O Ha Mọyì Ètò Àjọ Jèhófà Bí?
“Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: ‘Ọ̀run ni ìtẹ́ mi, ilẹ̀ ayé sì ni àpótí ìtìsẹ̀ mi.’”—AÍSÁYÀ 66:1.
1, 2. (a) Ẹ̀rí wo tí ó fi hàn pé Jèhófà ní ètò àjọ ni o lè tọ́ka sí? (b) Ibo ni Jèhófà ń gbé?
O HA gbà gbọ́ pé Jèhófà ní ètò àjọ kan? Bí o bá gbà bẹ́ẹ̀, èé ṣe? O lè dáhùn pé: ‘Tóò, a ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. A ní ìjọ tí a ṣètò lọ́nà gígún régé, tí ó ní ẹgbẹ́ àwọn alàgbà. A ní alábòójútó àyíká tí a yàn, tí ń bẹ̀ wá wò déédéé. A máa ń lọ sí àwọn àpéjọ àti àwọn àpéjọpọ̀ tí a ṣètò. A ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tí ó jẹ́ ti Watch Tower Society ní orílẹ̀-èdè wa. Dájúdájú, gbogbo èyí àti ọ̀pọ̀ ìdí jaburata mìíràn fi hàn pé Jèhófà ní ètò àjọ kan tí ó gbéṣẹ́.’
2 Irú àwọn apá fífanimọ́ra bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹ̀rí pé ètò àjọ kan ń bẹ. Àmọ́ ṣá o, bí ó bá jẹ́ pé kìkì ètò àjọ ti orí ilẹ̀ ayé níhìn-ín ni a rí tí a sì mọyì, a kò ni òye kíkún nípa ètò àjọ Jèhófà. Jèhófà sọ fún Aísáyà pé àpótí ìtìsẹ̀ Òun ni ilẹ̀ ayé jẹ́, ṣùgbọ́n ọ̀run ni ìtẹ́ Òun. (Aísáyà 66:1) “Ọ̀run” wo ni Jèhófà ń tọ́ka sí? Ṣé afẹ́fẹ́ àyíká wa ni ó ní lọ́kàn? Ṣé gbalasa òfuurufú ni? Àbí àwọn apá ibòmíràn tí ẹ̀dá alààyè ń gbé? Aísáyà sọ nípa “ibùjókòó . . . gíga fíofío ti ìjẹ́mímọ́ àti ẹwà” ti Jèhófà, onísáàmù sì ṣàpèjúwe ọ̀run yìí gẹ́gẹ́ bí “ibi àfìdímúlẹ̀ . . . tí ó ń gbé.” Nípa báyìí, “ọ̀run” tí Aísáyà 66:1 sọ túmọ̀ sí ilẹ̀ àkóso ẹ̀mí tí kò ṣeé fojú rí, níbi tí Jèhófà ti wà ní ipò àjùlọ pátápátá.—Aísáyà 63:15; Sáàmù 33:13, 14.
3. Báwo ni a ṣe lè borí iyèméjì?
3 Nítorí náà, bí a bá fẹ́ mọ ètò àjọ Jèhófà ní tòótọ́, tí a sì fẹ́ mọyì rẹ̀, a gbọ́dọ̀ bojú wo ọ̀run. Ìyẹn gan-an sì ni ìṣòro ọ̀pọ̀lọpọ̀. Níwọ̀n bí ètò àjọ Jèhófà ti òkè ọ̀run kò ti ṣeé fojú rí, báwo ni a ṣe lè mọ̀ pé ó ń bẹ ní ti gidi? Àwọn kan tilẹ̀ lè máa ṣiyèméjì, kí wọ́n máa kọminú pé, ‘Báwo ni a ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀?’ Tóò, báwo ni ìgbàgbọ́ ṣe lè borí iyèméjì? Ọ̀nà pàtàkì méjì ni ìdákẹ́kọ̀ọ́ jíjinlẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti wíwá sí àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé, kí a sì máa kópa nínú rẹ̀. Nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ lè mú iyèméjì wa kúrò. Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú wà tí wọ́n ṣiyèméjì. Ẹ jẹ́ kí a gbé ọ̀ràn ìránṣẹ́ Èlíṣà yẹ̀ wò nígbà tí ọba Síríà gbéjà ko Ísírẹ́lì.—Fi wé Jòhánù 20:24-29; Jákọ́bù 1:5-8.
Ẹnì Kan Tí Ó Rí Àwọn Ogun Ọ̀run
4, 5. (a) Ìṣòro wo ni ìránṣẹ́ Èlíṣà ní? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà Èlíṣà?
4 Ọba Síríà rán agbo ọmọ ogun tí ó bùáyà lọ sí Dótánì ní òru láti lọ mú Èlíṣà wá. Nígbà tí ìránṣẹ́ Èlíṣà dìde ní àfẹ̀mọ́jú, tí ó sì jáde síta, bóyá láti lọ gbatẹ́gùn sára lórí òrùlé pẹrẹsẹ tí ó sábà máa ń wà lórí ilé àwọn ará Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn, họ́wù, jìnnìjìnnì bá a! Odindi ẹgbẹ́ ọmọ ogun Síríà pẹ̀lú àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun ti yí ìlú náà ká, wọ́n ti wà ní sẹpẹ́ láti mú wòlíì Ọlọ́run. Ìránṣẹ́ náà ké sí Èlíṣà ní ohùn rara pé: “Págà, ọ̀gá mi! Kí ni àwa yóò ṣe?” Ó hàn gbangba pé, Èlíṣà fi ìfọkànbalẹ̀ àti ìgbàgbọ́ tó lágbára fèsì pé: “Má fòyà, nítorí àwọn tí ó wà pẹ̀lú wa pọ̀ ju àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn lọ.” Ìránṣẹ́ náà ti lè ṣe kàyéfì pé, ‘Níbo ni àwọn onítọ̀hún wà? N kò rí wọn!’ Nígbà mìíràn, ó lè jẹ́ ìṣòro tí a ní nìyẹn—àìlèfi ojú inú tàbí ojú ìmòye wa rí àwọn ogun ọ̀run.—2 Àwọn Ọba 6:8-16; Éfésù 1:18.
5 Èlíṣà gbàdúrà pé kí a la ojú ìránṣẹ́ òun. Kí ni ó wá ṣẹlẹ̀? “Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jèhófà la ojú ẹmẹ̀wà náà, bẹ́ẹ̀ ni ó sì ríran; sì wò ó! ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá náà kún fún àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun oníná yí Èlíṣà ká.” (2 Àwọn Ọba 6:17) Bẹ́ẹ̀ ni, ó rí àwọn ogun ọ̀run, ẹgbẹ́ ọmọ ogun áńgẹ́lì tí ó ti wà ní sẹpẹ́ láti dáàbò bo ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Wàyí o, ó lè wá lóye ìdí tí Èlíṣà kò fi mikàn.
6. Báwo ni a ṣe lè ní ìjìnlẹ̀ òye sínú ètò àjọ Jèhófà ti òkè ọ̀run?
6 Nígbà mìíràn, a ha máa ń ní irú ìṣòro ìfòyemọ̀ tí ìránṣẹ́ Èlíṣà ní bí? Kìkì àwọn apá tí ó ṣeé fojú rí tí ó jẹ́ ewu fún wa tàbí fún iṣẹ́ Kristẹni wa ní àwọn ilẹ̀ kan ha ni a ń rí bí? Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, a ha lè retí pé kí a fi ìran àrà ọ̀tọ̀ hàn wá láti là wá lóye bí? Rárá o, nítorí a ní ohun kan tí ìránṣẹ́ Èlíṣà kò ní—odindi ìwé tí ó kún fún ọ̀pọ̀ ìran, Bíbélì, tí ó lè fún wa ní ìjìnlẹ̀ òye nípa ètò àjọ ti òkè ọ̀run. Ọ̀rọ̀ onímìísí yẹn tún fúnni ní àwọn ìlànà, láti mú ọ̀ràn tọ́ nínú ìrònú wa àti ọ̀nà ìgbésí ayé wa. Ṣùgbọ́n, a gbọ́dọ̀ sapá láti wá ìfòyemọ̀, kí a sì mú ìmọrírì fún ètò tí Jèhófà ṣe dàgbà. A lè ṣe ìyẹn nípa dídákẹ́kọ̀ọ́, gbígbàdúrà àti ṣíṣe àṣàrò.—Róòmù 12:12; Fílípì 4:6; 2 Tímótì 3:15-17.
Kíkẹ́kọ̀ọ́ Láti Lè Ní Ìfòyemọ̀
7. (a) Ìṣòro wo ni àwọn kan lè ní nípa ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? (b) Èé ṣe tí ìdákẹ́kọ̀ọ́ fi yẹ fún irú ìsapá bẹ́ẹ̀?
7 Ìdákẹ́kọ̀ọ́ kì í ṣe ohun tí ó rọrùn fún ọ̀pọ̀ ènìyàn, fún àpẹẹrẹ, àwọn tí kò gbádùn kíkẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ tàbí tí kò láǹfààní láti lọ́wọ́ nínú rẹ̀ rí. Ṣùgbọ́n, bí a bá fẹ́ fi ojú inú wa rí ètò àjọ Jèhófà, kí a sì mọyì rẹ̀, a gbọ́dọ̀ mú ìfẹ́-ọkàn láti kẹ́kọ̀ọ́ dàgbà. O ha lè gbádùn oúnjẹ àjẹpọ́nnulá láìjẹ́ pé a ti gbọ́ ọ dáadáa bí? Bí agbọ́únjẹ èyíkéyìí yóò ti sọ fún ọ, gbígbọ́ oúnjẹ àjẹpọ́nnulá kò ṣàì ní wàhálà nínú. Síbẹ̀, láàárín ọgbọ̀n ìṣẹ́jú tàbí kí ó má tilẹ̀ tó bẹ́ẹ̀, a ti lè jẹ ẹ́ tán. Ní ọwọ́ kejì, a lè máa jàǹfààní ìdákẹ́kọ̀ọ́ jálẹ̀ àkókò ìgbésí ayé wa. Ìdákẹ́kọ̀ọ́ lè di ohun tí ń gbádùn mọ́ wa bí a bá ń rí bí a ṣe ń tẹ̀ síwájú. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tọ̀nà láti wí pé ó yẹ kí a máa fiyè sí ara wa àti ẹ̀kọ́ wa nígbà gbogbo, kí a sì máa fi ara wa fún ìwé kíkà ní gbangba. Ó ń béèrè ìsapá tí a kò dáwọ́ rẹ̀ dúró, àmọ́ àǹfààní rẹ̀ lè wà pẹ́ títí.—1 Tímótì 4:13-16.
8. Irú ìṣarasíhùwà wo ni Òwe dámọ̀ràn?
8 Ọkùnrin ọlọgbọ́n kan nígbàanì wí pé: “Ọmọ mi, bí ìwọ yóò bá gba àwọn àsọjáde mi, tí ìwọ yóò sì fi àwọn àṣẹ tèmi ṣúra sọ́dọ̀ rẹ, láti lè dẹ etí rẹ sí ọgbọ́n, kí o lè fi ọkàn-àyà rẹ sí ìfòyemọ̀; jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí o bá ké pe òye, tí o sì fọ ohùn rẹ jáde sí ìfòyemọ̀, bí o bá ń bá a nìṣó ní wíwá a bí fàdákà, tí o sì ń bá a nìṣó ní wíwá a kiri bí àwọn ìṣúra fífarasin, bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò lóye ìbẹ̀rù Jèhófà, ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an.”—Òwe 2:1-5.
9. (a) Báwo ni ìníyelórí wúrà ṣe rí ní ìfiwéra pẹ̀lú “ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an”? (b) Àwọn irinṣẹ́ wo ni a nílò láti ní ìmọ̀ pípéye?
9 O ha mọ ẹni tí ó ni ẹrù iṣẹ́ náà? Gbólóhùn náà tí a tẹnu mọ́ léraléra ni ‘bí o.’ Tún kíyè sí gbólóhùn náà, ‘Bí o bá ń bá a nìṣó ní wíwá a kiri bí àwọn ìṣúra fífarasin.’ Ronú nípa àwọn awakùsà tí ó ti ń wa kùsà nítorí fàdákà àti wúrà ní Bolivia, Gúúsù Áfíríkà, Mexico, àti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún. Wọ́n ṣiṣẹ́ àṣekára, nípa lílo jígà àti ṣọ́bìrì, láti wu àwọn òkúta tí wọn yóò ti rí àwọn irin tí ó ṣeyebíye náà jáde. Wọ́n mọyì wúrà tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ débi pé ní ibi ìwakùsà kan ní California, U.S.A., wọ́n gbẹ́ ọ̀nà abẹ́lẹ̀ tí ó tó 591 kìlómítà, tí jíjìn rẹ̀ sì tó kìlómítà kan àbọ̀—kí wọ́n ṣáà lè rí wúrà. Síbẹ̀, ṣé o lè jẹ wúrà? Àbí o lè mu wúrà? Ó ha lè gbé ẹ̀mí rẹ ró nínú aṣálẹ̀ bí ebi bá ń pa ọ́ kú lọ tàbí bí òùngbẹ bá ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gbẹ̀mí rẹ? Rárá o, ètò ọrọ̀ ajé àti ẹ̀mí èyí-wù-mí-kò-wù-ọ́ tí ń bá ọjà àgbáyé yí láti ọjọ́ dé ọjọ́ ni ó ń pinnu ìníyelórí rẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn ti tìtorí rẹ̀ kú. Wàyí o, báwo ni ìsapá tí a ń béèrè láti lè rí wúrà tẹ̀mí, “ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an” ti pọ̀ tó? Rò ó wò ná, ìmọ̀ Olúwa Ọba Aláṣẹ àgbáyé gan-an, ètò àjọ rẹ̀, àti ète rẹ̀! Nípa èyí, a lè lo jígà àti ṣọ́bìrì nípa tẹ̀mí. Ìwọ̀nyẹn ni àwọn ìtẹ̀jáde tí a gbé ka Bíbélì láti ràn wá lọ́wọ́ láti walẹ̀ jìn sínú Ọ̀rọ̀ Jèhófà, kí a sì fòye mọ ìtumọ̀ rẹ̀.—Jóòbù 28:12-19.
Wíwalẹ̀jìn fún Ìjìnlẹ̀ Òye
10. Kí ni Dáníẹ́lì rí nínú ìran?
10 Ẹ jẹ́ kí a walẹ̀ jìn díẹ̀ nípa tẹ̀mí, kí a lè bẹ̀rẹ̀ sí ní ìmọ̀ nípa ètò àjọ Jèhófà ti òkè ọ̀run gan-an. Láti lè ní ìjìnlẹ̀ òye pàtàkì, ẹ jẹ́ kí a yíjú sí ìran tí Dáníẹ́lì rí nípa Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé tí ó gúnwà sórí ìtẹ́ rẹ̀. Dáníẹ́lì kọ̀wé pé: “Mo ń wò títí a fi gbé àwọn ìtẹ́ kalẹ̀, Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé sì jókòó. Aṣọ rẹ̀ funfun bí ìrì dídì gẹ́lẹ́, irun orí rẹ̀ sì dà bí irun àgùntàn tí ó mọ́. Ọwọ́ iná ni ìtẹ́ rẹ̀; iná tí ń jó ni àgbá kẹ̀kẹ́ rẹ̀. Ìṣàn iná tí ń ṣàn sì wà, ó ń jáde lọ ní iwájú rẹ̀. Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún ń ṣe ìránṣẹ́ fún un, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ́nà ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì ń dúró níwájú rẹ̀ gangan. Kóòtù mú ìjókòó, a sì ṣí àwọn ìwé.” (Dáníẹ́lì 7:9, 10) Àwọn wo ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún yìí tí ń ṣe ìránṣẹ́ fún Jèhófà? Ìtọ́ka òpó ìwé ti inú Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, tí a lò gẹ́gẹ́ bí “jígà” àti “ṣọ́bìrì,” mú wa lọ sí àwọn ìtọ́ka bí Sáàmù 68:17 àti Hébérù 1:14. Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn áńgẹ́lì ọ̀run ni àwọn tí ń ṣe ìránṣẹ́ fún un!
11. Báwo ni ìran Dáníẹ́lì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ọ̀rọ̀ Èlíṣà?
11 Àkọsílẹ̀ Dáníẹ́lì kò sọ pé òun rí gbogbo áńgẹ́lì olóòótọ́ tí Ọlọ́run ń pè rán níṣẹ́. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ mìíràn lè wà. Ṣùgbọ́n, ó dájú pé nísinsìnyí a lè mọ ìdí tí Èlíṣà fi lè sọ pé: “Àwọn tí ó wà pẹ̀lú wa pọ̀ ju àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn lọ.” Bí àwọn áńgẹ́lì aláìṣòótọ́, àwọn ẹ̀mí èṣù, tilẹ̀ wà lẹ́yìn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọba Síríà, ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run ti Jèhófà pọ̀ jù wọ́n lọ!—Sáàmù 34:7; 91:11.
12. Báwo ni o ṣe lè mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn áńgẹ́lì?
12 Bóyá ìwọ yóò fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn áńgẹ́lì wọ̀nyí, irú ipa tí wọ́n ń kó nínú sísin Jèhófà. Láti inú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà fún áńgẹ́lì, a lè rí i pé wọ́n jẹ́ ońṣẹ́ nítorí pé ó tún túmọ̀ sí “ońṣẹ́.” Àmọ́ ṣá o, iṣẹ́ wọn kò mọ síbẹ̀ yẹn. Ṣùgbọ́n, láti lè mọ̀ ọ́n, o gbọ́dọ̀ walẹ̀ jìn. Bí o bá ní ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Insight on the Scriptures, o lè ka àpilẹ̀kọ náà, “Angels” (Áńgẹ́lì), tàbí kí o ṣàyẹ̀wò àwọn àpilẹ̀kọ àtẹ̀yìnwá nínú Ilé Ìṣọ́ nípa áńgẹ́lì. Ẹnu á yà ọ́ láti rí ohun tí ó lè kọ́ nípa àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí ń gbé ní ìsálú ọ̀run wọ̀nyí, oò sì wá mọyì ìtìlẹ́yìn wọn. (Ìṣípayá 14:6, 7) Àmọ́ ṣá o, nínú ètò àjọ Ọlọ́run ti òkè ọ̀run, àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí kan ń sìn fún àwọn ète àrà ọ̀tọ̀.
Ohun Tí Aísáyà Rí
13, 14. Kí ni Aísáyà rí nínú ìran, báwo sì ni èyí ṣe nípa lórí rẹ̀?
13 Wàyí o, ẹ jẹ́ kí a walẹ̀ jìn sínú ìran Aísáyà. Nígbà tí o bá ka orí 6, ẹsẹ 1 sí 7, orí rẹ yóò wú. Aísáyà wí pé òun “rí Jèhófà, tí ó jókòó lórí ìtẹ́ tí ó ga fíofío,” tí “àwọn séráfù dúró lókè rẹ̀.” Wọ́n ń pòkìkí ògo Jèhófà, wọ́n ń yin ìjẹ́mímọ́ rẹ̀ lógo. Kò sí àní-àní pé kíka àkọsílẹ̀ yìí lásán yóò nípa lórí rẹ. Kí ni ìhùwàpadà Aísáyà? “Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: ‘Mo gbé! Nítorí, kí a sáà kúkú sọ pé a ti pa mí lẹ́nu mọ́ [nínú Ṣìọ́ọ̀lù], nítorí pé ọkùnrin aláìmọ́ ní ètè ni mí, àárín àwọn ènìyàn aláìmọ́ ní ètè sì ni mo ń gbé; nítorí pé ojú mi ti rí Ọba, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, tìkára rẹ̀!’” Ìran yẹn mà wú u lórí gan-an o! Ìwọ ńkọ́?
14 Báwo ní Aísáyà ṣe lẹ́mìí àtidúrówo ìrísí ológo yìí? Ó ṣàlàyé pé séráfù kan ni ó wá ran òun lọ́wọ́, tí ó sì wí pé: “Ìṣìnà rẹ sì ti kúrò, ẹ̀ṣẹ̀ rẹ pàápàá ni a sì ti ṣètùtù fún.” (Aísáyà 6:7) Aísáyà gbójú lé àánú Ọlọ́run, ó sì fiyè sí ọ̀rọ̀ Jèhófà. Wàyí o, o kò ha ní fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí onípò gíga wọ̀nyí? Nígbà náà, kí ni ó yẹ kí o ṣe? Walẹ̀ jìn fún ìsọfúnni síwájú sí i. Àrànṣe kan tí o lè lò ni ìwé náà, Watch Tower Publications Index, kí o tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ka rẹ̀ sí ọ̀pọ̀ ìsọfúnni fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé.
Kí Ni Ìsíkíẹ́lì Rí?
15. Kí ni ó fi hàn pé ìran Ìsíkíẹ́lì ṣeé gbára lé?
15 Ẹ jẹ́ kí a yíjú sí oríṣi ẹ̀dá ẹ̀mí mìíràn. A fún Ìsíkíẹ́lì ní àǹfààní láti rí ìran afúnnilókun nígbà tí ó ṣì wà nígbèkùn ní Bábílónì. Ṣí Bíbélì rẹ sí Ìsíkíẹ́lì orí 1, ẹsẹ mẹ́ta àkọ́kọ́. Báwo ni àkọsílẹ̀ náà ṣe bẹ̀rẹ̀? Ǹjẹ́ ó wí pé, ‘Nígbà kan, ní ilẹ̀ kan tí ó jìnnà réré . . . ’? Rárá o, èyí kì í ṣe ìtàn àgbọ́sọ inú àlọ́. Ẹsẹ 1 sọ pé: “Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún ọgbọ̀n, ní oṣù kẹrin, ní ọjọ́ karùn-ún oṣù náà, nígbà tí mo wà ní àárín àwọn ìgbèkùn lẹ́bàá Odò Kébárì, pé ọ̀run ṣí sílẹ̀, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí rí àwọn ìran ti Ọlọ́run.” Kí ni o ṣàkíyèsí nípa ẹsẹ yìí? Ó sọ ọjọ́ pàtó àti ibi tí ọ̀ràn náà ti ṣẹlẹ̀ gan-an. Àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ wọ̀nyí ń tọ́ka sí ọdún karùn-ún ìgbèkùn Jèhóákínì Ọba, ní ọdún 613 ṣááju Sànmánì Tiwa.
16. Kí ni Ìsíkíẹ́lì rí?
16 Ọwọ́ Jèhófà sì wà lára Ìsíkíẹ́lì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rí ìran tí ń múni kún fún ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ nípa Jèhófà lórí ìtẹ́ nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin òkè ọ̀run ràgàjì kan, tí ó ní àwọn àgbá ńláńlá, tí ojú sì wà láyìíká ọwọ́ ìta àwọn àgbá náà. Kúlẹ̀kúlẹ̀ tí ó fà wá mọ́ra níhìn-ín ni pé, àwọn ẹ̀dá mẹ́rin ni ó wà níbẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan dúró sí ibi àgbá kọ̀ọ̀kan. “Bí wọ́n sì ti rí nìyí: wọ́n ní ìrí ará ayé. Ọ̀kọ̀ọ̀kan sì ní ojú mẹ́rin, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní ìyẹ́ apá mẹ́rin. . . . Àti ní ti ìrí ojú wọn, àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní ojú ènìyàn pẹ̀lú ojú kìnnìún ní ìhà ọ̀tún, àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì ní ojú akọ màlúù ní ìhà òsì; àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tún ní ojú idì.”—Ìsíkíẹ́lì 1:5, 6, 10.
17. Kí ni ojú mẹ́rin tí àwọn kérúbù náà ní dúró fún?
17 Ta ni àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin wọ̀nyí? Ìsíkíẹ́lì fúnra rẹ̀ sọ fún wa pé kérúbù ni wọ́n. (Ìsíkíẹ́lì 10:1-3, 14) Èé ṣe tí wọ́n fi ní ojú mẹ́rin? Láti dúró fún àwọn ànímọ́ títayọ mẹ́rin tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ní. Ojú idì dúró fún ọgbọ́n tí ó ríran jìnnà. (Jóòbù 39:27-29) Kí ni ojú akọ màlúù dúró fún? Nítorí iṣan líletantan tí ó ki sí ọ̀run àti èjìká rẹ̀, a gbọ́ pé lójú ìjà, akọ màlúù kan gbé ẹṣin àti ẹni tí ó gùn-ún kúrò nílẹ̀ gáú. Dájúdájú, akọ màlúù dúró fún agbára Jèhófà tí kò láàlà. A lo kìnnìún láti dúró fún ìdájọ́ òdodo tí kò bẹ̀rù ohunkóhun. Paríparí rẹ̀, lọ́nà tí ó ṣe wẹ́kú, ojú ènìyàn dúró fún ìfẹ́ Ọlọ́run, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ènìyàn nìkan ni ẹ̀dá orí ilẹ̀ ayé tí ó lè fi ànímọ́ yìí hàn lọ́nà tí ó fi òye hàn.—Mátíù 22:37, 39; 1 Jòhánù 4:8.
18. Báwo ni àpọ́sítélì Jòhánù ṣe fi kún òye wa nípa ètò àjọ ti òkè ọ̀run?
18 Àwọn ìran mìíràn wà tí ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ bí ọ̀ràn náà ti rí gan-an. Èyí ní ìran Jòhánù tí a sọ nínú Bíbélì ní ìwé Ìṣípayá nínú. Òun, gẹ́gẹ́ bí Ìsíkíẹ́lì, rí Jèhófà lórí ìtẹ́ ògo tí àwọn kérúbù rọ̀gbà yí i ká. Kí ni àwọn kérúbù wọ̀nyí ń ṣe? Wọ́n ń tún ìkéde tí àwọn séráfù ṣe ní Aísáyà orí 6 ṣe, ní sísọ pé: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Jèhófà Ọlọ́run, Olódùmarè, tí ó ti wà, tí ń bẹ, tí ó sì ń bọ̀.” (Ìṣípayá 4:6-8) Jòhánù tún rí ọ̀dọ́ àgùntàn kan lẹ́bàá ìtẹ́ náà. Ta ni onítọ̀hún lè jẹ́? Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run, Jésù Kristi, ni.—Ìṣípayá 5:13, 14.
19. Nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí, kí ni o ti mọ̀ nípa ètò àjọ Jèhófà?
19 Nítorí náà, nípasẹ̀ àwọn ìran wọ̀nyí, kí ni a ti róye rẹ̀? A róye pé Jèhófà Ọlọ́run tí ó gúnwà sórí ìtẹ́ rẹ̀ ni ó wà ní òkè téńté ètò àjọ ti òkè ọ̀run, tí Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, Jésù Kristi, ẹni tí í ṣe Ọ̀rọ̀ náà, tàbí Logos, sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, a ti rí ogun ọ̀run àwọn áńgẹ́lì ti òkè ọ̀run, títí kan àwọn séráfù àti kérúbù. Wọ́n jẹ́ apá kan ètò àjọ gbígbòòrò, tí ó ṣọ̀kan, tí ó wà fún àwọn ète Jèhófà. Ọ̀kan lára àwọn ète náà ni wíwàásù ìhìn rere náà kárí ayé ní àkókò òpin yìí.—Máàkù 13:10; Jòhánù 1:1-3; Ìṣípayá 14:6, 7.
20. Ìbéèrè wo ni a óò dáhùn nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e?
20 Paríparí rẹ̀, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà lórí ilẹ̀ ayé, tí wọ́n ń pàdé ní àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn láti kọ́ bí wọn yóò ṣe ṣèfẹ́ Olúwa Ọba Aláṣẹ. Dájúdájú, a lè mọ̀ nísinsìnyí pé àwọn tí ń bẹ pẹ̀lú wa ju àwọn tí ó wà pẹ̀lú Sátánì àti àwọn ọ̀tá òtítọ́ lọ. Ìbéèrè kan ń bẹ tí a kò tí ì dáhùn, Ipa wo ni ètò àjọ ti òkè ọ̀run ń kó nínú wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà? Àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e yóò ṣàyẹ̀wò ìyẹn àti àwọn ọ̀ràn mìíràn.
Àwọn Ìbéèrè fún Àtúnyẹ̀wò
◻ Láti mọyì ètò àjọ Jèhófà, kí ni a gbọ́dọ̀ mọ̀?
◻ Ìrírí wo ni ìránṣẹ́ Èlíṣà ní, báwo sì ni wòlíì náà ṣe fún un níṣìírí?
◻ Ojú wo ni ó yẹ kí a fi wo ìdákẹ́kọ̀ọ́?
◻ Báwo ni Dáníẹ́lì, Aísáyà, àti Ìsíkíẹ́lì ṣe pèsè kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ètò àjọ ti òkè ọ̀run?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Àǹfààní ìdákẹ́kọ̀ọ́ ju ti oúnjẹ àjẹpọ́nnulá lọ púpọ̀púpọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ìran àwọn ogun ọ̀run ni Jèhófà fi dáhùn àdúrà Èlíṣà