Ọlọrun Ha Mọ̀ Ọ́ Níti Gidi Bí?
“Oluwa, . . . gbogbo ọ̀nà mi . . . di mímọ̀ fún ọ.” —ORIN DAFIDI 139:1, 3.
1. Báwo ni ìmọ̀lára náà pé ‘àwọn mìíràn kò lóye’ àwọn àníyàn, ìṣòro, àti ìkìmọ́lẹ̀ tí a ń dojúkọ ti tànkálẹ̀ tó?
ẸNIKẸ́NI ha lóye àwọn àníyàn, ìkìmọ́lẹ̀, àti ìṣòro tí o dojúkọ níti gidi bí? Kárí-ayé àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ ènìyàn ni ń bẹ, lọ́mọdé àti lágbà, tí wọn kò ní ìdílé tàbí ẹbí tí ó bìkítà nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí wọn. Àní láàárín àwọn ìdílé pàápàá, ọ̀pọ̀lọpọ̀ aya—bẹ́ẹ̀ni, àti àwọn ọkọ pẹ̀lú—nímọ̀lára pé ẹnìkejì àwọn nínú ìgbéyàwó kò lóye àwọn ìkìmọ́lẹ̀ tí ó rìn wọ́n mọ́lẹ̀ nítòótọ́. Nígbà mìíràn, nínú ìjákulẹ̀, wọ́n a máa fẹ̀hónú hàn pé: “Ṣùgbọ́n kò yé ọ!” Kò sì mọ ní díẹ̀ àwọn ọ̀dọ́ ènìyàn tí wọ́n ti parí-èrò pé kò sí ẹni tí ó lóye wọn pẹ̀lú. Síbẹ̀, lára àwọn wọnnì tí wọ́n yánhànhàn fún pé kí àwọn ẹlòmíràn túbọ̀ lóye wọn síi ni a ti rí àwọn kan tí ìgbésí-ayé wọn ti ní ìtumọ̀ dídọ́ṣọ̀ lẹ́yìn náà. Báwo ni ìyẹn ṣe ṣeéṣe?
2. Kí ni ó lè mú kí ó ṣeéṣe fún àwọn olùjọ́sìn Jehofa láti ní ìgbésí-ayé tí ń tẹ́nilọ́rùn lọ́nà dídọ́ṣọ̀?
2 Ó jẹ́ nítorí pé, láìka yálà àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn lóye ìmọ̀lára wọn lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ tàbí bẹ́ẹ̀kọ́ sí, wọ́n ní ìgbọ́kànlé pé Ọlọrun lóye ohun tí wọn ń là kọjá àti pé, gẹ́gẹ́ bí ìráńṣẹ́ rẹ̀, wọn kò níláti dánìkan dojúkọ àwọn ìṣòro wọn. (Orin Dafidi 46:1) Síwájú síi pẹ̀lú, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun papọ̀ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn amòye Kristian alàgbà ń mú kí ó ṣeéṣe fún wọn láti ríran rékọjá àwọn ìṣòro ara-ẹni wọn. Ìwé Mímọ́ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọrírì pé iṣẹ́-ìsìn olùṣòtítọ́ wọn ṣe iyebíye ní ojú Ọlọrun àti pé ọjọ́-ọ̀la aláàbò kan wà fún àwọn wọnnì tí wọ́n bá gbé ìrètí wọn kà á àti àwọn ìpèsè tí ó ti ṣe nípasẹ̀ Jesu Kristi.—Owe 27:11; 2 Korinti 4:17, 18.
3, 4. (a) Báwo ni ìmọrírì òtítọ́ náà pé ‘Jehofa ni Ọlọrun’ àti pé òun ni “ó dá wa” ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti rí ayọ̀ nínú iṣẹ́-ìsìn rẹ̀? (b) Èéṣe tí a fi ní ìgbọ́kànlé kíkún nínú àbójútó onífẹ̀ẹ́ ti Jehofa?
3 Ìwọ ti lè mọ Orin Dafidi 100:2, èyí tí ó sọ pé: “Ẹ fi ayọ̀ sin Oluwa: ẹ wá ti ẹ̀yin ti orin sí iwájú rẹ̀.” Àwọn mélòó nítòótọ́ ni wọ́n ń sin Jehofa ní ọ̀nà yẹn? Àwọn ìdí yíyèkooro fún ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ni a fifúnni ní ẹsẹ 3, èyí tí ó rán wa létí pé: “Kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé [Jehofa, NW], òun ni Ọlọrun: òun ni ó dá wa, tirẹ̀ ni àwa; àwa ni ènìyàn rẹ̀, àti àgùtàn pápá rẹ̀.” Nínú ọ̀rọ̀ ẹsẹ-ìwé Heberu, òun ni a tọ́kasí níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ʼElo·himʹ, ní títipa báyìí tọ́ka sí ìtóbilọ́lá rẹ̀ ní ọláńlá, iyì-ọlá, àti ìtayọlọ́lá. Òun ni Ọlọrun òtítọ́ kanṣoṣo náà. (Deuteronomi 4:39; 7:9; Johannu 17:3) Àwọn ìráńṣẹ́ rẹ̀ wá mọ ipò jíjẹ́ Ọlọrun rẹ̀, kìí ṣe gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ tí a ti fi kọ́ wọn nìkan ni ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ohun kan tí wọ́n nírìírí àti nípa èyí tí wọn fi ẹ̀rí rẹ̀ hàn nípa ìgbọràn, ìgbẹ́kẹ̀lé, àti ìfọkànsìn.—1 Kronika 28:9; Romu 1:20.
4 Nítorí pé Jehofa ni Ọlọrun alààyè, tí ó lágbára láti rí ọkàn-àyà wa pàápàá, kò sí ohun tí ó pamọ́ kúrò ní ojú rẹ̀. Òun mọ ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí-ayé wa lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́. Òun lóye ohun tí ń ṣokùnfà àwọn ìṣòro tí a dojúkọ àti ìrusókè ti èrò-orí àti ti èrò-ìmọ̀lára tí ó lè jẹ jáde láti inú ìwọ̀nyí pẹ̀lú. Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá, òun mọ̀ wá dáadáa ju bí a ti mọ araawa lọ. Ó tún mọ bí òun ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú ipò wa àti bí ó ṣe lè pèsè ìtura-àlàáfíà pípẹ́títí. Òun yóò ràn wá lọ́wọ́ tìfẹ́tìfẹ́—bí olùṣọ́-àgùtàn kan tí ó gbé ọ̀dọ́-àgùtàn kan sí àyà rẹ̀—bí a ti gbẹ́kẹ̀lé e pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà wa. (Owe 3:5, 6; Isaiah 40:10, 11) Ìkẹ́kọ̀ọ́ Orin Dafidi 139 lè ṣe púpọ̀ láti fún ìgbọ́kànlé yẹn lókun.
Ẹni náà tí Ó Rí Gbogbo Ọ̀nà Wa
5. Kí ni ‘wíwádìí’ tí Jehofa ń wádìí wa túmọ̀sí, èésìtiṣe tí ìyẹn fi fanilọ́kànmọ́ra?
5 Pẹ̀lú ìmọrírì jíjinlẹ̀, olórin náà Dafidi kọ̀wé pé: “Oluwa, ìwọ ti wádìí mi, ìwọ sì ti mọ̀ mí.” (Orin Dafidi 139:1) Dafidi ní ìgbọ́kànlé pé ìmọ̀ Jehofa nípa òun kìí ṣe oréfèé. Ọlọrun kò rí Dafidi gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ti lè ṣe, ní kíkíyèsí ìrísí ara-ìyára rẹ̀, agbára ọ̀rọ̀ sísọ rẹ̀, tàbí ìjáfáfá rẹ̀ nínú fífi harpu kọrin nìkan. (1 Samueli 16:7, 18) Jehofa ti “wádìí” wọnú ibi ìkọ̀kọ̀ jùlọ Dafidi fúnraarẹ̀ ó sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìdàníyàn onífẹ̀ẹ́ fún ìwàlálàáfíà rẹ̀ tẹ̀mí. Bí ìwọ bá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùfọkànsìn ìráńṣẹ́ Jehofa, òun mọ̀ ọ́ gán-an gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe mọ Dafidi. Ìyẹn kò ha ru ìmọ̀lára ìmoore àti ìbẹ̀rù-ọlọ́wọ̀ sókè nínú rẹ bí?
6. Báwo ni Orin Dafidi 139:2, 3 ṣe fihàn pé Jehofa mọ gbogbo ohun tí a ń ṣe, àní gbogbo èrò wa pàápàá?
6 Gbogbo ìgbòkègbodò Dafidi ni a ṣí kalẹ̀ sí ojú Jehofa, Dafidi sì mọ bẹ́ẹ̀. “Ìwọ mọ ìjókòó mi àti ìdìde mi,” ni olórin náà kọ̀wé. “Ìwọ mọ ìrò mi ní ọ̀nà jíjìn réré. Ìwọ yí ipa ọ̀nà mi ká àti ìbúlẹ̀ mi, gbogbo ọ̀nà mi sì di mímọ̀ fún ọ.” (Orin Dafidi 139:2, 3) Òtítọ́ náà pé Jehofa wà nínú àwọn ọ̀run, tí ó jìnnà réré sí ilẹ̀-ayé, kò dí mímọ̀ tí ó mọ ohun tí Dafidi ń ṣe tàbí ohun tí ó ń rò lọ́wọ́. Ó “yí” àwọn ìgbòkègbodò Dafidi, lọ́sàn-án àti lóru “ká,” tàbí ṣàyẹ̀wò rẹ̀ kínníkínní, kí ó baà lè mọ ìrísí wọn.
7. (a) Ní lílo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ láti inú ìgbésí-ayé Dafidi gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀, fúnni ní àlàyé lórí díẹ̀ lára àwọn ohun tí Ọlọrun mọ̀ nínú ìgbésí-ayé wa. (b) Báwo ni mímọ̀ nípa èyí ṣe nípa lórí wa?
7 Nígbà tí ìfẹ́ fún Ọlọrun àti ìgbọ́kànlé nínú agbára Rẹ̀ láti dáninídè sún Dafidi gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́mọkùnrin kan láti yọ̀ǹda láti bá Goliati òmìrán Filistini jà, Jehofa mọ ìyẹn. (1 Samueli 17:32-37, 45-47) Nígbà tí ó yá, tí ìkóguntini àwọn ènìyàn mú ọkàn-àyà Dafidi ní ìrora gógó, tí ìkìmọ́lẹ̀ náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ débi pé òun bú sẹ́kún ní òru, òun ni a tù nínú nípa ìmọ̀ náà pé Jehofa gbọ́ àdúrà-ẹ̀bẹ̀ rẹ̀. (Orin Dafidi 6:6, 9; 55:2-5, 22) Bákan náà, nígbà tí ọkàn-àyà tí ó kún fún ìmoore sún Dafidi láti ronú jinlẹ̀ nípa Jehofa ní òru tí oorun dá, Jehofa mọ̀ nípa rẹ̀ dáadáa. (Orin Dafidi 63:6; fiwé Filippi 4:8, 9.) Ní alẹ́ ọjọ́ kan tí Dafidi wo aya aládùúgbò rẹ̀ tí ń wẹ̀, Jehofa mọ ìyẹn náà pẹ̀lú, ó sì rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Dafidi, àní fún àkókò kúkúrú kan pàápàá, fààyè gba ìfẹ́-ọkàn tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀ láti bo Ọlọrun mọ́lẹ̀ nínú àwọn èrò rẹ̀. (2 Samueli 11:2-4) Lẹ́yìn náà, nígbà tí a rán wòlíì Natani láti ko Dafidi lójú pẹ̀lú ìwúwo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kìí ṣe pé Jehofa gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu Dafidi jáde wá nìkan ni ṣùgbọ́n ó tún fòye mọ ọkàn-àyà onírònúpìwàdà láti inú èyí tí wọ́n ti wá. (2 Samueli 12:1-14; Orin Dafidi 51:1, 17) Ìyẹn kò ha níláti mú wa ronù gidigidi nípa ibi tí a ń lọ, ohun tí a ń ṣe, àti ohun tí ó wà nínú ọkàn-àyà wa bí?
8. (a) Ní ọ̀nà wo ni ‘àwọn ọ̀rọ̀ ahọ́n wa’ gbà nípa lórí ìdúró wa pẹ̀lú Ọlọrun? (b) Báwo ni a ṣe lè borí àwọn àìlera nínú ìlò ahọ́n? (Matteu 15:18; Luku 6:45)
8 Níwọ̀n ìgbà tí Ọlọrun ti mọ gbogbo ohun tí a ń ṣe, kò níláti yà wá lẹ́nu pé ó mọ bí a ṣe ń lo ẹ̀yà ara kan àní èyí tí ó kéré bí ahọ́n pàápàá. Ọba Dafidi mọ èyí dájú, ó sì kọ̀wé pé: “Nítorí tí kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ahọ́n mi, kíyèsí i, Oluwa, ìwọ mọ̀ ọ́n pátápátá.” (Orin Dafidi 139:4) Dafidi mọ̀ dáradára pé àwọn wọnnì tí a ó gbà gẹ́gẹ́ bí àlejò nínú àgọ́ Jehofa yóò jẹ́ àwọn ènìyàn tí kò fọ̀rọ̀ èké ba àwọn mìíràn jẹ́ tí wọ́n sì kọ̀ láti fi ahọ́n wọn tan àwọn ẹyọ òfófó tí ó lè mú ẹ̀gàn wá sórí ojúlùmọ̀ tímọ́tímọ́ kan kálẹ̀. Àwọn wọnnì tí Jehofa ń ṣojúrere sí yóò jẹ́ àwọn ènìyàn tí ń sọ òtítọ́ àní nínú ọkàn-àyà wọn pàápàá. (Orin Dafidi 15:1-3; Owe 6:16-19) Kò sí ẹnìkankan nínú wa tí ó lágbára láti pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ sábẹ́ ìkóníjàánu pípé, ṣùgbọ́n Dafidi kò fi àìlera parí-èrò pé kò sí ohun tí òun lè ṣe láti mú ipò òun sunwọ̀n síi. Ó lo àkókò púpọ̀ ní ṣíṣàkójọ àti kíkọ àwọn orin ìyìn sí Jehofa. Ó tún jẹ́wọ́ àìní rẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ ó sì gbàdúrà sí Ọlọrun fún un ní fàlàlà. (Orin Dafidi 19:12-14) Bí a ṣe ń lo ahọ́n wa ha nílò àfiyèsí tàdúrà-tàdúrà pẹ̀lú bí?
9. (a) Kí ni àpèjúwe inú Orin Dafidi 139:5 fihàn níti bí Ọlọrun ṣe mọ̀ ipò wa jinlẹ̀jinlẹ̀ tó? (b) Kí ni èyí mú wa ní ìgbọ́kànlé nípa rẹ̀?
9 Jehofa kò rí wa tàbí ipò wa láti igun ojú-ìwòye tí kò tó nǹkan lásán. Òun rí gbogbo rẹ̀ kedere, láti ìhà gbogbo. Ní lílo ìlú-ńlá kan tí a sémọ́ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ, Dafidi kọ̀wé pé: “Ìwọ sé mi mọ́ lẹ́yìn àti níwájú.” Nínú ọ̀ràn ti Dafidi, Ọlọrun kìí ṣe ọ̀tá tí ń sénimọ́; kàkà bẹ́ẹ̀, òun jẹ́ olùdáàbòbò oníṣọ̀ọ́ra. “Iwọ sì fi ọwọ́ rẹ lé mi,” ni Dafidi fikún un, ní títipa bẹ́ẹ̀ fi ìṣàkóso àti ààbò Ọlọrun tí ó lò fún àǹfààní pípẹ́títí àwọn wọnnì tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ hàn. “Irú ìmọ̀ yìí ṣe ohun ìyanu fún mi jù; ó ga, èmi kò lè mọ̀ ọ́n,” ni Dafidi jẹ́wọ́. (Orin Dafidi 139:5, 6) Ìmọ̀ Ọlọrun nípa àwọn ìráńṣẹ́ rẹ̀ pé pérépéré tóbẹ́ẹ̀, jinlẹ̀ tóbẹ́ẹ̀, débi pé a kò lè mọ̀ ọ́n lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́. Ṣùgbọ́n a mọ èyí tí ó pọ̀ tó láti ní ìgbọ́kànlé pé Jehofa lóye wa nítòótọ́ àti pé ìrànlọ́wọ́ tí ó ń pèsè yóò jẹ́ èyí tí ó dára jùlọ gan-an.—Isaiah 48:17, 18.
Níbikíbi tí A Bá Wà, Ọlọrun Lè Ràn Wá Lọ́wọ́
10. Òtítọ́ afúnni níṣìírí wo ni a gbéyọ nípasẹ̀ àpèjúwe ṣíṣe kedere tí ó wà ní Orin Dafidi 139:7-12?
10 Ní wíwo àbójútó onífẹ̀ẹ́ ti Jehofa láti ipò ojú-ìwòye mìíràn, olórin náà ń báa lọ pé: “Níbo ni èmi ó gbé lọ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀mí rẹ? tàbí níbo ni èmi ó sáré kúrò níwájú rẹ?” Òun kò ní ìfẹ́-ọkàn láti gbìyànjú láti sá kúrò níwájú Jehofa; kàkà bẹ́ẹ̀, òun mọ̀ pé níbikíbi tí òun lè wà, Jehofa yóò mọ̀ àti, nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́, ó lè ràn òun lọ́wọ́. “Bí èmi bá gòkè lọ sí ọ̀run,” ni ó ń báa lọ, “ìwọ wà níbẹ̀: bí èmi bá sì tẹ́ ẹní mi ní ipò òkú, kíyèsí i, ìwọ wà níbẹ̀. Èmi ìbáà mú ìyẹ́-apá òwúrọ̀, kí èmi sì lọ jókòó níhà òpin òkun; àní níbẹ̀ náà ni ọwọ́ rẹ yóò fà mí, ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì dì mí mú. Bi mo bá wí pé, Ǹjẹ́ kí òkùnkùn kí ó bò mí mọ́lẹ̀; kí ìmọ́lẹ̀ kí ó di òru yí mi ká. Nítòótọ́ òkùnkùn kìí ṣú lọ́dọ̀ rẹ; ṣùgbọ́n òru tan ìmọ́lẹ̀ bí ọ̀sán: àti òkùnkùn àti ọ̀sán, méjèèjì bákan náà ni fún ọ.” (Orin Dafidi 139:7-12) Kò sí ibi tí a lè lọ, kò sí ipò-àyíká tí a lè dojúkọ, tí yóò gbé wa rékọjá ojú-ìwòye Jehofa tàbí rékọjá ibi tí ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ lè dé láti ràn wá lọ́wọ́.
11, 12. (a) Àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jona gbàgbé rẹ̀ fún àkókò kan, báwo ni a ṣe fi agbára Jehofa láti ríran àti láti ṣèrànlọ́wọ́ hàn nínú ọ̀ràn ti Jona? (b) Báwo ni ìrírí Jona ṣe níláti ṣàǹfààní fún wa?
11 Ní orí kókó kan wòlíì Jona gbàgbé ìyẹn. Jehofa ti yàn án láti wàásù fún àwọn ènìyàn Ninefe. Fún àwọn ìdí kan ó nímọ̀lára pé òun kò lè bójútó iṣẹ́-àyànfúnni yẹn. Bóyá nítorí ìwà-òǹrorò tí a mọ̀ mọ́ àwọn ará Assiria, ìrònú ṣíṣiṣẹ́sìn ní Ninefe dáyàfo Jona. Nítorí náà ó gbìyànjú láti farapamọ́. Ní ibùdókọ̀-òkun Joppa, ó san iye owó ọkọ̀ ojú-omi tí ń lọ sí Tarṣiṣi (tí ó tan mọ́ Spain ní gbogbogbòò, èyí tí ó ju ẹ̀ẹ́dégbèjìdínlógún kìlómità lọ síhà ìwọ̀-oòrùn Ninefe). Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Jehofa rí i tí ó wọ ọkọ̀ ojú-omi náà tí ó sì lọ sùn ní ìsàlẹ̀ ní ààyè ẹrù. Ọlọrun tún mọ ibi tí Jona wà nígbà tí a gbé e sọ sínú omi, Jehofa sì gbọ́ ohùn Jona nígbà tí ó ṣèlérí láti inú ikùn ẹja ńlá náà pé òun yóò san ẹ̀jẹ́ òun. Bí a ti dá a nídè padà sórí ilẹ̀ gbígbẹ, Jona ni a tún fún ní àǹfààní lẹ́ẹ̀kan síi láti mú iṣẹ́-àyànfúnni rẹ̀ ṣẹ.—Jona 1:3, 17; 2:1–3:4.
12 Ìbá ti sàn lọ́pọ̀lọpọ̀ tó fún Jona láti ìbẹ̀rẹ̀ láti gbáralé ẹ̀mí Jehofa láti ràn án lọ́wọ́ láti mú iṣẹ́-àyànfúnni rẹ̀ ṣẹ! Lẹ́yìn náà, bí ó ti wù kí ó rí, Jona fi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ ṣàkọsílẹ̀ ìrírí rẹ̀, àkọsílẹ̀ yẹn sì ti ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́wọ́ láti ìgbà náà wá láti fi ìgbọ́kànlé tí ó jọbí èyí tí ó ṣòro tóbẹ́ẹ̀ fún Jona hàn nínú Jehofa.—Romu 15:4.
13. (a) Àwọn iṣẹ́-àyànfúnni wo ni Elijah fi ìṣòtítọ́ múṣẹ́ kí ó tó sá kúrò níwájú Ayaba Jesebeli? (b) Báwo ni Jehofa ṣe ran Elijah lọ́wọ́ àní nígbà tí ó wá ọ̀nà láti sá lọ sí ibi ìkọ̀kọ̀ lẹ́yìn òde ìpínlẹ̀ Israeli?
13 Ìrírí Elijah yàtọ̀ lọ́nà kan ṣá. Òun ti fi ìṣòtítọ́ jíṣẹ́ àṣẹ-òfin Jehofa pé Israeli yóò jìyà ọ̀gbẹlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìbáwí kíkan fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn. (1 Ọba 16:30-33; 17:1) Òun ti fi ìgboyà di ìjọsìn tòótọ́ mú nínú ìdíje láàárín Jehofa àti Baali ní Òkè Karmeli. Ó sì ti kẹ́sẹjárí pẹ̀lú pípa 450 àwọn wòlíì Baali ní àfonífojì alágbàrá ti Kiṣoni. Ṣùgbọ́n nígbà tí Ayaba Jesebeli nínú ìbínú-ńlá jẹ́jẹ̀ẹ́ láti ṣekú pa Elijah, Elijah sá kúrò ní orílẹ̀-èdè náà. (1 Ọba 18:18-40; 19:1-4) Jehofa ha wà níbẹ̀ láti ràn án lọ́wọ́ ní àkókò lílekoko yẹn bí? Bẹ́ẹ̀ni, nítòótọ́. Bí Elijah bá ti gun òkè gíga ni, gẹ́gẹ́ bíi sí ọ̀run; bí òun bá ti sápamọ́ sínú ihò jíjìn láàárín ilẹ̀-ayé, bíi nínú Sheol; bí òun bá ti sá lọ sí erékùṣù jíjìnnà réré kan pẹ̀lú ìyára bíi ti ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ tí ń tànkálẹ̀ sorí ilẹ̀-ayé—ọwọ́ Jehofa ìbá ti wà níbẹ̀ láti fún un lókun kí ó sì ṣamọ̀nà rẹ̀. (Fiwé Romu 8:38, 39.) Jehofa sì fún Elijah lókun kìí ṣe pẹ̀lú oúnjẹ fún ìrìn-àjò rẹ̀ nìkan ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìfihàn àgbàyanu ti ipá agbékánkánṣiṣẹ́ Rẹ̀ bákan náà. Bí a ti tipa báyìí tì í lẹ́yìn, Elijah bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́-àyànfúnni alásọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ tí ó tẹ̀lé e.—1 Ọba 19:5-18.
14. (a) Èéṣe tí yóò fi ṣàìtọ́ láti parí-èrò pé Ọlọrun jẹ́ olùwà-ní-ibi gbogbo? (b) Lábẹ́ àwọn ipò-àyíká wo ni Jehofa ti fi tìfẹ́tìfẹ́ gbé àwọn ìràńṣẹ́ rẹ̀ ró ní àwọn àkókò òde-òní? (c) Báwo ni ó ṣe jẹ́ pé bí a bá tilẹ̀ wà nínú Sheol pàápàá, Ọlọrun yóò wà níbẹ̀?
14 Àwọn ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ inú Orin Dafidi 139:7-12 kò túmọ̀sí pé Ọlọrun jẹ́ olùwà-níbi-gbogbo, pé òun fúnraarẹ̀ ń wà ní ibi gbogbo ní gbogbo ìgbà. Ìwé Mímọ́ fi ohun tí ó yàtọ̀ sí èyí hàn. (Deuteronomi 26:15; Heberu 9:24) Síbẹ̀, àwọn ìráńṣẹ́ rẹ̀ kò ṣàì sí ní àrọ́wọ́tó rẹ̀. Ìyẹn jẹ́ òtítọ́ nípa àwọn wọnnì tí iṣẹ́-àyànfúnni ti ìṣàkóso Ọlọrun wọn ti gbé wọn lọ sí àwọn ìbi jíjìnnà réré. Ó jẹ́ òtítọ́ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí adúróṣinṣin ní àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Nazi nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, ó sì jẹ́ òtítọ́ nípa àwọn òjíhìn-iṣẹ́-Ọlọ́run tí a hámọ́ yàrá ìhámọ́ àdádó ní China ní apá tí ó kẹ́yìn àwọn ọdún 1950 àti ìbẹ̀rẹ̀ 1960. Ó jẹ́ òtítọ́ nípa àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ọ̀wọ́n ní Àárín-Gbùngbùn orílẹ̀-èdè Africa tí wọ́n níláti sá léraléra kúrò ní àwọn abúlé wọn, àní kúrò ní ìlú pàápàá. Bí ó bá pọndandan, ọwọ́ Jehofa lè dé Sheol, sàárè lápapọ̀ gan-an, kí ó sì mú àwọn olùṣòtítọ́ padà nípasẹ̀ àjíǹde kan.—Jobu 14:13-15; Luku 20:37, 38.
Ẹni náà Tí Ó Lóye Wa Nítòótọ́
15. (a) Báwo ni àkókò náà ti yá tó láti ìgbà tí ó ti ṣeéṣe fún Jehofa láti ṣàkíyèsí ìdàgbàsókè wa? (b) Báwo ni a ṣe fi ìwọ̀n gbígbòòrò ìmọ̀ Ọlọrun nípa wa hàn nípa ìtọ́ka tí olórin náà ṣe sí kídìnrín?
15 Lábẹ́ ìmísí, olórin náà fa àfiyèsí sí òtítọ́ náà pé ìmọ̀ Ọlọrun nípa wa ṣáájú àkókò tí a bí wa pàápàá, ní wíwí pé: “Nítorí ìwọ ni ó dá [kídìnrín, “NW”] mi: ìwọ ni ó bò mí mọ́lẹ̀ ní inú ìyá mi. Èmi ó yìn ọ́; nítorí tẹ̀rù-tẹ̀rù àti tìyanu-tìyanu ni a dá mi: ìyanu ni iṣẹ́ rẹ; èyíinì ni ọkàn mi sì mọ̀ dájúdájú.” (Orin Dafidi 139:13, 14) Pípa àwọn apilẹ̀-àbùdá láti ọ̀dọ̀ bàbá àti ìyá wa pọ̀ ní ìgbà ìlóyún ń mú ọnà tí ó nípa jíjinlẹ̀ lórí agbára ti ara-ìyára àti ti èrò-orí wa jáde. Ọlọrun lóye agbára yẹn. Nínú orin yìí a mẹ́nukan kídìnrín lọ́nà àkànṣe, èyí tí a sábà máa ń lò nínú Ìwé Mímọ́ láti dúró fún apá-ìhà àkópọ̀ ànímọ́-ìwà inú lọ́hùn-ún jùlọ.a (Orin Dafidi 7:9; Jeremiah 17:10) Jehofa ti mọ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ wọ̀nyí nípa wa tipẹ́ ṣáájú kí á tó bí wa. Òun tún ni ẹni náà tí ó fi ìdàníyàn onífẹ̀ẹ́ ṣọnà ara ènìyàn kí ó baà lè jẹ́ pé ohun tín-ín-tìn-ìn-tín tí a sọ di ọmọ nínú ilé ọlẹ̀ ìyá yóò pèsè ilé aláàbò láti ‘pa ọlẹ̀ náà mọ́’ kí ó sì dáàbòbo bí ó ti ń dàgbà.
16. (a) Ní ọ̀nà wo ni Orin Dafidi 139:15, 16 gbà tẹnumọ́ agbára rírìnjìnnà ti ìríran Ọlọrun? (b) Èéṣe tí èyí fi níláti jásí ìṣírí fún wa?
16 Lẹ́yìn náà, ní títẹnumọ́ agbára ìríran Ọlọrun tí ó rìn jìnnà, olórin náà fikún un pé: “Ẹ̀dá ara mi kò pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ, nígbà tí a dá mi ní ìkọ̀kọ̀, tí a sì ń ṣiṣẹ́ mi ní àràbarà níhà ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé [tí ó ṣe kedere pé ó jẹ́ ìtọ́ka eléwì sí ilé-ọlẹ̀ ìyá rẹ̀ ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìdọ́gbọ́n tọ́kasí ìṣẹ̀dá Adamu láti inú erupẹ̀]. Ojú rẹ ti rí ohun ara mi tí ó wà láìpé: àti nínú ìwé rẹ ni a ti kọ gbogbo wọn sí, ní ojoojúmọ́ ni a ń dá wọn [àwọn ẹ̀yà ara], nígbà tí ọ̀kan [ẹ̀yà ara tí ó dá yàtọ̀] wọn kò tíì sí.” (Orin Dafidi 139:15, 16) Kò sí iyèméjì nípa rẹ̀—yálà àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa lóye wa tàbí bẹ́ẹ̀kọ́, Jehofa lóye wa. Báwo ni ìyẹn ṣe níláti nípa lórí wa?
17. Nígbà tí a bá wo àwọn iṣẹ́ Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó jẹ́ ìyanu, kí ni èyí ń sún wa láti ṣe?
17 Òǹkọ̀wé Orin Dafidi 139 náà jẹ́wọ́ pé àwọn iṣẹ́ Ọlọrun nípa èyí tí òun ń kọ̀wé jẹ́ ìyanu. Ìwọ ha nímọ̀lára bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú bí? Ohun kan tí ó jẹ́ àgbàyanu ń mú kí ènìyàn ronu jinlẹ̀ tàbí fi àfiyèsí wíwọnilọ́kàn ṣinṣin hàn. Bóyá ìwọ hùwàpadà ní ọ̀nà yẹn sí àwọn iṣẹ́ Jehofa nípa ìṣẹ̀dá tí a lè rí. (Fiwé Orin Dafidi 8:3, 4, 9.) Ìwọ ha tún rònú lọ́nà yẹn nípa ohun tí ó ti ṣe nínú fífìdí Ìjọba Messia múlẹ̀, nípa ohun tí ó ń ṣe nínú mímú kí a wàásù ìhìnrere ní gbogbo ilẹ̀-ayé, àti nípa ọ̀nà tí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń gbà yí àwọn àkópọ̀ ànímọ́-ìwà ènìyan padà bí?—Fiwé 1 Peteru 1:10-12.
18. Nígbà tí a bá rí iṣẹ́ Ọlọrun pé ó jẹ́ tẹ̀rù-tẹ̀rù, báwo ni yóò ṣe nípa lórí wa?
18 Ó ha jẹ́ ìrírí rẹ bákan náà pé ríronú lórí iṣẹ́ Ọlọrun jẹ́ tẹ̀rù-tẹ̀rù, pé ó ń pèsè ìbẹ̀rù pípéye nínú rẹ̀, ọ̀kan tí ń fi tagbára-tagbára súnni ṣiṣẹ́, ọ̀kan tí ó ní ipa jíjinlẹ̀ lórí àkópọ̀ ànímọ́-ìwà rẹ àti lórí ọ̀nà tí o gbà ń lo ìgbésí-ayé rẹ? (Fiwé Orin Dafidi 66:5.) Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ọkàn-àyà rẹ yóò sún ọ láti kókìkíyin Jehofa, láti yìn ín, láti wá àkókò láti sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa ète rẹ̀ àti àwọn ohun àgbàyanu tí ó ní ní ìpamọ́ fún àwọn wọnnì tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.—Orin Dafidi 145:1-3.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Insight on the Scriptures, tí a tẹ̀jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., Ìdìpọ̀ 2, ojú-ìwé 150.
Kí ni Àlàyé Rẹ?
◻ Báwo ni mímọ̀ tí a mọ̀ pé ‘Jehofa ni Ọlọrun’ ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́sìn ín pẹ̀lú ayọ̀?
◻ Báwo ni mímọ̀ tí Ọlọrun mọ gbogbo ohun tí a ń ṣe ṣe níláti nípa lórí ìgbésí-ayé wa?
◻ Èéṣe tí òtítọ́ náà pé a kò fìgbà kan ṣàì sí lábẹ́ àfiyèsí Ọlọrun fi jásí ìṣírí?
◻ Èéṣe tí Ọlọrun fi lè lóye wa ní àwọn ọ̀nà tí ènìyàn èyíkéyìí kan kò lè gbà lóye wa?
◻ Èéṣe tí ìkẹ́kọ̀ọ́ kan bí èyí ṣe mú wa fẹ́ láti kókìkíyin Jehofa?