Kíkọ́ Láti Rí Ìgbádùn Nínú Ìbẹ̀rù Jehofa
“Wá, ẹ̀yin ọmọ, fi etí sí mi: èmi ó sì kọ́ yín ní ẹ̀rù Oluwa.”—ORIN DAFIDI 34:11.
1. Báwo ni Ìjọba Ọlọrun yóò ṣe mú ìbẹ̀rù kúrò, ṣùgbọ́n ìyẹn ha túmọ̀ sí gbogbo ìbẹ̀rù bí?
ÀWỌN ènìyàn níbi gbogbo ń yánhànhàn fún òmìnira kúrò lọ́wọ́ ìbẹ̀rù—ìbẹ̀rù ìwà-ọ̀daràn àti ìwà-ipá, ìbẹ̀rù àìníṣẹ́lọ́wọ́, àti ìbẹ̀rù àìsàn lílekoko. Ẹ wo irú ọjọ́ pípabambarì tí yóò jẹ́ nígbà tí òmìnira náà bá di òtítọ́ gidi lábẹ́ Ìjọba Ọlọrun! (Isaiah 33:24; 65:21-23; Mika 4:4) Síbẹ̀, kì í ṣe gbogbo ìbẹ̀rù ni a óò mú kúrò nígbà náà, bẹ́ẹ̀ sì ni a kò níláti gbìyànjú láti ti gbogbo ìbẹ̀rù kúrò nínú ìgbésí-ayé wa nísinsìnyí. Ìbẹ̀rù tí ó dára wà èyí tí ó sì burú wà.
2. (a) Irú ìbẹ̀rù wo ni ó burú, irú èwo ni ó sì yẹ kí a ní ìfẹ́-ọkàn sí? (b) Kí ni ìbẹ̀rù Ọlọrun, báwo sì ni àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ tí a fàyọ ṣe fi ìyẹn hàn?
2 Ìbẹ̀rù lè jẹ́ májèlé fún èrò-inú, kí ó sì dènà agbára ẹnì kan láti ronú. Ó le bomi paná ìgboyà kí ó sì pa ìrètí run. Ẹnì kan tí ọ̀tá halẹ̀ mọ́ lójúkorojú lè ní irú ìrírí ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀. (Jeremiah 51:30) Ẹnì kan tí ó ka níní ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ àwọn ẹ̀dá ènìyàn kan tí wọ́n yọrí-ọlá sí ohun bàbàrà lè ní in. (Owe 29:25) Ṣùgbọ́n ìbẹ̀rù tí ó gbámúṣé tún wà, irú èyí tí ń fà wá sẹ́yìn kúrò nínú fífi ìwàǹwára ṣe ohunkóhun, kúrò nínú ṣíṣe ìpalára fún ara wa. Ìbẹ̀rù Ọlọrun tún ní nínú ju ìyẹn lọ. Ó jẹ́ ìbẹ̀rù-ọlọ́wọ̀ fún Jehofa, ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún un, ní àfikún sí ìfòyà gbígbámúṣé ti ṣíṣàìfẹ́ láti bà á nínú jẹ́. (Orin Dafidi 89:7) Ìbẹ̀rù rírí ìbínú Ọlọrun yìí ń wá láti inú ìmọrírì fún inúrere-ìfẹ́ àti ìwàrere rẹ̀. (Orin Dafidi 5:7; Hosea 3:5) Ó tún kan mímọ̀ pé Jehofa ni Onídàájọ́ Onípò Àjùlọ àti Olodumare, tí ó ní agbára láti fi ìyà jẹ, àní fi ikú pa, àwọn tí wọ́n kọ̀ láti ṣègbọràn sí i.—Romu 14:10-12.
3. Báwo ni ìbẹ̀rù Jehofa ṣe yàtọ̀ sí èyí tí a mọ̀ mọ àwọn ọlọrun kèfèrí?
3 Ìbẹ̀rù Ọlọrun gbámúṣé, kì í ṣe oníjìnnìjìnnì. Ó ń sún ẹnì kan láti dúró ṣinṣin fún ohun tí ó tọ́, láti máṣe juwọ́ sílẹ̀ nípa ṣíṣe ohun tí ó lòdì. Kò dàbí ìbẹ̀rù tí a mọ̀ mọ Phobos ọlọrun Griki ìgbàanì, tí a ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí olubi ọlọrun tí ń fa ìpayà. Kò sì dàbí ìbẹ̀rù tí a mọ̀ mọ Kali abo ọlọrun ti ìsìn Hindu, tí a ń ṣàpèjúwe nígbà mìíràn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí òùngbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ, tí ń lo àwọn òkú, ejò, àti agbárí gẹ́gẹ́ bí ohun-ọ̀ṣọ́. Ìbẹ̀rù Ọlọrun ń fanimọ́ra; kì í léni sá. Ó wémọ́ ìfẹ́ àti ìmọrírì. Nípa bẹ́ẹ̀, ìbẹ̀rù Ọlọrun ń fà wá súnmọ́ Jehofa.—Deuteronomi 10:12, 13; Orin Dafidi 2:11.
Ìdí Tí Àwọn Kan Fi Ní In tí Àwọn Mìíràn Kò Sì Ní In
4. Gẹ́gẹ́ bí aposteli Paulu ti fi hàn, ipò wo ni ìran ènìyàn ti dé dúró, kí ni ó sì fa èyí?
4 Ànímọ́ ìbẹ̀rù Ọlọrun kò sún aráyé lápapọ̀ ṣiṣẹ́. Ní Romu 3:9-18, aposteli Paulu ṣàpèjúwe bí ẹ̀dá ènìyàn ti ṣubú jìnnà tó kúrò nínú ìjẹ́pípé ìpilẹ̀ṣẹ̀. Lẹ́yìn sísọ pé gbogbo ènìyàn wà lábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, Paulu fa ọ̀rọ̀ yọ láti inú Orin Dafidi, ní sísọ pé: “Kò sí ẹni tíí ṣe olódodo, àní ẹyọ ẹnì kan pàápàá kò sí.” (Wo Orin Dafidi 14:1, NW.) Lẹ́yìn náà ó fúnni ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa títọ́ka sí àwọn nǹkan bí àìbìkítà ènìyàn láti wá Ọlọrun, àìní inúrere wọn, ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn wọn, èpè, àti ìtàjẹ̀sílẹ̀. Ẹ wo bí ìyẹn ti ṣàpèjúwe bí ayé ṣe rí lónìí lọ́nà tí ó ṣe rẹ́gí tó! Ọ̀pọ̀ jùlọ ènìyàn lónìí kò ní ọkàn-ìfẹ́ nínú Ọlọrun àti àwọn ète rẹ̀. Ohun tí ó bá dàbí inúrere ni wọ́n sábà máa ń fi di ìgbà tí ohun kan tí wọ́n lè rí jèrè bá wà. Irọ́ pípa àti ọ̀rọ̀ rírùn wọ́pọ̀. Ìtàjẹ̀sílẹ̀ ni a ń gbéjáde kì í ṣe kìkì nínú ìròyìn ṣùgbọ́n nínú eré ìnàjú pẹ̀lú. Kí ni ó fa irú ipò bẹ́ẹ̀? Òtítọ́ ni pé gbogbo wa jẹ́ àtọmọdọ́mọ Adamu ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ènìyàn bá mú ọ̀nà ìgbésí-ayé wọn bá ohun tí aposteli Paulu ṣàpèjúwe mu, ohun kan tí ó ju ìyẹn lọ ti wọ̀ ọ́. Ẹsẹ 18 ṣàlàyé ohun tí ó jẹ́, ní sísọ pé: “Ìbẹ̀rù Ọlọrun kò sí nínú wọn.”—Wo Orin Dafidi 36:1.
5. Èéṣe tí àwọn ènìyàn kan fi ní ìbẹ̀rù Ọlọrun, tí àwọn mìíràn kò sì ní?
5 Bí ó ti wù kí ó rí, èéṣe tí àwọn ènìyàn kan fi ní ìbẹ̀rù Ọlọrun, tí àwọn mìíràn kò sì ní? Ní ṣókí, ó jẹ́ nítorí pé àwọn kan mú un dàgbà, nígbà tí àwọn mìíràn kò ṣe bẹ́ẹ̀. A kò bí i mọ́ ẹnikẹ́ni nínú wa, ṣùgbọ́n gbogbo wa ní agbára láti ṣe é. Ìbẹ̀rù Ọlọrun jẹ́ ohun tí a níláti kọ́. Lẹ́yìn náà, kí ó tó lè ní agbára ìsúnniṣe nínú ìgbésí-ayé wa, a níláti mú un dàgbà.
Ìkésíni Fífanimọ́ra
6. Ta ni ó nawọ́ ìkésíni tí a kọ sínú Orin Dafidi 34:11 sí wa, báwo sì ni ẹsẹ ìwé mímọ́ yìí ṣe fi hàn pé a gbọ́dọ̀ kọ́ ìbẹ̀rù Ọlọrun?
6 Nínú Orin Dafidi 34 a nawọ́ ìkésíni fífanimọ́ra sí wa láti kọ́ ìbẹ̀rù Jehofa. Èyí jẹ́ psalmu Dafidi. Ta sì ni Dafidi jẹ́ òjìji ìṣáájú fún? Kò sí ẹlòmíràn bíkòṣe Jesu Kristi Oluwa. Àsọtẹ́lẹ̀ tí aposteli Johannu darí ní tààràtà sí Jesu ni a kọ sínú ẹsẹ 20 psalmu yìí. (Johannu 19:36) Ní ọjọ́ tiwa, Jesu ni ẹni náà tí ó ń nawọ́ irú ìkésíni yẹn ní ẹsẹ 11 pé: “[Ẹ] wá ẹ̀yin ọmọ, [ẹ] fi etí sí mi: èmi óò kọ́ yín ní ẹ̀rù [Jehofa, NW].” Èyí fi hàn ní kedere pé ìbẹ̀rù Ọlọrun jẹ́ ohun tí a lè kọ́, Jesu Kristi sì tóótun lọ́nà gíga lọ́lá láti kọ́ wa. Èéṣe tí ó fi rí bẹ́ẹ̀?
7. Èéṣe tí Jesu ní pàtàkì fi jẹ́ ẹni tí a níláti kọ́ ìbẹ̀rù Ọlọrun lára rẹ̀?
7 Jesu Kristi mọ ìjẹ́pàtàkì ìbẹ̀rù Ọlọrun. Heberu 5:7 sọ nípa rẹ̀ pé: “Ní awọn ọjọ́ rẹ̀ ninu ẹran-ara Kristi ṣe ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ ati ìtọrọ pẹlu sí Ẹni naa tí ó lè gbà á là kúrò ninu ikú, pẹlu igbe ẹkún kíkankíkan ati omijé, a sì gbọ́ ọ pẹlu ojúrere nitori ìbẹ̀rù rẹ̀ fún Ọlọrun.” Irúfẹ́ ìbẹ̀rù Ọlọrun bẹ́ẹ̀ ni ànímọ́ ti Jesu Kristi fi hàn àní ṣáájú kí ó tó dojú kọ ikú lórí òpó igi ìdálóró. Rántí, nínú Owe orí 8, Ọmọkùnrin Ọlọrun ni a ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí ògidì-àpẹẹrẹ ọgbọ́n. Àti nínú Owe 9:10, a sọ fún wa pé: “Ìbẹ̀rù Oluwa ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n.” Nípa bẹ́ẹ̀ ìbẹ̀rù Ọlọrun yìí jẹ́ apá pàtàkì nínú àkópọ̀ ìwà Ọmọkùnrin Ọlọrun tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí ó tó wá sórí ilẹ̀-ayé.
8. Nínú Isaiah 11:2, 3, kí ni a rí kọ́ nípa ìbẹ̀rù Jehofa?
8 Síwájú síi, nípa Jesu gẹ́gẹ́ bíi Messia Ọba, Isaiah 11:2, 3 sọ pé: “Ẹ̀mí Oluwa yóò sì bà lè e, ẹ̀mí ọgbọ́n àti òye, ẹ̀mí ìgbìmọ̀ àti agbára, ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ìbẹ̀rù Oluwa. Òórùn dídùn rẹ̀ sì wà ní ìbẹ̀rù Oluwa.” Ẹ wo bí a ti sọ ìyẹn lọ́nà tí ó dùn-ún gbọ́ tó! Ìbẹ̀rù Jehofa kì í ṣe ohun tí kò dùnmọ́ni. Ó ń ṣeni láǹfààní, ó sì ń gbéniró. Ó jẹ́ ànímọ́ kan tí yóò gbalẹ̀ káàkiri gbogbo ibi tí Kristi yóò ṣàkóso lé lórí gẹ́gẹ́ bí Ọba. Ó ń ṣàkóso nísinsìnyí, ó sì ń fún gbogbo àwọn tí a ń kójọpọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ abẹ́ rẹ̀ ní ìtọ́ni nínú ìbẹ̀rù Jehofa. Lọ́nà wo?
9. Báwo ni Jesu Kristi ṣe ń kọ́ wa ní ìbẹ̀rù Jehofa, kí ni ó sì fẹ́ kí a kọ́ nípa rẹ̀?
9 Nípasẹ̀ àwọn ìpàdé ìjọ, àpéjọ, àti àpéjọpọ̀, Jesu, gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a yàn sí ipò Orí ìjọ àti gẹ́gẹ́ bíi Messia Ọba, ń ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ohun tí ìbẹ̀rù Ọlọrun jẹ́ ní kedere àti ìdí tí ó fi ṣàǹfààní tóbẹ́ẹ̀. Ó ń tipa báyìí ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ mú ìmọrírì wa jinlẹ̀ fún un kí a baà lè kọ́ láti rí ìgbádùn nínú ìbẹ̀rù Jehofa gan-an gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe.
Ìwọ Yóò Ha Sapá Bí?
10. Nígbà tí a bá pésẹ̀ sí àwọn ìpàdé Kristian, kí ni a gbọ́dọ̀ ṣe bí a bá fẹ́ lóye ìbẹ̀rù Jehofa?
10 Àmọ́ ṣáá o, wíwulẹ̀ ka Bibeli tàbí pípésẹ̀ sí àwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba kì í ṣe ẹ̀rí ìdánilójú pé àwa yóò ní ìbẹ̀rù Ọlọrun. Kíyèsí ohun tí a níláti ṣe bí a bá fẹ́ láti lóye ìbẹ̀rù Jehofa níti gidi. Owe 2:1-5 sọ pé: “Ọmọ mi, bí ìwọ bá fẹ́ gba ọ̀rọ̀ mi, kí ìwọ sì pa òfin mi mọ́ pẹ̀lú rẹ. Tí ìwọ dẹtí rẹ sílẹ̀ sí ọgbọ́n, tí ìwọ sì fi ọkàn sí òye; àní bí ìwọ bá ń ké tọ ìmọ̀ lẹ́yìn, tí ìwọ sì gbé ohùn rẹ sókè fún òye; bí ìwọ bá ṣàfẹ́rí rẹ̀ bíi fàdákà, tí ìwọ sì ń wá a kiri bí ìṣúra tí a pamọ́; nígbà náà ni ìwọ ó mọ ìbẹ̀rù [Jehofa, NW] ìwọ ó sì rí ìmọ̀ Ọlọrun.” Nítorí náà nígbà tí a bá pésẹ̀ sí ìpàdé, a níláti fiyèsí ohun tí a ń sọ, kí a ṣe ìsapá àtọkànwá láti pọkànpọ̀ kí a sì rántí àwọn èrò tí ó ṣe kókó, kí a ronú jinlẹ̀ nípa bí ọ̀nà tí a gbà nímọ̀lára nípa Jehofa ṣe yẹ kí ó nípa ìdarí lórí ìhùwàsí wa sí ìmọ̀ràn tí a bá fún wa—bẹ́ẹ̀ni, kí a ṣí ọkàn-àyà wa payá. Nígbà náà ni a óò lóye ìbẹ̀rù Jehofa.
11. Láti mú ìbẹ̀rù Ọlọrun dàgbà, kí ni a níláti ṣe látọkànwá àti nígbà gbogbo?
11 Orin Dafidi 86:11 pe àfiyèsí sí kókó pàtàkì mìíràn, ìyẹn ni àdúrà. Onipsalmu náà gbàdúrà pé: “Oluwa, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ; èmi ó máa rìn nínú òtítọ́ rẹ: mú àyà mi ṣọ̀kan láti bẹ̀rù orúkọ rẹ.” Jehofa fọwọ́ sí àdúrà yẹn, nítorí ti òun mú kí a kọ ọ́ sínú Bibeli. Láti mu ìbẹ̀rù Ọlọrun dàgbà, àwa pẹ̀lú níláti gbàdúrà sí Jehofa fún ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, a óò sì jàǹfààní nípa gbígbàdúrà látọkànwá àti nígbà gbogbo.—Luku 18:1-8.
Ọkàn-Àyà Rẹ Wémọ́ Ọn
12. Èéṣe tí a fi níláti fún ọkàn-àyà wa ni àfiyèsí àrà-ọ̀tọ̀, kí sì ni èyí ní nínú?
12 Ohun mìíràn tún wà tí a níláti ṣàkíyèsí nínú Orin Dafidi 86:11. Onipsalmu náà kò béèrè fún wíwulẹ̀ ní òye ìbẹ̀rù Ọlọrun lọ́nà ti ọgbọ́n orí lásán. Ó mẹ́nuba ọkàn-àyà rẹ̀. Mímú ìbẹ̀rù Ọlọrun dàgbà wémọ́ ọkàn-àyà àfiṣàpẹẹrẹ, èyí tí ó ń béèrè àfiyèsí àrà-ọ̀tọ̀ nítorí pé òun ni ẹni inú lọ́hùn-ún gẹ́gẹ́ bí ó ti hàn nínú gbogbo ìgbòkègbodò ìgbésí-ayé wa ó sì ní nínú àwọn èrò wa, ìṣesí wa, ìfẹ́-ọkàn wa, ìsúnniṣe wa, góńgó wa.
13. (a) Kí ni ó lè fi hàn pé ọkàn-àyà ẹnì kan ti pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ? (b) Bí a ti ń mú ìbẹ̀rù Ọlọrun dàgbà, góńgó wo ni a níláti máa ṣiṣẹ́ síhà rẹ̀?
13 Bibeli kìlọ̀ fún wa pé ọkàn-àyà ẹnì kan lè pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Ó lè tannijẹ. (Orin Dafidi 12:2; Jeremiah 17:9) Ó lè sún wa láti lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò tí ó gbámúṣé—lílọ sí àwọn ìpàdé ìjọ àti jíjáde fún iṣẹ́-ìsìn pápá—ṣùgbọ́n ó tún lè mú kí a nífẹ̀ẹ́ sí apákan ọ̀nà ìgbésí-ayé aráyé. Èyí lè fà wá sẹ́yìn kúrò nínú jíjẹ́ ẹni tí ń fi tòótọ́ fi tọkàntọkàn gbé ire Ìjọba náà lárugẹ. Nígbà náà, ọkàn-àyà tí ń tannijẹ lè rọ̀ wá pé, ó ṣetán, a ń ṣe dáradára gẹ́gẹ́ bíi ti àwọn púpọ̀ mìíràn. Tàbí bóyá ní ilé-ẹ̀kọ́ tàbí lẹ́nu iṣẹ́ wa, ìbẹ̀rù ènìyàn lè nípa lórí ọkàn-àyà. Àbájáde rẹ̀ ni pé, a lè lọ́tìkọ̀ láti fi ara wa hàn gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jehofa ni irú àwọn àyíká wọ̀nyẹn a sì lè ṣe àwọn ohun tí kò yẹ fún Kristian láti ṣe pàápàá. Láìka èyí sí, lẹ́yìn náà, ẹ̀rí-ọkàn wa ń yọ wá lẹ́nu. Kì í ṣe irú ẹni yẹn ni a fẹ́ láti jẹ́. Nítorí náà, a darapọ̀ mọ́ onipsalmu náà ní gbígbàdúrà sí Jehofa pé: “Mú àyà mi ṣọ̀kan láti bẹ̀rù orúkọ rẹ.” A fẹ́ kí gbogbo ohun tí a jẹ́ nínú, gẹ́gẹ́ bí a ti fi hàn nínú gbogbo ìgbòkègbodò ìgbésí-ayé wa, fi ẹ̀rí hàn pé a ‘ń bẹ̀rù Ọlọrun a sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́.’—Oniwasu 12:13.
14, 15. (a) Nígbà tí ó ń sọtẹ́lẹ̀ nípa ìmúpadàbọ̀sípò Israeli láti ìgbèkùn Babiloni, kí ni Jehofa ṣèlérí láti fún àwọn ènìyàn rẹ̀? (b) Kí ni Jehofa ṣe láti lè gbin ìbẹ̀rù Ọlọrun sínú ọkàn-àyà àwọn ènìyàn rẹ̀? (d) Èéṣe tí Israeli fi yípadà kúrò ní ọ̀nà Jehofa?
14 Jehofa ṣèlérí pé òun yóò fún àwọn ènìyàn òun ní irú ọkàn-àyà bẹ́ẹ̀ tí ń bẹ̀rù Ọlọrun. Ó sọtẹ́lẹ̀ nípa ìmúpadàbọ̀sípò Israeli ó sì wí, gẹ́gẹ́ bí a ṣe kà á nínú Jeremiah 32:37-39 pé: “Èmi óò sì jẹ́ kí wọn kí ó máa gbé láìléwu: wọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi, èmi ó sì jẹ́ Ọlọrun wọn. Èmi óò sì fún wọn ní ọkàn kan, àti ọ̀nà kan, kí wọn kí ó lè bẹ̀rù mi ní ọjọ́ gbogbo, fún rere wọn, àti ti àwọn ọmọ wọn lẹ́yìn wọn.” Ní ẹsẹ 40, a túbọ̀ fìdí ìlérí Ọlọrun múlẹ̀ síi pé: “Èmi óò fi ìbẹ̀rù mi sí ọkàn wọn, tí wọn kì [yóò] lọ kúrò lọ́dọ̀ mi.” Ní 537 B.C.E., Jehofa mú wọn padà wá sí Jerusalemu gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí. Ṣùgbọ́n àwọn ìlérí tí ó kù ńkọ́—pé òun yóò fún wọn ni ‘ọkàn kan kí wọ́n lè bẹ̀rù rẹ̀ ní ọjọ́ gbogbo’? Èéṣe tí orílẹ̀-èdè Israeli ìgbàanì fi yípadà kúrò lọ́dọ̀ Jehofa lẹ́yìn tí ó ti mú wọn padà wá láti Babiloni, tí ìyẹn sì yọrí sí ìparun tẹ́ḿpìlì wọn ní 70 C.E., tí a kì yóò sì ṣe àtúnkọ́ rẹ̀ láé?
15 Èyí kì í ṣe nítorí àṣìṣe kankan ní ìhà ọ̀dọ̀ Jehofa. Níti gidi, Jehofa gbé ìgbésẹ̀ láti fi ìbẹ̀rù Ọlọrun sínú ọkàn-àyà àwọn ènìyàn rẹ̀. Nípasẹ̀ àánú tí ó fi hàn ní dídá wọn nídè kúrò ní Babiloni tí ó sì mú wọn padà sí ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn, ó fún wọn ní ìdí tí ó pọ̀ tó láti wo òun pẹ̀lú ọ̀wọ̀ tí ó jinlẹ̀. Ọlọrun fìdí ìyẹn múlẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìránnilétí, ìmọ̀ràn, àti ìbáwí nípasẹ̀ wòlíì Haggai, Sekariah, àti Malaki; nípasẹ̀ Esra, ẹni tí a rán sí wọn gẹ́gẹ́ bí olùkọ́; nípasẹ̀ Gomina Nehemiah; àti nípasẹ̀ Ọmọkùnrin Ọlọrun fúnra rẹ̀. Nígbà mìíràn àwọn ènìyàn náà máa ń fetísílẹ̀. Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí wọ́n tún tẹ́ḿpìlì Jehofa kọ́ lẹ́yìn tí Haggai àti Sekariah rọ̀ wọ́n àti nígbà tí wọ́n lé àwọn àjèjì aya wọn lọ ní ọjọ́ Esra. (Esra 5:1, 2; 10:1-4) Ṣùgbọ́n lọ́pọ̀ ìgbà wọn kì í ṣègbọràn. Wọn kò ṣedéédéé nínú fífiyèsílẹ̀; wọn kò bá a nìṣó ní títẹ́wọ́gba ìmọ̀ràn; wọn kò jẹ́ kí ọkàn-àyà wọn ṣípayá. Àwọn ọmọ Israeli kò mú ìbẹ̀rù Ọlọrun dàgbà, gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, kò jẹ́ ohun lílágbára tí ń súnniṣiṣẹ́ nínú ìgbésí-ayé wọn.—Malaki 1:6; Matteu 15:7, 8.
16. Inú ọkàn-àyà àwọn wo ni Jehofa gbin ìbẹ̀rù Ọlọrun sí?
16 Síbẹ̀, ìlérí Jehofa láti fi ìbẹ̀rù Ọlọrun sínú ọkàn-àyà àwọn ènìyàn rẹ̀ kò kùnà. Ó dá májẹ̀mú titun pẹ̀lú Israeli tẹ̀mí, àwọn Kristian wọnnì tí òun nawọ́ ìrètí ti ọ̀run sí. (Jeremiah 31:33; Galatia 6:16) Ní 1919, Ọlọrun mú wọn padàbọ̀sípò láti inú ìgbèkùn Babiloni Ńlá, ilẹ̀-ọba ìsìn èké àgbáyé. Ó ti gbin ìbẹ̀rù rẹ̀ sínú ọkàn-àyà wọn láìṣeéfàtu. Èyí ti mú àwọn ìbùkún jìngbìnnì wá fún wọn àti fún àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá,” tí wọ́n ní ìrètí ìyè gẹ́gẹ́ bí ọmọ abẹ́ Ìjọba náà lórí ilẹ̀-ayé. (Jeremiah 32:39; Ìṣípayá 7:9) Ìbẹ̀rù Jehofa ti wà ní ọkàn-àyà wọn pẹ̀lú.
Bí A Ṣe Gbin Ìbẹ̀rù Ọlọrun Sínú Ọkàn-Àyà Wa
17. Báwo ni Jehofa ti ṣe fi ìbẹ̀rù Ọlọrun sínú ọkàn-àyà wa?
17 Báwo ni Jehofa ṣe gbin ìbẹ̀rù Ọlọrun yìí sínú ọkàn-àyà wa? Nípasẹ̀ ìṣiṣẹ́ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Kí sì ni a ní tí ó jẹ́ àmújáde ẹ̀mí mímọ́? Bibeli, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí a mísí. (2 Timoteu 3:16, 17) Nípa ohun tí ó ti ṣe ní ìgbà àtijọ́, nípasẹ̀ ọ̀nà tí ó gbà ń bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lò nísinsìnyí ní ìmúṣẹ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti nípasẹ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí ń bọ̀, Jehofa ń pèsè ìdí yíyèkooro fún gbogbo wa láti mú ìbẹ̀rù Ọlọrun dàgbà.—Joṣua 24:2-15; Heberu 10:30, 31.
18, 19. Báwo ni àwọn àpéjọpọ̀, àwọn àpéjọ, àti ìpàdé ìjọ ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìbẹ̀rù Ọlọrun?
18 Ó yẹ fún àfiyèsí pé, gẹ́gẹ́ bí a ti ròyìn rẹ̀ ní Deuteronomi 4:10, Jehofa sọ fún Mose pé: “Pe àwọn ènìyàn yìí jọ fún mi, èmi óò sì mú wọn gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, kí wọn kí ó lè máa kọ́ àtibẹ̀rù mi ní ọjọ́ gbogbo tí wọn óò wà lórí ilẹ̀, àti kí wọn kí ó lè máa kọ àwọn ọmọ wọn.” Lọ́nà kan náà lónìí, Jehofa ti ṣe ìpèsè yanturu láti ran àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́wọ́ láti kọ́ àtibẹ̀rù rẹ̀. Ní àwọn àpéjọpọ̀, àwọn àpéjọ, àti àwọn ìpàdé ìjọ, a ń ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa àwọn ẹ̀rí inúrere-ìfẹ́ Jehofa àti ìwàrere-ìṣeun rẹ̀. Ìyẹn ni ohun tí a ń ṣe nígbà tí a ń kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Báwo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ yẹn ṣe nípa lórí rẹ àti ìṣesí rẹ sí Jehofa? Bí o ti rí onírúurú ìhà ànímọ́ gígalọ́lá tí Bàbá wa ọ̀run ní tí ó hàn lára Ọmọkùnrin rẹ̀, èyí kò ha fún ìfẹ́-ọkàn rẹ lókun láti máṣe mú Ọlọrun banújẹ́ láé bí?—Kolosse 1:15.
19 Ní àwọn ìpàdé wa, a tún ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn àkọsílẹ̀ ìgbàlà tí Jehofa ṣe fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ìgbà àtijọ́. (2 Samueli 7:23) Bí a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìtẹ̀jáde tí a gbékarí Bibeli, a ń kọ́ nípa àwọn ìran alásọtẹ́lẹ̀ tí wọ́n ti ní ìmúṣẹ ní ọ̀rúndún ogún yìí àti nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ tí ń múni kún fún ìbẹ̀rù. Nípa irú àwọn àmúwá Ọlọrun bẹ́ẹ̀, Orin Dafidi 66:5 (NW) sọ pé: “Ẹ wá, ẹ̀yin ènìyàn, kí ẹ sì rí àwọn ìgbòkègbodò Ọlọrun. Ìbálò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ènìyàn ń múni kún fún ìbẹ̀rù.” Bẹ́ẹ̀ni, bí a bá fi ojú tí ó tọ́ wò ó, àwọn ìṣe wọ̀nyí tí ó jẹ́ ti Ọlọrun gbin ìbẹ̀rù Jehofa, ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ sínú ọkàn-àyà wa. Nípa báyìí a lè lóye bí Jehofa ṣe ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé: “Èmi óò fi ìbẹ̀rù mi sí ọkàn wọn, tí wọn kì [yóò] lọ kúrò lọ́dọ̀ mi.”—Jeremiah 32:40.
20. Kí ó baà lè ṣeé ṣe fún ìbẹ̀rù Ọlọrun láti fìdí múlẹ̀ ṣinṣin nínú ọkàn-àyà wa, kí ni a ń béèrè níhà ọ̀dọ̀ wa?
20 Bí ó ti wù kí ó rí, ó ṣe kedere pé, ìbẹ̀rù yìí kì í wà ní ọkàn-àyà wa láìsí ìsapá àtọkànwá láti ìhà ọ̀dọ̀ wa. Àbájáde náà kì í kàn ṣàdédé wáyé. Jehofa ń ṣe ipa tirẹ̀. A gbọ́dọ̀ ṣe ipa tiwa nípa mímú ìbẹ̀rù Ọlọrun dàgbà. (Deuteronomi 5:29) Israeli àbínibí kùnà láti ṣe ìyẹn. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jehofa, Israeli tẹ̀mí àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ wọn ti ń ní ìrírí ọ̀pọ̀ àǹfààní tí ń wá sọ́dọ̀ àwọn wọnnì tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọrun. A óò gbé díẹ̀ lára àwọn àǹfààní wọ̀nyí yẹ̀wò nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí yóò tẹ̀lé e.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Kí ni ìbẹ̀rù Ọlọrun?
◻ Báwo ni a ṣe ń kọ́ wa láti rí ìgbádùn nínú ìbẹ̀rù Jehofa?
◻ Láti ní ìbẹ̀rù Ọlọrun, ìsapá wo ni a ń béèrè níhà ọ̀dọ̀ wa?
◻ Èéṣe tí níní ìbẹ̀rù Ọlọrun ṣe wémọ́ gbogbo apá ẹ̀ka ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ wa?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12, 13]
Ó ń béèrè ìkẹ́kọ̀ọ́ aláápọn láti lè lóye ìbẹ̀rù Jehofa