ORÍ 5
Agbára Ìṣẹ̀dá —“Aṣẹ̀dá Ọ̀run àti Ayé”
1, 2. Báwo ni oòrùn ṣe jẹ́rìí sí i pé agbára Jèhófà Ẹlẹ́dàá pọ̀ gan-an?
ṢÉ O ti yáná rí nígbà òtútù? Bóyá ńṣe lo rọra ń fọwọ́ ra iná yẹn kó o lè gbádùn ooru tó ń ti ibẹ̀ jáde. Tó o bá sún mọ́ iná yẹn jù, ó máa ta ẹ́ lára. Tó o bá sì jìnnà sí i jù, òtútù lè bẹ̀rẹ̀ sí í mú ẹ.
2 A lè fi oòrùn wé “iná” tó máa ń rani lára. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, oòrùn fi nǹkan bí àádọ́jọ mílíọ̀nù (150,000,000) kìlómítà jìnnà sí ayé!a Ẹ ò rí i pé agbára oòrùn pọ̀ gan-an, tó fi lè máa rà wá lára pẹ̀lú bá a ṣe jìnnà sí i tó! Síbẹ̀, ó gbàfiyèsí pé ibi tó yẹ kí ayé wà gẹ́lẹ́ ló wà. Kò jìnnà jù sí oòrùn, bẹ́ẹ̀ ní kò sún mọ́ ọn jù. Tí ayé bá sún mọ́ ọn jù, ooru rẹ̀ á fa gbogbo omi ayé gbẹ; tó bá sì jìnnà sí i jù, gbogbo omi tó wà láyé á di yìnyín. Tí èyíkéyìí nínú méjèèjì bá ṣẹlẹ̀, kò ní sí ohun alààyè kankan tó máa wà láyé. Ohun kan náà ló máa ṣẹlẹ̀ tí kò bá sí oòrùn rárá. Ká sòótọ́, kòṣeémáàní ni oòrùn, ó máa ń jẹ́ kí ibi gbogbo mọ́lẹ̀ kedere, kò síbi tí kò dé, kì í ba afẹ́fẹ́ jẹ́, ó sì máa ń ṣe wá láǹfààní gan-an.—Oníwàásù 11:7.
3. Kí ni oòrùn kọ́ wa nípa Jèhófà?
3 Òótọ́ ni pé oòrùn wà lára ohun tó máa ń gbé ẹ̀mí wa ró, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò fiyè sí i. Ìyẹn ò jẹ́ kí wọ́n lè ronú nípa ọ̀pọ̀ nǹkan tí wọ́n lè kọ́ látara oòrùn. Bíbélì sọ pé ‘Jèhófà ló ṣe ìmọ́lẹ̀ àti oòrùn.’ (Sáàmù 74:16) Ó dájú pé oòrùn ń fògo fún Jèhófà tó jẹ́ “Aṣẹ̀dá ọ̀run àti ayé.” (Sáàmù 19:1; 146:6) Àmọ́, ṣe ló wulẹ̀ jẹ́ ọkàn lára àìmọye ìràwọ̀ tó jẹ́rìí sí i pé agbára tí Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa ní kò láfiwé. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára àwọn ìṣẹ̀dá ojú ọ̀run yìí, lẹ́yìn náà a máa sọ̀rọ̀ nípa ayé àtàwọn nǹkan tí Jèhófà dá sínú rẹ̀.
‘Jèhófà ló ṣe ìmọ́lẹ̀ àti oòrùn’
“Ẹ Gbé Ojú Yín Sókè Ọ̀run, Kí Ẹ sì Wò Ó”
4, 5. Báwo ni oòrùn ṣe lágbára tó, báwo ló sì ṣe tóbi tó, síbẹ̀ ṣe òun ló tóbi jù nínú gbogbo ìràwọ̀?
4 Oòrùn jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìràwọ̀ tó wà lójú ọ̀run. Ohun tó jẹ́ kó dà bíi pé ó tóbi ju àwọn ìràwọ̀ tí à ń rí lálẹ́ ni pé ó sún mọ́ ayé jù wọ́n lọ. Báwo ló ṣe lágbára tó? Tá a bá fi ohun tí wọ́n fi ń díwọ̀n bí nǹkan ṣe gbóná tó wọn ibi tó gbóná jù nínú oòrùn, á gbóná tó mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15,000,000°C) lórí òṣùwọ̀n náà. Ká sọ pé o lè mú èyí tí kò ju orí abẹ́rẹ́ lọ lára oòrùn wá sí ayé yìí, ìwọ̀n bíńtín yẹn á gbóná débi pé o ò ní lè dúró ní nǹkan bí ogóje (140) kìlómítà síbi tó bá wà! Ńṣe ni agbára tó ń ti ara oòrùn jáde ní ìṣẹ́jú àáyá kọ̀ọ̀kan dà bí ìgbà tí ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù bọ́ǹbù átọ́míìkì bá bú gbàù pa pọ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.
5 Oòrùn tóbi débi pé tí wọ́n bá kó mílíọ̀nù kan àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (1,300,000) ayé yìí sínú ẹ̀, ńṣe ló máa gbé e mì. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé oòrùn ló tóbi jù nínú àwọn ìràwọ̀ tó wà lójú ọ̀run? Rárá, nítorí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé àwọn ìràwọ̀ kan wà tó tún tóbi ju oòrùn lọ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé “ògo ìràwọ̀ kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ síra.” (1 Kọ́ríńtì 15:41) Ó dájú pé ẹ̀mí mímọ́ ló mú kó sọ ọ̀rọ̀ yìí. Ìràwọ̀ kan wà tó tóbi débi pé tí wọ́n bá gbé e sí ibi tí oòrùn wà gangan, ó fẹ̀ débi pé á bo ayé mọ́lẹ̀. Ìràwọ̀ ńlá míì tún wà tó jẹ́ pé tí wọ́n bá gbé òun náà síbi tí oòrùn wà, ó fẹ̀ débi pé á dé ibi tí pílánẹ́ẹ̀tì tó ń jẹ́ Saturn wà. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, Saturn yìí jìnnà sí ayé gan-an débi pé ìrìn ọdún mẹ́rin gbáko láìdúró ni ọkọ̀ tí wọ́n fi ń rìnrìn àjò ojú sánmà á rìn kó tó débẹ̀. Ọkọ̀ yìí sì máa ń sáré gan-an ní ìlọ́po ogójì ju bí ọta ìbọn ṣe máa ń fò jáde lẹ́nu ìbọn lọ!
6. Báwo ni Bíbélì ṣe fi hàn pé ìràwọ̀ tó wà lójú ọ̀run pọ̀ ju ìwọ̀nba táwa èèyàn lè fojú rí lọ?
6 Yàtọ̀ sí bí àwọn ìràwọ̀ ṣe tóbi tó, ohun míì tó tún yani lẹ́nu ni bí wọ́n ṣe pọ̀ tó. Kódà, Bíbélì sọ pé bó ṣe jẹ́ pé kò sí èèyàn tó lè ka “iyanrìn òkun,” bẹ́ẹ̀ náà ni kò sí èèyàn tó lè ka iye ìràwọ̀. (Jeremáyà 33:22) Èyí fi hàn pé àìmọye ìràwọ̀ ló wà tá ò lè fojú lásán rí. Ká sọ pé ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì bíi Jeremáyà bá wo ojú ọ̀run lálẹ́, tó sì gbìyànjú láti ka iye ìràwọ̀ tó rí, kò ní lè kà ju nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) lọ. Téèyàn bá gbójú sókè nígbà tójú ọ̀run bá mọ́lẹ̀ kedere lálẹ́, ìràwọ̀ téèyàn lè fojú kà láìlo ohun tí wọ́n fi ń wo ọ̀nà jíjìn kò ju iye yẹn náà lọ. Ńṣe ni èyí dà bí ìgbà téèyàn bá kàn bu ẹ̀kúnwọ́ iyanrìn kan péré lára gbogbo iyanrìn òkun. Ká sòótọ́, òbítíbitì ìràwọ̀ ló wà lójú ọ̀run, ṣe ló pọ̀ bí iyanrìn etí òkun.b Ta ló wá lè ka iye wọn tán?
7. Kí làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì rò nípa iye ìràwọ̀ tó wà nínú ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Milky Way tàbí iye ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tó wà lágbàáyé?
7 Àìsáyà 40:26 dáhùn pé: “Ẹ gbé ojú yín sókè ọ̀run, kí ẹ sì wò ó. Ta ló dá àwọn nǹkan yìí? Òun ni Ẹni tó ń mú wọn jáde bí ẹgbẹ́ ọmọ ogun ní iye-iye; Ó ń fi orúkọ pe gbogbo wọn.” Sáàmù 147:4 sọ pé: “Ó ń ka iye àwọn ìràwọ̀.” Àmọ́, ìràwọ̀ mélòó ló wà? Kò rọrùn láti dáhùn ìbéèrè yìí. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì fojú bù ú pé ohun tó ju ọgọ́rùn-ún kan bílíọ̀nù ìràwọ̀ ló wà nínú ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Milky Way nìkan.c Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì míì tiẹ̀ tún sọ pé ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àìmọye ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ míì ṣì wà tó jẹ́ pé iye ìràwọ̀ tó wà nínú wọn pọ̀ ju ti Milky Way lọ dáadáa. Ó dáa, ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ mélòó ló wà? Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé wọ́n tó ọgọ́rọ̀ọ̀rún bílíọ̀nù. Títí di báyìí, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ò lè sọ iye ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tó wà lágbàáyé, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti pé wọ́n máa mọ iye bílíọ̀nù ìràwọ̀ tó wà nínú gbogbo wọn lápapọ̀. Àmọ́, Jèhófà mọ àròpọ̀ iye wọn. Kódà, ó tún fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn lórúkọ!
8. (a) Báwo ni ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Milky Way ṣe tóbi tó? (b) Kí ló ń darí àwọn ìṣẹ̀dá inú òfúrufú?
8 Tá a bá tún wá wo bí àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ ṣe tóbi tó, ẹ̀rù Ọlọ́run á túbọ̀ bà wá. Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká fi bí ìtànṣán iná ṣe máa ń yára rìn tó ṣàlàyé bí ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Milky Way ṣe tóbi tó. Téèyàn bá tan iná lára ògiri, báwo ló ṣe máa ń pẹ́ tó kó tó mọ́lẹ̀ yòò? Kíákíá ni. Tẹ́nì kan bá ń yára sáré bẹ́ẹ̀, onítọ̀hún á ṣì lò tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún (100,000) ọdún kó tó rìn láti ìbẹ̀rẹ̀ Milky Way débi tó parí sí! Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ kan tún wà tí wọ́n tóbi ju Milky Way lọ ní ìlọ́po-ìlọ́po. Bíbélì sọ pé ńṣe ni Jèhófà “na ọ̀run” bí ìgbà téèyàn kàn ta aṣọ lásán. (Sáàmù 104:2) Òun náà ló tún pàṣẹ pé káwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ náà máa lọ láti ibì kan síbòmíì, kí wọ́n sì máa yí po. Gbogbo ìṣẹ̀dá inú gbalasa òfúrufú yìí, látorí èyí tó kéré jù lọ dórí èyí tó tóbi jù lọ, ló ń lọ láti ibì kan síbòmíì níbàámu pẹ̀lú àwọn òfin tí Ọlọ́run là sílẹ̀ pé kí wọ́n máa tẹ̀ lé. Wọ́n sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tó ṣe rẹ́gí àti létòlétò. (Jóòbù 38:31-33) Èyí ló mú káwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé ọ̀nà táwọn nǹkan tó wà ní gbalasa òfúrufú ń gbà lọ láti ibì kan sí ibòmíì dà bí ìgbà táwọn oníjó bá ń dárà lójú agbo! Ronú nípa ẹni tó dá gbogbo nǹkan yìí. Ó dájú pé o máa gbà pé Ọlọ́run tí ọgbọ́n àti agbára rẹ̀ kò láfiwé ló dá wọn.
“Aṣẹ̀dá Ayé Tó Fi Agbára Rẹ̀ Dá A”
9, 10. Báwo ni ibi tí ayé wà láàárín àwọn pílánẹ́ẹ̀tì tó kù ṣe fi hàn pé Jèhófà tóbi lọ́ba?
9 Tá a bá ronú nípa ibi tí ayé yìí wà, a máa rí i pé Jèhófà tóbi lọ́ba. Ibi tó dáa jù ló dá ayé yìí sí. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan gbà pé ọ̀pọ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ ló wà tó jẹ́ pé ká ní ibẹ̀ layé wà ni, ohun alààyè kankan ò ní lè gbé ibẹ̀. Kódà, ìwádìí fi hàn pé ọ̀pọ̀ ìràwọ̀ tó wà nínú ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Milky Way tí ayé wà nínú ẹ̀ ló jẹ́ pé kò sí ohun alààyè kankan tó lè gbébẹ̀. Ìràwọ̀ tó wà láàárín ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ yìí pọ̀ gan-an, ìtànṣán olóró sì pọ̀ gan-an níbẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ìràwọ̀ tó wà níbẹ̀ máa ń fẹ́rẹ̀ẹ́ kọ lura. Bákan náà, ọ̀pọ̀ ohun tó jẹ́ kòṣeémánìí fún ẹ̀dá alààyè ní kò sí ní eteetí ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ yìí. Ṣùgbọ́n ibi tó yẹ gẹ́lẹ́ ni Ọlọ́run gbé oòrùn àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì tó ń yí i po sí.
10 Pílánẹ́ẹ̀tì ńlá kan wà tó ń jẹ́ Jupiter, ó jìn gan-an sí ayé, àmọ́ ó máa ń dáàbò bo ayé. Pílánẹ́ẹ̀tì yìí tóbi ju Ayé lọ ní ìlọ́po ẹgbẹ̀rún, agbára òòfà rẹ̀ sì pọ̀ gan-an. Tí àwọn nǹkan eléwu bá ń já bọ̀ láti gbalasa òfúrufú, ńṣe ni òòfà rẹ̀ máa ń bá wa fà á mọ́ra tàbí kó tì í dà nù. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé, tí kì í bá ṣe ti Jupiter yìí ni, àwọn ohun eléwu tó dà bí òkúta ràbàtà-ràbàtà tí ì bá máa rọ́ lu ayé yìí á pọ̀ gan-an ni. Jèhófà tún wá ṣe ohun àrà ọ̀tọ̀ kan tó wúlò gan-an fún ayé, ìyẹn òṣùpá. Yàtọ̀ sí pé òṣùpá rẹwà gan-an tó sì ń fún wa ni ìmọ́lẹ̀ lóru, ó tún ń mú kí ayé rọra dagun díẹ̀. Bí ayé ṣe dagun yìí ló mú ká lè máa ní onírúurú ìgbà tí kì í yẹ̀ lọ́dọọdún, èyí sì wà lára ohun pàtàkì tó ń mú káyé tura.
11. Báwo ni òfúrufú ṣe dà bí agboòrùn tó ń dáàbò bo ayé?
11 Gbogbo ohun tó wà láyé pátá ló ń jẹ́rìí sí i pé Jèhófà tóbi lọ́ba. Bí àpẹẹrẹ, òfúrufú dà bí agboòrùn tó ń dáàbò bo ayé yìí. Ìtànṣán tó dáa àti èyí tó léwu ló ń wá látinú oòrùn. Nígbà tí èyí tó léwu bá dé apá òkè òfúrufú, ó máa ń mú kí afẹ́fẹ́ ọ́síjìn di afẹ́fẹ́ tó léwu tí wọ́n ń pè ní afẹ́fẹ́ ozone. Afẹ́fẹ́ ozone yìí á wá bo òkè òfúrufú, òun ló sì máa ń gba ìtànṣán tó léwu náà sára. Èyí jẹ́ ká rí i pé ayé yìí ní ohun tó ń dáàbò bò ó!
12. Báwo ni omi tó ń yí po nínú ayé ṣe fi hàn pé Jèhófà tóbi lọ́ba?
12 Yàtọ̀ sí pé òfúrufú máa ń dáàbò bo ayé lọ́wọ́ ìtànṣán oòrùn, ó tún máa ń tún afẹ́fẹ́ ṣe, ó sì máa ń ṣe àwọn nǹkan míì káwọn ohun alààyè lè máa gbé ayé. Ọ̀nà àrà míì tó tún ń gbà ṣe ayé láǹfààní ni pé ó máa ń jẹ́ kí omi yí po nínú ayé. Lójoojúmọ́, omi tí oòrùn ń fà sókè látinú àwọn òkun fẹ́rẹ̀ẹ́ tó tírílíọ̀nù méje (7,000,000,000,000) dúrọ́ọ̀mù. Omi tó fà sókè yìí á di ìkùukùu, afẹ́fẹ́ á sì tú u ká sójú ọ̀run. Láàárín àkókò yìí, ohun àrà kan á ti ṣẹlẹ̀ tó máa yọ ìdọ̀tí kúrò nínú omi náà. Omi tó mọ́ lóló á wá rọ̀ bí òjò, yìnyín tàbí ìrì. Bí Oníwàásù 1:7 ṣe sọ ọ́ gẹ́lẹ́ ló rí, ó ní: “Gbogbo odò ló ń ṣàn lọ sínú òkun, síbẹ̀ òkun kò kún. Ibi tí àwọn odò ti ṣàn wá, ibẹ̀ ni wọ́n ń pa dà sí, kí wọ́n tún lè ṣàn jáde.” Ẹ ò rí i pé ọ̀nà àrà gbáà ni Jèhófà gbà ṣètò bí omi ṣe ń yí po nínú ayé!
13. Báwo làwọn ewéko àti ilẹ̀ ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run tóbi lọ́ba?
13 Kò síbi tá a yíjú sí láyé yìí tá ò ní rí ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run tóbi lọ́ba. Bí àpẹẹrẹ, à ń rí ọwọ́ agbára ńlá rẹ̀ nínú àwọn nǹkan àrà tó dá, irú bí àwọn igi ńláńlá bí igi sequoia tó máa ń ga ju ilé tó ní ọgbọ̀n àjà, títí dórí àwọn ohun tín-tìn-tín tó wà nínú òkun tó jẹ́ pé àwọn ló ń pèsè èyí tó pọ̀ jù lára afẹ́fẹ́ oxygen tá à ń mí sínú. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ nǹkan àgbàyanu ló wà nínú ilẹ̀, lára wọn ni àwọn kòkòrò, olú àtàwọn nǹkan tín-tìn-tín míì tó ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ lọ́nà àrà káwọn ewéko lè máa hù kí wọ́n sì máa dàgbà. Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé ilẹ̀ ní agbára.—Jẹ́nẹ́sísì 4:12, àlàyé ìsàlẹ̀.
14. Báwo ni ohun bíńtín kan tí wọ́n ń pè ní átọ́ọ̀mù ṣe lágbára tó?
14 Ó hàn kedere pé Jèhófà ni “Aṣẹ̀dá ayé,” “agbára rẹ̀” ló sì fi dá a. (Jeremáyà 10:12) Kódà, a rí ọwọ́ agbára rẹ̀ nínú àwọn nǹkan tín-tìn-tín tó dá. Bí àpẹẹrẹ, tí wọ́n bá to mílíọ̀nù kan átọ́ọ̀mù jọ sẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn, gbogbo ẹ̀ ò lè nípọn tó ọ̀kan ṣoṣo lára irun orí àwa èèyàn. Síbẹ̀, ohun bíńtín tó wà láàárín átọ́ọ̀mù yìí ni wọ́n fi ń ṣe bọ́ǹbù tó lágbára gan-an tó lè ba ọ̀pọ̀ nǹkan jẹ́!
“Gbogbo Ohun Tó Ń Mí”
15. Kí ni Jèhófà fẹ́ kọ́ Jóòbù nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹranko tó lágbára?
15 Ẹ̀rí míì tó fi hàn pé Jèhófà tóbi lọ́ba ni oríṣiríṣi àwọn ẹranko tó wà láyé. Sáàmù 148 sọ̀rọ̀ nípa oríṣiríṣi àwọn nǹkan tó ń yin Jèhófà, ẹsẹ kẹwàá mẹ́nu kan ‘ẹranko igbó àtàwọn ẹran ọ̀sìn.’ Nígbà kan tí Jèhófà ń kọ́ Jóòbù lẹ́kọ̀ọ́ kó lè mọ̀ pé òun tóbi lọ́ba, ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹranko bíi kìnnìún, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà, akọ màlúù igbó, Béhémótì (tàbí erinmi) àti Léfíátánì (tàbí ọ̀nì). Ìdí tí Jèhófà fi sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹranko yìí ni pé ó fẹ́ kí Jóòbù mọ̀ pé táwa èèyàn bá lè máa bẹ̀rù àwọn ẹranko tó lágbára yìí, ó yẹ ká bẹ̀rù ẹni tó dá wọn ju bá a ṣe bẹ̀rù wọn lọ.—Jóòbù orí 38 sí 41.
16. Kí ló wú ẹ lórí nípa àwọn ẹyẹ tí Jèhófà dá?
16 Sáàmù 148:10 tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn “ẹyẹ abìyẹ́.” Ronú nípa oríṣiríṣi ẹyẹ tó wà láyé! Jèhófà sọ fún Jóòbù pé ògòǹgò ń “fi ẹṣin àti ẹni tó gùn ún rẹ́rìn-ín.” Ẹyẹ yìí ga dé àtẹ́rígbà ilé, bẹ́ẹ̀ sì rèé kò lè fò, àmọ́ láàárín wákàtí kan, ó lè sáré dé ibi tó jìn tó kìlómítà márùnlélọ́gọ́ta (65). Kódà tó bá ń sáré, ìṣísẹ̀ rẹ̀ kan ṣoṣo tó mítà mẹ́rin ààbọ̀! (Jóòbù 39:13, 18) Ní ti ẹyẹ albatross, inú afẹ́fẹ́ ojú òkun ló ti ń lo èyí tó pọ̀ jù nínú ọjọ́ ayé ẹ̀. Ìyẹ́ apá ẹ̀ gùn tó mítà mẹ́ta, ó máa ń na ìyẹ́ náà lọ́nà tí afẹ́fẹ́ á fi máa tì í lọ síwájú. Torí náà, ó lè fò ní ọ̀pọ̀ wákàtí láìju ìyẹ́ rárá. Àmọ́, ẹyẹ akùnyùnmù yàtọ̀ ní tiẹ̀, òun ni ẹyẹ tó kéré jù lọ láyé, kò gùn ju páálí ìṣáná kékeré lọ, ṣe ló sì ń dán gbinrin bí òkúta iyebíye. Ó máa ń ju ìyẹ́ apá rẹ̀ ní nǹkan bí ọgọ́rin (80) ìgbà láàárín ìṣẹ́jú àáyá kan ṣoṣo! Tí ẹyẹ yìí bá wà lójú òfúrufú, ó lè máa ju ìyẹ́ ẹ̀ lójú kan, ó sì lè fò sẹ́yìn bíi ti hẹlikọ́pítà.
17. Báwo ni ẹja àbùùbùtán ṣe tóbi tó, kí ló sì yẹ ká ṣe tá a bá ronú nípa àwọn ẹranko tí Jèhófà dá?
17 Sáàmù 148:7 sọ pé àwọn ‘ẹ̀dá inú òkun’ náà ń yin Jèhófà. Àpẹẹrẹ kan ni ẹja àbùùbùtán. Òun ló tóbi jù nínú gbogbo ẹ̀dá inú òkun àti ẹranko orí ilẹ̀. Inú “ibú omi” ni ẹja yìí ń gbé, ká sọ pé ó lè dúró, ó máa ga tó ilé alájà mẹ́wàá tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó wúwo tó ọgbọ̀n (30) erin. Ahọ́n rẹ̀ lásán wúwo tó odindi erin kan. Ọkàn rẹ̀ tóbi tó ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kékeré kan, ìgbà mẹ́sàn-án péré ló sì máa ń lù kìkì láàárín ìṣẹ́jú kan. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọkàn ẹyẹ akùnyùnmù máa ń lù kìkì tó ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún méjì (1,200) ìgbà láàárín ìṣẹ́jú kan péré. Ó kéré tán, ọ̀kan nínú òpó ẹ̀jẹ̀ ẹja àbùùbùtán fẹ̀ débi pé ọmọ kékeré lè rá kòrò nínú ẹ̀. Tá a bá ronú lórí àwọn nǹkan àgbàyanu yìí, ó dájú pé àwa náà á fẹ́ tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ìyànjú tó parí ìwé Sáàmù, èyí tó sọ pé: “Kí gbogbo ohun tó ń mí yin Jáà.”—Sáàmù 150:6.
Ohun Tá A Kọ́ Látara Àwọn Nǹkan Tí Jèhófà Dá
18, 19. Kí lo lè sọ nípa oríṣiríṣi ohun alààyè tí Jèhófà dá sí ayé, kí sì ni ìṣẹ̀dá jẹ́ ká mọ̀ nípa ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run?
18 Kí làwọn nǹkan tí Jèhófà dá kọ́ wa nípa rẹ̀? Onírúurú nǹkan tí Jèhófà dá jẹ́ ká rí i pé ọgbọ́n àti agbára rẹ̀ ò láfiwé. Onísáàmù kan sọ pé: “Àwọn iṣẹ́ rẹ mà pọ̀ o, Jèhófà! . . . Ayé kún fún àwọn ohun tí o ṣe.” (Sáàmù 104:24) Bó sì ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn! Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan sọ pé oríṣiríṣi àwọn ohun alààyè tó wà láyé ju mílíọ̀nù kan lọ, àmọ́ àwọn míì gbà pé ó jù bẹ́ẹ̀ lọ dáadáa. Rò ó wò ná, oníṣẹ́ ọnà kan ti lè fi iṣẹ́ ọnà dá oríṣiríṣi àrà débi tó fi lè máa wò ó pé kò sí àrà tóun tún lè fi iṣẹ́ ọnà dá mọ́. Àmọ́ ní ti Jèhófà, agbára àti ọgbọ́n rẹ̀ ò lópin, torí náà kò lè dá gbogbo àrà tó wà lọ́wọ́ ẹ̀ tán láé.
19 Àwọn nǹkan tí Jèhófà dá jẹ́ ká rí i pé òun nìkan ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. Torí pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo, ó yàtọ̀ pátápátá sí gbogbo àwọn nǹkan tó kù láyé àtọ̀run. Lóòótọ́, Bíbélì sọ pé “àgbà òṣìṣẹ́” ni Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Jèhófà nígbà tí Jèhófà ń dá gbogbo nǹkan, síbẹ̀ Bíbélì ò sọ pé Ẹlẹ́dàá ni, bẹ́ẹ̀ ni kò sọ pé ńṣe ni òun àti Ọlọ́run jọ jẹ́ Ẹlẹ́dàá. (Òwe 8:30; Mátíù 19:4) Kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì pè é ní “àkọ́bí nínú gbogbo ẹ̀dá.” (Kólósè 1:15) Torí náà, bó ṣe jẹ́ pé Jèhófà ló fi agbára rẹ̀ dá gbogbo nǹkan láyé àtọ̀run, òun ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run.—Róòmù 1:20; Ìfihàn 4:11.
20. Kí ló túmọ̀ sí pé Jèhófà sinmi ní ọjọ́ keje?
20 Ṣé Jèhófà ṣì ń bá a nìṣó láti dá àwọn nǹkan sáyé? Rárá o. Nígbà tí Jèhófà parí iṣẹ́ ìṣẹ̀dá rẹ̀ ní ọjọ́ kẹfà, Bíbélì sọ pé ó “bẹ̀rẹ̀ sí í sinmi ní ọjọ́ keje lẹ́yìn gbogbo iṣẹ́ tó ti ń ṣe.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:2) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi hàn pé “ọjọ́” keje yìí gùn tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún, torí ó sọ pé ó ṣì ń bá a lọ nígbà ayé òun. (Hébérù 4:3-6) Ṣé bí Jèhófà ṣe “sinmi” yìí wá túmọ̀ sí pé kò ṣiṣẹ́ mọ́ rárá ni? Rárá o, Jèhófà ò fìgbà kan dáwọ́ iṣẹ́ dúró o. (Sáàmù 92:4; Jòhánù 5:17) Ohun tí ìsinmi yẹn túmọ̀ sí ni pé Jèhófà ò dá nǹkan kan sáyé mọ́. Àmọ́, ó ṣì ń bá a lọ láti ṣe ohun tó máa mú káwọn nǹkan tó ní lọ́kàn ṣẹ. Lára wọn ni bó ṣe fi ẹ̀mí rẹ̀ darí àwọn tó kọ Ìwé Mímọ́, tó sì ń ṣètò àwọn kan tí Bíbélì pè ní “ẹ̀dá tuntun.” A máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀dá tuntun yìí ní Orí 19.—2 Kọ́ríńtì 5:17.
21. Àǹfààní wo ni agbára tí Jèhófà fi ń dá nǹkan máa ṣe àwọn olóòótọ́ èèyàn títí ayé?
21 Tí ọjọ́ ìsinmi Jèhófà bá ti parí, Jèhófà máa lè sọ pé gbogbo iṣẹ́ tóun ṣe láyé “dára gan-an,” gẹ́lẹ́ bó ṣe sọ nígbà tó parí iṣẹ́ ìṣẹ̀dá ní ọjọ́ kẹfà. (Jẹ́nẹ́sísì 1:31) Torí pé agbára tí Jèhófà ní láti ṣẹ̀dá kò lópin, ó ṣeé ṣe kó ṣì lo agbára rẹ̀ láti ṣẹ̀dá àwọn nǹkan míì nígbà yẹn. Ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, ó dájú pé títí láé ni agbára tí Jèhófà fi ń dá nǹkan á máa jọ wá lójú, táá sì máa múnú wa dùn. Títí ayé la ó máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà látara àwọn nǹkan tó dá. (Oníwàásù 3:11) Bá a bá ṣe ń mọ Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa sí i, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa rí i pé ó tóbi lọ́ba lóòótọ́, èyí á sì mú kó wù wá láti túbọ̀ sún mọ́ ọn.
a Báwo ni ayé ṣe jìnnà sí oòrùn tó? Jẹ́ ká wò ó báyìí náà: Ká sọ pé ẹnì kan fẹ́ wa mọ́tò láti ayé lọ síbi tí oòrùn wà, tẹ́ni náà bá tiẹ̀ ń sáré ní ìwọ̀n ọgọ́jọ (160) kìlómítà láàárín wákàtí kan, tó sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ láìdúró rárá, ó máa lò ju ọgọ́rùn-ún ọdún lọ́nà kó tó lè débẹ̀!
b Àwọn kan rò pé ó ṣeé ṣe kí àwọn tó ń gbé láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì ní ohun kan tí wọ́n fi ń wo ohun tó wà lọ́nà tó jìn. Wọ́n ní láìjẹ́ bẹ́ẹ̀, báwo ni wọ́n ṣe mọ̀ pé àìmọye ìràwọ̀ ló ṣì wà lójú ọ̀run téèyàn ò lè fojú rí? Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé àwọn tó ń sọ irú ọ̀rọ̀ tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ bẹ́ẹ̀ kì í ro ti Jèhófà mọ́ ọn, wọn kì í rántí pé òun ló mí sí àwọn tó kọ Bíbélì.—2 Tímótì 3:16.
c Báwo ló ṣe máa pẹ́ tó tí wàá fi ka ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù ìràwọ̀ tán? Ká sọ pé ńṣe lò ń ka ìràwọ̀ kan ní ìṣẹ́jú àáyá kọ̀ọ̀kan, tó o sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ fún gbogbo wákàtí mẹ́rìnlélógún tó wà nínú ọjọ́ kan láìdúró, ó máa gbà ẹ́ ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé mọ́kànléláàádọ́sàn-án (3,171) ọdún kó o tó kà á tán!