Àwámáridìí ni Títóbi Jèhófà
“Jèhófà tóbi, ó sì yẹ fún ìyìn gidigidi, àwámáridìí sì ni títóbi rẹ̀.”—Sáàmù 145:3.
1, 2. Irú ènìyàn wo ni Dáfídì jẹ́, ipò wo ni ó sì fi ara rẹ̀ sí níwájú Ọlọ́run?
Ọ̀KAN lára àwọn gbajúmọ̀ ọkùnrin ayé ìgbàanì ló kọ Sáàmù 145. Nígbà tó wà lọ́mọdé, ó bá òmìrán kan tó dìhámọ́ra ogun jà, ó sì pa á. Nígbà tí onísáàmù yìí di ọba tó ń jagun, ó ṣẹ́gun ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀tá. Dáfídì ni orúkọ rẹ̀, òun sì ni ọba tó jẹ ṣìkejì ní Ísírẹ́lì ìgbàanì. Orúkọ rere tí Dáfídì ní kò pa rẹ́ lẹ́yìn ikú rẹ̀, kódà ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà láyé lónìí ló mọ ohun kan nípa rẹ̀.
2 Pẹ̀lú gbogbo àṣeyọrí tí Dáfídì ṣe yìí, síbẹ̀ ó tún jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Ó kọrin nípa Jèhófà pé: “Nígbà tí mo rí ọ̀run rẹ, àwọn iṣẹ́ ìka rẹ, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tí o ti pèsè sílẹ̀, kí ni ẹni kíkú tí o fi ń fi í sọ́kàn, àti ọmọ ará ayé tí o fi ń tọ́jú rẹ̀?” (Sáàmù 8:3, 4) Dípò tí Dáfídì ì bá fi ka ara rẹ̀ sí ẹni ńlá, Jèhófà ló sọ pé ó dá òun nídè kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá òun, ó sì sọ nípa Ọlọ́run pé: “Ìwọ yóò sì fún mi ní apata ìgbàlà rẹ, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ rẹ sì ni ó sọ mí di ńlá.” (2 Sámúẹ́lì 22:1, 2, 36) Jèhófà fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn nínú ọ̀nà tó gbà ń fi àánú hàn sí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, Dáfídì sì mọrírì inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Ọlọ́run fi hàn yìí.
‘Èmi Yóò Gbé Ọlọ́run Ọba Ga’
3. (a) Ojú wo ni Dáfídì fi wo ipò ọba Ísírẹ́lì? (b) Báwo ló ṣe wu Dáfídì láti yin Jèhófà tó?
3 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì ni ọba tí Ọlọ́run yàn lákòókò yẹn, síbẹ̀ ó gbà pé Jèhófà gan-an ni Ọba Ísírẹ́lì. Dáfídì sọ pé: “Tìrẹ ni ìjọba, Jèhófà, ìwọ Ẹni tí ń gbé ara rẹ sókè ṣe olórí pẹ̀lú lórí ohun gbogbo.” (1 Kíróníkà 29:11) Dáfídì mà mọyì jíjẹ́ tí Ọlọ́run jẹ́ Alákòóso yìí o! Ó kọ ọ́ lórin pé: “Ṣe ni èmi yóò gbé ọ ga, ìwọ Ọlọ́run mi Ọba, ṣe ni èmi yóò máa fi ìbùkún fún orúkọ rẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé. Láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ ni èmi yóò máa fi ìbùkún fún ọ, ṣe ni èmi yóò máa yin orúkọ rẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.” (Sáàmù 145:1, 2) Ohun tó wu Dáfídì ni pé kó máa yin Jèhófà Ọlọ́run láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀, kódà títí láé pàápàá.
4. Àwọn ẹ̀sùn èké wo ni Sáàmù 145 tú àṣírí rẹ̀?
4 Sáàmù 145 jẹ́ ká mọ̀ pé irọ́ gbuu ni sísọ tí Sátánì sọ pé Ọlọ́run jẹ́ alákòóso tó mọ ti ara rẹ̀ nìkan tí kò sì fún àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ lómìnira. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5) Sáàmù yìí tún túdìí àṣírí irọ́ tí Sátánì pa pé àwọn tó ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run kò nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, wọ́n kàn ń ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí ohun tí wọ́n máa rí gbà lọ́wọ́ rẹ̀ ni. (Jóòbù 1:9-11; 2:4, 5) Bíi ti Dáfídì, àwọn Kristẹni tòótọ́ òde òní náà ń fi hàn pé irọ́ gbuu làwọn ẹ̀sùn èké tí Èṣù ń fi kàn wọ́n. Ìyè àìnípẹ̀kun tí wọ́n ń retí lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba náà ṣeyebíye sí wọn gan-an, nítorí pé wọ́n fẹ́ láti máa yin Jèhófà títí ayérayé. Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ti ń ṣe bẹ́ẹ̀ báyìí nípa lílo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù, tí ìfẹ́ sì ń mú kí wọ́n máa fi ìgbọràn sin Jèhófà gẹ́gẹ́ bí àwọn olùjọsìn tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́, tí wọ́n sì ti ṣe ìrìbọmi.—Róòmù 5:8; 1 Jòhánù 5:3.
5, 6. Àwọn àǹfààní wo ló wà fún wa láti fi ìbùkún fún Jèhófà ká sì máa yìn ín?
5 Ronú nípa ọ̀pọ̀ àǹfààní táwa ìránṣẹ́ Jèhófà ní láti fi ìbùkún fún un àti láti yìn ín. A lè ṣe bẹ́ẹ̀ nínú àdúrà wa nígbà tí ohun kan tá a kà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, tí í ṣe Bíbélì, bá wọ̀ wá lára gan-an. A lè fi ìyìn tó kún fún ìmoore àti ọpẹ́ hàn nígbà tí ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń bá àwọn èèyàn rẹ̀ lò bá mórí wa wú gan-an tàbí nígbà tí apá kan nínú àgbàyanu ìṣẹ̀dá rẹ̀ bá múnú wa dùn gan-an. A tún máa ń fi ìbùkún fún Jèhófà Ọlọ́run nígbà táwa àtàwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ bá wà làwọn ìpàdé Kristẹni tí a sì ń jíròrò nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run máa ṣe tàbí nígbà tá a bá ń fọ̀rọ̀ wérọ̀ láàárín ara wa. Ní ti tòótọ́, gbogbo “àwọn iṣẹ́ àtàtà” tá a bá ṣe nítorí Ìjọba Ọlọ́run ló ń fi ìyìn fún Jèhófà.—Mátíù 5:16.
6 Àpẹẹrẹ irú àwọn ìṣẹ́ àtàtà bẹ́ẹ̀ tá a rí lẹ́nu àìpẹ́ yìí ni kíkọ́ táwọn èèyàn Jèhófà ń kọ́ ọ̀pọ̀ ìbi ìjọsìn sí àwọn orílẹ̀-èdè táwọn èèyàn kò ti rí jájẹ. Owó táwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa tó wà láwọn orílẹ̀-èdè mìíràn fi ṣèrànwọ́ la ń lò fún ọ̀pọ̀ lára iṣẹ́ ìkọ́lé yìí. Àwọn Kristẹni kan ti ṣèrànwọ́ nípa yíyọ̀ǹda ara wọn láti lọ sí irú àwọn àgbègbè bẹ́ẹ̀ kí wọ́n lè kópa nínú kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wọ̀nyí. Èyí tó sì ṣe pàtàkì jù lọ nínú gbogbo iṣẹ́ àtàtà ni pé kéèyàn máa yin Jèhófà nípa wíwàásù ìhìn rere Ìjọba rẹ̀. (Mátíù 24:14) Gẹ́gẹ́ bí apá tó gbẹ̀yìn nínú Sáàmù 145 ṣe fi hàn, Dáfídì mọyì ìṣàkóso Ọlọ́rùn gan-an ni, ó sì gbé ipò ọba Ọlọ́run ga. (Sáàmù 145:11, 12) Ǹjẹ́ ìwọ náà mọrírì ọ̀nà onífẹ̀ẹ́ tí Ọlọ́run gbà ń ṣàkóso? Ǹjẹ́ ò sì máa ń bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba rẹ̀ déédéé?
Àwọn Àpẹẹrẹ Tó Fi Títóbi Jèhófà Hàn
7. Sọ ìdí pàtàkì kan tó fi yẹ ká máa yin Jèhófà.
7 Ìwé Sáàmù 145:3 fún wa ní ìdí pàtàkì kan tó fi yẹ ká máa yin Jèhófà. Dáfídì kọrin pé: “Jèhófà tóbi, ó sì yẹ fún ìyìn gidigidi, àwámáridìí sì ni títóbi rẹ̀.” Títóbi Jèhófà kò ní ààlà. Àwámáridìí ló jẹ́ fún àwa èèyàn, a ò lè mọ bó ṣe tóbi tó, a ò sì lè díwọ̀n rẹ̀. Àmọ́ ó dájú pé yóò ṣe wá láǹfààní tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí wo àwọn àpẹẹrẹ títóbi Jèhófà tó jẹ́ àwámáridìí.
8. Kí ni àgbáálá ayé fi hàn nípa títóbi àti agbára Jèhófà?
8 Rántí ìgbà kan tó o wà níbi tí kò ti sí iná mànàmáná tó o sì wá gbójú sókè lálẹ́ láti wo ojú ọ̀run. Ǹjẹ́ kò yà ọ́ lẹ́nu láti rí ẹgbàágbèje àwọn ìràwọ̀ tó hàn kedere lójú òfuurufú tó dúdú lọ rabidun? Ǹjẹ́ èyí kò mú ọ yin Jèhófà nítorí bó ṣe tóbi tó, tó dá gbogbo àwọn ohun tí ń bẹ lójú ọ̀run yìí? Àmọ́, bíńtín ni ohun tó o rí yìí lára iye ìràwọ̀ tó wà nínú ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tí ayé wa yìí jẹ́ apá kan rẹ̀. Láfikún sí i, a fojú bú u pé iye ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tó wà lé ní ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù, mẹ́tà péré ló sì ṣeé fojú rí lára wọn láìlo awò-awọ̀nàjíjìn. Láìsí àní-àní, àìlóǹkà àwọn ìràwọ̀ àtàwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tó para pọ̀ di àgbáálá ayé kíkàmàmà yìí jẹ́ ẹ̀rí tó fi agbára ìṣẹ̀dá Jèhófà àti àwámáridìí títóbi rẹ̀ hàn.—Aísáyà 40:26.
9, 10. (a) Apá tó fi títóbi Jèhófà hàn wo la rí nínú ọ̀ràn Jésù Kristi? (b) Báwo ló ṣe yẹ kí àjíǹde Jésù nípa lórí ìgbàgbọ́ wa?
9 Tún ṣàgbéyẹ̀wò àwọn apá mìíràn tó fi títóbi Jèhófà hàn, ìyẹn àwọn ọ̀ràn nípa Jésù Kristi. A rí títóbi Ọlọ́run nínú bó ṣe dá Ọmọ rẹ̀ tó sì lò ó gẹ́gẹ́ bí “àgbà òṣìṣẹ́” fún àìmọye ọdún. (Òwe 8:22-31) Bí ìfẹ́ Jèhófà ṣe pọ̀ tó hàn kedere nígbà tó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo ṣe ẹbọ ìràpadà fún ìran ènìyàn. (Mátíù 20:28; Jòhánù 3:16; 1 Jòhánù 2:1, 2) Ohun téèyàn ò sì lè lóye rárá ni ara tẹ̀mí ológo tó jẹ́ aláìleèkú tí Jèhófà fún Jésù nígbà tó jí i dìde.—1 Pétérù 3:18.
10 Apá púpọ̀ ló wúni lórí nínú àjíǹde Jésù, tó fi bí títóbi Jèhófà ṣe jẹ́ àwámáridìí hàn. Ó dájú pé Ọlọ́run mú kí Jésù rántí àwọn iṣẹ́ tó ṣe nínú dídá àwọn ohun tí a kò lè rí àti àwọn ohun tí a lè rí. (Kólósè 1:15, 16) Lára ìwọ̀nyí ni àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí mìíràn, àgbáálá ayé, ilẹ̀ ayé tó ń mú èso jáde, àti gbogbo ohun alààyè tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Yàtọ̀ sí pé Jèhófà mú kí Jésù, Ọmọ rẹ̀ rántí gbogbo ìtàn tó mọ̀ nípa àwọn nǹkan ti ọ̀run àti àwọn nǹkan ti orí ilẹ̀ ayé nígbà tí kò tíì di ènìyàn, Ó tún jẹ́ kó rántí àwọn ohun tó ṣe nígbà tó jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn pípé. Dájúdájú, àwámáridìí títóbi Jèhófà hàn kedere nínú àjíǹde Jésù. Kò tán síbẹ̀ o, iṣẹ́ àrà tó ṣe yẹn jẹ́ ẹ̀rí ìdánilójú pé yóò ṣeé ṣe fún àwọn ẹlòmíràn láti ní àjíǹde. Ó sì yẹ kó fún ìgbàgbọ́ wa lókun pé Ọlọ́run lè mú ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn padà bọ̀ sí ìyè, ìyẹn àwọn tó ti kú tí wọ́n sì wà nínú ìrántí rẹ̀ pípé.—Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 17:31.
Àwọn Iṣẹ́ Àgbàyanu àti Ìṣe Agbára Ńlá
11. Iṣẹ́ ńlá wo ni Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa?
11 Jèhófà ti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àgbàyanu àti iṣẹ́ ńlá mìíràn lẹ́yìn àjíǹde Jésù. (Sáàmù 40:5) Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, Jèhófà mú orílẹ̀-èdè tuntun kan wá sójú táyé, ìyẹn “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” tó ní àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi tí a fi ẹ̀mí mímọ́ yàn nínú. (Gálátíà 6:16) Orílẹ̀-èdè tẹ̀mí tuntun yìí tàn ka gbogbo ayé tá a mọ̀ nígbà yẹn lọ́hùn-ún lọ́nà tó kàmàmà. Láìfi ìpẹ̀yìndà tó mú oríṣiríṣi ẹ̀sìn Kristẹni wá sójú táyé lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì Jésù pè, Jèhófà ń ṣe àwọn àgbàyanu iṣẹ́ láti rí i pé àwọn ète òun nímùúṣẹ.
12. Kí ni títúmọ̀ Bíbélì sí àwọn èdè tí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ń sọ jẹ́ ẹ̀rí rẹ̀?
12 Bí àpẹẹrẹ, ó dáàbò bo Bíbélì lódindi, ó sì jẹ́ kó di èyí tá a túmọ̀ sí gbogbo èdè tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ lórí ilẹ̀ ayé lónìí. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé inú ipò líle koko làwọn èèyàn ti túmọ̀ Bíbélì, àwọn aṣojú Sátánì sì máa ń fi ikú halẹ̀ mọ́ àwọn tó bá ń túmọ̀ rẹ̀. Ká sòótọ́, kó sọ́nà tá a fi lè túmọ̀ Bíbélì sí ohun tó lé ní ẹgbàá [2,000] èdè tí kì í bá ṣe ìfẹ́ Jèhófà Ọlọ́run ẹni tí títóbi rẹ̀ jẹ́ àwámáridìí.
13. Báwo ni ohun tí Ìjọba Ọlọ́run fẹ́ ṣe, ṣe fi títóbi Jèhófà hàn kedere látọdún 1914?
13 Ohun tí Ìjọba Ọlọ́run fẹ́ gbé ṣe ti fi títóbi Jèhófà hàn kedere. Bí àpẹẹrẹ, ó gbé Ọmọ rẹ̀ Jésù Kristi gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba ní ọ̀run lọ́dún 1914. Kété lẹ́yìn ìyẹn ni Jésù kọjúùjà sí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀. Ó lé wọn kúrò ní òkè ọ̀run, ò sì fi wọ́n sí àgbègbè ilẹ̀ ayé, níbi tí wọ́n ti ń dúró de ìgbà tá a ó jù wọ́n sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀. (Ìṣípayá 12:9-12; 20:1-3) Àtìgbà yẹn ni àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Jésù ti ń kojú inúnibíni líle koko. Àmọ́, Jèhófà ti mẹ́sẹ̀ wọn dúró láàárín àkókò wíwàníhìn-ín Kristi tí a kò lè fojú rí yìí.—Mátíù 24:3; Ìṣípayá 12:17.
14. Iṣẹ́ àgbàyanu wo ni Jèhófà ṣe lọ́dún 1919, kí ló sì jẹ́ àbájáde rẹ̀?
14 Ní ọdún 1919, Jèhófà tún ṣe iṣẹ́ àgbàyanu mìíràn tó fi títóbi rẹ̀ hàn. Àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Jésù tí wọn ò lè ṣe ohunkóhun mọ́ nípa tẹ̀mí di ẹni tá a tún mú sọjí. (Ìṣípayá 11:3-11) Láti ọdún yẹn wá ni àwọn ẹni àmì òróró ti ń fi ìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba ti ọ̀run tá a ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀. A sì ti kó àwọn ẹni àmì òróró yòókù jọ kí iye àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì náà lè pé. (Ìṣípayá 14:1-3) Jèhófà sì lo àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Kristi láti fi ìpìlẹ̀ “ayé tuntun” lélẹ̀, ìyẹn àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn tó jẹ́ olódodo. (Ìṣípayá 21:1) Ṣùgbọ́n, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí “ayé tuntun” náà lẹ́yìn tí gbogbo àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró bá lọ sọ́run?
15. Iṣẹ́ wo ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ń mú ipò iwájú nínú rẹ̀, kí sì ni àbájáde rẹ̀?
15 Ní 1935, ẹ̀dà August 1 àti ti August 15 ìwé ìròyìn yìí gbé àwọn àpilẹ̀kọ pàtàkì kan jáde tó sọ nípa “ogunlọ́gọ̀ ńlá,” tá a mẹ́nu kàn nínú Ìṣípayá orí keje. Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró bẹ̀rẹ̀ sí fìtara wá àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wọn wọ̀nyí, wọ́n sì ń pè wọ́n láti wá dara pọ̀ mọ́ wọn látinú gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà, ènìyàn, àti ahọ́n. Àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” yìí yóò la “ìpọ́njú ńlá” tó ti sún mọ́lé gan-an nísinsìnyí já, wọ́n sì ní ìrètí gbígbádùn ìyè ayérayé nínú Párádísè gẹ́gẹ́ bí ara àwọn tí yóò wà títí láé nínú “ayé tuntun” náà. (Ìṣípayá 7:9-14) Nítorí iṣẹ́ wíwàásù Ìjọba náà àti ti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn táwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ń mú ipò iwájú nínú rẹ̀ lónìí, ó ti lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà èèyàn báyìí tó ti ní ìrètí wíwà láàyè títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Ta ló yẹ kó gba ìyìn nítorí iye wa tó ń pọ̀ sí i lójú inúnibíni tí Sátánì àti ayé búburú rẹ̀ ń gbé dìde yìí? (1 Jòhánù 5:19) Jèhófà nìkan ṣoṣo ló lè ṣe gbogbo èyí, nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀.—Aísáyà 60:22; Sekaráyà 4:6.
Ọlá Ńlá Ológo àti Iyì Jèhófà
16. Kí nìdí téèyàn ò fi lè fojú rí ‘ọlá ńlá ológo ti iyì Jèhófà’?
16 Ohun yòówù tí wọn ì bàá jẹ́, a ò lè gbàgbé “àwọn iṣẹ́ àgbàyanu” àti “àwọn ìṣe agbára ńlá” Jèhófà láé. Dáfídì kọ̀wé pé: “Ìran dé ìran yóò máa gbóríyìn fún àwọn iṣẹ́ rẹ, àwọn ìṣe agbára ńlá rẹ ni wọn yóò sì máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ọlá ńlá ológo ti iyì rẹ àti ọ̀ràn nípa àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ ni èmi yóò fi ṣe ìdàníyàn mi. Wọn yóò sì máa sọ̀rọ̀ nípa okun àwọn ohun amúnikún-fún-ẹ̀rù rẹ; àti ní ti títóbi rẹ, ṣe ni èmi yóò máa polongo rẹ̀.” (Sáàmù 145:4-6) Níwọ̀n ìgbà tí “Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí” téèyàn ò sì lè fojú rí i, báwo ni Dáfídì ṣe lè mọ̀ nípa ọlá ńlá ológo Jèhófà?—Jòhánù 1:18; 4:24.
17, 18. Báwo ni Dáfídì ṣe lè mọrírì ‘ọlá ńlá ológo ti iyì Jèhófà’?
17 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì ò lè fojú rí Ọlọ́run, síbẹ̀ àwọn ọ̀nà pọ̀ fún Dáfídì láti túbọ̀ mọrírì iyì Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, ó lè kà nípa àwọn ìṣe agbára ńlá Ọlọ́run nínú Ìwé Mímọ́, irú bó ṣe fi ìkún omi tó kárí ayé pa ayé burúkú kan run. Ó sì ṣeé ṣe kí Dáfídì ti gbọ́ nípa bí Ọlọ́run ṣe dójú ti àwọn ọlọ́run èké Íjíbítì tó sì dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò lóko ẹrú àwọn ará Íjíbítì. Irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ jẹ́rìí sí ìyí Jèhófà àti títóbi rẹ̀.
18 Ó dájú pé kì í ṣe kíka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ nìkan ló mú kí Dáfídì mọrírì iyì Ọlọ́run àmọ́ nítorí pé ó tún máa ń ṣe àṣàrò lórí wọn pẹ̀lú. Bí àpẹẹrẹ, ó ti lè ṣàṣàrò lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jèhófà fún Ísírẹ́lì ní Òfin. Ààrá ń sán, mànàmáná sì ń kọ, àwọsánmà ṣíṣú dùdù wà níbẹ̀, wọ́n sì ń gbọ́ ìró ìwo tó ń dún ròkè lálá. Òkè Ńlá Sínáì mì tìtì ó sì rú èéfín. Kódà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kóra jọ sí ẹsẹ̀ òkè ńlá náà gbọ́ “Ọ̀rọ̀ Mẹ́wàá náà” láti àárín iná àti àwọsánmà bí Jèhófà ti ń gba ẹnu áńgẹ́lì tó jẹ́ aṣojú rẹ̀ sọ̀rọ̀. (Diutarónómì 4:32-36; 5:22-24; 10:4; Ẹ́kísódù 19:16-20; Ìṣe 7:38, 53) Èyí mà fi ọlá ńlá Jèhófà hàn o! Kò sí bí ‘ọlá ńlá ológo ti iyì Jèhófà’ kò ṣe ní jẹ́ ìwúrí fún àwọn olùfẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n ń ṣe àṣàrò lórí àwọn ìtàn wọ̀nyí. Odindi Bíbélì làwa náà ní lóde òní, èyí tó ní onírúurú ìran ológo nínú tá a fi mọ̀ pé Jèhófà tóbi lóòótọ́.—Ìsíkíẹ́lì 1:26-28; Dáníẹ́lì 7:9, 10;ṣípayá orí kẹrin.
19. Kí ni yóò jẹ́ ká túbọ̀ mọrírì iyì Jèhófà?
19 Ọ̀nà mìíràn tí iyì Ọlọ́run tún fi lè wọ Dáfídì lọ́kàn ni nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ àwọn òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Diutarónómì 17:18-20; Sáàmù 19:7-11) Ṣíṣe ìgbọràn sí àwọn òfin Jèhófà bu ọlá fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ó sì yà wọ́n sọ́tọ̀ kúrò lára gbogbo àwọn èèyàn yòókù. (Diutarónómì 4:6-8) Gẹ́gẹ́ bí ọ̀ràn ti Dáfídì ṣe rí, kíka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ déédéé, ṣíṣe àṣàrò tó jinlẹ̀ lórí wọn, àti kíkẹ́kọ̀ọ́ wọn taápọntaápọn yóò jẹ́ ká túbọ̀ mọrírì iyì Jèhófà.
Àwọn Ànímọ́ Rere Tí Ọlọ́run Ní Mà Ga Lọ́lá O!
20, 21. (a) Ìwé Sáàmù 145:7-9 fi títóbi Jèhófà hàn nípa títọ́ka sí àwọn ànímọ́ wo? (b) Ipa wo ni àwọn ànímọ́ Ọlọ́run tá a mẹ́nu kàn níbí yìí ní lórí gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀?
20 Gẹ́gẹ́ bá a ti kíyè sí i, àwọn ẹsẹ mẹ́fà àkọ́kọ́ nínú Sáàmù 145 fún wa ní ojúlówó ìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa yin Jèhófà fún àwọn nǹkan tó so pọ̀ mọ́ títóbi rẹ̀ tó jẹ́ àwámáridìí. Ẹsẹ keje sí ìkẹsàn-án fi títóbi Ọlọ́run hàn nípa títọ́ka sí àwọn ànímọ́ rere rẹ̀. Dáfídì kọrin pé: “Wọn yóò máa fi ọ̀yàyà sọ̀rọ̀ nígbà tí wọ́n bá ń mẹ́nu kan ọ̀pọ̀ yanturu oore rẹ, wọn yóò sì fi ìdùnnú ké jáde nítorí òdodo rẹ. Jèhófà jẹ́ olóore ọ̀fẹ́ àti aláàánú, Ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́. Jèhófà ń ṣe rere fún gbogbo gbòò, àánú rẹ̀ sì ń bẹ lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.”
21 Oore àti òdodo Jèhófà ni Dáfídì kọ́kọ́ tẹnu mọ́ níhìn-ín—àwọn ànímọ́ wọ̀nyí sì ni Sátánì Èṣù sọ pé Ọlọ́run kò ní. Ipa wo làwọn ànímọ́ wọ̀nyí ní lórí gbogbo ẹni tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tó sì fara mọ́ ìṣàkóso rẹ̀? Họ́wù, ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń fi ìwà rere àti òdodo ṣàkóso ń mú ayọ̀ wá fún àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ débi pé wọn ò lè ṣe kí wọ́n má máa fi ọ̀yàyà yìn ín. Ìyẹn nìkan kọ́ o, oore Jèhófà tún nasẹ̀ dé ọ̀dọ̀ ‘gbogbo èèyàn.’ A lérò pé èyí yóò ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti ronú pìwà dà, kí wọ́n sì di olùjọsìn Ọlọ́run tòótọ́ náà kó tó pẹ́ jù.—Ìṣe 14:15-17.
22. Báwo ni Jèhófà ṣe ń bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lò?
22 Dáfídì tún mọyì àwọn ànímọ́ tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ fi hàn nígbà tí Ọlọ́run “kọjá níwájú [Mósè] ní pípolongo pé: ‘Jèhófà, Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́.’” (Ẹ́kísódù 34:6) Abájọ tí Dáfídì fúnra rẹ̀ fi polongo pé: “Jèhófà jẹ́ olóore ọ̀fẹ́ àti aláàánú, Ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé títóbi Jèhófà jẹ́ àwámáridìí, síbẹ̀ ó ka àwọn èèyàn tó jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ sí nípa fífi ìyọ́nú bá wọn lò. Ó kún fún àánú, ó sì múra tán láti dárí ji àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù. Jèhófà tún máa ń lọ́ra láti bínú, ìdí nìyẹn tó fi fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láǹfààní láti ṣẹ́pá àwọn ìkùdíẹ̀-káàtó tó lè dí wọn lọ́wọ́ wíwọnú ayé tuntun òdodo rẹ̀.—2 Pétérù 3:9, 13, 14.
23. Ànímọ́ ṣíṣeyebíye wo la ó gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ́ lé e?
23 Dáfídì gbé inú-rere-onífẹ̀ẹ́ tàbí ìfẹ́ dídúróṣinṣin tí Ọlọ́run ní ga. Láìsí àní-àní, bí Jèhófà ṣe fi àwọn ànímọ́ wọ̀nyí hàn àti irú ọwọ́ táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ fi mú inú-rere-onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ni apá tó ṣẹ́ kù nínú Sáàmù 145 fi hàn. Kókó yìí la ó jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Àwọn àǹfààní wo ló wà fún wa láti yin Jèhófà “láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀”?
• Àwọn àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé àwámáridìí ni títóbi Jèhófà?
• Báwo la ṣe lè túbọ̀ mọrírì iyì ológo tí Jèhófà ní?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tó wà lágbàáyé ń fi bí Jèhófà ṣe tóbi tó hàn
[Credit Line]
Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Anglo-Australian Observatory, fọ́tò látọwọ́ David Malin
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Báwo ni títóbi Jèhófà ṣe hàn kedere nínú ọ̀ràn Jésù Kristi?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gba Òfin náà ní Òkè Sínáì, wọ́n rí ẹ̀rí iyì ológo tí Jèhófà ní