Jèhófà Ń Fìfẹ́ Tọ́ Wa Sọ́nà, Ṣé Wàá Tẹ̀ Lé Ìtọ́sọ́nà Rẹ̀?
“Gbogbo ipa ọ̀nà èké ni mo kórìíra.”—SM. 119:128.
1, 2. (a) Bó o bá ń béèrè ọ̀nà lọ́wọ́ ẹnì kan, kí lo máa fẹ́ kó sọ fún ẹ, kí sì nìdí? (b) Irú ìkìlọ̀ wo ni Jèhófà máa ń fún àwọn tó ń sìn ín, kí sì nìdí?
KÁ SỌ pé o fẹ́ lọ sí ibì kan. O wá lọ bá ọ̀rẹ́ rẹ kan tó o fọkàn tán tó sì mọ ibẹ̀ pé kó júwe ọ̀nà fún ẹ. Bó ṣe ń ṣàlàyé bó o ṣe máa rìn tí wàá fi débẹ̀, ó ṣeé ṣe kó sọ fún ẹ pé: “Tó o bá dé ibi ìyànà báyìí báyìí, kó o kíyè sára. Àmì ojú ọ̀nà tó wà níbẹ̀ lè ṣi èèyàn lọ́nà. Ọ̀pọ̀ èèyàn ti sọ nù torí pé wọ́n tẹ̀ lé àmì ojú ọ̀nà náà.” Ṣé inú rẹ á dùn tó bá sọ bẹ́ẹ̀, ṣé wàá sì fẹ́ láti tẹ̀ lé ohun tó sọ? Ní àwọn ọ̀nà kan, Jèhófà la lè fi wé ọ̀rẹ́ wa tó ń júwe ọ̀nà fún wa yìí. Ó ń jẹ́ ká mọ gbogbo ohun tó yẹ ká mọ̀ ká bàa lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun, bẹ́ẹ̀ ló sì tún ń kìlọ̀ fún wa nípa àwọn ewu tó yẹ ká sá fún ká máa bàa ṣìnà.—Diu. 5:32; Aísá. 30:21.
2 Nínú àpilẹ̀kọ yìí àti èyí tó tẹ̀ lé e, a máa sọ̀rọ̀ lórí díẹ̀ lára àwọn ewu yìí. A kò sì ní gbà gbé pé torí pé Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ Ọ̀rẹ́ wa, ọ̀rọ̀ wa jẹ ẹ́ lógún ó sì fẹ́ràn wa ló ṣe ń kìlọ̀ fún wa nípa àwọn ewu náà. Ó fẹ́ ká jèrè ìyè àìnípẹ̀kun. Ó máa ń dùn ún bí àwọn èèyàn bá ṣe ìpinnu tí kò tọ́ tí wọ́n sì dẹ́kun láti máa sìn ín. (Ìsík. 33:11) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ewu mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Èyí àkọ́kọ́ jẹ́ ewu táwọn èèyàn lè kó wa sí, ewu kejì sì jẹ́ àfọwọ́fà. Ewu kẹta kì í ṣe ohun tá a lè rí, àmọ́ ó lè ṣèpalára tó pọ̀ fún wa. Ó yẹ ká mọ ohun táwọn ewu náà jẹ́ àti bí Baba wa ọ̀run ṣe ń kọ́ wa láti sá fún wọn. Onísáàmù kan tí Ọlọ́run mí sí sọ fún Jèhófà pé: “Gbogbo ipa ọ̀nà èké ni mo kórìíra.” (Sm. 119:128) Ṣé ìwọ náà kórìíra ipa ọ̀nà èké bíi ti onísáàmù yìí? Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè pinnu láti yẹra fún ipa ọ̀nà èké ká sì dúró lórí ìpinnu wa.
Má Ṣe “Tẹ̀ Lé Ogunlọ́gọ̀”
3. (a) Tá a bá ń rìnrìn àjò, kí nìdí tó fi léwu pé ká kàn tẹ̀ lé àwọn míì bí a kò bá mọ ibi tó yẹ ká gbà? (b) Ìlànà pàtàkì wo la rí nínú Ẹ́kísódù 23:2?
3 Bó o bá ń lọ síbi tó jìn, kí lo máa ṣe tó o bá ń ṣiyè méjì nípa ibi tó yẹ kó o gbà? Ó lè ṣe ẹ́ bíi pé kó o tẹ̀ lé àwọn míì tẹ́ ẹ jọ ń rìnrìn àjò, pàápàá jù lọ tó bá jẹ́ pé ibì kan náà ni gbogbo wọn dorí kọ. Àmọ́ ó léwu láti gba ibì kan torí pé gbogbo èèyàn ń gbabẹ̀. Ó lè jẹ́ pé ọ̀tọ̀ ni ibi tí wọ́n ń lọ, tàbí kó jẹ́ pé àwọn náà ò mọ̀nà. Àpèjúwe yìí á jẹ́ kó o lóye ohun tí Jèhófà fẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì rí kọ́ látinú ọ̀kan lára àwọn òfin tó fún wọn. Jèhófà kìlọ̀ fún àwọn onídàájọ́ àtàwọn tó jẹ́ ẹlẹ́rìí nínú ọ̀ràn ìgbẹ́jọ́ pé kí wọ́n má ṣe “tẹ̀ lé ogunlọ́gọ̀.” (Ka Ẹ́kísódù 23:2.) Láìsí àní-àní, ó rọrùn fún àwọn ẹ̀dá aláìpé láti ṣe ohun tẹ́gbẹ́ ń ṣe, kí wọ́n gbé ẹ̀bi fún aláre, kí wọ́n sì gbé àre fún ẹlẹ́bi. Àmọ́, ṣé ọ̀ràn ìgbẹ́jọ́ nìkan ni ìlànà pé ká má ṣe tẹ̀ lé ogunlọ́gọ̀ wúlò fún ni? Rárá o.
4, 5. Báwo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù ṣe fẹ́ mú kí Jóṣúà àti Kálébù tẹ̀ lé ogunlọ́gọ̀, àmọ́ kí ló fún wọn ní ìgboyà tí wọn kò fi ṣe bẹ́ẹ̀?
4 Ká sòótọ́, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ìgbàkigbà la lè rí ohun tó máa mú ká fẹ́ láti “tẹ̀ lé ogunlọ́gọ̀.” Irú ohun bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ lójijì, ó sì lè ṣòro gan-an fún wa láti ṣe ohun tó yàtọ̀ sí tàwọn míì. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà kan èyí tí ì bá mú kí Jóṣúà àti Kálébù ṣe ohun táwọn míì retí pé kí wọ́n ṣe. Wọ́n wà lára àwọn ọkùnrin méjìlá tó lọ ṣe amí Ilẹ̀ Ìlérí. Nígbà tí wọ́n pa dà dé, mẹ́wàá lára wọ́n mú ìròyìn búburú tó ń múni rẹ̀wẹ̀sì wá. Wọ́n tiẹ̀ sọ pé díẹ̀ lára àwọn tó ń gbé ní ilẹ̀ náà jẹ́ òmìrán, ìyẹn àtọmọdọ́mọ àwọn Néfílímù táwọn obìnrin ọlọ̀tẹ̀ bí fáwọn áńgẹ́lì tó ṣọ̀tẹ̀ nígbà ayé Nóà. (Jẹ́n. 6:4) Ohun tí wọ́n sọ yẹn kò mọ́gbọ́n dání. Ìdí ni pé Àkúnya Omi ti gbá gbogbo àwọn àdàmọ̀dì ọmọ tó ń hùwà búburú yẹn lọ ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, kò sì ṣẹ́ ku ẹyọ hóró kan nínú wọn. Àmọ́, bí ìgbàgbọ́ èèyàn bá ti jó rẹ̀yìn, ó lè gba èrò tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ rárá pàápàá gbọ́. Kò pẹ́ tí ìròyìn búburú tí àwọn amí mẹ́wàá yìí mú wá fi dá ìbẹ̀rù sílẹ̀ láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Kíá ni ọ̀pọ̀ nínú wọn ti bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé àṣìṣe ló máa jẹ́ fún àwọn láti wọ Ilẹ̀ Ìlérí bí Jèhófà ṣe sọ. Níwọ̀n bí èyí ti lè dá wàhálà sílẹ̀, kí ni Jóṣúà àti Kálébù ṣe?—Núm. 13:25-33.
5 Wọn kò tẹ̀ lé ogunlọ́gọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn náà kò fẹ́ láti gbọ́ òótọ́ tí Jóṣúà àti Kálébù ń sọ, síbẹ̀ wọn kò dákẹ́ nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù fẹ́ láti sọ wọ́n lókùúta! Kí ló mú kí wọ́n ní irú ìgboyà bẹ́ẹ̀? Kò sí àní-àní pé ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Jèhófà ló mú kí wọ́n nígboyà. Àwọn tó nígbàgbọ́ máa ń rí ìyàtọ̀ kedere tó wà láàárín ọ̀rọ̀ tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ táwọn èèyàn máa ń sọ àti àwọn ìlérí tí Jèhófà Ọlọ́run bá ṣe. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Jóṣúà àti Kálébù jẹ́ káwọn èèyàn náà mọ bí àwọn ṣe mọrírì rẹ̀ tó pé Jèhófà máa ń mú gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ. (Ka Jóṣúà 14:6, 8; 23:2, 14.) Jóṣúà àti Kálébù nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run wọn tó jẹ́ olódodo gan-an, wọn kò sì jẹ́ tìtorí pé wọ́n fẹ́ láti tẹ̀ lé ogunlọ́gọ̀ tí kò nígbàgbọ́ kí wọn wá ṣe ohun tó máa mú un bínú. Torí náà, wọ́n dúró ṣinṣin, àpẹẹrẹ rere sì nìyẹn jẹ́ fún wa lónìí.—Núm. 14:1-10.
6. Àwọn ǹnkan wo ló lè mú ká fẹ́ láti tẹ̀ lé ogunlọ́gọ̀?
6 Ǹjẹ́ ó ti ṣe ẹ́ rí bíi kó o tẹ̀ lé ogunlọ́gọ̀? Lóde òní, ó dájú pé àwọn èèyàn tó sọ ara wọn di àjèjì sí Jèhófà tí wọn kì í sì í tẹ̀ lé ìlànà rẹ̀ nípa irú ìwà tó yẹ ká máa hù pọ̀ gan-an. Wọ́n máa ń fẹ́ káwọn èèyàn lọ́wọ́ nínú eré ìnàjú àti eré ìtura tó máa ń gbin èròkerò síni lọ́kàn. Wọ́n lè sọ pé kò sí ohun tó burú nínú ìṣekúṣe, ìwà ipá àti ìbẹ́mìílò èyí tó wọ́pọ̀ nínú àwọn eré orí tẹlifíṣọ̀n, fíìmù tàbí géèmù orí kọ̀ǹpútà. (2 Tím. 3:1-5) Bó o bá fẹ́ yan eré ìnàjú àti eré ìtura tí ìwọ àti ìdílé rẹ á máa ṣe, ṣé ohun tí àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn gbàgbàkugbà bá sọ lo fi ń pinnu ohun tó o máa ṣe àti ohun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ á fàyè gbà? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ṣe kì í ṣe pé o ti ń tẹ̀ lé ogunlọ́gọ̀ nìyẹn?
7, 8. (a) Báwo la ṣe lè kọ́ “agbára ìwòye” wa, kí sì nìdí tí irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ fi sàn ju kéèyàn máa tẹ̀ lé òfin rẹpẹtẹ? (b) Kí nìdí tí àpẹẹrẹ ọ̀pọ̀ àwọn èwe tó jẹ́ Kristẹni fi máa ń mú ẹ lọ́kàn yọ̀?
7 Jèhófà ti fún wa ní ẹ̀bùn ṣíṣeyebíye kan tó máa ń jẹ́ kó rọrùn fún wa láti ṣe ìpinnu, ẹ̀bùn náà ni “agbára ìwòye” wa. Àmọ́ kí ẹ̀bùn yìí tó lè ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ a gbọ́dọ̀ “tipasẹ̀ lílò” kọ́ ọ. (Héb. 5:14) A kò ní lè kọ́ agbára ìwòye wa tá a bá ń tẹ̀ lé ogunlọ́gọ̀. Bákàn náà, kò sí bí òfin rẹpẹtẹ ṣe lè dípò ẹ̀rí ọkàn wa bó bá di pé ká ṣe ìpinnu. Ìyẹn ló fà á tí ètò Ọlọ́run kò fi ṣe àkọsílẹ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ nípa irú fíìmù tí àwa èèyàn Jèhófà kò gbọ́dọ̀ máa wò, irú ìwé tí a kò gbọ́dọ̀ máa kà àti ìkànnì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tí kò yẹ ká máa lọ. Torí pé kì í pẹ́ táwọn nǹkan fi máa ń yí pa dà nínú ayé tá à ń gbé yìí, bí ètò Ọlọ́run bá tiẹ̀ ṣe irú àkọsílẹ̀ bẹ́ẹ̀ kò ní pẹ́ tí kò fi ní bágbà mu mọ́. (1 Kọ́r. 7:31) Ibi tí irú àkọsílẹ̀ bẹ́ẹ̀ tún wá burú sí ni pé kò ní jẹ́ ká lè ṣe ojúṣe pàtàkì tá a ní láti máa fara balẹ̀ gbé àwọn ìlànà Bíbélì yẹ̀ wò tàdúràtàdúrà, lẹ́yìn náà ká wá gbé àwọn ìpinnu tá a bá ṣe karí àwọn ìlànà wọ̀nyẹn.—Éfé. 5:10.
8 Àwọn èèyàn kan lè máà fẹ́ràn wa tá a bá ń ṣe àwọn ìpinnu tó bá Bíbélì mu. Ó lè ṣòro gan-an fún àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni láti má ṣe tẹ̀ lé ogunlọ́gọ̀ torí pé àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn níléèwé lè máa fúngun mọ́ wọn láti wo ohun táwọn ń wò, kí wọ́n sì máa ṣe bíi tàwọn. (1 Pét. 4:4) Torí náà, ó múnú wa dùn bá a ṣe ń rí àwọn Kristẹni tàgbà tèwe tí wọ́n ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Jóṣúà àti Kálébù torí bí wọ́n ṣe ń kọ̀ láti tẹ̀ lé ogunlọ́gọ̀.
Ẹ Má Ṣe Máa Tọ “Ọkàn-Àyà Yín àti Ojú Yín Lẹ́yìn”
9. (a) Tó o bá ń rìnrìn àjò, kí nìdí tó fi léwu pé kó o gba ọ̀nà èyíkéyìí tó bá ṣáà ti wù ẹ́? (b) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí àwọn èèyàn Ọlọ́run ní ìgbàanì tẹ̀ lé òfin tí Ọlọ́run fún wọn nínú Númérì 15:37-39?
9 Ewu kejì tá a máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ jẹ́ àfọwọ́fà. Ẹ jẹ́ ká ṣàpèjúwe rẹ̀ lọ́nà yìí: Ò ń rìnrìn àjò lọ sí ibì kan, o sì ní àwòrán tó júwe bó o ṣe máa débẹ̀. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ bí o kò bá lo àwòrán yẹn tó o kàn ń yà sí ojú ọ̀nà èyíkéyìí tó bá ti ní ìrísí tó fani mọ́ra? Bó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé o kò ní lè dé ibi tó ò ń lọ. Ní báyìí, wá ṣe àgbéyẹ̀wò òmíràn lára àwọn òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì. Ó lè ṣòro fún ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí láti lóye ìdí tí Ọlọ́run fi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lófin pé kí wọ́n fi ìṣẹ́tí àti okùn tín-ín-rín aláwọ̀ búlúù sára aṣọ wọn. (Ka Númérì 15:37-39.) Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí òfin yìí fi ṣe pàtàkì? Bí àwọn èèyàn Ọlọ́run bá pa òfin náà mọ́, ó máa mú kí wọ́n yàtọ̀ gedegbe sáwọn èèyàn tó wà ní orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà tó yí wọn ká. Ìyẹn sì ṣe pàtàkì kí wọ́n lè rí ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà, kí wọ́n má sì pàdánù ojú rere rẹ̀. (Léf. 18:24, 25) Síbẹ̀, ìdí mìíràn wà tí òfin yẹn fi ṣe pàtàkì. Ó jẹ́ ká mọ̀ pé ewu kan wà tó jẹ́ àfọwọ́fà, èyí tó lè ṣì wá lọ́nà kí ọwọ́ wa má bàa tẹ ìyè àìnípẹ̀kun. Ẹ jẹ́ ká wo bó ṣe lè rí bẹ́ẹ̀.
10. Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun mọ irú ẹni táwa èèyàn jẹ́?
10 Jèhófà sọ ìdí tó fi fún àwọn èèyàn rẹ̀ lófin pé kí wọ́n fi ìṣẹ́tí àti okùn tín-ín-rín aláwọ̀ búlúù sára aṣọ wọn. Ó sọ pé: “Kí ẹ má sì máa lọ káàkiri ní títọ ọkàn-àyà yín àti ojú yín lẹ́yìn, èyí tí ẹ ń tẹ̀ lé nínú ìbádàpọ̀ oníṣekúṣe.” Ohun tó mú kí Jèhófà sọ̀rọ̀ báyìí ni pé ó mọ irú ẹni táwa èèyàn jẹ́. Ó mọ bí ọkàn-àyà wa, tàbí irú ẹni tá a jẹ́ ní inú lọ́hùn-ún, ṣe tètè máa ń fà sí ohun tí ojú wa bá rí. Torí náà, Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé: “Ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà. Ta ni ó lè mọ̀ ọ́n?” (Jer. 17:9) Ṣé o ti wá rí ìdí tí ìkìlọ̀ Jèhófà fi ṣe pàtàkì fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì báyìí? Jèhófà mọ̀ dáadáa pé wọ́n á fẹ́ láti wo ohun táwọn abọ̀rìṣà tó yí wọn ká ń ṣe, ohun táwọn abọ̀rìṣà náà ń ṣe sì lè wọ̀ wọ́n lójú débi tí wọ́n á fi fẹ́ láti fìwà jọ wọ́n. Wọ́n lè fẹ́ láti máa múra bíi tàwọn aláìgbàgbọ́ náà, lẹ́yìn náà kí wọ́n máa ronú bíi tiwọn, kí wọ́n sì máa ṣe bíi tiwọn.—Òwe 13:20.
11. Kí ló lè mú kí ọkàn wa máa fà sí àwọn ohun tá à ń fojú rí?
11 Lóde òní, ó túbọ̀ rọrùn fún ọkàn-àyà wa tó ṣe àdàkàdekè láti fà sí àwọn ohun tá à ń fojú rí. Ìdí ni pé à ń gbé nínú ayé kan tó ń mú kí ọkàn-àyà wa máa fà sí àwọn ohun tí kò tọ́. Torí náà, báwo la ṣe lè fi ìlànà inú Númérì 15:39 sílò? Ronú lórí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí: Bí àwọn tẹ́ ẹ jọ ń lọ sílé ìwé, àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí àwọn aládùúgbò rẹ bá ń wọṣọ lọ́nà tó ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe, ṣé wàá fẹ́ láti máa múra bíi tiwọn? Ṣé wàá fẹ́ láti máa tọ ‘ọkàn-àyà rẹ àti ojú rẹ lẹ́yìn’ kó o sì gbà kí ohun tó ò ń rí sún ẹ dẹ́ṣẹ̀? Ṣé èyí sì lè mú kó o pa àwọn ìlànà Kristẹni lórí aṣọ wíwọ̀ tì kó o lè máa múra bíi tiwọn?—Róòmù 12:1, 2.
12, 13. (a) Kí la gbọ́dọ̀ ṣe bó bá ń wù wá láti máa wo ohun tí kò tọ́? (b) Kí nìdí tí kò fi dára pé ká máa ṣe ohun tó máa gbé èrò tí kò tọ́ wá sọ́kàn àwọn míì?
12 Ó pọn dandan pé ká ní ìkóra-ẹni-níjàánu. Bó bá ń wù wá láti máa wo ohun tí kò tọ́, ẹ jẹ́ ká máa rántí bí Jóòbù ti ṣe ìpinnu tó lágbára. Ọkùnrin olóòótọ́ yìí bá ojú rẹ̀ dá májẹ̀mú. Ìyẹn ni pé ó pinnu pé òun kò ní wo obìnrin èyíkéyìí tí kì í ṣe ìyàwó òun pẹ̀lú èrò láti bá a ṣèṣekúṣe. (Jóòbù 31:1) Bákan náà, Dáfídì Ọba pinnu pé: “Èmi kì yóò gbé ohun tí kò dára fún ohunkóhun ka iwájú mi.” (Sm. 101:3) Ní tiwa, bí ohunkóhun bá lè ba ẹ̀rí ọkàn mímọ́ tá a ní àti àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ jẹ́ “ohun tí kò dára fún ohunkóhun.” Lára rẹ̀ ni ìdẹwò èyíkéyìí tó bá ń mú kó máa wù wá láti wo ohun tí kò dára tó sì lè tan ọkàn-àyà wa láti hùwà àìtọ́.
13 Bákan náà, àwa pẹ̀lú gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má bàa di “ohun tí kò dára fún ohunkóhun” nípa ṣíṣe ohun tó lè mú káwọn míì máa ronú láti hùwà àìtọ́. Ìdí nìyẹn tá a fi gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú ìmọ̀ràn onímìísí tí Bíbélì fún wa pé ká máa wọ aṣọ lọ́nà tó wà létòletò tó sì fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà hàn. (1 Tím. 2:9) Àwa kọ́ la máa dá pinnu bóyá aṣọ wa ń fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà hàn. A gbọ́dọ̀ gba ti àwọn míì tó ń wò wá rò. Ká bi ara wa pé ṣé aṣọ náà kò ní da ẹ̀rí ọkàn wọn láàmú, ṣé kò sì ní gbé èrò tí kò tọ́ wá sọ́kàn wọn? Ó yẹ ká fi ire tiwọn ṣáájú tiwa. (Róòmù 15:1, 2) Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ rere tó bá dọ̀ràn aṣọ wíwọ̀ ni wọ́n wà nínú ìjọ Kristẹni. Àwọn ọ̀dọ́ yìí ń mú inú wa dùn torí pé wọn kò tọ ‘ọkàn-àyà àti ojú wọn lẹ́yìn.’ Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n yàn láti máa ṣe ohun tó wu Jèhófà nínú ohun gbogbo, tó fi mọ́ bí wọ́n ṣe ń múra.
Má Ṣe Tẹ̀ Lé “Òtúbáńtẹ́”
14. Kí nìdí tí Sámúẹ́lì fi kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n má ṣe lépa “òtúbáńtẹ́”?
14 Wàyí o, jẹ́ ká sọ pé bó o ṣe ń rìnrìn àjò lọ, o ní láti gba inú aṣálẹ̀ kọjá. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí ẹ tó o bá fi ibi tó yẹ kó o gbà sílẹ̀ tó o sì yà gba apá ibi tó o rò pé omi wà, tó o wá débẹ̀ tán tó o rí i pé kò sómi níbẹ̀? O lè sọ nù kó o sì kú sínú aṣálẹ̀ náà! Jèhófà náà mọ bó ṣe léwu tó fún èèyàn láti máa lépa òtúbáńtẹ́. Àpẹẹrẹ kan rèé: Nígbà kan, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fẹ́ kí èèyàn máa ṣàkóso lé wọn lórí bíi tàwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká. Ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ni ohun tí wọ́n sọ pé àwọn ń fẹ́ yẹn torí pé ohun tó túmọ̀ sí ni pé wọn kọ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọba wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà yọ̀ǹda pé kí èèyàn di ọba wọn, ó ní kí wòlíì rẹ̀ Sámúẹ́lì kìlọ̀ fún wọn. Ìkìlọ̀ náà sì mú kó ṣe kedere pé kí wọ́n má ṣe lépa “òtúbáńtẹ́.”—Ka 1 Sámúẹ́lì 12:21.
15. Ọ̀nà wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà lépa òtúbáńtẹ́?
15 Ṣé ohun táwọn èèyàn yẹn rò ni pé àwọn á lè ní ìgbọ́kànlé nínú irú ọba tó ṣeé fojú rí bẹ́ẹ̀ ju Jèhófà tí kò ṣeé fojú rí lọ? Bó bá jẹ́ pé ohun tí wọ́n rò nìyẹn, a jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n ń lépa òtúbáńtẹ́! Bí wọn kò bá sì ṣọ́ra, Sátánì á mú kí wọ́n lépa ọ̀pọ̀ òtúbáńtẹ́ míì. Bí àpẹẹrẹ, ọba tó jẹ́ èèyàn lè mú kí wọ́n máa bọ òrìṣà. Àṣìṣe táwọn abọ̀rìṣà sì máa ń ṣe ni pé wọ́n máa ń rò pé ó yẹ káwọn gbẹ́kẹ̀ lé àwọn òrìṣà tí wọ́n fi igi àti òkúta ṣe torí pé wọ́n lè fojú rí wọn, wọ́n sì lè fọwọ́ kàn wọ́n. Wọn kò ní ìgbọ́kànlé nínú Jèhófà, Ọlọ́run tí wọ́n kò lè fojú rí, tó dá ohun gbogbo. Àmọ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe sọ, àwọn òrìṣà wọ̀nyí kò “jámọ́ nǹkan kan.” (1 Kọ́r. 8:4) Wọn kò lè ríran, wọ́n kò lè gbọ́ràn, wọ́n kò lè sọ̀rọ̀, wọ́n kò sì lè ṣe ohunkóhun. Òótọ́ ni pé èèyàn lè rí wọn kó sì fọwọ́ kàn wọ́n, ṣùgbọ́n ńṣe lẹni tó bá ń sìn wọ́n ń lépa òtúbáńtẹ́. Irú ìlépa bẹ́ẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀tàn lásánlàsàn tó máa ń múni kàgbákò.—Sm. 115:4-8.
16. (a) Báwo ni Sátánì ṣe ń tan ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí kí wọ́n lè máa lépa òtúbáńtẹ́? (b) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run, òtúbáńtẹ́ ni àwọn ohun ìní tara jẹ́?
16 Ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ ni Sátánì, ó ṣì ń mú káwọn èèyàn máa lépa òtúbáńtẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ó ti mú kí àìlóǹkà èèyàn gbà gbọ́ pé ohun ìní tara lè mú kí ọkàn èèyàn balẹ̀. Òótọ́ ni pé ó lè dà bíi pé owó, àwọn ohun ìní tara àti iṣẹ́ olówó ńlá lè ranni lọ́wọ́. Àmọ́, báwo làwọn ohun ìní tara ṣe lè ranni lọ́wọ́ bí àìsàn bá dé, tí ọrọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀ tàbí tí omíyalé, ìsẹ̀lẹ̀ tàbí àjálù mìíràn bá wáyé? Báwo ni wọ́n ṣe lè ran àwọn tí nǹkan ti sú tí wọn kò sì mọ ibi tí ayé forí lé lọ́wọ́? Ìtọ́sọ́nà tàbí ìdáhùn wo ni wọ́n lè fún ẹni tí ọ̀pọ̀ ìbéèrè nípa ìgbésí ayé ń jà gùdù lọ́kàn rẹ̀? Ṣé wọ́n lè gbani lọ́wọ́ ikú? Bá a bá rò pé àwọn ohun ìní tara ló máa mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run sunwọ̀n sí i ńṣe là ń tan ara wa jẹ. Àwọn ohun ìní tara ò lè gbani sílẹ̀ lọ́jọ́ ìṣòro; òtúbáńtẹ́ ni wọ́n. Wọn ò tiẹ̀ lè fini lọ́kàn balẹ̀, torí pé wọn ò lè mú kí ìwàláàyè kúkúrú ti ẹ̀dá ní nísinsìnyí gùn sí i; wọn kò sì lè mú àìsàn àti ikú kúrò. (Òwe 23:4, 5) Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa, Jèhófà, ń bẹ láàyè, kì í ṣe òtúbáńtẹ́! Àyàfi tá a bá ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú rẹ̀ la tó lè rí ojúlówó ààbò. Àǹfààní tó ṣeyebíye mà nìyẹn o! Ǹjẹ́ ká má ṣe fi Jèhófà sílẹ̀ láé nítorí àtimáa lépa àwọn ohun tó jẹ́ òtúbáńtẹ́.
17. Kí lo pinnu láti ṣe nípa àwọn ewu tá a ti jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
17 Inú wa dùn pé Ọ̀rẹ́ wa ni Jèhófà. A sì dúpẹ́ pé ó ń tọ́ wa sọ́nà ká bàa lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun. Tá a bá ń bá a nìṣó láti máa ṣègbọràn sí àwọn ìkìlọ̀ tó ń fìfẹ́ fún wa nípa ewu tó wà nínú títẹ̀ lé ogunlọ́gọ̀, ọkàn-àyà wa àti òtúbáńtẹ́, á túbọ̀ dá wa lójú pé ọwọ́ wa máa tẹ ìyè àìnípẹ̀kun. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa ìkìlọ̀ mẹ́ta mìíràn tí Jèhófà fún wa, èyí tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti kórìíra àwọn ipa ọ̀nà èké tó ti kó ọ̀pọ̀ èèyàn ṣìnà ká máa bàa tọ irú ipa ọ̀nà bẹ́ẹ̀.—Sm. 119:128.
Kí Lèrò Rẹ?
Báwo lo ṣe lè fi àwọn ìlànà tó wà nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sílò?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Ṣó ti ṣe ẹ́ rí bíi pé kó o tẹ̀ lé ogunlọ́gọ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Kí nìdí tó fi léwu pé kéèyàn máa nífẹ̀ẹ́ sí gbogbo ohun tó bá ti rí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Ǹjẹ́ ò ń lépa ohunkóhun tó jẹ́ òtúbáńtẹ́?