Àwọn Wo Ni Yóò Jíǹde?
“Kí ẹnu má yà yín sí èyí, nítorí pé wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀, wọn yóò sì jáde wá.”—JÒHÁNÙ 5:28, 29.
1. Gbólóhùn tó ṣe pàtàkì wo ni Mósè gbọ́ láàárín iná tí ń jó nínú igi kékeré ẹlẹ́gùn-ún, ta ló sì tún gbólóhùn ọ̀hún sọ lẹ́yìn ìgbà náà?
NÍ ẸGBẸ̀RÚN mẹ́tà ààbọ̀ ọdún ó lé díẹ̀ sẹ́yìn, ohun àràmàǹdà kan ṣẹlẹ̀. Mósè ń tọ́jú àwọn àgùntàn bàbá àgbàlagbà kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jẹ́tírò. Áńgẹ́lì Jèhófà yọ sí Mósè látinú iná tó ń jó láàárín igi kékeré ẹlẹ́gùn-ún kan nítòsí Òkè Hórébù. Àkọsílẹ̀ inú ìwé Ẹ́kísódù sọ pé: “Bí ó ti ń wò ó, họ́wù, kíyè sí i, iná ń jó nínú igi kékeré ẹlẹ́gùn-ún náà, síbẹ̀ igi kékeré ẹlẹ́gùn-ún náà kò sì jó.” Lẹ́yìn náà ló gbọ́ ohùn kan tó ń bá a sọ̀rọ̀ láti àárín igi náà. Ohùn náà sọ fún un pé: “Èmi ni Ọlọ́run baba rẹ, Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù.” (Ẹ́kísódù 3:1-6) Jésù, Ọmọ Ọlọ́run fúnra rẹ̀ tún gbólóhùn yìí sọ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Tiwa.
2, 3. (a) Èrè wo ló wà nípamọ́ fún Ábúráhámù, Ísáákì àti Jékọ́bù? (b) Àwọn ìbéèrè wo lèyí sì mú wá?
2 Àwọn Sadusí kan tí wọn ò nígbàgbọ́ nínú àjíǹde ni Jésù ń bá sọ̀rọ̀ lákòókò náà. Jésù sọ pé: “Pé a gbé àwọn òkú dìde ni Mósè pàápàá sọ di mímọ̀, nínú ìròyìn nípa igi kékeré ẹlẹ́gùn-ún, nígbà tí ó pe Jèhófà ní ‘Ọlọ́run Ábúráhámù àti Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù.’ Kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, bí kò ṣe ti àwọn alààyè, nítorí gbogbo wọn wà láàyè lójú rẹ̀.” (Lúùkù 20:27, 37, 38) Gbólóhùn tí Jésù sọ yìí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Ọlọ́run ṣì ń rántí Ábúráhámù, Ísákì, àti Jékọ́bù tí wọ́n ti kú tipẹ́tipẹ́. Bíi ti Jóòbù, àwọn náà ń dúró de ìgbà tí ‘òpò àpàpàǹdodo’ wọn yóò wá sópin, ìyẹn oorun tí wọ́n ń sùn nínú ikú. (Jóòbù 14:14) Ọlọ́run yóò jí wọn dìde sínú ayé tuntun tó ń bọ̀.
3 Àmọ́, ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn èèyàn tí wọ́n ti ń kú látìgbà tí èèyàn ti wà lókè eèpẹ̀ ńkọ́? Ṣé Ọlọ́run yóò jí àwọn náà dìde? Ká lè rí ìdáhùn tó máa tẹ́ wa lọ́rùn, ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa ibi táwọn òkú wà.
Ibo Làwọn Tó Kú Wà
4. (a) Nígbà táwọn èèyàn bá kú, ibo ni wọ́n lọ? (b) Kí ni Ṣìọ́ọ̀lù?
4 Bíbélì sọ pé àwọn òkú “kò mọ nǹkan kan rárá.” Nígbà táwọn èèyàn bá kú, kò sí pé wọ́n ń joró nínú iná ọ̀run àpáàdì tàbí pé wọ́n ń dúró níbì kàn tí ìsìn Kátólíìkì pè ní Limbo, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ni wọ́n kàn padà sínú erùpẹ̀. Ìdí nìyí tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi gba àwọn tó ṣì wà láàyè nímọ̀ràn pé: “Gbogbo ohun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, fi agbára rẹ ṣe é, nítorí pé kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n ní Ṣìọ́ọ̀lù, ibi tí ìwọ ń lọ.” (Oníwàásù 9:5, 10; Jẹ́nẹ́sísì 3:19) Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ni kò gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, “Ṣìọ́ọ̀lù” rí. Èdè Hébérù ni, kò sẹ́ni tó mọ ibi tí ọ̀rọ̀ náà ti ṣẹ̀ wá. Ohun tí ọ̀pọ̀ ìsìn máa ń kọ́ àwọn èèyàn ni pé àwọn òkú ṣì wà láàyè. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní ìmísí ti fi hàn wá, òkú làwọn tó wà ní Ṣìọ́ọ̀lù, wọn ò mọ ohunkóhun rárá. Ipò òkú ni Ṣìọ́ọ̀lù jẹ́.
5, 6. Nígbà tí Jékọ́bù kú, ibo ni wọ́n gbé e lọ, àwọn wo ni wọ́n sì ti sin síbẹ̀ tẹ́lẹ̀?
5 Jẹ́nẹ́sísì 37:35 ni ibi tí “Ṣìọ́ọ̀lù” ti kọ́kọ́ fara hàn nínú Bíbélì. Lẹ́yìn tí Jékọ́bù baba ńlá náà ti rò pé Jósẹ́fù ọmọ òun ọ̀wọ́n ti kú, kò gbà káwọn èèyàn tu òun nínú, kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó sọ ni pé: “Èmi yóò máa bá a lọ láti ṣọ̀fọ̀ ọmọkùnrin mi wọnú Ṣìọ́ọ̀lù!” Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé èrò ọkàn Jékọ́bù ni pé ọmọ òun ti kú, ó gbà kí òun náà kú, kóun sì wà ní Ṣìọ́ọ̀lù. Lẹ́yìn ìgbà náà, àwọn mẹ́sàn-án tó dàgbà lára àwọn ọmọ Jékọ́bù fẹ́ mú Bẹ́ńjámínì tó jẹ́ àbíkẹ́yìn rẹ̀ dání lọ sílẹ̀ Íjíbítì. Wọ́n fẹ́ lọ wá oúnjẹ kí ìyàn kan tó mú má bàa pa wọ́n. Àmọ́, Jékọ́bù kò gbà fún wọn, ó sọ fún wọn pé: “Ọmọkùnrin mi kì yóò bá yín sọ̀ kalẹ̀ lọ, nítorí pé arákùnrin rẹ̀ ti kú, òun nìkan ni ó sì ṣẹ́ kù. Bí jàǹbá aṣekúpani bá ṣẹlẹ̀ sí i lójú ọ̀nà tí ẹ ń lọ, nígbà náà, dájúdájú, ẹ̀yin yóò mú ewú mi sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú Ṣìọ́ọ̀lù pẹ̀lú ẹ̀dùn-ọkàn.” (Jẹ́nẹ́sísì 42:36, 38) Àwọn àkọsílẹ̀ méjèèjì yìí fi hàn pé àwọn òkú ló wà ní Ṣìọ́ọ̀lù, kì í ṣe ibi téèyàn ti ń wà láàyè lẹ́yìn ikú.
6 Àkọsílẹ̀ inú ìwé Jẹ́nẹ́sísì fi hàn pé Jósẹ́fù ti di alábòójútó oúnjẹ nílẹ̀ Íjíbítì. Èyí ló mú kí Jékọ́bù lọ síbẹ̀ kóun àti Jósẹ́fù lè fayọ̀ pàdé ara wọn. Lẹ́yìn náà, Jékọ́bù bẹ̀rẹ̀ sí í gbé nílẹ̀ Íjíbítì títí tó fi darúgbó kùjọ́kùjọ́ tó sì kú lẹ́ni ọdún mẹ́tàdínláàádọ́jọ [147]. Àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe ohun tó sọ pé kí wọ́n ṣe nígbà tó fẹ́ kú, wọ́n gbé òkú rẹ̀ lọ sílẹ̀ Kénáánì wọ́n sì sìn ín sínú hòrò Mákípẹ́là. (Jẹ́nẹ́sísì 47:28; 49:29-31; 50:12, 13) Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sin Jékọ́bù síbi tí wọ́n sin Ísáákì bàbá rẹ̀ àti Ábúráhámù bàbá bàbá rẹ̀ sí.
‘A Kó Wọn Jọpọ̀ Mọ́ Àwọn Baba Ńlá Wọn’
7, 8. (a) Ibo ni Ábúráhámù lọ nígbà tó kú? Ṣàlàyé. (b) Kí ló fi hàn pé àwọn mìíràn náà lọ sí Ṣìọ́ọ̀lù nígbà tí wọ́n kú?
7 Ṣáájú ìgbà yẹn, Jèhófà ti sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Ábúráhámù nígbà tó ń fìdí májẹ̀mú tó bá a dá múlẹ̀ tó sì ń ṣèlérí fún un pé irú ọmọ rẹ̀ yóò di púpọ̀. Jèhófà sọ pé: “Ní tìrẹ, ìwọ yóò lọ sọ́dọ̀ àwọn baba ńlá rẹ ní àlàáfíà; a ó sin ọ́ ní ọjọ́ ogbó gidi gan-an.” (Jẹ́nẹ́sísì 15:15) Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn. Jẹ́nẹ́sísì 25:8 sọ pé: “Lẹ́yìn náà, Ábúráhámù gbẹ́mìí mì, ó sì kú ní ọjọ́ ogbó gidi gan-an, ó darúgbó, ó sì ní ìtẹ́lọ́rùn, a sì kó o jọpọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀.” Ta ni àwọn èèyàn yìí? Jẹ́nẹ́sísì 11:10-26 to orúkọ àwọn baba ńlá Ábúráhámù lẹ́sẹẹsẹ padà sẹ́yìn lọ dé ọ̀dọ̀ Ṣémù tó jẹ́ ọmọ Nóà. Nítorí náà, àwọn tó ti ń sùn ní Ṣìọ́ọ̀lù yìí ni Ọlọ́run kó Ábúráhámù jọ pọ̀ mọ́ nígbà tó kú.
8 Ọ̀pọ̀ ìgbà ni gbólóhùn náà, “kó o jọpọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀” fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù. Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé Ṣìọ́ọ̀lù ni Íṣímáẹ́lì ọmọ Ábúráhámù àti Áárónì arákùnrin Mósè lọ nígbà tí wọ́n kú. Wọ́n ń dúró níbẹ̀ títí dìgbà tí Ọlọ́run á fi jí wọn dìde. (Jẹ́nẹ́sísì 25:17; Númérì 20:23-29) Bákan náà lọ̀rọ̀ ti Mósè rí, Ṣìọ́ọ̀lù lòun náà lọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sẹ́ni tó mọ ibi tí sàréè rẹ̀ wà. (Númérì 27:13; Diutarónómì 34:5, 6) Bẹ́ẹ̀ náà sì ni Jóṣúà tó di aṣáájú orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lẹ́yìn Mósè àti gbogbo ìran àsìkò rẹ̀ ṣe lọ sí Ṣìọ́ọ̀lù nígbà tí wọ́n kú.—Àwọn Onídàájọ́ 2:8-10.
9. (a) Báwo ni Bíbélì ṣe fi hàn pé ibì kan náà ni “Ṣìọ́ọ̀lù” tó jẹ́ ọ̀rọ̀ Hébérù àti “Hédíìsì” tó jẹ́ ọ̀rọ̀ Gíríìkì ń tọ́ka sí? (b) Kí làwọn tó wà ní Ṣìọ́ọ̀lù tàbí Hédíìsì ń dúró dè?
9 Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn ìgbà náà ni Dáfídì di ọba lórí ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá. Nígbà tó kú, ó “dùbúlẹ̀ pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀.” (1 Àwọn Ọba 2:10) Ṣé Ṣìọ́ọ̀lù lòun náà wà? Ó yẹ ká kíyè sí ohun kan, ìyẹn ni pé, lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33, Sànmánì Tiwa, àpọ́sítélì Pétérù sọ̀rọ̀ nípa ikú Dáfídì, ó sì fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Sáàmù 16:10 tó sọ pé: “Ìwọ kì yóò fi ọkàn mi sílẹ̀ sínú Ṣìọ́ọ̀lù.” Lẹ́yìn tí Pétérù ti sọ pé Dáfídì ṣì wà nínú ibojì rẹ̀, ó sọ pé gbólóhùn náà ṣẹ sí Jésù lára ó sì sọ pé Dáfídì “ti rí i tẹ́lẹ̀, ó sì sọ nípa àjíǹde Kristi, pé a kò ṣá a tì sínú Hédíìsì, bẹ́ẹ̀ ni ẹran ara rẹ̀ kò rí ìdíbàjẹ́. Jésù yìí ni Ọlọ́run jí dìde, òtítọ́ tí gbogbo wa jẹ́ ẹlẹ́rìí fún.” (Ìṣe 2:29-32) Ọ̀rọ̀ náà “Hédíìsì” ni Pétérù lò nínú ẹsẹ yìí. Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ èdè Gíríìkì fún “Ṣìọ́ọ̀lù” tó jẹ́ èdè Hébérù. Nípa bẹ́ẹ̀, ipò kan náà làwọn tí Bíbélì sọ pé ó wà ní Hédíìsì àtàwọn tí Bíbélì sọ pé ó wà ní Ṣìọ́ọ̀lù jọ wà. Ńṣe ni wọ́n ń sùn tí wọ́n sì ń dúró de àjíǹde.
Ǹjẹ́ Àwọn Èèyàn Tó Jẹ́ Aláìṣòdodo Wà ní Ṣìọ́ọ̀lù?
10, 11. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé àwọn kan tí wọ́n jẹ́ aláìṣòdodo lọ sí Ṣìọ́ọ̀lù tàbí Hédíìsì nígbà tí wọ́n kú?
10 Lẹ́yìn tí Mósè kó orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì jáde kúrò nílẹ̀ Íjíbítì, ọ̀tẹ̀ kan ṣẹlẹ̀ nínú aginjù. Mósè wá sọ fáwọn èèyàn náà pé kí wọ́n kúrò láàárín àwọn tó dá ọ̀tẹ̀ náà sílẹ̀, ìyẹn Kórà, Dátánì, àti Ábírámù. Wọ́n yóò kú, àmọ́ ikú oró ni wọ́n máa kú. Mósè ṣàlàyé pé: “Bí ó bá jẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ikú gbogbo aráyé ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò fi kú àti pẹ̀lú ìyà gbogbo aráyé ni a ó fi mú ìyà wá sórí wọn, nígbà náà, kì í ṣe Jèhófà ni ó rán mi. Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ ohun kan tí a dá tí Jèhófà yóò dá, tí ilẹ̀ yóò sì la ẹnu rẹ̀ tí yóò sì gbé wọn mì àti ohun gbogbo tí ó jẹ́ tiwọn, dájúdájú, tí wọn yóò sì sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú Ṣìọ́ọ̀lù láàyè, nígbà náà ni ẹ ó mọ̀ dájú pé àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ti hùwà àìlọ́wọ̀ sí Jèhófà.” (Númérì 16:29, 30) Nítorí náà, Ṣìọ́ọ̀lù tàbí Hédíìsì ni gbogbo àwọn ọlọ̀tẹ̀ wọ̀nyí lọ, yálà àwọn tí ilẹ̀ lanu gbé mì tàbí àwọn tí iná jó run, irú bíi Kórà àtàwọn àádọ́ta lé igba [250] àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jọ dìtẹ̀ náà.—Númérì 26:10.
11 Sólómọ́nì tó di ọba lẹ́yìn Dáfídì ló ṣèdájọ́ ikú fún Ṣíméì tó ń ṣẹ́ èpè fún ọba Dáfídì. Dáfídì pàṣẹ fún Sólómọ́nì pé: “Má ṣàìfi ìyà jẹ ẹ́, nítorí ọlọ́gbọ́n ọkùnrin ni ọ́, o sì mọ ohun tí ó yẹ kí o ṣe sí i ní àmọ̀dunjú, kí o sì mú kí ewú rẹ̀ sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Ṣìọ́ọ̀lù pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀.” Sólómọ́nì pàṣẹ fún Bẹnáyà pé kó lọ pa Ṣíméì. (1 Àwọn Ọba 2:8, 9, 44-46) Ẹlòmíràn tí Bẹnáyà tún pa ni Jóábù, olórí ogun Ísírẹ́lì tẹ́lẹ̀. Ewú orí rẹ̀ kò “sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Ṣìọ́ọ̀lù ní àlàáfíà.” (1 Àwọn Ọba 2:5, 6, 28-34) Àwọn àpẹẹrẹ méjèèjì yìí fi hàn pé òótọ́ lohun tí Ọlọ́run mí sí Dáfídì láti kọ lórin pé: “Àwọn ènìyàn burúkú yóò padà sí Ṣìọ́ọ̀lù, àní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó bá gbàgbé Ọlọ́run.”—Sáàmù 9:17.
12. Ta ni Áhítófẹ́lì, ibo ló sì lọ nígbà tó kú?
12 Áhítófẹ́lì lẹni tó máa ń fún Dáfídì ní ìmọ̀ràn. Bí ìgbà tó jẹ́ pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ló fúnni nímọ̀ràn làwọn èèyàn ka ìmọ̀ràn Áhítófẹ́lì sí. (2 Sámúẹ́lì 16:23) Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé, ẹni tí Dáfídì fọkàn tán yìí ló tún wá dà á tó sì lọ dára pọ̀ mọ́ Ábúsálómù ọmọ Dáfídì nínú ọ̀tẹ̀ tó ń dì láti gbàjọba. Ó ní láti jẹ́ ìwà ọ̀dàlẹ̀ tí Áhítófẹ́lì hù yìí ni Dáfídì ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tó kọ̀wé pé: “Kì í ṣe ọ̀tá ni ó bẹ̀rẹ̀ sí gàn mí; bí bẹ́ẹ̀ bá ni, èmi ì bá fara dà á. Kì í ṣe ẹni tí ó kórìíra mi lọ́nà gbígbóná janjan ni ó gbé àgbéré ńláǹlà sí mi; bí bẹ́ẹ̀ bá ni, èmi ì bá fi ara mi pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.” Dáfídì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Kí ìsọdahoro dé bá wọn! Kí wọ́n sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú Ṣìọ́ọ̀lù láàyè; nítorí pé nígbà tí wọ́n ń ṣe àtìpó ni àwọn nǹkan búburú ti wà nínú wọn.” (Sáàmù 55:12-15) Nígbà tí Áhítófẹ́lì àtàwọn ìsọ̀ǹgbè rẹ̀ kú, inú Ṣìọ́ọ̀lù ni wọ́n lọ.
Àwọn Wo Ló Wà ní Gẹ̀hẹ́nà?
13. Kí nìdí tí Jésù fi pe Júdásì ní “ọmọ ìparun”?
13 Wo bí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì ṣe fara jọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù, ìyẹn Dáfídì Títóbi jù. Júdásì Ísíkáríótù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì méjìlá tí Kristi ní di ọ̀dàlẹ̀ bíi ti Áhítófẹ́lì. Ìwà ọ̀dàlẹ̀ ti Júdásì tiẹ̀ tún burú ju ti Áhítófẹ́lì lọ nítorí pé Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run ni Júdásì dà. Nínú àdúrà kan tí Ọmọ Ọlọ́run gbà níparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ó sọ fún Ọlọ́run nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Nígbà tí mo wà pẹ̀lú wọn, mo ti máa ń ṣọ́ wọn ní tìtorí orúkọ rẹ, èyí tí ìwọ ti fi fún mi; mo sì ti pa wọ́n mọ́, kò sì sí ọ̀kan lára wọn tí ó pa run àyàfi ọmọ ìparun, kí a lè mú ìwé mímọ́ ṣẹ.” (Jòhánù 17:12) Níwọ̀n bí Jésù ti pe Júdásì ní “ọmọ ìparun” níhìn-ín, ohun tó ń sọ ni pé nígbà tí Júdásì kú, kò sí ìrètí pé yóò jíǹde. Kò sí lára àwọn tí Ọlọ́run ń rántí wọn. Kò lọ sí Ṣìọ́ọ̀lù, inú Gẹ̀hẹ́nà ló lọ. Kí ni Gẹ̀hẹ́nà?
14. Kí ni Gẹ̀hẹ́nà dúró fún?
14 Jésù bẹnu àtẹ́ lu àwọn aṣáájú ìsìn ìgbà ayé rẹ̀ nítorí pé wọ́n sọ gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn wọn di èrò Gẹ̀hẹ́nà. (Mátíù 23:15) Lákòókò yẹn, àwọn èèyàn mọ ibi tó ń jẹ́ Àfonífojì Hínómù dáadáa. Ó jẹ́ ibi tí wọ́n máa ń da pàǹtírí sí tí wọ́n sì ń ju òkú àwọn ọ̀daràn tí wọ́n bá pa sí, ìyẹn àwọn tí wọ́n gbà pé ìsìnkú gidi ò tọ́ sí. Ṣáájú ìgbà yẹn, Jésù fúnra rẹ̀ ti kọ́kọ́ lo ọ̀rọ̀ náà, Gẹ̀hẹ́nà, nínú Ìwàásù rẹ̀ lórí Òkè. (Mátíù 5:29, 30) Ohun tó fẹ́ fà yọ tó fi lo ọ̀rọ̀ yìí yé àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ìparun yán-ányán-án ni Gẹ̀hẹ́nà dúró fún, kò sí ìrètí pé àwọn tó wà níbẹ̀ yóò jíǹde. Yàtọ̀ sí Júdásì Ísíkáríótù, ǹjẹ́ àwọn mìíràn tún ti lọ sí Gẹ̀hẹ́nà nígbà tí wọ́n kú dípò Ṣìọ́ọ̀lù tàbí Hédíìsì?
15, 16. Àwọn wo ló lọ sí Gẹ̀hẹ́nà nígbà tí wọ́n kú, kí sì nìdí tí wọ́n fi lọ síbẹ̀?
15 Èèyàn pípé ni Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà, ìyẹn ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́. Ńṣe ni wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ dá ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá. Ohun tó wà níwájú wọn láti yàn ni ìyè ayérayé tàbí ikú. Wọ́n ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run wọ́n sì fara mọ́ Sátánì. Nígbà tí wọ́n kú, kò sírètí fún wọn láti jàǹfààní nínú ẹbọ ìràpadà Kristi. Kàkà bẹ́ẹ̀, Gẹ̀hẹ́nà ni wọ́n lọ.
16 Kéènì tó jẹ́ àkọ́bí Ádámù pa Ébẹ́lì àbúrò rẹ̀ ó sì di ìsáǹsá lẹ́yìn náà. Àpọ́sítélì Jòhánù pe Kéènì ní “ẹni tí ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 3:12) Ó bọ́gbọ́n mu láti sọ pé Gẹ̀hẹ́nà lòun náà lọ nígbà tó kú bíi tàwọn òbí rẹ̀. (Mátíù 23:33, 35) Àmọ́ ọ̀rọ̀ ti Ébẹ́lì tó jẹ́ olódodo yàtọ̀ pátápátá! Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni Ébẹ́lì rú ẹbọ tí ó níye lórí ju ti Kéènì sí Ọlọ́run, nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ náà tí ó fi ní ẹ̀rí tí a jẹ́ sí i pé ó jẹ́ olódodo, tí Ọlọ́run ń jẹ́rìí nípa àwọn ẹ̀bùn rẹ̀.” Pọ́ọ̀lù fi kún un pé, “àti nípasẹ̀ èyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó kú, ó ń sọ̀rọ̀ síbẹ̀.” (Hébérù 11:4) Dájúdájú, Ṣìọ́ọ̀lù ni Ébẹ́lì wà báyìí tó ń dúró de àjíǹde.
Àjíǹde “Àkọ́kọ́” àti Àjíǹde tó “Dára Jù”
17. (a) Ní “àkókò òpin” yìí, àwọn wo ló ń lọ sí Ṣìọ́ọ̀lù? (b) Kí ni ìrètí àwọn tó wà ní Ṣìọ́ọ̀lù, kí ló sì máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tó wà ní Gẹ̀hẹ́nà?
17 Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń kà nípa ọ̀rọ̀ tá a ti ń sọ bọ̀ yìí ni yóò máa ronú nípa ibi tí àwọn èèyàn tó ń kú ní “àkókò òpin” yìí ń lọ. (Dáníẹ́lì 8:19) Ìwé Ìṣípayá orí kẹfà sọ nípa àwọn agẹṣin mẹ́rin kan tí wọ́n ń gẹṣin lọ lákòókò òpin yìí. Ohun kan tó yẹ ká kíyè sí nínú àkọsílẹ̀ náà ni pé, Ikú lorúkọ èyí tó kẹ́yìn lára wọn, Hédíìsì sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. Nítorí náà, Hédíìsì ni ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó ń kú ikú òjijì lákòókò yìí ń lọ, ìyẹn àwọn tó ń kú nítorí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ táwọn agẹṣin tó ṣáájú fà. Wọ́n á wà níbẹ̀ títí dìgbà tí Ọlọ́run á jí wọn dìde sínú ayé tuntun tó ń bọ̀. (Ìṣípayá 6:8) Kí wá ni ìrètí àwọn tó wà ní Ṣìọ́ọ̀lù tàbí Hédíìsì, kí sì ni ìrètí àwọn tó wà ní Gẹ̀hẹ́nà? Ní ṣókí, àwọn tó wà ní Ṣìọ́ọ̀lù yóò jíǹde, àmọ́ kò sí àjíǹde fún àwọn tó wà ní Gẹ̀hẹ́nà, ìparun ayérayé ni tiwọn.
18. Àǹfààní wo ni àwọn tó ní “àjíǹde èkíní” yóò ní?
18 Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Aláyọ̀ àti mímọ́ ni ẹnikẹ́ni tí ó ní ipa nínú àjíǹde èkíní; ikú kejì kò ní àṣẹ kankan lórí àwọn wọ̀nyí, ṣùgbọ́n wọn yóò jẹ́ àlùfáà Ọlọ́run àti ti Kristi, wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú rẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún ọdún náà.” “Àjíǹde èkíní” ni ti Jésù àtàwọn tí wọ́n máa bá a ṣàkóso, àmọ́ kí ni ìrètí gbogbo aráyé yòókù?—Ìṣípayá 20:6.
19. Ọ̀nà wo làwọn kan máa gbà jàǹfààní nínú “àjíǹde tí ó sàn jù”?
19 Láti ayé Èlíjà àti Èlíṣà tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni àjíǹde tó jẹ́ iṣẹ́ ìyanu ti ń mú káwọn èèyàn tún padà wà láàyè. Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa àwọn àjíǹde tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn pé: “Àwọn obìnrin rí àwọn òkú wọn gbà nípa àjíǹde; ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin mìíràn ni a dá lóró nítorí pé wọn kò jẹ́ tẹ́wọ́ gba ìtúsílẹ̀ nípa ìràpadà kankan, kí ọwọ́ wọn lè tẹ àjíǹde tí ó sàn jù.” Dájúdájú, àjíǹde táwọn tó ṣe olóòótọ́ títí dójú ikú yìí ń dúró de jẹ́ àjíǹde tó sàn jù ní ti pé, kì í ṣe pé wọ́n á kàn wà láàyè fún ọdún bíi mélòó kan tí wọ́n á sì kú, àmọ́ wọ́n á wà láàyè títí láé! Kò sí àní-àní pé “àjíǹde tí ó sàn jù” ni yóò jẹ́ lóòótọ́.—Hébérù 11:35.
20. Kí la óò jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí?
20 Bá a bá jẹ́ olóòótọ́ títí dòpin tá a sì kú kí Jèhófà tó fòpin sí ètò àwọn nǹkan búburú yìí, ìrètí wa dájú pé a óò ní “àjíǹde tí ó sàn jù” ní ti pé a nírètí láti wà láàyè títí ayé. Jésù ṣèlérí pé: “Kí ẹnu má yà yín sí èyí, nítorí pé wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀, wọn yóò sì jáde wá.” (Jòhánù 5:28, 29) Àpilẹ̀kọ wa tó tẹ̀ lé èyí yóò túbọ̀ jíròrò ìdí tí Ọlọ́run fi ṣètò fún àjíǹde. Yóò tún jẹ́ ká rí bí ìrètí àjíǹde ṣe ń fún ìgbàgbọ́ wa lágbára ká lè máa jẹ́ olóòótọ́ nìṣó ká sì lè máa ní ẹ̀mí ìyọ̀ǹda ara ẹni.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí nìdí tí Bíbélì fi pe Jèhófà ní Ọlọ́run “àwọn alààyè”?
• Ipò wo làwọn tó wà ní Ṣìọ́ọ̀lù wà?
• Kí ni ìpín àwọn tó wà ní Gẹ̀hẹ́nà?
• Ọ̀nà wo làwọn kan á gbà jàǹfààní látinú “àjíǹde tí ó sàn jù”?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Àwọn tó wà ní Ṣìọ́ọ̀lù ń retí àjíǹde bíi ti Ábúráhámù,
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Gẹ̀hẹ́nà ni Ádámù, Éfà, Kéènì, àti Júdásì Ísíkáríótù lọ?