Jèhófà Ni Ìpín Mi
“Èmi ni ìpín rẹ àti ogún rẹ láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”—NÚM. 18:20.
1, 2. (a) Nígbà tí Jóṣúà pín ilẹ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù, kí ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹ̀yà Léfì? (b) Kí ni Jèhófà mú kó dá àwọn ọmọ Léfì lójú?
LẸ́YÌN tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ṣẹ́gun èyí tó pọ̀ jù lọ lára Ilẹ̀ Ìlérí, Jóṣúà wá bẹ̀rẹ̀ sí í pín ilẹ̀ náà nípa ṣíṣẹ́ kèké lé e. Òun àti Élíásárì, Àlùfáà Àgbà àti àwọn olórí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ni wọ́n jọ ṣiṣẹ́ náà. (Núm. 34:13-29) Àmọ́ àwọn ọmọ Léfì kò ní rí ogún ilẹ̀ gbà bíi tàwọn ẹ̀yà yòókù. (Jóṣ. 14:1-5) Kí nìdí tí àwọn ọmọ Léfì kò fi ní ìpínlẹ̀ tàbí ìpín tó jẹ́ ti ẹ̀yà wọn, lára Ilẹ̀ Ìlérí náà? Ṣé wọ́n gbàgbé wọn ni?
2 A rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí nínú ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún àwọn ọmọ Léfì. Jèhófà fi hàn pé òun kò pa wọ́n tì nígbà tó sọ pé: “Èmi ni ìpín rẹ àti ogún rẹ láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.” (Núm. 18:20) Gbólóhùn náà, “èmi ni ìpín rẹ” mà fini lọ́kàn balẹ̀ o! Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ bí Jèhófà bá sọ bẹ́ẹ̀ fún ẹ? Ó ṣeé ṣe kó o kọ́kọ́ bi ara rẹ pé, ‘Ṣé mo yẹ lẹ́ni tó yẹ kí Olódùmarè fi irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ dá lójú?’ O tún lè ṣe kàyéfì pé, ‘Ṣé òótọ́ ni Jèhófà lè jẹ́ ìpín Kristẹni èyíkéyìí tó jẹ́ aláìpé lónìí?’ Àwọn ìbéèrè yìí kan ìwọ àtàwọn ìbátan rẹ. Torí náà, jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ yìí. Èyí máa jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe lè jẹ́ ìpín àwọn Kristẹni lónìí. Lọ́nà tó túbọ̀ ṣe tààràtà, ó lè jẹ́ ìpín rẹ, yálà o nírètí láti gbé ní ọ̀run tàbí ò ń fojú sọ́nà láti gbé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé.
Jèhófà Ń Pèsè Fáwọn Ọmọ Léfì
3. Kí ló mú kí Ọlọ́run ya àwọn ọmọ Léfì sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìsìn rẹ̀?
3 Ṣáájú kí Jèhófà tó fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Òfin, àwọn olórí ìdílé ló máa ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà láàárín wọn. Nígbà tí Ọlọ́run sì fún wọn ní Òfin, ó ṣètò pé kí àwọn kan lára ẹ̀yà Léfì máa fi iṣẹ́ àlùfáà ṣe iṣẹ́ ṣe, ó sì yan àwọn míì látinú ẹ̀yà kan náà láti máa ràn wọ́n lọ́wọ́. Báwo lọ̀rọ̀ ṣe rí bẹ́ẹ̀? Nígbà tí Ọlọ́run pa àwọn àkọ́bí run ní Íjíbítì, ó ya àwọn àkọ́bí Ísírẹ́lì sí mímọ́, ó sì yà wọ́n sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun ìní rẹ̀. Lẹ́yìn náà ni Ọlọrun ṣe ìyípadà pàtàkì yìí pé: “Èmi mú àwọn ọmọ Léfì . . . dípò gbogbo àkọ́bí . . . nínú àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì.” Níwọ̀n bó ti ṣe kedere pé àwọn àkọ́bí nínú àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì pọ̀ ju àwọn ọmọ Léfì lọ, wọ́n san owó ìràpadà dípò iye tí wọ́n fi lé sí àwọn ọmọ Léfì. (Núm. 3:11-13, 41, 46, 47) Nípa báyìí, ó ṣeé ṣe fún àwọn ọmọ Léfì láti máa ṣe ojúṣe wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run Ísírẹ́lì.
4, 5. (a) Kí ló túmọ̀ sí fún àwọn ọmọ Léfì láti ní Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn? (b) Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń pèsè ohun táwọn ọmọ Léfì nílò fún wọn?
4 Kí ni iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé àwọn ọmọ Léfì lọ́wọ́ túmọ̀ sí? Jèhófà sọ pé òun máa jẹ́ ìpín wọn ní ti pé dípò kí wọ́n gba ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ogún, Ọlọ́run fi àǹfààní iyebíye lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ jíǹkí wọn. ‘Iṣẹ́ àlùfáà tí Jèhófà’ gbé lé wọn lọ́wọ́ ni ogún tiwọn. (Jóṣ. 18:7) Nínú Númérì orí 18, àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣáájú ẹsẹ 20 àti èyí tó tẹ̀ lé e fi hàn pé èyí kò sọ wọ́n di òtòṣì nípa tara. (Ka Númérì 18:19, 21, 24.) Wọ́n gbọ́dọ̀ máa fún àwọn ọmọ Léfì ní “gbogbo ìdá mẹ́wàá ní Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ogún ní ìdápadà fún iṣẹ́ ìsìn wọn.” Wọ́n máa gba ìdá mẹ́wàá lára àwọn irè oko àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti ti àwọn àgùntàn wọn tó ń bí sí i. Àwọn ọmọ Léfì pẹ̀lú sì ní láti san ìdá mẹ́wàá lára ohun tí wọ́n bá rí gbà, “èyí tí ó dára jù lọ nínú rẹ̀,” láti ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ àlùfáà tí wọ́n ń ṣe.a (Núm. 18:25-29) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún máa ń kó “gbogbo ọrẹ mímọ́” tí wọ́n bá mú wá fún Ọlọ́run níbi ìjọsìn rẹ̀ fáwọn àlùfáà. Nípa báyìí àwọn tó jẹ́ àlùfáà ní ìdí pàtàkì láti gbà gbọ́ pé Jèhófà máa pèsè ohun tí wọ́n nílò fún wọn.
5 Ó dà bíi pé nínú Òfin Mósè, ètò tún wà fún oríṣi ìdá mẹ́wàá kejì, èyí tí ọmọ Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan yóò yà sọ́tọ̀ fún jíjẹ, mímu àti pípèsè ìgbádùn fún agbo ilé rẹ̀ níbi àwọn àpéjọ mímọ́ tí wọ́n máa ń lọ lọ́dọọdún. (Diu. 14:22-27) Àmọ́ ṣá o, ní òpin ọdún kẹta àti ìkẹfà láàárín ọdún méje tó jẹ́ ọdún sábáàtì, wọ́n máa mú ìdá mẹ́wàá yìí lọ sí ẹnubodè fún àǹfààní àwọn òtòṣì àti ti àwọn ọmọ Léfì. Kí nìdí tí wọ́n fi ka àwọn ọmọ Léfì mọ́ àwọn tó máa jàǹfààní ètò yìí? Ìdí ni pé wọn kò “ní ìpín tàbí ogún kankan” ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì.—Diu. 14:28, 29.
6. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Léfì kò ní ilẹ̀ kankan gẹ́gẹ́ bí ogún ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ibo ni wọn yóò máa gbé?
6 O lè máa wá ronú pé, ‘Bí Ọlọ́run kò bá ya ilẹ̀ kankan sọ́tọ̀ fún àwọn ọmọ Léfì, ibo ni wọn yóò máa gbé?’ Ọlọ́run pèsè fún wọn. Ó fún wọn ní àwọn ìlú méjìdínláàádọ́ta [48] àtàwọn ilẹ̀ ìjẹko tó yí àwọn ìlú náà ká. Lára wọn ni àwọn ìlú ńlá mẹ́fà tó wà fún ìsádi. (Núm. 35:6-8) Nípa báyìí, àwọn ọmọ Léfì ní ibi tí wọ́n lè gbé nígbà tí wọn kò bá sìn ní ibi mímọ́ Ọlọ́run. Jèhófà pèsè lọ́pọ̀ yanturu fún àwọn tó bá fi ara wọn fún iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Ó ṣe kedere nígbà náà pé àwọn ọmọ Léfì lè fi hàn pé Jèhófà ni ìpín àwọn nípa níní ìgbọ́kànlé nínú rẹ̀ pé ó fẹ́ láti pèsè fún àwọn, ó sì lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀.
7. Kí ni àwọn ọmọ Léfì gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n lè ní Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn?
7 Òfin kò sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ọmọ Ísírẹ́lì tó bá kọ̀ láti san ìdámẹ́wàá. Àmọ́ nígbà táwọn èèyàn kò fọwọ́ tó ṣe pàtàkì mú sísan ìdámẹ́wàá, àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì mọ̀ ọ́n lára. Èyí ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Nehemáyà. Torí náà, àwọn ọmọ Léfì pa iṣẹ́ ìsìn wọn tì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ ṣiṣẹ́ nínú àwọn pápá wọn. (Ka Nehemáyà 13:10.) Ó ṣe kedere nígbà náà pé, bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ń pa Òfin Ọlọ́run mọ́ nìkan làwọn tó wà nínú ẹ̀yà Léfì á fi lè máa gbọ́ bùkátà ara wọn. Àwọn àlùfáà àtàwọn ọmọ Léfì pẹ̀lú sì gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà àti ètò tó ṣe láti máa pèsè fún wọn.
Àwọn Ọmọ Léfì Lẹ́nì Kọ̀ọ̀kan Ní Jèhófà Gẹ́gẹ́ bí Ìpín Wọn
8. Ṣàlàyé wàhálà tó bá ọmọ Léfì kan tó ń jẹ́ Ásáfù.
8 Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà kan, àwọn ọmọ Léfì ní Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn. Àmọ́, ó gbàfiyèsí pé àwọn kan lára àwọn ọmọ Léfì lo gbólóhùn náà, “Jèhófà ni ìpín mi” láti fi ìfọkànsin wọn fún Ọlọ́run hàn, kí wọ́n sì tún fi hàn pé àwọn gbẹ́kẹ̀ lé e. (Ìdárò 3:24) Ọ̀kan lára irú àwọn ọmọ Léfì bẹ́ẹ̀ jẹ́ akọrin. A máa pè é ní Ásáfù, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ẹnì kan tó wá láti ìdílé Ásáfù, ìyẹn ọmọ Léfì tó jẹ́ aṣáájú àwọn akọrin nígbà ayé Dáfídì Ọba. (1 Kíró. 6:31-43) Nínú Sáàmù 73, a kà pé ìdààmú bá Ásáfù (tàbí ọ̀kan lára àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀). Ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìlara àwọn ẹni búburú tí wọ́n láásìkí, débi tó fi sọ pé: “Dájúdájú, lásán ni mo wẹ ọkàn-àyà mi mọ́, tí mo sì wẹ ọwọ́ mi ní àìmọwọ́mẹsẹ̀.” Ó ṣe kedere pé ó ti gbàgbé àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó ní; ó sì kùnà láti mọyì bí Jèhófà ṣe jẹ́ ìpín rẹ̀. Ohun tó rí náà kó ìdààmú ọkàn bá a “títí [tó] fi wá sínú ibùjọsìn títóbi lọ́lá ti Ọlọ́run.”—Sm. 73:2, 3, 12, 13, 17.
9, 10. Kí nìdí tí Ásáfù fi lè sọ pé Ọlọ́run jẹ́ “ìpín [òun] fún àkókò tí ó lọ kánrin”?
9 Nígbà tí Ásáfù dénú ibùjọsìn, ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi ojú tí Ọlọ́run fi ń wo nǹkan wò ó. Bóyá ohun tó jọ èyí ti ṣẹlẹ̀ sí ìwọ náà rí. Bóyá ó ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí pé o kò fi bẹ́ẹ̀ ka àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó o ní sí pàtàkì, tó o sì wá jẹ́ kí àwọn nǹkan tara tí o kò ní gbà ẹ́ lọ́kàn. Àmọ́ bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó o sì ń lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni, o wá bẹ̀rẹ̀ sí í rí àwọn nǹkan lọ́nà tí Jèhófà ń gbà wò wọ́n. Ásáfù mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹni ibi nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Ó ronú nípa àǹfààní tó ní láti máa sin Jèhófà, ó sì mọ̀ dájú pé Jèhófà máa gbá ọwọ́ ọ̀tún òun mú yóò si darí òun. Torí náà, Ásáfù sọ fún Jèhófà pé: “Yàtọ̀ sí ìwọ, èmi kò ní inú dídùn mìíràn lórí ilẹ̀ ayé.” (Sm. 73:23, 25) Lẹ́yìn náà ló wá pe Ọlọ́run ní ìpín rẹ̀. (Ka Sáàmù 73:26.) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ‘ẹ̀yà ara àti ọkàn-àyà’ onísáàmù náà lè “kọṣẹ́,” Ọlọ́run máa jẹ́ ‘ìpín rẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin.’ Ó dá onísáàmù náà lójú pé Jèhófà máa ka òun sí ọ̀rẹ́ rẹ̀, á sì rántí òun. Jèhófà kò ní gbàgbé pé onísáàmù náà fòótọ́ inú sin òun. (Oníw. 7:1) Ẹ sì wo bí ìyẹn á ṣe mú Ásáfù lọ́kàn le tó! Ó kọrin pé: “Ní tèmi, sísúnmọ́ Ọlọ́run dára fún mi. Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ni mo fi ṣe ibi ìsádi mi.”—Sm. 73:28.
10 Bí Jèhófà ṣe jẹ́ ìpín Ásáfù ṣe pàtàkì fún un ju àwọn ohun ìgbẹ́mìíró tó ń rí gbà gẹ́gẹ́ bí ọmọ Léfì lọ. Ohun tó sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ni àǹfààní tó ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run àti àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà, ìyẹn bó ṣe jẹ́ ọ̀rẹ́ Ẹni Gíga Jù Lọ. (Ják. 2:21-23) Kí àjọṣe yẹn má bàa bà jẹ́, onísáàmù náà gbọ́dọ̀ máa sọ ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Jèhófà dọ̀tun kó sì máa gbẹ́kẹ̀ lé e. Ásáfù gbọ́dọ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ibi tó dáa ni ìgbésí ayé òun máa já sí bóun bá ń gbé ìgbé ayé òun ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Ọlọ́run. Ìwọ náà lè ní irú ìgbọ́kànlé bẹ́ẹ̀ nínú Olódùmarè.
11. Kí ni Jeremáyà béèrè, báwo ló sì ṣe rí ìdáhùn sí ìbéèrè rẹ̀?
11 Wòlíì Jeremáyà ni ọmọ Léfì mìíràn tó gbà pé ‘Jèhófà jẹ́ ìpín òun.’ Ẹ jẹ́ ká ṣe àgbéyẹ̀wò ohun tó fà á tó fi lo gbólóhùn yẹn. Jeremáyà ń gbé ní ìlú Ánátótì, ìyẹn ìlú àwọn ọmọ Léfì kan tó wà lẹ́bàá Jerúsálẹ́mù. (Jer. 1:1) Ó nígbà kan tí nǹkan tojú sú Jeremáyà, tó sì béèrè pé: Kí nìdí táwọn èèyàn búburú fi ń láásìkí tí ìyà sì ń jẹ olódodo? (Jer. 12:1) Lẹ́yìn tó ti kíyè sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù àti Júdà, ara rẹ̀ kò gbà á mọ́, ó mú “ẹjọ́” ohun tó rí wá síwájú Ọlọ́run. Jeremáyà mọ̀ pé olódodo ni Jèhófà. Ohun tí Jèhófà mí sí Jeremáyà láti kọ lẹ́yìn ìgbà yẹn àti bí Ọlọ́run ṣe mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ṣẹ pèsè ìdáhùn tí kò ṣeé já ní koro sí ìbéèrè wòlíì náà. Ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run, àwọn tó tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà ‘rí ọkàn wọn gbà gẹ́gẹ́ bí ohun ìfiṣèjẹ,’ àmọ́ àwọn ẹni burúkú tó láásìkí kò tẹ́tí sí ìkìlọ̀ Ọlọ́run wọ́n sì ṣègbé.—Jer. 21:9.
12, 13. (a) Kí ló mú kí Jeremáyà polongo pé: “Jèhófà ni ìpín mi,” irú ẹ̀mí wo ló sì ní? (b) Kí nìdí tí gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì fi gbọ́dọ̀ ní ẹ̀mí ìdúródeni?
12 Lẹ́yìn náà, nígbà tí Jeremáyà bojú wo ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ tó ti dahoro, ńṣe ló dà bíi pé ó ń rìn nínú òkùnkùn. Ó wá jọ pé Jèhófà ti mú kó “jókòó . . . bí àwọn ènìyàn tí ó ti kú tipẹ́tipẹ́.” (Ìdárò 1:1, 16; 3:6) Jeremáyà ti sọ fún orílẹ̀-èdè alágídí náà pé kí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ Baba wọn ọ̀run, àmọ́ ìwà wọn ti burú débi pé Jèhófà pa Jerúsálẹ́mù àti Júdà run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jeremáyà kọ́ ló lẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà, èyí bà á lọ́kàn jẹ́. Àmọ́, bí ọ̀rọ̀ yìí ṣe ba wòlíì yìí lọ́kàn jẹ́ tó, ó rántí bí Ọlọ́run ṣe fi ọ̀pọ̀ àánú hàn. Ó sọ pé Jèhófà ni kò jẹ́ kí “a wá sí òpin wa.” Dájúdájú, Jèhófà máa ń sọ àánú rẹ̀ dọ̀tun ní òròòwúrọ̀! Lẹ́yìn náà ni Jeremáyà wa polongo pé: “Jèhófà ni ìpín mi.” Ó láǹfààní láti máa bá a nìṣó ní sísin Jèhófà gẹ́gẹ́ bíi wòlíì.—Ka Ìdárò 3:22-24.
13 Fún àádọ́rin [70] ọdún, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò ní ní ìlú ìbílẹ̀ rárá. Ìlú wọn á dahoro. (Jer. 25:11) Àmọ́ ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà sọ pé “Jèhófà ni ìpín mi” fi hàn pé ó dá a lójú pé Jèhófà máa fi àánú hàn, ìyẹn sì mú kó rí ìdí tó fi gbọ́dọ̀ ní “ẹ̀mí ìdúródeni.” Gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì máa pàdánù ogún wọn, torí náà, ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n ní irú ẹ̀mí tí wòlíì náà ní. Jèhófà nìkan ṣoṣo ló lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Lẹ́yìn àádọ́rin [70] ọdún, àwọn èèyàn Ọlọ́run pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn, wọ́n sì ní àǹfààní láti máa sìn ín níbẹ̀.—2 Kíró. 36:20-23.
Àwọn Mìíràn Lè Ní Jèhófà Gẹ́gẹ́ bí Ìpín Wọn
14, 15. Yàtọ̀ sí àwọn ọmọ Léfì, ta ló tún jẹ́ kí Jèhófà jẹ́ ìpín òun, kí sì nìdí?
14 Ẹ̀yà Léfì ni Ásáfù àti Jeremáyà ti wá, àmọ́ ṣé àwọn ọmọ Léfì nìkan ló lè ní àǹfààní láti máa sin Jèhófà? Ó tì o! Nígbà tí Dáfídì tó máa jẹ́ ọba fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì wà lọ́dọ̀ọ́, ó pe Ọlọ́run ní “ìpín mi ní ilẹ̀ àwọn alààyè.” (Ka Sáàmù 142:1, 5.) Ní àsìkò tí Dáfídì kọ sáàmù yìí, kò sí nínú ààfin tàbí nínú ilé. Inú hòrò, ìyẹn ihò inú àpáta tàbí ti abẹ́ ilẹ̀, níbi tó fara pa mọ́ sí torí àwọn ọ̀tá rẹ̀ ló wà. Ó kéré tán, ìgbà méjì ni Dáfídì fara pa mọ́ sínú hòrò, ọ̀kan nítòsí ìlú Ádúlámù àti èkejì ní aginjù Ẹ́ń-gédì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé inú ọ̀kan lára àwọn hòrò wọ̀nyẹn ló ti kọ Sáàmù ìkejìlélógóje [142].
15 Bó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, a jẹ́ pé Sọ́ọ̀lù Ọba ló ń lépa Dáfídì, tó sì ń wá bó ṣe máa gbẹ̀mí ẹ̀. Dáfídì sá lọ sínú hòrò tó ṣòro láti dé. (1 Sám. 22:1, 4) Ní ìbí àdádó tí Dáfídì wà yìí, ó lè dà bíi pé kò sí ọ̀rẹ́ kankan tó lè pèsè ìrànlọ́wọ́ tó nílò fún un. (Sm. 142:4) Ìgbà yẹn ni Dáfídì ké pe Ọlọ́run.
16, 17. (a) Kí nìdí tí Dáfídì fi rò pé òun kò ní olùrànlọ́wọ́? (b) Ta ni Dáfídì lè bẹ̀ pé kó ran òun lọ́wọ́?
16 Nígbà tí Dáfídì kọ Sáàmù ìkejìlélógóje [142], ó ṣeé ṣe kó ti gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Áhímélékì tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà, ẹni tí kò lọ́ tìkọ̀ láti ran Dáfídì lọ́wọ́ nígbà tó sá kúrò níwájú Sọ́ọ̀lù. Nítorí èyí, owú mú kí Sọ́ọ̀lù Ọba pa Áhímélékì àti gbogbo agbo ilé rẹ̀. (1 Sám. 22:11, 18, 19) Dáfídì ronú pé òun lòun fa ikú wọn. Ńṣe ló dà bíi pé òun ló fọwọ́ ara rẹ̀ pa àlùfáà tó ràn án lọ́wọ́. Ká sọ pé o bá ara rẹ ní ipò tí Dáfídì wà, ṣé wàá rò pé ìwọ lo jẹ̀bi ọ̀ràn náà? Ohun tó tún mú kí ìdààmú tó bá Dáfídì pọ̀ sí i ni pé ọkàn rẹ̀ kò balẹ̀ torí pé Sọ́ọ̀lù ṣì ń lépa rẹ̀.
17 Kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí wòlíì Sámúẹ́lì tó fòróró yan Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ọba lọ́la, kú. (1 Sám. 25:1) Ìyẹn pẹ̀lú sì ti lè pa kún ohun tó mú kí Dáfídì máa rò pé òun kò ní olùrànlọ́wọ́. Síbẹ̀, Dáfídì mọ̀ pé òun lè wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà. Dáfídì kò ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn kan náà bíi tàwọn ọmọ Léfì, àmọ́ Ọlọ́run ti fòróró yàn án láti ṣe iṣẹ́ ìsìn míì tó yàtọ̀ sí tiwọn, ó wà nípò láti di ọba fún àwọn èèyàn Ọlọ́run. (1 Sám. 16:1, 13) Torí náà, Dáfídì sọ ohun tó ń dùn ún fún Jèhófà, ó sì ń bá a lọ láti máa gbára lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. Ìwọ pẹ̀lú lè ṣe bíi ti Dáfídì, ó sì yẹ kó o fi Jèhófà ṣe ìpín rẹ àti ibi ààbò rẹ bó o ti ń lo ara rẹ tokuntokun lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀.
18. Báwo ni àwọn tá a jíròrò nípa wọn nínú àpilẹ̀kọ yìí ṣe fi hàn pé wọ́n ní Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn?
18 Àwọn tá a ti sọ̀rọ̀ nípa wọn nínú àpilẹ̀kọ yìí ní Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn ní ti pé Ọlọ́run yan ohun tí wọ́n á máa bójú tó fún wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run pé á máa pèsè jíjẹ àti mímu fún wọn bí wọ́n ti ń sìn ín. Àwọn ọmọ Léfì àtàwọn míì tí wọ́n wá látinú ẹ̀yà míì ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì, irú bíi Dáfídì, lè jẹ́ kí Ọlọ́run jẹ́ ìpín àwọn. Báwo ni ìwọ náà ṣe lè fi Jèhófà ṣe ìpín rẹ? Ìyẹn ni ohun tá a máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ wa tó kàn.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bó o bá fẹ́ ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa bí Jèhófà ṣe ń pèsè fáwọn tó jẹ́ àlùfáà, wo ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Insight on the Scriptures, Apá Kejì, ojú ìwé 684.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà jẹ́ ìpín àwọn ọmọ Léfì?
• Kí ni Ásáfù, Jeremáyà àti Dáfídì ṣe tó fi hàn pé Jèhófà ni ìpín wọn?
• Ànímọ́ wo ló yẹ kó o ní bó o bá fẹ́ kí Ọlọ́run jẹ́ ìpín rẹ?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]
Àwọn ọmọ Léfì kò ní ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ogún. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà ni ìpín wọn, torí pé wọ́n ní àǹfààní ńláǹlà láti máa sìn ín
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ ìpín àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Kí ló mú kí Ásáfù máa bá a nìṣó láti ní Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ìpín rẹ̀?