ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 43
Ẹ Má Ṣe Jẹ́ Kó Rẹ̀ Yín
“Ẹ má ṣe jẹ́ kí a jáwọ́ nínú ṣíṣe rere.”—GÁL. 6:9.
ORIN 68 Máa Fún Irúgbìn Ìjọba Náà
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Àǹfààní ńlá wo la ní?
Ẹ Ò RÍ I pé àǹfààní ńlá la ní bá a ṣe jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn sì ń múnú wa dùn gan-an. Èèyàn Jèhófà ni wá, bá a sì ṣe ń wàásù tá a sì ń kọ́ni ń fi hàn bẹ́ẹ̀. Inú wa máa dùn gan-an tá a bá ran “àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n ń fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun” lọ́wọ́ débi tí wọ́n fi ṣèrìbọmi. (Ìṣe 13:48) Ṣe lọ̀rọ̀ tiwa náà máa dà bíi ti Jésù tó “yọ̀ gidigidi nínú ẹ̀mí mímọ́” nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ dé látibi tí wọ́n ti lọ wàásù.—Lúùkù 10:1, 17, 21.
2. Kí la lè ṣe táá fi hàn pé a fọwọ́ pàtàkì múṣẹ́ ìwàásù wa?
2 Ọwọ́ pàtàkì la fi máa ń mú iṣẹ́ ìwàásù wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tún rọ Tímótì pé: “Máa kíyè sí ara rẹ àti ẹ̀kọ́ rẹ.” Pọ́ọ̀lù wá fi kún un pé: “Tí o bá ń ṣe é, wàá lè gba ara rẹ àti àwọn tó ń fetí sí ọ là.” (1 Tím. 4:16) Ẹ ò rí i pé iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà niṣẹ́ ìwàásù. Torí náà, a máa ń kíyè sí ara wa torí pé ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ni wá. A máa ń ṣe ohun tó ń fògo fún Jèhófà tí ò sì ní ta ko ìhìn rere tá à ń wàásù rẹ̀. (Fílí. 1:27) A máa fi hàn pé à ń ‘kíyè sí ẹ̀kọ́ wa’ tá a bá ń múra òde ẹ̀rí sílẹ̀ dáadáa, tá a sì ń bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká tó lọ wàásù fáwọn èèyàn.
3. Ṣé gbogbo èèyàn ló máa tẹ́tí sí ìhìn rere tá à ń wàásù rẹ̀? Sọ àpẹẹrẹ kan.
3 Bó ti wù ká sapá tó, àwọn èèyàn lè má fẹ́ gbọ́ ìhìn rere tá à ń wàásù rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa. Àpẹẹrẹ kan ni ti Arákùnrin Georg Lindal, tó jẹ́ pé òun nìkan ló wàásù lórílẹ̀-èdè Iceland látọdún 1929 sí 1947. Àìmọye ìwé ló fi síta, síbẹ̀ kò sẹ́nì kankan tó wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ó sọ pé: “Àwọn kan ń ta ko ẹ̀kọ́ òtítọ́, àmọ́ èyí tó pọ̀ jù nínú wọn ni ò tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ Bíbélì rárá.” Kódà, lẹ́yìn táwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì dé orílẹ̀-èdè yẹn, tí wọ́n sì mú kíṣẹ́ ìwàásù túbọ̀ gbòòrò, odindi ọdún mẹ́sàn-án kọjá ká tó ráwọn tó yara wọn sí mímọ́, tí wọ́n sì ṣèrìbọmi.b
4. Báwo ló ṣe máa ń rí lára wa táwọn èèyàn ò bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
4 Inú wa kì í dùn táwọn èèyàn ò bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó lè ṣe wá bíi ti Pọ́ọ̀lù tó “ní ẹ̀dùn ọkàn tó pọ̀ àti ìrora tí kò dáwọ́ dúró” nítorí pé ọ̀pọ̀ àwọn Júù ni ò gbà pé Jésù ni Mèsáyà. (Róòmù 9:1-3) Ká sọ pé o ti sa gbogbo ipá ẹ, o sì ti gbàdúrà nítorí ẹnì kan tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, síbẹ̀ tí ò tẹ̀ síwájú, tó o wá rí i pé ó yẹ kó o dá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà dúró, báwo ló ṣe máa rí lára ẹ? Tó bá jẹ́ pé o ò tíì kọ́ ẹnì kankan lẹ́kọ̀ọ́ débi tó fi ṣèrìbọmi ńkọ́? Ṣé ó yẹ kó o wá máa rò pé Jèhófà ò tíì bù kún iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa dáhùn ìbéèrè méjì: (1) Kí ló ń fi hàn pé a ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa? (2) Kí ló yẹ ká mọ̀ nípa iṣẹ́ ìwàásù wa?
KÍ LÓ Ń FI HÀN PÉ A ṢÀṢEYỌRÍ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ WA?
5. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà niṣẹ́ ìwàásù wa máa ń méso jáde?
5 Bíbélì sọ nípa ẹni tó ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run pé: “Gbogbo ohun tó bá ń ṣe yóò máa yọrí sí rere.” (Sm. 1:3) Àmọ́, ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé gbogbo nǹkan tá a bá ṣe lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ló máa rí bá a ṣe rò. Ìdí sì ni pé ‘wàhálà pọ̀ gan-an’ ní ìgbésí ayé àwa èèyàn torí pé aláìpé ni gbogbo wa. (Jóòbù 14:1) Ìgbà míì sì rèé, àwọn alátakò máa ń fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa. (1 Kọ́r. 16:9; 1 Tẹs. 2:18) Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ni Jèhófà máa fi díwọ̀n bóyá a ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa àbí a ò ṣe bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn ìlànà Bíbélì mélòó kan táá jẹ́ ká lè dáhùn ìbéèrè yẹn.
6. Báwo ni Jèhófà ṣe ń díwọ̀n àṣeyọrí tá a bá ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
6 Iṣẹ́ àṣekára àti ìfaradà wa ni Jèhófà máa ń wò. Bá a ṣe ṣiṣẹ́ kára lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ló fi ń díwọ̀n àṣeyọrí wa, kì í ṣe bóyá àwọn èèyàn gbọ́ wa tàbí wọn ò gbọ́. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tó fi máa gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀ bí ẹ ṣe ń ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́, tí ẹ sì ń bá a lọ láti ṣe ìránṣẹ́.” (Héb. 6:10) Jèhófà ò gbàgbé iṣẹ́ àṣekára wa àti ìfẹ́ tá a ní fún un kódà bí ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ò bá tiẹ̀ ṣèrìbọmi. Torí náà, ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ará Kọ́ríńtì máa fún ẹ ní ìṣírí, ó ní: “Làálàá yín kò ní já sí asán nínú Olúwa” bóyá iṣẹ́ àṣekára wa méso jáde tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.—1 Kọ́r. 15:58.
7. Kí la rí kọ́ nínú ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa iṣẹ́ ìwàásù tó ṣe?
7 Míṣọ́nnárì tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù torí ọ̀pọ̀ ìlú ló ti dá ìjọ sílẹ̀. Síbẹ̀, nígbà tó rí i pé ó yẹ kóun fi hàn pé òun jẹ́ òjíṣẹ́ Kristi tó kúnjú ìwọ̀n, kò bẹ̀rẹ̀ sí í sọ iye àwọn tó ti sọ di ọmọ ẹ̀yìn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló pa àwọn agbéraga tó ń ṣàríwísí rẹ̀ lẹ́nu mọ́, ó ní: “Mo ti ṣiṣẹ́ jù wọ́n lọ.” (2 Kọ́r. 11:23) Bíi ti Pọ́ọ̀lù, ẹ jẹ́ ká máa rántí pé iṣẹ́ àṣekára àti ìfaradà wa ni Jèhófà ń wò.
8. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù wa?
8 Inú Jèhófà máa ń dùn sí iṣẹ́ ìwàásù wa. Nígbà tí Jésù rán àádọ́rin (70) lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ jáde lọ wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, Bíbélì sọ pé wọ́n “pa dà dé tayọ̀tayọ̀” lẹ́yìn tí wọ́n parí iṣẹ́ náà. Kí ló mú kí wọ́n láyọ̀? Wọ́n sọ pé: “Àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá tẹrí ba fún wa torí pé a lo orúkọ rẹ.” Àmọ́, Jésù tún èrò wọn ṣe, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ má yọ̀ torí pé a mú kí àwọn ẹ̀mí tẹrí ba fún yín, àmọ́ ẹ yọ̀ torí pé a ti kọ orúkọ yín sílẹ̀ ní ọ̀run.” (Lúùkù 10:17-20) Jésù mọ̀ pé ìgbà gbogbo kọ́ làwọn ọmọ ẹ̀yìn òun á máa ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Kódà, a ò mọ iye àwọn tó di onígbàgbọ́ lára àwọn tó kọ́kọ́ gbọ́ ìwàásù àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Torí náà, kì í ṣe àṣeyọrí táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe nìkan ló yẹ kó máa fún wọn láyọ̀. Wọ́n á tún láyọ̀ tí wọ́n bá fi sọ́kàn pé inú Jèhófà ń dùn sí iṣẹ́ àṣekára àwọn.
9. Bí Gálátíà 6:7-9 ṣe sọ, kí la máa rí tá a bá ń fara dà á lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa?
9 Tá a bá ń fara dà á lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa, á máa jèrè ìyè àìnípẹ̀kun. Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni, ńṣe là “ń fúnrúgbìn nítorí ẹ̀mí” torí à ń jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run darí wa. Jèhófà sì ti mú kó dá wa lójú pé tá ò bá “jáwọ́” tá ò sì “jẹ́ kó rẹ̀ wá,” a máa jèrè ìyè àìnípẹ̀kun, kódà tá ò bá tiẹ̀ ran ẹnì kankan lọ́wọ́ débi tó fi ṣèrìbọmi.—Ka Gálátíà 6:7-9.
KÍ LÓ YẸ KÁ MỌ̀ NÍPA IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ WA?
10. Kí ló máa ń jẹ́ káwọn kan tẹ́tí sí wa, àmọ́ tí ò kì í jẹ́ káwọn míì ṣe bẹ́ẹ̀?
10 Àwọn èèyàn fúnra wọn ló máa pinnu bóyá àwọn fẹ́ gbọ́ tàbí àwọn ò ní gbọ́. Àpèjúwe afúnrúgbìn kan tí Jésù sọ ló jẹ́ ká mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ lọ́rọ̀ rí. Afúnrúgbìn náà fún irúgbìn sórí ilẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àmọ́ ilẹ̀ kan ṣoṣo ló méso jáde (Lúùkù 8:5-8) Jésù sọ pé ilẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ yẹn ṣàpẹẹrẹ ọ̀nà tí kálukú gbà tẹ́wọ́ gba “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” (Lúùkù 8:11-15) Bíi ti afúnrúgbìn yẹn, kò sí lọ́wọ́ wa láti díwọ̀n bí iṣẹ́ ìwàásù wa ṣe máa méso jáde torí pé ọwọ́ ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló wà. Iṣẹ́ tiwa ni pé ká máa wàásù ìhìn rere Ìjọba náà. Bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe sọ, “ẹnì kọ̀ọ̀kan máa gba èrè iṣẹ́ tirẹ̀,” kì í ṣe àṣeyọrí tó bá ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ló máa fi gba èrè náà.—1 Kọ́r. 3:8.
11. Àṣeyọrí wo ni Nóà tó jẹ́ “oníwàásù òdodo” ṣe? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)
11 Nígbà àtijọ́, àwọn èèyàn ò fẹ́ gbọ́ ìwàásù àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, Nóà jẹ́ “oníwàásù òdodo,” ọ̀pọ̀ ọdún ló sì fi wàásù. (2 Pét. 2:5) Ó dájú pé ó retí káwọn èèyàn tẹ́tí gbọ́ ìwàásù òun, àmọ́ Jèhófà ò sọ pé àwọn èèyàn máa gbọ́ tàbí wọn ò ní gbọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tí Ọlọ́run sọ fún Nóà nípa bó ṣe máa kan ọkọ̀ áàkì, ohun tó sọ ni pé: “Kí o wọ inú áàkì náà, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ àti ìyàwó rẹ pẹ̀lú ìyàwó àwọn ọmọ rẹ.” (Jẹ́n. 6:18) Ọkọ̀ tí Ọlọ́run ní kí Nóà kàn kò fi bẹ́ẹ̀ tóbi, kò sì lè gba èèyàn púpọ̀. Torí náà, ó ṣeé ṣe kí Nóà rò pé àwọn èèyàn tó máa gbọ́ ìwàásù òun ò ní pọ̀. (Jẹ́n. 6:15) Bá a sì ṣe mọ̀, kò sẹ́nì kankan nínú ayé ìgbà yẹn tó gbọ́ ìwàásù Nóà. (Jẹ́n. 7:7) Ṣé Jèhófà wá sọ pé Nóà ò ṣàṣeyọrí? Rárá o! Lójú Ọlọ́run, Nóà ṣàṣeyọrí, inú Jèhófà sì dùn sí i torí ó ṣiṣẹ́ náà tọkàntọkàn.—Jẹ́n. 6:22.
12. Kí ló mú kí wòlíì Jeremáyà máa láyọ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ò fẹ́ gbọ́rọ̀ ẹ̀ tí wọ́n sì ń ta kò ó?
12 Bíi ti Nóà, ọ̀pọ̀ ọdún ni wòlíì Jeremáyà fi wàásù fáwọn èèyàn tí ò fẹ́ gbọ́rọ̀ rẹ̀, tí wọ́n sì tún ń ta kò ó. Ìrẹ̀wẹ̀sì bá a nítorí “èébú àti yẹ̀yẹ́” látọ̀dọ̀ àwọn alátakò rẹ̀, ó sì rò pé òun ò ní lè ṣiṣẹ́ ìwàásù mọ́. (Jer. 20:8, 9) Àmọ́, Jeremáyà ò jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì mú òun! Kí ló jẹ́ kó borí èrò tí ò dáa tó ní, tó sì ń láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀? Ohun pàtàkì méjì ló ràn án lọ́wọ́. Àkọ́kọ́, iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán Jeremáyà sí àwọn èèyàn jẹ́ kí wọ́n ní “ìrètí” pé “ọjọ́ ọ̀la” máa dáa. (Jer. 29:11) Ìkejì, Jèhófà ti yan Jeremáyà láti máa sọ̀rọ̀ nípa orúkọ òun. (Jer. 15:16) Àwa náà ń wàásù fáwọn èèyàn pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa, a sì tún jẹ́ Ẹlẹ́rìí tó ń wàásù orúkọ rẹ̀. Tá a bá gbájú mọ́ ohun pàtàkì méjì yìí, àá máa láyọ̀ bóyá àwọn èèyàn gbọ́ wa tàbí wọn ò gbọ́.
13. Kí la rí kọ́ nínú àpèjúwe Jésù tó wà ní Máàkù 4:26-29?
13 Ó máa ń gba àkókò kéèyàn tó nígbàgbọ́ tó lágbára. Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí nínú àpèjúwe afúnrúgbìn kan tó sùn lẹ́yìn tó fúnrúgbìn. (Ka Máàkù 4:26-29.) Nígbà tó yá, irúgbìn náà bẹ̀rẹ̀ sí í dàgbà díẹ̀díẹ̀, àmọ́ kò sí ohun tó lè ṣe láti mú kí irúgbìn náà yára dàgbà. Iṣẹ́ ìwàásù tiwa náà lè má tètè so èso rere torí pé ó lè gba àkókò kí ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ṣe àwọn àyípadà tó yẹ. Bí àgbẹ̀ yẹn ò ṣe lè fipá mú kí irúgbìn náà tètè dàgbà bó ṣe fẹ́, bẹ́ẹ̀ náà la ò lè fipá mú àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti tètè tẹ̀ síwájú bá a ṣe fẹ́. Torí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì mú yín tẹ́ ẹ bá rí i pé wọn ò tètè tẹ̀ síwájú. Bí iṣẹ́ àgbẹ̀ ṣe gba sùúrù, bẹ́ẹ̀ náà ni iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn gba sùúrù.—Jém. 5:7, 8.
14. Àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé díẹ̀díẹ̀ ni iṣẹ́ ìwàásù wa máa so èso rere?
14 Láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù kan, ó lè gba ọ̀pọ̀ ọdún kí ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ṣèrìbọmi. Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí tẹ̀gbọ́n-tàbúrò kan tó ń jẹ́ Gladys àti Ruby Allen. Lọ́dún 1959, ètò Ọlọ́run ní kí wọ́n lọ ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé nílùú kan lágbègbè Quebec, lórílẹ̀-èdè Kánádà.c Àwọn ará ìlú náà ò gbọ́ ìwàásù wa torí wọ́n ń bẹ̀rù ohun táwọn èèyàn máa sọ àtohun tí àlùfáà Kátólíìkì máa ṣe. Gladys sọ pé: “Wákàtí mẹ́jọ la fi ń lọ láti ilé dé ilé lójoojúmọ́ fún odindi ọdún méjì gbáko láìsí ẹnì kankan tó dá wa lóhùn! Ńṣe làwọn èèyàn náà máa ń yọjú wò wá lẹ́nu ọ̀nà, tí wọ́n á sì pa dà. Àmọ́, a ò juwọ́ sílẹ̀.” Nígbà tó yá, ìwà àwọn èèyàn náà yí pa dà, ọ̀pọ̀ lára wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ ìwàásù. Ní báyìí, ìjọ mẹ́ta ti wà nílùú yẹn.—Àìsá. 60:22.
15. Kí ni 1 Kọ́ríńtì 3:6, 7 kọ́ wa nípa iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn?
15 Iṣẹ́ gbogbo wa ni iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn. Iṣẹ́ gbogbo àwa tá a wà nínú ìjọ ni láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ títí wọ́n á fi ṣèrìbọmi. (Ka 1 Kọ́ríńtì 3:6, 7.) Ká sọ pé arákùnrin kan fún ẹnì kan tó fìfẹ́ hàn ní ìwé ìròyìn tàbí ìwé àṣàrò kúkúrú kan. Àmọ́ ó rí i pé òun ò ní lè pa dà lọ sọ́dọ̀ ẹni tó fìfẹ́ hàn náà, ó wá sọ fún arákùnrin míì pé kó pa dà lọ bẹ ẹni náà wò. Arákùnrin tó pa dà lọ yẹn bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ẹni náà. Ó wá mú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ sọ́dọ̀ ẹni tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ará náà ló sì fún akẹ́kọ̀ọ́ yẹn níṣìírí. Gbogbo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó lọ sọ́dọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ náà ló máa ràn án lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú. Torí náà, afúnrúgbìn àti olùkórè máa yọ̀ pa pọ̀ tí akẹ́kọ̀ọ́ náà bá ṣèrìbọmi.—Jòh. 4:35-38.
16. Kí lá jẹ́ kó o ṣì máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù rẹ bí ara rẹ ò bá le bíi ti tẹ́lẹ̀ tàbí tó ò lókun mọ́?
16 Tó ò bá lè wàásù bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́ nítorí àìsàn ńkọ́? O ṣì lè máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ọba Dáfídì àtàwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú ẹ̀ lọ gba ìdílé wọn àtàwọn ẹrù wọn lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ámálékì. Ó ti rẹ ọgọ́rùn-ún méjì (200) lára àwọn ọkùnrin náà débi pé wọn ò lè jà mọ́, torí náà àwọn ni wọ́n dúró ti ẹrù. Lẹ́yìn tí wọ́n ṣẹ́gun, Dáfídì pàṣẹ pé kí wọ́n pín ẹrù tí wọ́n kó bọ̀ látojú ogun lọ́gbọọgba. (1 Sám. 30:21-25) Bí iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn tá à ń ṣe kárí ayé ṣe rí náà nìyẹn. Lóòótọ́, o lè má lè ṣe bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́ lẹ́nu iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn. Àmọ́ tó o bá ń ṣe gbogbo ohun tágbára ẹ gbé, inú ẹ á máa dùn ní gbogbo ìgbà tí ẹnì kan bá ṣèrìbọmi.
17. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà?
17 À ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí ó ń fìfẹ́ tẹ́wọ́ gba gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Ó mọ̀ pé a ò lè fipá mú àwọn èèyàn láti wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Síbẹ̀, ó ń kíyè sí gbogbo ohun tá à ń ṣe, ó sì ń bù kún wa. Ó tún ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè láyọ̀ bá a ṣe ń ṣe ipa tiwa lẹ́nu iṣẹ́ ìkórè yìí. (Jòh. 14:12) Torí náà, ó dájú pé tá ò bá jáwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ yìí, tá a sì ń ṣe gbogbo ohun tágbára wa gbé, inú Jèhófà máa dùn sí wa!
ORIN 67 Wàásù Ọ̀rọ̀ Náà
a Inú wa máa ń dùn táwọn èèyàn bá gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ inú wa kì í dùn tí wọn ò bá ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n, tẹ́ni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ò bá tẹ̀ síwájú ńkọ́? Tó bá sì jẹ́ pé o ò tíì kọ́ ẹnì kankan lẹ́kọ̀ọ́ débi tó fi ṣèrìbọmi ńkọ́? Ṣé ó wá yẹ kó o máa ronú pé iṣẹ́ ìwàásù ẹ ò méso jáde? Torí náà, nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí àwọn ohun tá a lè ṣe kí iṣẹ́ ìwàásù wa lè méso jáde àti bá a ṣe lè máa láyọ̀ báwọn èèyàn ò tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ tẹ́tí sí wa.
b Wo Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ọdún 2005, ojú ìwé 205 sí 211 lédè Gẹ̀ẹ́sì.
c Wo ìtàn ìgbésí ayé Gladys Allen, “Mi Ò Ní Yí Ohunkóhun Padà!” nínú Ilé Ìṣọ́ September 1, 2002.