“Ọlọ́run Àlàáfíà” Bìkítà fún Àwọn Tí A Ń Pọ́n Lójú
BÍBÉLÌ mú un ṣe kedere pé, Dáfídì ìgbàanì mọ ohun tí ìpọ́njú jẹ́ dáadáa. Fún ọ̀pọ̀ ọdún, ó gbé ìgbésí ayé gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá, tí ọba búburú, olórí kunkun kan sì ń lépa rẹ̀ láìdábọ̀, tí ó sì fẹ́ pa á dandan. Ní sáà ìpọ́njú yìí, Dáfídì fi ara rẹ̀ pa mọ́ ní àwọn ibi àdádó. Ṣùgbọ́n, ó ṣe ohun tí ó ju ìyẹn lọ. Ó gbàdúrà sí Jèhófà tọkàntọkàn nípa làásìgbò rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó kọ̀wé nípa ìrírí agbonijìgì rẹ̀ pé: “Ohùn mi ni mo fi ń bẹ̀bẹ̀ mi sí Olúwa. Èmi tú àròyé mi sílẹ̀ níwájú rẹ̀; èmi fi iṣẹ́ mi hàn níwájú rẹ̀.”—Orin Dáfídì 142:1, 2.
Lónìí, àwọn kan lè fi gbígbára tí Dáfídì gbára lé Ọlọ́run ṣe yẹ̀yẹ́. Wọn lè sọ pé, ọgbọ́n ìfini-lọ́kànbalẹ̀ lásán ni àdúrà jẹ́, pé ní ti gidi, fífi àkókò ṣòfò ni ó jẹ́. Síbẹ̀, Dáfídì kò ṣi ìgbọ́kànlé ní nínú Ọlọ́run, nítorí ó rẹ́yìn àwọn ọ̀tá rẹ̀ nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Ní ríronú lórí ìrírí rẹ̀, Dáfídì kọ̀wé pé: “Ọkùnrin olùpọ́njú yìí kígbe pè, Olúwa sì gbóhùn rẹ̀, ó sì gbà á nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.” (Orin Dáfídì 34:6) Níbò míràn, a pe Ọlọ́run tòótọ́ tí Dáfídì yíjú sí ní “Ọlọ́run àlàáfíà.” (Fílípì 4:9; Hébérù 13:20) Yóò ha mú ìpọ́njú kúrò, tí yóò yọrí sí àlàáfíà fún wa bí?
Jèhófà Bìkítà fún Ọ
Jèhófà kò dágunlá sí làásìgbò àwọn ènìyàn rẹ̀. (Orin Dáfídì 34:15) Kì í ṣe kìkì àìní àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan ni ó ń fiyè sí, ṣùgbọ́n, ó tún ń fiyè sí àìní ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ó bẹ̀rù rẹ̀. Nígbà tí ó ń ya tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù ìgbàanì sí mímọ́, Sólómọ́nì rọ Jèhófà láti fetí sílẹ̀ sí “àdúrà kí àdúrà, tàbí ẹ̀bẹ̀ kí ẹ̀bẹ̀ tí a bá ti ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni gbà, tàbí ọ̀dọ̀ gbogbo Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ̀, nígbà tí olúkúlùkù bá mọ ìpọ́njú rẹ̀, àti ìbànújẹ́ rẹ̀.” (Kíróníkà Kejì 6:29) Gẹ́gẹ́ bí Sólómọ́nì ti sọ, ìpọ́njú tí olúkúlùkù ní láti fara dà yàtọ̀ síra. Ti ẹnì kan lè jẹ́ àìsàn nípa ti ara. Ti ẹlòmíràn lè jẹ́ ìrora ọkàn. Ikú olólùfẹ́ kan lè kó ìpọ́njú bá àwọn kan. Àìríṣẹ́ṣe, ìnira ọrọ̀ ajé, àti ìṣòro ìdílé tún jẹ́ ìpọ́njú tí ó wọ́pọ̀ ní àwọn àkókò líle koko wọ̀nyí.
Ronú fún ìgbà díẹ̀ nípa ‘ìpọ́njú rẹ, àti ìbànújẹ́ rẹ.’ Nígbà míràn, o lè nímọ̀lára bíi ti onísáàmù náà, Dáfídì, tí ó kọ̀wé pé: “Èmi sì wòye fún ẹni tí yóò ṣàánú fún mi, ṣùgbọ́n kò sí; àti fún àwọn olùtùnú, èmi kò rí ẹnì kan.” Síbẹ̀, jẹ́ kí ó dá ọ lójú pé Ọlọ́run bìkítà nípa ipò rẹ, nítorí níwájú, nínú sáàmù kan náà, Dáfídì kọ̀wé pé: “Olúwa gbóhùn àwọn tálákà, kò sì fi ojú pa àwọn ará túbú rẹ̀ rẹ́.”—Orin Dáfídì 69:20, 33.
Ní fífẹ ọ̀rọ̀ Dáfídì lójú sí i, a lè ní ìfọkànbalẹ̀ pé Ẹlẹ́dàá aráyé ń tẹ́tí sí àdúrà àwọn tí ìpọ́njú wọn ti dè wọ́n nígbèkùn nínú túbú, kí a sọ ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀. Ní àfikún sí i, ó ń dáhùn pa dà sí ìṣòro wọn. Gbé àwọn gbólóhùn tí ó tẹ̀ lé e wọ̀nyí yẹ̀ wò, tí ó fi ìyọ́nú Jèhófà fún àwọn tí a pọ́n lójú hàn.
“Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ opó ní ìyà, tàbí ọmọ aláìníbaba. Bí ìwọ bá jẹ wọ́n ní ìyàkíyà, tí wọ́n sì kígbe pè mí, èmi óò gbọ́ igbe wọn ní tòótọ́. Ìbínú mi yóò sì gbóná.”—Ẹ́kísódù 22:22-24.
“Ọlọ́run kì yóò ha mú kí a ṣe ìdájọ́ òdodo fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ tí ń ké jáde sí i tọ̀sán tòru, kódà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ní ìpamọ́ra síhà ọ̀dọ̀ wọn?”—Lúùkù 18:7.
“Yóò gba aláìní nígbà tí ó bá ń ké: tálákà pẹ̀lú, àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Òun óò dá tálákà àti aláìní sí, yóò sì gba ọkàn àwọn aláìní là. Òun óò ra ọkàn wọn pa dà lọ́wọ́ ẹ̀tàn àti ìwà agbára: iyebíye sì ni ẹ̀jẹ̀ wọn ní ojú rẹ̀.”—Orin Dáfídì 72:12-14.
‘Ẹni tí ó tọ́ yín [àwọn ènìyàn Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé], ó tọ́ ọmọ ojú mi.’—Sekaráyà 2:8.
Àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ wọ̀nyí fi ọkàn ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí Ẹlẹ́dàá wa ní nínú ire àwọn ènìyàn rẹ̀ hàn. Nítorí náà, a ní ìdí rere láti tẹ̀ lé ìṣílétí àpọ́sítélì Pétérù pé: ‘Ẹ kó gbogbo àníyàn yín lé e, nítorí ó ń bìkítà fún yín.’ (Pétérù Kíní 5:7) Ṣùgbọ́n, báwo ni Ọlọ́run yóò ṣe ràn wá lọ́wọ́ ní àkókò ìpọ́njú yìí?
Bí Ọlọ́run Ṣe Ń Ran Àwọn Tí A Ń Pọ́n Lójú Lọ́wọ́
Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i, nígbà tí a pọ́n Dáfídì lójú, ó fi tọkàntọkàn gbàdúrà sí Ọlọ́run fún ìtọ́sọ́nà. Lọ́wọ́ kan náà, ó lo ìdánúṣe láti mú kí ipò náà ṣeé fara dà, ní lílo òye láti sá mọ́ àwọn tí ń lépa rẹ̀ lọ́wọ́. Nípa báyìí, gbígbára lé Jèhófà pẹ̀lú ìsapá ara ẹni ran Dáfídì lọ́wọ́ láti fara da làásìgbò rẹ̀. Kí ni a lè rí kọ́ láti inú èyí?
Nígbà tí a bá dojú kọ ìpọ́njú, ó dájú pé, kò burú bí a bá lo ìdánúṣe tí ó lọ́gbọ́n nínú láti yanjú ìṣòro náà. Fún àpẹẹrẹ, bí Kristẹni kan bá rí i pé òun kò níṣẹ́ lọ́wọ́, òun kò ha ní sapá láti rí iṣẹ́ bí? Bóyá ó ń ṣàìsàn, òun kò ha ní wá ìtọ́jú ìṣègùn kiri bí? Ní tòótọ́, Jésù pàápàá, tí ó ní agbára láti wo gbogbo oríṣi àìsàn sàn, gbà pé, ‘àwọn tí ń ṣòjòjò nílò oníṣègùn.’ (Mátíù 9:12; fi wé Tímótì Kíní 5:23.) Àmọ́ ṣáá o, a kò lè mú àwọn làásìgbò kan kúrò; a ṣáà gbọ́dọ̀ fara dà wọ́n ni. Síbẹ̀síbẹ̀, Kristẹni tòótọ́ kì í fi ìyà ṣayọ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ti ṣe. (Fi wé Àwọn Ọba Kìíní 18:28.) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń gbé ìgbésẹ̀ èyíkéyìí tí ó lè gbé láti kojú ìpọ́njú rẹ̀.
Ṣùgbọ́n, lọ́wọ́ kan náà, ó bọ́gbọ́n mu láti mú ọ̀ràn náà tọ Jèhófà lọ nínú àdúrà. Èé ṣe? Lákọ̀ọ́kọ́, nípa gbígbára lé Ẹlẹ́dàá wa, a ràn wá lọ́wọ́ láti “máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.” (Fílípì 1:10) Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí a bá ń wáṣẹ́, gbígbára lé Ọlọ́run tàdúràtàdúrà yóò ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ tí ó forí gbárí pẹ̀lú ìlànà Bíbélì. A óò tún yẹra fún dídi ẹni tí ìfẹ́ owó mú “ṣáko lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́.” (Tímótì Kíní 6:10) Ní tòótọ́, nígbà tí a bá ń ṣe ìpinnu tí ó lágbára—nípa iṣẹ́ tàbí apá èyíkéyìí mìíràn nínú ìgbésí ayé—ó yẹ kí a tẹ̀ lé ìṣílétí Dáfídì pé: “Kó ẹrù rẹ lọ sí ara Olúwa, òun ni yóò sì mú ọ dúró; òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ olódodo kí ó yẹ̀ láé.”—Orin Dáfídì 55:22.
Àdúrà tún ń ràn wá lọ́wọ́ láti mú kí ìrònú wa já gaara, kí ìpọ́njú wa má baà mú ọkàn wa pòrúurùu. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ papọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run.” Kí ni yóò yọrí sí? “Àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílípì 4:6, 7) Bẹ́ẹ̀ ni, àlàáfíà, àlàáfíà Ọlọ́run. Àlàáfíà yẹn “ta gbogbo ìrònú yọ,” nítorí náà, ó lè mú wa dúró ṣinṣin nígbà tí ìmọ̀lára ìrora ọkàn bá wọ̀ wá lọ́rùn. Yóò ‘ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn àyà wa àti agbára èrò orí wa,’ ní títipa bẹ́ẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún híhùwà pa dà láìronú jinlẹ̀ àti lọ́nà tí kò mọ́gbọ́n dání, èyí tí ó lè fi kún ìpọ́njú wa.—Oníwàásù 7:7.
Àdúrà ṣì lè ṣe púpọ̀ sí i. Ó lè mú ìyàtọ̀ wá ní ti ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lábẹ́ ipò kan. Gbé àpẹẹrẹ kan nínú Bíbélì yẹ̀ wò. Nígbà tí a fi àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sẹ́wọ̀n ní Róòmù, ó fún àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níṣìírí láti gbàdúrà nítorí òun. Èé ṣe? Ó kọ̀wé sí wọn pé: “Mo gbà yín níyànjú pàápàá jù lọ láti ṣe èyí, kí a lè tètè mú mi pa dà bọ̀ sípò sọ́dọ̀ yín.” (Hébérù 13:19) Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé àdúrà tí kò dáwọ́ dúró, tí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ òun ń gbà lè nípa lórí ìgbà tí a óò dá òun sílẹ̀.—Fílémónì 22.
Àdúrà yóò ha yí àbájáde ìpọ́njú tí ó bá ọ pa dà bí? Ó lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n, ó yẹ kí a mọ̀ pé Jèhófà kì í fìgbà gbogbo dáhùn àdúrà wa lọ́nà tí a lè retí. Fún àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù gbàdúrà léraléra nípa ‘ẹ̀gún nínú ẹran ara’—ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ìṣòro nípa ti ara tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ojú rẹ̀. Kàkà tí yóò fi mú ìpọ́njú náà kúrò, Ọlọ́run sọ fún Pọ́ọ̀lù pé: “Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí mi ti tó fún ọ; nítorí agbára mi ni a ń sọ di pípé nínú àìlera.”—Kọ́ríńtì Kejì 12:7-9.
Nítorí náà, nígbà míràn, a lè máà mú làásìgbò wa kúrò. Kàkà bẹ́ẹ̀, a óò ní àǹfààní láti fi hàn pé a gbára lé Ẹlẹ́dàá wa. (Ìṣe 14:22) Ní àfikún sí i, a lè ní ìdánilójú pé, bí Jèhófà kò bá tilẹ̀ mú ìpọ́njú náà kúrò, òun yóò “ṣe ọ̀nà àbájáde kí [a] lè fara dà á.” (Kọ́ríńtì Kíní 10:13) Bẹ́ẹ̀ ni, a ní ìdí rere láti pe Jèhófà ni “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo, ẹni tí ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.” (Kọ́ríńtì Kejì 1:3, 4) Ó ń fún wa ní ohun tí a nílò, láti lè fara dà pẹ̀lú àlàáfíà tí ó pọ̀ tó.
Láìpẹ́—Ayé Kan Tí Kò Sí Ìpọ́njú!
Ẹlẹ́dàá ṣèlérí pé nípasẹ̀ Ìjọba òun, òun yóò mú ìpọ́njú aráyé kúrò pátápátá láìpẹ́. Báwo ni òun yóò ṣe ṣàṣeparí èyí? Nípa mímú Sátánì Èṣù kúrò, olórí asúnnásí ìpọ́njú àti òléwájú nínú ọ̀tá àlàáfíà, ẹni tí Bíbélì fi hàn gẹ́gẹ́ bí “ọlọ́run ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí.” (Kọ́ríńtì Kejì 4:4) Ṣùgbọ́n, láìpẹ́, ìṣàkóso rẹ̀ lórí aráyé yóò dópin. Mímú tí a óò mú un kúrò yóò ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àìníye ìbùkún láti tọ àwọn tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run wá. Bíbélì ṣèlérí pé Jèhófà yóò “nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sì ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:1-4.
Ayé kan tí kò sí ìpọ́njú mọ́ ha dà bí ohun tí ó ṣòro láti gbà gbọ́ bí? Làásìgbò ti mọ́ wa lára tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí ó fi ṣòro fún wa láti ronú pé kò ní sí i mọ́. Ṣùgbọ́n, òmìnira kúrò lọ́wọ́ ìbẹ̀rù, àníyàn, àti àjálù ni ohun tí Ọlọ́run pète fún aráyé nígbà ìṣẹ̀dá, ète rẹ̀ yóò sì kẹ́sẹ járí.—Aísáyà 55:10, 11.
Ìrètí tí Sonia, Fabiana, àti Ana, tí a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ ìṣáájú yìí ní nìyẹn. Sonia, tí àrùn AIDS pa àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì, jèrè àlàáfíà púpọ̀ láti inú ìrètí tí Bíbélì nawọ́ rẹ̀ jáde—àjíǹde olódodo àti aláìṣòdodo. (Ìṣe 24:15) Ó sọ pé: “Ohun kan tí ó dájú ni pé ìrètí wa ju ìrora èyíkéyìí tí a lè ní lọ.”
Nígbà tí ó ṣì ń gbé ní ilé ìtọ́jú àwọn ọmọ òrukàn, ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ Ana wò. Ana sọ pé: “Ó fi orúkọ Jèhófà hàn mí nínú Bíbélì, omijé ayọ̀ sì bọ́ lójú mi. Mo nílò ìrànlọ́wọ́ gidigidi, mo sì kọ́ pé Ọlọ́run kan ń bẹ tí ó bìkítà fún wa.” Lẹ́yìn tí ó fi ilé ìtọ́jú àwọn ọmọ òrukàn sílẹ̀, Ana tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì kọ́ púpọ̀ sí i nípa ìlérí Jèhófà. Lẹ́yìn náà, ó ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, ó sì fẹ̀rí rẹ̀ hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi. “Láti ìgbà náà mo ti ń bá a nìṣó láti gbára lé Jèhófà nínú àdúrà, ìdánilójú pé òun yóò ràn mí lọ́wọ́ sì tù mí nínú.”
Fabiana pẹ̀lú ti rí ìtùnú àti ìbàlẹ̀ ọkàn nínú ìpọ́njú rẹ̀, nípa kíkọ́ nípa ìlérí Ọlọ́run fún ọjọ́ ọ̀la. “Kíkẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ láti inú Bíbélì dà bíi fífi ibi tí ó ṣókùnkùn biribiri, tí ó sì dágùdẹ̀ sílẹ̀, kí a wá wọ inú yàrá kan tí ó mọ́lẹ̀ kedere, tí ó sì tuni lára.”—Fi wé Orin Dáfídì 118:5.
Ṣùgbọ́n, báwo ni àlàáfíà gidi kárí ayé yóò ṣe dé, nígbà wo sì ni yóò dé? Ẹ jẹ́ kí a wò ó nínú àwọn àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
Oríṣiríṣi Ìpọ́njú
▪ Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdámẹ́rin àwọn olùgbé ayé tí ń gbé nínú ipò òṣì paraku, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù sí i sì ń gbé nínú ipò tí kò yẹ ọmọ ènìyàn, tí ń wu ìwàláàyè wọn léwu.
▪ Iye tí ó lé ní 200 mílíọ̀nù ọmọdé kì í jẹun kánú.
▪ Lọ́dọọdún, àrunṣu ń pa nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́ta ọmọdé tí kò tí ì pé ọmọ ọdún márùn-ún.
▪ Àwọn àrùn tí ń ranni pa nǹkan bí 16.5 mílíọ̀nù ènìyàn ní 1993 nìkan ṣoṣo. Níwọ̀n bí àwọn orílẹ̀-èdè kan ti ni ìsọ̀rí tí ó yàtọ̀ fún àwọn àrùn, iye tí ó jẹ́ gan-an lè jù bẹ́ẹ̀ lọ.
▪ Iye ènìyàn tí a fojú díwọ̀n pé ó tó 500 mílíọ̀nù ni ìṣòro ọpọlọ ń yọ lẹ́nu.
▪ Ìfọwọ́ ara ẹni para ẹni ń pọ̀ sí i láàárín àwọn èwe ju ti àwọn tí wọ́n wà ní ọjọ́ orí mìíràn lọ.
▪ Ìwé ìròyìn náà, The Unesco Courier, sọ pé: “Ebi àti àìríṣẹ́ṣe ti di àbùkù sára ayé. Mílíọ̀nù 35 ni kò ríṣẹ́ ṣe ní àwọn orílẹ̀-èdè méje tí ó lọ́rọ̀ jù lọ lágbàáyé, àti pé, ní Brazil nìkan ṣoṣo, 20 mílíọ̀nù òṣìṣẹ́ ni ń bẹ, tí ó jẹ́ pé níní tí wọ́n ní iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe, kò túmọ̀ sí pé wọ́n lè bọ́ ara wọn yó.”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àdúrà lè ràn wá lọ́wọ́ láti pa àfiyèsí pọ̀ sórí ìlérí Ọlọ́run nípa ayé kan tí kò sí ìpọ́njú