“Jesu Kristi Ni Oluwa”—Báwo àti Nígbà Wo?
“OLUWA wí fún Oluwa mi pé, Ìwọ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí èmi óò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di àpótí-ìtìsẹ̀ rẹ.” Bí ìtumọ̀ ti King James Version ṣe kà ní Orin Dafidi 110:1 nìyẹn. Ta ni “OLUWA” níhìn-ín, ta ni ó sì ń bá sọ̀rọ̀?
Ìtumọ̀ ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ tí ó túbọ̀ péye lédè Heberu yára dáhùn ìbéèrè àkọ́kọ́. “Ọ̀rọ̀ ìsọjáde Jehofa sì Oluwa mi ni pé: . . . ” Nípa báyìí, “OLUWA” ní ìkọ̀wé gàdàgbà gàdàgbà tọ́kasí Ọlọrun Olódùmarè, Jehofa fúnraarẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé King James Version jẹ́wọ́ orúkọ àtọ̀runwá náà nípa lílo “OLUWA” dípò “Oluwa,” kìí ṣe òun ni àkọ́kọ́ láti gbé orúkọ oyè wọ̀nyí síra wọn, nítorí pé Septuagint ti ìgbàanì tí a kọ ní èdè Griki, tí a tú láti inú èdè Heberu, lo “Oluwa” fún Jehofa nínú àwọn ẹ̀dà rẹ̀ tí ó jáde lẹ́yìn náà. Èéṣe? Nítorí pé orúkọ oyè náà “Oluwa” ni a fi dípò orúkọ àtọ̀runwá náà, àmì-ọ̀rọ̀ Heberu mẹ́rin fún orúkọ Ọlọrun (יהוה). Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ A. E. Garvie sọ pé: “Ìlò orúkọ oyè náà Oluwa [kyʹri·os] ní ó lè ṣeéṣe láti ṣàlàyé lọ́nà rírọrùn láti inú ìlo orúkọ oyè náà nínu sínágọ́gù àwọn Ju dípò orúkọ májẹ̀mú náà Yahveh [Jehovah], nígbà tí wọ́n bá ń ka ìwé mímọ́.”
Bibeli fi Jehofa hàn gẹ́gẹ́ bí ‘Oluwa Ọba-alaṣẹ.’ (Genesisi 15:2, 8; Iṣe 4:24; Ìfihàn 6:10) A tún pè é ní “Oluwa Jehofa” àti “Oluwa ayé.” (Eksodu 23:17; Joṣua 3:13; Ìfihàn 11:4) Nígbà náà, ta ni, “Oluwa” kejì ní Orin Dafidi 110:1, àti pé báwo ni ó ṣe di ẹni tí Jehofa mọ̀ sí “Oluwa”?
Jesu Kristi Gẹ́gẹ́ Bí “Oluwa”
A pe Jesu ní “Oluwa” nínú àwọn ìwé Ìhìnrere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, lọ́pọ̀ ìgbà nínú Luku àti Johannu. Ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní C.E., orúkọ oyè náà jẹ́ èyí tí a fi ń bu ọ̀wọ̀ àti ìyìn fúnni, tí ó ṣe rẹ́gí pẹ̀lú “Ọ̀gá.” (Johannu 12:21; 20:15, Kingdom Interlinear) Nínú Ìhìnrere ti Marku ọ̀rọ̀ náà “Olùkọ́ni,” tàbí Rab·boʹni, ní a lò léraléra fún Jesu. (Fi Marku 10:51 wé Luku 18:41.) Àní ìbéèrè Saulu ní ojú ọ̀nà Damasku pé, “Ìwọ ta ni, Oluwa?” ní èrò gbogbogbòò ti fífi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ béèrè nǹkan. (Iṣe 9:5) Ṣùgbọ́n bí àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu ṣe wá mọ Ọ̀gá wọn sí, ó hàn kedere pé bí wọ́n ṣe ń lo orúkọ oyè náà “Oluwa” fi ohun tí ó ju ọ̀wọ̀ lásán hàn.
Tẹ̀lé ikú àti àjíǹde rẹ̀ ṣùgbọ́n ṣáájú ìgòkè re ọ̀run rẹ̀, Jesu farahan àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ó sì ṣe ìkéde amúnitagìrì yìí pé: “Gbogbo agbára ní ọ̀run àti ní ayé ni a fifún mi.” (Matteu 28:18) Lẹ́yìn náà, ní ọjọ́ Pẹntikọsti, lábẹ́ agbára ìdarí ẹ̀mí mímọ́ tí a tú jáde, Peteru tọ́ka sí Orin Dafidi 110:1 ó sì sọ pé: “Kí gbogbo ilé Israeli mọ̀ dájúdájú láìsí tàbí ṣùgbọ́n pé Ọlọrun fií ṣe Oluwa àti Kristi, Jesu yìí tí ẹ̀yin kànmọ́gi.” (Iṣe 2:34-36, NW) Nítorí ìṣòtítọ́ rẹ̀ títí dójú ikú títinilójú lórí òpó igi ìdálóró, a jí Jesu dìde a sì fún un ní èrè gígalọ́lá jùlọ. Nígbà náà ni ó wọnú ipò jíjẹ́ oluwa rẹ̀ nínú àwọn ọ̀run.
Aposteli Paulu jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ Peteru nígbà tí ó kọ̀wé pé Ọlọrun “fi í [Kristi] jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún nínú àwọn ọ̀run, ga ju gbogbo ìjọba àti ọlá, àti agbára, àti oyè, àti gbogbo orúkọ tí a ń dá, kìí ṣe ní ayé yìí nìkan, ṣùgbọ́n ní èyí tí ń bọ̀ pẹ̀lú.” (Efesu 1:20, 21) Ipò jíjẹ́ oluwa Jesu Kristi ju ipò jíjẹ́ oluwa èyíkéyìí lọ, yóò sì máa bá a lọ títí wọ inú ayé titun. (1 Timoteu 6:15) A gbé e ga “gidigidi” a sì fún un ní “orúkọ kan . . . tí ó borí gbogbo orúkọ” kí gbogbo ènìyàn lè mọ̀ “pé Jesu Kristi ni Oluwa ogo Ọlọrun Baba.” (Filippi 2:9-11) Nípa báyìí apá àkọ́kọ́ Orin Dafidi 110:1 ní a múṣẹ, tí a sì fi “àwọn angẹli, àti àwọn ọlọ́lá àti àwọn alágbára” sábẹ́ ipò jíjẹ́ Oluwa Jesu.—1 Peteru 3:22; Heberu 8:1.
Nínú Ìwé Mímọ́ lédè Heberu, gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà “Oluwa àwọn oluwa” ní a lò fún Jehofa nìkan ṣoṣo. (Deuteronomi 10:17; Orin Dafidi 136:2, 3) Ṣùgbọ́n Peteru lábẹ́ ìmísí sọ nípa Kristi Jesu pé: “Òun ni Oluwa ohun gbogbo [tàbí, “Oluwa gbogbo wa,” Goodspeed].” (Iṣe 10:36) Òun nítòótọ́ “jẹ́ Oluwa àti òkú àti alààyè.” (Romu 14:8, 9) Àwọn Kristian fi pẹ̀lú ìmúratán pe Jesu Kristi ni Oluwa àti Olówó wọn, wọ́n sì fi tìfẹ́-inú tìfẹ́-inú ṣe ìgbọràn sí i gẹ́gẹ́ bí ọmọ abẹ́ rẹ̀, tí ó fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tí ó ṣeyebíye jùlọ rà. Jesu Kristi pẹ̀lú sì ti ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba àwọn ọba àti Oluwa àwọn oluwa lórí ìjọ rẹ̀ láti Pẹntikọsti 33 C.E. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, láti 1914, a ti fún un ní ọlá-àṣẹ ọlọ́ba láti ṣàkóso ní ipò yẹn pẹ̀lú àwọn ọ̀tá rẹ̀ tí a sọ di “àpótí-ìtìsẹ̀ rẹ̀.” Àkókò ti tó fún un nísinsìnyí láti ‘máa jọba láàárín wọn,’ gbogbo rẹ̀ ní ìmúṣẹ Orin Dafidi 110:1, 2.—Heberu 2:5-8; Ìfihàn 17:14; 19:16.
Báwo, nígbà náà, ni a ṣe níláti lóye ọ̀rọ̀ ti Jesu sọ ṣáájú ikú àti àjíǹde rẹ̀, pé, “ohun gbogbo ni a fifún mi láti ọ̀dọ̀ Bàbá mi wá”? (Matteu 11:25-27; Luku 10:21, 22) Èyí kìí ṣe gbólóhùn gbígbòòrò bí àwọn tí a ti ṣàlàyé níṣàájú. Nínú Matteu àti Luku, àwọn ọ̀rọ̀ tí ó yí i ká fihàn pé Jesu ń sọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀ tí ó farasin fún àwọn ọlọgbọ́n ayé ṣùgbọ́n tí a ṣípayá rẹ̀ nítorí pé òun “mọ” Baba rẹ̀ “dáradára.” Nígbà tí ó ṣèrìbọmi nínú omi tí a sì bí i gẹ́gẹ́ bí Ọmọkùnrin Ọlọrun nípa tẹ̀mí, ó ṣeéṣe fún Jesu láti rántí ìwàláàyè rẹ̀ ní ọ̀run kí ó tó di ènìyàn àti gbogbo ìmọ̀ tí ó bá a rìn, ṣùgbọ́n èyí yàtọ̀ sí ipò jíjẹ́ oluwa tí ó ní lẹ́yìn náà.—Johannu 3:34, 35.
Fífìyàtọ̀ sí Jesu Kristi Gẹ́gẹ́ Bí Oluwa
Àwọn ìtumọ̀ kan nínú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki máa ń gbé ìṣoro dìde nígbà tí wọ́n bá ń tú àwọn ọ̀rọ̀ tí a fàyọ láti inú Ìwé Mímọ́ Léde Heberu tí ó tọ́ka ní kedere sí “OLUWA,” Jehofa Ọlọrun. Fún àpẹẹrẹ, fi Luku 4:19 wéra pẹ̀lú Isaiah 61:2 yálà nínú King James Version tàbí The New Jerusalem Bible. Àwọn kan ṣì ní èrò náà pé Jesu ti gba orúkọ-oyè náà “Oluwa” kúrò lọ́wọ́ Jehofa àti pé Jesu nínú ẹran-ara ni Jehofa níti gidi, ṣùgbọ́n kókó ìjiyàn kan lásán tí kò ní ìtìlẹ́yìn Ìwé Mímọ́ ni èyí jẹ́. Jehofa Ọlọrun àti Ọmọkùnrin rẹ̀, Jesu Kristi, ni a máa ń fìgbà gbogbo fi tìṣọ́ra tìṣọ́ra fìyàtọ̀sí láàárín ọ̀kan àti èkejì nínú Ìwé Mímọ́. Jesu sọ orúkọ Baba rẹ̀ di mímọ̀ ó sì ṣojú fún un.—Johannu 5:36, 37.
Nínú àwọn àpẹẹrẹ tí ó tẹ̀lé e yìí, kíyèsí bí àwọn ọ̀rọ̀ tí a fàyọ láti inú Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu ṣe farahàn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Griki. Jehofa Ọlọrun àti Ẹni Àmì Òróró rẹ̀, tàbí Messia, ní a mẹ́nukàn nínú Iṣe 4:24-27, èyí tí ó fa ọ̀rọ̀ yọ láti inú Orin Dafidi 2:1, 2. Àwọn àyíká ọ̀rọ̀ inú Romu 11:33, 34 níti kedere ń tọ́ka sí Ọlọrun, Orísun gbogbo ọgbọ́n àti ìmọ̀, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ kan tí a fàyọ láti inú Isaiah 40:13, 14. Ní kíkọ̀wé sí àwọn ìjọ ní Kọrinti, Paulu tún ọ̀rọ̀ tí a fàyọ náà sọ pé, “Ta ni ó mọ inú Oluwa?” ó sì fikún un pé: “Ṣùgbọ́n àwa ní inú Kristi.” Oluwa náà Jesu ṣí ohun tí ó jẹ́ èrò-inú Jehofa payá fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lórí àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀ràn pàtàkì.—1 Korinti 2:16.
Nígbà mìíràn ẹsẹ̀ kan nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu ń tọ́ka sí Jehofa, ṣùgbọ́n nítorí agbára àti ọlá-àṣẹ tí Ó fifún un, a mú un ṣẹ nínú Jesu Kristi. Orin Dafidi 34:8, fún àpẹẹrẹ, késí wa láti “tọ́ ọ wò, kí [a] sì ríi pé rere ní Oluwa.” Ṣùgbọ́n Peteru lo èyí fún Oluwa náà Jesu Kristi nígbà tí ó sọ pé: “Bí ẹ̀yin bá ti tọ́ ọ wò pé, olóore ni Oluwa.” (1 Peteru 2:3) Peteru mú ìlànà kan ó sì fihàn bí ó ṣe jẹ́ òtítọ́ pẹ̀lú nípa Jesu Kristi. Nípa gbígba ìmọ̀ nípa Jehofa Ọlọrun àti Jesu Kristi kí a sì ṣiṣẹ́ lé e lórí, àwọn Kristian lè gbádùn ìbùkún ọlọ́ràá láti ọ̀dọ̀ Baba náà àti Ọmọkùnrin rẹ̀. (Johannu 17:3) Bí Peteru ṣe ṣàyọlò rẹ̀ kò sọ Jehofa Oluwa Ọba Aláṣẹ di ẹnìkan náà pẹ̀lú Oluwa náà Jesu Kristi.—Wo àlàyé etí ìwé tí ó wà nísàlẹ̀ 1 Peteru 2:3.
Ipò tí Jehofa Ọlọrun àti Ọmọkùnrin rẹ̀, Jesu Kristi wà síra wọn, ní a mú ṣe kedere nígbà tí aposteli Paulu sọ pé: “Ṣùgbọ́n fún àwa Ọlọrun kan ní ń bẹ, Baba, lọ́wọ́ ẹni tí ohun gbogbo ti wá, àti ti ẹni tí gbogbo wa ń ṣe; àti Oluwa kanṣoṣo Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo wà, àti àwa nípasẹ̀ rẹ̀.” (1 Kọrinti 8:6; 12:5, 6) Ní kíkọ̀wé sí ìjọ Kristian ní Efesu, Paulu fi “Oluwa kan,” Jesu Kristi hàn, gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó yàtọ̀ pátápátá sí “Ọlọrun kan àti Baba gbogbo [ènìyàn].”—Efesu 4:5, 6.
Jehofa Ga Ju Ẹni Gbogbo Lọ
Láti ọdún 1914, àwọn ọ̀rọ̀ Ìfihàn 11:15 ti jásí òtítọ́: “Ìjọba ayé di ti Oluwa wa [Jehofa Ọlọrun] àti ti Kristi rẹ̀; oun ó sì jọba láé àti láéláé.” Ìwé atúmọ̀ èdè náà The New International Dictionary of New Testament Theology (Ìdìpọ̀ 2, ojú-ìwé 514) sọ pé: “Nígbà tí Kristi bá ti ṣẹ́pá gbogbo agbára (1 Kor. 15:25), òun yóò fi ara rẹ̀ sábẹ́ Ọlọrun Baba náà. Nípa èyí ipò jíjẹ́ oluwa Jesu yóò ti ṣàṣeyọrí góńgó rẹ̀ tí Ọlọrun yóò sì jẹ́ ohun gbogbo nínú ohun gbogbo (1 Kor. 15:28).” Ní òpin Ìgbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún rẹ̀, Kristi Jesu yóò dá agbára àti ọlá-àṣẹ tí a yàn lé e lọ́wọ́ tẹ́lẹ̀ náà padà fún Baba rẹ̀, Ọlọrun Olodumare. Nígbà náà, lọ́nà tí ó tọ̀nà gbogbo ògo àti ìjọsìn ni a ń fún Jehofa, “Ọlọrun Jesu Kristi Oluwa wa.”—Efesu 1:17.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jesu nísinsìnyí ni Oluwa àwọn oluwa, a kò fìgbàkan pè é ní Ọlọrun àwọn ọlọrun. Jehofa ṣì ní ẹni tí ó ga ju ẹni gbogbo lọ. Lọ́nà yìí, Jehofa yóò di “ohun gbogbo ní ohun gbogbo.” (1 Korinti 15:28) Ipò jíjẹ́ oluwa ti Jesu fún un ní àyè tí ó tọ́ sí i gẹ́gẹ́ bí Orí ìjọ Kristian. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè rí ọ̀pọ̀ “àwọn oluwa” alágbára ní ọ̀pọ̀ ibi gíga nínú ayé yìí, a fi ìgbọ́kànlé wa sínú ẹni náà tí ó jẹ́ Oluwa àwọn oluwa. Síbẹ̀, Jesu Kristi, nínú ipò gíga rẹ̀ tí a tún gbéga, ṣì wà lábẹ́ Baba rẹ̀, “kí Ọlọrun lè ṣàkóso lórí oun gbogbo.” (1 Korinti 15:28, The Translator’s New Testament) Ẹ wo irú àpẹẹrẹ ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tí Jesu fi lélẹ̀ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti tẹ̀lé, àní bí wọ́n ṣe jẹ́wọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Oluwa wọn!
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 30]
“Nígbà tí àwọn òǹkọ̀wé Májẹ̀mú Titun bá sọ̀rọ̀ nípa Ọlọrun wọ́n ní Ọlọrun àti Baba Jesu Kristi Oluwa wa lọ́kàn. Nígbà tí wọ́n bá sọ̀rọ̀ nípa Jesu Kristi, wọn kìí sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, tàbí ronú nípa rẹ̀ pé òun ni Ọlọrun. Òun ni Kristi Ọlọrun, Ọmọkùnrin Ọlọrun, Ọgbọ́n Ọlọrun, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Àní àwọn Ọ̀rọ̀-àkọ́sọ ìwé Johannu Mímọ́, tí ó tilẹ̀ súnmọ́ Ẹ̀kọ́ Ìgbàgbọ́ Àjọ Nicaea, ní a gbọ́dọ̀ kà ní ríronú lórí ẹ̀kọ́ tí ó ṣe kedere ti wíwà lábẹ́ ẹni tí Ìwé Ìhìnrere lódindi kéde rẹ̀; Ọ̀rọ̀-àkọ́sọ ọ̀rọ̀ ìṣáájú náà kò ṣe kedere tó ní Griki láìlo ọ̀rọ̀ atọ́ka náà [the·osʹ] ju bí ó ṣe ri ní èdè Gẹ̀ẹ́sì.”—Ìwé “The Divinity of Jesus Christ,” láti ọwọ́ John Martin Creed.