Sún Mọ́ Ọlọ́run
“Jèhófà Ni Olùṣọ́ Àgùntàn Mi”
WO ÀWÒRÁN tó wà lójú ìwé yìí. Ǹjẹ́ o rí i bí ọkàn àgùntàn yẹn ṣe balẹ̀ nígbà tí olùṣọ́ àgùntàn yẹn gbé e mọ́ra? Ní Sáàmù 23, Bíbélì lo àfiwé kan nípa olùṣọ́ àgùntàn àti àgùntàn rẹ̀ láti fi ṣàpèjúwe bí Jèhófà ṣe ń bójú tó àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ tìfẹ́tìfẹ́. Ọlọ́run fẹ́ kí ọkàn àwa náà balẹ̀ bíi ti àwọn èèyàn bíi Dáfídì, tó kọ sáàmù yìí, tó fi ìgbọ́kànlé sọ pé: “Jèhófà ni Olùṣọ́ àgùntàn mi.”a—Ẹsẹ 1.
Dáfídì tó kọ sáàmù yìí jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn nígbà tó wà ní ọ̀dọ́. Ó mọ ohun tí àwọn àgùntàn ń fẹ́ àti ohun tó yẹ kí olùṣọ́ àgùntàn kan ṣe. Dáfídì gbádùn ìtọ́jú Ọlọ́run ní ìgbésí ayé rẹ̀, èyí ló sì mú kó kọ sáàmù tí wọ́n pè ní “sáàmù afinilọ́kànbalẹ̀.” Jèhófà tó jẹ́ orúkọ Ọlọ́run fara hàn ní ìbẹ̀rẹ̀ àti ìparí sáàmù náà. (Ẹsẹ 1, 6) Àwọn ọ̀rọ̀ tó wà láàárín sáàmù yẹn ṣàpèjúwe ọ̀nà mẹ́ta tí Jèhófà ń gbà bójú tó àwọn èèyàn rẹ̀ bí olùṣọ́ àgùntàn kan ṣe ń bójú tó àwọn àgùntàn rẹ̀.—Sáàmù 100:3.
Jèhófà ń darí àwọn àgùntàn rẹ̀. Àwọn àgùntàn máa ń sọnù tí ẹni tó ń ṣọ́ wọn kò bá sí lọ́dọ̀ wọn. Bákan náà, a nílò ìrànlọ́wọ́ ká lè mọ ọ̀nà tó tọ́ ní ìgbésí ayé wa. (Jeremáyà 10:23) Dáfídì ṣàlàyé pé, Jèhófà ń darí àwọn èèyàn rẹ̀ lọ sí “pápá ìjẹko tí ó kún fún koríko” àti “àwọn ibi ìsinmi tí ó lómi dáadáa.” Ó ń darí wọn “ní àwọn òpó ọ̀nà òdodo.” (Ẹsẹ 2, 3) Àkàwé nípa olùṣọ́ àgùntàn yìí jẹ́ kó dá wa lójú pé a lè gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run. Tá a bá ń tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Bíbélì, a ó lè máa gbé ìgbé ayé tó tẹ́ni lọ́rùn, tó tuni lára tó sì fini lọ́kàn balẹ̀.
Jèhófà ń dáàbò bo àwọn àgùntàn rẹ̀. Ẹ̀rù máa ń ba àwọn àgùntàn, kò sì sí ohun tí wọ́n lè ṣe láìsí ìrànwọ́ olùṣọ́ àgùntàn. Jèhófà sọ pé kí àwọn èèyàn òun má ṣe bẹ̀rù, títí kan ìgbà tí wọ́n bá “ń rìn ní àfonífojì ibú òjìji,” ìyẹn ìgbà tó dà bíi pé nǹkan kò rọgbọ ní ìgbésí ayé wọn. (Ẹsẹ 4) Jèhófà ń dáàbò bò wọ́n, ó sì ṣe tán láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Ó lágbára láti fún àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ ní ọgbọ́n àti okun tí wọ́n nílò kí wọ́n lè fara da àdánwò.—Fílípì 4:13; Jákọ́bù 1:2-5.
Jèhófà ń bọ́ àwọn àgùntàn rẹ̀. Olùṣọ́ àgùntàn ló máa ń wá oúnjẹ fún àwọn àgùntàn, àwọn àgùntàn sì gbára lé e. A nílò pé kí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run dára, Ọlọ́run náà ló sì máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣe bẹ́ẹ̀. (Mátíù 5:3) A dúpẹ́ pé Jèhófà jẹ́ Olùpèsè tó jẹ́ ọ̀làwọ́, tó ń ṣètò tábìlì tó kún fún oúnjẹ tẹ̀mí síwájú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. (Ẹsẹ 5) Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde tó dá lórí Bíbélì, irú èyí tí ò ń kà lọ́wọ́ yìí, jẹ́ ara oúnjẹ tẹ̀mí, tó jẹ́ ká mọ ìdí tá a fi wà láàyè àti ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún wa.
Ọkàn Dáfídì balẹ̀, ó mọ̀ pé tí òun kò bá kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà tó jẹ́ Olùṣọ́ Àgùntàn tó ń bójú tó òun láti ọ̀run, òun máa gbádùn àbójútó onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ “ní gbogbo ọjọ́ ayé [òun].” (Ẹsẹ 6) Ǹjẹ́ ìwọ náà ń fẹ́ irú àbójútó yìí? Tó o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, kẹ́kọ̀ọ́ nípa bó o ṣe lè sún mọ́ Jèhófà. Wàá tipa bẹ́ẹ̀ rí ààbò lábẹ́ apá Olùṣọ́ Àgùntàn Ńlá, ẹni tó ń darí, tó dáàbò boni tó sì ń bọ́ àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin.—Aísáyà 40:11.
Bíbélì kíkà tá a dábàá fún May:
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀pọ̀ èèyàn mọ gbólóhùn náà, “OLÚWA ni Olùṣọ́ Àgùntàn mi.” Láti mọ ìdí tí àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì kan fi yọ Jèhófà tó jẹ́ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú Bíbélì, ka ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? lójú ìwé 195 sí 197. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.