Kí Ni Ó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ Nínú Ìgbésí Ayé Rẹ?
“Mú mi mọ ọ̀nà tí èmi ì bá máa tọ̀.”—ORIN DÁFÍDÌ 143:8.
1. Ìparí èrò wo ni Ọba Sólómọ́nì dé nípa ìlépa àti àṣeyọrí ẹ̀dá ènìyàn?
ÓṢEÉ ṣe kí o mọ̀ pé ìgbésí ayé kún fún àwọn ìgbòkègbodò àti àníyàn. Nígbà tí o bá ronú nípa rẹ̀, o ṣeé ṣe kí o lè dá àwọn tí ó ṣe pàtàkì mọ̀ yàtọ̀. Àwọn ìgbòkègbodò àti àníyàn míràn kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì tàbí kí wọn má tilẹ̀ ṣe pàtàkì rárá. Òkodoro òtítọ́ náà pé ìwọ mọ èyí túmọ̀ sí pé, o fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin tí ó gbọ́n jù lọ tí ó tí ì gbé ayé rí, Ọba Sólómọ́nì. Lẹ́yìn tí ó ti ṣàyẹ̀wò àwọn ìgbòkègbodò ìgbésí ayé jinlẹ̀jinlẹ̀, ó mú ọ̀rọ̀ wá sí òpin ní sísọ pé: “Bẹ̀rù Ọlọ́run kí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́: nítorí èyí ni fún gbogbo ènìyàn.” (Oníwàásù 2:4-9, 11; 12:13) Báwo ni èyí ṣe ṣe pàtàkì fún wa tó lónìí?
2. Ìbéèrè pàtàkì wo ni ó yẹ kí àwọn olùbẹ̀rù Ọlọ́run bi ara wọn, àwọn ìbéèrè tí ó tan mọ́ ọn wo ni yóò sì gbé dìde?
2 Bí o bá fẹ́ “bẹ̀rù Ọlọ́run kí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́,” béèrè ìbéèrè tí ń peni níjà yìí lọ́wọ́ ara rẹ, ‘Kí ni ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé mi?’ Òtítọ́ ni pé, ó lè máà jẹ́ ojoojúmọ́ ni o ń ronú jinlẹ̀ lórí ìbéèrè yẹn, ṣùgbọ́n èé ṣe tí o kò fi ronú lórí rẹ̀ nísinsìnyí? Ní tòótọ́, ó pe àwọn ìbéèrè kan tí ó ní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ síni lọ́kàn, irú bí, ‘O ha lè jẹ́ pé mo ń gbé ìjẹ́pàtàkì àrà ọ̀tọ̀ tí kò yẹ karí iṣẹ́ mi tàbí iṣẹ́ àmúṣe mi tàbí karí àwọn ohun ìní ti ara bí? Àyè wo ni mo fi ilé, ìdílé, àti àwọn tí mo nífẹ̀ẹ́ sí nínú ọ̀ràn yìí?’ Ọ̀dọ́ kan lè béèrè pé, ‘Títí dé àyè wo ni ìmọ̀ ẹ̀kọ́ fi gba àfiyèsí àti àkókò mi? Ní tòótọ́, ìgbòkègbodò àfipawọ́, eré ìdárayá, tàbí irú àwọn eré ìnàjú kan tàbí ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ha jẹ́ àwọn ohun tí mo nífẹ̀ẹ́ sí jù lọ bí?’ Láìka ọjọ́ orí wa tàbí ipò wa sí, ó tọ́ kí a bi ara wa pé, ‘Ipò wo ni ṣíṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run wà nínú ìgbésí ayé mi?’ Ó dájú pé ìwọ yóò gbà pé ó ṣe pàtàkì láti ní àwọn ohun àkọ́múṣe. Ṣùgbọ́n báwo ni a ṣe lè rí ìrànlọ́wọ́ gbà láti lè fi ọgbọ́n to àwọn ohun àkọ́múṣe wa, níbo sì ni a ti lè rí ìrànlọ́wọ́ náà gbà?
3. Kí ni gbígbé ohun àkọ́múṣe kalẹ̀ ní nínú fún àwọn Kristẹni?
3 “Ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ” ní ìtumọ̀ ìpìlẹ̀ ti ohun kan tí ó ṣáájú gbogbo ohun mìíràn, tàbí ohun tí ó yẹ kí a kọ́kọ́ gbé yẹ̀ wò. Yálà o jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí o wà lára àwọn àràádọ́ta ọ̀kẹ́ tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ọkàn, akẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí ń dara pọ̀ mọ́ wọn, gbé òtítọ́ yìí yẹ̀ wò: “Olúkúlùkù ohun ni àkókò wà fún, àti ìgbà fún iṣẹ́ gbogbo lábẹ́ ọ̀run.” (Oníwàásù 3:1) Lọ́nà tí ó tọ́, ìyẹ́n ní fífi tí o ń fi ìfẹ́ onídàníyàn hàn fún ipò ìbátan ìdílé nínú. (Kólósè 3:18-21) Ó ní nínú fífi iṣẹ́ àmúṣe pèsè fún ìdílé rẹ̀ láìlábòsí ọkàn. (Tẹsalóníkà Kejì 3:10-12; Tímótì Kìíní 5:8) Láti yí ìgbòkègbodò padà, o lè wá àkókò fún ìgbòkègbodò àfipawọ́ kan tàbí eré ìnàjú àtìgbàdégbà tàbí eré ìtura. (Fi wé Máàkù 6:31.) Ṣùgbọ́n, bí o bá ronú jinlẹ̀ lé e lórí, ìwọ kò ha rí i pé kò sí èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí tí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé? Ohun mìíràn ń bẹ tí ó ṣe pàtàkì jù lọ.
4. Báwo ni Fílípì 1:9, 10 ṣe kan gbígbé àwọn ohun àkọ́múṣe wa kalẹ̀?
4 Ó ṣeé ṣe kí o ti mọ̀ pé, àwọn ìlànà Bíbélì tí ń tọ́ni sọ́nà jẹ́ àrànṣe ṣíṣeyebíye nínú gbígbé àwọn ohun àkọ́múṣe kalẹ̀ àti nínú ṣíṣe àwọn ìpinnu tí ó bọ́gbọ́n mu. Fún àpẹẹrẹ, nínú Fílípì 1:9, 10, a rọ àwọn Kristẹni láti “túbọ̀ máa pọ̀ gidigidi síwájú àti síwájú pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye àti ìfòyemọ̀ kíkún.” Láti lè ṣe kí ni? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi kún un pé: “Kí ẹ lè máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.” Ìyẹn kò ha bọ́gbọ́n mu bí? Lórí ìpìlẹ̀ ìmọ̀ pípéye, Kristẹni kan tí ń fòye mọ̀ lè pinnu ohun tí ó yẹ kí ó jẹ ẹ́ lógún jù lọ—tí ó ṣe pàtàkì jù lọ fún un—nínú ìgbésí ayé.
Àwòkọ́ṣe Ní Ti Ohun Tí Ó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ
5. Ní ṣíṣàpèjúwe àwòkọ́ṣe tí a fi lélẹ̀ fún àwọn Kristẹni, báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe fi ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé Jésù hàn?
5 A rí ẹ̀ka ìmọ̀ kan tí ó ṣeyebíye nínú àwọn ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pétérù pé: “Ìlà ipa ọ̀nà yìí ni a pè yín sí, nítorí Kristi pàápàá jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.” (Pétérù Kìíní 2:21) Bẹ́ẹ̀ ni, láti lè mọ ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé, a lè ṣàyẹ̀wò èrò Jésù Kristi nípa rẹ̀. Orin Dáfídì 40:8 sọ nípa rẹ̀ lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Inú mi dùn láti ṣe [ìfẹ́ inú, NW] rẹ, Ọlọ́run mi, ní tòótọ́, òfin rẹ ń bẹ ní àyà mi.” Bí ó ṣe sọ èrò kan náà nìyí: “Oúnjẹ mi ni fún mi láti ṣe ìfẹ́ inú ẹni tí ó rán mi àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀.”—Jòhánù 4:34; Hébérù 12:2.
6. Báwo ni a ṣe lè ní irú àbájáde tí Jésù ní, ní fífi ìfẹ́ inú Ọlọ́run sí ipò kíní?
6 Kíyè sí kókó pàtàkì yẹn—ṣíṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run. Àpẹẹrẹ Jésù tẹnu mọ́ ohun tí ó yẹ kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jẹ́ kí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé wọn, nítorí ó wí pé “gbogbo ẹni tí a fún ní ìtọ́ni lọ́nà pípé yóò dà bí olùkọ́ rẹ̀.” (Lúùkù 6:40) Bí Jésù sì ṣe ń rìn ní ọ̀nà tí Bàbá rẹ̀ wéwèé, ó fi hàn pé “ayọ̀ àyọ̀tẹ́rùn” wà nínú kíka ìfẹ́ inú Ọlọ́run sí ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ. (Orin Dáfídì 16:11, NW; Ìṣe 2:28) Ìwọ́ ha lóye ohun tí ìyẹ́n dọ́gbọ́n túmọ̀ sí bí? Bí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ti yan ṣíṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé wọn, wọn yóò gbádùn “ẹ̀kún ayọ̀” àti ìgbésí ayé gidi. (Tímótì Kìíní 6:19) Nítorí náà, ìdí tí a ní fún mímú kí ṣíṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run jẹ́ ohun àkọ́múṣe nínú ìgbésí ayé wa ju ẹyọ kan lọ.
7, 8. Àdánwò wo ni Jésù dojú kọ, kí sì ni a lè rí kọ́ láti inú èyí?
7 Kété lẹ́yìn tí Jésù fi ẹ̀rí fífa ara rẹ̀ kalẹ̀ fún ṣíṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run hàn, Èṣù wọ́nà láti bì í ṣubú. Lọ́nà wo? Nípa gbígbé àdánwò kálẹ̀ lọ́nà mẹ́ta. Nígbà kọ̀ọ̀kan, Jésù fi Ìwé Mímọ́ fún un lésì, ní lílo àwọn ọ̀rọ̀ tí a kò fi bọpo bọyọ̀. (Mátíù 4:1-10) Ṣùgbọ́n àwọn àdánwò míràn ṣì ń dúró dè é—inúnibíni, ìfiṣẹ̀sín, dídà á láti ọwọ́ Júdásì, fífẹ̀sùn èké kàn án, àti ikú lórí igi ìdálóró. Síbẹ̀, kò sí èyíkéyìí nínú àwọn àdánwò wọ̀nyí tí ó mú kí adúróṣinṣin Ọmọkùnrin Ọlọ́run yẹsẹ̀. Nígbà kan tí ọ̀ràn náà dójú ẹ̀, Jésù gbàdúrà pé: “Kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí èmí ti fẹ́, bí kò ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti fẹ́. . . . Jẹ́ kí ìfẹ́ inú rẹ ṣẹ.” (Mátíù 26:39, 42) Kò ha yẹ kí ẹ̀ka yìí nínú àwòkọ̀ṣe tí ó fi lélẹ̀ fún wa sún wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan lọ́nà jíjinlẹ̀, ní mímú kí a “ní ìforítì nínú àdúrà”?—Róòmù 12:12.
8 Bẹ́ẹ̀ ni, nígbà tí a bá gbé àwọn ohun àkọ́múṣe wa kalẹ̀ nínú ìgbésí ayé, ìtọ́sọ́nà àtọ̀runwá ń ṣèrànwọ́ gidigidi, ní pàtàkì, bí a bá dojú kọ àwọn ọ̀tá òtítọ́ àti alátakò ìfẹ́ inú Ọlọ́run. Rántí àrọwà Ọba Dáfídì olùṣòtítọ́ fún ìtọ́sọ́nà nígbà tí ọ̀tá gbógun tì í. A óò lóye èyí bí a ṣe ń gbé apá kan nínú Orin Dáfídì 143 yẹ̀ wò. Èyí yẹ kí ó ràn wá lọ́wọ́ láti fòye mọ bí a ṣe lè fún ipò ìbátan ara ẹni wa pẹ̀lú Jèhófà lókun sí i, kí a sì di alágbára láti máa bá ṣíṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run nìṣó gẹ́gẹ́ bí ohun àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wa.
Jèhófà Ń Tẹ́tí Sí Àdúrà Wa, Ó Sì Ń Dáhùn Rẹ̀
9. (a) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, kí ni àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀ ṣí payá? (b) Èé ṣe tí kò fi yẹ kí a juwọ́ sílẹ̀ nínú ṣíṣe ohun tí ó tọ́?
9 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ ẹ̀dá ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ó lè kú, Dáfídì ní ìgbàgbọ́ pé Jèhófà yóò gbọ́ àrọwà òun. Ó fi ìrẹ̀lẹ̀ jírẹ̀ẹ́bẹ̀ pé: “Olúwa, gbọ́ àdúrà mi, fi etí sí ẹ̀bẹ̀ mi; nínú òtítọ́ rẹ dá mi lóhùn àti nínú òdodo rẹ. Kí o má sì bá ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ lọ sínú ìdájọ́, nítorí tí kò sí ẹni tí ó wà láàyè tí a óò dá láre níwájú rẹ.” (Orin Dáfídì 143:1, 2) Dáfídì mọ̀ dájú pé aláìpé ni òun, síbẹ̀ ọkàn-àyà rẹ̀ pé pérépéré sí Ọlọ́run. Nípa báyìí, ó ní ìgbọ́kànlé pé, òun yóò rí ìdáhùn gbà nínú òdodo. Èyí kò ha fún wa níṣìírí bí? Kódà bí a bá tilẹ̀ kùnà òdodo Ọlọ́run, a lè ní ìgbọ́kànlé pé, òún ń gbọ́ wa bí ọkàn-àyà wa bá pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀. (Oníwàásù 7:20; Jòhánù Kìíní 5:14) Bí a ṣe ń ní ìforítì nínú àdúrà, a gbọ́dọ̀ ní in lọ́kàn láti “máa fi ire ṣẹ́gun ibi” ní àwọn ọjọ́ búburú wọ̀nyí.—Róòmù 12:20, 21; Jákọ́bù 4:7.
10. Èé ṣe tí Dáfídì fi ní àwọn sáà tí ó fi ṣàníyàn?
10 Dáfídì ní àwọn ọ̀tá, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú ṣe ní. Yálà gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá lọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù, tí a fipá mú láti wá ibi ìsádi ní ibi àdádó tí a kò lè rọ́nà wọ̀, tàbí gẹ́gẹ́ bí ọba tí àwọn ọ̀tá halẹ̀ mọ́, Dáfídì ní àwọn sáà tirẹ̀ tí ó fi ṣàníyàn. Ó ṣàpèjúwe bí èyí ṣe nípa lórí rẹ̀ pé: “Ọ̀tá ti ṣe inúnibíni sí ọkàn mi . . . Ó ti mú mi jókòó ní òkùnkùn . . . Nítorí náà ni ẹ̀mí mi ṣe rẹ̀wẹ̀sì nínú mi; òfò fo àyà mi nínú mi.” (Orin Dáfídì 143:3, 4) Ìwọ́ ha ti ní ìdí láti ní irú ìmọ̀lára kan náà bí?
11. Àwọn sáà tí ó kún fún àníyàn wo ni àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní dojú kọ?
11 Wàhálà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀tá, àdánwò nítorí ìṣòro ọrọ̀ ajé líle koko, àìsàn líle koko, tàbí àwọn ìṣòro mìíràn tí ń dani láàmú, ti mú kí àwọn kan tí wọ́n jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run nímọ̀lára pé ẹ̀mí wọn yóò bọ́. Nígbà míràn ọkàn-àyà wọn ti dà bí èyí tí ó ti kú. Ní ṣe ni ó dà bíi pé wọ́n ti kígbe jáde lẹ́nì kọ̀ọ̀kan pé: “Nítorí tí o ti mú mi rí ọ̀pọ̀ wàhálà àti àjálù, ǹjẹ́ kí o sọ mí jí lẹ́ẹ̀kan sí i . . . Ǹjẹ́ kí o yí mi ká, kí o sì tù mí nínú.” (Orin Dáfídì 71:20, 21, NW) Báwo ni a ti ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́?
Bí A Ṣe Lè Dojú Kọ Ìsapá Ọ̀tá
12. Báwo ni Ọba Dáfídì ṣe kojú ewu àti àdánwò?
12 Orin Dáfídì 143:5 fi ohun tí Dáfídì ṣe hàn, nígbà tí ó dojú kọ ewu àti àdánwò ńláǹlà pé: “Èmí rántí ọjọ́ àtijọ́; èmí ṣe àṣàrò iṣẹ́ rẹ gbogbo, èmí ń ronú iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.” Dáfídì rántí ìbálò Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ àti bí òun fúnra rẹ̀ ṣe nírìírí ìdáǹdè. Ó ṣàṣàrò lórí ohun tí Jèhófà ti ṣe nítorí orúkọ ńlá Rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, Dáfídì ṣàníyàn nípa àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run.
13. Nígbà tí a bá dojú kọ àdánwò, báwo ni ríronú tí a ń ronú nípa àwọn àpẹẹrẹ ìránṣẹ́ olùṣòtítọ́ ní ìgbàanì àti nì òde òní ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà?
13 A kò ha ti fìgbà gbogbo rántí ìbálò Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ bí? Dájúdájú! Èyí ní nínú àkọsílẹ̀ tí “àwọ sánmà àwọn ẹlẹ́rìí tí ó pọ̀” ní àkókò tí ó ṣáájú ìgbà àwọn Kristẹni ní. (Hébérù 11:32-38; 12:1) A fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní ọ̀rúndún kìíní pẹ̀lú níṣìírí láti “máa bá a nìṣó ní rírántí àwọn ọjọ́ àtijọ́” àti ohun tí wọ́n ti fara dà. (Hébérù 10:32-34) Kí ni nípa ìrírí ti àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní, irú èyí tí a sọ nínú ìwé Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom?a Àwọn ìròyìn tí a kọ síbẹ̀ àti nínú àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn ń ràn wá lọ́wọ́ láti rántí bí Jèhófà ti ṣe ran àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́wọ́ láti fara da ìfòfindè, ìfisẹ́wọ̀n, ìgbésẹ̀ àwọn ènìyànkénìyàn, àti àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ òun àgọ́ ìmúnisinrú. Àdánwò ti wà ní àwọn ilẹ̀ tí ogun ti fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, irú bíi Burundi, Liberia, Rwanda, àti Yugoslavia tẹ́lẹ̀ rí. Nígbà tí àtakò dìde, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run fara dà nítorí dídi ipò ìbátan lílágbára mú pẹ̀lú Jèhófà. Ọwọ́ rẹ̀ mú àwọn tí wọ́n jẹ́ kí ṣíṣe ìfẹ́ inú rẹ̀ jẹ́ ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé wọn dúró.
14. (a) Àpẹẹrẹ kan wo ni ó wà ní ti bí Ọlọ́run ṣe ń mú ẹnì kan dúró nínú ipò kan tí ó lè rí bíi tiwa? (b) Kí ni o kọ́ láti inú àpẹẹrẹ yẹn?
14 Ṣùgbọ́n, o lè sọ pé o kò tí ì ní irú ìrírí oníwà ìkà rírorò bẹ́ẹ̀, o sì lè rò pé o lè máà ní irú rẹ̀ láé. Ṣùgbọ́n, ìtìlẹ́yìn tí Ọlọ́run ń fún àwọn ènìyàn rẹ̀ lè má fìgbà gbogbo jẹ́ irú ohun tí àwọn kan lè kà sí àwọn àyíká ipò amúnijígìrì. Ó ti ran ọ̀pọ̀ “tí kì í ṣe ẹ̀dá àrà ọ̀tọ̀” lọ́wọ́ nínú àwọn àyíká ipò “tí ó sábà ń ṣẹlẹ̀.” Àpẹẹrẹ kan ṣoṣo nìyí nínú ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ tí ó wà: Ìwọ́ ha mọ ẹni tí ó wà nínú fọ́tò tí ó wà lókè yìí, ó ha sì ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rántí ìbálò Ọlọ́run pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ bí? Ó fara hàn nínú Ilé Ìṣọ́ ti December 1, 1996. O ha ka ìròyìn tí Penelope Makris sọ bí? Ẹ wo irú ìwà títọ́ Kristẹni tí ó pinminrin tí ìyẹn jẹ́! O ha lè rántí ohun tí ó fara dà láti ọ̀dọ̀ àwọn aládùúgbò, bí ó ṣe gbógun ti àìlera líle koko, àti ìsapá tí ó ṣe láti lè dúró nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún? Ìrírí elérè ẹ̀san tí ó ní ní Mytilene ńkọ́? Kókó náà ni pé, Ìwọ́ ha rí irú àwọn àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìrànwọ́ fún gbogbo wa láti gbé àwọn ohun àkọ́múṣe wa kalẹ̀, kí a sì fi ìfẹ́ inú Ọlọ́run ṣe àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wa bí?
15. Kí ni díẹ̀ nínú àwọn ìṣe Jèhófà tí ó yẹ kí a fara wé?
15 Ṣíṣàṣàrò lórí àwọn ìgbòkègbodò Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí Dáfídì ti ṣe ń fún wa lókun. Láti mú ète rẹ̀ ṣẹ, Jèhófà mú kí ìgbàlà ṣeé ṣe nípasẹ̀ ikú Ọmọkùnrin rẹ̀, àjíǹde rẹ̀, àti ìṣelógo rẹ̀. (Tímótì Kìíní 3:16) Ó ti gbé Ìjọba rẹ̀ ti ọ̀run kalẹ̀, ó ti palẹ̀ Sátánì àti àwọn ẹ̀mí Èṣù rẹ̀ mọ́ kúrò ní ọ̀run, ó sì ti mú ìjọsìn tòótọ́ padà bọ̀ sípò lórí ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 12:7-12) Ó ti mú kí párádísè tẹ̀mí wà, ó sì ti fi ìbísí bù kún àwọn ènìyàn rẹ̀. (Aísáyà 35:1-10; 60:22) Àwọn ènìyàn rẹ̀ ń jẹ́rìí àjẹ́kẹ́yìn nísinsìnyí, kí ìpọ́njú ńlá tó bẹ́ sílẹ̀. (Ìṣípayá 14:6, 7) Bẹ́ẹ̀ ni, a ní ohun púpọ̀ láti ṣàṣàrò lé lórí.
16. Kí ni a rọ̀ wá láti ṣàníyàn lé lórí, kí sì ni èyí yóò gbìn sí wa lọ́kàn?
16 Ṣíṣàníyàn nípa iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run dípò dídi ẹni tí ìgbòkègbodò ẹ̀dá ènìyàn gbà lọ́kàn ń tẹ̀ ẹ́ mọ́ wa lọ́kàn pé, agbára gbígbéṣẹ́ tí Jèhófà ní kò ṣeé kò lójú. Ṣùgbọ́n, àwọn iṣẹ́ wọnnì kò mọ sórí àwọn arabaríbí iṣẹ́ tí a lè fojú rí, ti ìṣẹ̀dá tí ń bẹ ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé níhìn-ín. (Jóòbù 37:14; Orin Dáfídì 19:1; 104:24) Àwọn arabaríbí iṣẹ́ rẹ̀ ní àwọn ọ̀nà tí ó gbà dá àwọn ènìyàn rẹ́ nídè kùró lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá tí ń ni wọ́n lára nínú, gẹ́gẹ́ bí ìrírí àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ ìgbàanì ti fi hàn.—Ẹ́kísódù 14:31; 15:6.
Mímọ Ọ̀nà Tí A Óò Tọ̀
17. Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ ẹni gidi sí Dáfídì tó, báwo sì ni èyí ṣe lè fi wá lọ́kàn balẹ̀?
17 Dáfídì gbàdúrà fún ìrànwọ́, kí ẹ̀mí rẹ̀ má baà pin, ní sísọ pé: “Èmí na ọwọ́ mi sí ọ; òùngbẹ rẹ ń gbẹ ọkàn mi bí ilẹ̀ gbígbẹ. Olúwa, gbọ́ tèmi nísinsìnyí; ó rẹ ọkàn mi tán; má ṣe pa ojú rẹ mọ́ kúrò lára mi, kí èmi kí ó má baà dà bí àwọn tí ó lọ sínú ihò.” (Orin Dáfídì 143:6, 7) Dáfídì tí ó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, mọ̀ pé Ọlọ́run mọ ipò tí òun wà. (Orin Dáfídì 31:7) Nígbà míràn, àwa pẹ̀lú lè nímọ̀lára pé ipò wa nípa tẹ̀mí ti lọ sílẹ̀. Ṣùgbọ́n ipò náà kì í ṣe èyí tí kò ní àtúnṣe mọ́. Jèhófà, ẹni tí ń gbọ́ àdúrà wa, lè mú kí ìmúpadàbọ̀sípò wa yára kánkán nípa mímú kí àwọn alàgbà onífẹ̀ẹ́, àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ inú Ilé Ìṣọ́, tàbí àwọn apá inú ìpàdé tí ó dà bí èyí tí a wéwèé fún àwa gan-an tù wá lára.—Aísáyà 32:1, 2.
18, 19. (a) Kí ni ó yẹ kí ó jẹ́ àrọwà àtọkànwá wa sí Jèhófà? (b) Kí ni a lè ní ìdálójú rẹ̀?
18 Ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú Jèhófà ń sún wa láti pàrọwà fún un pé: “Mú mi gbọ́ ìṣeun ìfẹ́ rẹ ní òwúrọ̀; nítorí ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé: mú mi mọ ọ̀nà tí èmi ì bá máa tọ̀.” (Orin Dáfídì 143:8) Ó ha já Arábìnrin Makris kulẹ̀ bí, ẹni tí ó wà ní àdádó ní erékùṣù ilẹ̀ Gíríìsì? Nítorí náà, bí o bá ń jẹ́ kí ṣíṣe ìfẹ́ inú rẹ̀ jẹ́ ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé rẹ, òun yóò ha já ọ kulẹ̀ bí? Èṣù àti àwọn agbódegbà rẹ̀ yóò fẹ́ láti fà wá sẹ́yìn nínú iṣẹ́ wa ti pípòkìkí Ìjọba Ọlọ́run tàbí kí wọ́n fẹ́ láti dá iṣẹ́ náà dúró pátápátá. Yálà a ń ṣiṣẹ́ sìn ní àwọn ilẹ̀ tí a ti fàyè gba ìjọsìn tòótọ́ fàlàlà, tàbí a ń ṣiṣẹ́ sìn níbi tí a ti ká a lọ́wọ́ kò, àdúrà tí gbogbo wa ń gbà bá ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ Dáfídì mu pé: “Olúwa, gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi: ọ̀dọ̀ rẹ ni mo sá pamọ́ sí.” (Orin Dáfídì 143:9) Ààbò wa kúrò lọ́wọ́ àjálù nípa tẹ̀mí wà ní ibi ìkọ̀kọ̀ Ẹni Gíga Jù Lọ.—Orin Dáfídì 91:1.
19 Ìgbàgbọ́ wa nípa ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ fìdí múlẹ̀ gbọn-in. (Róòmù 12:1, 2) Nígbà náà, dènà ìsapá ayé láti fipá mú ọ gba ohun tí ó rò pé ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìwéwèé ẹ̀dá ènìyàn. Máa bá a nìṣó ní jíjẹ́ kí gbogbo apá ìgbésí ayé rẹ̀ fi ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ sí ọ hàn—ṣíṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run.—Mátíù 6:10; 7:21.
20. (a) Kí ni a ti kọ́ nípa Dáfídì nínú Orin Dáfídì 143:1-9? (b) Báwo ni àwọn Kristẹni lónìí ṣe ń fi ẹ̀mí tí Dáfídì ní hàn?
20 Àwọn ẹsẹ mẹ́sàn-án àkọ́kọ́ nínú Orin Dáfídì 143 tẹnu mọ́ ipò ìbátan ara ẹni tímọ́tímọ́, tí Dáfídì ní pẹ̀lú Jèhófà. Nígbà tí àwọn ọ̀tá kógun tì í, ó bẹ Ọlọ́run fún ìtọ́sọ́nà rẹ̀ láìlọ́ tìkọ̀. Ó tú ọkàn-àyà rẹ̀ jáde, ní wíwá ìrànlọ́wọ́ ní ọ̀nà tí ó tọ́ láti tọ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀ràn ṣe rí pẹ̀lú àwọn àṣẹ́kù ẹni àmì òróró tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé lónìí àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ wọn. Wọ́n ka ipò ìbátan wọn pẹ̀lú Jèhófà sí iyebíye bí wọ́n ṣe ń pàrọwà sí i fún ìtọ́sọ́nà. Wọ́n fi ṣíṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run ṣe ohun àkọ́kọ́, láìka wàhálà tí Èṣù àti ayé rẹ̀ lè gbé kò wọ́n sí.
21. Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì pé kí a fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀, bí a bá ní láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn ní ohun tí ó yẹ kí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé wọn?
21 Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn tí ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní láti mọ̀ pé ṣíṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run ni ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ. A lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye èyí nígbà tí a bá ń bá wọn jíròrò orí 13 ti ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, èyí tí ó tẹnu mọ́ àwọn ìlànà tí ó wé mọ́ jíjẹ́ onígbọràn sí Ọ̀rọ̀ náà.b Àmọ́ ṣáá o, ó yẹ kí wọ́n rí i pé a ń fi ohun tí a ń kọ̀ wọn ṣèwàhù. Lẹ́yìn sáà díẹ̀, àwọn pẹ̀lú yóò mọ ọ̀nà tí ó yẹ kí wọ́n tọ̀. Bí àwọn àràádọ́ta ọ̀kẹ́ wọ̀nyí ti ń finú wòye ohun tí ó yẹ kí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé wọn, a óò sún ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti ṣe ìyàsímímọ́ àti ìbatisí. Lẹ́yìn náà, ìjọ lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa rìn ní ọ̀nà ìyè.
22. Àwọn ìbéèrè wo ni a óò gbé yẹ̀ wò nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí yóò tẹ̀ lé e?
22 Ọ̀pọ̀ ti fi tọkàntọkàn gbà pé ìfẹ́ inú Ọlọ́run ni ó yẹ kí ó jẹ́ ohun pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé wọn. Ṣùgbọ́n, báwo ni Jèhófà ṣe ń kọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé, làti ṣe ìfẹ́ inú rẹ̀? Àǹfààní wo ni èyí ń mú wà fún wọn? A óò gbé àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yẹ̀ wò, pẹ̀lú ìjíròrò ẹsẹ pàtàkì kan, Orin Dáfídì 143:10, nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí yóò tẹ̀ lé e.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A tẹ̀ ẹ́ jáde ní 1992 láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
b A tẹ̀ ẹ́ jáde ní 1995 láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?
◻ Nípa fífi Fílípì 1:9, 10 sílò, báwo ni a ṣe lè gbé àwọn ohun àkọ́múṣe kalẹ̀?
◻ Báwo ni Jésù ṣe fi ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé rẹ̀ hàn?
◻ Kí ni a lè rí kọ́ nínú àwọn ìgbésẹ̀ Dáfídì nígbà tí ó wà nínú àdánwò?
◻ Ọ̀nà wo ni Orin Dáfídì 143:1-9 gbà ràn wá lọ́wọ́ lónìí?
◻ Kí ni ó yẹ kí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé wa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Àwọn ìgbésẹ̀ Dáfídì fi hàn pé ó gbára lé Jèhófà
[Credit Line]
A tún un gbé jáde láti ọwọ́ Illustrirte Pracht - Bibel/Heilige Schrift des Alten und Neuen Testaments, nach der deutschen Uebersetzung D. Martin Luther’s