Ẹ Jẹ́ Ká Jọ Gbé Orúkọ Jèhófà Ga
“Ẹ gbé Jèhófà ga lọ́lá pẹ̀lú mi, ẹ sì jẹ́ kí a jọ gbé orúkọ rẹ̀ ga.”—SÁÀMÙ 34:3.
1. Àpẹẹrẹ tó dára wo ni Jésù fi lélẹ̀ nígbà tó ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé?
NÍ ALẸ́ ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù Nísàn, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ jọ kọ orin ìyìn sí Jèhófà nínú yàrá òkè kan ní Jerúsálẹ́mù. (Mátíù 26:30) Ìyẹn nìgbà ìkẹyìn tí Jésù máa bá àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ kọrin ìyìn. Àmọ́, ó dára gan-an pé ọ̀nà yẹn ló gbà parí ìpàdé tó bá wọn ṣe. Látìgbà tí Jésù ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé títí tó fi parí rẹ̀, ńṣe ló ń yin Bàbá rẹ̀ tó sì gbájú mọ́ sísọ orúkọ Bàbá rẹ̀ di mímọ̀. (Mátíù 4:10; 6:9; 22:37, 38; Jòhánù 12:28; 17:6) Àwọn ohun tó ṣe yìí fi hàn pé ó fára mọ́ bí onísáàmù náà ṣe rọ àwọn èèyàn tìfẹ́tìfẹ́ pé: “Ẹ gbé Jèhófà ga lọ́lá pẹ̀lú mi, ẹ sì jẹ́ kí a jọ gbé orúkọ rẹ̀ ga.” (Sáàmù 34:3) Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà tó yẹ ká tẹ̀ lé lèyí jẹ́!
2, 3. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé àsọtẹ́lẹ̀ lohun tó wà nínú Sáàmù kẹrìnlélọ́gbọ̀n? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e?
2 Wákàtí díẹ̀ lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Jòhánù kọ àwọn orin ìyìn yẹn pẹ̀lú Jésù, ó tún rí ohun mìíràn tó yàtọ̀ pátápátá. Wọ́n pa ọ̀gá rẹ̀ àtàwọn ọ̀daràn méjì míì lórí igi oró níṣojú rẹ̀. Àwọn ọmọ ogun Róòmù ṣẹ́ ẹsẹ̀ àwọn ọ̀daràn méjì náà kí wọ́n bàa lè tètè kú. Àmọ́, Jòhánù sọ pé wọn ò ṣẹ́ ẹsẹ̀ Jésù ní tiẹ̀. Ìdí ni pé ó ti kú káwọn sójà náà tó dé ọ̀dọ́ rẹ̀. Nínú ìwé Ìhìn Rere tí Jòhánù kọ, ó sọ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn jẹ́ ìmúṣẹ apá mìíràn nínú Sáàmù kẹrìnlélọ́gbọ̀n tó ní: “A kì yóò fọ́ ìkankan nínú egungun rẹ̀.”—Jòhánù 19:32-36; Sáàmù 34:20.
3 Sáàmù kẹrìnlélọ́gbọ̀n tún ní ọ̀pọ̀ kókó mìíràn nínú táwọn Kristẹni á nífẹ̀ẹ́ sí. Nítorí náà, nínú àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e, a óò ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ipò tí Dáfídì wà tó fi kọ sáàmù yìí. Lẹ́yìn náà, a ó jíròrò àwọn ohun tó lè fún wa níṣìírí nínú sáàmù náà fúnra rẹ̀.
Dáfídì Sá Lọ Nítorí Sọ́ọ̀lù
4. (a) Kí nìdí tí Sámúẹ́lì fi lọ fòróró yan Dáfídì láti di ọba Ísírẹ́lì lọ́jọ́ iwájú? (b) Kí ló mú kí Sọ́ọ̀lù “wá nífẹ̀ẹ́” Dáfídì gidigidi?
4 Sọ́ọ̀lù ni ọba ilẹ̀ Ísírẹ́lì nígbà tí Dáfídì wà lọ́dọ̀ọ́. Àmọ́ Sọ́ọ̀lù di aláìgbọràn, Jèhófà sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Èyí ló mú kí wòlíì Sámúẹ́lì sọ fún un pé: “Jèhófà ti fa ìṣàkóso ọba Ísírẹ́lì ya kúrò lọ́wọ́ rẹ lónìí, dájúdájú, yóò sì fi í fún ọmọnìkejì rẹ tí ó sàn jù ọ́.” (1 Sámúẹ́lì 15:28) Lẹ́yìn ìgbà náà, Jèhófà sọ fún Sámúẹ́lì pé kó lọ fòróró yan Dáfídì tó jẹ́ àbíkẹ́yìn lára àwọn ọmọkùnrin Jésè gẹ́gẹ́ bí ọba tó máa rọ́pò Sọ́ọ̀lù. Ní gbogbo àkókò yìí, ìdààmú ọkàn tó le gan-an ti máa ń dé bá Sọ́ọ̀lù Ọba nítorí pé kò lẹ́mìí Ọlọ́run mọ́. Bí wọ́n ṣe mú Dáfídì tó jẹ́ kọrinkọrin wá sílùú Gíbíà nìyẹn láti wá máa kọrin fún Sọ́ọ̀lù, orin Dáfídì sì mára tu Sọ́ọ̀lù gan-an. Èyí mú kí Sọ́ọ̀lù “wá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gidigidi.”—1 Sámúẹ́lì 16:11, 13, 21, 23.
5. Kí nìdí tí ìwà Sọ́ọ̀lù sí Dáfídì fi yí padà, kí ló sì di dandan kí Dáfídì ṣe?
5 Bí àkókò ti ń lọ, Jèhófà wà pẹ̀lú Dáfídì. Ó ràn án lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun òmìrán ará Filísínì tó ń jẹ́ Gòláyátì, ó sì tún fi hàn pé òun ti Dáfídì lẹ́yìn nítorí pé àwọn èèyàn Ísírẹ́lì ṣàyẹ́sí Dáfídì fún jíjẹ́ tó jẹ́ akọni lójú ogun. Àmọ́ Sọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí í jowú nítorí pé Jèhófà ń bù kún Dáfídì, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í kórìíra rẹ̀. Ẹ̀ẹ̀méjì ni Sọ́ọ̀lù sọ ọ̀kọ̀ láti fi gún Dáfídì pa bó ti ń fi háàpù rẹ̀ kọrin fún Sọ́ọ̀lù lọ́wọ́. Àmọ́ Dáfídì yẹ ọ̀kọ̀ náà nígbà méjèèjì. Nígbà tí Sọ́ọ̀lù gbìyànjú lẹ́ẹ̀kẹta láti pa Dáfídì tó máa tó di ọba Ísírẹ́lì, ó rí i pé òun ní láti tètè sá lọ tóun ò bá fẹ́ kú. Níkẹyìn, nítorí pé Sọ́ọ̀lù kò dẹ̀yìn lẹ́yìn rẹ̀, tó ṣáà ń wá ọ̀nà láti pa á, Dáfídì pinnu láti sá lọ síbi tó jìnnà sílẹ̀ Ísírẹ́lì.—1 Sámúẹ́lì 18:11; 19:9, 10.
6. Kí nìdí tí Sọ́ọ̀lù fi pàṣẹ pé kí wọ́n pa àwọn èèyàn tó ń gbé ìlú Nóbù?
6 Bí Dáfídì ti ń lọ sí ààlà orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, ó dúró nílùú Nóbù, níbi tí àgọ́ ìjọsìn Jèhófà wà. Kò sí àní-àní pé bí Dáfídì ti ń sá lọ, àwọn ọ̀dọ́kùnrin kan bá a lọ, Dáfídì sì wọ́nà àtirí oúnjẹ díẹ̀ fún wọn àti fún ara rẹ̀. Sọ́ọ̀lù gbọ́ pé àlùfáà àgbà ti fún Dáfídì àtàwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní oúnjẹ díẹ̀ àti idà tí Dáfídì gbà lọ́wọ́ Gòláyátì nígbà tó pa á. Èyí bí Sọ́ọ̀lù nínú ó sì ní kí wọ́n pa gbogbo àwọn èèyàn ìlú náà, títí kan àwọn àlùfáà márùnlélọ́gọ́rin tó wà níbẹ̀.—1 Sámúẹ́lì 21:1, 2; 22:12, 13, 18, 19; Mátíù 12:3, 4.
Ó Tún Bọ́ Lọ́wọ́ Ikú
7. Kí nìdí tí ìlú Gátì kò fi jẹ́ ibi tí Dáfídì lè forí pa mọ́ sí?
7 Láti ìlú Nóbù, Dáfídì sá gba apá gúúsù lọ sílẹ̀ àwọn Filísínì tó jẹ́ nǹkan bí ogójì kìlómítà sílùú Nóbù, ó sì sá sọ́dọ̀ Ákíṣì ọba ìlú Gátì tó jẹ́ ìlú Gòláyátì. Ó ṣeé ṣe kí Dáfídì rò pé Sọ́ọ̀lù kò jẹ́ wá òun wá sílùú Gátì láé. Àmọ́ kò pẹ́ rárá tó débẹ̀ tí àwọn ìránṣẹ́ ọba ìlú Gátì fi dá Dáfídì mọ̀. Nígbà tó ta sí Dáfídì létí pé wọ́n ti dá òun mọ̀, ó “fòyà gidigidi ní tìtorí Ákíṣì ọba Gátì.”—1 Sámúẹ́lì 21:10-12.
8. (a) Kí ni Sáàmù kẹrìndínlọ́gọ́ta sọ fún wa nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì ní Gátì? (b) Báwo ni Dáfídì ṣe bọ́ lọ́wọ́ ikú?
8 Báwọn ará Filísínì ṣe mú Dáfídì nìyẹn. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àkókò yìí ló ṣàkójọ sáàmù àtọkànwá yẹn, níbi tó ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà pé: “Fi omijé mi sínú ìgò awọ rẹ.” (Sáàmù 56:8 àti àkọlé) Ó tipa báyìí fi hàn pé òun gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé kò ní gbàgbé ìbànújẹ́ òun, pé yóò bójú tó òun tìfẹ́tìfẹ́, pé á sì dá ẹ̀mí òun sí. Bákan náà, Dáfídì ta ọgbọ́n kan láti fi tan ọba ìlú Filísínì jẹ. Ó ṣe bíi pé wèrè lòun. Nígbà tí Ákíṣì Ọba rí èyí, ó sọ̀kò ọ̀rọ̀ sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí ló dé tí wọ́n mú “ayírí” èèyàn wá síwájú òun? Ó hàn gbangba pé Jèhófà mú kí ọgbọ́n tí Dáfídì ta yẹn yọrí sí rere. Bí wọ́n ṣe lé Dáfídì jáde kúrò nínú ìlú náà nìyẹn, ó sì tún tipa báyìí bọ́ lọ́wọ́ ikú.—1 Sámúẹ́lì 21:13-15.
9, 10. Kí ló ṣẹlẹ̀ tó mú kí Dáfídì kọ Sáàmù kẹrìnlélọ́gbọ̀n, àwọn wo ló sì ṣeé ṣe kí Dáfídì ní lọ́kàn nígbà tó ń ṣàkójọ sáàmù náà?
9 Bíbélì kò sọ bóyá àwọn alátìlẹyìn Dáfídì bá a sá lọ sílùú Gátì tàbí bóyá ńṣe ni wọ́n dúró sáwọn abúlé ilẹ̀ Ísírẹ́lì tí kò jìnnà síbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí amí láti dáàbò bò ó. Yálà bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó dájú pé inú wọn á dùn gan-an nígbà tí wọ́n padà rí Dáfídì tó sì sọ fún wọn bí Jèhófà tún ṣe kó òun yọ. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí làwọn ọ̀rọ̀ inú Sáàmù kẹrìnlélọ́gbọ̀n dá lé, gẹ́gẹ́ bí àkọlé sáàmù náà ti fi hàn. Ní ẹsẹ méje àkọ́kọ́ nínú sáàmù náà, Dáfídì yin Ọlọ́run pé ó kó òun yọ, ó sì rọ àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ pé kí wọ́n bá òun gbé Jèhófà ga, nítorí pé òun ni Agbẹ̀mílà tí kò lẹ́gbẹ́ tó ń kó àwọn èèyàn rẹ̀ yọ.—Sáàmù 34:3, 4, 7.
10 Dáfídì àtàwọn èèyàn rẹ̀ fara pa mọ́ sínú àwọn ihò àpáta Ádúlámù tó jẹ́ àgbègbè tí òkè pọ̀ sí nílẹ̀ Ísírẹ́lì, ibẹ̀ sì jẹ́ nǹkan bíi kìlómítà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí ìlú Gátì lápá ìlà oòrùn. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tínú wọn ò dùn sí bí ipò nǹkan ṣe rí lábẹ́ àkóso Sọ́ọ̀lù Ọba bẹ̀rẹ̀ sí í wá bá wọn níbẹ̀, wọ́n sì ń dára pọ̀ mọ́ wọn. (1 Sámúẹ́lì 22:1, 2) Nígbà tí Dáfídì ṣàkójọ àwọn ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 34:8-22, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn èèyàn wọ̀nyẹn ló ní lọ́kàn. Àwọn ìránnilétí tó wà nínú àwọn ẹsẹ yìí ṣe pàtàkì fáwa náà lónìí, ó sì dájú pé a ó jàǹfààní látinú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìjíròrò tá a máa ṣe nípa sáàmù tó ń fúnni níṣìírí yìí.
Ṣé Ohun Tó Jẹ Dáfídì Lọ́kàn Jù, Ló Jẹ Ìwọ Náà Lọ́kàn Jù?
11, 12. Àwọn ìdí wo ló fi yẹ ká máa yin Jèhófà nígbà gbogbo?
11 “Ṣe ni èmi yóò máa fi ìbùkún fún Jèhófà ní gbogbo ìgbà; ìgbà gbogbo ni ìyìn rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi.” (Sáàmù 34:1) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ńṣe ni Dáfídì ń sá kiri, ó dájú pé yóò ṣàníyàn gan-an nípa ọ̀pọ̀ nǹkan ti ara tó nílò, àmọ́ kò jẹ́ káwọn nǹkan tó nílò lójoojúmọ́ yìí borí ìpinnu rẹ̀ láti yin Jèhófà. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà lèyí jẹ́ fún wa nígbà tá a bá wà nínú ìṣòro! Yálà iléèwé la wà, tàbí ibi iṣẹ́, tàbí a wà pẹ̀lú àwọn Kristẹni bíi tiwa, tàbí kẹ̀ a wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ohun tó yẹ kó jẹ wá lọ́kàn jù ni bá a ó ṣe máa yin Jèhófà. Ìwọ tiẹ̀ ronú ná lórí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìdí tó fi yẹ ká máa yin Jèhófà! Bí àpẹẹrẹ, àwọn ohun tá a lè rí tó sì lè fún wa láyọ̀ nínú àwọn ohun tí Jèhófà dá tí wọ́n jẹ́ àgbàyanu kò níye. Sì tún wo ohun tó ti gbéṣe nípa lílo apá ti orí ilẹ̀ ayé lára ètò rẹ̀! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé làwọn olóòótọ́ èèyàn tí Jèhófà ń lò, síbẹ̀ ó ti lò wọ́n lọ́nà tó kàmàmà lákòókò tiwa yìí. Ǹjẹ́ a lè fi àwọn iṣẹ́ ọwọ́ Jèhófà wé iṣẹ́ ọwọ́ àwọn èèyàn táráyé sọ dòrìṣà? Ǹjẹ́ ìwọ náà ò gbà pẹ̀lú Dáfídì, ẹni tó sọ pé: “Jèhófà, kò sí ẹni tí ó dà bí rẹ nínú àwọn ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni kò sí iṣẹ́ kankan tí ó dà bí tìrẹ”?—Sáàmù 86:8.
12 Bíi ti Dáfídì, a fẹ́ láti máa yin Jèhófà nígbà gbogbo nítorí àwọn iṣẹ́ rẹ̀ tí kò láfiwé. Ìyẹn nìkan kọ́, mímọ̀ tá a mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ti wà lọ́wọ́ Jésù Kristi báyìí, ẹni tó máa jogún Dáfídì títí láé, ń múnú wa dùn gan-an. (Ìṣípayá 11:15) Èyí túmọ̀ sí pé òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ti sún mọ́lé. Ọjọ́ ọ̀la àwọn èèyàn tó lé ní bílíọ̀nù mẹ́fà wà nínú ewu. Kò tíì sígbà kan tó ṣe pàtàkì tó àkókò yìí láti sọ fáwọn èèyàn nípa Ìjọba Ọlọ́run àtohun tó máa tó ṣe fún aráyé, àti láti ràn wọ́n lọ́wọ́ káwọn náà lè máa yin Jèhófà. Ó dájú pé ohun tó yẹ ká fi ṣáájú nígbèésí ayé wa ni bá a ṣe máa lo àǹfààní èyíkéyìí tá a bá ní láti fún àwọn èèyàn níṣìírí pé kí wọ́n tẹ́wọ́ gba ìhìnrere Ìjọba Ọlọ́run kó tó pẹ́ jù.—Mátíù 24:14.
13. (a) Ta ni Dáfídì fi yangàn, irú àwọn èèyàn wo ló sì tipa báyìí wá sọ́dọ̀ Jèhófà? (b) Kí ló ń mú káwọn ọlọ́kàn tutù wá sínú ìjọ Kristẹni lónìí?
13 “Ọkàn mi yóò máa ṣògo nínú Jèhófà; àwọn ọlọ́kàn tútù yóò gbọ́, wọn yóò sì máa yọ̀.” (Sáàmù 34:2) Nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí, Dáfídì kò fi àwọn ohun tó gbéṣe yangàn. Bí àpẹẹrẹ, kò fọ́nnu nípa ọ̀nà tó gbà tan ọba ìlú Gátì jẹ. Ó mọ̀ pé Jèhófà ló dáàbò bo òun nígbà tóun wà nílùú Gátì, àti pé Jèhófà ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fóun láti bọ́ lọ́wọ́ ikú. (Òwe 21:1) Nípa báyìí, ńṣe ni Dáfídì ń fi ohun tó ṣe yìí yìn Jèhófà lógo. Níwọ̀n bí Dáfídì ti gbé Jèhófà ga, ó wu àwọn ọlọ́kàn tútù èèyàn láti wá sọ́dọ̀ Jèhófà. Jésù náà gbé orúkọ Jèhófà ga, èyí sì mú káwọn onírẹ̀lẹ̀, tí wọ́n rọrùn láti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ fẹ́ láti wá sọ́dọ̀ Jèhófà. Lóde òní, àwọn tó jẹ́ ọlọ́kàn tútù látinú gbogbo orílẹ̀-èdè ń wá sínú ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà káàkiri ayé, èyí tí Jésù jẹ́ Orí rẹ̀. (Kólósè 1:18) Ohun tó ń mú àwọn ọlọ́kàn tútù wá sínú ìjọ Kristẹni ni gbígbọ́ tí wọ́n ń gbọ́ táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ń gbé orúkọ rẹ̀ ga, tí wọ́n sì ń gbọ́ ọ̀rọ̀ inú Bíbélì tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye rẹ̀.—Jòhánù 6:44; Ìṣe 16:14.
Àwọn Ìpàdé Kristẹni Ń Mú Kí Ìgbàgbọ́ Wa Lágbára
14. (a) Ǹjẹ́ ìgbà tí Dáfídì bá dá wà nìkan ló ń yin Jèhófà? (b) Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ nípa àwọn ìpàdé tá a ti ń jọ́sìn Ọlọ́run?
14 “Ẹ gbé Jèhófà ga lọ́lá pẹ̀lú mi, ẹ sì jẹ́ kí a jọ gbé orúkọ rẹ̀ ga.” (Sáàmù 34:3) Kì í ṣe ìgbà tí Dáfídì bá dá wà nìkan ló ń yin Jèhófà. Tìfẹ́tìfẹ́ ló fi ké sáwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n jẹ́ káwọn jọ gbé orúkọ Ọlọ́run ga. Bákan náà lọ̀rọ̀ rí pẹ̀lú Jésù Kristi tó jẹ́ Dáfídì Ńlá náà. Inú rẹ̀ dùn gan-an láti máa yin Jèhófà láàárín àwọn èèyàn, ìyẹn nínú sínágọ́gù, nígbà àwọn àjọyọ̀ tí wọ́n máa ń ṣe nínú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run ní Jerúsálẹ́mù, àti nígbà tó wà pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. (Lúùkù 2:49; 4:16-19; 10:21; Jòhánù 18:20) Ẹ ò rí i pé àǹfààní tó ń fúnni láyọ̀ la ní láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nínú yíyin Jèhófà pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwa ní gbogbo ìgbà tó bá ti ṣeé ṣe, pàápàá jù lọ lákòókò yìí, bá a ti “rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé”!—Hébérù 10:24, 25.
15. (a) Ipa wo lohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì ní lórí àwọn èèyàn rẹ̀? (b) Báwo la ṣe ń jàǹfààní nínú wíwá sáwọn ìpàdé wa?
15 “Mo wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, ó sì dá mi lóhùn, ó sì dá mi nídè nínú gbogbo jìnnìjìnnì mi.” (Sáàmù 34:4) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì yìí jọ ọ́ lójú gan-an. Ìdí nìyẹn tó tún fi sọ pé: “Ẹni yìí tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pè, Jèhófà tìkára rẹ̀ sì gbọ́. Ó sì gbà á là nínú gbogbo wàhálà rẹ̀.” (Sáàmù 34:6) Nígbà tá a bá wà pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwa, a ní ọ̀pọ̀ àǹfààní láti sọ àwọn ìrírí tó lè fún wọn níṣìírí nípa bí Jèhófà ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àwọn ipò tó nira. Èyí máa ń mú kí ìgbàgbọ́ àwọn ará wa lágbára, gẹ́gẹ́ báwọn ohun tí Dáfídì sọ ṣe mú ìgbàgbọ́ àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ lágbára. Nígbà tí Dáfídì ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ “gbára lé [Jèhófà] wọ́n sì wá tàn yinrin, ojú wọn ni kò sì ṣeé ṣe láti kó ìtìjú bá.” (Sáàmù 34:5) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n ń sá fún Sọ́ọ̀lù Ọba lákòókò náà, ojú kò tì wọ́n. Ó dá wọn lójú pé Ọlọ́run ń ti Dáfídì lẹ́yìn, ayọ̀ sì hàn lójú wọn. Lọ́nà kan náà, àwọn ẹni tuntun tí wọ́n fẹ́ láti jọ́sìn Jèhófà àtàwọn tó ti jẹ́ Kristẹni tòótọ́ tipẹ́ ń gbára lé Jèhófà pé yóò ti àwọn lẹ́yìn. Nítorí pé wọ́n ti rí àwọn ọ̀nà tó gbà ràn wọ́n lọ́wọ́, ayọ̀ tó ń hàn lójú wọn fi hàn pé wọ́n ti pinnu láti máa jẹ́ olóòótọ́ títí lọ.
Mọrírì Ìrànlọ́wọ́ Táwọn Áńgẹ́lì Ń Ṣe
16. Ọ̀nà wo ni Jèhófà ti gbà lo àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láti dáàbò bò wá?
16 “Áńgẹ́lì Jèhófà dó yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká, ó sì ń gbà wọ́n sílẹ̀.” (Sáàmù 34:7) Dáfídì mọ̀ pé kì í ṣe òun nìkan ni Jèhófà lè kó yọ nínú ewu. Lóòótọ́, ẹni àmì òróró Jèhófà tó máa ṣàkóso lórí ilẹ̀ Ísírẹ́lì ni Dáfídì. Síbẹ̀ ó mọ̀ pé Jèhófà máa ń lo àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láti dáàbò bo gbogbo àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ tó jẹ́ olóòótọ́, yálà wọ́n jẹ́ ẹni tó gbajúmọ̀ tàbí ẹni tó wà nípò tó rẹlẹ̀. Lóde òní náà, àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ ti rí bí Jèhófà ṣe ń dáàbò bò wọ́n. Lákòókò tí ìjọba Násì ń ṣàkóso, àwọn aláṣẹ gbógun ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti rí i pé wọn ò sí mọ́ nílẹ̀ Jámánì, àti láwọn orílẹ̀-èdè bí Àǹgólà, Màláwì, Mòsáńbíìkì, àtàwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Àmọ́ asán ni gbogbo ìsapá wọn já sí. Kàkà kí èyí ṣẹlẹ̀, ńṣe làwọn èèyàn Jèhófà láwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ń pọ̀ sí i bí wọ́n ti ń jùmọ̀ gbé orúkọ Ọlọ́run ga. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jèhófà ń lo àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ mímọ́ láti dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ àti láti tọ́ wọn sọ́nà.—Hébérù 1:14.
17. Àwọn ọ̀nà wo làwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run ń gbà ràn wá lọ́wọ́?
17 Láfikún sí i, àwọn áńgẹ́lì Jèhófà tún lè rí sí i pé ẹnikẹ́ni tó bá ń mú àwọn mìíràn kọsẹ̀ á dẹni tá a mú kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀. (Mátíù 13:41; 18:6, 10) Àwọn áńgẹ́lì sì lè mú àwọn ohun tó ṣeé ṣe kó ṣèdíwọ́ fún iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run kúrò, wọ́n sì ń dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn ohun tó lè ba àjọṣe àárín àwa àti Jèhófà jẹ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè má mọ̀ nígbà tí nǹkan wọ̀nyẹn bá ṣẹlẹ̀. Èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé, wọ́n ń tọ́ wa sọ́nà lẹ́nu iṣẹ́ kíkéde “ìhìn rere àìnípẹ̀kun” fún gbogbo aráyé, títí kan àwọn ibi tó jẹ́ pé inú ewu làwọn arákùnrin wa ti ń ṣiṣẹ́ ìwàásù. (Ìṣípayá 14:6) Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé àwọn áńgẹ́lì ń ṣèrànwọ́ ti jáde nínú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.a Àwọn ìrírí wọ̀nyí pọ̀ kọjá kéèyàn rò pé àwọn nǹkan yẹn ṣèèṣì ṣẹlẹ̀.
18. (a) Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ káwọn áńgẹ́lì ràn wá lọ́wọ́? (b) Kí la óò jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
18 Káwọn áńgẹ́lì tó lè máa tọ́ wa sọ́nà kí wọ́n sì máa dáàbò bò wá nìṣó, a gbọ́dọ̀ máa bá a lọ láti máa gbé orúkọ Jèhófà ga, kódà nígbà táwọn èèyàn bá ń ṣe inúnibíni sí wa. Rántí pé, kìkì “àwọn tí ó bẹ̀rù [Jèhófà]” nìkan ni áńgẹ́lì Ọlọ́run ń dáàbò bò. Kí lèyí túmọ̀ sí? Kí ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run, báwo la sì ṣe lè ní in? Kí nìdí tí Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ ṣe fẹ́ ká bẹ̀rù òun? A ó dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ìwé Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom, ojú ìwé 550; ìwé ọdọọdún náà, Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ti ọdún 2005, ojú ìwé 53 sí 54; Ilé Ìṣọ́, March 1, 2000, ojú ìwé 5 àti 6; January 1, 1991, ojú ìwé 27; àti February 15, 1991, ojú ìwé 26.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Àwọn ìṣòro wo ni Dáfídì fara dà nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́?
• Bíi ti Dáfídì, kí lohun tó ń jẹ wá lọ́kàn jù?
• Ojú wo la fi ń wo àwọn ìpàdé Kristẹni?
• Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà ń gbà lo àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́?
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 21]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Rámà
Gátì
Síkílágì
Gíbíà
Nóbù
Jerúsálẹ́mù
Bẹ́tílẹ́hẹ́mù
Ádúlámù
Kéílà
Hébúrónì
Sífù
Hóréṣì
Kámẹ́lì
Máónì
Ẹ́ń-gédì
Òkun Iyọ̀
[Credit Line]
Àwòrán-ilẹ̀: Based on maps copyrighted by Pictorial Archive (Near Eastern History) Est. and Survey of Israel
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Kódà, nígbà tí Dáfídì ń sá kiri, ó gbé orúkọ Jèhófà ga
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ìgbàgbọ́ wa ń lágbára sí i bá a ti ń gbọ́ àwọn ìrírí tó lè gbé wa ró láwọn àpéjọ wa