ORÍ KẸWÀÁ
Ó Gbèjà Ìjọsìn Mímọ́
1, 2. (a) Ìpọ́njú wo ló bá àwọn èèyàn Èlíjà? (b) Àwọn wo ni alátakò Èlíjà ní orí Òkè Ńlá Kámẹ́lì?
ÈLÍJÀ ń wo àwọn èrò tó ń bọ̀ lọ́ọ̀ọ́kán bí wọ́n ṣe ń rọ́jú gun Òkè Ńlá Kámẹ́lì bọ̀. Ilẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mọ́ bọ̀ ni o, síbẹ̀ èèyàn lè rí i lára àwọn èèyàn náà pé ìṣẹ́ àti ìyàn ti hàn wọ́n léèmọ̀ kọjá wẹ́rẹwẹ̀rẹ. Wọ́n ti dìdàkudà torí àìrọ̀ òjò láti ọdún mẹ́ta ààbọ̀ sẹ́yìn tí kò jẹ́ kí wọ́n lè jẹunre kánú.
2 Àwọn àádọ́ta-lé-nírínwó [450] wòlíì Báálì ń yan fanda-fanda bọ̀ láàárín àwọn èrò náà. Inú wọn ń ru ṣùù sí Èlíjà tó jẹ́ wòlíì Jèhófà, wọ́n sì kórìíra rẹ̀ gan-an. Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Jèhófà ni Jésíbẹ́lì ayaba ti pa, síbẹ̀ Èlíjà ṣì ń gbógun ti ìjọsìn Báálì. Àmọ́, èrò àwọn àlùfáà Báálì yẹn ni pé ó máa tó sú Èlíjà. Wọ́n lè rò pé kò sí bí ọkùnrin kan ṣoṣo yìí ṣe lè borí àwọn láéláé. (1 Ọba 18:4, 19, 20) Áhábù Ọba pàápàá wá, tòun ti kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun rẹ̀. Òun náà ò sì fẹ́ràn Èlíjà rárá.
3, 4. (a) Kí nìdí tí ẹ̀rù fi lè ba Èlíjà láàárọ̀ ọjọ́ yẹn? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò?
3 Lọ́jọ́ tí gọngọ fẹ́ sọ yẹn, Èlíjà nìkan ṣoṣo gíro ni olùjọsìn Jèhófà láàárín wọn. Bó ṣe ń wò wọ́n bí wọ́n ṣe ń dé síbi ojú ọlọ́mọ ò to yìí, ó mọ̀ pé ohun àrà mériyìírí kan máa tó wáyé láàárín òun èèyàn Ọlọ́run àti àwọn olubi, tí wọ́n á fi mọ ẹni tó jẹ́ Ọlọ́run tòótọ́. Báwo ni ọkàn Èlíjà ṣe máa rí láàárọ̀ ọjọ́ yẹn? Ó ṣeé ṣe kí ẹ̀rù fẹ́ máa bà á, nítorí “ènìyàn tí ó ní ìmọ̀lára bí tiwa” lòun náà. (Ka Jákọ́bù 5:17.) Ohun kan tó dá wa lójú ni pé Èlíjà á túbọ̀ mọ̀ ọ́n lára pé òun nìkan lòun dá wà, torí pé àwọn èèyàn tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run àti ọba wọn tó ti di apẹ̀yìndà, àtàwọn àlùfáà Báálì tó jẹ́ apààyàn ló yí i ká.—1 Ọba 18:22.
4 Àmọ́, kí ló kó ìdààmú yìí bá Ísírẹ́lì? Báwo sì ni ìtàn yìí ṣe kàn ọ́ lónìí? Ẹ jẹ́ ká wo bí Èlíjà ṣe ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, ká sì wo bí a ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ lóde òní.
Ọ̀rọ̀ Náà Dójú Ọ̀gbagadè
5, 6. (a) Èrò wo ló ń da àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láàmú? (b) Àwọn nǹkan wo ni Áhábù Ọba ṣe tó burú jáì lójú Jèhófà?
5 Ọjọ́ pẹ́ tí Èlíjà ti ń rí bí àwọn èèyàn ṣe pa ìjọsìn mímọ́ tó ṣe pàtàkì jù ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àti láàárín àwọn èèyàn rẹ̀ tì, tí wọ́n sì ń tàbùkù rẹ̀, tí kò sì sí ohun tó lè ṣe sí i. Ṣẹ́ ẹ rí i, ó pẹ́ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ń dààmú lórí èrò méjì, tí wọn ò mọ èyí tí wọn ì bá ṣe nínú ìsìn tòótọ́ àti ìsìn èké, ìyẹn ni pé bóyá kí wọ́n máa sin Jèhófà Ọlọ́run nìkan tàbí kí wọ́n kúkú máa bọ òrìṣà bíi tàwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká. Nígbà tó fi máa di ìgbà ayé Èlíjà, ọ̀rọ̀ wọn ti wá burú gan-an.
6 Áhábù Ọba ṣe ohun tó burú jáì lójú Jèhófà. Ó fi Jésíbẹ́lì ọmọ ọba Sídónì ṣaya. Jésíbẹ́lì sì pinnu pé òun á mú kí ìjọsìn Báálì tàn kálẹ̀ nílẹ̀ Ísírẹ́lì, òun á sì pa ìjọsìn Jèhófà rẹ́. Kò sì pẹ́ tí Áhábù fi ń bá Jésíbẹ́lì bọ̀rìṣà. Áhábù kọ́ tẹ́ńpìlì fún Báálì ó sì mọ pẹpẹ fún un, ó sì tún jẹ́ aṣáájú nínú àwọn tó ń tẹrí ba fún òrìṣà yìí.—1 Ọba 16:30-33.
7. (a) Kí nìdí tí ìjọsìn Báálì fi jẹ́ ohun ìríra? (b) Kí nìdí tó fi lè dá wa lójú pé Bíbélì kò ta kora lórí ọ̀rọ̀ bí ọ̀dá tó wáyé nígbà ayé Èlíjà ṣe pẹ́ tó? (Tún wo àpótí.)
7 Kí nìdí tí ìjọsìn Báálì fi jẹ́ ohun ìríra? Ìdí ni pé ó ń mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dẹ́sẹ̀, ó sì ń jẹ́ kí wọ́n kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́. Òkú òǹrorò làwọn olùjọsìn Báálì o, ẹ̀sìn wọn sì kún fún àwọn nǹkan tó ń ríni lára. Ara ohun tí wọ́n ń ṣe nínú ìjọsìn Báálì ni iṣẹ́ aṣẹ́wó nínú tẹ́ńpìlì, ìṣekúṣe nínú ààtò ẹ̀sìn, wọ́n sì ń fi ọmọ rúbọ. Jèhófà gbé ìgbésẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí, ó ní kí Èlíjà sọ fún Áhábù pé òjò kò ní rọ̀ ní ilẹ̀ náà títí dìgbà tí wòlíì Ọlọ́run bá sọ pé kó rọ̀. (1 Ọba 17:1) Ọdún mélòó kan kọjá kí Èlíjà tó tún yọjú sí Áhábù, ó sì sọ fún Áhábù pé kí ó kó àwọn èèyàn àtàwọn wòlíì Báálì jọ sórí Òkè Ńlá Kámẹ́lì.a
Ká sòótọ́, gbogbo nǹkan tí wọ́n kà sí pàtàkì nínú ìjọsìn Báálì làwọn èèyàn ṣì ń ṣe títí dòní
8. Báwo lọ̀rọ̀ nípa ìjọsìn Báálì ṣe kàn wá lóde òní?
8 Báwo lọ̀rọ̀ yìí ṣe kàn wá lóde òní? Àwọn kan lè rò pé ìtàn àtijọ́ ni ọ̀rọ̀ àwọn tó ń bọ Báálì, torí pé kò sí tẹ́ńpìlì tàbí àwọn pẹpẹ Báálì lóde òní. Àmọ́ ìtàn yìí kì í ṣe ìtàn àtijọ́ kan lásán o. (Róòmù 15:4) Ọ̀rọ̀ náà “Báálì” túmọ̀ sí “oníǹkan” tàbí “ọ̀gá.” Jèhófà sọ fáwọn èèyàn rẹ̀ pé òun ni kí wọ́n fi ṣe “báálì” wọn, ìyẹn ọkọ olówó orí wọn. (Aísá. 54:5) Lóde òní, ǹjẹ́ kì í ṣe oríṣiríṣi nǹkan làwọn èèyàn ṣì sọ di ọ̀gá tí wọ́n ń sìn dípò Ọlọ́run Olódùmarè? Lọ́rọ̀ kan ṣá, ohunkóhun táwọn èèyàn bá ń fi ìgbésí ayé wọn lépa ni ọ̀gá wọn, ì báà jẹ́ owó, ipò ọlá, eré ìtura, fàájì, ìbálòpọ̀ tàbí ohun yòówù táwọn èèyàn ń sìn dípò Jèhófà. (Mát. 6:24; ka Róòmù 6:16.) Ká sòótọ́, gbogbo nǹkan tí wọ́n kà sí pàtàkì nínú ìjọsìn Báálì làwọn èèyàn ṣì ń ṣe títí dòní. Nítorí náà, tí a bá ń ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín Jèhófà àti Báálì yìí, yóò jẹ́ ká lè yan ẹni tó bọ́gbọ́n mu pé ká máa sìn.
Báwo Ló Ṣe Jẹ́ Pé Wọ́n Ń “Tiro Lórí Èrò Méjì”?
9. (a) Báwo ni gbígbẹ tí Òkè Ńlá Kámẹ́lì gbẹ táútáú ṣe mú kó jẹ́ ibi tó dáa jù láti táṣìírí ìjọsìn Báálì? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.) (b) Kí ni Èlíjà sọ fún àwọn èèyàn náà?
9 Téèyàn bá wà lórí Òkè Ńlá Kámẹ́lì, èèyàn lè rí ọ̀nà jíjìn rere, ìyẹn láti àfonífojì ọ̀gbàrá Kíṣónì lọ dé Òkun Ńlá (ìyẹn Òkun Mẹditaréníà) tí kò jìnnà sí Òkè Ńlá Kámẹ́lì, títí dé ilẹ̀ olókè ńláńlá ti Lẹ́bánónì tó wà lọ́nà jíjìn lápá àríwá.b Bí oòrùn ṣe wá yọ láàárọ̀ ọjọ́ tí Èlíjà fìpàdé sí yìí, téèyàn bá wo ọ̀ọ́kán, èèyàn á rí i pé gbogbo ilẹ̀ náà ti di ìdàkudà. Ilẹ̀ ọlọ́ràá tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ábúráhámù ti dà bí aṣálẹ̀ tí kò méso jáde. Ìwà òpònú àwọn tó jẹ́ èèyàn Ọlọ́run ti fa oòrùn tó ń mú débi pé ilẹ̀ náà gbẹ táútáú. Bí àwọn èèyàn náà ṣe kóra jọ, Èlíjà sún mọ́ wọn, ó sì wí pé: “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ ó fi máa tiro lórí èrò méjì tí ó yàtọ̀ síra? Bí Jèhófà bá ni Ọlọ́run tòótọ́, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn; ṣùgbọ́n bí Báálì bá ni, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.”—1 Ọba 18:21.
10. Báwo ló ṣe jẹ́ pé àwọn èèyàn Èlíjà ń “tiro lórí èrò méjì tó yàtọ̀ síra,” ohun pàtàkì wo ni wọ́n sì gbàgbé?
10 Kí ni Èlíjà ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé wọ́n ń “tiro lórí èrò méjì tí ó yàtọ̀ síra”? Ohun tó ní lọ́kàn ni pé àwọn èèyàn náà kò mọ̀ pé ọ̀kan ló yẹ káwọn yàn nínú ìjọsìn Jèhófà àti ti Báálì. Wọ́n rò pé àwọn lè máa ṣe ìjọsìn méjèèjì pa pọ̀, kí àwọn máa fi àwọn ètùtù wọn tó ń kóni nírìíra tu Báálì lójú, lẹ́sẹ̀ kan náà kí àwọn máa bẹ Jèhófà Ọlọ́run pé kó ṣojú rere sáwọn. Bóyá wọ́n rò pé Báálì á jẹ́ kí irè oko àwọn dàgbà á sì tún máa bù kún àwọn ohun ọ̀sìn wọn, pé “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun” á sì máa dáàbò bò àwọn lójú ogun. (1 Sám. 17:45) Wọ́n ti gbàgbé ohun pàtàkì kan, ìyẹn ni pé Jèhófà kì í bá ohunkóhun pín ìjọsìn pa pọ̀. Kókó yìí náà ò sì tíì yé ọ̀pọ̀ èèyàn lóde òní. Jèhófà sọ pé òun nìkan la gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn, òun nìkan ló sì yẹ ká máa sìn lóòótọ́. Tá a bá da ìjọsìn èyíkéyìí míì pọ̀ mọ́ ìjọsìn wa, Ọlọ́run kò ní tẹ́wọ́ gbà á. Kódà ìríra ló máa jẹ́ lójú rẹ̀!—Ka Ẹ́kísódù 20:5.
11. Báwo ni ọ̀rọ̀ Èlíjà lórí Òkè Kámẹ́lì ṣe lè mú ká yẹ ara wa wò láti mọ ohun tó gbawájú nígbèésí ayé wa àti ọwọ́ tá a fi mú ìjọsìn wa?
11 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń “tiro lórí èrò méjì” láìmọ èyí tí wọn ì bá ṣe. Wọ́n wá dà bí ẹni tó ń léku méjì lẹ́ẹ̀kan náà. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣe irú àṣìṣe kan náà lóde òní. Wọ́n jẹ́ kí àwọn nǹkan míì di báálì wọn tí wọ́n ń sìn, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ pa ìjọsìn Ọlọ́run tòótọ́ tì. Tí a bá tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ tí Èlíjà sọ fáwọn èèyàn náà pé kí wọ́n yéé ṣiyè méjì, àwa náà á lè yẹ ara wa wò láti mọ ohun tó gbawájú nígbèésí ayé wa àti irú ọwọ́ tá a fi mú ìjọsìn wa.
Ìdánwò Pàtàkì Kan
12, 13. (a) Ìdánwò wo ni Èlíjà dá lábàá? (b) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà bíi ti Èlíjà?
12 Èlíjà wá dábàá ìdánwò kan. Ìdánwò yìí ò le rárá. Ó ní kí àwọn àlùfáà Báálì ṣe pẹpẹ kan, kí wọ́n sì kó àwọn ohun tí wọ́n á fi rúbọ sórí pẹpẹ náà, kí wọ́n wá ké pe òrìṣà wọn pé kó finá sí ẹbọ náà. Èlíjà ní òun náà máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ó wá sọ pé: “Ọlọ́run tòótọ́ tí ó bá fi iná dáhùn ni Ọlọ́run tòótọ́.” Èlíjà kúkú mọ ẹni tó jẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ dáadáa ní tiẹ̀. Ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára débi pé ó gba àwọn wòlíì Báálì yẹn láyè dáadáa kí wọ́n kọ́kọ́ pa gbogbo itú ọwọ́ wọn ná. Torí náà, wọ́n yan akọ màlúù tí wọ́n á fi rúbọ, wọ́n sì lọ sí ìdí pẹpẹ Báálì.c—1 Ọba 18:24, 25.
13 Lóde òní, iṣẹ́ ìyanu kì í sábà wáyé bíi ti àtijọ́. Àmọ́ ṣá, kì í ṣe pé Jèhófà ti yí pa dà o. Àwa náà lè gbẹ́kẹ̀ lé e bíi ti Èlíjà. Bí àpẹẹrẹ, tí àwọn èèyàn kò bá fara mọ́ ohun tí Bíbélì sọ, kò yẹ ká bẹ̀rù láti jẹ́ kí wọ́n sọ èrò ọkàn wọn jáde. Ká wá gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run tòótọ́ bíi ti Èlíjà pé yóò yanjú ọ̀ràn náà. Bá a ṣe lè ṣe é ni pé, ká má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé òye ti ara wa, kàkà bẹ́ẹ̀ ká máa lo Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, èyí tó wà “fún mímú àwọn nǹkan tọ́.”—2 Tím. 3:16.
Èlíjà mọ̀ dájú pé ayédèrú gbáà ni ìjọsìn Báálì, ó sì fẹ́ kí àwọn èèyàn Ọlọ́run fojú ara wọn rí i pé ẹ̀tàn lásánlàsàn ni
14. Báwo ni Èlíjà ṣe fi àwọn wòlíì Báálì ṣe yẹ̀yẹ́? Kí nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀?
14 Àwọn wòlíì Báálì ṣètò ẹbọ tí wọ́n fẹ́ rú, wọ́n sì ń ké pe òrìṣà wọn. Wọ́n ṣáà ń kígbe pé, “Báálì, dá wa lóhùn!” Wọ́n kígbe láti òwúrọ̀ títí di ọ̀sán gangan. Bíbélì sọ pé: “Ṣùgbọ́n kò sí ohùn kankan, kò sì sí ẹnì kankan tí ó dáhùn.” Nígbà tó di ọ̀sán gangan, Èlíjà bẹ̀rẹ̀ sí í fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́, ó sọ fún wọn pé ó ní láti jẹ́ pé ọwọ́ Báálì dí ni kò fi dá wọn lóhùn, àbí ó lọ ṣe ìgbọ̀nsẹ̀, àbí ó ń sùn, tó sì yẹ kó jí. Èlíjà wá sọ fún àwọn ẹlẹ́tàn yẹn pé: “Ẹ ké ní bí ohùn yín ṣe lè ròkè tó.” Èlíjà mọ̀ dájú pé ayédèrú gbáà ni ìjọsìn Báálì, ó sì fẹ́ kí àwọn èèyàn Ọlọ́run fojú ara wọn rí i pé ẹ̀tàn lásánlàsàn ni.—1 Ọba 18:26, 27.
15. Báwo ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn àlùfáà Báálì ṣe jẹ́ ká rí i pé ìwà òmùgọ̀ ló jẹ́ láti sọ ohunkóhun di ọ̀gá téèyàn ń sìn yàtọ̀ sí Jèhófà?
15 Kí làwọn àlùfáà Báálì ṣe? Ńṣe lorí wọn túbọ̀ gbóná tí “wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ké ní bí ohùn wọn ṣe lè ròkè tó, wọ́n sì ń fi ọ̀bẹ aláṣóró àti aṣóró gé ara wọn gẹ́gẹ́ bí àṣà wọn, títí wọ́n fi mú kí ẹ̀jẹ̀ ṣàn jáde lára wọn.” Ṣùgbọ́n pàbó ni gbogbo rẹ̀ já sí! Bíbélì ní: “Kò sí ohùn kankan, kò sì sí ẹnì kankan tí ó dáhùn, kò sì sí fífetísílẹ̀.” (1 Ọba 18:28, 29) Ká sòótọ́, kò sí Báálì kan níbì kankan o. Ńṣe ni Sátánì hùmọ̀ rẹ̀ kó bàa lè fi tan àwọn èèyàn kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà. Dájúdájú, ṣe ni ohunkóhun téèyàn bá sọ di ọ̀gá tó ń sìn yàtọ̀ sí Jèhófà máa já a kulẹ̀, táá sì kó ìtìjú bá a.—Ka Sáàmù 25:3; 115:4-8.
Èsì Ìdánwò
16. (a) Kí ni bí Èlíjà ṣe tún pẹpẹ Jèhófà ṣe lórí Òkè Ńlá Kámẹ́lì lè rán àwọn èèyàn náà létí? (b) Báwo ni Èlíjà ṣe túbọ̀ fi hàn pé ó dá òun lójú pé kò sí ohun tí Ọlọ́run ò lè ṣe?
16 Nígbà tó ń sún mọ́ ọwọ́ ìrọ̀lẹ́, ọpọ́n sún kan Èlíjà láti rúbọ. Ó tún pẹpẹ Jèhófà táwọn ọ̀tá ìjọsìn mímọ́ ti ya lulẹ̀ ṣe. Ó fi òkúta méjìlá tún un ṣe bóyá láti lè rán ọ̀pọ̀ nínú ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì létí pé wọ́n ṣì wà lábẹ́ òfin tí Ọlọ́run fún gbogbo ẹ̀yà méjìlá Ísírẹ́lì. Lẹ́yìn náà, Èlíjà wá kó àwọn ohun tí yóò fi rúbọ sórí rẹ̀, ó sì ní kí wọ́n da omi sí i. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Òkun Mẹditaréníà tó wà nítòsí ni wọ́n ti lọ pọn omi náà. Èlíjà tiẹ̀ tún ní kí wọ́n wa yàrà yí pẹpẹ náà ká, kí wọ́n sì pọn omi kún un. Ó gba àwọn wòlíì Báálì láyè dáadáa láti ṣe bó ṣe wù wọ́n o, àmọ́ nígbà tó kan ẹbọ ti Jèhófà, ó da omi sí i kó lè dà bíi pé iná ò ní lè jó o láéláé. Èyí tó fi hàn pé ó dá a lójú gan-an pé kò sóhun tí Ọlọ́run rẹ̀ ò lè ṣe.—1 Ọba 18:30-35.
Àdúrà tí Èlíjà gbà fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀ ṣì jẹ ẹ́ lógún, nítorí ó wù ú kí Jèhófà “yí ọkàn-àyà wọn padà”
17. Báwo ni àdúrà tí Èlíjà gbà ṣe fi ohun tó jẹ ẹ́ lógún hàn? Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Èlíjà tá a bá ń gbàdúrà?
17 Nígbà tí Èlíjà ṣe tán, ó gbàdúrà. Àdúrà náà kò gùn jàn-ànràn jan-anran, àmọ́ ó nítumọ̀, ó sì fi ohun tó jẹ Èlíjà lógún hàn kedere. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó fẹ́ káwọn èèyàn náà mọ̀ pé Jèhófà ni “Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì” kì í ṣe Báálì. Lẹ́yìn náà, ó fẹ́ káwọn èèyàn náà mọ̀ pé ìránṣẹ́ Jèhófà lòun, pé Ọlọ́run ni gbogbo ìyìn àti ògo yẹ. Níkẹyìn, ó fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn òun ṣì jẹ òun lógún, nítorí ó wù ú kí Jèhófà “yí ọkàn-àyà wọn padà.” (1 Ọba 18:36, 37) Pẹ̀lú gbogbo ìnira táwọn èèyàn náà ti fà nítorí àìnígbàgbọ́ wọn, Èlíjà ṣì nífẹ̀ẹ́ wọn. Tí àwa náà bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, ǹjẹ́ à ń gbàdúrà tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀? Ǹjẹ́ à ń fi hàn pé a fẹ́ kí àwọn èèyàn máa gbé orúkọ Ọlọ́run ga, àti pé àánú àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́ ń ṣe wá?
18, 19. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà Èlíjà? (b) Kí ni Èlíjà pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe, kí sì nìdí tí àánú ò fi tọ́ sí àwọn àlùfáà Báálì?
18 Kí Èlíjà tó gbàdúrà, àwọn èèyàn yẹn lè ti máa rò ó pé, ṣé Jèhófà máa dáhùn, àbí tiẹ̀ náà máa dà bíi ti Báálì tó jẹ́ ẹ̀tàn lásánlàsàn? Àmọ́ lẹ́yìn àdúrà Èlíjà, gbogbo wọn rí i pé Jèhófà dáhùn lóòótọ́. Bíbélì sọ pé: “Látàrí ìyẹn, iná Jèhófà já bọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ọrẹ ẹbọ sísun náà àti àwọn igi àti àwọn òkúta àti ekuru náà ní àjẹtán, ó sì lá omi tí ó wà nínú yàrà náà láú.” (1 Ọba 18:38) Ẹ ò rí i pé Jèhófà dáhùn àdúrà yẹn lọ́nà àrà gbáà! Kí làwọn èèyàn náà wá ṣe?
19 Ńṣe ni gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe pé: “Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́! Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́!” (1 Ọba 18:39) Nígbẹ̀yìngbẹ́yín wọ́n mọ ẹni tó jẹ́ Ọlọ́run tòótọ́. Àmọ́ ṣá, wọn ò tíì fi hàn pé àwọn ní ìgbàgbọ́ o. Ká sòótọ́, báwọn èèyàn náà ṣe sọ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́ lẹ́yìn tí wọ́n rí iná tó já bọ́ látọ̀run lẹ́yìn àdúrà Èlíjà, kò fi hàn pé wọ́n ní ojúlówó ìgbàgbọ́. Ìdí nìyí tí Èlíjà fi ní kí wọ́n ṣe ohun míì tó máa fi hàn pé wọ́n nígbàgbọ́. Ó ní kí wọ́n ṣe ohun tó yẹ kí wọ́n ti ṣe láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, ìyẹn ni pé kí wọ́n ṣe ohun tí Òfin Jèhófà wí. Ṣe ni òfin Ọlọ́run sọ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn wòlíì èké àtàwọn abọ̀rìṣà. (Diu. 13:5-9) Àwọn àlùfáà Báálì yìí dìídì sọ ara wọn di ọ̀tá Jèhófà Ọlọ́run, wọ́n sì mọ̀ọ́mọ̀ ń ta ko ète Ọlọ́run. Ǹjẹ́ àánú tọ́ sí wọn? Rárá o. Torí àwọn náà kì í ṣàánú àwọn ọmọ aláìmọwọ́mẹsẹ̀ tí wọ́n ń dáná sun láàyè láti fi rúbọ sí Báálì. (Ka Òwe 21:13; Jer. 19:5) Àánú ò tọ́ sí wọn rárá! Torí náà, Èlíjà pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo wọn, wọ́n sì pa wọ́n.—1 Ọba 18:40.
20. Kí nìdí tí àríwísí àwọn aṣelámèyítọ́ nípa bí Èlíjà ṣe ní kí wọ́n pa àwọn àlùfáà Báálì kò fi lẹ́sẹ̀ nílẹ̀?
20 Lóde òní, àwọn aṣelámèyítọ́ lè máa ṣe àríwísí nípa bí Èlíjà ṣe sọ lórí Òkè Ńlá Kámẹ́lì pé kí wọ́n lọ pa àwọn àlùfáà Báálì. Àwọn kan lè máa wò ó pé àwọn onítara ìsìn lè lo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí láti wí àwíjàre pé kò burú tí àwọn bá ń ja ìjà ẹ̀sìn. Àwọn agbawèrèmẹ́sìn tó ń dá rògbòdìyàn ìsìn sílẹ̀ sì pọ̀ gan-an lóde òní. Àmọ́, Èlíjà kì í ṣe agbawèrèmẹ́sìn ní tiẹ̀. Ohun tó tọ́ ni Èlíjà ṣe, torí iṣẹ́ Jèhófà ló jẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀ pé àwọn kò gbọ́dọ̀ pa àwọn ẹni burúkú bí Èlíjà ti ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n ń tẹ̀ lé ìlànà tí Jésù fi lélẹ̀ fún gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, èyí tó wà nínú ọ̀rọ̀ tí Kristi sọ fún Pétérù pé: “Dá idà rẹ padà sí àyè rẹ̀, nítorí gbogbo àwọn tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.” (Mát. 26:52) Ọjọ́ iwájú ni Jèhófà máa lo Ọmọ rẹ̀ láti mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ lórí àwọn ẹni burúkú.
21. Báwo ni Èlíjà ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ rere tó yẹ kí àwa Kristẹni tòótọ́ lóde òní máa tẹ̀ lé?
21 Ojúṣe Kristẹni kọ̀ọ̀kan ni láti gbé ìgbé ayé tó fi hàn pé ó ní ìgbàgbọ́. (Jòh. 3:16) Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe èyí ni pé ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn èèyàn tó ní ìgbàgbọ́ bí Èlíjà. Jèhófà nìkan ṣoṣo ló sìn, ó sì rọ àwọn yòókù pé Jèhófà nìkan ni kí wọ́n máa sìn. Ó fi ìgboyà jẹ́ kó hàn kedere pé ayédèrú ni ẹ̀sìn tí Sátánì ń lò nígbà yẹn láti fi tan àwọn èèyàn kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà. Èlíjà kò ṣe ìfẹ́ inú ara rẹ̀ kò sì gbára lé agbára rẹ̀, Jèhófà ló gbẹ́kẹ̀ lé pé kó yanjú ọ̀ràn. Láìsí àní-àní, Èlíjà gbèjà ìjọsìn mímọ́. Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa náà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ rẹ̀!
a Wo àpótí náà, “Báwo Ni Ọ̀dá Ìgbà Ayé Èlíjà Ṣe Pẹ́ Tó?”
b Torí pé afẹ́fẹ́ tó ní ọ̀rinrin máa ń fẹ́ wá láti òkun, ó sì máa ń mú kí òjò rọ̀ kí ìrì sì sẹ̀ láyìíká Kámẹ́lì, àwọn ewéko ibẹ̀ sábà máa ń tutù yọ̀yọ̀. Àwọn tó ń bọ Báálì wá ka orí òkè yìí sí ojúbọ pàtàkì, torí wọ́n gbà pé Báálì ló ń rọ̀jò. Àmọ́ ní báyìí tí orí òkè yìí ti wá gbẹ táútáú, ibẹ̀ ló dáa jú láti fìpàdé sí láti lè tú àṣírí ìjọsìn Báálì.
c Ó ṣe pàtàkì bí Èlíjà ṣe sọ fáwọn èèyàn náà pé, “ẹ má fi iná sí” ẹbọ náà. Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé àwọn abọ̀rìṣà yẹn sábà máa ń lo pẹpẹ tó ní ihò ìkọ̀kọ̀ lábẹ́, wọ́n á wá dọ́gbọ́n fi iná sí ihò yẹn kó lè dà bí pé iná ṣẹ́ yọ lọ́nà àrà.