Ọlọ́run Ha Jẹ́ Ẹni Gidi Sí Ọ Bí?
NÍGBÀ tí ìṣòro tí ń fa ìrora ọkàn bá dé bá ọ, o ha ṣe tán láti tọ Ọlọ́run lọ nínú àdúrà bí? Bí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o ha ń nímọ̀lára pé o ń bá ẹnì gidi kan sọ̀rọ̀ bí?
Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa Baba rẹ̀ ọ̀run, Jésù Kristi wí pé: “Ẹni tí ó rán mi jẹ́ ẹni gidi.” (Jòhánù 7:28) Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ ẹni gidi, gbígbàdúrà sí i sì dà bí yíyíjú sí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kan fún ìrànwọ́ tàbí ìmọ̀ràn. Àmọ́ ṣá o, láti jẹ́ ẹni tí Ọlọ́run ń gbọ́ tirẹ̀, àdúrà wa gbọ́dọ̀ wà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Ìwé Mímọ́ ń béèrè kí ó tó lè ṣètẹ́wọ́gbà. Fún àpẹẹrẹ, a gbọ́dọ̀ fi ìrẹ̀lẹ̀ tọ “Olùgbọ́ àdúrà” lọ nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi.—Sáàmù 65:2; 138:6; Jòhánù 14:6.
Àwọn kan lè rò pé nítorí tí a kò lè rí Ọlọ́run, kì í ṣe ẹni gidi. Lójú tiwọn, ó ṣòro láti mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́. Àní àwọn Kristẹni kan pàápàá, tí wọ́n ti kọ́ nípa àwọn ànímọ́ àgbàyanu tí Ọlọ́run ní, lè wá rí i nígbà mìíràn pé ó ṣòro fún wọn láti mọ bí òun ṣe jẹ́ ẹni gidi tó. Ó ha ti ṣe ọ́ bẹ́ẹ̀ rí bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ní lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mú kí Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ ẹni gidi sí ọ?
Kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́
Ìwọ ha ń kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ déédéé bí? Bí o bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé tó, tí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà sì jinlẹ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà Ọlọ́run yóò ṣe jẹ́ ẹni gidi sí ọ tó. A óò tipa báyìí fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun, yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ‘rí Ẹni tí a kò lè rí.’ (Hébérù 11:6, 27) Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ó ṣe ségesège tàbí tí ó jẹ́ ní ìdákúrekú lè máà ní ipa pàtàkì lórí ìgbàgbọ́ rẹ.
Láti ṣàkàwé: Kí a sọ pé dókítà rẹ sọ fún ọ pé kí ó máa fi oògùn kan pa ohun tí ó sú sí ọ lára, ní ẹ̀ẹ̀mejì lóòjọ́, kí ó lè tètè lọ. Ǹjẹ́ ohun tí ó sú sí ọ lára náà yóò lọ bí ó bá jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kan tàbí ẹ̀ẹ̀mejì lóṣù ni ò ń fi oògùn náà pa á? Kò dájú. Bákan náà, onísáàmù náà fún wa ní “egbòogi” fún ìlera tẹ̀mí. Máa “fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́” ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “tọ̀sán-tòru.” (Sáàmù 1:1, 2) Láti gbádùn àǹfààní tí ń pọ̀ sí i, a ní láti máa lo “egbòogi” náà—ríronú lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ pẹ̀lú ìrànwọ́ àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni.—Jóṣúà 1:8.
Ìwọ yóò ha fẹ́ láti mú kí sáà ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ túbọ̀ máa fúngbàgbọ́ lókun bí? Ìmọ̀ràn kan rèé: Lẹ́yìn kíka orí kan nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tàbí Bíbélì mìíràn tí ó ní atọ́ka, yan ẹsẹ kan tí ó fà ọ́ mọ́ra, kí o sì yẹ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí lábẹ́ rẹ̀ wò. Èyí yóò mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ sunwọ̀n sí i, kò sì sí àní-àní pé ìṣọ̀kan tí ó wà nínú Bíbélì látòkè délẹ̀ yóò wú ọ lórí. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, èyí yóò mú kí Òǹṣèwé náà, Jèhófà Ọlọ́run, túbọ̀ jẹ́ ẹni gidi sí ọ.
Lílo atọ́ka tún lè jẹ́ kí ó mọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì àti ìmúṣẹ wọn dunjú. O ti lè mọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ pàtàkì pàtàkì kan nínú Bíbélì, irú àwọn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìparun Jerúsálẹ́mù láti ọwọ́ àwọn ará Bábílónì. Síbẹ̀, Bíbélì kún fún àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí ó tan mọ́ra àti ìmúṣẹ wọn. Àwọn kan wà tí gbogbo ènìyàn kò mọ̀.
Fún àpẹẹrẹ, ka àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìyà ẹ̀ṣẹ̀ títún Jẹ́ríkò kọ́, kí o sì tún ronú lórí ìmúṣẹ rẹ̀. Jóṣúà 6:26 sọ pé: “Nígbà náà ni Jóṣúà mú kí a kéde ìbúra ní àkókò yẹn gan-an pé: ‘Ègún ni fún ọkùnrin náà níwájú Jèhófà, tí ó bá dìde, tí ó sì tẹ ìlú ńlá yìí dó, àní Jẹ́ríkò. Pẹ̀lú ìpàdánù àkọ́bí rẹ̀ ni kí ó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀, àti pẹ̀lú ìpàdánù àbíkẹ́yìn rẹ̀ ni kí ó gbé àwọn ilẹ̀kùn rẹ̀ nà ró.’” Ìmúṣẹ náà dé ní nǹkan bí 500 ọdún lẹ́yìn náà, nítorí a kà nínú 1 Àwọn Ọba 16:34 pé: “Ní àwọn ọjọ́ [Ọba Áhábù], Híélì ará Bẹ́tẹ́lì kọ́ Jẹ́ríkò. Pẹ̀lú ìpàdánù Ábírámù àkọ́bí rẹ̀ ni ó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀, àti pẹ̀lú ìpàdánù Ségúbù àbíkẹ́yìn rẹ̀ ni ó gbé àwọn ilẹ̀kùn rẹ̀ nà ró, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Jèhófà tí ó sọ nípasẹ̀ Jóṣúà ọmọkùnrin Núnì.”a Ọlọ́run tí ó jẹ́ ẹni gidi nìkan ni ó lè mí sí irú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀, kí ó sì rí i pé wọ́n ní ìmúṣẹ.
Bí o bá ń ka Bíbélì, o lè fẹ́ rí fìn-ín ìdí kókò nípa kókó kan. Fún àpẹẹrẹ, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí ronú nípa iye ọdún tí ó wà láàárín àsọtẹ́lẹ̀ kan àti ìmúṣẹ rẹ̀. Kàkà tí ìwọ yóò fi wulẹ̀ béèrè lọ́wọ́ ẹnì kan, èé ṣe tí ìwọ fúnra rẹ̀ kò sapá láti ṣèwádìí? Pẹ̀lú lílo ṣáàtì àti àwọn àrànṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wá ìdáhùn náà bí ìgbà tí ìwọ bá ń fi aápọn sakun láti lóye àwòrán ilẹ̀ tí ń sọ nípa ibi tí ohun ìṣúra kan wà. (Òwe 2:4, 5) Rírí ìdáhùn náà yóò ní ipa jíjinlẹ̀ lórí ìgbàgbọ́ rẹ, yóò sì mú kí Jèhófà Ọlọ́run túbọ̀ jẹ́ ẹni gidi sí ọ.
Máa Gbàdúrà Déédéé Pẹ̀lú Ìgbóná Ọkàn
Má ṣe gbójú fo ìjẹ́pàtàkì àdúrà àti ìgbàgbọ́. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù béèrè èyí ní tààràtà: “Fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i.” (Lúùkù 17:5) Bí Jèhófà kò bá jẹ́ ẹni gidi sí ọ, èé ṣe tí o kò fi gbàdúrà sí i nípa bí o ṣe nílò ìgbàgbọ́ sí i tó? Fi ìgbọ́kànlé béèrè lọ́wọ́ Baba rẹ ọ̀run fún ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ láti mú kí òun jẹ́ ẹni gidi sí ọ.
Bí ìṣòro kan bá ń jà rànyìn lọ́kàn rẹ, wá àkókò láti sọ ohun tí ń bẹ lọ́kàn rẹ fún Ọ̀rẹ́ rẹ ọ̀run lọ́nà tí ó fi ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ hàn. Nígbà tí ikú Jésù ń sún mọ́lé, ó gbàdúrà lọ́nà gbígbóná janjan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó bẹnu àtẹ́ lu àṣà ìsìn ti gbígbàdúrà gígùn nítorí ṣekárími, ó lo gbogbo òru nínú àdúrà ara ẹni kí ó tó yan àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ 12. (Máàkù 12:38-40; Lúùkù 6:12-16) A tún lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Hánà, tí ó di ìyá wòlíì Sámúẹ́lì. Bí ó ti ń hára gàgà láti ní ọmọkùnrin kan, “ó gbàdúrà lọ títí níwájú Jèhófà.”—1 Sámúẹ́lì 1:12.
Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ni èyí kọ́ wa? Bí o bá retí láti rí ìdáhùn gbà sí àwọn àdúrà rẹ, o gbọ́dọ̀ fi taratara, pẹ̀lú ìgbóná ọkàn gbàdúrà láìsinmi—àmọ́ ṣá o, kí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run. (Lúùkù 22:44; Róòmù 12:12; 1 Tẹsalóníkà 5:17; 1 Jòhánù 5:13-15) Ṣíṣe èyí yóò ṣèrànwọ́ láti mú kí Ọlọ́run jẹ́ ẹni gidi sí ọ.
Ṣàkíyèsí Ìṣẹ̀dá
Àwọn àwòrán tí oníṣọ̀nà kan yà lè fi àkópọ̀ ìwà rẹ̀ hàn. Bákan náà, “àwọn ànímọ́ . . . tí a kò lè rí” ti Jèhófà, Olùṣègbékalẹ̀ àti Ẹlẹ́dàá àgbáyé, ni a ń rí kedere nínú ìṣẹ̀dá. (Róòmù 1:20) Nígbà tí a bá ṣàkíyèsí iṣẹ́ ọwọ́ Jèhófà fínnífínní, a túbọ̀ ń lóye àkópọ̀ ìwà rẹ̀ sí i, ó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ túbọ̀ jẹ́ ẹni gidi sí wa.
Bí o bá ṣe ju wíwulẹ̀ ṣàkíyèsí àwọn ìṣẹ̀dá Ọlọ́run lóréfèé, ìjótìítọ́ àwọn ànímọ́ rẹ̀ yóò túbọ̀ wú ọ lórí gidigidi. Fún àpẹẹrẹ, ìsọfúnni nípa agbára àtifò àwọn ẹyẹ lè mú kí ìmọrírì rẹ fún ọgbọ́n Jèhófà túbọ̀ ga sí i. Bí o bá kà nípa àgbáyé wa, o lè mọ̀ pé Ìṣùpọ̀ Ìràwọ̀ Onírìísí Wàrà, tí yóò gbà tó 100,000 ọdún tí ìmọ́lẹ̀ yóò lò láti lè là á kọjá, jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo péré nínú ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tí ó wà ní gbalasa ojúde òfuurufú. Ìyẹn kò ha tẹ ìjótìítọ́ ọgbọ́n Ẹlẹ́dàá náà mọ́ ọ lọ́kàn bí?
Dájúdájú, ọgbọ́n Jèhófà jẹ́ ohun gidi! Ṣùgbọ́n kí ni ìyẹn túmọ̀ sí fún ọ? Tóò, ó dájú pé kò sí ìṣòro tí ẹnikẹ́ni nínú wa lè mú tọ̀ ọ́ lọ nínú àdúrà tí ó lè sú u. Àní, ìmọ̀ díẹ̀ nípa ìṣẹ̀dá pàápàá lè mú kí Jèhófà túbọ̀ jẹ́ ẹni gidi sí ọ.
Bá Jèhófà Rìn
Ìwọ fúnra rẹ ha lè mọ bí Jèhófà ṣe jẹ́ ẹni gidi tó? Bẹ́ẹ̀ ni, bí ìwọ bá dà bí Nóà, baba ńlá olùṣòtítọ́ náà. Ìgbà gbogbo ni ó ń ṣègbọràn sí Jèhófà, tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí a fi lè sọ pé: “Nóà bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:9) Nóà gbé ìgbésí ayé bí ẹni pé Jèhófà wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ọlọ́run lè jẹ́ ẹni gidi bẹ́ẹ̀ sí ìwọ náà.
Bí o bá ń bá Ọlọ́run rìn, ìwọ yóò gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìlérí inú Ìwé Mímọ́, ìwọ yóò sì hùwà ní ìbámu pẹ̀lú wọn. Fún àpẹẹrẹ, o gba ọ̀rọ̀ Jésù gbọ́ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó . . . ní wíwá ìjọba náà àti òdodo [Ọlọ́run] lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí [àwọn ohun kòṣeémánìí ti ara] ni a ó sì fi kún un fún yín.” (Mátíù 6:25-33) Lóòótọ́, Jèhófà lè má fìgbà gbogbo pèsè ohun tí o nílò lọ́nà tí o retí. Síbẹ̀, nígbà tí ìwọ bá gbàdúrà, tí o sì rí ìrànwọ́ Ọlọ́run, òun yóò wá jẹ́ ẹni gidi sí ọ bí ẹnì kan tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ.
Irú ìbátan tímọ́tímọ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà ń dàgbà bí ẹnì kan bá ṣe ń tẹra mọ́ bíbá Ọlọ́run rìn. Gbé ọ̀ràn Manuela yẹ̀ wò, Ẹlẹ́rìí kan tí ó jẹ́ ará Sípéènì, tí ó ti fara da ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àdánwò. Ó sọ pé: “Nígbàkigbá tí ìdààmú bá bá mi tàbí tí mo bá nílò ìrànlọ́wọ́, ìlànà tí ó wà nínú Òwe 18:10 ni mo máa ń lò. Mo máa ń sá di Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́. Ó ti fìgbà gbogbo jẹ́ ‘ilé gogoro tí ó lágbára’ fún mi.” Manuela lè sọ èyí lẹ́yìn gbígbára lé Jèhófà fún ọdún 36, tí ó sì rí ìtìlẹ́yìn rẹ̀.
Ṣe o ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í fi Jèhófà ṣe ìgbọ́kànlé rẹ ni? Má rẹ̀wẹ̀sì bí ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ kó bá tí ì rí bí ó ṣe fẹ́ kí ó rí. Máa gbé ìgbésí ayé lójoojúmọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń bá Ọlọ́run rìn. Bí o ti ń gbé ìgbésí ayé olóòótọ́, ìwọ yóò wá gbádùn ìbátan tímọ́tímọ́ sí i pẹ̀lú Jèhófà.—Sáàmù 25:14; Òwe 3:26, 32.
Ọ̀nà mìíràn láti bá Ọlọ́run rìn ni láti ri ara rẹ bọnú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Nígbà tí o bá ń lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò ìwàásù Ìjọba náà, ìwọ pẹ̀lú Jèhófà ni ẹ jọ ń ṣiṣẹ́. (1 Kọ́ríńtì 3:9) Mímọ èyí dájú ń ràn ọ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ mú kí Ọlọ́run jẹ́ ẹni gidi sí ọ.
Onísáàmù náà rọni pé: “Yí ọ̀nà rẹ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà, kí o sì gbójú lé e, òun yóò sì gbé ìgbésẹ̀.” (Sáàmù 37:5) Má ṣe gbàgbé láé láti yí gbogbo ẹrù ìnira tàbí àròdùn tí o lè ní lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run. Máa wò ó nígbà gbogbo fún ìrànwọ́ àti ìtọ́sọ́nà. Bí o bá fi tàdúràtàdúrà gbára lé Jèhófà Ọlọ́run, tí o sì fìgbà gbogbo gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá, ọkàn rẹ yóò balẹ̀ nítorí tí o mọ̀ pé òun kò ní kùnà láti dúró tì ọ́. Ọkàn rẹ ha ń balẹ̀ nígbà tí o bá ń mú àníyàn rẹ tọ Jèhófà lọ bí? Yóò rí bẹ́ẹ̀—bí Ọlọ́run bá jẹ́ ẹni gidi sí ọ.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ mìíràn, kà nípa bí a ṣe sàsọtẹ́lẹ̀ bíba pẹpẹ Jéróbóámù jẹ́ nínú 1 Àwọn Ọba 13:1-3. Lẹ́yìn náà, ṣàkíyèsí ìmúṣẹ tí ó wà nínú 2 Àwọn Ọba 23:16-18.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Jẹ́ kí àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ máa fúngbàgbọ́ lókun
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Wá àkókò fún gbígbàdúrà déédéé pẹ̀lú ìgbóná ọkàn
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ṣàkíyèsí bí àwọn ànímọ́ Ọlọ́run ṣe fara hàn nínú ìṣẹ̀dá
[Àwọn Credit Line]
Ẹyẹ Akùnyùnmù: U.S. Fish and Wildlife Service, Washington, D.C./Dean Biggins; ìràwọ̀: Fọ́tò: Ẹ̀tọ́ àdàkọ IAC/RGO 1991, Dr. D. Malin et al, Isaac Newton Telescope, Roque de los Muchachos Observatory, La Palma, Canary Islands