Jóòbù
36 Élíhù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé:
2 “Ní sùúrù fún mi díẹ̀ sí i kí n lè ṣàlàyé,
Torí mo ṣì ní ohun tí mo fẹ́ gbẹnu sọ fún Ọlọ́run.
3 Màá sọ̀rọ̀ dáadáa nípa ohun tí mo mọ̀,
Màá sì ka Aṣẹ̀dá mi sí olódodo.+
4 Ó dájú pé àwọn ọ̀rọ̀ mi kì í ṣe irọ́;
Ẹni tí ìmọ̀ rẹ̀ pé+ nìyí níwájú rẹ.
7 Kì í gbé ojú rẹ̀ kúrò lára àwọn olódodo;+
Ó ń fi wọ́n sórí ìtẹ́ pẹ̀lú àwọn ọba,*+ ó sì gbé wọn ga títí láé.
8 Àmọ́ tí a bá fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ dè wọ́n,
Tí a sì fi okùn ìpọ́njú dè wọ́n,
9 Ó ń fi ohun tí wọ́n ṣe hàn wọ́n,
Ẹ̀ṣẹ̀ tí ìgbéraga mú kí wọ́n dá.
10 Ó ń ṣí etí wọn kí wọ́n lè gba ìtọ́sọ́nà,
Ó sì ń sọ fún wọn pé kí wọ́n yí pa dà kúrò nínú ìwà burúkú.+
11 Tí wọ́n bá ṣègbọràn tí wọ́n sì sìn ín,
Nǹkan á máa lọ dáadáa fún wọn jálẹ̀ ọjọ́ ayé wọn,
Àwọn ọdún wọn á sì dùn.+
13 Àwọn tí kò mọ Ọlọ́run* nínú ọkàn wọn máa ń di ìbínú sínú.
Wọn kì í kígbe fún ìrànlọ́wọ́ kódà nígbà tó bá dè wọ́n.
15 Àmọ́ Ọlọ́run* máa ń gba àwọn tí ìyà ń jẹ sílẹ̀;
Ó ń ṣí etí wọn nígbà tí wọ́n ń ni wọ́n lára.
16 Ó ń fà ọ́ kúrò ní bèbè ìdààmú+
Wá sí ibi tó fẹ̀, tí kò sí ìdílọ́wọ́,+
Tí oúnjẹ tó dọ́ṣọ̀ ti wà lórí tábìlì rẹ láti tù ọ́ nínú.+
17 Ìdájọ́ tó máa dé sórí ẹni burúkú máa wá tẹ́ ọ lọ́rùn,+
Nígbà tí a bá ṣèdájọ́ tí òdodo sì lékè.
19 Ṣé igbe tí ò ń ké fún ìrànlọ́wọ́,
Tàbí gbogbo bí o ṣe ń sapá gidigidi lè gbà ọ́ lọ́wọ́ wàhálà?+
20 Má ṣe retí òru,
Tí àwọn èèyàn kì í sí ní àyè wọn.
21 Ṣọ́ra kí o má lọ hùwà àìtọ́,
Kí o wá yan èyí dípò ìyà.+
22 Wò ó! A gbé Ọlọ́run ga nínú agbára rẹ̀;
Olùkọ́ wo ló dà bíi rẹ̀?
25 Gbogbo aráyé ti rí i,
Ẹni kíkú ń wò ó láti ọ̀ọ́kán.
32 Ó fi ọwọ́ rẹ̀ bo mànàmáná,
Ó sì dojú rẹ̀ kọ ohun tó fojú sùn.+
33 Ààrá rẹ̀ ń sọ̀rọ̀ rẹ̀,
Ẹran ọ̀sìn pàápàá ń sọ ẹni* tó ń bọ̀.