Iṣẹ́ Àrà Inú Ìṣẹ̀dá Ń Gbé Jèhófà Ga
JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN ga lọ́lá ju gbogbo bí àwa ẹ̀dá èèyàn aláìpé ti rò lọ. Àwọn ohun tó dá sórí ilẹ̀ ayé àti sójú ọ̀run ń fi ìyìn fún un, wọ́n sì ń jẹ́ ká rí i pé Ọlọ́run tóbi lọ́ba.—Sáàmù 19:1-4.
Torí pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá àti Ọba Aláṣẹ Ayé òun Ọ̀run, ńṣe ló yẹ ká tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ nígbà tó bá ń bá wa sọ̀rọ̀. Ẹ ò rí i pé ìyàlẹ́nu gbáà ló máa jẹ́ fáwa ẹ̀dá èèyàn lásánlàsàn tí Ọlọ́run bá bá wa sọ̀rọ̀ lórí ilẹ̀ ayé! Ká ní pé ó gbẹnu áńgẹ́lì kan bá ọ sọ̀rọ̀ ńkọ́? Ó dájú pé ṣe ni wàá fara balẹ̀ gbọ́ ọ. Láìsí àní-àní, Jóòbù ọkùnrin olóòótọ́ ayé ìgbàanì fetí sílẹ̀ dáadáa nígbà tí Ọlọ́run ń bá a sọ̀rọ̀ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [3,500] ọdún sẹ́yìn. Kí la lè rí kọ́ látinú ohun tí Ọlọ́run sọ fún Jóòbù nípa ayé wa yìí àtàwọn nǹkan tí ń bẹ lójú ọ̀run?
Ta Ló Fi Ìpìlẹ̀ Ilẹ̀ Ayé Sọlẹ̀, Tó sì Tún Ń Darí Òkun?
Inú ìjì ẹlẹ́fùúùfù ni Ọlọ́run ti bi Jóòbù láwọn ìbéèrè kan nípa ilẹ̀ ayé àti òkun. (Jóòbù 38:1-11) Kò sí ayàwòrán ilé kankan tó ya bí ayé yìí á ṣe tóbi tó, tó sì ṣe é. Ọlọ́run fi ilẹ̀ ayé wé ilé, ó wá bi Jóòbù léèrè pé: “Ta ní fi òkúta igun rẹ̀ lélẹ̀?” Kò sí ẹ̀dá ọmọ aráyé kankan tó ṣe é! Tayọ̀tayọ̀ làwọn áńgẹ́lì ọmọ Ọlọ́run ń wo Jèhófà nígbà tó ń dá ilẹ̀ ayé yìí.
Bí ọmọ kékeré ni òkun rí lọ́wọ́ Ọlọ́run, ẹni tó fi aṣọ wọ̀ ọ́ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Òkun “bẹ̀rẹ̀ sí jáde lọ bí ìgbà tí ó ya jáde láti inú ilé ọlẹ̀.” Ọlọ́run sé òkun mọ́ bí ìgbà tó fi ọ̀pá ìdábùú àtàwọn ilẹ̀kùn tó ní kọ́kọ́rọ́ tì í mọ́ ibì kan, ó sì ń fi òṣùpá àti oòrùn darí ìṣa òun ìyọ omi.
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé: “Afẹ́fẹ́ ló sábà ń mú kí òkun ru, kó máa bì síwá-sẹ́yìn díẹ̀díẹ̀ tàbí kó mú kó ru dé ìwọ̀n ọgọ́rùn-ún ẹsẹ̀ bàtà (ọgbọ̀n mítà) sókè. . . . Tí afẹ́fẹ́ ò bá tiẹ̀ fẹ́ mọ́, ìgbì náà yóò ṣì máa bì síwá-sẹ́yìn lọ lójú òkun títí táá fi bẹ̀rẹ̀ sí sẹ́ wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́, ó sì lè máa ṣe bẹ́ẹ̀ lọ débi tó jìnnà gan-an. Níkẹyìn, ìgbì náà á bì dé etíkun níbi tí kò ti ní lágbára mọ́ táá sì di ìfófòó.” Àṣẹ Ọlọ́run ni òkun ń tẹ̀ lé, àṣẹ náà sì ni pé: “Ìhín yìí ni o lè dé mọ, má sì ṣe ré kọjá; ìhín yìí sì ni kí ìgbì rẹ tí ń ru gùdù mọ.”
Ta Ló Ń Mú Kí Ọ̀yẹ̀ Là?
Lẹ́yìn ìyẹn, Ọlọ́run béèrè ìbéèrè kan lọ́wọ́ Jóòbù nípa ìmọ́lẹ̀ àtàwọn nǹkan mìíràn. (Jóòbù 38:12-18) Kò sí ẹ̀dá èèyàn kankan tó lè mú kí ilẹ̀ ṣú kó sì tún mú kí ilẹ̀ mọ́. Ìmọ́lẹ̀ máa ń di àwọn ìkángun ilẹ̀ ayé mú lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ ó sì máa ń gbọn àwọn ẹni burúkú inú rẹ̀ dà nù. Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lè fi “òkùnkùn alẹ́” bora kí wọ́n máa ṣe iṣẹ́ ibi wọn. (Jóòbù 24:15, 16) Àmọ́, ọ̀pọ̀ àwọn aṣebi ló máa tú ká nígbà tí ọ̀yẹ̀ bá là, ìyẹn tí ilẹ̀ bá mọ́.
Ńṣe ni oòrùn àárọ̀ dà bí èdìdì tàbí òǹtẹ̀ tí Ọlọ́run fi lu ilẹ̀ ayé tó mú kí ẹwà rẹ̀ yọ. Oòrùn ló máa ń jẹ́ ká rí oríṣiríṣi àwọ̀ táá fi dà bíi pé ilẹ̀ ayé wọ aṣọ aláràbarà. Kò séyìí tí Jóòbù ṣe nínú gbogbo iṣẹ́ yìí o, bẹ́ẹ̀ ni kò rìn káàkiri nínú ibú omi kó lè mọ ìṣúra tí ń bẹ nínú rẹ̀. Kẹ́ ẹ sì wá wò ó o, ìwọ̀nba díẹ̀ làwọn tó ń ṣèwádìí mọ̀ nípa ẹ̀dá inú òkun títí dòní olónìí!
Ta Lẹni Tó Ni Ilé Tí Ìrì Dídì àti Yìnyín Wà?
Kò sẹ́ni tó tẹ̀ lé ìmọ́lẹ̀ tàbí òkùnkùn délé rẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ ni kò sẹ́ni tó tíì wọlé ìrì dídì àti yìnyín, èyí tí Ọlọ́run pa mọ́ “de ọjọ́ ìjà àti ogun.” (Jóòbù 38:19-23) Nígbà tí Jèhófà fi yìnyín bá àwọn ọ̀tá rẹ̀ jà ní Gíbéónì, ‘àwọn tí ó kú láti ọwọ́ òkúta yìnyín pọ̀ ju àwọn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi idà pa lọ.’ (Jóṣúà 10:11) Ó lè jẹ́ pé yìnyín tá ò mọ bó ṣe máa tóbi tó ni Jèhófà yóò fi pa àwọn èèyàn búburú tó wà lẹ́yìn Gọ́ọ̀gù, ìyẹn Sátánì.—Ìsíkíẹ́lì 38:18, 22.
Ní oṣù July ọdún 2002, òkúta yìnyín tó tóbi tó ẹyin adìyẹ bẹ̀rẹ̀ sí já lu àwọn èèyàn lórí ní ìpínlẹ̀ Henan lórílẹ̀-èdè Ṣáínà. Èèyàn márùndínlọ́gbọ̀n ló kú sí i, igba [200] èèyàn sì fara pa yánnayànna. Nígbà tí gbẹ́nàgbẹ́nà ọmọ ilẹ̀ Ítálì kan tó ń jẹ́ Benvenuto Cellini ń sọ̀rọ̀ nípa òjò yìnyín kan tó rọ̀ lọ́dún 1545, ó kọ̀wé pé: “Ó ku ìrìn àjò ọjọ́ kan lórí ẹṣin ká dé ìlú Lyons nígbà tí ààrá bẹ̀rẹ̀ sí sán tó sì ń pariwo burúkú-burúkú. . . . Nígbà tí ààrá sán tán, ariwo ńlá kan dún lójú ọ̀run, ariwo ọ̀hún ga débi pé mo rò pé ayé ti pa rẹ́. Torí náà mo dá ẹṣin mi dúró fún ìṣẹ́jú díẹ̀, yìnyín sì ń já bọ́ láìsí omi kankan. . . . Yìnyín kéékèèké ló kọ́kọ́ ń já bọ́, nígbà tó yá èyí tó tóbi tó òroǹbó ńlá bẹ̀rẹ̀ sí já bọ́. . . . Ó ṣe díẹ̀ kí ìjì rẹ̀ tó rọlẹ̀ . . . A wá ń fi ibi tí yìnyín ti ṣe wá léṣe han ara wa; àmọ́ nígbà tá a fi máa rìn síwájú ní ìwọ̀n ibùsọ̀ kan, a dé ibi igbó kan tí ìjì náà ti ṣọṣẹ́ gan-an tó jẹ́ pé ẹní bá débẹ̀ nìkan ló lè sọ. Gbogbo ewé orí igi ni ìjì náà ti gbọ̀n dà nù; àìmọye òkú àwọn ẹran nílẹ̀; ọ̀pọ̀ àwọn darandaran ló ṣòfò ẹ̀mí; a rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ òkúta yìnyín nílẹ̀ tó jẹ́ pé ọwọ́ èèyàn méjèèjì ò lè ká ọ̀kọ̀ọ̀kan rẹ̀.”—Ìwé Autobiography (Ìwé Kejì, 50), Harvard Classics, Ìdìpọ̀ 31, ojú ìwé 352 àti 353.
Kí ló máa ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jèhófà bá ṣílẹ̀kùn ibi tí ìrì dídì àti yìnyín wà láti fi bá àwọn ọ̀tá rẹ̀ jà? Kò ní sọ́nà àbáyọ kankan fáwọn ọ̀tá wọ̀nyí nígbà tí Ọlọ́run bá lo ìrì dídì tàbí yìnyín láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ.
Ta Ló Ṣe Òjò, Ìrì, Ìrì Dídì Wínníwínní, àti Omi Dídì?
Ìbéèrè tó kàn tí Jèhófà bi Jóòbù dá lórí òjò, ìrì, ìrì dídì wínníwínní àti omi dídì. (Jóòbù 38:24-30) Ọlọ́run ni Ẹni tó ṣe òjò, kódà ó ń rọ òjò sí “aginjù nínú èyí tí ará ayé kankan kò sí.” Kò sí ẹ̀dá ọmọ aráyé kankan tí í ṣe bàbá òjò, omi dídì, àti ìrì dídì wínníwínní.
Ìwé ìròyìn Nature Bulletin sọ pé: “Ohun kan tó ṣàjèjì jù lọ, bóyá tó tiẹ̀ ṣe pàtàkì jù lọ [nípa omi dídì] ni pé bí omi ṣe ń di yìnyín bẹ́ẹ̀ ló ń fẹ̀ sí i . . . Yìnyín tó máa ń léfòó sójú omi nígbà òtútù ni kì í jẹ́ kí ewéko àtàwọn ẹran (ẹja àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ) tó wà nínú omi kú. Ká . . . ní pé yìnyín wúwo ju omi lọ ni, ńṣe ni ì bá máa rì sínú odò torí pé kò ní lè léfòó. Bí yìnyín bá sì ṣe ń pọ̀ sí i lókè omi ni yóò máa lọ sísàlẹ̀ odò títí odò náà á fi dì gbagidi. . . . Tó bá sì wá lọ jẹ́ láwọn àgbègbè tó tutù gan-an láyé, ńṣe ni odò, adágún, àti agbami òkun pàápàá máa dì gbagidi.”
A mà dúpẹ́ o pé omi odò kì í dì gbagidi! A sì tún dúpẹ́ pé òjò àti ìrì tó jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ Jèhófà ń mú káwọn nǹkan ọ̀gbìn tó wà láyé ṣe dáadáa.
Ta Ló Gbé Àwọn Ìlànà Ọ̀run Kalẹ̀?
Ìbéèrè mìíràn tí Ọlọ́run bi Jóòbù dá lórí àwọn ohun tó wà lójú ọ̀run. (Jóòbù 38:31-33) Àgbájọ ìràwọ̀ Kímà làwọn èèyàn ń pè ní ìràwọ̀ Píleyádésì, ìyẹn àgbájọ ìràwọ̀ tí ìràwọ̀ méje ńláńlá àtàwọn ìràwọ̀ kéékèèké míì wà nínú rẹ̀. Tí ìmọ́lẹ̀ bá gbéra níbi tí ìràwọ̀ yìí wà, yóò gbà á ní okòódínnírínwó [380] ọdún kó tó débi tí oòrùn wà. Bẹ́ẹ̀ kẹ̀ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta kìlómítà ni ìmọ́lẹ̀ fi ń rìn láàárín ìṣẹ́jú àáyá kan. Kò sí ẹ̀dá èèyàn tó “lè so àwọn ìdè àgbájọ ìràwọ̀ Kímà pinpin,” ìyẹn ni pé èèyàn ò lè so wọ́n pọ̀. Kò sì sẹ́ni tó “lè tú . . . àwọn okùn àgbájọ ìràwọ̀ Késílì,” tí wọ́n ń pè ní àgbájọ ìràwọ̀ Óríónì. Orúkọ yòówù tí ẹ̀dá èèyàn ì báà máa pe àgbájọ ìràwọ̀ Másárótì àti àgbájọ ìràwọ̀ Ááṣì, òótọ́ ibẹ̀ ni pé wọn ò lè darí wọn tàbí kí wọ́n ṣàkóso wọn. Ẹ̀dá èèyàn ò lè ṣe ìyípadà kankan sí “àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ ọ̀run,” ìyẹn àwọn ìlànà tí ayé òun ìsálú ọ̀run ń tẹ̀ lé.
Ọlọ́run ló gbé ìlànà tí oòrùn, òṣùpá àtàwọn ìràwọ̀ ń tẹ̀ lé kalẹ̀, àwọn nǹkan wọ̀nyí ló sì ń darí ojú ọjọ́, ìṣa òun ìyọ omi, afẹ́fẹ́ àtàwọn ohun ẹlẹ́mìí tó wà nínú ayé. Ẹ jẹ́ ká fi ti oòrùn ṣàpẹẹrẹ. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia Americana (ẹ̀dà ti ọdún 1996) sọ nípa oòrùn pé: “Oòrùn ló ń jẹ́ kí ooru àti ìmọ́lẹ̀ wà ní ilẹ̀ ayé, òun ló ń mú kí nǹkan ọ̀gbìn àti ewéko dàgbà, òun ló ń fa omi tó wà nínú òkun àtàwọn odò lọ sí àwọsánmà, ó wà lára ohun tó ń jẹ́ kí afẹ́fẹ́ máa fẹ́, ó sì tún máa ń ṣe ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan pàtàkì míì tó ń jẹ́ kí àwọn ẹ̀dá ẹlẹ́mìí gbádùn ayé wọn.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan náà tún sọ pé: “Téèyàn bá fẹ́ mọ bí agbára oòrùn ṣe tó, kéèyàn ṣáà ronú pé látinú ìwọ̀nba oòrùn tó ń ràn dénú ayé láti àádọ́jọ [150] mílíọ̀nù kìlómítà tí oòrùn wà sí ayé ni afẹ́fẹ́, àwọn adágún omi, odò, àwọn nǹkan bí igi, èédú àti epo rọ̀bì ti ń rí gbogbo agbára tí wọ́n ní.”
Ta Ló Fi Ọgbọ́n Sínú Àwọsánmà?
Jèhófà sọ fún Jóòbù pé kó ronú nípa àwọsánmà. (Jóòbù 38:34-38) Èèyàn ò lè ṣe àwọsánmà kó sì mú kí òjò rọ̀. Láìsí ètò tí Ẹlẹ́dàá ṣe pé kí oòrùn máa fa omi lọ sí ojú ọ̀run kó sì padà máa rọ òjò sórí ilẹ̀ ayé, kò sóhun tí ẹ̀dá èèyàn ì bá lè gbé ṣe!
Báwo ni Ọlọ́run ṣe ṣètò yìí? Ìwé kan sọ pé: “Nínú ètò bí omi ṣe ń lọ yípo, ohun mẹ́rin ló máa ń ṣẹlẹ̀. Omi máa ń wà ní ìpamọ́ fúngbà díẹ̀ nínú ilẹ̀, tàbí nínú òkun, adágún tàbí odò, ó sì lè jẹ́ yìnyín tàbí òkìtì yìnyín. Lẹ́yìn náà oòrùn á fà lára omi náà lọ sí ojú ọ̀run níbi tó ti máa gbára jọ, lẹ́yìn ìyẹn omi náà yóò tún padà wá sórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí òjò tàbí yìnyín, níkẹyìn yóò wá ṣàn lọ sínú òkun tàbí kí oòrùn tún fà á lọ sójú ọ̀run. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo omi tó wà láyé yìí ni oòrùn ti fà lọ sójú ọ̀run tó sì tún padà rọ òjò láìmọye ìgbà.”—Microsoft Encarta Reference Library 2005.
Òjò tó ṣú dẹ̀dẹ̀ dà bí ìṣà omi lójú ọ̀run. Bí Jèhófà bá da omi inú rẹ̀ jáde, òjò lè bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀ gan-an débi pé eruku á di ẹrẹ̀, iyẹ̀pẹ̀ tó wà lórí ilẹ̀ á sì ṣù mọ́ra. Ọlọ́run lè rọ òjò, ó sì tún lè ṣe é kí òjò má rọ̀.—Jákọ́bù 5:17, 18.
Lọ́pọ̀ ìgbà tí òjò bá rọ̀ mànàmáná máa ń kọ, àmọ́ èèyàn ò lágbára lórí mànàmáná. Ìwé Jóòbù sọ ọ́ bíi pé àwọn mànàmáná ń padà lọ jíṣẹ́ fún Ọlọ́run pé “Àwa rèé!” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Compton’s Encyclopedia sọ pé: “Mànàmáná máa ń mú kí àwọn nǹkan kan yí padà nínú afẹ́fẹ́. Bí mànàmáná ṣe ń kọ yẹ̀rì nínú afẹ́fẹ́, ó máa ń fa ooru tó lágbára débi pé yóò pa afẹ́fẹ́ nitrogen pọ̀ mọ́ afẹ́fẹ́ ọ́síjìn láti di èròjà nitrate àtàwọn èròjà míì. Nígbà tí òjò bá sì rọ̀, àwọn èròjà wọ̀nyí á bẹ̀rẹ̀ sí já bọ́. Nípa báyìí, ìgbà gbogbo ni afẹ́fẹ́ àyíká máa ń pèsè àwọn èròjà tó máa ń fún ilẹ̀ ní ọ̀rá tó máa mú kí irè oko ṣe dáadáa.” Àdììtú ni mànàmáná ṣì jẹ́ fọ́mọ aráyé títí dòní, àmọ́ kì í ṣe àdììtú fún Ọlọ́run.
Iṣẹ́ Àrà inú Ìṣẹ̀dá Ń Fi Ògo fún Ọlọ́run
Lóòótọ́ ni iṣẹ́ àrà inú ìṣẹ̀dá ń gbé Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo ga. (Ìṣípayá 4:11) Ó dájú pé àwọn nǹkan tí Jèhófà sọ fún Jóòbù nípa ilẹ̀ ayé àti òṣùpá àtàwọn ìràwọ̀ tó wà lójú ọ̀run á wú u lórí gan-an ni!
Kì í ṣe àwọn iṣẹ́ àrà inú ìṣẹ̀dá tá a sọ̀rọ̀ lé lórí yìí nìkan ni Ọlọ́run béèrè nípa rẹ̀ lọ́wọ́ Jóòbù bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ìwọ̀nyí nìkan ni gbogbo ohun tó sọ fún un nípa ìṣẹ̀dá. Síbẹ̀, àwọn tá a ti gbé yẹ̀ wò yìí ń mú ká polongo pé: “Kíyè sí i! Ọlọ́run ga ju bí a ṣe lè mọ̀.”—Jóòbù 36:26.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 14]
Ìrì dídì: snowcrystals.net
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 15]
Ìràwọ̀ Píleyádésì: NASA, ESA àti AURA/Caltech; ẹja: U.S. Fish & Wildlife Service, Washington, D.C./William W. Hartley