Ẹ Kọrin Ìyìn Sí Jehofa
“Èmi ó kọrin sí OLUWA, nítorí tí ó pọ̀ ní ògo.”—EKSODU 15:1.
1. Àwọn ànímọ́-ìwà àti ànímọ́ Jehofa wo ni ó fún wa ní ìdí láti fi ìyìn fún un?
NÍ ÌGBÀ 13 ni Orin Dafidi 150 fúnni ní àṣẹ náà láti yin Jehofa tàbí Jah. Ẹsẹ tí ó gbẹ̀yìn polongo pé: “Jẹ́ kí ohun gbogbo tí ó ní ẹ̀mí kí ó yin Oluwa. Ẹ fi ìyìn fún Oluwa.” Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí fún Jehofa, àwa mọ̀ pé ó tọ́ fún Jehofa láti gba ìyìn wa. Òun ni Ọba-Aláṣẹ Àgbáyé, Ẹni Gíga Jùlọ, Ọba ayérayé, Ẹlẹ́dàá wa, Olóore wa. Ó jẹ́ aláìlábàádọ́gba, aláìlẹ́gbẹ́, aláìláfiwé, aláìlójúgbà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà. Òun ni olùmọ ohun gbogbo, alágbára gbogbo, pípé nínú ìdájọ́ òdodo, àti ògidi àpẹẹrẹ ìfẹ́. Ó jẹ́ rere ju ẹni gbogbo mìíràn lọ; ó jẹ́ adúróṣinṣin. (Luku 18:19; Ìfihàn 15:3, 4) Ó ha yẹ ni ẹni tí a ń fìyìn fún bí? Ó dájú hán-ún-hán-ún pé òun yẹ bẹ́ẹ̀!
2. Kí ni àwọn ìdí tí a ní fún sísọ̀rọ̀ ìmoore wa jáde fún Jehofa?
2 Kìí ṣe kìkì pé Jehofa yẹ ni ẹni tí a ń jọ́sìn tí a sì ń fìyìn fún nìkan ni ṣùgbọ́n ó tún yẹ ni ẹni tí a ń fi ìmoore àti ọpẹ́ hàn fún nítorí gbogbo ohun tí ó ti ṣe fún wa. Òun ni Olùfúnni ní “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ẹ̀bùn pípé.” (Jakọbu 1:17) Òun ni Ojúsun, Orísun, gbogbo ìwàláàyè. (Orin Dafidi 36:9) Ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni gbogbo àwọn nǹkan tí a ń gbádùn gẹ́gẹ́ bíi mẹ́ḿbà ẹ̀yà ìran ẹ̀dá ènìyàn ti ń wá, nítorí pé òun ni Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá wa. (Isaiah 42:5) Òun tún ni Olùfúnni ní gbogbo àwọn ìbùkún tẹ̀mí tí ń wá sọ́dọ̀ wa nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀, ètò-àjọ rẹ, àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀. A ń rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà lórí ìpìlẹ̀ pípèsè Ọmọkùnrin rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìràpadà wa. (Johannu 3:16) A ní ìrètí Ìjọba náà ti ‘àwọn ọ̀run titun àti ayé titun nínú èyí tí òdodo yóò gbé.’ (2 Peteru 3:13) A ní ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ rere pẹ̀lú àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ wa. (Romu 1:11, 12) A ní ọlá àti àwọn ìbùkún ti jíjẹ́ Ẹlẹ́rìí rẹ̀. (Isaiah 43:10-12) A sì ní àǹfààní ṣíṣeyebíye ti àdúrà. (Matteu 6:9-13) Nítòótọ́, a ní ìdí púpọ̀ láti fi ọpẹ́ fún Jehofa!
Àwọn Ọ̀nà tí A Lè Gbà Yin Jehofa
3. Ní onírúurú àwọn ọ̀nà wo ni a lè gbà yin Jehofa kí a sì sọ̀rọ̀ ìmoore wa jáde fún un?
3 Gẹ́gẹ́ bí àwọn ìránṣẹ́ tí a yàsọ́tọ̀ fún Jehofa, báwo ni àwa ṣe lè yìn ín kí a sì sọ̀rọ̀ ìmoore wa jáde? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa kíkópa nínú iṣẹ́òjíṣẹ́ Kristian—jíjẹ́rìí láti ilé-dé-ilé, ṣíṣe àwọn ìpadàbẹ̀wò, dídarí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, àti lílọ́wọ́ nínú ìjẹ́rìí òpópónà. A tún lè yìn ín nípa jíjẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà nígbàkígbà tí àǹfààní náà bá ṣí sílẹ̀. A sì tún lè yin Jehofa nípa ìwà ìdúróṣinṣin wa, kódà nípa ọ̀nà mímọ́ tónítóní tí ó wà níwọ̀ntunwọ̀nsì tí a gbà ń wọṣọ ti a sì gbà ń túnraṣe. A ti yin àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lọ́pọ̀ ìgbà fún jíjẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ ni àwọn ọ̀nà wọ̀nyí. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, a lè yin Jehofa kí a sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ nípasẹ̀ àdúrà.—Wo 1 Kronika 29:10-13.
4. Kí ni ọ̀kan nínú àwọn ọ̀nà dídára jùlọ tí a lè gbà yin Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́?
4 Ní àfikún, ọ̀kan nínú àwọn ọ̀nà dídára jùlọ tí a lè gba yin Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ ni nípa kíkókìkí rẹ̀ àti àwọn agbára ìtóye rẹ̀ pẹ̀lú àwọn orin Ìjọba tí ń tunilára. Ọ̀pọ̀ àwọn olórin àti àkórinjọ gbà pé ohun-èlò orin tí ó dára jùlọ ni ohùn ènìyàn. Àwọn ọ̀gá nínú orin-àtijọ́ dáwọ́ lé e láti kọ àwọn eré orin nítorí pé ìtẹ́lọ́rùn púpọ̀ gidigidi wà nínú títẹ́tísílẹ̀ sí ohùn ènìyàn nígbà tí ó bá ń kọrin.
5. Fún àwọn ìdí wo ni a fi níláti fi ọwọ́ tí ó ṣe pàtàkì mú kíkọ àwọn orin Ìjọba wa?
5 Ẹ sì wo bí Jehofa ṣe níláti gbádùn fífetísílẹ̀ sí àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí ń kọrin tó, pàápàá jùlọ nígbà tí wọ́n bá ń kọ àwọn orin ìyìn àti ìmoore! Dájúdájú nígbà náà, a níláti fi ọwọ́ tí ó ṣe pàtàkì mú bí a ṣe ń kọ àwọn orin Ìjọba ní onírúurú àwọn ibi àpéjọ wa—àwọn ìpàdé ìjọ, àpéjọ àyíká, ọjọ́ àpéjọ àkànṣe, àpéjọpọ̀ àgbègbè, àti àwọn àpéjọpọ̀ àgbáyé. Ìwé orin wa kún fún àwọn orin atunilára tí ń múni kún fún ìdùnnú nítòótọ́, èyí tí àwọn ará ìta ń sọ̀rọ̀ ìyìn nípa ẹwà rẹ̀ lemọ́lemọ́. Bí a bá ti fi ara wa fún kíkọ àwọn orin Ìjọba tó, bẹ́ẹ̀ ni àwa yóò mú kí àwọn ẹlòmíràn jẹ̀gbádùn tó tí a óò sì ṣàǹfààní fún araawa.
Kíkọrin Ìyìn sí Jehofa ní Àwọn Àkókò tí A Kọ Bibeli
6. Báwo ni àwọn ọmọ Israeli ṣe sọ̀rọ̀ ìmọrírì jáde fún ìdáǹdè wọn ní Òkun Pupa?
6 Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ fún wa pé Mose àti àwọn ọmọ Israeli yòókù fi ayọ̀ ìṣẹ́gun kọrin nígbà tí a dá wọn nídè kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun Farao ní Òkun Pupa. Orin wọn bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ náà: “Èmi ó kọrin sí OLUWA, nítorí tí ó pọ̀ ní ògo: àti ẹṣin àti ẹlẹ́ṣin òun ni ó bì ṣubú sínú òkun. OLUWA ni agbára àti orin mi, òun ni ó sì di ìgbàlà mi: èyí ni Ọlọrun mi, èmi ó sì fi ìyìn fún un.” (Eksodu 15:1, 2) Àwa lè ronúwòye ìtara ọkàn àti ayọ̀ àwọn ọmọ Israeli lọ́nà dídára bí wọ́n ti ń kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn lórin lẹ́yìn ìdáǹdè wọn lọ́nà ìyanu!
7. Àwọn àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ gbígbàfiyèsí mìíràn wo ni Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ pé àwọn ọmọ Israeli fi orin yin Jehofa?
7 Ní 1 Kronika 16:1, 4-36, a kà pé Jehofa ni a fìyìn fún nípa kíkọrin àti fífi àwọn ohun-èlò orin kọrin nígbà tí Dafidi gbé Àpótí Ẹ̀rí lọ sí Jerusalemu. Àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ aláyọ̀ kan ni ìyẹn jẹ́ nítòótọ́. Fífi ohun-èlò orin kọrin ìyìn sí Jehofa tún wáyé nígbà tí Ọba Solomoni ya tẹ́ḿpìlì tí ń bẹ ní Jerusalemu sí mímọ́. A kà nínú 2 Kronika 5:13, 14 pé: “Ó sì ṣe bí ẹni pé ẹnìkan, nígbà tí a gbọ́ ohùn àwọn afùnpè àti àwọn akọrin, bí ohùn kan láti máa yìn, àti láti máa dúpẹ́ fún Oluwa; nígbà tí wọ́n sì gbé ohùn wọn sókè pẹ̀lú ipè àti kíḿbáálì, àti ohun-èlò orin, láti máa yin Oluwa pé, Ó ṣeun; àánú rẹ̀ sì dúró láéláé: nígbà náà ni ilé náà kún fún àwọ̀sánmà, àní ilé Oluwa; tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn àlùfáà kò lè dúró láti ṣiṣẹ́ ìsìn nítorí àwọ̀sánmà náà: nítorí ògo Oluwa kún ilé Ọlọrun.” Kí ni ìyẹn fihàn? Pé Jehofa ń fetísílẹ̀ sí orin ìyìn atunilára yìí ó sì mú inú rẹ̀ dùn, gẹ́gẹ́ bí àwọ̀sánmà tí ó ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá ti fihàn. Lẹ́yìn náà ni àwọn ẹgbẹ́ akọrin méjì kọrin nígbà ayẹyẹ ìfilọ́lẹ̀ àwọn ògiri Jerusalemu ní àwọn ọjọ́ Nehemiah.—Nehemiah 12:27-42.
8. Kí ni ó fihàn pé àwọn ọmọ Israeli fi ọwọ́ tí ó ṣe pàtàkì mú kíkọrin?
8 Ní tòótọ́, orin kíkọ jẹ́ apá pàtàkì gan-an nínú ìjọsìn ní tẹ́ḿpìlì tí ó fi jẹ́ pé 4,000 àwọn ọmọ Lefi ni a yàsọ́tọ̀ fún iṣẹ́-ìsìn orin kíkọ. (1 Kronika 23:4, 5) Àwọn wọ̀nyí ni wọn yóò jùmọ̀ kọrin pọ̀ pẹ̀lú àwọn akọrin. Orin, ní pàtàkì àwọn akọrin, wà ní ipò pàtàkì nínú ìjọsìn, kò fi dandan jẹ́ láti gbin àwọn ọ̀ràn Òfin tí ó wúwo jù sínilọ́kàn, bíkòṣe láti fúnni ní ẹ̀mí tí ó yẹ fún ìjọsìn. Ó ran àwọn ọmọ Israeli lọ́wọ́ láti fi ẹ̀mí ìtara jọ́sìn Jehofa. Ṣàkíyèsí ìmúrasílẹ̀ àti ìfiyèsí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tí a yàsọ́tọ̀ fún apá ẹ̀ka yìí: “Iye wọn, pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn tí a kọ́ ní orin Oluwa, àní gbogbo àwọn tí ó mòye, jásí ọ̀rìnlúgba ó lé mẹ́jọ.” (1 Kronika 25:7) Ṣàkíyèsí bí wọ́n ti fi ọwọ́ tí ó ṣe pàtàkì mú kíkọ orin ìyìn sí Jehofa. A fún wọn ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa kíkọ orin wọ́n sì jẹ́ amòye!
9. Ìtẹnumọ́ wo ní a fifún kíkọrin nínú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki?
9 Ní wíwá sí ọ̀rúndún kìn-ín-ní nínú sànmánì tiwa, kí ni a rí? Jesu, ní alẹ́ ọjọ́ tí a fi í hàn, pẹ̀lú àwọn ọ̀ràn wíwúwo púpọ̀ ní ọkàn rẹ̀, ṣì nímọ̀lára àìní náà láti parí ayẹyẹ Ìrékọjá àti ìdásílẹ̀ Ìṣe-Ìrántí ikú rẹ̀ nípa kíkọ orin ìyìn sí Jehofa. (Matteu 26:30) A sì tún kà pé “láàárín ọ̀gànjọ́,” lẹ́yìn ti a ti lù wọ́n tí a sì ti tì wọ́n mọ́ inú túbú, Paulu òun Sila “ń gbàdúrà, wọ́n sì ń kọrin ìyìn sí Ọlọrun: àwọn ará túbú sì ń tẹ́tí sí wọn.”—Iṣe 16:25.
Kíkọrin Ìyìn—Apá Pàtàkì kan Nínú Ìjọsìn Wa
10. Àwọn àṣẹ wo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọrun fifúnni níti kíkọrin yìn ín?
10 Ó ha lè jẹ́ pé ìwọ ń ronú pé kíkọ àwọn orin Ìjọba kò ṣe pàtàkì tó ohun tí ìwọ lè fún ní àfiyèsí àtọkànwá rẹ bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kò ha yẹ kí ìwọ tún ọ̀ràn náà gbéyẹ̀wò, lójú ìwòye ìjẹ́pàtàkì tí Jehofa Ọlọrun àti Jesu Kristi gbékarí kíkọ́ orin ìyìn? Họ́wù, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun kún fún àwọn àṣẹ láti yin Jehofa kí a sì kọrin ìyìn sí i! Fún àpẹẹrẹ, ní Isaiah 42:10, a kà pé: “Ẹ kọ orin titun sí Oluwa, ìyìn rẹ̀ láti òpin ayé, ẹ̀yin tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀: erékùṣù, àti àwọn tí ń gbé inú wọn.”—Tún wo Orin Dafidi 96:1; 98:1.
11. Ìṣílétí wo ni aposteli Paulu fúnni níti kíkọrin?
11 Aposteli Paulu mọ̀ pé orin lè ru ọkàn wa sókè, nítorí náà ó fún wa ní ìṣílétí nígbà méjì lórí ọ̀ràn náà. A kà nínú Efesu 5:18, 19 pé: “Ẹ kún fún ẹ̀mí; ẹ sì máa bá ara yín sọ̀rọ̀ nínú psalmu, àti orin ìyìn, àti orin ẹ̀mí, ẹ máa kọrin, kí ẹ sì máa kọrin dídùn ní ọkàn yín sí Oluwa.” A sì tún kà ní Kolosse 3:16 pé: “Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Kristi máa gbé inú yín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú ọgbọ́n gbogbo; kí ẹ máa kọ́, kí ẹ sì máa gba araayín níyànjú nínú psalmu, àti orin ìyìn, àti orin ẹ̀mí, ẹ máa fi oore-ọ̀fẹ́ kọrin ní ọkàn yín sí Oluwa.”
12. Àwọn àpẹẹrẹ wo ni a ní nípa ìrànlọ́wọ́ tí orin wa ń ṣe fún wa láti kọ́ kí a sì máa gba araawa níyànjú?
12 Ṣàkíyèsí pé nínú ọ̀ràn kọ̀ọ̀kan léraléra ni Paulu tọ́ka sí kíkọrin, nígbà tí ó mẹ́nukan ‘psalmu, orin ìyìn sí Oluwa, orin ẹ̀mí, kíkọrin ní ọkàn yín.’ Pẹ̀lúpẹ̀lù, o nasẹ̀ ọ̀rọ̀ àkíyèsí rẹ̀ sí àwọn ará Kolosse nípa sísọ pé ní ọ̀nà yìí a lè máa “kọ́, kí ẹ sì máa gba araayín níyànjú.” Ìyẹn gan-an ni a sì ń ṣe nítòótọ́, gẹ́gẹ́ bí àkọlé àwọn orin wa ti fihàn—“Ẹ Yin Jehofah Gbogbo Ẹ̀dá!” (orin 5), “Ẹ Durogangan, Laiyẹsẹ!” (orin 10), “Ẹ Kún fun Ìdùnnú-Ayọ̀ ninu Ireti Ijọba Naa!” (orin 16), “Ẹ Maṣe Bẹru Wọn!” (orin 27), “Ẹ Kókìkíyìn Jehofah Ọlọrun Wa!” (orin 100), láti fúnni ní ìwọ̀nba àpẹẹrẹ díẹ̀.
13. Báwo ni “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú” ṣe fi ìjẹ́pàtàkì kíkọrin gẹ́gẹ́ bí apákan ìjọsìn wa hàn?
13 Ní ìbáramu pẹ̀lú àwọn àṣẹ wọ̀nyí, “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú” ti ṣètò pé àwọn ìpéjọpọ̀ wa—àwọn ìpàdé ìjọ, àpéjọ àyíká, ọjọ́ àpéjọ àkànṣe, àpéjọpọ̀ àgbègbè, àti àwọn àpéjọpọ̀ àgbáyé—ni kí á bẹ̀rẹ̀ kí á sì mú wá sí ìparí nípa kíkọ àwọn orin Ìjọba. (Matteu 24:45, NW) Ní àfikún, a wéwèé pé kí a kọ orin ní àwọn àkókò mìíràn nígbà tí àwọn ìpéjọpọ̀ wọ̀nyí bá ń lọ lọ́wọ́. Níwọ̀n bí a ti sábà máa ń bẹ̀rẹ̀ àwọn ìpàdé wa pẹ̀lú kíkọ orin Ìjọba kan, kì yóò ha jẹ́ ohun yíyẹ pé kí a máa tètè dé, ṣáájú àkókò láti kópa nínú apá ìjọsìn wa yẹn bí? Níwọ̀nbí àwọn ìpàdé náà sì ti ń parí pẹ̀lú orin kíkọ, kì yóò ha dára pé kí a dúró títí di ìgbà orin ìparí àti àdúrà tí ó máa ń wáyé kété lẹ́yìn rẹ̀ bí?
14. Àwọn àpẹẹrẹ wo ni a ní nípa yíyan àwọn orin yíyẹ fún àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ wa?
14 A ti fi ìṣọ́ra yan àwọn orin ìpàdé wa láti wà ní ìbáramuṣọ̀kan pẹ̀lú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Fún àpẹẹrẹ, ní àwọn Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá” ní 1993, orin nọmba 191, “Sọ Otitọ naa Di Tìrẹ,” tí ó fún àwọn Kristian ní ìṣírí láti gbéjako Satani, ayé, àti ẹran-ara ẹlẹ́ṣẹ̀, ni a kọ tẹ̀lé àwọn ọ̀rọ̀-àsọyé mẹ́ta náà tí ó sọ nípa àwọn ọ̀tá wọ̀nyí. Bákan náà, orin nọmba 164, “Awọn Ọmọ—Ẹ̀bùn Oniyebiye Lati Ọ̀dọ̀ Ọlọrun,” tí ó kún fún ọ̀rọ̀-ìṣítí fún àwọn òbí, ni ó tẹ̀lé e kété lẹ́yìn ọ̀rọ̀-àsọyé kan tí ó tẹnumọ́ ojúṣe àwọn òbí láti kọ́ àwọn ọmọ wọn. Orin nọmba 70, “Ẹ Dabi Jeremiah,” ṣáájú ọ̀wọ́ àwọn ọ̀rọ̀-àsọyé tí a gbékarí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Jeremiah. Àti lẹ́yìn àpínsọ ọ̀rọ̀-àsọyé kan lórí onírúurú àwọn apá-ẹ̀ka iṣẹ́-òjíṣẹ́ Ìjọba wa ni a kọ orin nọmba 156, “Mo Fẹ́ Bẹẹ,” orin kan tí ó tẹ̀síhà iṣẹ́-ìsìn gan-an. Ìṣọ́ra kan náà yìí ni a ń lò nínú yíyan àwọn orin fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé-Ìṣọ́nà, Ìpàdé Iṣẹ́-Ìsìn, àti Ilé-Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun. Nígbà náà ó wá jásí pé nígbà tí àwọn alàgbà bá ń fúnni ní ọ̀rọ̀-àsọyé tí wọ́n sì yan orin tí a ó fi ṣí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, wọ́n níláti yan orin kan tí ó bá ẹṣin-ọ̀rọ̀ ọ̀rọ̀-àsọyé wọn mu.
15. Báwo ni alága ìpàdé ṣe lè mú ìmọrírì pọ̀ síi fún orin tí a fẹ́ láti kọ?
15 Ní ṣíṣèfilọ̀ orin náà ti a óò kọ, alága lè mú ìmọrírì pọ̀ síi fún orin náà nípa sísọ àkọlé tàbí ẹṣin-ọ̀rọ̀ rẹ̀. Kìí ṣe nọ́ḿbà orin náà ni a ń kọ bíkòṣe àwọn ẹṣin-ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́. Yóò tún ṣèrànwọ́ fún ìjọ láti mọrírì orin náà síi bí a bá pe àfiyèsí sí ẹsẹ ìwé mímọ́ tí a fúnni lábẹ́ àkọlé náà. Lẹ́yìn náà, ọ̀rọ̀ àkíyèsí díẹ̀ tún lè jẹ́ ohun yíyẹ, irú bíi ẹ jẹ́ kí a kọ orin yìí pẹ̀lú ọ̀yàyà, ìmọ̀lára, ayọ̀, tàbí ìgboyà àìṣojo, ní sísinmi lórí irú èrò ìmọ̀lára tí a rí nínú orin náà.
Fi Ìmọrírì Hàn fún Ìwàrere Ìṣeun Jehofa Nípa Kíkọrin
16. Báwo ni a ṣe lè fi ara wa fún àwọn orin tí a ń kọ?
16 Níwọ̀nbí àwọn ọ̀rọ̀ inú orin Ìjọba wa ti kún fún ìtumọ̀, a níláti pọkànpọ̀ sórí àwọn ọ̀rọ̀ orin náà bí a ti ń kọ wọ́n. A fẹ́ fi ara wa fún kíkọ orin kọ̀ọ̀kan. Àwọn díẹ̀, bí àwọn wọnnì tí ń sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́, èso ti ẹ̀mí, jẹ́ àtọkànwá. (Galatia 5:22) Ìwọ̀nyí ni a ń kọ kíkankíkan àti pẹ̀lú ìgbónára. Àwọn mìíràn kún fún ayọ̀, a sì níláti gbìyànjú láti kọ wọ́n tayọ̀tayọ̀. Síbẹ̀ àwọn mìíràn jẹ́ orin alágbára tí ń dún bárajọ lọ́nà ṣíṣe kánmọ́kánmọ́, ìwọ̀nyí ni a sì níláti kọ pẹ̀lú ìtara-ọkàn àti ìgboyà lílágbára. Nínú Ilé-Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun wa, a gbà wá nímọ̀ràn láti lo ìgbónára àti ìtanijí àti ìtara-ọkàn pẹ̀lú nínú àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ wa. Láti fi ìgbónára, ìtanijí, àti ìtara-ọkàn hàn nígbà tí a bá ń kọ àwọn orin wa tilẹ̀ tún ṣe pàtàkì jù.
17. (a) Ìbáwí ìdálẹ́bi wo tí a fifún àwọn ọmọ Israeli aláìṣòtítọ́ ni àwa kì yóò fẹ́ kí ó jẹ́ òtítọ́ nípa bí a ti ń kọrin? (b) Kí ni ìyọrísí rẹ̀ nígbà tí a bá fi ọwọ́ tí ó ṣe pàtàkì mú ìṣílétí tí ó wà nínú orin wa?
17 Bí a bá níláti kọ àwọn orin Ìjọba wa nígbà tí ọkàn wa wà lórí àwọn nǹkan mìíràn, láìmọrírì ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ náà ní kíkún, àwa kì yóò ha dọ́gbọ́n dàbí àwọn ọmọ Israeli aláìṣòtítọ́ tí a báwí nítorí pé, nígbà tí wọ́n fi ètè wọn yin Ọlọrun, ọkàn-àyà wọn jìnnà réré sí i? (Matteu 15:8) Àwa kì yóò fẹ́ kí ìbáwí ìdálẹ́bi yẹn jẹ́ òtítọ́ nípa ọ̀nà tí a gbà ń kọ àwọn orin Ìjọba, àbí a fẹ́ bẹ́ẹ̀? Nípa ṣíṣe ẹ̀tọ́ níti ọ̀nà tí a gbà ń kọ àwọn orin Ìjọba, kìí ṣe araawa nìkan ni a óò rusókè bíkòṣe àwọn wọnnì tí wọ́n yí wa ká pẹ̀lú, títíkan àwọn tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́. Bẹ́ẹ̀ni, bí gbogbo àwọn tí ń kọrin ní àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa bá fi ọwọ́ tí ó ṣe pàtàkì mú ìṣílétí tí àwọn orin wọ̀nyí ní nínú, èyí yóò jẹ́ ìṣírí lílágbára láti jẹ́ onítara nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ náà kí a sì yẹra fún àwọn ìdẹkùn ìwà-àìtọ́.
18. Ìyọrísí wo ni kíkọ àwọn orin Ìjọba ní lórí obìnrin kan?
18 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, àwọn ará ìta ni kíkọ àwọn orin Ìjọba wa máa ń wú lórí. Ilé-Ìṣọ́nà tẹ ìsọfúnni yìí jáde rí: “Pé orin kíkọ [wa] lè ṣiṣẹ́ láti fa àwọn ènìyàn wá sínu ìmọ̀ Jehofa Ọlọrun ní a fihàn nípa ìrírí kan nípa obìnrin kan ẹni tí a baptisi rẹ̀ ní Ìpàdé ‘Ìṣẹ́gun Àtọ̀runwá’ ní ọdún 1973, ní Yankee Stadium, ní ìlú New York. Ó ti ṣe ìbẹ̀wò rẹ̀ kìn-ín-ní sí Gbọ̀ngàn Ìjọba àdúgbò náà fúnraarẹ̀ ní òun nìkan ó sì dúró fún ìpàdé méjèèjì. Bí ìjọ náà ti kọ orin . . . ‘Tẹjumọ Èrè Na!,’ àwọn ọ̀rọ̀ orin náà àti ọ̀nà tí wọ́n gba kọ ọ́ wọ obìnrin náà lọ́kàn púpọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi pinnu pé, níhìn-ín yìí ni ibi tí òun fẹ́ láti wà. Lẹ́yìn náà ó tọ ọ̀kan nínú àwọn Ẹlẹ́rìí lọ ó sì béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, ó sì ti tẹ̀síwájú títí ó fi di Kristian ẹlẹ́rìí Jehofah kan.”
19. Ìṣírí wo ní àkótán ni a fifúnni níti kíkọ àwọn orin Ìjọba wa tọkàntara?
19 Níbi àwọn ìpàdé wa tí ó pọ̀ jùlọ, ìwọ̀nba àǹfààní ní o máa ń ṣí sílẹ̀ ní ìfiwéra fún àwùjọ láti fi ìmọ̀lára àti ìmọrírì wọn hàn. Ṣùgbọ́n gbogbo wa lè fi ìmọ̀lára wa hàn nípa ìwàrere ìṣeun Jehofa nípa fífi tinútinú darapọ̀ nínú kíkọ àwọn orin Ìjọba. Yàtọ̀ sí ìyẹn, nígbà tí a bá pàdépọ̀, kìí ha ṣe pé ayọ̀ ń kún inú wa bí? Nítorí náà ó yẹ kí a fẹ́ láti kọrin! (Jakọbu 5:13) Nítòótọ́, dé ìwọ̀n àyè tí a bá fi ìmọrírì hàn fún ìwàrere ìṣeun Jehofa àti inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀, ni a óò fi máa kọ orin ìyìn jáde síi tọkàntọkàn.
Kí Ni Yóò Jẹ́ Ìdáhùn Rẹ?
◻ Kí ni àwọn ìdí pàtàkì méjì fún yíyin Jehofa?
◻ Ní onírúurú àwọn ọ̀nà wo ni a lè gbà yin Jehofa?
◻ Kí ni ọ̀kan nínú àwọn ọ̀nà dídára jùlọ tí a lè gbà yin Jehofa?
◻ Àwọn àpẹẹrẹ inú Ìwé Mímọ́ wo ni a ní níti fífi orin yin Jehofa?
◻ Báwo ni a ṣe lè ṣe ẹ̀tọ́ nípa ọ̀nà tí a gbà ń kọ àwọn orin Ìjọba?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 11]
Gbádùn Àwọn Orin Wọ̀nyẹn!
Ó jọbí ẹni pé àwọn kan ti ní ìṣòro díẹ̀ nínú kíkọ díẹ̀ lára àwọn orin náà. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìjọ kan kò ní ìṣòro bàbàrà níti kíkọ èyí tí ó pọ̀ jùlọ lára àwọn orin wọ̀nyẹn. Bóyá kìkì ìwọ̀nba ìsapá díẹ̀ síi láti kọ́ ohun tí ó dàbí èyí tí a kò mọ̀ dunjú lákọ̀ọ́kọ́ ni gbogbo ohun tí a nílò. Ní gbàrà tí wọ́n bá ti mọ irúfẹ́ àwọn orin bẹ́ẹ̀ dunjú, ìjọ sábà máa ń mọrírì wọn ju àwọn wọnnì tí kò béèrè fún ìsapá láti kọ. Lẹ́yìn náà gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú ìjọ lè fi tìgboyàtìgboyà kọ wọ́n. Bẹ́ẹ̀ni, wọ́n lè gbádùn àwọn orin wọ̀nyẹn!
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 12]
Kọ Àwọn Orin Ìjọba Níbi Àwọn Ìpéjọpọ̀ Ẹgbẹ́-òun-Ọ̀gbà
Àwọn orin Ìjọba tí a ń kọ ni a kò níláti fimọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Paulu àti Sila kọ orin ìyìn sí Jehofa nígbà tí wọ́n wà nínú túbú. (Iṣe 16:25) Ọmọlẹ́yìn náà Jakọbu sì wí pé: “Ẹnikẹ́ni ha wà nínú ara yíyá gágá bí? Jẹ́ kí ó kọ orin ìyìn sí Ọlọrun.” (Jakọbu 5:13, àkíyèsí-ẹsẹ̀-ìwé, NW) Níbi àwọn ìpéjọpọ̀ ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà ara olúkúlùkù a máa yá gágá. Nítorí náà èéṣe tí ẹ kò fi kọ àwọn orin Ìjọba? Èyí ní pàtàkì jùlọ lè múni kún fún ayọ̀ bí a bá lu dùùrù tàbí gìtá sí orin kíkọ náà. Yàtọ̀ sí ìyẹn, a ní àwọn orin Ìjọba tí a ti gbohùn rẹ̀ sílẹ̀ tí a lu dùùrù olóhùn gooro sí; ọ̀pọ̀ àwọn ìdílé tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí ní album àwọn orin tí a ti gbohùn rẹ̀ sílẹ̀ wọ̀nyí. Kìí ṣe pé wọn ṣeé lò fún kíkọ tẹ̀lé orin nìkan ni ṣùgbọ̀n wọn tún yẹ wẹ́kú gẹ́gẹ́ bí ohùn abẹ́lẹ̀ lílẹ́wà fún ohùn-orin.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Lẹ́yìn ìdáǹdè wọn ní Òkun Pupa, àwọn ọmọ Israeli fi ayọ̀ wọn hàn nípasẹ̀ orin
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Orin aláyọ̀ jẹ́ apákan ìjọsìn Kristian lónìí