Ọba Kan Tí Ó Ní Ọrọ̀ àti Ọgbọ́n
O ha lérò pé ọrọ̀ lè mú ọ láyọ̀ bí? Ká ní ẹnì kan fún ọ ní owó tí ó pọ̀ níye, ǹjẹ́ inú rẹ kò ní dùn? Àfàìmọ̀ kí inú rẹ má dùn. O lè bẹ̀rẹ̀ sí ronú lórí bí o ṣe máa ná an.
ÒTÍTỌ́ ni, ohun púpọ̀ rẹpẹtẹ ń bẹ láti rà kí ìgbésí ayé lè túbọ̀ rọni lọ́rùn, kí ó sì gbádùn mọ́ni. Pẹ̀lúpẹ̀lù, owó lè jẹ́ “fún ìdáàbòbò” lọ́wọ́ àwọn ìṣòro àìròtẹ́lẹ̀, bí àìsàn tàbí àìríṣẹ́ṣe.—Oníwàásù 7:12.
Ṣùgbọ́n ìbátan wo ni ó wà láàárín owó àti ayọ̀? Ìwọ ha rò pé níní ọrọ̀ ní ń mú ayọ̀ wá, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti rò? Rírí ìdáhùn sí ìbéèrè wọ̀nyí lè nira nítorí pé ó rọrùn láti ṣírò owó, tàbí láti kà á, ṣùgbọ́n ayọ̀ kò ṣeé ṣírò, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ṣeé kà. O kò lè gbé ayọ̀ sórí ìwọ̀n kí o sì díwọ̀n rẹ̀.
Ní àfikún, ó dà bí ẹni pé àwọn ọlọ́rọ̀ kan láyọ̀, nígbà tí àwọn ọlọ́rọ̀ mìíràn kò sì láyọ̀. Bákan náà ni ọ̀ràn rí ní ti àwọn òtòṣì. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ jù lọ—àní àwọn tí ó tilẹ̀ ní ọrọ̀ nísinsìnyí—gbà gbọ́ pé owó púpọ̀ sí i yóò mú ayọ̀ púpọ̀ sí i wá fún wọn.
Ẹnì kan tí ó kọ̀wé nípa irú nǹkan báwọ̀nyí ni Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí ó ní ọrọ̀ jù lọ láyé. O lè kà nípa bí a ṣe ṣàpèjúwe ọrọ̀ tabua tí ó ní nínú Bíbélì, nínú ìwé Àwọn Ọba Kìíní orí kẹwàá. Fún àpẹẹrẹ, yíjú sí ẹsẹ 14, tí ó kà pé: “Ìwọ̀n wúrà tí ó ń dé sọ́dọ̀ Sólómọ́nì ní ọdún kan sì jẹ́ ọ̀tà-lé-lẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà tálẹ́ńtì wúrà.” Iye yẹn jẹ́ tọ́ọ̀nù 25 wúrà. Lónìí, wúrà tí ó tó yẹn yóò ju 200,000,000 dọ́là, owó U.S.!
Síbẹ̀, kì í ṣe ọrọ̀ nìkan ni Sólómọ́nì ní; Ọlọ́run tún fi ọgbọ́n jíǹkí rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Sólómọ́nì Ọba pọ̀ ní ọrọ̀ àti ọgbọ́n ju gbogbo àwọn ọba yòókù ní ilẹ̀ ayé. Gbogbo ènìyàn ilẹ̀ ayé sì ń wá ojú Sólómọ́nì láti gbọ́ ọgbọ́n rẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi sínú ọkàn-àyà rẹ̀.” (1 Àwọn Ọba 10:23, 24) Àwa náà lè jàǹfààní láti inú ọgbọ́n Sólómọ́nì, níwọ̀n bí àwọn ìwé tí ó kọ ti jẹ́ ara Bíbélì. Ẹ jẹ́ kí a wo ohun tí ó sọ nípa ìbátan tí ó wà láàárín ọrọ̀ àti ayọ̀.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Ẹ̀dà yìí wá láti inú Die Heilige Schrift - Übersetzt von Dr. Joseph Franz von Allioli. Druck und Verlag von Eduard Hallberger, Stuttgart