Awọn Irisi-Iran Lati Ilẹ Ileri
Bẹ Ilẹ Naa Wò, Bẹ Awọn Agutan Naa Wò!
ẸGBẸẸGBẸRUN Awọn Kristẹni ti ṣebẹwo si Ilẹ Ileri, ni rironu pe rírí awọn ibi ti awọn iṣẹlẹ ti ṣẹlẹ yoo ran wọn lọwọ lati loye Bibeli, ni mímú ki o tubọ nitumọ sii. Ó sì ti rí bẹẹ.
Yala iwọ ti ṣebẹwo niti gidi tabi iwọ ti ṣebẹwo lọna ironu nipa kika awọn iwe ati ọrọ-ẹkọ nipa ilẹ naa, ki ni nipa bibẹ awọn agutan wò? Iwọ lè ṣe kayeefi pe, ‘Ki ni awọn agutan ni lati ṣe pẹlu Ilẹ Ileri?’ Niti gasikia, awọn agutan fi pupọpupọ jẹ apakan igbesi-aye ni akoko ti a kọ Bibeli debi pe ibẹwo si Ilẹ Ileri, ni ọna kan, jẹ eyi ti kò pé laifi awọn agutan kún un.
Awọn aworan ti o ri nihin-in lè jẹ apakan ibẹwo rẹ, niwọn bi awọn agutan ti a lè ri ni ẹkùn naa lonii ti jọra pupọpupọ pẹlu eyi ti o wọ́pọ̀ ni akoko ti a kọ Bibeli.a Ìrù wọn ti o fẹ̀ ni ó kún fun ọ̀rá. (Lefitiku 7:3; 9:19) Irun agutan ti o lẹ̀ típẹ́típẹ́ mọ́ra naa saba maa ń funfun. Ṣugbọn ranti pe agbo agutan ńlá ti Jakọbu ní “ẹran abilà ati alámì . . . ati gbogbo ẹran pupa rúsúrúsú” ninu.—Jẹnẹsisi 30:32.
Akọsilẹ yii kan naa ṣapejuwe pe ọkunrin kan ti o ni agbo agutan ńlá kan ni a kà sí ọlọ́rọ̀. (Jẹnẹsisi 30:43) A kà nipa Joobu pe: “Ohun ọ̀sìn rẹ̀ si jẹ ẹẹdẹgbarin agutan, ati ẹgbẹẹdogun rakunmi, ati ẹẹdẹgbẹta ajaga maluu, ati ẹẹdẹgbẹta abo kẹtẹkẹtẹ . . . [Ó] sì pọ̀ ju gbogbo awọn ọmọ ara ila-oorun lọ.” (Joobu 1:3; 42:12) Tabi ranti pe Nabali ní 3,000 agutan ati 1,000 ewurẹ. Ki ni o rò pe iduro ati agbara rẹ̀ láwùjọ jẹ́ ni ọjọ Dafidi? (1 Samuẹli 25:2) Ṣugbọn ní pàtó eeṣe ti agbo agutan ńlá fi jẹ́ ọrọ̀ ńlá?
Ó jẹ́ nitori pe awọn agutan pese awọn nǹkan ṣiṣeyebiye fun awọn oluṣọ agutan tabi olówó wọn. Irun agutan funraarẹ jẹ́ ohun àmúṣọrọ̀ ti kii tán. Owe 31:13, 21, 22 ran wa lọwọ lati ri bi aya ọlọgbọn, òṣìṣẹ́ kára ṣe lè lo iru nǹkan bẹẹ lati fi dá aṣọ fun idile rẹ̀ tabi ẹwu ti a lè tà. (Joobu 31:20) Irun agutan jẹ́ ẹrù iṣowo ti o ṣe pataki. Eyi ti a tọka si ninu ọrọ naa pe ọba Moabu “di ẹni ti ń sin agutan ó sì san ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un ọdọ agutan ati ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un akọ agutan ti a kò rẹ́run [wọn] fun ọba Isirẹli.” (2 Ọba 3:4, NW) Bẹẹni, wọn jẹ́ awọn agutan “ti a kò rẹ́run” [wọn]; ọpọ yanturu irun wọn fikun iniyelori wọn.
Akọ agutan, àgbò, lè ni awọn ìwo ti o jọni loju, bi iru eyi ti o wà ninu aworan apá ọ̀tún yii. Eyi ha mu ọ ranti pe ìwo àgbò ni a lò lati kéde Jubili bi? (Lefitiku 25:8-10) Awọn ìwo oníhò ti o jọra ni a lò ni fífọn fèrè igbe ìdágìrì tabi idari ọgbọ́n ogun.—Onidaajọ 6:34; 7:18, 19; Joẹli 2:1.
Lọna ti o yéni, bi iwọ ba ni agbo agutan kan, a mú orisun atijẹ dá ọ loju nitori pe awọn agutan wà lara awọn ẹran ti ó mọ́ ti awọn ọmọ Isirẹli lè jẹ. (Deutaronomi 14:4) Ẹran (ti agutan tabi ọ̀dọ́ agutan) ni a lè bọ̀ tabi yan. Agutan ti a yan jẹ́ ohun ti ó ṣe pataki julọ ninu Ajọ-Irekọja ọdọọdun. (Ẹkisodu 12:3-9) Awọn agutan tun jẹ́ orisun wàrà deedee, ti a ń lò fun mímu, ati fun ṣiṣe wàràkàṣì.—1 Samuẹli 17:17, 18; Joobu 10:10; Aisaya 7:21, 22.
Kò si ibẹwo sọdọ agutan ti yoo pé pérépéré lai ṣakiyesi ìdè timọtimọ ti o wà laaarin agbo agutan ati oluṣọ agutan. Oluṣọ agutan oloootọ bojuto awọn agutan rẹ̀. Gẹgẹ bi Jesu ṣe sọ, wọn yoo dá ohùn oluṣọ agutan wọn mọ̀ wọn yoo sì dahun pada nigba ti o ba ké sí wọn pẹlu orukọ. (Johanu 10:3, 4) Ti ọ̀kan bá sọnu, oluṣọ agutan ti ń fiyesilẹ yoo wá a kiri. Nigba ti o ba rí agutan ti o ti sọnu naa, ó lè gbé e lori èjìká rẹ̀ ki o sì gbé e pada saaarin agbo.—Luuku 15:4, 5.
Dafidi lo iriri araarẹ pẹlu agbo agutan kan nigba ti o fi araarẹ wé agutan ti o ni Jehofa gẹgẹ bi Oluṣọ agutan rẹ̀. Dafidi ni a daabobo, gẹgẹ bi a ti gbeja awọn agutan kuro lọwọ awọn ẹranko ti ń gbéjà kò wọn. Awọn agutan lè tẹle idari oluṣọ agutan wọn ti ń bikita. Bi a bá pa wọn lara, oun yoo wẹ egbò wọn, boya pẹlu ororo itura. Iyatọ gedegede wo ni ó jẹ́ si awọn iṣesi onimọtara-ẹni-nikan ti awọn aṣaaju Isirẹli, ti a ṣapejuwe ni Esekiẹli 34:3-8!
Bibeli ní ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ awọn itọka alasọtẹlẹ ati iṣapẹẹrẹ si agutan. Nitori naa ibẹwo rẹ sọdọ, didojulumọ pẹlu, awọn agutan Ilẹ Ileri lè mu òye rẹ nipa awọn ede isọrọ bii “agbo kekere,” “Ọdọ Agutan Ọlọrun,” ati “awọn agutan miiran,” jinlẹ sii.—Luuku 12:32; Johanu 1:36; 10:16.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Aworan agutan ninu aginju Judia ti ó wà loke yii ni a lè wò kínníkínní ninu 1992 Calendar of Jehovah’s Witnesses.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 24]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 25]
Garo Nalbandian