Orí 13
Ìdí Tí Gbígbé Ìgbésí-Ayé Ìwà-bí-Ọlọ́run Fi Ń Mú Ayọ̀ Wá
1. Èéṣe tí a fi lè sọ pé ọ̀nà Jehofa ń mú ayọ̀ wá?
JEHOFA jẹ́ “Ọlọrun aláyọ̀,” ó sì fẹ́ kí o gbádùn ìwàláàyè. (1 Timoteu 1:11) Nípa rírìn ní ọ̀nà rẹ̀, o lè ṣe ara rẹ̀ láǹfààní kí o sì nírìírí ìtòròmini tí ó jinlẹ̀ tí ó sì wà pẹ́, bí odò tí ó ń ṣàn ní gbogbo ìgbà. Rírìn ní ọ̀nà Ọlọrun tún ń sún ẹnì kan láti máa ṣe àwọn ìṣe òdodo tí ń bá a nìṣó, “bí ìgbì-omi òkun.” Èyí ń mú ayọ̀ tòótọ́ wá.—Isaiah 48:17, 18.
2. Báwo ni àwọn Kristian ṣe lè láyọ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ń ṣe wọ́n níkà nígbà mìíràn?
2 Àwọn ènìyàn kan lè ṣàtakò pé, ‘Nígbà mìíràn àwọn ènìyàn máa ń jìyà fún ṣíṣe ohun tí ó tọ́.’ Òtítọ́ ni, ohun tí ó sì ṣẹlẹ̀ sí àwọn aposteli Jesu nìyẹn. Bí ó ti wù kí ó rí, bí a tilẹ̀ ṣe inúnibíni sí wọn, wọ́n yọ̀ wọ́n sì ń bá a lọ ní “pípolongo ìhìnrere nipa Kristi.” (Ìṣe 5:40-42) A lè kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì láti inú èyí. Ọ̀kan ni pé gbígbé ìgbésí-ayé ìwà-bí-Ọlọ́run kì í ṣe ẹ̀rí ìdánilójú pé àwọn ènìyàn yóò bá wa lò lọ́nà tí ó dára ní gbogbo ìgbà. Aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Níti tòótọ́, gbogbo awọn wọnnì tí wọ́n ń ní ìfẹ́-ọkàn lati gbé pẹlu ìfọkànsin Ọlọrun ní ìbákẹ́gbẹ́ pẹlu Kristi Jesu ni a óò ṣe inúnibíni sí pẹlu.” (2 Timoteu 3:12) Ìdí èyí ni pé Satani àti ayé rẹ̀ lòdì sí àwọn wọnnì tí wọ́n ń gbé ní ọ̀nà ìwà-bí-Ọlọ́run. (Johannu 15:18, 19; 1 Peteru 5:8) Ṣùgbọ́n ojúlówó ayọ̀ kò sinmi lórí àwọn ohun tí ó wà lẹ́yìn òde. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń wá láti inú ìgbàgbọ́ tí ó dájú pé a ń ṣe ohun tí ó tọ́ àti nítorí náà a ní ìtẹ́wọ́gbà Ọlọrun.—Matteu 5:10-12; Jakọbu 1:2, 3; 1 Peteru 4:13, 14.
3. Báwo ni ó ṣe yẹ kí ìjọsìn Jehofa nípa lórí ìgbésí-ayé ẹnì kan?
3 Àwọn ènìyàn kan wà tí wọ́n nímọ̀lára pé àwọn lè jèrè ojúrere Ọlọrun nípasẹ̀ àwọn ìṣe onífọkànsìn ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ṣùgbọ́n wọ́n lè gbàgbé nípa rẹ̀ ní àwọn ìgbà mìíràn. Ìjọsìn tòótọ́ ti Jehofa Ọlọrun kò rí bẹ́ẹ̀. Ó kan ìwà ẹnì kan jálẹ̀jálẹ̀ gbogbo wákàtí tí ó fi wà lójúfò, láti ọjọ́ dé ọjọ́, láti ọdún dé ọdún. Ìdí nìyẹn tí a fi pè é ní “Ọ̀nà Naa.” (Ìṣe 19:9; Isaiah 30:21) Ó jẹ́ gbígbé ní ọ̀nà ìwà-bí-Ọlọ́run tí ó béèrè pé kí a sọ̀rọ̀ kí a sì gbégbèésẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun.
4. Èéṣe tí ó fi ṣàǹfààní láti ṣe àwọn ìyípadà kí á baà lè gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀nà Ọlọrun?
4 Nígbà tí àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli bá rí i pé àwọn níláti ṣe àwọn ìyípadà kan láti lè wu Jehofa, wọ́n lè ṣe kàyéfì pé, ‘Ìgbésí-ayé ìwà-bí-Ọlọ́run ha yẹ láti gbé níti gidi bí?’ Jẹ́ kí ó dá ọ lójú pé ó yẹ níti gidi. Èéṣe? Nítorí pé “Ọlọrun jẹ́ ìfẹ́,” àwọn ọ̀nà rẹ̀ sì tipa báyìí jẹ́ fún àǹfààní wa. (1 Johannu 4:8) Ọlọrun tún jẹ́ ọlọ́gbọ́n tí ó sì mọ ohun tí ó dára jùlọ fún wa. Níwọ̀n bí Jehofa Ọlọrun ti jẹ́ alágbára ńlá, ó ní agbára láti fún wa lókun láti mú ìfẹ́ ọkàn wa ṣẹ láti wù ú nípa fífi àṣà búburú kan sílẹ̀. (Filippi 4:13) Ẹ jẹ́ kí a gbé àwọn ìlànà díẹ̀ tí gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú ìwà-bí-Ọlọ́run ní nínú yẹ̀wò kí a sì rí bí ṣíṣe ìfisílò wọn ṣe lè mú ayọ̀ wá.
ÀÌLÁBÒSÍ Ń YỌRÍ SÍ AYỌ̀
5. Kí ni Bibeli sọ nípa irọ́ pípa àti olè jíjà?
5 Jehofa jẹ́ “Ọlọrun òtítọ́.” (Orin Dafidi 31:5) Kò sí iyèméjì pé ìwọ fẹ́ láti tẹ̀lé àpẹẹrẹ rẹ̀ kí a sì mọ̀ ọ́ bí olóòótọ́. Àìlábòsí ń ṣamọ̀nà sí ọ̀wọ̀ ara-ẹni àti ìmọ̀lára pé o láásìkí. Bí ó ti wù kí ó rí, nítorí pé àbòsí wọ́pọ̀ nínú ayé ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí, àwọn Kristian nílò ìránnilétí yìí: “Ẹ máa sọ òtítọ́ olúkúlùkù yín pẹlu aládùúgbò rẹ̀ . . . Kí ẹni tí ń jalè máṣe jalè mọ́, ṣugbọn kàkà bẹ́ẹ̀ kí ó máa ṣe iṣẹ́ àṣekára . . . kí oun lè ní nǹkan lati há fún ẹni tí ó wà ninu àìní.” (Efesu 4:25, 28) Àwọn Kristian tí a gbà síṣẹ́ ń ṣe àìlábòsí lẹ́nu iṣẹ́ òòjọ́ wọn. Bí kì í bá ṣe pé agbanisíṣẹ́ wọn bá yọ̀ọ̀da fún wọn, wọ́n kì í mú ohunkóhun tí ó jẹ́ tirẹ̀. Bóyá lẹ́nu iṣẹ́, ní ilé-ẹ̀kọ́, tàbí ní ilé, ẹnì kan tí ó jẹ́ olùjọsìn Jehofa gbọ́dọ̀ “hùwà láìṣàbòsí ninu ohun gbogbo.” (Heberu 13:18) Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń sọ irọ́ pípa tàbí olè jíjà dàṣà kò lè ní ojúrere Ọlọrun.—Deuteronomi 5:19; Ìṣípayá 21:8.
6. Báwo ni àìlábòsí ènìyàn oníwà-bí-Ọlọ́run kan ṣe lè mú ògo wá fún Jehofa?
6 Híhùwà láìṣàbòsí ń mú ọ̀pọ̀ ìbùkún wá. Selina jẹ́ opó aláìní kan ní Africa tí ó nífẹ̀ẹ́ Jehofa Ọlọrun àti àwọn ìlànà òdodo rẹ̀. Ní ọjọ́ kan, ó rí àpamọ́wọ́ kan tí ó ní ìwé sọ̀wédowó àti owó tí ó pọ̀ rẹpẹtẹ nínú. Ní lílo ìwé tẹlifóònù kan, ó ṣeé ṣe fún un láti rí ẹni tí ó ni ín—olùtọ́jú ilé ìtajà kan tí a ti jà lólè. Ọkùnrin náà kò lè gba ohun tí ó rí gbọ́ nígbà tí Selina, ẹni tí ń ṣàìsàn gidigidi, bẹ̀ ẹ́ wò tí ó sì dá gbogbo ohun tí ó wà nínú àpamọ́wọ́ náà padà. “Irú àìlábòsí bẹ́ẹ̀ yẹ fún èrè,” ni ọkùnrin náà sọ tí ó sì fún un ní iye owó kan. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ọkùnrin yìí yin ìsìn Selina. Bẹ́ẹ̀ni, ìṣe àìlábòsí ń ṣe ẹ̀kọ́ Bibeli lọ́ṣọ̀ọ́, ó ń fi ògo fún Jehofa Ọlọrun, ó sì ń mú ayọ̀ wá fún àwọn olùjọsìn rẹ̀ aláìlábòsí.—Titu 2:10; 1 Peteru 2:12.
ÌWÀ-Ọ̀LÀWỌ́ Ń MÚ AYỌ̀ WÁ
7. Kí ni kò tọ̀nà nínú tẹ́tẹ́ títa?
7 Ayọ̀ wà nínú jíjẹ́ ọ̀làwọ́, ṣùgbọ́n àwọn wọ̀bìà kì “yoo jogún ìjọba Ọlọrun.” (1 Korinti 6:10) Irú wọ̀bìà kan tí ó wọ́pọ̀ ni tẹ́tẹ́ títa, tí ó jẹ́ ìgbìyànjú láti jèrè láti inú àdánù àwọn ẹlòmíràn. Jehofa kò tẹ́wọ́gba àwọn wọnnì tí wọ́n “jẹ́ oníwọra fún èrè àbòsí.” (1 Timoteu 3:8) Kódà níbi tí tẹ́tẹ́ títa bá bófinmu tí ẹnì kan sì ń ta á fún fàájì, ó lè di bárakú fún un kí ó sì máa gbé ìwà tí ó ti run ìgbésí-ayé ọ̀pọ̀ ènìyàn lárugẹ. Tẹ́tẹ́ títa sábà máa ń mú ìnira wá fún ìdílé atatẹ́tẹ́ náà, tí ó lè ní ìwọ̀nba owó díẹ̀ tí ó ṣẹ́kù láti fi ra àwọn ohun tí ó pọndandan bí oúnjẹ àti aṣọ.—1 Timoteu 6:10.
8. Báwo ni Jesu ṣe fi àpẹẹrẹ tí ó dára lélẹ̀ nínú ìwà-ọ̀làwọ́, báwo sì ni a ṣe lè jẹ́ ọ̀làwọ́?
8 Nítorí ìwà-ọ̀làwọ́ onífẹ̀ẹ́ wọn, àwọn Kristian ń rí ìdùnnú-ayọ̀ nínú ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́, ní pàtàkì àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn tí wọ́n wà ní ipò àìní. (Jakọbu 2:15, 16) Ṣáájú kí Jesu tó wá sórí ilẹ̀-ayé, ó ṣàkíyèsí ìwà-ọ̀làwọ́ Ọlọrun sí aráyé. (Ìṣe 14:16, 17) Jesu fúnra rẹ̀ fi àkókò rẹ̀, talẹnti rẹ̀, àní ìwàláàyè rẹ̀ pàápàá fún aráyé. Nítorí náà, ó tóótun dáradára láti sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà ninu fífúnni ju èyí tí ó wà ninu rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Jesu tún sọ̀rọ̀ dáradára nípa òtòṣì opó kan ẹni tí ó lo ìwà-ọ̀làwọ́ láti fi ẹyọ-owó kéékèèké méjì sínú àpótí ìṣúra ní tẹmpili, nítorí ó fi “gbogbo ohun-ìní ìgbésí-ayé rẹ̀” sílẹ̀. (Marku 12:41-44) Àwọn ọmọ Israeli ìgbàanì àti àwọn Kristian ọ̀rúndún kìn-ínní pèsè àpẹẹrẹ ti ìwà-ọ̀làwọ́ onídùnnú-ayọ̀ ní fífúnni ní ìtìlẹyìn ohun-ìní ti ara fún ìjọ àti fún iṣẹ́ Ìjọba náà. (1 Kronika 29:9; 2 Korinti 9:11-14) Ní àfikún sí ṣíṣe ọrẹ ohun-ìní ti ara fún àwọn ète wọ̀nyí, àwọn Kristian ní òde-òní ń rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọrun tayọ̀tayọ̀ wọ́n sì ń lo ìgbésí-ayé wọn nínú iṣẹ́-ìsìn rẹ̀. (Romu 12:1; Heberu 13:15) Jehofa ń bùkún wọn fún lílo àkókò, okun-inú, àti àwọn ohun àmúṣọrọ̀ mìíràn, títí kan owó wọn, láti ṣètìlẹyìn fún ìjọsìn tòótọ́ àti láti gbé iṣẹ́ ìwàásù ìhìnrere Ìjọba náà kárí-ayé ga síwájú.—Owe 3:9, 10.
ÀWỌN KÓKÓ ABÁJỌ MÌÍRÀN TÍ Ń GBÉ AYỌ̀ GA
9. Kí ni ṣàìtọ̀nà nínú àmujù ohun mímu ọlọ́tí?
9 Láti jẹ́ aláyọ̀, àwọn Kristian tún gbọ́dọ̀ ‘pa agbára ìrònú wọn mọ́.’ (Owe 5:1, 2, NW) Èyí béèrè pé kí wọ́n ka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun àti àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí ó jíire kí wọ́n sì ṣe àṣàrò lé wọn lórí. Ṣùgbọ́n àwọn ohun kan wà tí wọ́n níláti yẹra fún. Fún àpẹẹrẹ, àlòjù àwọn ohun mímu ọlọ́tí lè mú kí ẹnì kan pàdánù àkóso ìrònú rẹ̀. Nínú ipò èrò-orí yẹn, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ń lọ́wọ́ nínú ìwà pálapàla, wọ́n ń hu ìwà-ipá, wọ́n sì ń ṣe okùnfà àwọn ìjàm̀bá aṣekúpani. Kò yanilẹ́nu nígbà náà pé Bibeli sọ pé àwọn ọ̀mùtí kì yóò jogún Ìjọba Ọlọrun! (1 Korinti 6:10) Bí wọ́n ti pinnu láti “yèkooro ní èrò-inú,” àwọn Kristian tòótọ́ ń yẹra fún ìmùtípara, èyí sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti gbé ayọ̀ ga síwájú láàárín ara wọn.—Titu 2:2-6.
10. (a) Èéṣe tí àwọn Kristian kì í fi í lo tábà? (b) Àǹfààní wo ni ó ń wá láti inú jíjáwọ́ nínú àwọn àṣà tí ó ti di bárakú?
10 Ara tí ó mọ́ tónítóní ń fikún ayọ̀. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ti sọ àwọn nǹkan tí ó lè panilára di bárakú. Fún àpẹẹrẹ, ronú lórí ìlò tábà. Ètò-Àjọ Ìlera Àgbáyé ròyìn pé sìgá mímu “ń pa àádọ́jọ ọ̀kẹ́ ènìyàn lọ́dọọdún.” Jíjáwọ́ nínú àṣà tábà mímu lè ṣòro nítorí pé àwọn àmì ìdáwọ́ àṣà dúró onígbà díẹ̀ yóò wà. Ní òdìkejì, ọ̀pọ̀ àwọn amusìgá tẹ́lẹ̀rí ti ríi pé wọ́n ní ìlera tí ó sàn jù àti owó tí ó pọ̀ síi fún àìní agboolé wọn. Bẹ́ẹ̀ni, bíborí àṣà tábà mímu tàbí sísọ àwọn nǹkan tí ó lè panilára di bárakú yóò fikún ara kan tí ó mọ́ tónítóní, ẹ̀rí-ọkàn tí ó mọ́ gaara, àti ayọ̀ tòótọ́.—2 Korinti 7:1.
AYỌ̀ NÍNÚ ÌGBÉYÀWÓ
11. Kí ni a béèrè fún láti ní ìgbéyàwó bíbófinmu tí ó wà pẹ́títí tí ó sì lọ́lá?
11 Àwọn tí wọ́n ń gbé papọ̀ bí ọkọ àti aya níláti rí i dájú pé ìgbéyàwó wọn ni a ti fi orúkọ rẹ̀ sílẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ lọ́nà tí ó tọ́. (Marku 12:17) Wọ́n tún níláti wo ìgbéyàwó bí ẹrù-iṣẹ́ wíwúwo kan. Nítòótọ́, ìpínyà lè di ohun tí ó pọndandan nínú àwọn ọ̀ràn ìmọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọ́bùkátà, ìfìyàjẹni tí ó rékọjá ààlà, tàbí wíwu ipò tẹ̀mí léwu dé góńgó. (1 Timoteu 5:8; Galatia 5:19-21) Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ aposteli Paulu ní 1 Korinti 7:10-17 fún alábàáṣègbéyàwó ní ìṣírí láti wà papọ̀. Dájúdájú, láti ní ayọ̀ tòótọ́, wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ sí ẹnìkínní kejì. Paulu kọ̀wé pé: “Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo ènìyàn, kí ibùsùn ìgbéyàwó sì wà láìní ẹ̀gbin, nitori Ọlọrun yoo dá awọn àgbèrè ati awọn panṣágà lẹ́jọ́.” (Heberu 13:4) Èdè ọ̀rọ̀ náà “ibùsùn ìgbéyàwó” túmọ̀ ní ìpìlẹ̀ sí ìbálòpọ̀ takọtabo láàárín ọkùnrin kan àti obìnrin kan tí wọ́n ti bá ara wọn ṣègbéyàwó lábẹ́ òfin. Kò sí ìbálòpọ̀ takọtabo mìíràn, bí ìgbéyàwó pẹ̀lú aya tí ó ju ọ̀kan lọ, tí a lè ṣàpèjúwe bí èyí tí ó “ní ọlá láàárín gbogbo ènìyàn.” Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Bibeli dá ìbádàpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó àti ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ lẹ́bi.—Romu 1:26, 27; 1 Korinti 6:18.
12. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìyọrísí búburú tí ìwà àgbèrè ní?
12 Àgbèrè lè mú ìgbádùn ara-ìyára onígbà kúkúrú wá, ṣùgbọ́n kì í mú ayọ̀ tòótọ́ wá. Kò wu Ọlọrun ó sì lè dápàá sí ẹ̀rí-ọkàn ẹnì kan. (1 Tessalonika 4:3-5) Ìyọrísí bíbaninínújẹ́ ti ìbálòpọ̀ aláìbófinmu lè jẹ́ àrùn AIDS àti àwọn òkùnrùn mìíràn tí ìbálòpọ̀ takọtabo ń ta látaré. Ìròyìn ìṣègùn kan sọ pé: “A ti díwọ̀n rẹ̀ pé àwọn ènìyàn tí ó ju 250 million kárí-ayé ní ń kó àrùn àtọ̀sí lọ́dọọdún, tí 50 million sì ń kó àrùn rẹ́kórẹ́kó.” Ìṣòro oyún tí a kò fẹ́ tún wà níbẹ̀. Ètò Fètòsọ́mọbíbí Lágbàáyé ròyìn pé, ní gbogbo ayé, iye tí ó ju 15 million àwọn ọmọbìnrin láàárín ọjọ́-orí 15 sí 19 ń lóyún lọ́dọọdún, ìpín mẹ́ta lára wọn sì ń ṣẹ́yún. Ìwádìí kan fi hàn pé ní orílẹ̀-èdè kan ni Africa, ìṣòro ìṣẹ́yún ń yọrí sí ìpín 72 nínú ọgọ́rùn-ún lára gbogbo àwọn ọmọbìnrin ọ̀dọ́langba tí ń kú. Àwọn alágbèrè kan lè yèbọ́ lọ́wọ́ òkùnrùn kí wọ́n sì yẹra fún oyún ṣùgbọ́n wọn kò lè yèbọ́ lọ́wọ́ ìpalára èrò-ìmọ̀lára. Ọ̀pọ̀ ti pàdánù ọ̀wọ̀ ara-ẹni wọn tí wọ́n sì tilẹ̀ kórìíra ara wọn.
13. Kí ni àwọn àfikún ìṣòro tí ìwà panṣágà ń fà, ọjọ́ iwájú wo ni ó sì wà fún àwọn tí wọ́n ń bá a lọ láti jẹ́ alágbèrè àti onípanṣágà?
13 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé panṣágà lè ní ìdáríjì, ó jẹ́ ìpìlẹ̀ tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀ fún ìkọ̀sílẹ̀ tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu níhà ọ̀dọ̀ alájọṣègbéyàwó tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀ náà. (Matteu 5:32; fiwé Hosea 3:1-5.) Bí irú ìwàpálapàla bẹ́ẹ̀ bá yọrí sí ìtúká ìgbéyàwó kan, èyí lè fi àpá tí ó jinlẹ̀ níti èrò-ìmọ̀lára sọ́kàn alájọṣègbéyàwó tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀ náà àti àwọn ọmọ rẹ̀. Fún àǹfààní ìdílé ẹ̀dá ènìyàn, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ṣàlàyé pé ìdájọ́ rẹ̀ tí kò báradé yóò wá sórí àwọn alágbèrè àti onípanṣágà tí kò ronúpìwàdà. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó fi hàn kedere pé àwọn wọnnì tí wọ́n ń sọ ìwàpálapàla ìbálòpọ̀ takọtabo dàṣà “kì yoo jogún ìjọba Ọlọrun.”—Galatia 5:19, 21.
“KÌ Í ṢE APÁKAN AYÉ”
14. (a) Kí ni díẹ̀ lára oríṣi ìbọ̀rìṣà tí ènìyàn oníwà-bí-Ọlọ́run kan ń yẹra fún? (b) Ìtọ́sọ́nà wo ni Johannu 17:14 àti Isaiah 2:4 pèsè?
14 Àwọn wọnnì tí wọ́n nífẹ̀ẹ́-ọkàn láti wu Jehofa kí wọ́n sì gbádùn àwọn ìbùkún Ìjọba ń yẹra fún ìbọ̀rìṣà ní oríṣiríṣi ọ̀nà. Bibeli fi hàn pé kò tọ̀nà láti yá ère kí a sì jọ́sìn rẹ̀, títí kan ti Kristi, tàbí ìya Jesu, Maria. (Eksodu 20:4, 5; 1 Johannu 5:21) Nítorí náà, àwọn Kristian tòótọ́ kì í kúnlẹ̀ bọ àwọn àwòrán fún ìjọsìn, àgbélébùú, àti ère. Wọ́n tún ń yẹra fún àṣà ìbọ̀rìṣà tí ó túbọ̀ jẹ́ lọ́nà àrékérekè, irú bí ìṣe ìfọkànsìn fún àwọn àsíá tàbí kíkọ àwọn orin láti fi buyìn fún orílẹ̀-èdè. Nígbà tí a bá fagbára mú wọn láti ṣe irú àwọn ìṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ń rántí àwọn ọ̀rọ̀ Jesu sí Satani: “Jehofa Ọlọrun rẹ ni iwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, oun nìkanṣoṣo sì ni iwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́-ìsìn mímọ́-ọlọ́wọ̀ fún.” (Matteu 4:8-10) Jesu sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun “kì í ṣe apákan ayé.” (Johannu 17:14) Èyí túmọ̀ sí wíwà láìdásí tọ̀tún tòsì nínú àwọn àlámọ̀rí ìṣèlú àti gbígbé ní àlàáfíà ní ìbámu pẹ̀lú Isaiah 2:4, tí ó sọ pé: “Òun [Jehofa Ọlọrun] óò sì dájọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, yóò sì bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn wí: wọn óò fi idà wọn rọ [ohun-èlò ìtúlẹ̀, NW], wọn óò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé; orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè; bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.”
15. Kí ni Babiloni Ńlá, kí sì ni àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ń ṣe láti jáde kúrò nínú rẹ̀?
15 Ṣíṣàìjẹ́ “apákan ayé” tún túmọ̀ sí jíjá gbogbo ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú “Babiloni Ńlá,” ilẹ̀-ọba ìsìn èké àgbáyé. Ìjọsìn àìmọ́ gbilẹ̀ láti Babiloni ìgbàanì títí tí ó fi jẹgàba nípa tẹ̀mí lọ́nà tí ń pani lára lórí àwọn ènìyàn kárí ayé. “Babiloni Ńlá” kó gbogbo ìsìn tí ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ àti ìṣe-àṣà wọn kò sí ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ Ọlọrun mọ́ra. (Ìṣípayá 17:1, 5, 15) Kò sí olùṣòtítọ́ olùjọsìn Jehofa kankan tí yóò lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò alámùúlùmálà ìgbàgbọ́ nípa ṣíṣàjọpín nínú ìjọsìn pẹ̀lú àwọn ìsìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tàbí nípa níní àjọṣe nípa tẹ̀mí pẹ̀lú apá èyíkéyìí nínú Babiloni Ńlá. (Numeri 25:1-9; 2 Korinti 6:14) Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí èyí, ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ti kọ lẹ́tà mi-ò-ṣe-mọ́ ránṣẹ́ sí ètò-àjọ ìsìn tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀. Èyí ti mú kí wọ́n túbọ̀ súnmọ́ Ọlọrun tòótọ́ náà, bí a ti ṣèlérí pé: “‘Ẹ jáde kúrò láàárín wọn, kí ẹ sì ya ara yín sọ́tọ̀,’ ni Jehofa wí, ‘kí ẹ sì jáwọ́ ninu fífọwọ́kan ohun àìmọ́’; ‘dájúdájú emi yoo sì gbà yín wọlé.’” (2 Korinti 6:17; Ìṣípayá 18:4, 5) Kì í ha ṣe ìtẹ́wọ́gbà Bàbá wa ọ̀run ni o nífẹ̀ẹ́-ọkàn mímúhánhán sí?
GBÍGBÉ ÀWỌN ÀÀTÒ ÀKÍYÈSÍ ỌDỌỌDÚN YẸ̀WÒ
16. Èéṣe tí àwọn Kristian tòótọ́ kò fi ń ṣe àṣeyẹ Keresimesi?
16 Ìgbésí-ayé oníwà-bí-Ọlọ́run tú wa sílẹ̀ kúrò nínú ẹrù-ìnira ṣíṣe àṣeyẹ họlidé ayé. Fún àpẹẹrẹ, Bibeli kò ṣí ọjọ tí a bí Jesu gan-an ní pàtó payá. Àwọn kan lè fìyàlẹ́nu sọ pé: ‘Mo rò pé wọ́n bí Jesu ní December 25!’ Ìyẹn kò lè rí bẹ́ẹ̀ nítorí ó kú ní ìgbà ìrúwé 33 C.E. ní ẹni ọdún 33 1/2. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ní àkókò ìbí rẹ̀, àwọn olùṣọ́ àgùtàn “ń gbé ní ìta tí wọ́n sì ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí awọn agbo-ẹran wọn ní òru.” (Luku 2:8) Ní ilẹ̀ Israeli, ìparí December jẹ́ àkókò òtútù, olójò nígbà tí a óò tọ́jú àwọn àgùtàn sábẹ́ ààbò mọ́jú láti dáàbòbò wọ́n kúrò lọ́wọ́ ojú-ọjọ́ ìgbà òtútù. Níti tòótọ́, December 25 ni àwọn ará Romu yà sọ́tọ̀ bí ọjọ́ ìbí ọlọrun oòrùn. Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn tí Jesu wá sórí ilẹ̀-ayé, àwọn Kristian apẹ̀yìndà gba déètì náà fún àṣeyẹ ìbí Kristi. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí èyí, àwọn Kristian tòótọ́ kì í ṣe àṣeyẹ Keresimesi tàbí họlidé èyíkéyìí mìíràn tí a gbé karí ìgbàgbọ́ ìsìn èké. Nítorí wọ́n fún Jehofa ní ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gédégbé, wọ́n kò tún ń pa àwọn họlidé tí ó ń sọ àwọn ẹ̀dá-ènìyàn tàbí orílẹ̀-èdè di òrìṣà mọ́.
17. Èéṣe tí àwọn ènìyàn oníwà-bí-Ọlọ́run kò fi ń ṣe àríyá ọjọ́ ìbí, èésìtiṣe tí àwọn ọmọdé tí ó jẹ́ Kristian fi ń láyọ̀ síbẹ̀síbẹ̀?
17 Ní pàtó ni Bibeli mẹ́nukan kìkì àkíyèsí ọjọ́-ìbí méjì, méjèèjì jẹ́ nípa àwọn ọkùnrin tí kì í jọ́sìn Ọlọrun. (Genesisi 40:20-22; Matteu 14:6-11) Níwọ̀n bí Ìwé Mímọ́ kò ti ṣí ọjọ́ tí a bí ọkùnrin pípé náà Jesu Kristi payá, èéṣe tí a fi níláti fi àkànṣe àfiyèsí sórí ọjọ́ ìbí àwọn ẹ̀dá-ènìyàn aláìpé? (Oniwasu 7:1) Dájúdájú, àwọn òbí oníwà-bí-Ọlọ́run kì í dúró dé ọjọ́ àkànṣe kan kí wọ́n tó fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ọmọ wọn. Kristian ọmọbìnrin ọlọ́dún 13 kan sọ pé: “Èmi àti ìdílé mi máa ń gbádùn ara wa. . . . Mo súnmọ́ àwọn òbí mi pẹ́kípẹ́kí, bí àwọn ọmọ yòókù bá sì béèrè ìdí ti èmí kò fi ń ṣe àṣeyẹ àwọn họlidé, mo ń sọ fún wọn pé ojoojúmọ́ lọdún tèmi.” Kristian èwe ọmọ ọlọ́dún 17 kan sọ pé: “Nínú ilé wa, yípo ọdún ni a ń fúnni lẹ́bùn.” Ayọ̀ tí ó pọ̀ sí i ń wá nígbà tí àwọn ẹ̀bùn bá jẹ́ láìgbèròtẹ́lẹ̀.
18. Àfiyèsí ẹlẹ́ẹ̀kan lọ́dún wo ni Jesu pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti pamọ́, kí ni ó sì rán wa létí rẹ̀?
18 Fún àwọn wọnnì tí ń lépa ìgbésí-ayé oníwà-bí-Ọlọ́run, ọjọ́ kan wà lọ́dọọdún tí wọ́n máa ń kíyèsí lọ́nà àkànṣe. Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa ni, tí a sábà máa ń pè ní Ìṣe-Ìrántí ikú Kristi. Nípa èyí, Jesu pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (Luku 22:19, 20; 1 Korinti 11:23-25) Nígbà tí Jesu dá oúnjẹ yìí sílẹ̀ ní alẹ́ Nisan 14, 33 C.E., ó lo búrẹ́dì aláìwú àti ọtí wáìnì pupa, tí ó dúró fún ara ẹ̀dá ènìyàn aláìlẹ́ṣẹ̀ àti ẹ̀jẹ̀ pípé rẹ̀. (Matteu 26:26-29) Àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ wọ̀nyí ni àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró ń ṣàjọpín nínú rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́ Ọlọrun. A ti mú wọn wọ inú májẹ̀mú titun àti májẹ̀mú Ìjọba náà, wọ́n sì ní ìrètí ti ọ̀run. (Luku 12:32; 22:20, 28-30; Romu 8:16, 17; Ìṣípayá 14:1-5) Bí ó ti wù kí ó rí, gbogbo àwọn tí ó pésẹ̀ ní alẹ́ tí ó dọ́gba pẹ̀lú Nisan 14 lórí kàlẹ́ńdà ìgbàanì ti àwọn Júù ni wọ́n ń jàǹfààní. Ó ń rán wọn létí ìfẹ́ tí Jehofa Ọlọrun àti Jesu Kristi fi hàn nínú ẹbọ ìràpadà ètùtù-ẹ̀ṣẹ̀ tí ó mú kí ìyè ayérayé ṣeé ṣe fún àwọn wọnnì tí wọ́n ní ojúrere àtọ̀runwá.—Matteu 20:28; Johannu 3:16.
IṢẸ́ ṢÍṢE ÀTI ERÉ ÌNÀJÚ
19. Ìpèníjà wo ni àwọn Kristian dojúkọ lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn?
19 Àwọn Kristian tòótọ́ wà lábẹ́ àìgbọdọ̀máṣe láti ṣiṣẹ́ kára láti pèsè fún àìní ara wọn. Ṣíṣe àṣeparí èyí ń fún àwọn olórí ìdílé ní ìtẹ́lọ́rùn. (1 Tessalonika 4:11, 12) Dájúdájú, bí iṣẹ́ Kristian kan bá forígbárí pẹ̀lú Bibeli, èyí yóò dù ú ní ayọ̀. Síbẹ̀, ó máa ń ṣòro nígbà mìíràn fún Kristian kan láti rí iṣẹ́ tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n Bibeli. Fún àpẹẹrẹ, àwọn agbanisíṣẹ́ kan lè béèrè pé kí o tan àwọn oníbàárà jẹ. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn agbanisíṣẹ́ yóò fàyègba ẹ̀rí-ọkàn òṣìṣẹ́ aláìlábòsí kan, bí wọn kò ti ní fẹ́ láti pàdánù ẹni tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀lé tí wọ́n gbà síṣẹ́. Bí ó ti wù kí ó rí, ohun yòówù kí ó ṣẹlẹ̀, jẹ́ kí ó dá ọ lójú pé Ọlọrun yóò bùkún ìsapá rẹ láti rí iṣẹ́ tí yóò mú kí o ní ẹ̀rí-ọkàn tí ó mọ́ tónítóní.—2 Korinti 4:2.
20. Èéṣe tí a fi níláti ṣe àṣàyàn eré ìnàjú?
20 Níwọ̀n bí Ọlọrun ti fẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láyọ̀, a níláti jẹ́ kí iṣẹ́ àṣekára wà lórí ìwọ̀n kan náà pẹ̀lú sáà eré ìtura àti ìsinmi tí ó tuni lára. (Marku 6:31; Oniwasu 3:12, 13) Ayé Satani ń gbé àwọn eré ìnàjú aláìwà-bí-Ọlọ́run ga síwájú. Ṣùgbọ́n láti wu Ọlọrun, a gbọ́dọ̀ ṣe àṣàyàn àwọn ìwé, ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí rédíò àti orin tí a ń fetísílẹ̀ sí, àti eré orí ìtàgé, sinimá, eré àṣedárayá, ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n, àti fídíò tí a ń wò. Bí eré ìnàjú tí a yàn ní ìgbà àtijọ́ bá forígbárí pẹ̀lú àwọn ìkìlọ̀ nínú àwọn ìwé mímọ́ bíi Deuteronomi 18:10-12, Orin Dafidi 11:5, àti Efesu 5:3-5, a óò wu Jehofa a óò sì láyọ̀ síi bí a bá ṣe àwọn ìyípadà.
Ọ̀WỌ̀ FÚN ÌWÀLÁÀYÈ ÀTI Ẹ̀JẸ̀
21. Báwo ni ọ̀wọ̀ fún ìwàláàyè ṣe yẹ kí ó nípa lórí ojú tí a fi ń wo ìṣẹ́yún, papọ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà àti ìwà wa?
21 Láti lè ní ayọ̀ tòótọ́, a níláti wo ìwàláàyè ẹ̀dá-ènìyàn bí ohun mímọ́ ọlọ́wọ̀, gan-an bí Jehofa ti wò ó. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ka ìṣìkàpànìyàn léèwọ̀. (Matteu 19:16-18) Níti tòótọ́, Òfin Ọlọrun fún Israeli fi hàn pé ó wo ọmọ inú ọlẹ̀ bí ìwàláàyè kan tí ó ṣe iyebíye—kì í ṣe ohun kan tí a lè parun. (Eksodu 21:22, 23) Nítorí èyí, a kò gbọdọ̀ wo ìwàláàyè bí ohun kan tí kò níyelórí nípa lílo tábà, lílo ara wa nílòkulò pẹ̀lú oògùn tàbí ọtí líle, tàbí fífi í wewu láìnídìí. Bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọdọ̀ lọ́wọ́ nínú àwọn ìlépa èyíkéyìí tí ń wu ìwàláàyè léwu a kò sì gbọdọ̀ ṣàìfiyèsí àwọn ìṣọ́ratẹ́lẹ̀ lòdì sí ewu, tí ó lè yọrí sí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀.—Deuteronomi 22:8.
22. (a) Kí ni ojú-ìwòye Ọlọrun nípa ẹ̀jẹ̀ àti ìlò rẹ̀? (b) Ẹ̀jẹ̀ ti ta ni ó ń gba ẹ̀mí lá nítòótọ́?
22 Jehofa sọ fún Noa àti ìdílé rẹ̀ pé ẹ̀jẹ̀ dúró fún ọkàn, tàbí ìwàláàyè. Nítorí náà, Ọlọrun ka jíjẹ ẹ̀jẹ̀ léèwọ̀ fún wọn. (Genesisi 9:3, 4) Níwọ̀n bí a ti jẹ́ ọmọ-ìran wọn, òfin yẹn de àwa náà pẹ̀lú. Jehofa sọ fún àwọn ọmọ Israeli pé kí wọ́n tú ẹ̀jẹ̀ jáde sórí ilẹ̀ kí ẹ̀dá ènìyàn má sì ṣe lò ó fún ète ara rẹ̀. (Deuteronomi 12:15, 16) Òfin Ọlọrun lórí ẹ̀jẹ̀ ni a sì tún sọ nígbà tí a fún àwọn Kristian ọ̀rúndún kìn-ínní ní ìtọ́ni pé: “[Ẹ] máa takété . . . sí ẹ̀jẹ̀.” (Ìṣe 15:28, 29) Nítorí ọ̀wọ̀ fún ìjẹ́mímọ́ ìwàláàyè, àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ìwà-bí-Ọlọ́run kì í gba ẹ̀jẹ̀ sára, kódà bí àwọn mìíràn bá tilẹ̀ tẹpẹlẹ mọ́ ọn pé irú ìlànà bẹ́ẹ̀ yóò gba ẹ̀mí là. Ọ̀pọ̀ ìpèsè àfidípò ìtọ́jú ìṣègùn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tẹ́wọ́gbà ti jásí èyí tí ó gbéṣẹ́ gidi kò sì ṣí ẹnì kan sílẹ̀ sí àwọn ewu ìfàjẹ̀sínilára. Àwọn Kristian mọ̀ pé kìkì ẹ̀jẹ̀ tí Jesu tasílẹ̀ nìkan ni ó lè gba ẹ̀mí là. Ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ ń mú ìdáríjì àti ìfojúsọ́nà fún ìyè ayérayé wá.—Efesu 1:7.
23. Kí ni àwọn èrè ẹ̀san díẹ̀ ti ọ̀nà ìgbésí-ayé oníwà-bí-Ọlọ́run?
23 Ní kedere, gbígbé ìgbésí-ayé ìwà-bí-Ọlọ́run ń béèrè ìsapá. Ó lè yọrí sí ẹ̀gàn láti ọ̀dọ̀ àwọn mẹ́ḿbà ìdílé tàbí ojúlùmọ̀. (Matteu 10:32-39; 1 Peteru 4:4) Ṣùgbọ́n èrè gbígbé irú ìgbésí-ayé bẹ́ẹ̀ tẹ̀wọ̀n ju àdánwò èyíkéyìí lọ. Ó ń yọrí sí ẹ̀rí-ọkàn mímọ́ tónítóní kan ó sì ń pèsè àjọṣepọ̀ sísunwọ̀n pẹ̀lú àwọn olùjọsìn Jehofa ẹlẹgbẹ́ ẹni. (Matteu 19:27, 29) Lẹ́yìn náà, tún ronú nípa gbígbé títí láé nínú ayé titun òdodo ti Ọlọrun. (Isaiah 65:17, 18) Sì wo ìdùnnú-ayọ̀ tí ó wà nínú mímú ara-ẹni bá àwọn ìmọ̀ràn Bibeli mu àti títipa báyìí mú ọkàn-àyà Jehofa dùn! (Owe 27:11) Kò yani lẹ́nu nígbà náà pé gbígbé ìgbésí-ayé ìwà-bí-Ọlọ́run ń mú ayọ̀ wá!—Orin Dafidi 128:1, 2.
DÁN ÌMỌ̀ RẸ WÒ
Kí ni àwọn ìdí díẹ̀ tí gbígbé ìgbésí-ayé ìwà-bí-Ọlọ́run fi ń mú ayọ̀ wá?
Ìgbésí-ayé ìwà-bí-Ọlọ́run lè béèrè fún àwọn ìyípadà wo?
Èéṣe tí o fi fẹ́ gbé ìgbésí-ayé ìwà-bí-Ọlọ́run?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 124, 125]
Àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí tí ó wà ní ìwọ̀ndéédéé pẹ̀lú sáà ìdẹ̀ra ń fikún ayọ̀ àwọn wọnnì tí ń gbé ìgbésí-ayé ìwà-bí-Ọlọ́run