Sáàmù
Fún olùdarí. Ti Dáfídì. Orin.
Láti ibi tó jìnnà réré, o mọ ohun tí mò ń rò.+
3 Ò ń kíyè sí* mi nígbà tí mo bá ń rìnrìn àjò àti nígbà tí mo bá dùbúlẹ̀;
Gbogbo àwọn ọ̀nà mi ò ṣàjèjì sí ọ.+
5 Lẹ́yìn mi àti níwájú mi, o yí mi ká;
O sì gbé ọwọ́ rẹ lé mi.
6 Irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ kọjá òye mi.*
Ó kọjá ohun tí ọwọ́ mi lè tẹ̀.*+
9 Tí mo bá fi ìyẹ́ apá ọ̀yẹ̀ fò lọ,
Kí n lè máa gbé létí òkun tó jìnnà jù lọ,
10 Kódà, ọwọ́ rẹ yóò darí mi níbẹ̀,
Ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì dì mí mú.+
11 Tí mo bá sọ pé: “Dájúdájú, òkùnkùn yóò fi mí pa mọ́!”
Nígbà náà, òkùnkùn tó yí mi ká yóò di ìmọ́lẹ̀.
12 Kódà, òkùnkùn náà kò ní ṣú jù fún ọ,
Ṣe ni òru yóò mọ́lẹ̀ bí ọ̀sán;+
Ìkan náà ni òkùnkùn àti ìmọ́lẹ̀ lójú rẹ.+
14 Mo yìn ọ́ nítorí pé lọ́nà tó ń bani lẹ́rù ni o ṣẹ̀dá mi tìyanutìyanu.+
16 Kódà, ojú rẹ rí mi nígbà tí mo ṣì wà nínú ikùn;*
Gbogbo àwọn ẹ̀yà rẹ̀ wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé rẹ
Ní ti àwọn ọjọ́ tí o ṣẹ̀dá wọn,
Kí ìkankan lára wọn tó wà.
17 Lójú tèmi, àwọn ìrònú rẹ mà ṣeyebíye o!+
Ọlọ́run, àròpọ̀ iye wọn mà pọ̀ o!+
18 Tí mo bá ní kí n máa kà wọ́n, wọ́n pọ̀ ju iyanrìn lọ.+
Nígbà tí mo jí, mo ṣì wà pẹ̀lú rẹ.*+
19 Ọlọ́run, ká ní o bá pa ẹni burúkú!+
Nígbà náà, àwọn oníwà ipá* yóò kúrò lọ́dọ̀ mi,
20 Àwọn tó ń sọ̀rọ̀ rẹ pẹ̀lú èrò ibi lọ́kàn;*
Àwọn ni ọ̀tá rẹ tí wọ́n ń lo orúkọ rẹ lọ́nà tí kò ní láárí.+