Ohun tí àwọn òpìtàn tí kò ṣàbòsí máa ń ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ kì í ṣe kìkì àwọn àjàṣẹ́gun tiwọn nìkan (bí irú àkọsílẹ̀ nípa bí Senakéríbù ṣe gba Lákíṣì) ṣùgbọ́n wọn a máa kọ bí a ṣe ṣẹ́gun àwọn náà pẹ̀lú, kì í ṣe kìkì àwọn àṣeyọrí nìkan ṣùgbọ́n wọn a tún máa kọ àwọn ìkùnà wọn, kì í ṣe kìkì agbára wọn nìkan ṣùgbọ́n wọn a máa kọ àìlera pẹ̀lú. Ó lójú àwọn ìtàn ayé tí ń gbé irú àìṣàbòsí bẹ́ẹ̀ yọ.
Daniel D. Luckenbill ṣàlàyé nípa àwọn òpìtàn ará Ásíríà pé: “Ó sábà máa ń ṣe kedere pé wíwú tí àwọn ọba máa ń fẹ́ wú fùkẹ̀ béèrè pé kí a lo àrékendá nínú ọ̀ràn ti ìpéye ìtàn.”11 Ní ṣíṣàpèjúwe irú “wíwú tí àwọn ọba máa ń fẹ́ wú fùkẹ̀” bẹ́ẹ̀, àkọsílẹ̀ ìtàn Ọba Ashurnasirpal ti Ásíríà fọ́nnu pé: “Mo tóbi lọ́ba, mo ga lọ́lá, a gbé mi ga, mo lágbára ńlá, a bọlá fún mi, a ṣe mí lógo, mo tayọ lọ́lá, alágbára ni mí, mo jẹ́ akíkanjú, aláyà bíi kìnnìún ni mí, akọni sì ni mí!”12 Ìwọ yóò ha gba gbogbo ohun tí o bá kà nínú irú àkọsílẹ̀ ìtàn ọba bẹ́ẹ̀ pé ìtàn pípéye ni bí?
Ní ìyàtọ̀ sí èyí, àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì lo àìṣàbòsí, èyí tí ń tuni lára. Mósè, tí ó jẹ́ aṣáájú Ísírẹ́lì, sọ ojú abẹ níkòó nípa ríròyìn àwọn àìkúnjú-ìwọ̀n arákùnrin rẹ̀, Áárónì, ti arábìnrin rẹ̀ Míríámù, ti àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀, Nádábù àti Ábíhù, àti ti àwọn ènìyàn rẹ̀, àti àwọn àṣìṣe tòun fúnra rẹ̀ pẹ̀lú. (Ẹ́kísódù 14:11, 12; 32:1-6; Léfítíkù 10:1, 2; Númérì 12:1-3; 20:9-12; 27:12-14) Àwọn àṣìṣe rírinlẹ̀ tí Ọba Dáfídì ṣe ni a kò bò mọ́lẹ̀ ṣùgbọ́n a kọ wọ́n sílẹ̀—a sì ṣe ìyẹn nígbà tí Dáfídì ṣì ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba. (2 Sámúẹ́lì, orí 11 àti 24) Mátíù, tí ó kọ ìwé tí ń jẹ́ orúkọ rẹ̀, sọ nípa bí àwọn àpọ́sítélì (ọ̀kan lára àwọn ẹni tí òun jẹ́) ṣe ṣawuyewuye lórí bí olúkúlùkù wọn ṣe jẹ́ pàtàkì sí àti bí wọ́n ṣe fi Jésù sílẹ̀ ní alẹ́ tí wọ́n mú un. (Mátíù 20:20-24; 26:56) Àwọn òǹkọ̀wé àwọn lẹ́tà Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gírí ìkì, fi òtítọ́ inú sọ pé àwọn ìṣòro, tí ó ní ìwà pálapàla àti ìyapa nínú, wà láàárín àwọn ìjọ Kristẹni ìjímìjí. Wọn kò sì fọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀ bí wọ́n ṣe ń bójú tó àwọn ìṣòro wọ̀nyẹn.—1 Kọ́ríńtì 1:10-13; 5:1-13.
Irú ríròyìn láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀ bẹ́ẹ̀ fi àníyàn olótìítọ́ ọkàn fún òtítọ́ hàn. Níwọ̀n bí àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì ti ṣe tán láti ròyìn àwọn ìsọfúnni tí kò buyì kúnni nípa àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́, àwọn ènìyàn wọn, àti ti àwọn fúnra wọn pàápàá, ìdí rere kò ha wà láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn àkọsílẹ̀ wọn bí?
Ó Péye Ní Ti Kúlẹ̀kúlẹ̀
Lọ́pọ̀ ìgbà, nígbà ìyẹ̀wò ẹjọ́ ní kóòtù, ìpinnu ti bóyá ẹlẹ́rìí kan yóò ṣeé gbà gbọ́ ni a lè gbé kárí àwọn kókó ọ̀ràn kéékèèké. Ìfohùnṣọ̀kan lórí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kéékèèké lè fi hàn pé ẹ̀rí náà péye tí ó sì jẹ́ òótọ́, nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn ìtakora tí ó rinlẹ̀ lè fi í hàn gẹ́gẹ́ bí ohun tí a hùmọ̀ rẹ̀. Lọ́wọ́ kejì, àkọsílẹ̀ kan tí a ti tò nigínnigín jù—ọ̀kan tí a to kúlẹ̀kúlẹ̀ tí ó kéré jù lọ sí létòlétò—lè fi hàn pé ó jẹ́ ẹ̀rí èké pẹ̀lú.
Báwo wá ni “ẹ̀rí” àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì ti ṣe sí ní ti èyí? Àwọn tí ó kọ Bíbélì wà ní ìṣọ̀kan délẹ̀ lọ́nà tí ó bùáyà. Ìfohùnṣọ̀kan pẹ́kípẹ́kí wà lórí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kéékèèké pàápàá. Ṣùgbọ́n, kì í ṣe pé wọ́n to àwọn ìbáramu wọ̀nyẹn wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ débi pé yóò ru ìfura ti pé ṣe ni wọ́n dìmọ̀lù sókè. Ó ṣe kedere pé kò sí àhùmọ̀ṣe nínú àwọn ìṣekòńgẹ́ wọ̀nyẹn, ṣe ni àwọn òǹkọ̀wé sábà máa ń fohùn ṣọ̀kan láìpète rẹ̀ bẹ́ẹ̀. Gbé àwọn àpẹẹrẹ mélòó kan yẹ̀ wò.
Òǹkọ̀wé Bíbélì náà Mátíù kọ̀wé pé: “Bí Jésù sì ti wọ inú ilé Pétérù, ó rí ìyá ìyàwó rẹ̀ tí ó dùbúlẹ̀, tí ó sì ṣàìsàn ibà.” (Mátíù 8:14) Níhìn-ín, Mátíù pèsè kúlẹ̀kúlẹ̀ kan tí ó dùn mọ́ni ṣùgbọ́n tí kò pọn dandan, ìyẹn ni pé: Pétérù ní ìyàwó. Pọ́ọ̀lù ti kókó kékeré yìí lẹ́yìn, ẹni tí ó kọ̀wé pé: “Ṣé n kò ní ẹ̀tọ́ láti máa mú aya tí ó jẹ́ Kristẹni káàkiri pẹ̀lú mi ni, gẹ́gẹ́ bí àwọn àpọ́sítélì yòó kù àti . . . Kéfà?”b (1 Kọ́ríńtì 9:5, The New English Bible) Àwọn àyíká ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi hàn pé ṣe ni Pọ́ọ̀lù ń gbèjà ara rẹ̀ lójú lámèyítọ́ tí kò fẹ́. (1 Kọ́ríńtì 9:1-4) Lọ́nà tí ó ṣe kedere, kì í ṣe pé Pọ́ọ̀lù mú kókó kékeré yìí—ti pé Pétérù ní ìyàwó—wọlé láti ti ìpéye àkọsílẹ̀ Mátíù lẹ́yìn ṣùgbọ́n, mímú tí ó mú un jáde kàn ṣe kòńgẹ́ èyí ni.
Gbogbo àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó kọ ìwé Ìhìn Rere—Mátíù, Máàkù, Lúùkù, àti Jòhánù—kọ ọ́ sílẹ̀ pé ní alẹ́ tí wọ́n mú Jésù, ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ yọ idà, ó sì ṣá ẹrú àlùfáà àgbà, ó sì ké etí ọkùnrin náà sọ nù. Kìkì Ìhìn Rere Jòhánù ni ó ròyìn kúlẹ̀kúlẹ̀ tí ó jọ bíi pé kò pọn dandan, pé: “Orúkọ ẹrú náà ni Málíkọ́sì.” (Jòhánù 18:10, 26) Èé ṣe tí ó jẹ́ pé Jòhánù nìkan ni ó sọ orúkọ ọkùnrin náà? Ní ẹsẹ mélòó kan níwájú, àkọsílẹ̀ náà pèsè kókó kékeré kan tí a kò kọ sí ibòmíràn rárá: Jòhánù “jẹ́ ẹni mímọ̀ fún àlùfáà àgbà.” Agbo ilé àlùfáà àgbà náà sì mọ̀ ọ́n pẹ̀lú; ó jẹ́ ojúlùmọ̀ àwọn ìránṣẹ́, òun náà sì mọ̀ wọ́n. (Jòhánù 18:15, 16) Nígbà náà, ó wulẹ̀ bá ìwà ẹ̀dá mu pé kí Jòhánù dárúkọ ẹni tí a ṣe léṣe náà, nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn òǹkọ̀wé Ìhìn Rere yòó kù, tí ọkùnrin náà ṣàjèjì sí kò ṣe bẹ́ẹ̀.
Nígbà míràn, àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé lè máà sí nínú àkọsílẹ̀ kan ṣùgbọ́n tí àkọsílẹ̀ míràn yóò pèsè wọn níbòmíràn nípasẹ̀ àlàyé tí wọ́n kàn ṣáà mẹ́nu kàn. Fún àpẹẹrẹ, àkọsílẹ̀ Mátíù nípa ìjẹ́jọ́ Jésù níwájú Sànhẹ́dírìn àwọn Júù sọ pé àwọn kan lára àwọn tí ó wà níbẹ̀ “gbá a lójú, wọ́n wí pé: ‘Sọ tẹ́lẹ̀ fún wa, ìwọ Kristi. Ta ni ẹni tí ó gbá ọ?’ ” (Mátíù 26:67, 68) Èé ṣe tí wọ́n fi sọ pé kí Jésù “sọ tẹ́lẹ̀” nípa ẹni tí ó gbá a, nígbà tí ẹni tí ó gbá a wà ní ìdúró níwájú rẹ̀? Mátíù kò ṣàlàyé. Ṣùgbọ́n méjì lára àwọn òǹkọ̀wé Ìhìn Rere yòó kù pèsè kúlẹ̀kúlẹ̀ tí kò sí níbẹ̀ yí: Àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí Jésù bo ojú rẹ̀ kí wọ́n tó gbá a. (Máàkù 14:65; Lúùkù 22:64) Mátíù gbé àkọsílẹ̀ tirẹ̀ jáde láìbìkítà nípa bóyá gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ pé síbẹ̀.
Ìhìn Rere Jòhánù sọ nípa àkókò kan tí àwùjọ ńlá kan kóra jọ láti gbọ́ ohun tí Jésù fi ń kọ́ni. Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ náà ṣe sọ, nígbà tí Jésù kíyè sí àwùjọ náà, “ó wí fún Fílípì pé: ‘Níbo ni a óò ti ra ìṣù búrẹ́dì fún àwọn wọ̀nyí láti jẹ?’ ” (Jòhánù 6:5) Nínú gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí ó wà níbẹ̀, ó ṣe jẹ́ Fílípì ni Jésù bi léèrè nípa ibi tí wọ́n ti lè ra búrẹ́dì? Òǹkọ̀wé náà kò sọ. Bí ó ti wù kí ó rí, nínú ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ kan náà, Lúùkù ròyìn pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé ní ìtòsí Bẹtisáídà, ìlú kan tí ó wà ní èbúté ìhà àríwá Òkun Gálílì, bẹ́ẹ̀ kẹ̀ rèé, ṣáájú nínú Ìhìn Rere Jòhánù, ó sọ pé “Fílípì wá láti Bẹtisáídà.” (Jòhánù 1:44; Lúùkù 9:10) Nítorí náà, lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu, Jésù béèrè lọ́wọ́ ẹnì kan tí ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ wà nítòsí. Ìfohùnṣọ̀kan tí ó wá láàárín àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ náà jọni lójú, síbẹ̀ ó ṣe kedere pé kì í ṣe àmọ̀ọ́mọ̀ṣe.
Nínú àwọn ọ̀ràn kan, ṣíṣàì mẹ́nu kan àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan wulẹ̀ fi kún jíjẹ́ tí òǹkọ̀wé Bíbélì náà jẹ́ ẹni tí ó ṣeé gbà gbọ́ ni. Fún àpẹẹrẹ, ẹni tí ó kọ 1 Àwọn Ọba sọ nípa ọ̀gbẹlẹ̀ mímúná kan ní Ísírẹ́lì. Ó múná tó bẹ́ẹ̀ tí ọba kò fi lè rí omi àti koríko tí ó tó láti fi mú kí àwọn ẹṣin àti ìbaaka rẹ̀ wà láàyè. (1 Àwọn Ọba 17:7; 18:5) Síbẹ̀, àkọsílẹ̀ náà ròyìn pé wòlí ì Èlíjà sọ pé kí wọ́n gbé omi tí ó pọ̀ tó láti fi kún yàrà kan tí a wà yípo àyè ilẹ̀ kan tí ó ṣeé ṣe kí ó fẹ̀ tó 1,000 mítà níbùú lóòró wá fún òun (fún lílò nínú ọ̀ràn ìrúbọ kan) lórí Òkè Ńlá Kámẹ́lì. (1 Àwọn Ọba 18:33-35) Ibo ní gbogbo omi náà ti wá nínú ọ̀gbẹlẹ̀ náà? Ẹni tí ó kọ 1 Àwọn Ọba kò wulẹ̀ ṣòpò láti ṣàlàyé. Bí ó ti wù kí ó rí, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń gbé ní Ísírẹ́lì mọ̀ pé Kámẹ́lì wà ní èbúté Òkun Mẹditaréníà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ kan tí a kàn ṣáà mẹ́nu kàn lẹ́yìn èyí nínú àkọsílẹ̀ ìtàn náà ṣe fi hàn. (1 Àwọn Ọba 18:43) Nípa báyìí, àrọ́ọ́wọ́tó ni omi òkun yóò wà. Yàtọ̀ sí ti eléyìí, bí ìwé tí a kọ tòun ti kúlẹ̀kúlẹ̀ yí bá jẹ́ àròsọ kan tí ó wulẹ̀ gbé àwọ̀ òkodoro òtítọ́ wọ̀, èé ṣe tí ẹni tí ó kọ ọ́, tí ó jẹ́ pé, bí ọ̀ràn bá rí báyìí, yóò jẹ́ ògbóǹkangí nínú ìwé irọ́ kíkọ, yóò fi jẹ́ kí irú ìtakora bẹ́ẹ̀ wà nínú ẹsẹ ìwé náà?
Nítorí náà, Bíbélì ha ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé bí? Àwọn awalẹ̀pìtàn ti wú àwọn ohun èlò tí ó pọ̀ tó jáde láti f ìdí òtítọ́ náà múlẹ̀ pé Bíbélì tọ́ka sí àwọn ènìyàn gidi, àwọn ibi tí ó jẹ́ gidi, àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gidi. Ṣùgbọ́n, èyí tí ó tilẹ̀ tún ń wọni lọ́kàn jù bẹ́ẹ̀ lọ ni ẹ̀rí tí a rí nínú Bíbélì fúnra rẹ̀. Àwọn òǹkọ̀wé aláìlẹ́tàn kò dá ẹnikẹ́ni sí—kódà, wọn kò dá ara wọn pàápàá sí—ní ti kíkọ òkodoro òtítọ́ nípa ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Wíwà tí àwọn àkọsílẹ̀ rẹ̀ wà ní ìṣọ̀kan látòkè délẹ̀, títí kan àwọn ibi tí ó ti ṣe kòńgẹ́ láìṣepé a hùmọ̀ rẹ̀ bẹ́ẹ̀, pèsè “ẹ̀rí,” àwọn àmì ṣíṣe kedere pé ó jẹ́ òtítọ́. Pẹ̀lú irú “àwọn ẹ̀rí dídáni lójú ti ìjójúlówó” bẹ́ẹ̀, ní ti tòótọ́, Bíbélì jẹ́ ìwé kan tí ìwọ lè gbẹ́kẹ̀ lé.
[Àwọ̀n àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Lẹ́yìn àwárí náà, Ọ̀jọ̀gbọ́n André Lemaire ròyìn pé àtúnṣe tuntun tí a ṣe sí ìlà kan tí ó bà jẹ́ lára òkúta ìrántí ti Mesha (tí a tún ń pè ní Òkúta Móábù), èyí tí a ṣàwárí rẹ̀ ní 1868, fi hàn pé ó ní ìtọ́ka sí “Ilé Dáfídì” nínú pẹ̀lú.4
b “Pétérù” ni “Kéfà” ní èdè àwọn Júù.—Jòhánù 1:42.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Àfọ́kù tí a rí ní Tel Dan
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Àwòrán ara ògiri ní Asíríà, tí ń fi bí a ṣe gbógun ti Lákíṣì hàn, èyí tí a mẹ́nu kàn nínú 2 Àwọn Ọba 18:13, 14