Àwọn Ọba Kejì
6 Àwọn ọmọ wòlíì+ sọ fún Èlíṣà pé: “Wò ó! Ibi tí à ń gbé lọ́dọ̀ rẹ ti há jù fún wa. 2 Jọ̀ọ́, jẹ́ kí a lọ sí Jọ́dánì. Kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gbé ìtì igi kan níbẹ̀, kí a sì ṣe ibì kan síbẹ̀ tí a lè máa gbé.” Ó sọ pé: “Ẹ lọ.” 3 Ọ̀kan lára wọn sọ pé: “Jọ̀ọ́, ṣé wàá bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ lọ?” Ó fèsì pé: “Màá lọ.” 4 Torí náà, ó bá wọn lọ, nígbà tí wọ́n dé Jọ́dánì, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gé igi. 5 Bí ọ̀kan lára wọn ṣe ń gé igi lọ́wọ́, irin àáké rẹ̀ já bọ́ sínú omi, ó sì kígbe pé: “Áà, ọ̀gá mi, ńṣe la yá a!” 6 Èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ wá bi í pé: “Ibo ló bọ́ sí?” Torí náà, ó fi ibẹ̀ hàn án. Ó wá gé igi kan, ó sọ ọ́ sí ibẹ̀, ó sì mú kí irin àáké náà léfòó. 7 Ó sọ pé: “Mú un jáde.” Torí náà, ó na ọwọ́ rẹ̀, ó sì mú un.
8 Nígbà náà, ọba Síríà jáde lọ láti bá Ísírẹ́lì jà.+ Ó fọ̀rọ̀ lọ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì sọ pé: “Ibi báyìí-báyìí ni a máa dó sí.” 9 Lẹ́yìn náà, èèyàn Ọlọ́run tòótọ́+ ránṣẹ́ sí ọba Ísírẹ́lì pé: “Ṣọ́ra, má ṣe gba ibí kọjá, torí pé àwọn ará Síríà ń bọ̀ wá síbẹ̀.” 10 Nítorí náà, ọba Ísírẹ́lì ránṣẹ́ láti kìlọ̀ fún àwọn tó wà ní ibi tí èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ sọ fún un nípa rẹ̀. Èlíṣà ò yéé kìlọ̀ fún un, ọ̀pọ̀ ìgbà* ni ọba Ísírẹ́lì sì yẹra fún ibẹ̀.+
11 Èyí bí ọba Síríà nínú,* torí náà ó pe àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ sọ fún mi! Ta ló ń gbè sẹ́yìn ọba Ísírẹ́lì lára wa?” 12 Ìgbà náà ni ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ pé: “Kì í ṣe ìkankan lára wa, olúwa mi ọba! Èlíṣà, wòlíì tó wà ní Ísírẹ́lì lẹni tó ń sọ àwọn ohun tí o bá sọ nínú yàrá rẹ fún ọba Ísírẹ́lì.”+ 13 Ọba wá sọ pé: “Ẹ lọ wá ibi tó wà, kí n lè rán àwọn èèyàn lọ mú un.” Nígbà tó yá, wọ́n ròyìn fún un pé: “Ó wà ní Dótánì.”+ 14 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó rán àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ọmọ ogun lọ síbẹ̀; wọ́n lọ síbẹ̀ ní òru, wọ́n sì yí ìlú náà ká.
15 Nígbà tí ìránṣẹ́* èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ dìde ní àárọ̀ kùtù, tí ó sì jáde, ó rí i tí àwọn ọmọ ogun pẹ̀lú àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun yí ìlú náà ká. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ìránṣẹ́ náà sọ fún un pé: “Áà, ọ̀gá mi! Kí la máa ṣe?” 16 Ṣùgbọ́n ó sọ pé: “Má bẹ̀rù!+ Torí pé àwọn tó wà pẹ̀lú wa pọ̀ ju àwọn tó wà pẹ̀lú wọn.”+ 17 Èlíṣà wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà, ó sọ pé: “Jèhófà, jọ̀ọ́, la ojú rẹ̀, kó lè ríran.”+ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jèhófà la ojú ìránṣẹ́ náà, ó sì ríran, wò ó! àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun oníná+ kún agbègbè olókè náà, wọ́n sì yí Èlíṣà ká.+
18 Nígbà tí àwọn ará Síríà náà wá bá a, Èlíṣà gbàdúrà sí Jèhófà, ó sì sọ pé: “Jọ̀ọ́, bu ìfọ́jú lu orílẹ̀-èdè yìí.”+ Nítorí náà, ó bu ìfọ́jú lù wọ́n bí Èlíṣà ṣe béèrè. 19 Èlíṣà wá sọ fún wọn pé: “Ibí kọ́ ni ọ̀nà, ibí kọ́ sì ni ìlú náà. Ẹ tẹ̀ lé mi, ẹ jẹ́ kí n mú yín lọ sọ́dọ̀ ọkùnrin tí ẹ̀ ń wá.” Àmọ́, ó mú wọn lọ sí Samáríà.+
20 Nígbà tí wọ́n dé Samáríà, Èlíṣà sọ pé: “Jèhófà, la ojú wọn kí wọ́n lè ríran.” Nítorí náà, Jèhófà la ojú wọn, wọ́n sì rí i pé àárín Samáríà ni àwọn wà. 21 Nígbà tí ọba Ísírẹ́lì rí wọn, ó sọ fún Èlíṣà pé: “Ṣé kí n pa wọ́n, ṣé kí n pa wọ́n, bàbá mi?” 22 Àmọ́, ó sọ pé: “O ò gbọ́dọ̀ pa wọ́n. Ṣé o máa ń pa àwọn tí o fi idà rẹ àti ọrun rẹ mú lẹ́rú ni? Ṣe ni kí o fún wọn ní oúnjẹ àti omi, kí wọ́n lè jẹ, kí wọ́n mu,+ kí wọ́n sì pa dà sọ́dọ̀ olúwa wọn.” 23 Torí náà, ó se àsè ńlá fún wọn, wọ́n jẹ, wọ́n sì mu, lẹ́yìn náà ó ní kí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ olúwa wọn. Àwọn jàǹdùkú* ilẹ̀ Síríà+ kò sì tún wá sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì mọ́.
24 Lẹ́yìn ìgbà náà, Bẹni-hádádì ọba Síríà kó gbogbo ọmọ ogun* rẹ̀ jọ, ó sì lọ dó ti Samáríà.+ 25 Torí náà, ìyàn ńlá+ kan mú ní Samáríà, wọ́n sì dó tì í títí wọ́n fi ń ta orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́+ kan ní ọgọ́rin (80) ẹyọ fàdákà, ìlàrin òṣùwọ̀n káàbù* imí àdàbà sì di ẹyọ fàdákà márùn-ún. 26 Bí ọba Ísírẹ́lì ṣe ń kọjá lọ lórí ògiri, obìnrin kan ké sí i pé: “Olúwa mi ọba, gbà wá!” 27 Ó fèsì pé: “Bí Jèhófà ò bá gbà ọ́, báwo ni mo ṣe lè gbà ọ́? Ṣé láti ibi ìpakà ni? Àbí láti ibi tí wọ́n ti ń fún wáìnì tàbí òróró?” 28 Ọba wá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ni ìṣòro rẹ?” Ó dáhùn pé: “Obìnrin yìí sọ fún mi pé, ‘Mú ọmọ rẹ wá, kí a lè jẹ ẹ́ lónìí, a ó sì jẹ ọmọ tèmi ní ọ̀la.’+ 29 Torí náà, a se ọmọ mi, a sì jẹ ẹ́.+ Lọ́jọ́ kejì, mo sọ fún un pé, ‘Mú ọmọ rẹ wá kí a lè jẹ ẹ́.’ Àmọ́, ó fi ọmọ rẹ̀ pa mọ́.”
30 Bí ọba ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ obìnrin náà, ó fa aṣọ rẹ̀ ya.+ Nígbà tó sì ń kọjá lọ lórí ògiri, àwọn èèyàn rí i pé ó wọ aṣọ ọ̀fọ̀* sí abẹ́ aṣọ* rẹ̀. 31 Ni ó bá sọ pé: “Kí Ọlọ́run fìyà jẹ mí gan-an, bí orí Èlíṣà ọmọ Ṣáfátì kò bá kúrò lọ́rùn rẹ̀ lónìí!”+
32 Èlíṣà jókòó nínú ilé rẹ̀, àwọn àgbààgbà sì jókòó sọ́dọ̀ rẹ̀. Ọba rán ọkùnrin kan ṣáájú ara rẹ̀, àmọ́ kí òjíṣẹ́ náà tó débẹ̀, Èlíṣà sọ fún àwọn àgbààgbà náà pé: “Ǹjẹ́ ẹ rí bí ọmọ apààyàn+ yìí ṣe ránṣẹ́ pé kí wọ́n wá bẹ́ mi lórí? Ẹ máa ṣọ́nà, tí òjíṣẹ́ náà bá dé, kí ẹ pa ilẹ̀kùn dé, kí ẹ sì di ilẹ̀kùn náà mú kó má bàa ráyè wọlé. Ǹjẹ́ kì í ṣe ìró ẹsẹ̀ olúwa rẹ̀ ló ń dún bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ yẹn?” 33 Bó ṣe ń bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, òjíṣẹ́ náà dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ọba sì sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni àjálù yìí ti wá. Kí nìdí tí màá tún fi dúró de Jèhófà?”