Òwe
4 Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ fetí sí ìbáwí bàbá;+
Ẹ fiyè sílẹ̀, kí ẹ lè ní òye,
2 Nítorí màá fún yín ní ìtọ́ni rere;
4 Bàbá mi kọ́ mi, ó sì sọ pé: “Kí àwọn ọ̀rọ̀ mi wà lọ́kàn rẹ digbí.+
Pa àwọn àṣẹ mi mọ́ kí o sì máa wà láàyè.+
Má gbàgbé, má sì kúrò nínú ohun tí mo sọ.
6 Má pa á tì, yóò dáàbò bò ọ́.
Nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, yóò sì pa ọ́ mọ́.
8 Jẹ́ kó níyì gan-an lójú rẹ, yóò sì gbé ọ ga.+
Yóò bọlá fún ọ nítorí pé o gbá a mọ́ra.+
9 Yóò fi òdòdó ẹ̀yẹ tó fani mọ́ra sí ọ lórí;
Yóò sì dé ọ ní adé ẹwà.”
12 Nígbà tí o bá ń rìn, ẹsẹ̀ rẹ kò ní kọ́lẹ̀;
Tí o bá sì ń sáré, o ò ní kọsẹ̀.
13 Di ìbáwí mú; má ṣe jẹ́ kó lọ.+
Pa á mọ́, nítorí òun ni ẹ̀mí rẹ.+
16 Torí wọn ò lè sùn àfi tí wọ́n bá ṣe ohun tí kò dáa.
Wọn kì í rí oorun sùn àfi tí wọ́n bá mú kí ẹnì kan ṣubú.
17 Oúnjẹ ìwà burúkú ni wọ́n fi ń bọ́ ara wọn,
Wáìnì ìwà ipá ni wọ́n sì ń mu.
19 Ọ̀nà àwọn ẹni burúkú dà bí òkùnkùn;
Wọn ò mọ ohun tó ń mú wọn kọsẹ̀.
20 Ọmọ mi, fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ mi;
Fetí sílẹ̀ dáadáa* sí àwọn ọ̀rọ̀ mi.
21 Máa fi wọ́n sọ́kàn;
Jẹ́ kí wọ́n jinlẹ̀ lọ́kàn rẹ,+
22 Nítorí ìyè ni wọ́n jẹ́ fún àwọn tó wá wọn rí+
Wọ́n sì jẹ́ ìlera fún gbogbo ara* wọn.
23 Ju gbogbo ohun mìíràn tí ò ń dáàbò bò, dáàbò bo ọkàn rẹ,+
Nítorí inú rẹ̀ ni àwọn ohun tó ń fúnni ní ìyè ti ń wá.
27 Má yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì.+
Má fi ẹsẹ̀ rẹ lé ọ̀nà búburú.