Ǹjẹ́ o Gbà Pé Àjíǹde Ń bọ̀ Lóòótọ́?
“Àjíǹde . . . yóò wà.”—ÌṢE 24:15.
1. Kí nìdí tó fi dà bíi pé ikú ò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀?
“DANDAN lowó orí, bẹ́ẹ̀ náà ni ikú. Kò sóhun tó dájú láyé yìí bí ikú àti owó orí.” Olóṣèlú kan ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà tó ń jẹ́ Benjamin Franklin ló kọ ọ̀rọ̀ yẹn lọ́dún 1789, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì kà á sí ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n. Bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í san iye owó orí tó yẹ kí wọ́n san tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ san án rárá. Ikú wá ńkọ́? Ó jọ pé ikú ò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. Tá a bá fi dídàá wa, kò sẹ́ni tí ì bá lè bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Gbogbo èèyàn ni ikú ń lé. Ṣìọ́ọ̀lù, ìyẹn ipò òkú, kì í nítẹ̀ẹ́lọ́rùn, ńṣe ló kàn ń já àwọn èèyàn wa gbà mọ́ wa lọ́wọ́. (Òwe 27:20) Àmọ́ ṣa o, ọ̀rọ̀ ìtùnú kan wà.
2, 3. (a) Kí nìdí tí kì í fi í ṣe gbogbo èèyàn ló máa tọ́ ikú wò bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe rò? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
2 Ọ̀rọ̀ Jèhófà sọ pé àwọn tó ti kú yóò jíǹde, ìrètí àjíǹde yìí sì dájú. Kì í ṣe àlá tí ò lè ṣẹ, kò sì sí alágbára kan láyé àtọ̀run tó lè dí Jèhófà lọ́wọ́ kó má jí òkú dìde. Àmọ́, àwọn èèyàn kan lè má tọ́ ikú wò rárá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ò mọ̀ bẹ́ẹ̀. Báwo làwọn kan ò ṣe ní tọ́ ikú wò rárá? Bó ṣe máa rí bẹ́ẹ̀ ni pé “ogunlọ́gọ̀ ńlá” èèyàn kan yóò la “ìpọ́njú ńlá” tó máa wáyé láìpẹ́ já. (Ìṣípayá 7:9, 10, 14) Wọ́n á wá máa wà láàyè lọ, àní wọ́n á lè wà títí láé. Nítorí náà, kì í ṣe dandan pé kí àwọn kú ní tiwọn. Yàtọ̀ síyẹn, “ikú ni a ó sọ di asán.”—1 Kọ́ríńtì 15:26.
3 Ó yẹ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run yóò jí àwọn òkú dìde, àní bó ṣe dá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lójú tó fi sọ pé: “Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” (Ìṣe 24:15) Ẹ jẹ́ ká gbé ìbéèrè mẹ́ta yẹ̀ wò nípa àjíǹde. Àkọ́kọ́, kí ló mú kí ìrètí àjíǹde dájú hán-ún? Ìkejì, báwo ni ìwọ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan ṣe lè jẹ́ kí ìrètí yìí tù ọ́ nínú? Ìkẹta, báwo ni ìrètí yìí ṣe lè nípa lórí ọ̀nà tó ò ń gbà gbé ìgbésí ayé rẹ nísinsìnyí?
Àjíǹde Dájú
4. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé àjíǹde gbọ́dọ̀ wáyé kí ohun tí Jèhófà pinnu láti ṣe tó lè nímùúṣẹ?
4 Ìdí tí ìrètí àjíǹde fi dájú pọ̀. Ìdí tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, àjíǹde gbọ́dọ̀ wáyé kí ohun tí Jèhófà pinnu láti ṣe tó lè nímùúṣẹ. Ṣó o rántí pé Sátánì kó aráyé sínú ẹ̀ṣẹ̀, èyí tó mú kó di dandan fún aráyé láti máa kú. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ nípa Sátánì pé: “Apànìyàn ni ẹni yẹn nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀.” (Jòhánù 8:44) Àmọ́ Jèhófà ṣèlérí pé “obìnrin” òun, ìyẹn ètò rẹ̀ lọ́run tó dà bí aya fún un, yóò mú “irú-ọmọ” kan jáde tó máa fọ́ “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀” yẹn ní orí, tàbí lédè mìíràn, tó máa pa Sátánì run ráúráú. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6, 15; Ìṣípayá 12:9, 10; 20:10) Bí Jèhófà ṣe ń sọ ìpinnu rẹ̀ nípa Irú-ọmọ tó jẹ́ Mèsáyà yìí di mímọ̀ díẹ̀díẹ̀, ó wá hàn gbangba pé Irú-ọmọ náà yóò tún ṣe ohun mìíràn yàtọ̀ sí pé kó pa Sátánì run. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Fún ète yìí ni a ṣe fi Ọmọ Ọlọ́run hàn kedere, èyíinì ni, láti fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú.” (1 Jòhánù 3:8) Ikú tí ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù fà ló burú jù lọ lára àwọn iṣẹ́ Sátánì tí Jèhófà ṣèlérí pé òun yóò lo Jésù Kristi láti mú kúrò tàbí láti fọ́ túútúú. Kí èyí tó lè ṣeé ṣe, a nílò ẹbọ ìràpadà Jésù, àjíǹde òkú sì gbọ́dọ̀ wáyé.—Ìṣe 2:22-24; Róòmù 6:23.
5. Kí nìdí tí àjíǹde fi máa ṣe orúkọ Jèhófà lógo?
5 Ìdí mìíràn tí àjíǹde fi dájú ni pé, Jèhófà ti pinnu pé òun á ṣe orúkọ mímọ́ òun lógo. Sátánì ba Ọlọ́run lórúkọ jẹ́ ó sì ń mú kí irọ́ tàn kálẹ̀. Ó parọ́ pé Ádámù àti Éfà ‘ò ní kú’ tí wọ́n bá jẹ èso tí Ọlọ́run sọ pé wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ. (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17; 3:4) Látìgbà yẹn wá ni Sátánì ti ń mú kí àwọn irọ́ mìíràn tó jọ ìyẹn tàn kálẹ̀, irú bí ẹ̀kọ́ èké táwọn kan fi ń kọ́ni pé ẹ̀mí máa ń jáde kúrò nínú ara láti lọ máa gbé níbòmíràn nígbà téèyàn bá kú. Àmọ́, jíjí tí Jèhófà máa jí àwọn òkú dìde ló máa fi hàn pé irọ́ gbuu ni irú àwọn ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀. Jèhófà máa fìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí láé pé, òun nìkan ni Ẹni tó ń pa ìwàláàyè mọ́ tó sì ń dá a padà fúnni.
6, 7. Báwo ni ọ̀rọ̀ jíjí òkú dìde ṣe rí lára Jèhófà, báwo la sì ṣe mọ̀?
6 Ìdí mìíràn tí àjíǹde fi dájú ni pé, ó ń wu Jèhófà gan-an láti jí òkú dìde. Bíbélì jẹ́ ká mọ bí ọ̀rọ̀ jíjí òkú dìde ṣe rí lára Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, Jóòbù tó jẹ́ olóòótọ́ sọ ọ̀rọ̀ kan tí Ọlọ́run mí sí, ó ní: “Bí abarapá ènìyàn bá kú, ó ha tún lè wà láàyè bí? Jálẹ̀ gbogbo ọjọ́ òpò tí mo ní láti ṣe lápàpàǹdodo ni èmi yóò fi dúró, títí ìtura mi yóò fi dé. Ìwọ yóò pè, èmi fúnra mi yóò sì dá ọ lóhùn. Ìwọ yóò ṣe àfẹ́rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.” (Jóòbù 14:14, 15) Kí lọ̀rọ̀ tí Jóòbù sọ yìí túmọ̀ sí?
7 Jóòbù mọ̀ pé tóun bá kú, òun máa ní láti sùn nínú ikú fún àkókò kan. Ó ka àkókò tó fi máa sùn náà sí ‘òpò àpàpàǹdodo,’ ìyẹn àkókò tó pọn dandan pé kó fi sùn nínú ikú títí dìgbà tó máa rí ìtúsílẹ̀. Ó mọ̀ pé òun máa rí ìtúsílẹ̀ dájúdájú, àti pé ìtura òun ń bọ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó mọ bí ọ̀rọ̀ àjíǹde ṣe rí lára Jèhófà. Jèhófà yóò ‘ṣe àfẹ́rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀,’ ìyẹn ni pé yóò máa hára gàgà láti tún rí ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ padà. Bẹ́ẹ̀ ni o, ó ń wu Ọlọ́run gan-an láti mú kí gbogbo àwọn olódodo tó ti kú padà wà láàyè. Ó tún máa fún àwọn míì yàtọ̀ sí àwọn olódodo láǹfààní láti wa láàyè títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. (Lúùkù 23:43; Jòhánù 5:28, 29) Níwọ̀n bó ti jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run láti ṣe bẹ́ẹ̀, ta ló wá lè dí i lọ́wọ́?
8. Báwo ni Jèhófà ṣe “pèsè ẹ̀rí ìfọwọ́sọ̀yà” pé àjíǹde ọjọ́ iwájú dájú?
8 Ẹ jẹ́ ká tún wo ìdí mìíràn tí àjíǹde fi dájú. Ìdí ọ̀hún ni pé, jíjí tí Jésù jíǹde mú kí ìrètí ọjọ́ ọ̀la wa dájú. Nígbà kan tí Pọ́ọ̀lù ń bá àwọn kan sọ̀rọ̀ ní Áténì, ó ní: “[Ọlọ́run] ti dá ọjọ́ kan nínú èyí tí ó pète láti ṣèdájọ́ ilẹ̀ ayé tí a ń gbé ní òdodo nípasẹ̀ ọkùnrin kan tí ó ti yàn sípò, ó sì ti pèsè ẹ̀rí ìfọwọ́sọ̀yà fún gbogbo ènìyàn ní ti pé ó ti jí i dìde kúrò nínú òkú.” (Ìṣe 17:31) Ńṣe làwọn kan lára àwọn tó ń gbọ́rọ̀ Pọ́ọ̀lù fi í rẹ́rìn-ín nígbà tó mẹ́nu kan àjíǹde. Àmọ́, àwọn míì lára wọn di onígbàgbọ́. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù tó fi hàn pé “ẹ̀rí ìfọwọ́sọ̀yà” wà pé Ọlọ́run á jí òkú dìde dájúdájú ló wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Iṣẹ́ ìyanu tó tóbi jù lọ ni Jèhófà ṣe nígbà tó jí Jésù dìde. Ó jí i dìde gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára. (1 Pétérù 3:18) Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ipò rẹ̀ tún wá ga ju ipò tó wà kó tó wá sáyé gẹ́gẹ́ bí èèyàn. Ó di ẹ̀dá aláìleèkú, òun sì ni agbára rẹ̀ pọ̀ jù lẹ́yìn ti Jèhófà. Èyí mú kó wà ní ipò tí Bàbá rẹ̀ fi lè gbé iṣẹ́ bàǹtà-banta lé e lọ́wọ́. Jésù ni Jèhófà gbé iṣẹ́ jíjí òkú dìde lé lọ́wọ́, yálà àjíǹde sí ọ̀run tàbí sórí ilẹ̀ ayé. Jésù alára sọ pé: “Èmi ni àjíǹde àti ìyè.” (Jòhánù 5:25; 11:25) Ńṣe ni Jèhófà fi jíjí tó jí Ọmọ rẹ̀ dìde ṣe ẹ̀rí pé, ìrètí àjíǹde tí gbogbo àwọn olóòótọ́ ní máa nímùúṣẹ dájúdájú.
9. Báwo ni àkọsílẹ̀ Bíbélì ṣe fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àjíǹde dájú?
9 Ìdí tó kẹ́yìn tí àjíǹde fi dájú ni pé, àjíǹde òkú ti wáyé níṣojú àwọn èèyàn rí, àkọsílẹ̀ rẹ̀ sì wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bíbélì ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa àjíǹde àwọn èèyàn mẹ́jọ kan tó wáyé lórí ilẹ̀ ayé ńbí. Ìkọ̀kọ̀ kọ́ làwọn iṣẹ́ ìyanu náà ti wáyé o, gbangba ni, ó sì sábà máa ń jẹ́ níṣojú àwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, Jésù jí Lásárù dìde lẹ́yìn ọjọ́ kẹrin tó ti kú. Èyí ṣẹlẹ̀ níṣojú àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀, ó sì dájú pé àwọn ìbátan Lásárù wà lára wọn, tó fi mọ́ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ àtàwọn aládùúgbò rẹ̀. Ẹ̀rí yìí tó fi hàn pé Ọlọ́run ló rán Jésù wá sáyé lágbára débi pé àwọn ẹlẹ́sìn tó jẹ́ ọ̀tá Jésù pàápàá ò jiyàn rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n kúkú gbìmọ̀ pọ̀ láti pa Jésù àti Lásárù! (Jòhánù 11:17-44, 53; 12:9-11) Bẹ́ẹ̀ ni o, ó dá wa lójú pé àjíǹde máa wáyé dandan. Ọlọ́run mú kí wọ́n ṣàkọsílẹ̀ àwọn àjíǹde tó wáyé láyé ọjọ́un kó lè máa tù wá nínú kó sì mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára.
Bí Ìrètí Àjíǹde Ṣe Lè Tù Ọ́ Nínú
10. Kí ló máa jẹ́ káwọn àjíǹde tí àkọsílẹ̀ rẹ̀ wà nínú Bíbélì tù wá nínú?
10 Ǹjẹ́ ò ń wá ìtùnú nítorí ikú tó ń pa àwa èèyàn? Ó dájú pé àkọsílẹ̀ àwọn àjíǹde tó wà nínú Bíbélì máa fún ẹ ní irú ìtùnú bẹ́ẹ̀. Tó o bá ń ká irú àwọn àkọsílẹ̀ bẹ́ẹ̀, tó ò ń ronú jinlẹ̀ lé wọn lórí, tó o sì ń fojú inú rí bí wọ́n ṣe ṣẹlẹ̀, á mú kó o túbọ̀ gbà gbọ́ pé àjíǹde máa wáyé lóòótọ́. (Róòmù 15:4) Àlọ́ lásán kọ́ làwọn àkọsílẹ̀ náà o. Àwọn tó jíǹde wọ̀nyẹn jẹ́ èèyàn ẹlẹ́ran ara bíi tiwa tí wọ́n gbénú ayé kan náà yìí nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Wàyí o, jẹ́ ká jíròrò ọ̀kan lára àwọn àjíǹde náà ní ṣókí. Àjíǹde tó kọ́kọ́ wáyé nínú ìtàn Bíbélì la máa gbé yẹ̀ wò.
11, 12. (a) Ohun ìbànújẹ́ wo ló ṣẹlẹ̀ sí opó Sáréfátì, irú ọ̀rọ̀ wo ló sì kọ́kọ́ sọ? (b) Ṣàlàyé ohun tí Jèhófà mú kí wòlíì rẹ̀ Èlíjà ṣe fún opó náà.
11 Fojú inú wo bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé. Ó ti tó ọ̀sẹ̀ mélòó kan tí opó Sáréfátì ti gba wòlíì Èlíjà lálejò tí wòlíì náà sì ń gbé nínú yàrá kan tó wà lórí òrùlé ilé rẹ̀. Nǹkan ò dáa lákòókò tá à ń wí yìí. Ọ̀dá àti ìyàn ń han àwọn èèyàn léèmọ̀ lágbègbè náà. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń kú. Jèhófà sì ti lo Èlíjà láti ṣe iṣẹ́ ìyanu kan tó fi jẹ́ pé oúnjẹ opó aláìní yìí ò tán fún ìgbà pípẹ́ láti lè san èrè fún opó náà nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀. Nǹkan tí opó yìí àti ọmọdékùnrin rẹ̀ ń retí tẹ́lẹ̀ ni pé kí ebi pa àwọn kú, nítorí pé ìwọ̀nba oúnjẹ tó kù wọ́n kù ni wọ́n fẹ́ sè jẹ. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run mú kí Èlíjà ṣiṣẹ́ ìyanu tó fi jẹ́ pé ìyẹ̀fun àti òróró náà ò tán. Àmọ́ ohun ìbànújẹ́ kan wá ṣẹlẹ̀ sí opó náà wàyí. Àìsàn ṣàdédé kọ lu ọmọ rẹ̀, kò sì pẹ́ tó fi gbẹ́mìí mì. Ìbànújẹ́ tó bá a kọjá sísọ! Ẹni tó jẹ́ pé sí ọkọ tó lè fẹ̀yìn tì mọ́, tí ọmọ kan ṣoṣo tó bí tún wá kú. Ìbànújẹ́ rẹ̀ tiẹ̀ pọ̀ débi pé ó dá Èlíjà àti Jèhófà Ọlọ́run tí Èlíjà ń sìn lẹ́bi! Kí ni Èlíjà wá ṣe?
12 Èlíjà ò bá opó náà wí pé ó parọ́ mọ́ òun àti Jèhófà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló sọ pé: “Gbé ọmọkùnrin rẹ fún mi.” Nígbà tí Èlíjà sì gbé òkú ọmọ náà dé yàrá tó wà lórí òrùlé, ó gbàdúrà léraléra pé kí Jèhófà dá ẹ̀mí ọmọ náà padà. Nígbà tó yá, Jèhófà dá a lóhùn. Ìwọ wo bínú Èlíjà ṣe máa dùn tó nígbà tó rí i tí ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí í mí, tó sì lajú! Ó ti jíǹde! Èlíjà wá mú un lọ fún ìyá rẹ̀ ó sì sọ fún un pé: “Wò ó, ọmọkùnrin rẹ yè.” Inú opó náà dùn kọjá sísọ. Ó ní: “Mo mọ̀ wàyí, ní tòótọ́, pé ìwọ jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run àti pé ọ̀rọ̀ Jèhófà ní ẹnu rẹ jẹ́ òótọ́.” (1 Àwọn Ọba 17:8-24) Ìgbàgbọ́ tí obìnrin yìí ní nínú Jèhófà àti wòlíì tó ń ṣojú fún un wá lágbára sí i.
13. Kí nìdí tí àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa bí Èlíjà ṣe jí ọmọkùnrin opó kan dìde fi ń tù wá nínú lónìí?
13 Kò sí àní-àní pé wàá rí ìtùnú ńlá tó o bá ṣàṣàrò lórí irú àkọsílẹ̀ Bíbélì yìí. Ó hàn gbangba pé Jèhófà lágbára láti ṣẹ́gun ikú tó jẹ́ ọ̀tá wa! Ìwọ fojú inú wo bí àwọn tó máa ní irú ayọ̀ tí opó yẹn ní yóò ṣe pọ̀ tó láyé nígbà tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn òkú bá ń jíǹde lọ́jọ́ iwájú! Ayọ̀ àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó wà lọ́run pẹ̀lú yóò pọ̀ jọjọ bí Jèhófà bá ṣe ń fi ìdùnnú darí Ọmọ rẹ̀ kó máa jí òkú dìde jákèjádò ayé. (Jòhánù 5:28, 29) Tó bá ṣẹlẹ̀ pé èèyàn rẹ kan kú, fọkàn balẹ̀. Jèhófà lágbára láti jí àwọn òkú dìde, ó sì máa jí wọn dìde dájúdájú!
Bí Ìrètí Rẹ Ṣe Lè Nípa Lórí Ìgbésí Ayé Rẹ Nísinsìnyí
14. Báwo ni ìrètí àjíǹde ṣe lè nípa lórí ọ̀nà tó ò ń gbà gbé ìgbésí ayé?
14 Báwo ni ìrètí àjíǹde ṣe lè nípa lórí ọ̀nà tó ò ń gbà gbé ìgbésí ayé nísinsìnyí? Ìrètí yìí lè fún ẹ lókun nígbà ìpọ́njú, ìṣòro, inúnibíni tàbí nígbà tó o bá wà nínú ewu. Sátánì fẹ́ kó o bẹ̀rù ikú débi ti wàá fi pa ìṣòtítọ́ rẹ sí Jèhófà tì láti ṣe ohun àìníláárí kan tó lòdì táwọn èèyàn bá sọ pé òun ló máa yọ ẹ́. Má gbàgbé pé Sátánì sọ fún Jèhófà pé: “Ohun gbogbo tí ènìyàn bá sì ní ni yóò fi fúnni nítorí ọkàn rẹ̀.” (Jóòbù 2:4) Gbogbo wa ni Sátánì fi ọ̀rọ̀ tó sọ yìí bà lórúkọ jẹ́, títí kan ìwọ náà. Ṣé òótọ́ ni pé o ò ní sin Ọlọ́run mọ́ to o bá rí ìṣòro? Tó o bá ń ronú jinlẹ̀ nípa ìrètí àjíǹde, wàá lè jẹ́ kí ìpinnu rẹ pé o ò ní ṣíwọ́ ṣíṣe ìfẹ́ Bàbá rẹ ọ̀run túbọ̀ lágbára.
15. Báwo ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Mátíù 10:28 ṣe lè tù wá nínú tí ẹ̀mí wa bá wà nínú ewu?
15 Jésù sọ pé: “Ẹ má . . . bẹ̀rù àwọn tí ń pa ara ṣùgbọ́n tí wọn kò lè pa ọkàn; ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ bẹ̀rù ẹni tí ó lè pa àti ọkàn àti ara run nínú Gẹ̀hẹ́nà.” (Mátíù 10:28) Kò sídìí tó fi yẹ ká máa bẹ̀rù Sátánì àtàwọn èèyàn tó ń lò. Lóòótọ́, àwọn kan lára wọn lè kó ìnira bá wa, kódà wọ́n lè pa wá pàápàá. Àmọ́, bó ti wù kí ohun tí wọ́n fi ṣe wá burú tó, fúngbà díẹ̀ ni. Jèhófà lágbára láti mú aburú tí wọ́n bá ṣe sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ kúrò ó sì máa ṣe bẹ́ẹ̀, kódà ó máa jí wọn dìde. Jèhófà nìkan ló yẹ ká máa bẹ̀rù, òun nìkan ló yẹ ká kà sí ẹni ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ ká sì máa bọ̀wọ̀ tó ga jù lọ fún. Torí òun nìkan ló lágbára láti pa ẹnì kan run tónítọ̀hún ò sì ní jíǹde mọ́ láéláé, tó túmọ̀ sí pé ó pa ara ẹni náà àti ọkàn rẹ̀ run nínú Gẹ̀hẹ́nà. Àmọ́ ó dùn mọ́ni pé Jèhófà ò fẹ́ kírú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí ọ. (2 Pétérù 3:9) Níwọ̀n bá a ti mọ̀ dájú pé àjíǹde máa wáyé, ó dá àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run lójú pé ohun tó wù kó ṣẹlẹ̀, ìrètí ń bẹ fún wa. Tá a bá sáà ti ń ṣe ìfẹ́ Jèhófà láìyẹsẹ̀, ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun wà níwájú wa, Sátánì àtàwọn tó wà lábẹ́ rẹ̀ ò sì lè dènà ìyẹn rárá.—Sáàmù 118:6; Hébérù 13:6.
16. Báwo ni bí ìrètí àjíǹde ṣe rí lọ́kàn wa ṣe ń nípa lórí àwọn ohun tá a fi ṣáájú nígbèésí ayé?
16 Tó bá dá wa lójú pé àjíǹde máa wáyé lóòótọ́, ìyẹn máa nípa lórí ojú tá a fi ń wo ìgbésí ayé. A óò mọ̀ pé ‘yálà a wà láàyè tàbí a kú, a jẹ́ ti Jèhófà.’ (Róòmù 14:7, 8) Ìdí nìyẹn tá a fi máa ń fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sílò nígbà tá a bá ń pinnu ohun tá a máa fi ṣáájú nígbèésí ayé. Ìmọ̀ràn ọ̀hún ni pé: “Ẹ sì jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí, ṣùgbọ́n ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín padà, kí ẹ lè ṣàwárí fúnra yín ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.” (Róòmù 12:2) Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń fìkánjú wá bí wọ́n á ṣe tẹ́ ìfẹ́ wọn lọ́rùn, wọ́n ń fìkánjú wá bọ́wọ́ wọn ṣe máa tẹ ohun tí wọ́n ń fẹ́ àti gbogbo ohun tó bá sáà ti sọ sí wọn lọ́kàn. Nítorí pé ìwàláàyè kúrú lójú wọn, ńṣe ni wọ́n ń fi torí tọrùn wá adùn, tí wọ́n bá sì láwọn ń ṣèjọsìn, kì í bá ‘ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó pé’ mu.
17, 18. (a) Báwo ni Bíbélì Ọ̀rọ̀ Jèhófà ṣe jẹ́ kó hàn pé ìwàláàyè èèyàn kúrú, àmọ́ kí ló jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run fún wa? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa yin Jèhófà lójoojúmọ́?
17 Ká sòótọ́, ìwàláàyè èèyàn kúrú. “Kíákíá ni yóò kọjá lọ, àwa yóò sì fò lọ,” bóyá ní nǹkan bí àádọ́rin [70] tàbí ọgọ́rin [80] ọdún. (Sáàmù 90:10) Ńṣe làwọn èèyàn ń wá tí wọ́n sì ń lọ bíi koríko, bí òjìji tó ń kọjá lọ, bí èémí àmíjáde. (Sáàmù 103:15; 144:3, 4) Àmọ́ kì í ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run pé ká lo ìwọ̀nba ọdún díẹ̀ láti fi dàgbà, ká ní ìwọ̀nba ọgbọ́n àti ìrírí, kó wá di pé níwọ̀nba ọdún mélòó kan sí í, ara wa á máa daṣẹ́ sílẹ̀ díẹ̀díẹ̀ tí àìsàn àti ikú á sì wá gbẹ̀yìn rẹ̀. Ńṣe ni Jèhófà dá ìfẹ́ láti wà láàyè títí láé mọ́ àwa èèyàn. Bíbélì sọ fún wa pé: “Àkókò tí ó lọ kánrin ni ó ti fi sínú ọkàn-àyà wọn.” (Oníwàásù 3:11) Ṣé Ọlọ́run wá ṣèkà ni, tó dá irú ìfẹ́ yẹn mọ́ wa tí ò sì wá jẹ́ kọ́wọ́ wa lè tẹ̀ ẹ́? Rárá o, kò rí bẹ́ẹ̀, nítorí ó dájú pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Ó máa jí àwọn tó ti kú dìde kó bàa lè ṣeé ṣe fún wọn láti wà láàyè títí láé.
18 Níwọ̀n bá a ti ní ìrètí àjíǹde, ó dájú pé ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ ń bẹ fún wa. Kò yẹ ká máa sọ pé dandan ni kọ́wọ́ wa tẹ gbogbo ohun tá a fẹ́ nínú ètò àwọn nǹkan yìí, ká wá máa kánjú wá a. Kò sídìí tó fi yẹ ká lo ayé tó máa tó kọjá lọ yìí “dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 7:29-31; 1 Jòhánù 2:17) Àwa ò dà bí àwọn tí kò nírètí, nítorí Ọlọ́run jẹ́ ká ní ìmọ̀ àgbàyanu kan, ìyẹn ni pé: Tá a bá ń bá a nìṣó láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, títí láé la ó máa yìn ín tí a ó sì máa gbádùn ìwàláàyè wa. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká rí i pé à ń fojoojúmọ́ yin Jèhófà tó mú kí ìrètí àjíǹde dájú!
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Báwo ló ṣe yẹ kí ìrètí àjíǹde rí lára wa?
• Àwọn ìdí wo ni ìrètí àjíǹde fi dájú?
• Báwo ni ìrètí àjíǹde ṣe lè tù ọ́ nínú?
• Báwo ni ìrètí àjíǹde ṣe lè nípa lórí ọ̀nà tó ò ń gbà gbé ìgbésí ayé?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Jóòbù mọ̀ pé ó ń wu Jèhófà gan-an láti jí àwọn olódodo dìde
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
“Wò ó, ọmọkùnrin rẹ yè”