“Ọlọrun, Wádìí Mi”
“Ọlọrun, wádìí mi, kí o sì mọ àyà mi . . . Kí o sì fi ẹsẹ̀ mi lé ọ̀nà àìnípẹ̀kun.”—ORIN DAFIDI 139:23, 24.
1. Báwo ni Jehofa ṣe ń bá àwọn ìráńṣẹ́ rẹ̀ lò?
GBOGBO wa ni a fẹ́ràn àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ẹnìkan tí òye yé, ẹnìkan tí ó ń gba ti àwọn ipò-àyíká wa rò, ẹnìkan tí ń rannilọ́wọ́ nígbà tí a bá kù-díẹ̀-káà-tó, ẹnìkan tí kò béèrè púpọ̀ ju bí a ti lè ṣe lọ. Jehofa Ọlọrun ń bá àwọn ìráńṣẹ́ rẹ̀ lò ní ọ̀nà yẹn. Orin Dafidi 103:14 sọ pé: “Ó mọ ẹ̀dá wa; ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.” Jesu Kristi, ẹni tí ó ṣàgbéyọ Bàbá rẹ̀ lọ́nà pípé, sì nawọ́ ìkésíni ọlọ́yàyà náà pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá tí ẹrù sì wọ̀ lọ́rùn, èmi yóò sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sí ọrùn yín [tàbí, “Ẹ bọ́ sábẹ́ àjàgà mi pẹ̀lú mi,” àkíyèsí ẹsẹ̀-ìwé] kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí pé ọlọ́kàn-tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ̀yin yóò sì rí ìtura fún ọkàn yín. Nítorí àjàgà mi rọrùn ẹrù mí sì fúyẹ́.”—Matteu 11:28-30, NW.
2. Fi ojú-ìwòye Jehofa wéra pẹ̀lú ti àwọn ènìyàn nípa (a) Jesu Kristi, àti (b) àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi.
2 Ojú tí Jehofa fi ń wo àwọn ìráńṣẹ́ rẹ̀ sábà máa ń yàtọ̀ gan-an sí ti àwọn ènìyàn. Òun ń fi ojú-ìwòye tí ó yàtọ̀ wo àwọn ọ̀ràn ó sì máa ń ro àwọn apá ìhà tí àwọn mìíràn lè má mọ ohunkóhun nípa rẹ̀. Nígbà tí Jesu Kristi wà lórí ilẹ̀-ayé, òun ni “a kẹ́gàn rẹ̀ a sì kọ̀ ọ́ lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn.” Àwọn wọnnì tí wọn kò ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Messia “kò sì kà á sí.” (Isaiah 53:3; Luku 23:18-21) Síbẹ̀, ní ojú Ọlọrun, òun jẹ́ “olùfẹ́-ọ̀wọ́n Ọmọkùnrin [Ọlọrun],” tí Baba sọ fún pé: “Mo ti tẹ́wọ́gbà ọ́.” (Luku 3:22, NW; 1 Peteru 2:4) Lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu Kristi ni àwọn ènìyàn tí a kà sí aláìjámọ́ nǹkan nítorí pé wọ́n jẹ́ òtòṣì nípa ohun ti ara tí wọ́n sì ń farada ọ̀pọ̀ ìpọ́njú. Síbẹ̀, ní ojú Jehofa àti Ọmọkunrin rẹ̀, irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ ọlọ́rọ̀. (Romu 8:35-39; Ìfihàn 2:9) Kí ni ó fa ìyàtọ̀ nínú ojú-ìwòye?
3. (a) Èéṣe tí ojú-ìwòye Jehofa nípa àwọn ènìyàn fi sábà máa ń yàtọ̀ gan-an sí ti ẹ̀dá? (b) Èéṣe tí ó fi ṣe pàtàkì lọ́nà tí ó ṣekókó fún wa láti ṣàyẹ̀wò irú ẹni tí a jẹ́ nínú?
3 Jeremiah 11:20 fèsìpadà pé: “Oluwa . . . ń dán àyà àti inú wò.” Ó ń rí ohun tí a jẹ́ nínú, àní àwọn apá-ìhà àkópọ̀ ànímọ́-ìwà wa wọnnì tí ó farasin kúrò ní ojú àwọn mìíràn. Nínú àyẹ̀wò rẹ̀, ó ń fún àwọn ànímọ́ àti ipò tí ó ṣekókó fún ipò-ìbátan rere pẹ̀lú rẹ̀ ní ìtẹnumọ́ pàtàkì, ìwọnnì tí ó ṣàǹfààní fún wa jùlọ lọ́nà wíwàtítí lọ. Mímọ̀ tí a mọ ìyẹn ń finilọ́kàn balẹ̀; ó tún ń múni ronú jinlẹ̀. Níwọ̀n ìgbà tí Jehofa ti ń fiyèsí ohun tí a jẹ́ nínú, ó ṣe pàtàkì fún wa láti ṣàyẹ̀wò ohun tí a jẹ́ nínú bí a bá níláti jásí irú àwọn ènìyàn tí ó ń fẹ́ nínú ayé titun rẹ̀. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe irú àyẹ̀wò bẹ́ẹ̀.—Heberu 4:12, 13.
Àwọn Ìrò-Inú Ọlọrun ti Ṣeyebíye Tó!
4. (a) Kí ni ó sún olórin náà láti polongo pé ìrò-inú Ọlọrun ṣeyebíye fún òun? (b) Èéṣe tí wọ́n fi níláti ṣeyebíye fún wa?
4 Lẹ́yìn tí ó ti ronú jinlẹ̀ lórí ìbú àti jíjìn ìmọ̀ Ọlọrun nípa àwọn ìráńṣẹ́ rẹ̀, àti lórí agbára àrà-ọ̀tọ̀ Ọlọrun láti pèsè ìrànlọ́wọ́ yòówù tí wọ́n lè nílò, Dafidi olórin náà kọ̀wé pé: “Ìrò inú rẹ ti ṣe iyebíye tó fún mi!” (Orin Dafidi 139:17a) Àwọn ìrò-inú wọnyẹn, tí a ṣípayá nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí a kọ, ga fíìfíì ju ohunkóhun láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn, bí ó ti wù kí àwọn èrò wọn ti lè dàbí ọlọ́gbọ́nféfé tó. (Isaiah 55:8, 9) Àwọn ìrò-inú Ọlọrun ń ràn wá lọ́wọ́ láti darí àfiyèsí wa sí àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì níti gidi nínú ìgbésí-ayé àti láti jẹ́ onítara nínú iṣẹ́-ìsìn rẹ̀. (Filippi 1:9-11) Wọ́n fi bí a ṣe níláti wo àwọn ọ̀ràn ní ọ̀nà tí Ọlọrun ń gbà wò wọ́n hàn wá. Wọ́n ń ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ aláìlábòsí pẹ̀lú araawa, láti gba pẹ̀lú irú ènìyàn tí a jẹ́ ní ọkàn-àyà nítòótọ́. Ìwọ ha múratán láti ṣe ìyẹn bí?
5. (a) Kí ni Ọ̀rọ̀ Ọlọrun rọ̀ wá láti ṣọ́ “ju gbogbo ohun ìpamọ́” lọ? (b) Báwo ni àkọsílẹ̀ Bibeli nípa Kaini ṣe ṣàǹfààní fún wa? (c) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò sí lábẹ́ Òfin Mose, báwo ni ó ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ohun tí ó wu Jehofa?
5 Àwọn ènìyàn ní ìtẹ̀sí láti gbé ìtẹnumọ́ púpọ̀ karí àwọn ìrísí òde-ara, ṣùgbọ́n Ìwé Mímọ́ gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ju gbogbo ohun ìpamọ́, pa àyà rẹ mọ́.” (Owe 4:23) Nípa àwọn ìlànà àti nípa àwọn àpẹẹrẹ, Bibeli ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìyẹn. Ó sọ fún wa pé Kaini fi àìbìkítà ṣe ìrúbọ sí Ọlọrun nígbà tí ọkàn-àyà rẹ̀ wà nínú ipò ìbínú, lẹ́yìn náà ìkórìíra, sí Abeli arákùnrin rẹ̀. Ó sì rọ̀ wá láti máṣe dàbíi rẹ̀. (Genesisi 4:3-5; 1 Johannu 3:11, 12) Ó ṣàkọsílẹ̀ ohun tí Òfin Mose béèrè fún nípa ìgbọràn. Ṣùgbọ́n ó tún tẹnumọ́ ọn pé ohun-àbéèrè-fún tí ó gba iwájú jùlọ nínú Òfin ni pé àwọn wọnnì tí ń jọ́sìn Jehofa gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà, èrò-inú, ọkàn, àti okun wọn; ó sì sọ pé èyí tí ó ṣe pàtàkì tẹ̀lé e ni àṣẹ náà pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wọn gẹ́gẹ́ bí araawọn.—Deuteronomi 5:32, 33; Marku 12:28-31.
6. Nínú fífi Owe 3:1 sílò, àwọn ìbéèrè wo ni a níláti béèrè lọ́wọ́ araawa?
6 Ní Owe 3:1, a rọ̀ wá kìí ṣe láti wulẹ̀ pa àwọn àṣẹ Ọlọrun mọ́ ṣùgbọ́n láti rí i dájú pé ìgbọràn náà jẹ́ ìfihàn ohun tí ó wà nínú ọkàn-àyà wa nítòótọ́. Lẹ́nìkọ̀ọ̀kan a níláti béèrè lọ́wọ́ araawa pé, ‘Ìyẹn ha jẹ́ òtítọ́ nípa ìgbọràn mi sí àwọn ohun-àbéèrè-fún Ọlọrun bí?’ Bí a bá mọ̀ pé nínú àwọn ọ̀ràn kan ète ìsúnniṣe tàbí èrò wa kò kún tó—tí kò sì sí ẹnikẹ́ni nínú wa tí ó lè sọ pé aláìlábùkù ni òun—nígbà náà a níláti béèrè pé, ‘Kí ni mo ń ṣe láti mú ipò náà sunwọ̀n síi?’—Owe 20:9; 1 Johannu 1:8.
7. (a) Báwo ni bíbù tí Jesu bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn Farisi ní Matteu 15:3-9 ṣe ràn wá lọ́wọ́ nínú dídáàbòbo ọkàn-àyà wa? (b) Àwọn ipò wo ni ó lè béèrè lọ́wọ́ wa láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ lílágbára láti bá èrò-inú àti ọkàn-àyà wa wí?
7 Nígbà tí àwọn Farisi tí wọ́n jẹ́ Ju díbọ́n bíbọlá fún Ọlọrun nígbà tí wọ́n ń fi ọgbọ́nkọ́gbọ́n ṣagbátẹrù ìṣe-àṣà kan tí ó jẹyọ láti inú ìfẹ́-ọkàn fún ire ara tiwọn, Jesu bu ẹnu àtẹ́ lù wọ́n gẹ́gẹ́ bí àgàbàgebè ó sì fihàn pé ìjọsìn wọn jẹ́ asán. (Matteu 15:3-9) Jesu tún kìlọ̀ pé láti wu Ọlọrun, ẹni tí ó rí ọkàn-àyà, kò tó láti gbé ìgbésí-ayé ìwàrere nínú ìrísí òde nígbà tí, pẹ̀lú èrò jíjẹ̀gbádùn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, a tún ń lọ́wọ́ nínú àwọn ìrò-inú tí ó jẹ́ ti oníwà-pálapàla lemọ́lemọ́. A lè níláti gbé àwọn ìgbésẹ̀ aláìbojúwẹ̀yìn láti bá èrò-inú àti ọkàn-àyà wa wí. (Owe 23:12; Matteu 5:27-29) Irú ìbáwí bẹ́ẹ̀ ni a tún nílò bí ó bá jẹ́ pé nítorí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa, góńgó wa nínú ẹ̀kọ́-ìwé, tàbí irú eré-ìnàjú tí a yàn, a ń di aláfarawé ayé, ní yíyọ̀ǹda rẹ̀ láti sọ wá dàbí ó ti fẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀pá-ìdíwọ̀n rẹ̀. Ǹjẹ́ kí àwa máṣe gbàgbé láé pé ọmọ-ẹ̀yìn náà Jakọbu pe àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́wọ́ jíjẹ́ ti Ọlọrun ṣùgbọ́n tí wọ́n fẹ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé ní “panṣágà obìnrin.” Èéṣe? Nítorí pé “gbogbo ayé ni ó wà ní agbára ẹni búburú nì.”—Jakọbu 4:4; 1 Johannu 2:15-17; 5:19.
8. Láti jàǹfààní ní kíkún láti inú àwọn ìrò-inú ṣíṣeyebíye ti Ọlọrun, kí ni a níláti ṣe?
8 Kí á baà lè jàǹfààní ní kíkún láti inú ìrò-inú Ọlọrun lórí ìwọ̀nyí àti àwọn ọ̀ràn mìíràn, a níláti ya àkókò sọ́tọ̀ láti kà wọ́n tàbí gbọ́ wọn. Ju ìyẹn lọ, a níláti kẹ́kọ̀ọ́ wọn, sọ̀rọ̀ nípa wọn, kí á sì ronú jinlẹ̀ lé wọn lórí. Ọ̀pọ̀ àwọn òǹkàwé Ilé-Ìṣọ́nà ń pésẹ̀ sí àwọn ìpàdé ìjọ ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, níbi tí a ti ń jíròrò Bibeli déédéé. Wọ́n ń ra ìgbà padà láti inú àwọn ìlépa mìíràn kí wọ́n baà lè ṣe é. (Efesu 5:15-17) Ohun tí wọ́n sì ń rígbà padà fi púpọ̀púpọ̀ ṣeyebíye ju ọlà ti ara lọ. Bẹ́ẹ̀ ha kọ́ ni ìmọ̀lára rẹ rí bí?
9. Èéṣe tí àwọn kan tí wọ́n ń wá sí àwọn ìpàdé Kristian fi ń ní ìtẹ̀síwájú lọ́nà tí ó yára ju àwọn mìíràn lọ?
9 Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn kan tí wọ́n ń pésẹ̀ sí àwọn ìpàdé wọ̀nyí ń ní ìtẹ̀síwájú tí ó túbọ̀ yára ju bí àwọn mìíràn ti ń ṣe lọ. Wọn a túbọ̀ máa fi òtítọ́ sílò lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ nínú ìgbésí-ayé wọn. Kí ni ó lè ṣàlàyé èyí? Lemọ́lemọ́, kókó-abájọ kan ni aápọn wọn nínú ìdákẹ́kọ̀ọ́. Wọ́n mọrírì pé a kò wàláàyè nípa búrẹ́dì nìkan; oúnjẹ tẹ̀mí lójoojúmọ́ wulẹ̀ ṣe pàtàkì bíi jíjẹ oúnjẹ ti ara déédéé. (Matteu 4:4; Heberu 5:14) Nítorí náà wọ́n sakun láti lo ó kérétán àkókò díẹ̀ lójoojúmọ́ láti máa ka Bibeli tàbí àwọn ìtẹ̀jáde tí ó ṣàlàyé rẹ̀. Wọ́n ń múrasílẹ̀ fún àwọn ìpàdé ìjọ, ní kíkẹ́kọ̀ọ́ àwọn apá tí ó wà fún kíkà ṣaájú àti ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ìwé mímọ́. Wọ́n ń ṣe ju kíka àkójọpọ̀-ọ̀rọ̀ náà lọ; wọ́n ń ṣàṣàrò lé e lórí. Ọ̀nà ìgbà kẹ́kọ̀ọ́ wọn ní nínú ríronú gidigidi nípa ipa tí ohun tí wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ níláti ní lórí ìgbésí-ayé wọn. Bí ipò-tẹ̀mí wọn ti ń gbé pẹ́ẹ́lí síi, wọ́n wá nímọ̀lára gẹ́gẹ́ bí olórin náà ti ṣe ẹni tí ó kọ̀wé pé: “Èmi ti fẹ́ òfin rẹ tó! . . . Ìyanu ni ẹ̀rí rẹ.”—Orin Dafidi 1:1-3; 119:97, 129.
10. (a) Fún àkókò gígùn tó báwo ni ó fi lérè láti máa báa lọ láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun? (b) Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe fi èyí hàn?
10 Yálà a ti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun fún ọdún kan, ọdún márùn-ún, tàbí àádọ́ta ọdún, ìyẹn kìí sọ ọ́ di àkọ́túnkọ́ lásán—kìí ṣe bí àwọn ìrònú Ọlọrun bá ṣeyebíye fún wa. Kò sí bí ohun tí ẹnìkẹ́ni nínú wa mọ̀ láti inú Ìwé Mímọ́ ti lè pọ̀ tó, púpọ̀ síi ń bẹ tí a kò mọ̀. “Ọlọrun, ìrò inú rẹ ti ṣe iyebíye tó fún mi, iye wọn ti pọ̀ tó!” ni Dafidi sọ. “Èmi ìbá kà wọ́n, wọ́n ju iyanrìn lọ ní iye.” Àwọn ìrò-inú Ọlọrun rékọjá ohun tí agbára wa lè kà lọ. Bí àwa bá níláti ka àwọn ìrò-inú Ọlọrun láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ tí oorun sì gbé wa lọ sẹ́nu ṣíṣe bẹ́ẹ̀, nígbà tí a bá tají ní òwúrọ̀, púpọ̀ síi ni yóò ṣì tún wà fún wa láti ronú lé lórí. Nípa báyìí, Dafidi kọ̀wé pé: “Nígbà tí mo bá jí, èmi wà lọ́dọ̀ rẹ síbẹ̀.” (Orin Dafidi 139:17, 18) Títí ayérayé púpọ̀ síi ni yóò ṣì tún wà fún wa láti kọ́ nípa Jehofa àti àwọn ọ̀nà rẹ̀. Àwa kò ní dórí kókó náà tí a ó ti mọ gbogbo rẹ̀ tán láé.—Romu 11:33.
Kíkórìíra Ohun tí Jehofa Kórìíra
11. Èéṣe tí ó fi ṣe pàtàkì kìí ṣe láti mọ àwọn ìrò-inú Ọlọrun nìkan ṣùgbọ́n láti ṣàjọpín àwọn ìmọ̀lára rẹ̀?
11 Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun wa kìí wulẹ̀ ṣe fún ojú-ìwòye náà láti fi àwọn òtítọ́ kún orí wa lásán. Bí a ti ń jẹ́ kí ó wọnú ọkàn-àyà wa lọ, àwa pẹ̀lú tún bẹ̀rẹ̀ síí ṣàjọpín àwọn ìmọ̀lára Ọlọrun. Ìyẹn sì ti ṣe pàtàkì tó! Bí a kò bá mú irú àwọn ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ dàgbà, kí ni ó lè jẹ́ ìyọrísí rẹ̀? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè ṣeéṣe fún wa láti ṣàtúnsọ ohun tí Bibeli sọ, síbẹ̀ náà, a lè wo ohun tí a kàléèwọ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó fanilọ́kànmọ́ra, tàbí a lè nímọ̀lára pé ohun tí a béèrè-fún jẹ́ ẹrù-ìnira kan. Òtítọ́ ni pé bí a bá tilẹ̀ kórìíra ohun tí ó burú, a lè ní ìjàkadì kan nítorí àìpé ènìyàn. (Romu 7:15) Ṣùgbọ́n bí a kò bá lo ìsapá aláápọn láti mú ohun tí a jẹ́ nínú wá sí ìlà pẹ̀lú ohun tí ó tọ́, àwa ha lè retí láti wu Jehofa, “olùṣàyẹ̀wò àwọn ọkàn-àyà” bí?—Owe 17:3, NW.
12. Báwo ni ìfẹ́ bíi ti Ọlọrun àti ìkórìíra bíi ti Ọlọrun ti ṣe pàtàkì tó?
12 Ìkórìíra bíi ti Ọlọrun jẹ́ ààbò alágbára lòdìsí ìwà-àìtọ́, àní gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ bíi ti Ọlọrun ti ń mú kí ṣíṣe ohun tí ó tọ̀nà jẹ́ ìgbádùn. (1 Johannu 5:3) Léraléra ni Ìwé Mímọ́ rọ̀ wá láti mú ìfẹ́ àti ìkórìíra dàgbà. “Ẹ̀yin tí ó fẹ́ Oluwa, ẹ kórìíra ibi.” (Orin Dafidi 97:10) “Ẹ máa takété sí ohun tíí ṣe búburú; ẹ faramọ́ ohun tíí ṣe rere.” (Romu 12:9) Àwa ha ń ṣe ìyẹn bí?
13. (a) Pẹ̀lú àdúrà Dafidi wo nípa ìparun àwọn ènìyàn búburú ni a wà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìṣọ̀kan? (b) Gẹ́gẹ́ bí a ti fihàn nínú àdúrà Dafidi, àwọn wo ni olùṣe búburú tí ó gbàdúrà pé kí Ọlọrun parun?
13 Jehofa ti sọ ète rẹ̀ láti fa gbòǹgbò àwọn ẹni búburú tu kúrò lórí ilẹ̀-ayé àti láti mú ilẹ̀-ayé titun kan wá nínú èyí tí òdodo yóò máa gbé. (Orin Dafidi 37:10, 11; 2 Peteru 3:13) Àwọn olùfẹ́ òdodo ń yánhànhàn fún àkókò yẹn láti dé. Wọ́n wà ní ìfohùnṣọ̀kan kíkún pẹ̀lú Dafidi olórin náà, tí ó gbàdúrà pé: “Ọlọrun ìbá jẹ́ pa ènìyàn búburú nítòótọ́: nítorí náà kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin ọkùnrin ẹ̀jẹ̀. Ẹni tí ń fi inú búburú sọ̀rọ̀ sí ọ, àwọn ọ̀tá rẹ ń pe orúkọ rẹ ní asán!” (Orin Dafidi 139:19, 20) Dafidi kò yánhànhàn láti pa irú àwọn ẹni búburú bẹ́ẹ̀ fúnraarẹ̀. Ó gbàdúrà pé ìyà-ibi yóò ti ọwọ́ Jehofa wá. (Deuteronomi 32:35; Heberu 10:30) Àwọn wọ̀nyí kìí ṣe àwọn ènìyàn tí wọ́n wulẹ̀ ti ṣẹ̀ sí Dafidi fúnraarẹ̀ ní àwọn ọ̀nà kan. Wọ́n ti ṣojú fún Ọlọrun lọ́nà òdì, ní lílo orúkọ rẹ̀ ní ọ̀nà tí kò níláárí. (Eksodu 20:7) Lọ́nà àbòsí, wọ́n fẹ́nujẹ́wọ́ pé àwọn ń jọ́sìn rẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n ń lo orúkọ rẹ̀ láti gbé àwọn ìhùmọ̀ tiwọn fúnraawọn lárugẹ. Dafidi kò ní ìfẹ́ fún àwọn wọnnì tí wọ́n yàn láti jẹ́ ọ̀tá Ọlọrun.
14. Àwọn ẹni búburú tí a lè ràn lọ́wọ́ ha wà bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo?
14 Àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ ènìyàn tí wọn kò mọ Jehofa ni wọ́n wà. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ń fi àìmọ̀kan ṣe àwọn ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun fihàn pé ó jẹ́ búburú. Bí wọ́n bá ń baa lọ ní ipa-ọ̀nà yìí, wọn yóò wà lára àwọn wọnnì tí yóò ṣègbé nígbà ìpọ́njú ńlá. Síbẹ̀, Jehofa kò ní inúdídùn nínú ikú ẹni búburú, bẹ́ẹ̀ ni àwa kò níláti ṣe bẹ́ẹ̀. (Esekieli 33:11) Níwọ̀n bí àkókò bá ti yọ̀ǹda tó, a ń sakun láti ran irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n sì fi ọ̀nà Jehofa sílò. Ṣùgbọ́n kí ni bí àwọn ènìyàn kan bá fi ìkórìíra mímúná hàn fún Jehofa?
15. (a) Àwọn wo ni olórin náà kà sí “ọ̀tá” tòótọ́? (b) Báwo ni àwa lónìí ṣe lè fihàn pé a “kórìíra” àwọn wọnnì tí ń ṣọ̀tẹ̀ sí Jehofa?
15 Nípa wọn, olórin náà sọ pé: “Oluwa, ǹjẹ́ èmi kò kórìíra àwọn tí ó kórìíra rẹ? ǹjẹ́ inú mi kò ha sì bàjẹ́ sí àwọn tí ó dìde sí ọ? Èmi kórìíra wọn ní àkótán: èmi kà wọ́n sí ọ̀tá mi.” (Orin Dafidi 139:21, 22) Nítorí pé wọ́n kórìíra Jehofa lọ́nà mímúná ni ó jẹ́ kí Dafidi fi ìkórìíra-tẹ̀gàntẹ̀gàn wò wọn. Àwọn apẹ̀yìndà wà lára àwọn wọnnì tí wọ́n fi ìkórìíra wọn hàn sí Jehofa nípa ṣíṣọ̀tẹ̀ lòdìsí i. Ìpẹ̀yìndà jẹ́, níti tòótọ́, ìṣọ̀tẹ̀ lòdìsí Jehofa. Àwọn apẹ̀yìndà kan fẹnujẹ́wọ́ pé àwọn mọ Ọlọrun àti pé àwọn ń ṣíṣẹ́sìn ín, ṣùgbọ́n wọ́n ṣá ẹ̀kọ́ tàbí àwọn ohun-àbéèrè-fún tí a là kalẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tì. Àwọn mìíràn jẹ́wọ́ pé àwọn gba Bibeli gbọ́, ṣùgbọ́n wọ́n ṣá ètò-àjọ Jehofa tì wọ́n sì ń fi ìtara gbìyànjú láti dí iṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́. Nígbà tí wọ́n bá fi ìmọ̀ọ́mọ̀ yan irú ìwà-búburú bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n bá ti mọ ohun tí ó tọ́, nígbà tí búburú náà bá di mọ́ọ́lí gan-an débi pé ó ti di apá tí kò ṣeé yàsọ́tọ̀ nínú ara wọn, nígbà náà Kristian kan gbọ́dọ̀ kórìíra (ní èrò ìtumọ̀ tí ó bá Bibeli mu ti ọ̀rọ̀ náà) àwọn wọnnì tí wọ́n ti so araawọn pọ̀ mọ́ ìwà-búburú lọ́nà tí kò ṣeé yàsọ́tọ̀. Àwọn Kristian tòótọ́ ń ṣàjọpín ìmọ̀lára Jehofa nípa irú àwọn apẹ̀yìndà bẹ́ẹ̀; wọn kìí ṣojúmìító nípa èrò àwọn apẹ̀yìndà. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ‘inú wọn bàjẹ́’ sí àwọn wọnnì tí wọ́n ti sọ araawọn di ọ̀tá Ọlọrun, ṣùgbọ́n wọ́n fi sílẹ̀ sọ́wọ́ Jehofa láti gbẹ̀san.—Jobu 13:16; Romu 12:19; 2 Johannu 9, 10.
Nígbà tí Ọlọrun Bá Wádìí Wa Wò
16. (a) Èéṣe tí Dafidi fi fẹ́ kí Jehofa wádìí òun wò? (b) Kí ni ó wà níbẹ̀ nípa ọkàn-àyà tiwa tí a níláti sọ fún Ọlọrun pé kí ó ràn wá lọ́wọ́ láti lóye?
16 Dafidi kò fẹ́ láti dàbí àwọn olùṣe búburú ní ọ̀nà èyíkéyìí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn gbìyànjú láti fi ohun tí wọ́n jẹ́ nínú pamọ́, ṣùgbọ́n Dafidi fi ìrẹ̀lẹ̀ gbàdúrà pé: “Ọlọrun, wádìí mi, kí o sì mọ [ọkàn-àyà, “NW”] mi: dán mi wò, kí o sì mọ ìrò-inú mi: Kí o sì wò bí ipa-ọ̀nà [ríronilára, “NW”] kan bá wà nínú mi, kí o sì fi ẹsẹ̀ mi lé ọ̀nà àìnípẹ̀kun.” (Orin Dafidi 139:23, 24) Nígbà tí ó ń tọ́ka sí ọkàn-àyà rẹ̀, Dafidi kò ní ẹ̀yà-ara gidi lọ́kàn. Ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ìtumọ̀ àfiṣàpẹẹrẹ ọ̀rọ̀ yẹn, ó tọ́ka sí ohun tí òun jẹ́ nínú, ọkùnrin inú lọ́hùn-ún. Àwa pẹ̀lú níláti fẹ́ kí Ọlọrun wádìí ọkàn-àyà wa wò kí ó sì fòyemọ̀ bí a bá ní ìfẹ́-ọkàn, ìfẹ́ni, èrò-ìmọ̀lára, ète, ìrò-inú, tàbí ète-ìsúnniṣe tí kò yẹ. (Orin Dafidi 26:2) Jehofa késí wa pé: “Ọmọ mi, fi àyà rẹ fún mi, kí o sì jẹ́ kí ojú rẹ kí ó ní inú-dídùn sí ọ̀nà mi.”—Owe 23:26.
17. (a) Dípò bíbo àwọn ìrònú amúniṣàníyàn mọ́lẹ̀, kí ni a níláti ṣe? (b) Ó ha níláti yà wá lẹ́nu láti rí ìtẹ̀sí tí kò tọ́ nínú ọkàn-àyà wa bí, kí sì ni a níláti ṣe nípa wọn?
17 Bí àwọn ìrò-inú ríronilára, amúniṣàníyàn bá farapamọ́ nínú wa nítorí àwọn ìfẹ́-ọkàn tàbí ète-ìsúnniṣe tí kò tọ́ tàbí nítorí àwọn ìwà àìtọ́ kan ní apá ọ̀dọ̀ wa, nígbà náà dájúdájú a fẹ́ kí Jehofa ràn wá lọ́wọ́ láti bá wa yanjú ọ̀ràn náà kúrò nílẹ̀. Dípò àwọn ọ̀rọ̀ náà “ipa-ọ̀nà ríronilára,” ìtumọ̀ Moffatt lo ọ̀rọ̀ náà “ipa-ọ̀nà àìtọ́”; The New English Bible sọ pé: “Ipa-ọ̀nà èyíkéyìí tí ó mú inú rẹ̀ [ìyẹn ni, Ọlọrun] bàjẹ́.” Àwa fúnraawa lè má lóye àwọn ìrónú amúniṣàníyàn wa àti nítorí náà kí á má mọ bi a ó ti sọ ìṣòro wa fún Ọlọrun, ṣùgbọ́n òun lóye ipò wa. (Romu 8:26, 27) Kò níláti yà wá lẹ́nu bí àwọn ìtẹ̀sí búburú bá wà nínú ọkàn-àyà wa; síbẹ̀, àwa kò níláti fààyè gbà wọ́n. (Genesisi 8:21) A níláti wá ìrànlọ́wọ́ Ọlọrun láti fà wọ́n tu tigbòǹgbò tigbòǹgbò. Bí a bá nífẹ̀ẹ́ Jehofa àti àwọn ọ̀nà rẹ̀ nítòótọ́, a lè tọ̀ ọ́ lọ fún irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìgbọ́kànlé náà pé “Ọlọrun tóbi ju ọkàn wa lọ.”—1 Johannu 3:19-21.
18. (a) Báwo ni Jehofa ṣe ń ṣamọ̀nà wa ní ọ̀nà àìnípẹ̀kun? (b) Bí a bá ń báa lọ láti tẹ̀lé ìdarí Jehofa, oríyìn ọlọ́yàyà wo ni a lè retí láti rígbà?
18 Ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà olórin náà pé Jehofa yóò ṣamọ̀nà òun ní ọ̀nà àìnípẹ̀kun, Jehofa, nítòótọ́, ń ṣamọ̀nà àwọn ìráńṣẹ́ rẹ̀ onírẹ̀lẹ̀ àti onígbọràn. Ó ń ṣamọ̀nà wọn kìí ṣe kìkì ní ipa-ọ̀nà tí ó lè túmọ̀sí ẹ̀mí gígùn nítorí pé a kò ké wọn kúrò láìtọ́jọ́ fún ṣíṣe búburú ṣùgbọ́n ní ọ̀nà tí ń ṣamọ̀nà sí ìyè àìnípẹ̀kun. Ó tẹ́ àìní wa fún ìtóye ẹbọ ètùtù-ẹ̀ṣẹ̀ Jesu mọ́ wa lọ́kàn. Nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ètò-àjọ rẹ̀, ó ń pèsè ìtọ́ni ṣíṣekókó fún wa kí ó baà lè ṣeéṣe fún wa láti ṣe ìfẹ́-inú rẹ̀. Ó ń tẹnumọ́ ìjẹ́pàtàkì dídáhùnpadà sí ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ fún wa kí á baà lè di irú ẹni tí a jẹ́wọ́ pé a jẹ́ ní òde-ara ní inú pẹ̀lú. (Orin Dafidi 86:11) Ó sì fún wa níṣìírí pẹ̀lú ìfojúsọ́nà fún ìlera pípé nínú ayé titun òdodo kan papọ̀ pẹ̀lú ìyè ayérayé tí a ó lò láti fi ṣiṣẹ́sìn ín, òun Ọlọrun òtítọ́ kanṣoṣo náà. Bí a bá ń báa lọ láti máa dáhùnpadà sí ìdarí rẹ̀ pẹ̀lú ìdúróṣinṣin, òun, ní ọ̀nà yìí, yóò sọ fún wa, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún Ọmọkùnrin rẹ̀ pé: “Mo ti tẹ́wọ́gbà ọ́.”—Luku 3:22, NW; Johannu 6:27; Jakọbu 1:12.
Kí ni Àlàyé Rẹ?
◻ Èéṣe tí ojú-ìwòye Jehofa nípa àwọn ìráńṣẹ́ rẹ̀ fi sábà máa ń yàtọ̀ sí ojú-ìwòye ti ènìyàn?
◻ Kí ni ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti fòyemọ ohun tí Ọlọrun rí nígbà tí ó bá ń ṣàyẹ̀wò ọkàn-àyà wa?
◻ Irú oríṣi ìkẹ́kọ̀ọ́ wo ní ń ràn wá lọ́wọ́ láti mọ àwọn òtítọ́ àti láti dáàbòbo ọkàn-àyà wa?
◻ Èéṣe tí ó fi ṣe pàtàkì kìí ṣe láti mọ ohun tí Ọlọrun sọ nìkan ṣùgbọ́n láti ṣàjọpín àwọn ìmọ̀lára rẹ̀?
◻ Èéṣe tí a fi níláti dá gbàdúrà pé: “Ọlọrun, wádìí mi, kí o sì mọ àyà mi”?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Nígbà tí o bá ń kẹ́kọ̀ọ́, sakun láti sọ àwọn ìrò-ìnú àti ìmọ̀lára Ọlọrun di tìrẹ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwọn ìrò-ìnú Jehofa “ju iyanrìn lọ ní iye”
[Credit Line]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.