Máa Rìn Ní Ọ̀nà Ìwà Títọ́
“Ní tèmi, èmi yóò máa rìn nínú ìwà títọ́ mi.”—SÁÀMÙ 26:11.
1, 2. (a) Kí nìdí tí ìwà títọ́ èèyàn fi wọnú ọ̀ràn bóyá Ọlọ́run jẹ́ ọba aláṣẹ tàbí kò jẹ́ bẹ́ẹ̀? (b) Báwo làwọn ẹ̀dá onílàákàyè ṣe lè fi hàn pé ipò ọba aláṣẹ Jèhófà làwọn fara mọ́?
NÍGBÀ tí Sátánì ṣọ̀tẹ̀ ní ọgbà Édẹ́nì, ohun tó ń sọ ni pé Ọlọ́run ò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso gbogbo ohun tó dá. Nígbà tó yá, ó ní ohun táwọn téèyàn ń rí gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run ló mú kí wọ́n máa sìn ín. (Jóòbù 1:9-11; 2:4) Bí ọ̀rọ̀ nípa ìwà títọ́ èèyàn ṣe wọnú ọ̀ràn tí Sátánì dá sílẹ̀ nípa bóyá Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso tàbí kò lẹ́tọ̀ọ́ nìyẹn.
2 Òótọ́ ni pé yálà àwọn tí Ọlọ́run dá pa ìwà títọ́ mọ́ tàbí wọn ò pa á mọ́, ìyẹn ò ní kí Ọlọ́run máà jẹ́ Ọba Aláṣẹ mọ́, síbẹ̀ àwọn èèyàn àtàwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó jẹ́ ọmọ Ọlọ́run lè fi hàn pé àwọn fara mọ́ Ọlọ́run tàbí àwọn ò fara mọ́ ọn. Ọ̀nà wo ni wọ́n lè gbà ṣèyẹn? Tí wọ́n bá ń rìn ní ọ̀nà ìwà títọ́ á jẹ́ pé wọ́n fara mọ́ ọn, tí wọ́n ò bá rìn nínú rẹ̀, wọn ò fara mọ́ ọn nìyẹn. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ìwà kálukú la ó fi ṣèdájọ́ rẹ̀.
3. (a) Kí ni Jóòbù àti Dáfídì fẹ́ kí Jèhófà yẹ̀ wò kó sì tún ṣèdájọ́ rẹ̀? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló jẹ yọ lórí ọ̀rọ̀ ìwà títọ́?
3 Jóòbù fi ìdánilójú sọ pé: “[Jèhófà] yóò wọ̀n mí lórí òṣùwọ̀n pípéye, Ọlọ́run yóò sì wá mọ ìwà títọ́ mi.” (Jóòbù 31:6) Ìwà títọ́ ni Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì sọ pé kí Jèhófà yẹ̀ wò nígbà tó gbàdúrà pé: “Ṣe ìdájọ́ mi, Jèhófà, nítorí pé mo ti rìn nínú ìwà títọ́ mi, Jèhófà sì ni mo gbẹ́kẹ̀ lé, kí n má bàa gbò yèpéyèpé.” (Sáàmù 26:1) Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì káwa náà máa rìn ní ọ̀nà ìwà títọ́! Àmọ́ kí ni ìwà títọ́, kí ló sì túmọ̀ sí tá a bá sọ pé èèyàn ń rìn ní ọ̀nà ìwà títọ́? Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti máa pa ìwà títọ́ wa mọ́ nìṣó?
“Mo Ti Rìn Nínú Ìwà Títọ́ Mi”
4. Kí ni ìwà títọ́?
4 Tá a bá sọ pé ẹnì kan pa ìwà títọ́ mọ́, ó túmọ̀ sí pé onítọ̀hún jẹ́ ẹni mímọ́, tí ò lábààwọ́n, olóòótọ́ èèyàn, tí ò sì lálèébù. Àmọ́, kì í ṣe kéèyàn máa ṣe ohun tó tọ́ nìkan ni ìwà títọ́ túmọ̀ sí o. Ó tún túmọ̀ sí pé kéèyàn níwà tó dáa tàbí kéèyàn máa fi gbogbo ọkàn sin Ọlọ́run. Sátánì ò gbà pé tọkàntọkàn ni Jóòbù fi ń sin Ọlọ́run, ìdí nìyẹn to fi sọ fún Ọlọ́run pé: “Fún ìyípadà, jọ̀wọ́, na ọwọ́ rẹ, kí o sì fi kan egungun rẹ̀ àti ẹran ara rẹ̀, kí o sì rí i bóyá kì yóò bú ọ ní ojú rẹ gan-an.” (Jóòbù 2:5) Yàtọ̀ sí pé kéèyàn máa hùwà tó dára, ìwà títọ́ tún gba pé kéèyàn lẹ́mìí tó dáa.
5. Kí ló jẹ́ ká mọ̀ pé kò dìgbà téèyàn bá di ẹni pípé kó tó lè pa ìwà títọ́ mọ́?
5 Àmọ́ ṣá o, kò túmọ̀ sí pé ẹnì kan ní láti di ẹni pípé kó tó lè pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́. Aláìpé ni Dáfídì Ọba, ó sì ṣe ọ̀pọ̀ àṣìṣe nígbà ayé rẹ̀. Síbẹ̀, Bíbélì pè é ní ọkùnrin tó rìn “pẹ̀lú ìwà títọ́ ọkàn-àyà.” (1 Àwọn Ọba 9:4) Kí nìdí? Ìdí ni pé Dáfídì fẹ́ràn Jèhófà. Gbogbo ọkàn ló fi ń sìn ín. Ó gba àṣìṣe rẹ̀ láìjiyàn, ó gba ìbáwí, ó sì tún ìwà rẹ̀ ṣe. Bí Dáfídì ṣe fi gbogbo ọkàn sin Jèhófà Ọlọ́run àti ìfẹ́ tó ní sí i jẹ́ ká rí i pé lóòtọ́ ló jẹ́ oníwà títọ́.—Diutarónómì 6:5, 6.
6, 7. Kí ni rírìn nínú ìwà títọ́ túmọ̀ sí?
6 Kì í ṣe nínú ọ̀ràn ìsìn nìkan ló ti yẹ ká máa pa ìwà títọ́ mọ́, ó yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀ nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe. Dáfídì “rìn” nínú ìwà títọ́ rẹ̀. Bíbélì The New Interpreter’s Bible sọ pé, “Ọ̀rọ̀ ìṣe náà ‘rìn’ túmọ̀ sí ‘ìgbésí ayé ẹni’ tàbí ‘irú ìgbésí ayé téèyàn ń gbé.’” Nígbà tí onísáàmù náà ń sọ̀rọ̀ nípa “àwọn aláìní-àléébù ní ọ̀nà wọn,” ó sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí ń pa àwọn ìránnilétí [Ọlọ́run] mọ́; wọ́n ń fi gbogbo ọkàn-àyà wá a. Ní ti tòótọ́, wọn kò fi àìṣòdodo kankan ṣe ìwà hù. Àwọn ọ̀nà rẹ̀ ni wọ́n ń rìn.” (Sáàmù 119:1-3) Pípa ìwà títọ́ mọ́ gba pé ká máa wá bí a óò ṣe máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà ká sí tún máa wá bí a óò ṣe máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀.
7 Rírìn ní ọ̀nà ìwà títọ́ gba pè kéèyàn máa fọkàn sin Ọlọ́run, kódà bí nǹkan ò tiẹ̀ rọgbọ pàápàá. Gbogbo èèyàn ló máa rí i pé a jẹ́ oníwà títọ́ tá a bá fara da àdánwò, tá a dúró gbọn-in nígbà ìṣòro, tá ò sì kó sínú ìdẹwò ayé búburú yìí. Ńṣe là ‘ń mú ọkàn Jèhófà yọ̀’ nítorí pé yóò lẹ́nu ọ̀rọ̀ láti fún ẹni tó ń gàn án lésì. (Òwe 27:11) Ó wá yẹ kí èyí mú ká pinnu bíi ti Jóòbù tó sọ pé: “Títí èmi yóò fi gbẹ́mìí mì, èmi kì yóò mú ìwà títọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi!” (Jóòbù 27:5) Sáàmù kẹrìndínlọ́gbọ̀n sọ àwọn ohun tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti rìn ní ọ̀nà ìwà títọ́.
“Yọ́ Kíndìnrín Mi àti Ọkàn-Àyà Mi Mọ́.”
8. Kí lohun tó o rí kọ́ látinú ẹ̀bẹ̀ tí Dáfídì bẹ Jèhófà pé kó yẹ kíndìnrín òun àti ọkàn òun wò?
8 Dáfídì gbàdúrà pé: “Wádìí mi wò, Jèhófà, kí o sì dán mi wò; yọ́ kíndìnrín mi àti ọkàn-àyà mi mọ́.” (Sáàmù 26:2) Inú lọ́hùn-ún ni kíndìnrín wà. Nínú Bíbélì, ohun tí kíndìnrín ṣàpẹẹrẹ ni èrò inú èèyàn àti bí ọ̀ràn ṣe máa ń rí lára ẹni. Ní ti ọkàn, ó ṣàpẹẹrẹ irú èèyàn tẹ́nì kan jẹ́ gan-an, ìyẹn ohun tó ń rò, bí ọ̀ràn ṣe máa ń rí lára rẹ̀, àti làákàyè tó ní. Nígbà tí Dáfídì sọ fún Jèhófà pé kó yẹ òun wò, ńṣe ló ń fẹ́ kó yẹ èrò ọkàn òun wò fínnífínní.
9. Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń yọ́ kíndìnrín wa àti ọkàn wa mọ́?
9 Dáfídì bẹ Jèhófà pé kó yọ́ kíndìnrín òun àti ọkàn òun mọ́. Báwo ni Jèhófà ṣe ń yọ́ irú èèyàn tá a jẹ́ gan-an mọ́? Dáfídì kọ ọ́ lórin pé: “Èmi yóò fi ìbùkún fún Jèhófà, ẹni tí ó ti fún mi ní ìmọ̀ràn. Ní ti tòótọ́, kíndìnrín mi ti tọ́ mi sọ́nà ní òru.” (Sáàmù 16:7) Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Ó túmọ̀ sí pé àwọn ìmọ̀ràn Ọlọ́run wọ Dáfídì lákínyẹmí ara, ó ríbi gbé nínú ọkàn rẹ̀, ó sì tún èrò ọkàn rẹ̀ ṣe. Ìmọ̀ràn Ọlọ́run lè tún èrò tiwa náà ṣe tá a bá ń ronú dáadáa lórí àwọn ìmọ̀ràn tá à ń kà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àtèyí tá à ń gbá látọ̀dọ̀ àwọn aṣojú rẹ̀ àti ètò rẹ̀, tá a sì ń jẹ́ kó silẹ̀ nínú ọkàn wa. Tá a bá ń gbàdúrà sí Jèhófà nígbà gbogbo pé kó yọ́ wa mọ́ lọ́nà yìí, èyí máa ràn wá lọ́wọ́ láti máa rìn ní ọ̀nà ìwà títọ́.
“Inú Rere Rẹ Onífẹ̀ẹ́ Ń Bẹ Ní Iwájú Mi”
10. Kí ló ran Dáfídì lọ́wọ́ láti máa rìn nínú òtítọ́ Ọlọ́run?
10 Dáfídì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Nítorí pé inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ń bẹ ní iwájú mi, mo sì ti rìn nínú òtítọ́ rẹ.” (Sáàmù 26:3) Dáfídì mọ àwọn ọ̀nà tí Ọlọ́run gba fi inú rere onífẹ̀ẹ́ hàn, ó mọyì wọn, ó sì máa ń ronú lé wọn lórí. Ó kọ ọ́ lórin pé: “Fi ìbùkún fún Jèhófà, ìwọ ọkàn mi, má sì gbàgbé gbogbo ìgbòkègbodò iṣẹ́ rẹ̀.” Nígbà tí Dáfídì rántí ọkàn lára àwọn “ìgbòkègbodò” Ọlọ́run, ó sọ pé: “Jèhófà ń mú àwọn ìṣe òdodo ṣẹ ní kíkún àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ fún gbogbo àwọn tí a ń lù ní jìbìtì. Ó sọ àwọn ọ̀nà rẹ̀ di mímọ̀ fún Mósè, àní ìbálò rẹ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.” (Sáàmù 103:2, 6, 7) Ó lè jẹ́ pé jìbìtì táwọn ará Íjíbítì lu àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà ayé Mósè ni Dáfídì ń ronú nípa rẹ̀. Tó bá jẹ́ pé ìyẹn ni, á jẹ́ pé àṣàrò tí Dáfídì ń ṣe nípa bí Jèhófà ṣe fi àwọn ọ̀nà tó gbà dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè han Mósè wọ̀ ọ́ lọ́kàn, ó sì mú kó túbọ̀ pinnu láti máa rìn nínú òtítọ́ Ọlọ́run.
11. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa rìn ní ọ̀nà ìwà títọ́?
11 Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nígbà gbogbo tá a sì ń ṣe àṣàrò lórí àwọn ohun tá a kọ́, ìyẹn á ràn wá lọ́wọ́ láti máa rìn ní ọ̀nà ìwà títọ́. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá rántí pé ńṣe ni Jósẹ́fù sá jáde nígbà tí ìyàwó Pọ́tífárì fi ìlọ̀kulọ̀ lọ̀ ọ́, ó dájú pé ìṣírí lèyí máa jẹ́ fún wa láti sá fún irú àwọn ìlọ̀kulọ̀ bẹ́ẹ̀ níbi iṣẹ́ wa, nílé ìwé, tàbí làwọn ibòmíràn. (Jẹ́nẹ́sísì 39:7-12) Ǹjẹ́ àpẹẹrẹ kankan wà tá a lè ronú nípa rẹ̀ nígbà táǹfààní tó lè sọni dọlọ́rọ̀ tàbí tó lè gbéni dépò ọlá nínú ayé bá yọjú? Àpẹẹrẹ Mósè, ẹni tí ó kọ ògo Íjíbítì sílẹ̀ wà níbẹ̀. (Hébérù 11:24-26) Tá a bá ń rántí ìfaradà Jóòbù nígbà gbogbo, ó dájú pé ó máa ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, láìka àìsàn àti ìṣòro sí. (Jákọ́bù 5:11) Tí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí wa ńkọ́? Ìyẹn náà ò dẹ́rù bà wá, nítorí pé tá a bá ń rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Dáníẹ́lì wà nínú ihò kìnnìún, a óò túbọ̀ ní ìgboyà!—Dáníẹ́lì 6:16-22.
“Èmi Kò Bá Àwọn Tí Kì Í Sọ Òtítọ́ Jókòó”
12, 13. Irú àwọn èèyàn wo ni kò yẹ ká máa bá kẹ́gbẹ́?
12 Nígbà tí Dáfídì ń tọ́ka sí ohun mìíràn tó mú kó túbọ̀ pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́, ó sọ pé: “Èmi kò bá àwọn tí kì í sọ òtítọ́ jókòó; àwọn tí ń fi ohun tí wọ́n jẹ́ pa mọ́ ni èmi kì í sì í bá wọlé. Mo kórìíra ìjọ àwọn aṣebi, èmi kì í sì í bá àwọn ẹni burúkú jókòó.” (Sáàmù 26:4, 5) Dáfídì ò kì í bá àwọn ẹni ibi jókòó. Ó kórìíra ẹgbẹ́ búburú.
13 Àwa náà ńkọ́? Ǹjẹ́ a máa ń bá àwọn tí kì í sọ òtítọ́ kẹ́gbẹ́ nípasẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n, fídíò, sinimá, Íńtánẹ́ẹ̀tì, tàbí làwọn ọ̀nà míì? Ṣé a máa ń jìnnà sáwọn tó ń fi ohun tí wọ́n jẹ́ pa mọ́? Nílé ìwé wa tàbí níbi iṣẹ́ wa, àwọn kan lè máa ṣe bíi pé ọ̀rẹ́ wa ni wọ́n, àmọ́ tó jẹ́ pé bí tiwa ṣe máa bà jẹ́ ni wọ́n ń wá. Ṣé ó wá yẹ ká máa bá àwọn tí kì í rìn ní ọ̀nà òtítọ́ Ọlọ́run ṣe wọléwọ̀de? Àwọn apẹ̀yìndà lè máa ṣe bíi pé èèyàn dáadáa ni wọ́n, kí wọ́n sì fi ohun tó wà lọ́kàn wọn pa mọ́ kí wọ́n bàa lè fà wá kúrò nínú ìjọsìn Jèhófà. Tí àwọn kan nínú ìjọ bá ń ṣe dáadáa lójú àwọn èèyàn àmọ́ tí wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ lábẹ́lẹ̀ ńkọ́? Ńṣe làwọn náà ń fi ohun tí wọ́n jẹ́ pa mọ́. Nígbà tí Jayson tó ti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ báyìí wà lọ́dọ̀ọ́, irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ló ń bá ṣọ̀rẹ́. Ohun tó sọ nípa àwọn ọ̀rẹ́ ọ̀hún rèé, ó ní: “Lọ́jọ́ kan, ọkàn lára wọn sọ fún mi pé: ‘Ohun tá a ṣe nísinsìnyí ò já mọ́ nǹkan kan, nítorí pé nígbà tí ayé tuntun bá dé, kíkú la máa kú. A ò tiẹ̀ ní mọ̀ pé a pàdánù nǹkan kan.’ Ńṣe ni irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ mú kí n tún inú rò. Mi ò fẹ́ kú nígbà tí ayé tuntun bá dé.” Jayson ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mú, kò bá irú àwọn èèyàn yẹn kẹ́gbẹ́ mọ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé: “Kí a má ṣì yín lọ́nà. Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.” (1 Kọ́ríńtì 15:33) Ẹ ò rí i pé kò yẹ ká máa kẹ́gbẹ́kẹ́gbẹ́!
‘Èmi Yóò Polongo Gbogbo Iṣẹ́ Àgbàyanu Rẹ’
14, 15. Báwo la ṣe lè máa “rìn yí ká pẹpẹ [Jèhófà]”?
14 Dáfídì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Èmi yóò wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀, dájúdájú, èmi yóò rìn yí ká pẹpẹ rẹ, Jèhófà.” Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? “Láti mú kí a gbọ́ ohùn ìdúpẹ́ lọ́nà tí ó dún sókè, àti láti polongo gbogbo iṣẹ́ àgbàyanu rẹ.” (Sáàmù 26:6, 7) Dáfídì ò fẹ́ ní àbààwọ́n kankan kó bàa lè jọ́sìn Jèhófà, kó sì hàn pé kedere Ọlọ́run lòun ń sìn.
15 Gbogbo nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn tòótọ́ nínú àgọ́ ìjọsìn àti nínú tẹ́ńpìlì tí wọ́n kọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn jẹ́ “àwòrán ìṣàpẹẹrẹ àti . . . òjìji àwọn ohun ti ọ̀run.” (Hébérù 8:5; 9:23) Pẹpẹ tí wọ́n ń lò nígbà yẹn ṣàpẹẹrẹ ìfẹ́ Jèhófà láti tẹ́wọ́ gba ẹbọ tí Jésù Kristi fi ra aráyé padà. (Hébérù 10:5-10) A wẹ ọwọ́ wa mọ́ ní àìlẹ́ṣẹ̀, a sì ń “rìn yí ká pẹpẹ [Jèhófà]” nípa lílo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà náà.—Jòhánù 3:16-18.
16. Àwọn ọ̀nà wo ni sísọ àwọn iṣẹ́ àwòyanu Ọlọ́run fáwọn èèyàn gbà ń ṣe wá láǹfààní?
16 Nígbà tá a bá ronú nípa gbogbo àǹfààní tí ìràpadà náà ṣílẹ̀kùn rẹ̀ fún wa, ǹjẹ́ a kì í dúpẹ́ nínú ọkàn wa nítorí ohun tí Jèhófà àti ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo ṣe fún wa? Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa fi ìmọrírì sọ̀rọ̀ nípa àwọn iṣẹ́ àwòyanu Ọlọ́run fáwọn èèyàn, ìyẹn àwọn iṣẹ́ tó ti bẹ̀rẹ̀ látìgbà tí Ọlọ́run ti dá èèyàn sínú ọgbà Édẹ́nì táá sì máa bá a lọ títí dìgbà tó máa mú gbogbo nǹkan padà bọ̀ sípò nínú ayé tuntun òdodo rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7; Ìṣe 3:21) Ẹ ò rí i pé ààbò tẹ̀mí ní iṣẹ́ wíwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn jẹ́! (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Tá a bá ń ṣe iṣẹ́ náà lójú méjèèjì, yóò mú kí àwọn ohun tá à ń retí lọ́jọ́ iwájú túbọ̀ dá wa lójú, yóò mú kí ìgbàgbọ́ wa nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run lágbára sí i, yóò sì mú kí ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà àtàwọn ọmọnìkejì wa pọ̀ sí i.
“Mo Nífẹ̀ẹ́ Ibùgbé Ilé Rẹ”
17, 18. Irú ọwọ́ wo ló yẹ ká fi mú àwọn ìpàdé Kristẹni?
17 Inú àgọ́ ìjọsìn tó ní pẹpẹ ìrúbọ ni wọ́n ti ń jọ́sìn Jèhófà ní Ísírẹ́lì. Nígbà tí Dáfídì ń sọ bí inú òun ṣe máa ń dùn tó láti wà níbẹ̀, ó gbà á ládùúrà pé: “Jèhófà, mo nífẹ̀ẹ́ ibùgbé ilé rẹ àti ibi gbígbé ògo rẹ.”—Sáàmù 26:8.
18 Ǹjẹ́ inú wa máa ń dùn láti pé jọ sáwọn ibi tá a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà? Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a ti ń gba àwọn ìtọ́ni tẹ̀mí déédéé ni ibi ìjọsìn tòótọ́. Yàtọ̀ síyẹn, a tún máa ń ṣe àpéjọ àgbègbè, àpéjọ àyíká, àti àpéjọ àkànṣe lọ́dọọdún. “Àwọn ìránnilétí” Jèhófà la máa ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ làwọn ìpàdé wọ̀nyí. Tá a bá “nífẹ̀ẹ́ wọn lọ́nà tí ò peléke,” a ó máa hára gàgà láti lọ sípàdé a óò sì tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ nígbà tá a bá débẹ̀. (Sáàmù 119:167) Ìtura gbáà ló jẹ́ láti wà pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ tó jẹ́ pé ire wa ló jẹ wọn lógún tí wọ́n sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa rìn ní ọ̀nà ìwà títọ́ nìṣó!—Hébérù 10:24, 25.
‘Má Ṣe Mú Ìwàláàyè Mi Kúrò’
19. Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni Dáfídì ò fẹ́ dá?
19 Nítorí pé Dáfídì mọ ohun tójú ẹni tó bá kúrò lójú ọ̀nà òtítọ́ Ọlọ́run máa ń rí, ó bẹ̀bẹ̀ pé: “Má ṣe mú ọkàn mi kúrò pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe mú ìgbésí ayé mi kúrò pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ajẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, àwọn tí ìwà àìníjàánu ń bẹ ní ọwọ́ wọn, àwọn tí ọwọ́ ọ̀tún wọn sì kún fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀.” (Sáàmù 26:9, 10) Dáfídì ò fẹ́ kí wọ́n ka òun mọ́ àwọn tí kì í ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tí wọn ò kì í kó ara wọn níjàánu, tí wọ́n sì máa ń gba rìbá.
20, 21. Kí láwọn ohun tá a lè máa ṣe tó lè mú ká hùwà bíi tàwọn tí ò sin Ọlọ́run?
20 Ìwà pálapàla kúnnú ayé lónìí. Tẹlifíṣọ̀n, ìwé ìròyìn, àti sinimá máa ń gbé ìwà àìníjàánu lárugẹ. (Gálátíà 5:19) Ó ti di bárakú fáwọn kan láti máa wo àwòrán tó ń rùfẹ́ ìṣekúṣe sókè, èyí sì máa ń yọrí sí ìṣekúṣe lọ́pọ̀ ìgbà. Àwọn ọ̀dọ́ ló sì tètè máa ń kó sínú páńpẹ́ yìí. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, kì í ṣe nǹkan àjèjì bí ọmọkùnrin kan àti ọmọbìnrin kan bá jọ ń ṣeré jáde, ìdí rèé táwọn ọ̀dọ́langba kan fi máa ń rò pé ọ̀ranyàn ni káwọn ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ni ìfẹ́ ti kó sí lórí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ò tíì dàgbà tẹ́ni tó lè ṣègbéyàwó. Kí wọ́n sì lè gbádùn ìfẹ́ ìbálòpọ̀ tó ti kó sí wọn lórí, wọ́n á wá bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà àìmọ́ débi tí wọ́n á fi ṣàgbèrè.
21 Bí ọ̀ràn náà ṣe kan àwọn ọ̀dọ́ náà ló kan àwọn àgbàlagbà o. Ìwà àìṣòótọ́ ló jẹ́ téèyàn bá ń ṣèrú nídìí òwò tó sì tún jẹ́ pé tara rẹ̀ nìkan ló mọ̀. Tá a bá lọ ń rìn ní ọ̀nà ayé, ńṣe ló máa mu wa jìnnà sí Jèhófà. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká “kórìíra ohun búburú, kí [á] sì nífẹ̀ẹ́ ohun rere,” ká sì máa rìn ní ọ̀nà ìwà títọ́ nìṣó.—Ámósì 5:15.
“Tún Mi Rà Padà Kí O Sì Fi Ojú Rere Hàn Sí Mi”
22-24. (a) Ìṣírí wo lo rí nínú àwọn ọ̀rọ̀ tó parí Sáàmù kẹrìndínlọ́gbọ̀n? (b) Ìdẹkùn wo la máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
22 Ohun tí Dáfídì fi parí àdúrà tó gbà sí Ọlọ́run rèé, ó ní: “Ní tèmi, èmi yóò máa rìn nínú ìwà títọ́ mi. Tún mi rà padà, kí o sì fi ojú rere hàn sí mi. Dájúdájú, ẹsẹ̀ mi yóò dúró lórí ibi títẹ́jú pẹrẹsẹ; inú àpéjọpọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn ni èmi yóò ti máa fi ìbùkún fún Jèhófà.” (Sáàmù 26:11, 12) Bí Dáfídì ṣe pinnu láti pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́ bẹ́ẹ̀ ló ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run tún òun rà padà. Ìyẹn mà dáa o! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá, Jèhófà yóò ràn wá lọ́wọ́ tá a bá pinnu pé ọ̀nà ìwà títọ́ la ti fẹ́ máa rìn.
23 Ǹjẹ́ kí ọ̀nà tá a gbà ń ṣe gbogbo nǹkan fi hàn pé a mọyì ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ. Olúkúlùkù wa lè máa gbàdúrà sí Jèhófà pé kó yẹ èrò ọkàn òun wò kó sì yọ́ ọ mọ́. Kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójú méjèèjì ò ní jẹ́ ká gbàgbé àwọn òtítọ́ inú rẹ̀. Nígbà náà, ẹ jẹ́ ká sa gbogbo ipá wa láti má ṣe kẹ́gbẹ́ búburú, kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa fi ìbùkún fún Jèhófà láàárín ọ̀pọ̀ èèyàn. Ẹ jẹ́ ká máa fi ìtara ṣe iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, ká má ṣe jẹ́ kí ayé yìí ba àjọse rere tá a ní pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Bá a ṣe ń sa gbogbo ipá wa láti máa rìn ní ọ̀nà ìwà títọ́, ó dá wa lójú pé Jèhófà yóò ṣíjú àánú rẹ̀ wò wá.
24 Níwọ̀n bí ọ̀ràn ìwà títọ́ ti kan gbogbo nǹkan tá à ń ṣe láyé yìí, ó yẹ ká mọ̀ nípa ìdẹkùn burúkú kan, ìyẹn ọtí àmujù. A óò sọ̀rọ̀ nípa kókó yìí nínú àpilẹ̀kọ́ tó kàn.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí nìdí tó fi tọ́ pé ká ṣèdájọ́ àwọn ẹ̀dá onílàákàyè ní ìbámu pẹ̀lú bí ìwà wọn ṣe rí?
• Kí ni ìwà títọ́, kí ló sì túmọ̀ sí láti máa rìn ní ọ̀nà ìwà títọ́?
• Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti máa rìn ní ọ̀nà ìwà títọ́?
• Àwọn ewu wo la gbọ́dọ̀ mọ̀ tá a bá fẹ́ pa ìwà títọ́ mọ́?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Ǹjẹ́ o máa ń sọ fún Jèhófà nígbà gbogbo pé kó yẹ ohun tó wà nísàlẹ̀ ikùn rẹ̀ wò?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Ǹjẹ́ o máa ń ronú nípa àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń fi inú rere onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ hàn nígbà gbogbo?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ńṣe ni inú Jèhófà máa ń dùn tá a bá pa ìwà títọ́ wa mọ́ lójú àdánwò
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ǹjẹ́ o máa ń lo gbogbo ohun tí Jèhófà ń pèsè láti mú ká máa rìn ní ọ̀nà ìwà títọ́?