147 Ẹ yin Jáà!
Ó dára láti máa kọ orin ìyìn sí Ọlọ́run wa;
Ẹ wo bí ó ti dùn tó, tí ó sì tọ́ láti máa yìn ín!+
2 Jèhófà ń kọ́ Jerúsálẹ́mù;+
Ó ń kó àwọn tí wọ́n fọ́n ká lára Ísírẹ́lì jọ.+
3 Ó ń mú àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn lára dá;
Ó ń di àwọn egbò wọn.
4 Ó ń ka iye àwọn ìràwọ̀;
Gbogbo wọn ni ó ń fi orúkọ pè.+
5 Olúwa wa tóbi, agbára rẹ̀ sì pọ̀;+
Òye rẹ̀ ò ṣeé díwọ̀n.+
6 Jèhófà ń gbé àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ dìde,+
Àmọ́, ó ń rẹ àwọn ẹni burúkú wálẹ̀.
7 Ẹ kọrin sí Jèhófà pẹ̀lú ìdúpẹ́;
Ẹ fi háàpù kọ orin ìyìn sí Ọlọ́run wa,
8 Ẹni tó ń fi àwọsánmà bo ojú ọ̀run,
Ẹni tó ń pèsè òjò fún ayé,+
Ẹni tó ń mú kí koríko hù+ lórí àwọn òkè.
9 Ó ń fún àwọn ẹranko lóúnjẹ,+
Àwọn ọmọ ẹyẹ ìwò tó ń kígbe fún oúnjẹ.+
10 Kì í ṣe agbára ẹṣin ló ń mú inú rẹ̀ dùn;+
Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe agbára ẹsẹ̀ èèyàn ló ń wú u lórí.+
11 Inú Jèhófà ń dùn sí àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀,+
Sí àwọn tó ń dúró de ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.+
12 Yin Jèhófà lógo, ìwọ Jerúsálẹ́mù.
Yin Ọlọ́run rẹ, ìwọ Síónì.
13 Ó ń mú kí ọ̀pá ìdábùú àwọn ẹnubodè rẹ lágbára;
Ó ń bù kún àwọn ọmọ rẹ nínú rẹ.
14 Ó ń mú àlàáfíà wá sórí ilẹ̀ rẹ;+
Ó ń fi àlìkámà tó dára jù lọ tẹ́ ọ lọ́rùn.+
15 Ó ń fi àṣẹ rẹ̀ ránṣẹ́ sí ayé;
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń yára kánkán.
16 Ó ń fi yìnyín ránṣẹ́ bí ẹ̀gbọ̀n òwú;+
Ó ń fọ́n ìrì dídì ká bí eérú.+
17 Ó ń fi yìnyín rẹ̀ sọ̀kò sílẹ̀ bí òkèlè.+
Ta ló lè fara da òtútù rẹ̀?+
18 Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀ jáde, wọ́n sì yọ́.
Ó mú kí ẹ̀fúùfù rẹ̀ fẹ́,+ omi sì ń ṣàn.
19 Ó sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún Jékọ́bù,
Ó sọ àwọn ìlànà rẹ̀ àti àwọn ìdájọ́ rẹ̀ fún Ísírẹ́lì.+
20 Kò ṣe bẹ́ẹ̀ fún orílẹ̀-èdè míì;+
Wọn ò mọ nǹkan kan nípa ìdájọ́ rẹ̀.
Ẹ yin Jáà!+