Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
SEPTEMBER 26–OCTOBER 2
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 1 ÀWỌN ỌBA 15-16
“Jẹ́ Onígboyà Bíi Ti Ásà?”
it-1 184-185
Ásà
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ásà hu àwọn ìwà tó kù díẹ̀ káàtó láwọn ìgbà kan, ìwà rere tí Ásà ní àti bí kò ṣe lọ́wọ́ sí ìbọ̀rìṣà múnú Jèhófà dùn gan-an, wọ́n sì kà á sí ọ̀kan lára àwọn ọba rere tó jẹ ní ìlà ìdílé Júdà. (2Kr 15:17) Ọdún mọ́kànlélógójì (41) ni Ásà fi jọba ní Júdà, àwọn ọba mẹ́jọ ló sì jẹ ní Ísírẹ́lì láàárín àkókò tí Ásà fi jọba. Àwọn ọba mẹ́jọ náà ni, Jèróbóámù, Nádábù, Bááṣà, Élà, Símírì, Ómírì, Tíbínì (òun ló jọba ní apá kan Ísírẹ́lì, ó sì jẹ́ ọ̀tá Ómírì), àti Áhábù. (1Ọb 15:9, 25, 33; 16:8, 15, 16, 21, 23, 29) Nígbà tí Ásà kú, Jèhóṣáfátì ọmọ rẹ̀ di ọba.—1Ọb 15:24.
OCTOBER 17-23
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 1 ÀWỌN ỌBA 21-22
“Fara Wé Bí Jèhófà Ṣe Ń Lo Ọlá Àṣẹ Rẹ̀”
it-2 21
Jèhófà Ọlọ́run Àwọn Ọmọ Ogun
Nígbà tí Jóṣúà wà nítòsí Jẹ́ríkò, áńgẹlì kan tó mú idà lọ́wọ́ yọ sí i, Jóṣúà lọ bá a, ó sì bi í bóyá ó wá láti gbèjà àwọn tàbí àwọn ọ̀tá wọn ló wá gbèjà, áńgélì náà dáhùn pé, “Rárá o, mo wá gẹ́gẹ́ bí olórí àwọn ọmọ ogun Jèhófà.” (Joṣ 5:13-15) Wòlíì Mikáyà sọ fún ọba Áhábù àti Jèhóṣáfátì pé, “Mo rí Jèhófà tó jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀, gbogbo ọmọ ogun ọ̀run sì dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, lápá ọ̀tún àti lápá òsì.” Àwọn ọmọ ogun ọ̀run yìí ń tọ́ka sí àwọn áńgẹ́lì. (1Ọb 22:19-21) Bí wọ́n ṣe lo gbólóhùn náà “Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun” fi hàn pé kì í ṣe ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan péré ni Jèhófà ń darí. Èyí sì bá a mu torí pé Bíbélì mẹ́nu kan ẹgbẹ́ àwọn kérúbù, séráfù àti tàwọn áńgẹ́lì. (Ais 6:2, 3; Jẹ 3:24; Ifi 5:11) Àmọ́, àwọn yìí tún máa ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀, ìdí nìyẹn tí Jésù Kristi fi sọ pé òun “ní àwọn áńgẹ́lì tó ju líjíónì méjìlá (12) lọ” tóun lè pè. (Mt 26:53) Nínú àdúrà tí Hesekáyà gbà pé kí Jèhófà ran àwọn lọ́wọ́, ó pe Jèhófà ní “Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tí o jókòó sórí ìtẹ́ lókè àwọn kérúbù.” Kò sí àní-àní pé àpótí májẹ̀mú táwọn kérúbù wà lórí ìbòrí rẹ̀ ló ń tọ́ka sí, èyí sì ń ṣàpẹẹrẹ ìtẹ́ Jèhófà. (Ais 37:16; fi wé 1Sa 4:4; 2Sa 6:2.) Nígbà tí ẹ̀rù bá ìránṣẹ́ Èlíṣà, Jèhófà mú kó rí ìràn kan tó fi í lọ́kàn balẹ̀. Nínú ìran náà, ó rí “àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun oníná” tí wọ́n jẹ́ ara ẹgbẹ́ ogun Jèhófà tó yí agbègbè olókè tí wọ́n wà ká.—2Ọb 6:15-17.
it-2 245
Irọ́
Jèhófà Ọlọ́run máa ń fàyè gba àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ẹ̀tàn láti “ṣìnà, kí wọ́n lè gba irọ́ gbọ́” dípò kí wọ́n gba ìhìn rere nípa Jésù Kristi. (2Tẹ 2:9-12) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Áhábù ọba Ísírẹ́lì ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn nìyẹn. Àwọn wòlíì èké fi dá Áhábù lójú pé ó máa borí tó bá lọ bá Ramoti-gílíádì jà, àmọ́ Mikáyà tó jẹ́ wòlíì Jèhófà sọ fún un pé kò ní borí tó bá lọ. Nínú ìran tí Mikáyà rí, Jèhófà gbà kí áńgẹ́lì kan di “ẹ̀mí tó ń tanni jẹ” ní ẹnu gbogbo wòlíì Áhábù. Ìyẹn ni pé áńgẹ́lì yìí mú kí àwọn wòlíì náà sọ ohun tó wù wọ́n láti sọ àti ohun tó wu Áhábù láti gbọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wòlíì Jèhófà kìlọ̀ fún Áhábù, ó yàn láti gba irọ́ àwọn wòlíì èké rẹ̀ gbọ́, ẹ̀mí ẹ̀ sì lọ sí i.—1Ọb 22:1-38; 2Kr 18.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-2 697 ¶2
Wòlíì
“Àwọn Ọmọ Wòlíì.” Bí Gesenius’ Hebrew Grammar ṣe sọ (Oxford, 1952, ojú ìwé 418), ọ̀rọ̀ Hébérù náà ben (ọmọ) tàbí benehʹ (ọmọ) lè túmọ̀ sí “ẹni tó wà lára ẹgbẹ́ kan (tàbí ẹ̀yà kan, tàbí àwùjọ kan).” (Fi wé Ne 3:8, níbi tí “ọ̀kan lára àwọn olùpo òróró ìpara” tún ti túmọ̀ sí “ọmọ àwọn olùpo òróró ìpara.”) Torí náà, “àwọn ọmọ wòlíì” lè tọ́ka sí àwùjọ àwọn tó ń gba ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ àwọn wòlíì tàbí kó jẹ́ ẹgbẹ́ àwọn wòlíì tó ń gbé pa pọ̀. Bíbélì mẹ́nu kan irú ẹgbẹ́ àwọn wòlíì bẹ́ẹ̀ ní Bẹ́tẹ́lì, Jẹ́ríkò àti Gílígálì. (2Ọb 2:3, 5; 4:38; fi wé 1Sa 10:5, 10.) Sámúẹ́lì ló jẹ́ olórí ẹgbẹ́ tó wà ní Rámà (1Sa 19:19, 20), Èlíṣà sì jẹ́ olórí ẹgbẹ́ kan nígbà ayé rẹ̀. (2Ọb 4:38; 6:1-3; fi wé 1Ọb 18:13.) Àkọsílẹ̀ Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ẹgbẹ́ yìí máa ń kọ́ ilé tí wọ́n á máa gbé, wọ́n sì yá àwọn irinṣẹ́, tó fi hàn pé ìgbésí ayé ṣe-bó-o-ti-mọ ni wọ́n gbé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n sábà máa ń gbé pa pọ̀, wọ́n sì jọ máa ń pín oúnjẹ wọn, wọ́n lè ní kí èyíkéyìí nínú wọn lọ jíṣẹ́ fáwọn èèyàn.—1Ọb 20:35-42; 2Ọb 4:1, 2, 39; 6:1-7; 9:1, 2.