Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
AUGUST 3-9
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 13-14
“Ẹ Dúró Gbọn-in, Kí Ẹ sì Rí Bí Jèhófà Ṣe Máa Gbà Yín Là”
Mósè Jẹ́ Ẹni Tó Ní Ìgbàgbọ́
Ó ṣeé ṣe kí Mósè fúnra rẹ̀ má mọ̀ pé ṣe ni Ọlọ́run fẹ́ lànà sáàárín Òkun Pupa, kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè rí ọ̀nà kọjá. Àmọ́ ṣá, ó dá Mósè lójú pé Ọlọ́run máa ṣe nǹkan kan láti dáàbò bo àwọn èèyàn Rẹ̀. Ó sì fẹ́ kó dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì náà lójú. Bíbélì sọ pé: “Mósè wí fún àwọn ènìyàn náà pé: ‘Ẹ má fòyà. Ẹ dúró gbọn-in-gbọn-in, kí ẹ sì rí ìgbàlà Jèhófà, èyí tí yóò ṣe fún yín lónìí.’ ” (Ẹ́kísódù 14:13) Ǹjẹ́ Mósè sì mú kí ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fẹsẹ̀ múlẹ̀ lóòótọ́? Bẹ́ẹ̀ ni. Ohun tí Bíbélì sọ nípa Mósè àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi hàn bẹ́ẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni wọ́n la Òkun Pupa kọjá bí pé lórí ilẹ̀ gbígbẹ.” (Hébérù 11:29) Mósè nìkan kọ́ ló jàǹfààní ìgbàgbọ́ tó ní yìí o. Ó tún ṣe gbogbo àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ lára ìgbàgbọ́ rẹ̀ láǹfààní.
Alágbára Ńlá Ni Jèhófà, Síbẹ̀ Ó Ń Gba Tẹni Rò
Ka Ẹ́kísódù 14:19-22. Fojú inú wò ó pé o wà pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́jọ́ yẹn. Òkun Pupa rèé níwájú, àwọn ọmọ ogun Fáráò sì ń ya bọ̀ lẹ́yìn. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jèhófà ṣe ohun àrà kan. Ṣe ni ọwọ̀n àwọsánmà náà ṣí kúrò níwájú yín, ó sì pààlà sáàárín ẹ̀yin àtàwọn ọmọ ogun Íjíbítì. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé àwọsánmà náà mú kí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Íjíbítì ṣókùnkùn biribiri, àmọ́ ṣe ni ọ̀dọ̀ tiyín mọ́lẹ̀ rekete! Lẹ́yìn náà lo rí i tí Mósè na ọwọ́ rẹ̀ sí òkun, afẹ́fẹ́ kan sì fẹ́ wá láti ìlà oòrùn, afẹ́fẹ́ náà lágbára débi pé ó pín òkun náà sí méjì, ó sì la ọ̀nà sáàárín rẹ̀. Gbogbo àwọn èèyàn náà títí kan ìwọ àti ìdílé rẹ àtàwọn ẹran ọ̀sìn yín sì rọra tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ gba àárín omi náà kọjá. Àmọ́, o tún kíyè sí ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ṣe ni orí ilẹ̀ tẹ́ ẹ̀ ń rìn gbẹ táútáú, kò sí ẹrẹ̀ níbẹ̀ débi pé á máa yọ̀, ìyẹn sì mú kó rọrùn fún gbogbo yín títí kan àwọn ọmọdé àtàwọn aláìlera láti rìn kọjá níbẹ̀. Gbogbo yín sì sọdá òkun náà láyọ̀ àti àlàáfíà.
Ìwọ Kò Gbọ́dọ̀ Gbàgbé Jèhófà
Orí wàhálà kẹ̀kẹ́ ẹṣin wọn tí kò lè rìn mọ́ yìí làwọn ará Íjíbítì wà tí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi dé èbúté òdì kejì òkun níhà ìlà oòrùn. Mósè wá na ọwọ́ rẹ̀ sí orí Òkun Pupa. Jèhófà sì mú kí omi tó dúró bí ògiri lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì tí ọ̀nà fi là láàárín òkun, ya wálẹ̀. Bí alagbalúgbú omi ṣe ya bo Fáráò àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ mọ́lẹ̀ bámúbámú nìyẹn, wọ́n sì kú sínú òkun. Kò sí ọ̀kan tó yè bọ́ lára àwọn ọ̀tá náà. Báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe dòmìnira nìyẹn!—Ẹ́kís. 14:26-28; Sm. 136:13-15.
Ó pẹ́ gan-an kí jìnnìjìnnì ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tó kúrò lára àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní àyíká ibẹ̀. (Ẹ́kís. 15:14-16) Kódà, ní ogójì ọdún lẹ́yìn náà, Ráhábù ọmọ ìlú Jẹ́ríkò ṣì sọ fáwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì méjì pé: ‘Jìnnìjìnnì yín ti bá wa, nítorí a ti gbọ́ bí Jèhófà ti gbẹ omi Òkun Pupa táútáú kúrò níwájú yín nígbà tí ẹ jáde kúrò ní Íjíbítì.’ (Jóṣ. 2:9, 10) Àní, àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà wọ̀nyẹn pàápàá kò gbàgbé bí Jèhófà ṣe gba àwọn èèyàn rẹ̀ là. Dájúdájú, kò sídìí kankan rárá tó fi yẹ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbàgbé Jèhófà.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-1 1117
Ojú Pópó, Ojú Ọ̀nà
Láyè àtijọ́, àwọn ìlú tó wà ní agbègbè Palẹ́sìnì láwọn ojú pópó àti ojú ọ̀nà títí kan èyí táwọn oníṣòwò máa ń gbà kọjá. (Nọ 20:17-19; 21:21, 22; 22:5, 21-23; Joṣ 2:22; Ond 21:19; 1Sa 6:9, 12; 13:17, 18; wo OJÚ Ọ̀NÀ OBA.) Ọ̀nà kan wà láti Íjíbítì lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí tó yá gan-an. Ẹni tó bá ń rin ọ̀nà yìí máa gba Gásà àti Áṣíkẹ́lónì tó jẹ́ ìlú àwọn ará Filísínì, látibẹ̀ á forí lé Mẹ́gídò ní apá àríwá. Lẹ́yìn náà, á dé Hásórì ní apá àríwá Òkun Gálílì, á sì tibẹ̀ lọ sí Damásíkù. Ọ̀nà yìí yá gan-an lóòótọ́, àmọ́ Jèhófà darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gba ọ̀nà míì, torí ó mọ̀ pé àwọn ará Filísínì lè gbéjà kò wọ́n, kí èyí sì mú kí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì.—Ẹk 13:17.
it-1 782 ¶2-3
Jíjáde Lọ
Ibo ló ṣeé ṣe kí Òkun Pupa ti pín yà káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè sọdá?
Ohun kan tó gbà àfíyèsí ni pé, nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì rìnrìn àjò dé Étámù “létí aginjù,” Ọlọ́run pàṣẹ fún Mósè pé “kí wọ́n ṣẹ́rí pa dà, kí wọ́n sì pàgọ́ síwájú Píháhírótì . . . lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkun.” Ìgbésẹ̀ yìí máa jẹ́ kí Fáráò ronú pé ṣe làwọn ọmọ Ísírẹ́lì “ń rìn gbéregbère.” (Ẹk 13:20; 14:1-3) Àwọ́n ọ̀mọ̀wé kan tó gbà pé ojú ọ̀nà el Haj làwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà sọ pé ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n tú sí “ṣẹ́rí pa dà” ṣe kedere, kì í kàn ṣe pé wọ́n “yà bàrá” àmọ́ ohun tó ń sọ ni pé wọ́n yí pa dà. Wọ́n sọ pé nígbà tí wọ́n dé ibì kan ní apá àríwá Suez, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa dà sẹ́yìn wọ́n sì lọ yípo gba apá ìlà oòrùn Jebel ʽAtaqah, ìyẹn òkè kan ní ìwọ̀ oòrùn. Tí wọ́n bá gbéjà ko àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lápá àríwá yìí, kò ní sí bí wọ́n ṣe máa sá àsálà torí pé wọ́n pọ̀ gan-an, wọ́n máa há wọn mọ́ torí pé àwọn ọ̀tá máa wà níwájú wọn, òkun pupa á sì wà lẹ́yìn wọn.
Báwọn Júù ọgọ́rùn ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni ṣe máa ń sọ ìtàn nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ jẹ́ ká rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. (Wo PÍHÁHÍRÓTÌ.) Àmọ́ ní pàtàkì, ìṣẹ̀lẹ̀ náà bá ohun tó wà nínú Bíbélì mu, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé ń sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà ò bá Bíbélì mu. (Ẹk 14:9-16) Ó ṣe kedere pé, ibi táwọn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti sọdá máa jìnnà sí etí Òkun Pupa náà, torí tó bá jẹ́ etí Òkun Pupa ni, ó máa rọrùn fáwọn ọmọ ogun Fáráò láti lọ yípo etí òkun náà, kí wọ́n lè lọ pàdé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì níwájú.—Ẹk 14:22, 23.
AUGUST 10-16
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 15-16
“Máa Fi Orin Yin Jèhófà”
Èé Ṣe Tí Ó Fi Yẹ Kí A Bẹ̀rù Ọlọrun Tòótọ́ náà Nísinsìnyí??
Pípa tí Jehofa pa agbo ọmọ ogun Egipti run gbé e lékè lójú àwọn olùjọsìn rẹ̀, ó sì mú kí orúkọ rẹ̀ di mímọ̀ káàkiri. (Joṣua 2:9‚ 10; 4:23, 24) Bẹ́ẹ̀ ni, a gbé orúkọ rẹ̀ ga borí àwọn ọlọrun èké àwọn ará Egipti, tí kò lágbára, tí wọ́n fi ẹ̀rí hàn pé wọ́n kò lè gba àwọn tí ń jọ́sìn wọn là. Gbígbé tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ọlọrun wọn àti àwọn ènìyàn tí wọ́n lè kú àti agbára ológun yọrí sí ìjákulẹ̀ kíkorò. (Orin Dafidi 146:3) Abájọ tí èyí fi sún àwọn ọmọ Israeli láti kọrin tí ó fi ìbẹ̀rù gbígbámúṣé nínú Ọlọrun tí ń bẹ láàyè hàn, tí ó fi agbára rẹ gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là!
Èé Ṣe Tí Ó Fi Yẹ Kí A Bẹ̀rù Ọlọrun Tòótọ́ náà Nísinsìnyí??
Ká sọ pé a wà pẹ̀lú Mósè, àwa náà ò bá kọrin pé: “Jèhófà, ta ló dà bí rẹ nínú àwọn ọlọ́run? Ta ló dà bí rẹ, ìwọ tí o fi hàn pé ẹni mímọ́ jù lọ ni ọ́? Ẹni tó yẹ ká máa bẹ̀rù, ká máa fi orin yìn, Ẹni tó ń ṣe ohun ìyanu.” (Eksodu 15:11) A ti sọ irú èrò ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ ni àsọtúnsọ jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún láti ìgbà náà wá. Nínú ìwé tí ó kẹ́yìn Bibeli, aposteli Johannu ṣàpèjúwe ẹgbẹ́ àwọn ẹni àmì òróró olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Ọlọrun pé: “Wọ́n ń kọ orin Mósè ẹrú Ọlọ́run àti orin Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” Kí ni orin ńlá náà? “Jèhófà Ọlọ́run, Olódùmarè, àwọn iṣẹ́ rẹ tóbi, ó sì kàmàmà. Òdodo àti òótọ́ ni àwọn ọ̀nà rẹ, Ọba ayérayé. Ta ni kò ní bẹ̀rù rẹ Jèhófà, tí kò ní yin orúkọ rẹ lógo, torí pé ìwọ nìkan ni adúróṣinṣin?”—Ìfihàn 15:2-4.
16 Bákan náà lónìí, kì í ṣe kìkì iṣẹ́ ìṣẹ̀dá Ọlọrun nìkan làwọn olùjọsìn rẹ̀ mọrírì, wọ́n tún mọrírì àwọn òfin rẹ̀ pẹ̀lú. A ti dá àwọn ènìyàn láti orílẹ̀-èdè gbogbo sílẹ̀ lómìnira nípa tẹ̀mí, a ti yà wọ́n sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé tí ó ti bàjẹ́ yìí, nítorí wọ́n mọ àwọn òfin òdodo Ọlọrun, wọ́n sì ń fi wọ́n sílò. Lọ́dọọdún, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ń bọ́ lọ́wọ́ ayé tí ó ti díbàjẹ́ yìí kí wọ́n lè wà nínú ètò Ọlọ́run tó jẹ́ mímọ́. Láìpẹ́, lẹ́yìn tí a bá ti mú ìdájọ́ Ọlọrun, tí ó mú bí iná, ṣẹ lórí ìsìn èké àti ìyókù ètò ìgbékalẹ̀ búburú yìí, wọn yóò wà láàyè títí láé nínú ayé tuntun òdodo.
it-2 454 ¶1
Orin
Ó jọ pé àkọgbà ni àwọn ẹgbẹ́ akọrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń kọrin. Àwọn kan á kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ orín náà, àwọn kan á máa gbè é tàbí kí àwọn akọrin míì máa fi onírúurú ohùn kọ ọ́ tẹ̀ lé àwọn akọrin tó kù ní àkọgbà. Tí wọ́n bá ń kọrin lọ́nà yìí, Bíbélì sábà máa ń sọ pé ẹgbẹ́ àkọ́kọ́ dá ẹgbẹ́ kejì lóhùn. (Ẹk 15:21; 1Sa 18:6, 7) A lè rí irú àpẹẹrẹ ọ̀nà ìgbà kọrin bẹ́ẹ̀ nínú àwọn sáàmù kan, irú bí i Sáàmù kẹrìndínlógóje (136). Ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ẹgbẹ́ akọrin ńlá méjì tí wọ́n kọrin ìdúpẹ́ nígbà ayé Nehemáyà àti ipa tí wọ́n kó nígbà tí wọ́n ṣí odi Jerúsálẹ́mù tí wọ́n kọ́ fi hàn pé àkọgbà ni wọ́n kọrin.—Ne 12:31, 38, 40-42.
it-2 698
Wòlíì Obìnrin
Míríámù ni obìnrin àkọ́kọ́ tí Bíbélì sọ pé ó jẹ́ wòlíì. Ẹ̀rí fi hàn pé ó jíṣẹ́ Ọlọ́run fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ nípasẹ̀ orin. (Ẹk 15:20, 21) Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé òun àti Áárónì sọ fún Mósè pé: “Ṣé [Jèhófà] kò gbẹnu tiwa náà sọ̀rọ̀ ni?” (Nọ 12:2) Jèhófà fúnra ẹ̀ sọ nípasẹ̀ wòlíì Míkà pé òun rán “Mósè, Áárónì àti Míríámù” sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n ń jáde kúrò nílẹ̀ Íjíbítì. (Mik 6:4) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Míríámù làǹfààní láti kéde ọ̀rọ̀ Jèhófà fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ipò rẹ̀ bíi wòlíì rẹlẹ̀ gan-an sí ti Mósè àbúrò rẹ̀. Nígbà kan tó ráhùn sí Mósè, Jèhófà bá a wí.—Nọ 12:1-15.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Kí nìdí tó fi jẹ́ pé àparò ni Ọlọ́run fi bọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní aginjù?
Lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè lóko ẹrú Íjíbítì, ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Ọlọ́run pèsè ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àparò fún wọn láti jẹ.—Ẹ́kísódù 16:13; Númérì 11:31.
Àparò jẹ́ ẹ̀dá abìyẹ́, kò sì fí bẹ́ẹ̀ tóbi, ó gùn tó àtẹ́lẹwọ́, ó sì wúwo tó ọgọ́rùn-ún gíráàmù (100 g). Wọ́n máa ń pamọ ní apá ibi tó pọ̀ ní ìwọ̀ oòrùn Éṣíà àti Yúróòpù. Nítorí pé àwọn àparò máa ń ṣí kiri, wọ́n máa ń ṣí lọ sí Àríwá ilẹ̀ Áfíríkà àti Arébíà láti lọ lo ìgbà òtútù níbẹ̀. Lákòókò tí wọ́n bá ń ṣí lọ sáwọn àgbègbè míì, àgbájọ wọn máa ń fò gba ìlà oòrùn etí Òkun Mẹditaréníà, wọ́n á sì fò gba àgbègbè Sínáì tí omi yíká kọjá.
Gẹ́gẹ́ bí ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì ti sọ, ìyẹn, The New Westminster Dictionary of the Bible, àwọn àparò “máa ń yára gan-an, wọ́n sì máa ń fò dáadáa, wọ́n máa ń jẹ́ kí afẹ́fẹ́ gbé wọn lọ, àmọ́ tí afẹ́fẹ́ kò bá gba ibi tí wọ́n dorí kọ tàbí tí ó bá rẹ̀ wọ́n nítorí wọ́n ti ń fò bọ̀ láti ọ̀nà tó jìn, ńṣe ni àgbájọ àwọn àparò náà máa jábọ́, tí wọn ò sì ní lè ṣe nǹkan kan.” Kí wọ́n tún tó lè bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjo wọn, wọ́n ní láti sinmi nílẹ̀ níbẹ̀ fún ọjọ́ kan tàbí méjì, lákòókò yìí, ó máa ń rọrùn fún àwọn èèyàn láti mú wọn. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lọ́nà ogún, àwọn ará Íjíbítì máa ń kó àwọn àparò tó tó nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́ta lọ́dún lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè míì fún àwọn tó fẹ́ jẹ́ ẹ.
Ìgbà ìrúwé ni ìgbà méjèèjì táwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ àparò. Bó tílẹ̀ jẹ́ pé àwọn àparò máa ń fò kọjá dáadáa ní àgbègbè Sínáì lákòókò yẹn, síbẹ̀ Jèhófà ló mú kí ‘ẹ̀fúùfù fẹ́’ tó sì gbá àwọn àparò náà lọ sí àgọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.—Númérì 11:31.
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Kò pẹ́ rárá tí Ọlọ́run gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí kùn nítorí oúnjẹ. Jèhófà sì fún wọn ní Mánà. (Ẹ́kísódù 12:17, 18; 16:1-5) Lákòókò yẹn, Mósè wí fún Áárónì pé: “Mú ìṣà kan, kí o sì fi mánà ẹ̀kún òṣùwọ̀n ómérì kan sínú rẹ̀, kí o sì gbé e kalẹ̀ níwájú Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ohun tí a ní láti pa mọ́ jálẹ̀ ìran-ìran yín.” Ìtàn náà fi yé wa pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè, Áárónì sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé e kalẹ̀ síwájú Gbólóhùn Ẹ̀rí [ìyẹn ibi tí wọ́n ń kó àwọn àkọsílẹ̀ pàtàkì sí] gẹ́gẹ́ bí ohun tí a ní láti pa mọ́.” (Ẹ́kísódù 16:33, 34) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí àní-àní pé Áárónì kó mánà sínú ìṣà kan nígbà náà, ìgbà tí Mósè kan Àpótí Ẹ̀rí tó sì kó wàláà sínú rẹ̀ ni wọ́n tó gbé ìṣà náà síwájú Gbólóhùn Ẹ̀rí.
AUGUST 17-23
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 17-18
“Àwọn Tó Lẹ́mìí Ìrẹ̀lẹ̀ Máa Ń Faṣẹ́ Lé Àwọn Míì Lọ́wọ́”
Mósè Jẹ́ Onífẹ̀ẹ́
Mósè fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Àwọn náà sì mọ̀ pé òun ni Jèhófà ń lò láti darí àwọn. Torí náà tí wọ́n bá ní ìṣòro, wọ́n máa ń wá bá Mósè. Bíbélì sọ pé: “Àwọn ènìyàn náà sì ń dúró níwájú Mósè láti òwúrọ̀ títí di alẹ́.” (Ẹ́kísódù 18:13-16) Fojú inú wo bí á ṣe máa rẹ Mósè tó lẹ́yìn tó bá ti fi gbogbo ọjọ́ tẹ́tí gbọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, bí ọ̀kan tẹ̀ lé òmíràn ṣe ń sọ ìṣòro rẹ̀ fún un! Síbẹ̀, torí pé Mósè nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn náà, inú rẹ̀ máa ń dùn láti fetí sí wọn.
Fífọkàntánni Ló Ń Mú Kí Ìgbésí Ayé Èèyàn Láyọ̀
Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ti ní àwọn ànímọ́ tínú Ọlọ́run dùn sí kó tó di pé a yàn wọ́n sípò tá a ti lè fọkàn tán wọn. Wọ́n ti fi ẹ̀rí hàn pé àwọn bẹ̀rù Ọlọ́run, wọ́n ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Ẹlẹ́dàá, wọ́n sì ń bẹ̀rù pé káwọn má ṣe ohun tó lè múnú bí i. Ó hàn gbangba sí gbogbo èèyàn pé àwọn ọkùnrin wọ̀nyí sa gbogbo ipá wọn láti pa àwọn ìlànà Ọlọ́run mọ́. Wọ́n kórìíra èrè ìjẹkújẹ, tó fi hàn pé ìwà wọn dáa gan-an, ìyẹn ni ò sì jẹ́ kí agbára máa gun wọn gàlègàlè. Wọn ò ní sọ ara wọn di ẹni tí kò ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé mọ́ nítorí èrè tí wọ́n fẹ́ jẹ tàbí nítorí àtiwá ire àwọn mọ̀lẹ́bí àti tàwọn ọ̀rẹ́ wọn.
Ìwà Títọ́ Ń ṣamọ̀nà Àwọn Adúróṣánṣán
Mósè náà mẹ̀tọ́mọ̀wà, ó sì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Nígbà tó ń ṣe àṣekúdórógbó iṣẹ́ níbi tó ti ń bójú tó ìṣòro àwọn ẹlòmíràn, Jẹ́tírò, tó jẹ́ baba ìyàwó rẹ̀, fún un nímọ̀ràn kan tó gbéṣẹ́ pé: Yan àwọn ẹrù iṣẹ́ kan fún àwọn ọkùnrin mìíràn tí ó tóótun. Mósè mọ ibi tí agbára òun mọ, ó si fi ọgbọ́n tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn náà. (Ẹ́kísódù 18:17-26; Númérì 12:3) Ẹni tó bá mẹ̀tọ́mọ̀wà kì í lọ́ tìkọ̀ láti gbé ẹrù iṣẹ́ lé àwọn ẹlòmíràn tó bá tóótun lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì í bẹ̀rù pé gbígbé ẹrù iṣẹ́ lé àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ lè mú kí ọ̀pá àṣẹ bọ́ lọ́wọ́ òun. (Númérì 11:16, 17, 26-29) Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa ń hára gàgà láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. (1 Tímótì 4:15) Ǹjẹ́ kò yẹ kí àwa náà rí bẹ́ẹ̀?
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
“Má Ṣe Jẹ́ Kí Ọwọ́ Rẹ Rọ Jọwọrọ”
Nínú ogun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá àwọn ọmọ Ámálékì jà, ṣe ni Áárónì àti Húrì gbé ọwọ́ Mósè sókè títí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ṣẹ́gun. Ó yẹ káwa náà máa wá ọ̀nà láti fún àwọn míì lókun, ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́. Àwọn wo ló yẹ ká fún lókun? Àwọn tí ara wọn ti ń dara àgbà, àwọn tó ń ṣàìsàn, àwọn tí ìdílé wọn ń ṣenúnibíni sí, àwọn tí kò rẹ́ni fojú jọ àtàwọn téèyàn wọn kú. Ká má sì gbàgbé àwọn ọmọ táwọn ọ̀rẹ́ fẹ́ kí wọ́n máa ṣe bíi tiwọn. Àwọn ọ̀rẹ́ wọn yìí lè máa rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n lọ́wọ́ sí àwọn ìwà tí kò tọ́ tàbí kí wọ́n máa lé àtirí towó ṣe, kí wọ́n sì lóókọ láwùjọ. (1 Tẹs. 3:1-3; 5:11, 14) Tẹ́ ẹ bá jọ wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí lóde ẹ̀rí, ẹ máa lo àǹfààní yẹn láti gbé ara yín ró. Ẹ sì tún lè ṣe bẹ́ẹ̀ tẹ́ ẹ bá jọ ń sọ̀rọ̀ lórí fóònù tàbí tẹ́ ẹ jọ ń jẹun.
it-1 406
Àkọsílẹ̀ Bíbélì
Àwọ́n ẹ̀rí tó wà nínu Bíbélì jẹ́ ká rí i pé àwọn ọ̀rọ̀ tí Mósè ṣàkọsílẹ̀ ní ìmísí Ọlọ́run, ó sì jẹ́ ìtọ́ni tó wúlò fún ìjọsìn tòótọ́. Kì í ṣe Mósè ló sọ ara ẹ̀ di aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kódà nígbà tí Jèhófà kọ́kọ́ yàn án, ó kọ̀ jálẹ̀. (Ẹk 3:10, 11; 4:10-14) Àmọ́ nígbà tó yá, Jèhófà fún Mósè lágbára kó lè ṣiṣẹ́ ìyanu tó fi jẹ́ pé àwọn àlùfáà onídán Fáráò pàápàá gbà pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run làwọn ìṣẹ́ ìyanu tí Mósè ṣe ti wá. (Ẹk 4:1-9; 8:16-19) Torí náà, kì í ṣe pé Mósè ń lépa bó ṣe máa di òǹkọ̀wé Bíbélì. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà fúnra ẹ̀ ló pàṣẹ fún un, tó sì fún un ní ẹ̀mí mímọ́ kó lè jíṣẹ́ Ọlọ́run, lẹ́yìn náà kó tún ṣàkọsílẹ̀ àwọn apá kan nínú Bíbélì.—Ẹk 17:14.
AUGUST 24-30
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 19-20
“Ẹ̀kọ́ Tí Òfin Mẹ́wàá Náà Kọ́ Wa Lónìí”
w89 11/15 6 ¶1
Kí Ni Òfin Mẹ́wàá Túmọ̀ Sí fún Ọ?
Òfin mẹ́rin àkọ́kọ́ tẹnu mọ́ àjọṣe tó wà láàárín àwa àti Ọlọ́run. (Àkọ́kọ́) Ọlọ́run fẹ́ ká máa sin òun nìkan ṣoṣo. (Mt 4:10) (Ìkejì) Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ò gbọ́dọ̀ máa lo ère nínú ìjọsìn. (1 Jo 5:21) (Ìkẹta) A ò gbọ́dọ̀ lo orúkọ Ọlọ́run lọ́nà tí kò tọ́ tàbí lọ́nà tí kò fi ọ̀wọ̀ hàn. (Jo 17:26; Ro 10:13) (Ìkẹrin) Ọ̀rọ̀ ìjọsìn Jèhófà ló yẹ́ kó gba iwájú nígbèésí ayé wa. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn máa jẹ́ ká lè gba ìsinmi kúrò lọ́wọ́ ẹ̀mí tinú-mi-ní-máa-ṣe.—Heb 4:9, 10.
w89 11/15 6 ¶2-3
Kí Ni Òfin Mẹ́wàá Túmọ̀ Sí fún Ọ?
(Ìkarùn-ún) Tí àwọn ọmọ bá ń ṣègbọràn sáwọn òbí wọn, ìyẹn máa ń jẹ́ kí ìdílé wà níṣọ̀kan, wọ́n sì máa ń rí ìbùkún Jèhófà. Àǹfààní sì wà nínú “àṣẹ kìíní pẹ̀lú ìlérí” yìí. Yàtọ̀ sí pé ‘nǹkan á máa lọ dáadáa fún ọ’ wà á tún “pẹ́ láyé.” (Éfésù 6:1-3) Ní báyìí tá a ti wà ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò búburú yìí, àwọn ọmọ tó bá jẹ́ onígbọràn máa láǹfààní láti wà láàyè títí láé.—2Ti 3:1; Jo 11:26.
Ìfẹ́ tá a bá ní fún ọmọnìkejì wa ò ní jẹ́ ká hùwà ìkà sí i, irú bí i (Ìkẹfà) ìpànìyàn, (Ìkeje) àgbèrè, (Ìkẹjọ) olè jíjà, àti (Ìkẹsàn-án) jíjẹ́rìí èké. (1Jo 3:10-12; Heb 13:4; Ef 4:28; Mt 5:37; Owe 6:16-19) Àmọ́ tó bá kan ohun tó wà lọ́kàn wa ńkọ́? Òfin (Kẹwàá) tó dẹ́bi fún ojúkòkòrò rán wa létí pé Jèhófà fẹ́ ká jẹ́ mímọ́ nínú èrò ọkàn wa nígbà gbogbo.—Owe 21:2.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-2 687 ¶1-2
Àlùfáà
Àwọn Àlùfáà fún Kristi. Jèhófà ṣèlérí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé tí wọ́n bá pa májẹ̀mú òun mọ́, wọ́n máa di “ìjọba àwọn àlùfáà àti orílẹ̀-èdè mímọ́” fún òun. (Ẹk 19:6) Torí náà, ìlà ìdílé Áárónì á ṣì máa bá iṣẹ́ àlùfáà lọ títí ẹgbẹ́ àlùfáà títóbi jù lọ tí ìlà ìdílé Áárónì ṣàpẹẹrẹ fi máa dé. (Heb 8:4, 5) Iṣẹ́ àlùfáà ìlà ìdílé Áárónì máa wá sópin nígbà tí májẹ̀mú tuntun bá rọ́pò májẹ̀mú Òfin. (Heb 7:11-14; 8:6, 7, 13) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni Jèhófà kọ́kọ́ fún láǹfààní láti di àlùfáà lábẹ́ Ìjọba tó ṣèlérí. Nígbà tó yá, ó nawọ́ àǹfààní yìí sáwọn tí kì í ṣe Júù.—Iṣe 10:34, 35; 15:14; Ro 10:21.
Ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn Júù ló tẹ́wọ́ gba Kristi, ìyẹn jẹ́ kí wọ́n kùnà láti di ìjọba àwọn àlùfáà àti orílẹ̀-èdè mímọ́. (Ro 11:7, 20) Torí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di aláìṣòótọ́, Ọlọ́run ti kìlọ̀ fún wọn tẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ wòlíì Hósíà ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn pé: “Nítorí pé wọ́n ti kọ̀ láti mọ̀ mí, èmi náà á kọ̀ wọ́n pé kí wọ́n má ṣe àlùfáà mi mọ́; àti nítorí pé wọ́n gbàgbé òfin Ọlọ́run wọn, èmi náà á gbàgbé àwọn ọmọ wọn.” (Ho 4:6) Ohun kan náà ni Jésù sọ fún àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù, ó ní: “A máa gba Ìjọba Ọlọ́run kúrò lọ́wọ́ yín, a sì máa fún orílẹ̀-èdè tó ń mú èso rẹ̀ jáde.” (Mt 21:43) Síbẹ̀, Jésù pa Òfin Mósè mọ́ nígbà tó wà láyé, ó sì gbà pé ìlà ìdílé Áárónì ṣì ń báṣẹ́ lọ, ìdí nìyẹn tó fi sọ́ fún àwọn alárùn ẹ̀tẹ̀ tó wò sàn pé kí wọ́n lọ fi ara wọn han àlùfáà, kí wọ́n sì mú ẹ̀bùn tí Òfin Mósè pa láṣẹ dání.—Mt 8:4; Mk 1:44; Lk 17:14.
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ẹ́kísódù
20:5—Ọ̀nà wo ni Jèhófà ń gbà ń fi “ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba” jẹ àwọn àtọmọdọ́mọ wọn? Lẹ́yìn tí ọmọ Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan bá ti dàgbà, ìwà àti ìṣe rẹ̀ ni wọ́n fi máa ń dá a lẹ́jọ́. Ṣùgbọ́n nígbà tí gbogbo orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí bọ̀rìṣà, àtìrandíran wọn ló jìyà ohun tí wọ́n ṣe. Kódà, èyí ò yọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ olùṣòtítọ́ sílẹ̀. Nítorí pé ìwàkiwà tí orílẹ̀-èdè náà mú wọnú ìjọsìn mú kó ṣòro fún wọn láti pa ìwà títọ́ mọ́.
AUGUST 31–SEPTEMBER 6
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 21-22
“Jẹ́ Kí Ẹ̀mí Jọ Ẹ́ Lójú Bíi Ti Jèhófà”
it-1 271
Lílù
Òfin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fàyè gba ẹnì kan tó ní ẹrú láti fi ọ̀pá na ẹrù rẹ̀ tí ẹrú náà bá ṣàìgbọràn tàbí tó ṣọ̀tẹ̀. Tí ẹrú náà bá kú bí ọ̀gá rẹ̀ ṣe ń lù ú, ṣe ni wọ́n máa fìyà jẹ ọ̀gá ẹrú náà. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ọjọ́ méjì tàbí mẹ́tà lẹ́yìn ìgbà yẹn ni ẹrú náà kú, ìyẹn máa jẹ́ ẹ̀rí pé ọ̀gá náà ò ní in lọ́kàn láti lù ú pa. Ọ̀gá ẹrú kan láṣẹ láti bá ẹrú rẹ̀ wí tó bá ṣàìgbọràn torí pé “owó” rẹ̀ ló fi rà á. Ó dájú pé ẹnì kan ò ní fẹ́ fọwọ́ ara rẹ̀ ba ohun ìní rẹ̀ jẹ́ torí ìyẹn máa jẹ́ kó pàdánù owó rẹ̀. Bákan náà, tó bá jẹ́ pé ẹrú kan kú lẹ́yìn ọjọ́ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lẹ́yìn tí ọ̀gá rẹ̀ lù ú, wọn ò lè mọ̀ bóyá lílù yẹn ló pa ẹrú náà tàbí nǹkan míì ló fa ikú rẹ̀. Torí náà, tí ẹrú kan bá kú lẹ́yìn ọjọ́ kan tàbí méjì tí ọ̀gá rẹ̀ lù ú, wọn ò ní fìyà jẹ ọ̀gá náà rárá.—Ẹk 21:20, 21.
Ṣé Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Ẹ̀mí Lo Fi Ń Wò Ó?
Ẹ̀mí àwọn ọmọ inú oyún pàápàá ṣeyebíye lójú Ọlọ́run. Láyé ọjọ́un, lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, ẹnikẹ́ni tó bá ta lu aláboyún tí aláboyún náà tàbí ọmọ rẹ̀ sì kú ti jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, ó ti di apààyàn, ẹ̀mí ara ẹ̀ ló sì máa fi dí i, ìyẹn ló túmọ̀ sí “ọkàn fún ọkàn.” (Ka Ẹ́kísódù 21:22, 23) O lè wá fojú yàwòrán bí nǹkan ṣe máa ń rí lára Jèhófà tó bá rí báwọn èèyàn ṣe ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣẹ́ ọ̀kẹ́ àìmọye oyún dà nù lọ́dọọdún, bóyá nítorí pé wọn ò tíì nílò wọn báyìí tàbí bóyá nítorí ìwà ìṣekúṣe tó ti jàrábà wọn.
Jèhófà Fẹ́ Kó O Wà ní “Àlàáfíà” àti Láìséwu
Lábẹ́ òfin, ìjìyà tún wà fún ẹni tí ẹranko agbéléjẹ̀ rẹ̀ bá ṣe èèyàn léṣe. Bí màlúù bá kan ẹnì kan pa, ẹni tó ni màlúù náà gbọ́dọ̀ pa á kó má bàa tún ṣe àwọn míì ní jàǹbá. Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹran màlúù náà tàbí kó tà á fún jíjẹ, àdánù ńlá ni pípa ẹranko náà máa jẹ́ fún un. Àmọ́, ká sọ pé ẹni tó ni màlúù náà kò sé e mọ́ lẹ́yìn tó ti ṣe ẹnì kan léṣe ńkọ́? Kí ló máa tìdí ẹ̀ yọ? Bí màlúù kan náà yẹn bá pa ẹnì kan lẹ́yìn ìgbà yẹn, pípa ni wọ́n máa pa màlúù náà àti olówó rẹ̀. Òfin yìí mú kó pọn dandan fún olúkúlùkù láti fọwọ́ pàtàkì mú àbójútó ohun ọ̀sìn rẹ̀.—Ẹ́kís. 21:28, 29.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Ya Ara Rẹ Sí Mímọ́ Fún Jèhófà?
Ọ̀ràn pàtàkì ni ìyàsímímọ́ àwa Kristẹni jẹ́. Kì í wulẹ̀ ṣe àdéhùn ṣákálá kan lásán. Àmọ́ àǹfààní wo là ń rí nínú ṣíṣe ìyàsímímọ́? Ẹ jẹ́ ká fọ̀rọ̀ yìí wé àǹfààní tó wà nínú pé kí àwọn èèyàn tó bára wọn ṣàdéhùn máa ṣe ojúṣe wọn. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ìwọ àti ẹnì kan yàn láti máa bára yín ṣọ̀rẹ́. Kó o tó lè gbádùn ọ̀rẹ́ rẹ dáadáa, o ní láti máa ṣe ohun tó fi ẹ́ hàn bí ọ̀rẹ́ gidi. Èyí fi hàn pé o gbọ́dọ̀ máa fi ọ̀rọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ sọ́kàn, kó o sì máa gba tiẹ̀ rò. Ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ tí ọ̀rọ̀ wọn wọ̀ jù lọ tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn ni Dáfídì àti Jónátánì. Kódà, wọ́n bára wọn dá májẹ̀mú. (Ka 1 Sámúẹ́lì 17:57; 18:1, 3.) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé irú ọ̀rẹ́ tí wọ́n bára wọn ṣe yẹn kò wọ́pọ̀, síbẹ̀ táwọn tó ń bára wọn ṣọ̀rẹ́ bá ń fi ọwọ́ pàtàkì mú àjọṣe tó wà láàárín àwọn méjèèjì, tí wọ́n ń ṣe ojúṣe wọn, àárín wọn á gún régé.—Òwe 17:17; 18:24.
Nínú Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, a tún rí irú àjọṣe míì tó máa ń ṣe àwọn èèyàn láǹfààní bí wọ́n bá fọwọ́ pàtàkì mú àdéhùn tí wọ́n bára wọn ṣe. Bí àpẹẹrẹ, tí ẹrú kan bá fẹ́ máa gbé títí lọ pẹ̀lú ọ̀gá rẹ̀ tó ń ṣe dáadáa sí i, ó lè bá ọ̀gá náà ṣe àdéhùn tí kò lè yí pa dà pé títí ayé ni òun á fi máa sìn ín. Òfin yẹn sọ pé: “Bí ẹrú náà bá fi ìtẹpẹlẹmọ́ wí pé, ‘Mo nífẹ̀ẹ́ ọ̀gá mi, aya mi àti àwọn ọmọ mi ní ti gidi; èmi kò fẹ́ jáde lọ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a dá sílẹ̀ lómìnira,’ nígbà náà, kí ọ̀gá rẹ̀ mú un sún mọ́ Ọlọ́run tòótọ́, kí ó sì mú un wá síbi ilẹ̀kùn tàbí òpó ilẹ̀kùn; kí ọ̀gá rẹ̀ sì fi òòlu lu etí rẹ̀, kí ó sì jẹ́ ẹrú rẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Ẹ́kís. 21:5, 6.
it-1 1143
Ìwo
Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ inú Ẹ́kísódù 21:14 túmọ̀ sí pé tí àlùfáà kan bá pààyàn, wọ́n gbọ́dọ̀ pa òun náà. Ó sì lè túmọ̀ sí pé tẹ́nì kan bá jẹ̀bi ẹ̀sùn ìpànìyàn, wọ́n máa pa òun náà, kódà tí ẹni náà bá lọ gbá ìwo pẹpẹ mú, ikú ò lè yẹ̀ lórí ẹ̀.—Fi wé 1Ọb 2:28-34.