ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 5
A Máa Bá Yín Lọ
“A fẹ́ bá yín lọ, torí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.”—SEK. 8:23.
ORIN 26 Ẹ Ti Ṣe É fún Mi
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Kí ni Jèhófà sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ lákòókò wa yìí?
NÍGBÀ tí Jèhófà ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ọjọ́ wa yìí, ó ní: “Ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè yóò di aṣọ Júù kan mú, àní wọn yóò dì í mú ṣinṣin, wọ́n á sì sọ pé: ‘A fẹ́ bá yín lọ, torí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.’” (Sek. 8:23) “Júù” tí ẹsẹ yìí ń sọ ṣàpẹẹrẹ àwọn tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí yàn. Bíbélì tún pè wọ́n ní “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” (Gál. 6:16) Ní ti àwọn “ọkùnrin mẹ́wàá” náà, wọ́n dúró fún àwọn tó nírètí àtigbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Wọ́n mọ̀ pé Jèhófà ti bù kún àwùjọ àwọn ẹni àmì òróró yìí, wọ́n sì gbà pé àǹfààní ńlá ni báwọn ṣe ń jọ́sìn Jèhófà pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹni àmì òróró.
2. Báwo làwọn “ọkùnrin mẹ́wàá” náà ṣe ń “bá” àwọn ẹni àmì òróró lọ?
2 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò ṣeé ṣe láti mọ orúkọ gbogbo àwọn ẹni àmì òróró tó wà lórí ilẹ̀ ayé báyìí,b àwọn tó nírètí àtigbé láyé ṣì lè “bá” àwọn ẹni àmì òróró lọ. Lọ́nà wo? Bíbélì sọ pé “ọkùnrin mẹ́wàá” máa di aṣọ Júù kan mú ṣinṣin, “wọ́n á sì sọ pé: ‘A fẹ́ bá yín lọ, torí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.’” Júù kan péré ni ẹsẹ Bíbélì yìí mẹ́nu kàn. Àmọ́ ọ̀rọ̀ náà “yín” tí wọ́n lò lẹ́ẹ̀mejì nínú ẹsẹ yìí fi hàn pé ó ju ẹnì kan lọ. Èyí túmọ̀ sí pé kì í ṣe ẹnì kan ṣoṣo ni Júù náà ń tọ́ka sí, àmọ́ ó dúró fún àwùjọ àwọn ẹni àmì òróró lápapọ̀. Àwọn tí kì í ṣe ẹni àmì òróró ń sin Jèhófà pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹni àmì òróró. Àmọ́, wọn kì í wo àwọn ẹni àmì òróró bí aṣáájú wọn torí wọ́n mọ̀ pé Jésù nìkan ni Aṣáájú.—Mát. 23:10.
3. Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn ẹni àmì òróró ṣì wà láàárín àwa èèyàn Ọlọ́run lónìí, àwọn kan lè máa béèrè pé: (1) Ojú wo ló yẹ káwọn ẹni àmì òróró máa fi wo ara wọn? (2) Ojú wo ló yẹ ká fi wo ẹni tó jẹ búrẹ́dì tó sì mu wáìnì níbi Ìrántí Ikú Kristi? (3) Ṣó yẹ ká máa dara wa láàmú tí iye àwọn tó ń jẹ búrẹ́dì tí wọ́n sì ń mu wáìnì níbi Ìrántí Ikú Kristi bá ń pọ̀ sí i? A máa rí ìdáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí.
OJÚ WO LÓ YẸ KÁWỌN ẸNI ÀMÌ ÒRÓRÓ MÁA FI WO ARA WỌN?
4. Bó ṣe wà nínú 1 Kọ́ríńtì 11:27-29, ìkìlọ̀ wo ló yẹ káwọn ẹni àmì òróró ronú lé lórí dáadáa, kí sì nìdí?
4 Ó yẹ káwọn ẹni àmì òróró ronú dáadáa lórí ìkìlọ̀ tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 11:27-29. (Kà á.) Báwo ni ẹni àmì òróró kan ṣe lè jẹ búrẹ́dì kó sì mu wáìnì “láìyẹ” níbi Ìrántí Ikú Kristi? Ó lè ṣe bẹ́ẹ̀ tó bá ń tẹ àwọn òfin Jèhófà àti ìlànà rẹ̀ lójú tí kò sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀. (Héb. 6:4-6; 10:26-29) Àwọn ẹni àmì òróró gbọ́dọ̀ jẹ́ adúróṣinṣin jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn tí wọ́n bá fẹ́ gba “èrè ìpè Ọlọ́run sí òkè nípasẹ̀ Kristi Jésù.”—Fílí. 3:13-16.
5. Ojú wo ló yẹ káwọn ẹni àmì òróró máa fi wo ara wọn?
5 Ṣe ni ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà máa ń mú káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, kì í sọ wọ́n di agbéraga. (Éfé. 4:1-3; Kól. 3:10, 12) Torí náà, àwọn ẹni àmì òróró kì í ronú pé àwọn sàn ju àwọn míì lọ. Wọ́n mọ̀ pé ẹ̀mí mímọ́ tí Jèhófà fún àwọn kò ju èyí tó fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó kù lọ. Wọn kì í sì í ronú pé àwọn lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́ ju àwọn yòókù lọ. Wọn ò jẹ́ sọ fẹ́nì kan pé Ọlọ́run ti fẹ̀mí yàn án torí náà kóun náà bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ búrẹ́dì kó sì máa mu wáìnì níbi Ìrántí Ikú Kristi. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, wọ́n sì mọ̀ pé Jèhófà nìkan ló ń yan àwọn tó máa lọ sọ́run.
6. Bó ṣe wà nínú 1 Kọ́ríńtì 4:7, 8, báwo ló ṣe yẹ káwọn ẹni àmì òróró máa hùwà?
6 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àǹfààní ńlá làwọn ẹni àmì òróró kà á sí bí Jèhófà ṣe yàn wọ́n láti lọ sọ́run, wọn kì í retí pé káwọn èèyàn máa fún àwọn láfiyèsí àrà ọ̀tọ̀. (Fílí. 2:2, 3) Wọ́n sì mọ̀ pé nígbà tí Jèhófà fẹ̀mí yan àwọn, kò sọ fún ẹnikẹ́ni nípa ẹ̀. Torí náà, ẹni àmì òróró kan ò ní jẹ́ kó ya òun lẹ́nu táwọn kan ò bá tètè gbà pé Jèhófà ti fẹ̀mí yan òun. Ó ṣe tán, Bíbélì pàápàá sọ pé ká má ṣe yára gbà gbọ́ tẹ́nì kan bá sọ pé Jèhófà fún òun ní àkànṣe iṣẹ́. (Ìfi. 2:2) Torí pé ẹni àmì òróró kan ò retí pé káwọn èèyàn máa fún òun láfiyèsí àrà ọ̀tọ̀, kò ní máa sọ fáwọn èèyàn tó bá pàdé pé ẹni àmì òróró lòun. Kò sì ní máa fọ́nnu nípa ẹ̀ fáwọn míì.—Ka 1 Kọ́ríńtì 4:7, 8.
7. Kí ni kò yẹ káwọn ẹni àmì òróró máa ṣe, kí sì nìdí?
7 Àwọn ẹni àmì òróró kì í ronú pé àwọn ẹni àmì òróró bíi tiwọn nìkan ló yẹ káwọn máa bá ṣọ̀rẹ́ bí ẹní ń ṣẹgbẹ́ àwa-ara-wa. Wọn kì í wá àwọn ẹni àmì òróró míì kiri bóyá torí kí wọ́n lè jọ máa sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe máa ń rí téèyàn bá di ẹni àmì òróró tàbí kí wọ́n lè jọ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀. (Gál. 1:15-17) Ìjọ ò ní wà níṣọ̀kan táwọn ẹni àmì òróró bá ń hu irú ìwà yìí. Ìdí sì ni pé irú ìwà bẹ́ẹ̀ ta ko ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run tó ń jẹ́ kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà nínú ìjọ.—Róòmù 16:17, 18.
OJÚ WO LÓ YẸ KÓ O MÁA FI WO ÀWỌN ẸNI ÀMÌ ÒRÓRÓ?
8. Kí nìdí tó fi yẹ kó o ṣọ́ra nípa ojú tó o fi ń wo àwọn tó ń jẹ búrẹ́dì tí wọ́n sì ń mu wáìnì níbi Ìrántí Ikú Kristi? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
8 Ojú wo ló yẹ kó o máa fi wo àwọn ẹni àmì òróró lọ́kùnrin àti lóbìnrin? Kò dáa ká máa fún ẹnì kan láfiyèsí kọjá bó ṣe yẹ, kódà bí ẹni náà tiẹ̀ jẹ́ arákùnrin Kristi. (Mát. 23:8-12) Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn alàgbà, ó gbà wá níyànjú pé ká máa “tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ wọn,” àmọ́ kò sọ pé ká sọ èèyàn èyíkéyìí di aṣáájú wa. (Héb. 13:7) Òótọ́ ni pé Bíbélì sọ pé ká fún àwọn kan ní “ọlá ìlọ́po méjì.” Àmọ́ èyí jẹ́ nítorí pé wọ́n “ń ṣe àbójútó lọ́nà tó dáa,” wọ́n sì “ń ṣiṣẹ́ kára nínú ọ̀rọ̀ sísọ àti kíkọ́ni,” kì í ṣe torí pé wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró. (1 Tím. 5:17) A máa dójú ti àwọn ẹni àmì òróró tá a bá ń fún wọn láfiyèsí àrà ọ̀tọ̀ tàbí tá a bá ń yìn wọ́n kọjá bó ṣe yẹ.c Èyí tó tiẹ̀ wá burú jù ni pé a lè mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga. (Róòmù 12:3) Ó sì dájú pé kò sẹ́nì kankan nínú wa táá fẹ́ kí ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin Kristi ṣe irú àṣìṣe ńlá bẹ́ẹ̀!—Lúùkù 17:2.
9. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún àwọn ẹni àmì òróró?
9 Báwo la ṣe lè fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún àwọn tí Jèhófà fẹ̀mí yàn? A ò ní máa béèrè lọ́wọ́ wọn nípa bí wọ́n ṣe di ẹni àmì òróró. Ó yẹ ká mọ̀ pé ọ̀rọ̀ àárín àwọn àti Jèhófà ni, a ò sì lẹ́tọ̀ọ́ láti mọ̀. (1 Tẹs. 4:11; 2 Tẹs. 3:11) Kò sì yẹ ká máa ronú pé Ọlọ́run ti fẹ̀mí yan ọkọ tàbí aya wọn, àwọn òbí wọn tàbí àwọn mọ̀lẹ́bí wọn. Ó yẹ ká mọ̀ pé ìrètí táwọn ẹni àmì òróró ní kì í ṣe ogún ìdílé. Ọlọ́run ló ń fún èèyàn ní ẹ̀mí mímọ́. (1 Tẹs. 2:12) Bákan náà, kò yẹ ká máa béèrè àwọn ìbéèrè tó lè kó ẹ̀dùn ọkàn báni. Bí àpẹẹrẹ, kò yẹ ká máa béèrè lọ́wọ́ ìyàwó ẹni àmì òróró kan pé báwo ló ṣe máa ń rí lára rẹ̀ tó bá ń rántí pé òun máa gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé tí ọkọ rẹ̀ sì máa wà lọ́run. Ó ṣe tán, ó dá wa lójú pé nínú ayé tuntun, Jèhófà máa “fún gbogbo ohun alààyè ní ohun tí wọ́n ń fẹ́.”—Sm. 145:16.
10. Tí a kì í bá “kan sáárá sí” àwọn ẹni àmì òróró, báwo nìyẹn ṣe lè dáàbò bò wá?
10 A máa dáàbò bo ara wa tá a bá ń fojú tó tọ́ wo àwọn ẹni àmì òróró, tí a kì í wò wọ́n bí ẹni pé wọ́n ṣe pàtàkì ju àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó kù lọ. Lọ́nà wo? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ẹni àmì òróró kan lè di aláìṣòótọ́. (Mát. 25:10-12; 2 Pét. 2:20, 21) Àmọ́, tí a kì í bá “kan sáárá” sáwọn èèyàn, a ò ní sọ ẹnikẹ́ni di ọlọ́run wa, yálà ẹni àmì òróró ni tàbí ẹnì kan táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa tàbí ẹni tó ti ń sin Jèhófà tipẹ́tipẹ́ pàápàá. (Júùdù 16, àlàyé ìsàlẹ̀) Tírú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ bá wá lọ di aláìṣòótọ́ tàbí tí wọ́n fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀, ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Jèhófà ò ní wọmi, a ò sì ní pa ìjọsìn Jèhófà tì.
ṢÓ YẸ KÁ MÁA DARA WA LÁÀMÚ TÍ WỌ́N BÁ Ń PỌ̀ SÍ I?
11. Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí iye àwọn tó ń jẹ búrẹ́dì tí wọ́n sì ń mu wáìnì níbi Ìrántí Ikú Kristi?
11 Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, ńṣe ni iye àwọn tó ń jẹ búrẹ́dì tí wọ́n sì ń mu wáìnì níbi Ìrántí Ikú Kristi ń dín kù. Àmọ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ṣe ni iye wọn ń pọ̀ sí i lọ́dọọdún. Ṣó yẹ ká máa dara wa láàmú nítorí èyí? Rárá. Ẹ jẹ́ ká wo ìdí tí kò fi yẹ kíyẹn kó ìdààmú ọkàn bá wa.
12. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa da ara wa láàmú tí iye àwọn tó ń jẹ búrẹ́dì tí wọ́n sì ń mu wáìnì níbi Ìrántí Ikú Kristi bá ń pọ̀ sí i?
12 “Jèhófà mọ àwọn tó jẹ́ tirẹ̀.” (2 Tím. 2:19) Àwọn arákùnrin tó ń ka iye àwọn tó ń jẹ ohun ìṣàpẹẹrẹ kì í ṣe Jèhófà, torí náà wọn ò lè mọ àwọn tó jẹ́ ẹni àmì òróró lóòótọ́. Ìdí sì ni pé àwọn tí wọ́n rò pé ẹni àmì òróró làwọn àmọ́ tí wọn kì í ṣe ẹni àmì òróró wà lára àwọn tí wọ́n kà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan tí wọ́n ti máa ń jẹ àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà tẹ́lẹ̀ kò jẹ ẹ́ mọ́ nígbà tó yá. Àwọn míì lè ní ìṣòro ọpọlọ tàbí ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn, kí wọ́n sì máa rò pé àwọn wà lára àwọn tó máa bá Kristi jọba lọ́run. Ó ṣe kedere pé a ò mọ iye àwọn ẹni àmì òróró tó kù láyé báyìí.
13. Ṣé Bíbélì sọ iye àwọn ẹni àmì òróró tó máa wà láyé nígbà tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀?
13 Àwọn ẹni àmì òróró máa wà ní ọ̀pọ̀ ibi lórí ilẹ̀ ayé nígbà tí Jésù bá dé láti kó wọn lọ sọ́run. (Mát. 24:31) Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn ẹni àmì òróró díẹ̀ máa ṣẹ́ kù lórí ilẹ̀ ayé. (Ìfi. 12:17) Àmọ́, kò sọ iye àwọn tó máa ṣẹ́ kù nígbà tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀.
14. Bó ṣe wà nínú Róòmù 9:11, 16, kí ló yẹ ká mọ̀ nípa ìgbà tí Jèhófà fẹ̀mí yan àwọn ẹni àmì òróró?
14 Jèhófà ló ń pinnu ìgbà tó máa fẹ̀mí yan ẹnì kan. (Róòmù 8:28-30) Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde ni Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í yan àwọn ẹni àmì òróró. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé gbogbo àwọn Kristẹni tòótọ́ tó wà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ni ẹni àmì òróró. Láwọn ọdún tó tẹ̀ lé e, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni ni kò tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Síbẹ̀ náà, láàárín àwọn ọdún yẹn, Jèhófà fẹ̀mí yan ìwọ̀nba àwọn tó jẹ́ Kristẹni tòótọ́. Àwọn yẹn ló dà bí àlìkámà tí Jésù sọ pé ó máa wà láàárín àwọn èpò. (Mát. 13:24-30) Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, Jèhófà ṣì ń yan àwọn èèyàn tó máa wà lára àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) náà.d Torí náà, bí Ọlọ́run bá pinnu láti yan àwọn kan lára wọn ní àkókò díẹ̀ kí òpin tó dé, ó dájú pé kò sẹ́ni tó lè yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ wò. (Ka Róòmù 9:11, 16.)e A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí ọ̀rọ̀ wa má bàa dà bíi tàwọn òṣìṣẹ́ tí Jésù sọ nínú àkàwé kan tí wọ́n ń bínú sí ọ̀gá wọn torí iye owó tó san fún àwọn òṣìṣẹ́ tó dé kẹ́yìn.—Mát. 20:8-15.
15. Bó ṣe wà nínú Mátíù 24:45-47, ṣé gbogbo àwọn ẹni àmì òróró ló para pọ̀ jẹ́ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye”? Ṣàlàyé.
15 Kì í ṣe gbogbo àwọn tó nírètí láti lọ sọ́run ló para pọ̀ jẹ́ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” (Ka Mátíù 24:45-47.) Bó ṣe rí ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ìwọ̀nba àwọn arákùnrin ni Jèhófà àti Jésù ń lò láti bọ́ tàbí kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí. Ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ni Jèhófà lò láti kọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Bákan náà lónìí, ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn ẹni àmì òróró ni Jèhófà gbé iṣẹ́ lé lọ́wọ́ pé kí wọ́n máa fún àwọn èèyàn òun ní “oúnjẹ wọn ní àkókò tó yẹ.”
16. Kí lo ti rí kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí?
16 Kí la ti rí kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí? Jèhófà ti pinnu láti fún èyí tó pọ̀ jù lára àwọn èèyàn rẹ̀ ní ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé, ó sì ti pinnu láti fún àwọn mélòó kan tó máa bá Jésù jọba ní ìyè ti ọ̀run. Gbogbo wa pátá ni Jèhófà máa fún lérè, yálà àwọn tí Bíbélì pè ní “Júù” tàbí àwọn “ọkùnrin mẹ́wàá” náà. Òfin kan náà ló ní kí gbogbo wa máa tẹ̀ lé, ká sì jẹ́ olóòótọ́ sí òun jálẹ̀ ìgbésí ayé wa. Gbogbo wa gbọ́dọ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Gbogbo wa gbọ́dọ̀ máa sìn ín ká sì wà níṣọ̀kan. Gbogbo wa gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun táá mú kí àlàáfíà wà nínú ìjọ. Bí òpin ṣe túbọ̀ ń sún mọ́lé, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa máa sin Jèhófà nìṣó, ká sì máa tẹ̀ lé Kristi gẹ́gẹ́ bí “agbo kan.”—Jòh. 10:16.
a Tuesday, April 7 la máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún yìí. Ojú wo ló yẹ kó o fi wo ẹni tó jẹ búrẹ́dì tó sì mu wáìnì níbi Ìrántí Ikú Kristi lálẹ́ ọjọ́ náà? Ṣó yẹ ká máa dara wa láàmú tí iye àwọn tó ń jẹ búrẹ́dì tí wọ́n sì ń mu wáìnì níbi Ìrántí Ikú Kristi bá ń pọ̀ sí i? Àpilẹ̀kọ yìí máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí. A gbé àpilẹ̀kọ yìí ka àpilẹ̀kọ kan tó jáde nínú Ilé Ìṣọ́ January 2016
b Bí Sáàmù 87:5, 6 ṣe sọ, lọ́jọ́ iwájú, ó ṣeé ṣe kí Ọlọ́run jẹ́ ká mọ orúkọ gbogbo àwọn tó ń bá Jésù jọba lọ́run.—Róòmù 8:19.
c Wo àpótí náà, “Ìfẹ́ ‘Kì Í Hùwà Lọ́nà Tí Kò Bójú Mu’” nínú Ilé Ìṣọ́ January 2016.
d Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ìṣe 2:33 fi hàn pé ipasẹ̀ Jésù ni àwọn ẹni àmì òróró fi rí ẹ̀mí mímọ́ gbà, ó ṣe kedere pé Jèhófà ló yàn wọ́n.
e Tó o bá ń fẹ́ àlàyé síwájú sí i, wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ May 1, 2007.
ORIN 34 Máa Rìn Nínú Ìwà Títọ́
f ÀWÒRÁN: Ẹ wo bó ṣe máa rí táwọn èèyàn bá ṣùrù bo aṣojú ètò Ọlọ́run àti ìyàwó rẹ̀ ní àpéjọ agbègbè torí pé wọ́n fẹ́ bá wọn ya fọ́tò. Ẹ ò rí i pé ìwà tí kò bójú mu gbáà ni