Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jóṣúà
NÍGBÀ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì pàgọ́ sí Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù lọ́dún 1473 ṣáájú Sànmánì Tiwa, ó dájú pé inú wọn á dùn gan-an nígbà tí Jóṣúà sọ fún wọn pé: “Ẹ ṣètò àwọn ìpèsè oúnjẹ sílẹ̀ fún ara yín, nítorí pé ní ọjọ́ mẹ́ta òní, ẹ ó sọdá Jọ́dánì yìí láti wọlé lọ gba ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run yín yóò fi fún yín láti gbà.” (Jóṣúà 1:11) Ní báyìí, wọ́n ti sún mọ́ òpin ìrìn àjò tí wọ́n fi ogójì ọdún rìn láginjù.
Ní nǹkan bí ogún ọdún ó lé díẹ̀ lẹ́yìn ìgbà yẹn, Jóṣúà tó jẹ́ olórí dúró sáàárín ilẹ̀ Kénáánì, ó sì sọ fáwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì pé: “Wò ó, nípa kèké, èmi ti fi àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí tí ó kù fún yín gẹ́gẹ́ bí ogún fún àwọn ẹ̀yà yín, gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí mo ké kúrò, láti Jọ́dánì títí dé Òkun Ńlá níbi wíwọ̀ oòrùn. Jèhófà Ọlọ́run yín sì ni ẹni tí ń tì wọ́n kúrò níwájú yín, òun sì ni ẹni tí ó lé wọn kúrò ní tìtorí yín, ẹ sì gba ilẹ̀ wọn, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà Ọlọ́run yín ti ṣèlérí fún yín.”—Jóṣúà 23:4, 5.
Jóṣúà ló kọ ìwé Jóṣúà ní ọdún 1450 ṣáájú Sànmánì Tiwa, ìwé náà sọ ìtàn alárinrin nípa àwọn nǹkan tó wáyé láàárín ọdún méjìlélógún yẹn. Àwa náà tá a wà ní bèbè àtiwọ ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí wà ní ipò tó jọ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó fẹ́ gba Ilẹ̀ Ìlérí. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká fára balẹ̀ gbé ìwé Jóṣúà yẹ̀ wò.—Hébérù 4:12.
WỌ́N LỌ SÍ “ÀWỌN PẸ̀TẸ́LẸ̀ AṢÁLẸ̀ JẸ́RÍKÒ”
Iṣẹ́ ńlá gbáà ni Jèhófà gbé fún Jóṣúà nígbà tó sọ fún un pé: “Mósè ìránṣẹ́ mi ti kú; dìde nísinsìnyí, kí o sì sọdá Jọ́dánì yìí, ìwọ àti gbogbo ènìyàn yìí, sórí ilẹ̀ tí èmi yóò fi fún wọn, fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì”! (Jóṣúà 1:2) Ọlọ́run ní kí Jóṣúà kó àwọn èèyàn tí ó tó mílíọ̀nù mélòó kan lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí. Kó tó di pé ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ọ̀hún, ó rán àwọn méjì lọ ṣe amí ilẹ̀ Jẹ́ríkò, ìyẹn ìlú tí wọ́n máa kọ́kọ́ gbà. Ibẹ̀ ni Ráhábù aṣẹ́wó ń gbé, ó sì ti gbọ́ nípa àwọn iṣẹ́ àrà tí Jèhófà ṣe nítorí àwọn èèyàn rẹ̀. Ráhábù dáàbò bo àwọn amí náà, ó tún ràn wọ́n lọ́wọ́, àwọn amí náà sì ṣèlérí fún un pé ewu kan ò ní wu ú.
Nígbà táwọn amí náà fi máa padà dé, Jóṣúà àtàwọn èèyàn náà ti múra tán láti bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò, kí wọ́n sì sọdá odò Jọ́dánì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé odò náà ti kún àkúnya, èyí kò jẹ́ ìṣòro kankan fún wọn nítorí pé Jèhófà dá ìṣàn odò náà dúró lápá òkè, omi tó wà lápá ìsàlẹ̀ odò náà láti ibi tí Jèhófà ti dá a dúró wá wọ́ lọ sínú Òkun Òkú. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì gba àárín Jọ́dánì kọjá tán, wọ́n lọ pàgọ́ sí Gílígálì nítòsí ìlú Jẹ́ríkò. Ní ọjọ́ mẹ́rin lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n ṣe àjọ̀dún Ìrékọjá ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ Jẹ́ríkò, ìyẹn ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Ábíbù. (Jóṣúà 5:10) Lọ́jọ́ kejì, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ lára àwọn ohun ọ̀gbìn ilẹ̀ náà, bí ìpèsè mánà ṣe dópin nìyẹn. Láàárín àkókò yìí ni Jóṣúà dádọ̀dọ́ gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí wọ́n bí láginjù.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́:
2:4, 5—Kí nìdí tí Ráhábù fi tan àwọn ọkùnrin tí ọba rán pé kí wọ́n lọ mú àwọn amí wọ̀nyẹn? Ráhábù dáàbò bo àwọn amí wọ̀nyẹn bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí fi ẹ̀mí rẹ̀ sínú ewu, ìgbàgbọ́ tó ní nínú Jèhófà ló sì mú kó ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, kò sófin tó dè é tí kò bá sọ ibi táwọn amí náà wà fáwọn ọkùnrin tó fẹ́ wá wu àwọn èèyàn Ọlọ́run léwu yìí. (Mátíù 7:6; 21:23-27; Jòhánù 7:3-10) Àní, a “polongo” Ráhábù ní “olódodo nípa àwọn iṣẹ́,” ara àwọn iṣẹ́ ọ̀hún sì ni títàn tó tan àwọn ọkùnrin tí ọba rán níṣẹ́ gba ọ̀nà ibòmíràn.—Jákọ́bù 2:24-26.
5:14, 15—Ta ni “olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Jèhófà”? Olórí náà tó fún Jóṣúà lókun nígbà tí Jóṣúà bẹ̀rẹ̀ sí í gba Ilẹ̀ Ìlérí ṣeé ṣe kó jẹ́ “Ọ̀rọ̀ náà,” ìyẹn Jésù Kristi ṣáájú kó tó di èèyàn. (Jòhánù 1:1; Dáníẹ́lì 10:13) Ìṣírí ló jẹ́ láti mọ̀ dájú pé Jésù Kristi tá a ti ṣe lógo ń ti àwọn èèyàn Ọlọ́run lẹ́yìn lóde òní bí wọ́n ṣe ń ja ogun tẹ̀mí!
Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:
1:7-9. Tá a bá fẹ́ kẹ́sẹ járí nínú nǹkan tẹ̀mí tá a dáwọ́ lé, ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, ká máa ṣe àṣàrò déédéé lórí ohun tí Bíbélì sọ, ká sì máa fi àwọn ohun tá à ń kọ́ ṣèwà hù.
1:11. Jóṣúà sọ fáwọn èèyàn náà pé kí wọ́n múra àwọn ohun tí wọ́n máa lò sílẹ̀, kì í ṣe pé kí wọ́n kàn kọ́wọ́ lẹ́rán, kí wọ́n wá máa retí pé kí Ọlọ́run pèsè fáwọn. Nígbà tí Jésù gbà wá nímọ̀ràn pé ká yéé máa ṣàníyàn nípa àwọn nǹkan ti ara, tó sì ṣe ìlérí pé “gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún [wa],” kò túmọ̀ sí pé ká wá jókòó tẹtẹrẹ láìṣe ohunkóhun.—Mátíù 6:25, 33.
2:4-13. Lẹ́yìn tí Ráhábù gbọ́ ìròyìn nípa àwọn nǹkan ńláńlá tí Jèhófà ṣe, tó sì mọ̀ pé wàhálà ò ní pẹ́ dé, ó pinnu pé àwọn olùjọsìn Jèhófà lóun máa tì lẹ́yìn. Tó bá ti pẹ́ díẹ̀ tó o ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tó sì dá ọ lójú pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” là ń gbé, ǹjẹ́ kò ní dáa kó o bẹ̀rẹ̀ sí í sin Ọlọ́run báyìí?—2 Tímótì 3:1.
3:15. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìròyìn rere làwọn amí tá a rán lọ wo ilẹ̀ Jẹ́ríkò mú wa, kíámọ́sá ni Jóṣúà káràmáásìkí ọ̀rọ̀ náà, kó ṣẹ̀ṣẹ̀ dúró dìgbà tí odò Jọ́dánì máa lọ sílẹ̀. Nígbà tó bá kan ọ̀rọ̀ ìjọsìn tòótọ́, ó yẹ ká lo ìgboyà dípò tí a óò fi máa dúró kí nǹkan dẹrùn ká tó ṣe àwọn ohun tó yẹ ní ṣíṣe.
4:4-8, 20-24. Ohun ìrántí làwọn òkúta méjìlá táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó ní etí odò Jọ́dánì jẹ́ fún wọn. Gbígbà tí Jèhófà ń gba àwọn èèyàn rẹ̀ òde òní sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀ ń rán wọn létí pé òun wà pẹ̀lú wọn.
WỌ́N Ń ṢẸ́GUN NÌṢÓ
Ńṣe ni wọ́n ti ìlú Jẹ́ríkò “pa gbọn-in gbọn-in . . . kò sí ẹnì kankan tí ń jáde, kò sì sí ẹnì kankan tí ń wọlé.” (Jóṣúà 6:1) Báwo ni wọ́n ṣe máa wá ṣẹ́gun ìlú náà? Jèhófà sọ ọgbọ́n tí Jóṣúà máa dá fún un. Ká tó pajú pẹ́, odi ìlú náà tí wo, ìlú náà sì ti pa run. Ráhábù àtàwọn ara ilé rẹ̀ nìkan ni kò pa run.
Ìlú ọlọ́ba tó ń jẹ́ Áì ni wọ́n wá ṣẹ́gun lẹ́yìn ìyẹn. Àwọn amí tí wọ́n rán lọ wo ìlú náà sọ pé àwọn tó ń gbébẹ̀ ò pọ̀, nítorí náà, ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ni wọ́n máa rán lọ kọlu ìlú náà. Àmọ́, ńṣe ni nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́tà [3,000] jagunjagun tí wọ́n rán lọ kọlu ìlú náà feré gé e nígbà tí wọ́n rí àwọn ìgìrìpá ọkùnrin Áì. Kí nìdí tí wọ́n fi sá? Ìdí ni pé Jèhófà ti kọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ákánì tó jẹ́ ẹ̀yà Júdà dá ẹ̀ṣẹ̀ kan nígbà tí wọ́n lọ kọlu Jẹ́ríkò. Nígbà tí Jóṣúà yanjú ọ̀ràn náà tán, ó múra àtilọ kọlu ìlú Áì. Nítorí pé ọba Áì ti kọ́kọ́ ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó ń hára gàgà láti tún bá wọn jà. Jóṣúà rí i pé àwọn ará ìlú Áì ti dá ara wọn lójú jù, ló bá dá ọgbọ́n kan, ó fi àwọn èèyàn kan sí ibùba, ó tán àwọn ará Áì jáde nílùú ó sì ṣẹ́gun ìlú náà.
Gíbéónì jẹ́ ‘ìlú ńlá kan tí ó tóbi, ó tóbi ju Áì lọ, gbogbo ọkùnrin rẹ̀ sì jẹ́ àwọn alágbára ńlá.’ (Jóṣúà 10:2) Ṣùgbọ́n, nígbà tí àwọn ará Gíbéónì gbọ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun ìlú Jẹ́ríkò àti Áì, wọ́n lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ kí Jóṣúà bàa lè bá wọn dá májẹ̀mú àlàáfíà. Àwọn orílẹ̀-èdè tó múlé gbè wọ́n rí i pé ẹ̀mí àwọn ò dè nítorí ohun tí wọ́n ṣe yìí. Bí márùn-ún lára àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè náà ṣe lẹ̀dí àpò pọ̀ nìyẹn tí wọ́n sì gbógun ti Gíbéónì. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gba àwọn ará Gíbéónì sílẹ̀, wọ́n sì ṣẹ́gun gbogbo àwọn tó wá gbógun tì wọ́n. Àwọn ìlú míì tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun nígbà tí Jóṣúà jẹ́ olórí wọn ni àwọn ìlú tó wà ní gúúsù àti ní ìwọ̀ oòrùn, wọ́n tún ṣẹ́gun àwọn ọba tó lẹ̀dí àpò pọ̀ níhà àríwá. Gbogbo àwọn ọba tí wọ́n ṣẹ́gun níhà ìwọ̀ oòrùn Jọ́dánì jẹ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́:
10:13—Báwo nirú nǹkan yẹn ṣe lè ṣẹlẹ̀? “Ohunkóhun ha ṣe àrà ọ̀tọ̀ jù fún Jèhófà, [Ẹlẹ́dàá ọ̀run òun ayé] bí”? (Jẹ́nẹ́sísì 18:14) Tó bá wu Jèhófà, ó lè yí bí ayé ṣe ń yípo padà táá sì wá dà bí ẹni pé ńṣe ni oòrùn àti òṣùpá dúró sójú kan lójú ọmọ aráyé. Jèhófà sì lè má fọwọ́ kan bí ayé òun òṣùpá ṣe ń yípo kó kàn jẹ́ pé ìtànṣán tó ń tinú oòrùn òun òṣùpá jáde ni Jèhófà máa ṣe nǹkan sí tí ìtànṣán ọ̀hún ò fi ní dáwọ́ dúró. Èyí ó wù kó jẹ́, “kò . . . sí ọjọ́ kankan tí ó tíì dà bí ìyẹn” látọjọ́ táláyé ti dáyé.—Jóṣúà 10:14.
10:13—Ìwé wo ni ìwé Jáṣárì? Bíbélì tún mẹ́nu kan ìwé náà nínú 2 Sámúẹ́lì 1:18 nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa orin ewì kan tí wọ́n ń pè ní “Ọrun,” ìyẹn orin arò tí wọ́n kọ nítorí Sọ́ọ̀lù Ọba Ísírẹ́lì àti Jónátánì ọmọ rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àkópọ̀ àwọn orin àti orin ewì nípa ìtàn àtayébáyé ló wà nínú ìwé náà, ó sì ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ àwọn Hébérù mọ ìwé náà.
Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:
6:26; 9:22, 23. Ègún tí Jóṣúà gún lákòókò ìparun Jẹ́ríkò ṣẹ ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún [500] lẹ́yìn ìgbà yẹn. (1 Àwọn Ọba 16:34) Ègún tí Nóà gún fún Kénáánì ọmọ ọmọ rẹ̀ ló mọ́ ọn nígbà tí àwọn ará Gíbíónì di ẹrú. (Jẹ́nẹ́sísì 9:25, 26) Ọ̀rọ̀ Jèhófà kì í yẹ̀.
7:20-25. Àwọn kan lè máa fojú kékeré wo ẹ̀ṣẹ̀ tí Ákánì dá bóyá kí wọ́n máa sọ pé kò sáà pa ẹnikẹ́ni lára. Wọ́n lè wá máa fi irú ojú kan náà wo kéèyàn máa fẹ́wọ́ tàbí kéèyàn máa ṣe àwọn nǹkan kéékèèké míì tí Bíbélì sọ pé ó lòdì. Ṣùgbọ́n, bíi ti Jóṣúà, ó yẹ kí àwa náà pinnu láti má ṣe ṣe ohun tó lòdì sófin ká mà sí hùwà ìbàjẹ́.
9:15, 26, 27. Ó yẹ ká máa fi ọwọ́ pàtàkì mú àdéhùn tá a bá ṣe ká sì máa mú ìlérí wa ṣẹ.
IṢẸ́ BÀǸTÀBANTA TÍ JÓṢÚÀ ṢE GBẸ̀YÌN
Jóṣúà ti darúgbó wàyí, ó ti ń sún mọ́ àádọ́rùn-ún ọdún, ó sì fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í pín ilẹ̀ náà. Iṣẹ́ kékeré kọ́ niṣẹ́ yìí o! Wọ́n ti kọ́kọ́ fún ẹ̀yà Rúbẹ́nì àti ti Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè ní ilẹ̀ tó wà ní ìlà oòrùn odò Jọ́dánì. Wọ́n wá ṣẹ́ kèké láti fún àwọn ẹ̀yà tó kù ní ogún tiwọn níhà ìwọ̀ oòrùn.
Ṣílò tó wà ní ìpínlẹ̀ àwọn ọmọ Éfúráímù ni wọ́n kọ́ àgọ́ ìjọsìn sí. Kálébù ni wọ́n fún ní ìlú Hébúrónì, Jóṣúà sì gba ìlú Timunati-sérà. Wọ́n fún àwọn ọmọ Léfì ní ìlú méjìdínláàádọ́ta, ìlú mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tó jẹ́ ìlú ààbò sì wà lára wọn. Nígbà táwọn jagunjagun ọmọ Rúbẹ́nì àti ti Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè ń padà sórí ilẹ̀ tí wọ́n jogún ní ìlà oòrùn odò Jọ́dánì, wọ́n tẹ́ pẹpẹ kan tí ó “tóbi lọ́nà tí ó fara hàn gbangba-gbàǹgbà.” (Jóṣúà 22:10) Àwọn ẹ̀yà tó wà níhà ìwọ̀ oòrùn Jọ́dánì kà wọ́n sí apẹ̀yìndà nítorí ohun tí wọ́n ṣe yẹn, díẹ̀ ló sì kù kí ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàárín wọn, ìjà ọ̀hún ì bá sì gbẹ́mìí ọ̀pọ̀ èèyàn, ọpẹ́lọpẹ́ pé wọ́n tètè ṣàlàyé bọ́rọ̀ ṣe jẹ́.
Lẹ́yìn tí Jóṣúà ti gbé nílùú Timunati-sérà fúngbà díẹ̀, ó ní kí àwọn àgbà ọkùnrin, àwọn olórí, àwọn onídàájọ́, àtàwọn olóyè Ísírẹ́lì kóra jọ, ó sì gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n má fòyà kí wọ́n máa bá a lọ láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Ẹ̀yìn ìyẹn ni Jóṣúà wá ní kí gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì pé jọ sí Ṣékémù. Ibẹ̀ ló ti sọ ìtàn nípa bí Jèhófà ṣe ń bá wọn lò bọ̀ látìgbà Ábúráhámù, ó tún gbà wọ́n nímọ̀ràn pé kí wọ́n “bẹ̀rù Jèhófà, kí [wọ́n] sì máa sìn ín ní àìlálèébù àti ní òtítọ́.” Àwọn èèyàn náà sì fèsì pé: “Jèhófà Ọlọ́run wa ni àwa yóò máa sìn, ohùn rẹ̀ sì ni àwa yóò fetí sí!” (Jóṣúà 24:14, 15, 24) Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí, Jóṣúà kú lẹ́ni àádọ́fà [110] ọdún.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́:
13:1—Ǹjẹ́ ohun tí ẹsẹ yìí sọ kò ta ko ohun tó wà nínú Jóṣúà 11:23? Rárá o, kò ta kò ó, nítorí pé ọ̀nà méjì ni wọ́n gbà ṣẹ́gun Ilẹ̀ Ìlérí: Èkíní ni ìjà tí orílẹ̀-èdè náà jà tí wọ́n fi ṣẹ́gun àwọn ọba mọ́kànlélọ́gbọ̀n tí ńbẹ nílẹ̀ Kénáánì tí wọ́n sì ṣẹ́gun àwọn ọmọ Kénáánì. Èkejì ni ìjà tí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan jà àtèyí tí ẹnì kọ̀ọ̀kan jà tí wọ́n fi gba gbogbo ilẹ̀ náà lọ́wọ́ wọn. (Jóṣúà 17:14-18; 18:3) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò lé gbogbo àwọn ọmọ Kénáánì kúrò láàárín wọn tán pátápátá, àwọn tó ṣẹ́ kù ò lè tu irun kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Jóṣúà 16:10; 17:12) Jóṣúà 21:44 sọ pé: “Jèhófà fún wọn ní ìsinmi yí ká.”
24:2—Ṣé abọ̀rìṣà ni Térà, bàbá Ábúráhámù? Térà ò kì í ṣe olùjọsìn Jèhófà ní ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọlọ́run òṣùpá tí wọ́n ń pè ní Sin ló ń jọ́sìn tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ìyẹn òrìṣà kan tó gbajúmọ̀ nílùú Úrì. Gẹ́gẹ́ bí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn ará Júù ṣe fi hàn, ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó jẹ́ pé iṣẹ́ ère gbígbẹ́ ni Térà ń ṣe tẹ́lẹ̀. Àmọ́, nígbà tí Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù pé kó kúrò nílùú Úrì, Térà tẹ̀ lé e lọ sí Háránì.—Jẹ́nẹ́sísì 11:31.
Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:
14:10-13. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni ọdún márùnlélọ́gọ́rin ni Kálébù, síbẹ̀ ó ní kí wọ́n jẹ́ kóun lé àwọn tó ń gbé lágbègbè Hébúrónì kúrò. Àwọn ọmọ Ánákímù tó rí fìrìgbọ̀n ló ń gbé ní gbogbo àgbègbè náà. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, akin ọkùnrin ogún yìí mú gbogbo wọn balẹ̀, Hébúrónì sì di ọ̀kan lára àwọn ìlú ààbò. (Jóṣúà 15:13-19; 21:11-13) Ìṣírí ni ohun tí Kálébù ṣe yìí jẹ́ fún wa pé ká má máa sá fún iṣẹ́ Ọlọ́run tó bá dà bíi pé kò rọrùn láti bójú tó.
22:9-12, 21-33. Ó yẹ ká kíyè sára ká má máa ní ìfura òdì sáwọn èèyàn.
‘Kò Sí Ọ̀rọ̀ Kan Tí Ó Kùnà’
Nígbà tí Jóṣúà ti darúgbó, ó sọ fáwọn ọkùnrin tó jẹ́ aṣáájú ní Ísírẹ́lì pé: “Kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà Ọlọ́run yín sọ fún yín. Gbogbo wọn ti ṣẹ fún yín.” (Jóṣúà 23:14) Ẹ ò rí i pé kedere ni ìtàn inú ìwé Jóṣúà fi èyí hàn!
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ ọ́ pé: “Gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.” (Róòmù 15:4) Ìyẹn fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé ìrètí tá a ní nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run kì yóò já sásán. Kò sí èyí tó máa kùnà nínú ìlérí rẹ̀; gbogbo wọn ló máa ṣẹ pátá.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 10]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Àwọn Ilẹ̀ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà nígbà tí Jóṣúà jẹ́ olórí wọn
BÁṢÁNÌ
GÍLÍÁDÌ
ÁRÁBÀ
NÉGÉBÙ
Odò Jọ́dánì
Òkun Iyọ̀
A.O. ti Jábókù
A.O. ti Áánónì
Hásórì
Mádónì
Lasiṣárónì
Ṣímúrónì
Jókínéámù
Dórì
Mẹ́gídò
Kédéṣì
Táánákì
Héfà
Tírísà
Áfékì
Tápúà
Bẹ́tẹ́lì
Áì
Gílígálì
Jẹ́ríkò
Gésérì
Jerúsálẹ́mù
Mákédà
Jámútì
Ádúlámù
Líbínà
Lákíṣì
Ẹ́gílónì
Hébúrónì
Débírì
Árádì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ǹjẹ́ o mọ ìdí tá a fi pe Ráhábù aṣẹ́wó ní olódodo?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Jóṣúà gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì níyànjú pé kí wọ́n “bẹ̀rù Jèhófà, kí [wọ́n] sì máa sìn ín”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Olè tí Ákánì jà kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ kékeré, àgbákò tó sì fà kì í ṣe kékeré
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
“Nípa ìgbàgbọ́ ni àwọn ògiri Jẹ́ríkò wó lulẹ̀.”—Hébérù 11:30