ORÍ 133
Wọ́n Ṣètò Òkú Jésù, Wọ́n sì Lọ Sin Ín
MÁTÍÙ 27:57–28:2 MÁÀKÙ 15:42–16:4 LÚÙKÙ 23:50–24:3 JÒHÁNÙ 19:31–20:1
WỌ́N GBÉ ARA JÉSÙ SỌ̀ KALẸ̀ LÁTORÍ ÒPÓ IGI ORÓ
WỌ́N ṢÈTÒ ÒKÚ NÁÀ KÍ WỌ́N LÈ SIN ÍN
ÀWỌN OBÌNRIN BÁ IBOJÌ NÁÀ TÓ ṢÓFO
Ọjọ́ Friday Nísàn 14 ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí. Sábáàtì lọjọ́ tó tẹ̀ lé e, ìyẹn Nísàn 15, ó sì máa tó bẹ̀rẹ̀ nígbà tí oòrùn bá wọ̀. Jésù ti kú báyìí, àmọ́ àwọn olè méjì tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ò tíì kú ní tiwọn. Ohun tí Òfin sọ nípa ẹni tí wọ́n bá kàn mọ́gi ni pé wọn ò gbọ́dọ̀ fi òkú rẹ̀ “sílẹ̀ lórí òpó igi náà di ọjọ́ kejì,” àmọ́ wọ́n gbọ́dọ̀ sin ín “lọ́jọ́ yẹn.”—Diutarónómì 21:22, 23.
Bákan náà, àwọn Júù máa ń pe ọ̀sán Friday yìí ní àsìkò Ìpalẹ̀mọ́. Àsìkò yẹn ni wọ́n máa dáná, tí wọ́n sì máa ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá fẹ́ ṣe, torí tí Sábáàtì bá ti bẹ̀rẹ̀, wọn ò ní lè ṣe iṣẹ́ kankan mọ́ títí tó fi máa parí. Tí oòrùn bá ti wọ̀, Sábáàtì onípele méjì tàbí Sábáàtì “ńlá” bẹ̀rẹ̀ nìyẹn. (Jòhánù 19:31) Ìdí tí wọ́n fi pè é bẹ́ẹ̀ ni pé Nísàn 15 yìí ni ọjọ́ àkọ́kọ́ nínú ọjọ́ méje tí wọ́n fi ń ṣe Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú, Sábáàtì ni wọ́n sì máa ń ka ọjọ́ yẹn sí. (Léfítíkù 23:5, 6) Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, ọjọ́ kìíní àjọyọ̀ yìí bọ́ sí ọjọ́ kan náà pẹ̀lú ọjọ́ Sábáàtì táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń pa mọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.
Torí náà, àwọn Júù ní kí Pílátù tètè wá bí wọ́n ṣe máa pa Jésù àtàwọn olè méjì tí wọ́n kàn mọ́gi sẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ọgbọ́n wo ni wọ́n máa dá sí i? Wọ́n máa ní láti ṣẹ́ ẹsẹ̀ wọn. Ìyẹn á jẹ́ kó tètè rẹ̀ wọ́n, wọn ò sì ní lè mí mọ́. Làwọn ọmọ ogun bá lọ ṣẹ́ ẹsẹ̀ àwọn olè méjì tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésù. Àmọ́ torí pé Jésù ti kú ní tiẹ̀, wọn ò ṣẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. Ìyẹn mú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Sáàmù 34:20 ṣẹ, pé: “Ó ń dáàbò bo gbogbo egungun rẹ̀; kò sí ìkankan nínú wọn tí a ṣẹ́.”
Káwọn ọmọ ogun yìí lè gbà pé Jésù ti kú lóòótọ́, ọ̀kan lára wọn fi ọ̀kọ̀ gún un lẹ́gbẹ̀ẹ́, lápá ibi tí ọkàn rẹ̀ wà, “ẹ̀jẹ̀ àti omi sì tú jáde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.” (Jòhánù 19:34) Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí mú àsọtẹ́lẹ̀ míì ṣẹ nínú Ìwé Mímọ́, pé: “Wọ́n máa wo ẹni tí wọ́n gún.”—Sekaráyà 12:10.
“Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan” tó ń jẹ́ Jósẹ́fù wà níbẹ̀ nígbà tí wọ́n pa Jésù, ará Arimatíà lọkùnrin yìí, ọ̀kan lára ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn táwọn èèyàn máa ń bọ̀wọ̀ fún sì ni. (Mátíù 27:57) ‘Èèyàn dáadáa àti olódodo’ làwọn èèyàn mọ̀ ọ́n sí, ó sì ń “retí Ìjọba Ọlọ́run.” Kódà, kò fara mọ́ bí wọ́n ṣe dá ẹjọ́ Jésù, torí ó “jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù, àmọ́ tí kò jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ torí pé ó ń bẹ̀rù àwọn Júù.” (Lúùkù 23:50; Máàkù 15:43; Jòhánù 19:38) Jósẹ́fù fìgboyà béèrè lọ́wọ́ Pílátù pé kó jẹ́ kóun gbé òkú Jésù. Pílátù wá pe ọ̀gágun tó bójú tó bí wọ́n ṣe pa Jésù, ọ̀gágun náà sì jẹ́rìí sí i pé Jésù ti kú. Torí náà, Pílátù gbà kí Jósẹ́fù lọ gbé òkú náà.
Jósẹ́fù ra aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa tó sì mọ́, lẹ́yìn náà ó gbé òkú Jésù sọ̀ kalẹ̀ látorí òpó igi. Ó fi aṣọ yẹn di òkú Jésù, kí wọ́n lè lọ sin ín. Nikodémù náà wà níbẹ̀, òun lẹni tó “wá sọ́dọ̀ [Jésù] ní òru.” (Jòhánù 19:39) Ó mú àdàpọ̀ òjíá àti álóé wá síbẹ̀, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún (100) ìwọ̀n pọ́n-ùn àwọn ará Róòmù (ìyẹn nǹkan bíi dọ́là méjìdínláàádọ́rùn-ún [88]). Lẹ́yìn tí wọ́n fi àwọn èròjà yìí pa ara Jésù, wọ́n fi aṣọ wé e lọ́nà táwọn Júù ń gbà wé òkú kí wọ́n tó sin ín.
Jósẹ́fù ní ibojì kan sítòsí ibi ti wọ́n ti pa Jésù. Inú òkúta ni wọ́n gbẹ́ ibojì náà sí, wọn ò sì tẹ́ ẹnikẹ́ni síbẹ̀ rí, ibẹ̀ ni wọ́n lọ tẹ́ Jésù sí. Lẹ́yìn tí wọ́n tẹ́ ẹ síbẹ̀, wọ́n yí òkúta ńlá kan dí ẹnu ọ̀nà ibojì náà. Kíákíá ni wọ́n ṣe gbogbo ohun tí wọ́n ṣe yìí kí Sábáàtì tó bẹ̀rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí Màríà Magidalénì àti Màríà ìyá Jémíìsì Kékeré náà wà níbẹ̀, káwọn náà lè lọ́wọ́ sí bí wọ́n ṣe sin òkú Jésù. Lẹ́yìn tí wọ́n ṣe tán, wọ́n sáré lọ sílé láti lọ “pèsè èròjà tó ń ta sánsán àti àwọn òróró onílọ́fínńdà,” kí wọ́n lè túbọ̀ fi tọ́jú òkú Jésù lẹ́yìn tí Sábáàtì bá parí.—Lúùkù 23:56.
Nígbà tó di ọjọ́ kejì, ìyẹn ọjọ́ Sábáàtì, àwọn olórí àlùfáà àtàwọn Farisí lọ bá Pílátù, wọ́n sọ fún un pé: “A rántí ohun tí afàwọ̀rajà yẹn sọ nígbà tó ṣì wà láàyè, pé, ‘Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, a máa jí mi dìde.’ Torí náà, pàṣẹ kí wọ́n sé sàréè náà mọ́ títí di ọjọ́ kẹta, kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ má bàa wá jí i gbé, kí wọ́n sì sọ fún àwọn èèyàn pé, ‘A ti jí i dìde!’ Ẹ̀tàn tó gbẹ̀yìn yìí máa wá burú ju ti àkọ́kọ́ lọ.” Pílátù wá dá wọn lóhùn pé: “Ẹ mú ẹ̀ṣọ́. Ẹ lọ sé ibẹ̀ mọ́ bí ẹ bá ṣe lè ṣe é.”—Mátíù 27:63-65.
Láàárọ̀ kùtù ọjọ́ Sunday, Màríà Magidalénì, Màríà ìyá Jémíìsì àtàwọn obìnrin míì mú èròjà tó ń ta sánsán lọ síbi ibojì náà kí wọ́n lè fi tọ́jú òkú Jésù. Wọ́n ń sọ láàárín ara wọn pé: “Ta ló máa bá wa yí òkúta kúrò ní ẹnu ọ̀nà ibojì náà?” (Máàkù 16:3) Àmọ́ ìmìtìtì ilẹ̀ kan ti wáyé kí wọ́n tó dé ibẹ̀. Ọlọ́run ti rán áńgẹ́lì rẹ̀ láti yí òkúta yẹn kúrò lẹ́nu ọ̀nà ibojì náà, àwọn ẹ̀ṣọ́ ti sá lọ, ibojì náà sì ti ṣófo!