Ẹ Máa Gbé Ọwọ́ Ìdúróṣinṣin Sókè Nínú Àdúrà
“Mo ní ìfẹ́-ọkàn pé ní ibi gbogbo, kí àwọn ọkùnrin máa bá a lọ ní gbígbàdúrà, kí wọ́n máa gbé ọwọ́ ìdúróṣinṣin sókè, láìsí ìrunú àti ọ̀rọ̀ fífà.”—1 TÍMÓTÌ 2:8.
1, 2. (a) Báwo ni 1 Tímótì 2:8 ṣe kan àdúrà tó jẹ mọ́ àwọn èèyàn Jèhófà? (b) Kí la fẹ́ gbé yẹ̀ wò báyìí?
JÈHÓFÀ retí pé kí àwọn èèyàn òun dúró ṣinṣin ti òun àti ara wọn lẹ́nì kìíní kejì. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù so ìdúróṣinṣin pọ̀ mọ́ àdúrà nígbà tó kọ̀wé pé: “Mo ní ìfẹ́-ọkàn pé ní ibi gbogbo, kí àwọn ọkùnrin máa bá a lọ ní gbígbàdúrà, kí wọ́n máa gbé ọwọ́ ìdúróṣinṣin sókè, láìsí ìrunú àti ọ̀rọ̀ fífà.” (1 Tímótì 2:8) Ó hàn gbangba pé àdúrà tí a ń gbà láwùjọ, “ní ibi gbogbo” tí àwọn Kristẹni ti ń pàdé pọ̀ ni Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí. Àwọn wo ló yẹ kó máa ṣojú àwọn ènìyàn Ọlọ́run nínú àdúrà nínú àwọn ìpàdé ìjọ? Kìkì àwọn ọkùnrin mímọ́, olódodo, àti olùfọkànsìn, tí ń fi tọkàntọkàn ṣe gbogbo ojúṣe tí Ọlọ́run lànà sílẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ ni. (Oníwàásù 12:13, 14) Wọ́n ní láti jẹ́ mímọ́ nípa tẹ̀mí àti nípa ti ìwà híhù, wọ́n sì ní láti ya ara wọn sọ́tọ̀ pátápátá fún Jèhófà Ọlọ́run lọ́nà tí ẹnì kan kò fi ní kọminú nípa wọn.
2 Ní pàtàkì, ó yẹ kí àwọn alàgbà ìjọ máa ‘gbé ọwọ́ ìdúróṣinṣin sókè nínú àdúrà.’ Àdúrà àtọkànwá wọn nípasẹ̀ Jésù Kristi ń fi ìdúróṣinṣin wọn sí Ọlọ́run hàn, ó sì ń mú kí wọ́n yàgò fún ọ̀rọ̀ fífà àti ìbínú fùfù. Lóòótọ́, ẹnikẹ́ni tó bá láǹfààní láti ṣojú ìjọ Kristẹni nínú àdúrà kò gbọ́dọ̀ jẹ́ oníbìínú, oníkèéta, tàbí aláìdúróṣinṣin ti Jèhófà àti ètò àjọ rẹ̀. (Jákọ́bù 1:19, 20) Kí tún ni àwọn ìtọ́ni láti inú Bíbélì tó wà fún àwọn tó láǹfààní láti ṣojú àwọn ẹlòmíràn nínú àdúrà láwùjọ? Kí sì ni àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ táa ní láti fi sílò nígbà táa bá ń gbàdúrà ní àwa nìkan àti nínú ìdílé?
Ronú Kóo Tó Gbàdúrà
3, 4. (a) Èé ṣe tó fi ṣàǹfààní láti ronú lórí ohun tí a ó sọ ká tó gbàdúrà láwùjọ? (b) Kí ni Ìwé Mímọ́ fi hàn nípa bó ṣe yẹ kí àdúrà gùn tó?
3 Báa bá sọ fún wa pé ká gbàdúrà láwùjọ, ó yẹ kí ó ṣeé ṣe fún wa, ó kéré tán, láti ronú díẹ̀ lórí ohun tí a ó sọ nínú àdúrà náà. Ṣíṣe èyí lè jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀ràn pàtàkì tó bójú mu, láìjẹ́ pé a gba àdúrà gígùn, táa ń fi àtamọ́ mọ́ àtamọ̀. Àmọ́ o, bó bá jẹ́ àwa nìkan là ń gbàdúrà, bó bá wù wá, a lè gbà á síta. A sì lè jẹ́ kí ó gùn tó bí a bá ṣe fẹ́. Jésù fi gbogbo òru gbàdúrà kó tó yan àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá. Ṣùgbọ́n nígbà tó dá Ìṣe Ìrántí ikú rẹ̀ sílẹ̀, ṣókí làdúrà tó gbà lé búrẹ́dì àti wáìnì. (Máàkù 14:22-24; Lúùkù 6:12-16) A sì mọ̀ pé Ọlọ́run gbọ́ àdúrà kúkúrú tí Jésù gbà.
4 Ká sọ pé a láǹfààní láti ṣojú ìdílé nínú àdúrà àgbàṣáájú oúnjẹ. Irú àdúrà bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ àdúrà ráńpẹ́—ṣùgbọ́n ó yẹ kí ohun táa bá sọ ní ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ fún oúnjẹ náà nínú. Báa bá ń gbàdúrà láwùjọ, ṣáájú tàbí lẹ́yìn ìpàdé Kristẹni, kò sídìí fún gbígba àdúrà gígùn tó kárí àìmọye kókó ọ̀rọ̀. Jésù bá àwọn akọ̀wé òfin wí, àwọn tí “ń gba àdúrà gígùn fún bojúbojú.” (Lúùkù 20:46, 47) Èèyàn Ọlọ́run kò ní fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ rárá. Àmọ́ ṣá o, nígbà mìíràn ó lè bójú mu láti gba àdúrà tó gùn mọ níwọ̀n níwájú àwùjọ. Fún àpẹẹrẹ, ó yẹ kí alàgbà táa bá yàn láti gba àdúrà àgbàkẹ́yìn àpéjọ àyíká tàbí àpéjọpọ̀ àgbègbè ronú ṣáájú lórí ohun tó fẹ́ sọ, ó sì lè mẹ́nu kan àwọn kókó mélòó kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ bẹ́ẹ̀ pàápàá, kò yẹ kí irú àdúrà bẹ́ẹ̀ gùn jàn-àn-ràn jan-an-ran.
Tọ Ọlọ́run Lọ Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀
5. (a) Kí ló yẹ ká ní lọ́kàn nígbà táa bá ń gbàdúrà láwùjọ? (b) Èé ṣe tó fi yẹ ká gbàdúrà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ àti tẹ̀yẹtẹ̀yẹ?
5 Nígbà táa bá ń gbàdúrà láwùjọ, ó yẹ ká máa rántí pé ènìyàn kọ́ là ń bá sọ̀rọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ká máa rántí pé ẹ̀dá ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá, tí ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ. (Sáàmù 8:3-5, 9; 73:28) Fún ìdí yìí, ó yẹ ká ní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ ti ṣíṣàìfẹ́ ṣẹ̀ ẹ́ nípa ohun táa bá sọ àti báa ṣe sọ ọ́. (Òwe 1:7) Dáfídì onísáàmù kọ ọ́ lórin pé: “Ní tèmi, èmi yóò wá sínú ilé rẹ nínú ọ̀pọ̀ yanturu inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́, èmi yóò tẹrí ba síhà tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ nínú ẹ̀rù rẹ.” (Sáàmù 5:7) Báa bá ní ẹ̀mí yẹn, báwo la ó ṣe sọ̀rọ̀ bí wọ́n bá ní ká gbàdúrà ní ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Wàyí o, bó bá ṣe pé ọba ẹlẹ́ran ara là ń bá sọ̀rọ̀, a óò bá a sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ àti tẹ̀yẹtẹ̀yẹ. Kò ha yẹ kí àdúrà wa tilẹ̀ tún fi ìwà ìbọ̀wọ̀fúnni àti ìbọláfúnni tó jù bẹ́ẹ̀ lọ hàn, níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé Jèhófà, “Ọba ayérayé” là ń gbàdúrà sí? (Ìṣípayá 15:3) Nítorí náà, táa bá ń gbàdúrà, a ní láti yẹra fún àwọn gbólóhùn bí, “Káàárọ̀ o, Jèhófà,” “A fi ìfẹ́ wa ránṣẹ́ sí ọ,” tàbí, “Ó dìgbà kan ná.” Ìwé Mímọ́ fi hàn pé Jésù Kristi, Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run, kò bá Baba rẹ̀ ọ̀run sọ̀rọ̀ báyẹn rí.
6. Kí ló yẹ ká ní lọ́kàn nígbà táa bá “sún mọ́ ìtẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí”?
6 Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a sún mọ́ ìtẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí pẹ̀lú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ.” (Hébérù 4:16) A lè tọ Jèhófà lọ pẹ̀lú “òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ” láìka ipò ẹ̀ṣẹ̀ táa wà sí, nítorí ìgbàgbọ́ wa nínú ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi. (Ìṣe 10:42, 43; 20:20, 21) Síbẹ̀, irú “òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ” bẹ́ẹ̀ kò wá túmọ̀ sí pé ká máa bá Ọlọ́run tàkúrọ̀sọ; a kò sì gbọ́dọ̀ sọ ọ̀rọ̀ àìlọ́wọ̀ sí i. Bí àdúrà tí a gbà láwùjọ yóò bá dùn mọ́ Jèhófà nínú, a gbọ́dọ̀ gbà á tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ àti tẹ̀yẹtẹ̀yẹ, kò sì ní bójú mu rárá ká máa fi irú àdúrà bẹ́ẹ̀ ṣe ìkéde, ká máa fi bá àwọn ẹlòmíràn wí, tàbí ká máa fi na àwùjọ lẹ́gba ọ̀rọ̀.
Máa Fi Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Gbàdúrà
7. Báwo ni Sólómọ́nì ṣe fẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn nígbà tó ń gbàdúrà níbi ìyàsímímọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà?
7 Yálà a ń gbàdúrà níwájú àwùjọ tàbí ní àwa nìkan, ìlànà Ìwé Mímọ́ tó ṣe pàtàkì láti fi sọ́kàn ni pé a ní láti máa fẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ gbàdúrà. (2 Kíróníkà 7:13, 14) Ọba Sólómọ́nì fẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ gbàdúrà níwájú àwùjọ nígbà ìyàsímímọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù. Sólómọ́nì ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ ọ̀kan lára ilé tó rẹwà jù lọ láyé tán ni. Síbẹ̀, ó fi ìrẹ̀lẹ̀ gbàdúrà pé: “Ọlọ́run yóò ha máa gbé lórí ilẹ̀ ayé ní tòótọ́ bí? Wò ó! Àwọn ọ̀run, bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀run àwọn ọ̀run, kò lè gbà ọ́; nígbà náà, áńbọ̀sìbọ́sí ilé yìí tí mo kọ́!”—1 Àwọn Ọba 8:27.
8. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà táa lè gbà fẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn táa bá ń gbàdúrà láwùjọ?
8 Gẹ́gẹ́ bí Sólómọ́nì, a ní láti rẹ ara wa sílẹ̀ nígbà táa bá ń ṣojú fún àwùjọ nínú àdúrà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ní láti yàgò fún sísọ̀rọ̀ bí ẹni mímọ́, síbẹ̀ ohùn táa fi ń sọ̀rọ̀ lè fi ìwà ìrẹ̀lẹ̀ hàn. Àdúrà táa fẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ gbà kì í kún fún ọ̀rọ̀ kàǹkà-kàǹkà tàbí èyí táa fẹ́ fi fi hàn pé a mọ ọ̀rọ̀ọ́ sọ. Àdúrà táa fẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ gbà kì í pe àfiyèsí sára ẹni, bí kò ṣe sí Ẹni táa ń bá sọ̀rọ̀. (Mátíù 6:5) A tún lè fẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn nípa ohun táa ń sọ nínú àdúrà. Báa bá gbàdúrà tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀, a ò ní máa sọ̀rọ̀ bí ẹni pé ṣe là ń pàṣẹ fún Ọlọ́run pé kó ṣe àwọn nǹkan kan báa ṣe fẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe la óò máa bẹ Jèhófà pé kó gbégbèésẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ète rẹ̀ mímọ́. Onísáàmù náà ṣe àpẹẹrẹ irú ẹ̀mí tó yẹ ká ní, nígbà tó bẹ̀bẹ̀ pé: “Áà, wàyí o, Jèhófà, jọ̀wọ́ gbani là! Áà, wàyí o, Jèhófà, jọ̀wọ́ yọ̀ǹda àṣeyọrí sí rere!”—Sáàmù 118:25; Lúùkù 18:9-14.
Máa Gbàdúrà Látọkànwá
9. Ìmọ̀ràn rere wo látẹnu Jésù la rí nínú Mátíù 6:7, báwo sì ni a ṣe lè lò ó?
9 Bí àdúrà táa ń gbà láwùjọ tàbí ní àwa nìkan yóò bá dùn mọ́ Jèhófà nínú, ó gbọ́dọ̀ tọkàn wa wá. Fún ìdí yìí, a ò kàn ní máa tún àdúrà kan táa ti kọ́ sórí gbà ṣáá, láìronú nípa ohun táa ń sọ. Nínú Ìwàásù rẹ̀ lórí Òkè, Jésù gbani nímọ̀ràn pé: “Nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, má ṣe sọ ohun kan náà ní àsọtúnsọ, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè ti ń ṣe, nítorí wọ́n lérò [bẹ́ẹ̀ èrò òdì ni] pé a óò gbọ́ tiwọn nítorí lílò tí wọ́n ń lo ọ̀rọ̀ púpọ̀.” Lédè mìíràn, Jésù sọ pé: “Má rojọ́ wuuru; má sọ àsọtúnsọ tí kò nítumọ̀.”—Mátíù 6:7; àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.
10. Èé ṣe tí yóò fi bójú mu láti máa gbàdúrà nípa ohun kan ju ẹ̀ẹ̀kan lọ?
10 Àmọ́ ṣá o, ó lè di dandan ká máa gbàdúrà léraléra nípa ohun kan. Ìyẹn ò lòdì, nítorí Jésù rọ̀ wá pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, a ó sì fi í fún yín; ẹ máa bá a nìṣó ní wíwá kiri, ẹ ó sì rí; ẹ máa bá a nìṣó ní kíkànkùn, a ó sì ṣí i fún yín.” (Mátíù 7:7) Bóyá a nílò Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun nítorí pé Jèhófà ń bù kún iṣẹ́ ìwàásù ládùúgbò wa. (Aísáyà 60:22) Kò sóhun tó burú nínú mímẹ́nukan àìní yìí léraléra táa bá ń dá nìkan gbàdúrà tàbí táa bá ń gbàdúrà láwùjọ, níbi ìpàdé àwọn ènìyàn Jèhófà. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ‘sísọ àsọtúnsọ tí kò nítumọ̀.’
Rántí Ìyìn àti Ọpẹ́
11. Báwo ni Fílípì 4:6, 7 ṣe kan àdúrà táa dá gbà àti èyí táa gbà láwùjọ?
11 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé ìgbà tí wọ́n bá fẹ́ tọrọ nǹkan kan nìkan ni wọ́n ń gbàdúrà, ṣùgbọ́n ó yẹ kí ìfẹ́ wa fún Jèhófà Ọlọ́run sún wa láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, ká sì máa yìn ín nínú àdúrà tí a ń dá gbà àti èyí táa ń gbà láwùjọ. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílípì 4:6, 7) Àní, ní àfikún sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ àti ìtọrọ nǹkan, ó yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún àwọn ìbùkún tẹ̀mí àti tara. (Òwe 10:22) Onísáàmù náà kọ ọ́ lórin pé: “Rú ìdúpẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ rẹ sí Ọlọ́run, kí o sì san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ fún Ẹni Gíga Jù Lọ.” (Sáàmù 50:14) Orin àdúrà Dáfídì sì ní àwọn ọ̀rọ̀ ìwúrí yìí nínú: “Ṣe ni èmi yóò máa fi orin yin orúkọ Ọlọ́run, èmi yóò sì fi ìdúpẹ́ gbé e ga lọ́lá.” (Sáàmù 69:30) Kò ha yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀ nínú àdúrà táa ń gbà láwùjọ àti èyí táa ń dá nìkan gbà?
12. Báwo ni Sáàmù 100:4, 5 ṣe ń ní ìmúṣẹ lónìí, a sì lè dúpẹ́ ká sì yin Ọlọ́run nítorí kí ni?
12 Onísáàmù náà kọrin nípa Ọlọ́run pé: “Ẹ wá sí àwọn ẹnubodè rẹ̀ ti ẹ̀yin ti ìdúpẹ́, sínú àwọn àgbàlá rẹ̀ ti ẹ̀yin ti ìyìn. Ẹ fi ọpẹ́ fún un, ẹ fi ìbùkún fún orúkọ rẹ̀. Nítorí pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere; inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ jẹ́ fún àkókò tí ó lọ kánrin, àti ìṣòtítọ́ rẹ̀ láti ìran dé ìran.” (Sáàmù 100:4, 5) Lónìí, àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè ń wọ àwọn àgbàlá ibùjọsìn Jèhófà, a sì lè máa yìn ín, ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ ní tìtorí èyí. O ha ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorí Gbọ̀ngàn Ìjọba tiyín, tóo sì ń fi ìmọrírì rẹ hàn nípa pípésẹ̀ síbẹ̀ déédéé pẹ̀lú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀? Tóo bá wà níbẹ̀, o ha máa ń fi tọkàntọkàn gbóhùn rẹ sókè nínú orin ìyìn àti ìdúpẹ́ sí Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ bí?
Ojú Kò Gbọ́dọ̀ Tì Wá Láti Gbàdúrà
13. Àpẹẹrẹ wo nínú Ìwé Mímọ́ ló fi hàn pé ó yẹ ká máa rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà, kódà báa bá nímọ̀lára pé a ti di aláìyẹ nítorí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀?
13 Ká tilẹ̀ sọ pé a nímọ̀lára pé a ti di aláìyẹ nítorí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀, ṣe ló yẹ ká yíjú sí Ọlọ́run nínú ẹ̀bẹ̀ àtinúwá. Nígbà tí àwọn Júù ṣẹ̀ nípa fífẹ́ àwọn àjèjì aya, ṣe ni Ẹ́sírà kúnlẹ̀, tó tẹ́wọ́ ìdúróṣinṣin sí Ọlọ́run, tó sì fìrẹ̀lẹ̀ gbàdúrà pé: “Ìwọ Ọlọ́run mi, ojú ń tì mí, ara sì ń tì mí láti gbé ojú mi sókè sí ọ, ìwọ Ọlọ́run mi, nítorí pé àwọn ìṣìnà wa pàápàá ti di púpọ̀ sí i ní orí wa, ẹ̀bi wa sì ti di ńlá, àní títí dé ọ̀run. Láti ọjọ́ àwọn baba ńlá wa ni a ti wà nínú ẹ̀bi ńláǹlà títí di òní yìí . . . Lẹ́yìn gbogbo ohun tí ó sì ti dé bá wa nítorí àwọn iṣẹ́ búburú wa àti ẹ̀bi ńláǹlà wa—nítorí pé ìwọ fúnra rẹ, ìwọ Ọlọ́run wa, ti ka ìṣìnà wa sí kékeré ju bí ó ti yẹ lọ, ìwọ sì ti fún wa ní àwọn tí ó sá àsálà, bí àwọn wọ̀nyí—ǹjẹ́ ó yẹ kí a tún máa rú àwọn àṣẹ rẹ, kí a sì máa bá àwọn ènìyàn tí ń ṣe àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí wọ̀nyí dána? Ìbínú rẹ kì yóò ha ru sókè sí wa dójú ààlà, tí kì yóò fi sí ẹnì kankan tí yóò ṣẹ́ kù, tí kì yóò sì fi sí ẹnì kankan tí yóò sá àsálà? Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, olódodo ni ìwọ, nítorí pé a ti ṣẹ́ wa kù gẹ́gẹ́ bí olùsálà bí ó ti rí lónìí yìí. Àwa rèé níwájú rẹ nínú ẹ̀bi wa, nítorí pé kò ṣeé ṣe láti dúró níwájú rẹ ní tìtorí èyí.”—Ẹ́sírà 9:1-15; Diutarónómì 7:3, 4.
14. Lójú ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ Ẹ́sírà, kí ni ṣíṣe láti lè rí ìdáríjì Ọlọ́run gbà?
14 Láti rí ìdáríjì Ọlọ́run gbà, a gbọ́dọ̀ jẹ́wọ́ fún un pẹ̀lú ìròbìnújẹ́ ọkàn àti “àwọn èso tí ó yẹ ìrònúpìwàdà.” (Lúùkù 3:8; Jóòbù 42:1-6; Aísáyà 66:2) Lọ́jọ́ Ẹ́sírà, ní àfikún sí fífi ẹ̀mí ìrònúpìwàdà hàn, wọ́n tún sapá láti ṣàtúnṣe, nípa lílé àwọn àjèjì aya náà lọ. (Ẹ́sírà 10:44; fi wé 2 Kọ́ríńtì 7:8-13.) Báa bá ń wá ìdáríjì Ọlọ́run nítorí ìwà àìtọ́ wíwúwo, ẹ jẹ́ ká jẹ́wọ́ nínú àdúrà táa fẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ gbà, ká sì so àwọn èso tó yẹ ìrònúpìwàdà. Ẹ̀mí ìrònúpìwàdà àti ìfẹ́ láti ṣàtúnṣe yóò sún wa láti wá ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí lọ́dọ̀ àwọn Kristẹni alàgbà.—Jákọ́bù 5:13-15.
Rí Ìtùnú Nínú Àdúrà
15. Báwo ni ìrírí Hánà ṣe fi hàn pé a lè rí ìtùnú nínú àdúrà?
15 Táa bá ní ẹ̀dùn ọkàn fún ìdí kan, a lè rí ìtùnú nínú àdúrà. (Sáàmù 51:17; Òwe 15:13) Hánà adúróṣinṣin rí ìtùnú nínú àdúrà. Nígbà ayé rẹ̀, ìdílé ńlá wọ́pọ̀ ní Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n òun ò tètè rọ́mọ bí. Pẹ̀nínà, orogún rẹ̀, bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin fún Ẹlikénà, ọkọ rẹ̀, Pẹ̀nínà sì máa ń fi Hánà ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé ó yàgàn. Hánà gbàdúrà tọkàntọkàn, ó ṣèlérí pé bí Ọlọ́run bá fọmọ jíǹkí òun, ‘òun yóò fi í fún Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.’ Torí pé ó rí ìtùnú nínú àdúrà rẹ̀ àti nínú ọ̀rọ̀ Élì, Àlùfáà Àgbà, “ìdàníyàn fún ara ẹni kò sì hàn lójú” Hánà mọ́. Ó bí ọmọkùnrin kan tó porúkọ rẹ̀ ní Sámúẹ́lì. Nígbà tó ṣe, ó fi í fún iṣẹ́ ìsìn ní ibùjọsìn Jèhófà. (1 Sámúẹ́lì 1:9-28) Nínú ọpẹ́ fún inú rere Ọlọ́run sí i, ó gbàdúrà ìdúpẹ́—àdúrà tó gbé Jèhófà lárugẹ, tó fi hàn pé kò lẹ́gbẹ́. (1 Sámúẹ́lì 2:1-10) Gẹ́gẹ́ bí Hánà, a lè rí ìtùnú nínú àdúrà, pẹ̀lú ìdánilójú pé Ọlọ́run yóò dáhùn gbogbo ìbéèrè wa tó bá bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. Táa bá sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wa fún un tán, ká yéé ‘dàníyàn,’ torí pé yóò ràn wá lẹ́rù, tàbí kó fún wa lókun àtigbé e.—Sáàmù 55:22.
16. Gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀ràn Jékọ́bù, èé ṣe tó fi yẹ ká gbàdúrà nígbà tí àyà wa bá ń já tàbí táa ń ṣàníyàn?
16 Báa bá wà nínú ipò kan tí ń fa ìpayà, ẹ̀dùn ọkàn, tàbí àníyàn, ká má gbàgbé láti yíjú sí Ọlọ́run fún ìtùnú nínú àdúrà. (Sáàmù 55:1-4) Àyà Jékọ́bù ń já nígbà tó fẹ́ pàdé Ísọ̀, arákùnrin rẹ̀ tó dì í sínú. Àmọ́ o, Jékọ́bù gbàdúrà pé: “Ìwọ Ọlọ́run Ábúráhámù baba mi àti Ọlọ́run Ísákì baba mi, Jèhófà, ìwọ tí o sọ fún mi pé, ‘Padà sí ilẹ̀ rẹ àti sọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ, èmi yóò sì ṣe dáadáa sí ọ,’ èmi kò yẹ fún gbogbo inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti gbogbo ìṣòtítọ́ tí o ti ṣe sí ìránṣẹ́ rẹ, nítorí pẹ̀lú ọ̀pá mi nìkan ṣoṣo ni mo sọdá Jọ́dánì yìí, mo sì ti di ibùdó méjì nísinsìnyí. Mo bẹ̀ ọ́, dá mi nídè lọ́wọ́ arákùnrin mi, lọ́wọ́ Ísọ̀, nítorí tí àyà rẹ̀ ń fò mí, pé ó lè dé, kí ó sì fipá kọlù mí dájúdájú, àti ìyá àti àwọn ọmọ mi. Àti pé ìwọ, ìwọ ti sọ pé, ‘Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, èmi yóò ṣe dáadáa sí ọ, èmi yóò sì mú irú-ọmọ rẹ dà bí àwọn egunrín iyanrìn òkun, tí kì yóò níye nítorí jíjẹ́ ògìdìgbó.’” (Jẹ́nẹ́sísì 32:9-12) Ísọ̀ kò kọlu Jékọ́bù àti agboolé rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, nínú ọ̀ràn yìí, Jèhófà “ṣe dáadáa” sí Jékọ́bù lóòótọ́.
17. Ní ìbámu pẹ̀lú Sáàmù 119:52, báwo ni àdúrà ṣe lè tù wá nínú táa bá wà nínú àdánwò líle koko?
17 Nígbà táa bá ń gbàdúrà, a lè rí ìtùnú nípa rírántí àwọn nǹkan tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nínú sáàmù tó gùn jù lọ—àdúrà gbígbámúṣé táa sọ dorin—ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Ọmọọba Hesekáyà ló kọ ọ́ lórin pé: “Jèhófà, mo rántí àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ láti àkókò tí ó lọ kánrin, mo sì rí ìtùnú fún ara mi.” (Sáàmù 119:52) Nínú àdúrà táa gbà nínú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ nígbà táa bá wà nínú àdánwò líle koko, a lè rántí ìlànà tàbí òfin Bíbélì tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti tẹ̀ lé ipa ọ̀nà tí yóò yọrí sí ìfinilọ́kànbalẹ̀ tí ń tuni nínú pé a ń ṣe ohun tó wu Baba wa ọ̀run.
Àwọn Adúróṣinṣin Ń Ní Ìforítì Nínú Àdúrà
18. Èé ṣe táa fi lè sọ pé ‘gbogbo ẹni ìdúróṣinṣin ni yóò máa gbàdúrà sí Ọlọ́run’?
18 Gbogbo àwọn adúróṣinṣin ti Jèhófà Ọlọ́run yóò “ní ìforítì nínú àdúrà.” (Róòmù 12:12) Nínú Sáàmù kejìlélọ́gbọ̀n, tó jọ pé a kọ lẹ́yìn tí Dáfídì dẹ́ṣẹ̀ pẹ̀lú Bátí-ṣébà, ó ṣàpèjúwe kíkérora tóun ń kérora nítorí kíkùnà láti wá ìdáríjì àti ìtura tí ìrònúpìwàdà àti ìjẹ́wọ́ fún Ọlọ́run mú wá bá a. Dáfídì wá kọ ọ́ lórin pé: “Ní tìtorí èyí [torí pé ìdáríjini látọ̀dọ̀ Jèhófà wà fún àwọn tó ronú pìwà dà látọkànwá], gbogbo ẹni ìdúróṣinṣin yóò máa gbàdúrà sí ọ ní kìkì irúfẹ́ àkókò tí a lè rí ọ.”—Sáàmù 32:6.
19. Èé ṣe tó fi yẹ ká máa gbé ọwọ́ ìdúróṣinṣin sókè nínú àdúrà?
19 Báa bá mọrírì ìbátan wa pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run, a óò máa gbàdúrà fún àánú rẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù. Nínú ìgbàgbọ́, a lè sún mọ́ ìtẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí pẹ̀lú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ láti rí àánú àti ìrànlọ́wọ́ tó bọ́ sákòókò gbà. (Hébérù 4:16) Àmọ́, ìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà kò mà lóǹkà o! Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká “máa gbàdúrà láìdabọ̀”—ká máa lo ọ̀rọ̀ ìyìn àti ọpẹ́ àtọkànwá sí Ọlọ́run nígbà gbogbo. (1 Tẹsalóníkà 5:17) Tọ̀sán tòru, ẹ jẹ́ ká máa gbé ọwọ́ ìdúróṣinṣin sókè nínú àdúrà.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Kí làǹfààní tó wà nínú ríronú nípa ohun tí a ó sọ ká tó gbàdúrà láwùjọ?
◻ Èé ṣe tó fi yẹ ká máa gbàdúrà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ àti tẹ̀yẹtẹ̀yẹ?
◻ Irú ẹ̀mí wo ló yẹ ká ní nígbà táa bá ń gbàdúrà?
◻ Táa bá ń gbàdúrà, èé ṣe tó fi yẹ ká máa rántí ìdúpẹ́ àti ìyìn?
◻ Báwo ni Bíbélì ṣe fi hàn pé a lè rí ìtùnú nínú àdúrà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ọba Sólómọ́nì fẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn nínú àdúrà tó gbà níbi ìyàsímímọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Gẹ́gẹ́ bí Hánà, o lè rí ìtùnú nínú àdúrà