Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli—Nínú Ọgbà Ẹranko!
NÍGBÀ kan, a yan ibi ṣíṣàjèjì kan fún ìjíròrò tí ìdílé wa máa ń ṣe lórí Bibeli lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀—Ọgbà Ẹranko Emmen, tí ó wà ní itòsí ilé wa ní Netherlands. Ó sì nídìí pàtàkì kan tí a fi yàn án, tí ìwọ kò ní pẹ́ mọ̀.
Bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn ìdílé Kristian míràn káàkiri àgbáyé, a máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Nígbà tí a bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí lọ́wọ́, a sábà máa ń kà nípa àwọn ẹranko tí wọ́n lò nínú Bibeli gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ àwọn ànímọ́ rere àti búburú. A máa ń ṣe kàyéfì bóyá a lè mọ àwọn ẹranko náà dunjú sí i, a sì pinnu láti ṣe é ní ohun tí gbogbo ìdílé lọ́wọ́ nínú rẹ̀. A yan ẹranko pàtó kan fún mẹ́ḿbà ìdílé kọ̀ọ̀kan, a sì sọ fún wọn kí wọ́n wá ìsọfúnni nípa ẹranko yìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde bí ìwé Insight on the Scriptures àti àwọn ìdìpọ̀ Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí!
Bí a ti ń wo ẹnu ọ̀nà Ọgbà Ẹranko Emmen náà ní ọ̀ọ́kán, àwọn ọmọ wa, Mari-Claire, Charissa, àti Pepijn, ti ń fojú sọ́nà ní rekete. A óò rí ọ̀ni, beari, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà, àwọn èèrùn, àti bóyá, púpọ̀ àwọn ẹranko tí a ti kà nípa wọn nínú Bibeli pàápàá. Àmọ́, jẹ́ kí a kọ́kọ́ sọ fún ọ nípa ọgbà ẹranko pípabanbarì yìí.
Kò Sí Àgò, Kò Sí Àkámọ́
Ọgbà Noorder Dierenpark, gẹ́gẹ́ bí àwọn ará Netherlands ṣe máa ń pe Ọgbà Ẹranko Emmen, jẹ́ ọgbà ẹranko kan tí ó ṣàrà ọ̀tọ̀ pátápátá, tí a fi àwọn ìlànà òde òní ti bí ọgbà ẹranko ṣe gbọ́dọ̀ rí gbé kalẹ̀. Níhìn-ín yìí, o kò lè rí ẹranko kankan nínú àgo tàbí nínú àkámọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ní Emmen, gbogbo ohun tí ó ṣeé ṣe ni wọ́n ti ṣe láti mú kí àwọn ẹranko náà wà ní àyíká tí ó jọra pẹ̀lú ibùgbé wọn gan-an nínú igbó bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Ọ̀kan lára àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè ní ọgbà náà, Wijbren Landman, fi tẹ̀ríntẹ̀rín sọ pé: “Kàkà tí ì bá fi jẹ́ pé àwọn ẹranko ló wà nínú àkámọ́, àlejò ló wà nínú rẹ̀.”
“A kò kó àwọn ẹranko náà jọ látàrí irú ẹ̀yà wọn, ṣùgbọ́n látàrí ibi tí wọ́n ti wá. Ìdí nìyẹn tí ó fi jẹ́ pé ní pápá ilẹ̀ Áfíríkà salalu tí ẹ̀ ń wò níhìn-ín, ọ̀pọ̀ àwọn ẹranko tí wọ́n ń gbé pa pọ̀ nínú ìgbẹ́ ni a kó pa pọ̀ bí ó ti ṣeé ṣe tó.” Kò sì purọ́, a rí wọn lóòótọ́—àwọn ẹranko tí ó ga jù lọ lágbàáyé, àgùnfọn ọlọ́rùn gígùn, tí ó lè ga tó nǹkan bí mítà mẹ́fà. Wọ́n wà pa pọ̀ pẹ̀lú springbok, impala, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà, gnu, òtòlò, àti àwọn ẹranko rhinoceros bíi mélòó kan pàápàá.
Àmọ́ ọ̀rọ̀ ṣì kù lẹ́nu Wijbren tó fẹ́ sọ fún wa nípa pápá Emmen: “Àwọn ẹranko náà ní àyè tí ó pọ̀ gan-an débi pé kò tilẹ̀ dà bí èyí tí a há wọn mọ́ lójú wọn. Síbẹ̀, a tún ti pèsè ibi ìsápamọ́ bíi mélòó kan fún wọn. Ǹjẹ́ ẹ rí àwọn òkúta ńlá ńlá tí ó wà lọ́ọ̀ọ́kán wọ̀nyẹn? Àwọn ẹranko springbok lè mórí pa mọ́ sáàárín wọn, kí rhino má baà dà wọ́n láàmú. Òkè tí ó sì wà lọ́hùn-ún yẹn kì í jẹ́ kí àwọn ẹranko náà wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ibi tí wọ́n ti lè ríra wọn. Àmọ́, lọ́pọ̀ ìgbà agbára káká ni àwọn ẹranko náà fi ń kọbi ara sí i pé ẹranko mìíràn wà láyìíká àwọn. Èyí kò yani lẹ́nu pẹ́ẹ̀pẹ́ẹ̀, níwọ̀n bí wọ́n ti jìjọ n gbé pọ̀ ní ilẹ̀ Áfíríkà fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún.”
Àwọn Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Abilà Olóùngbẹ
“Ẹ wò ó! Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà!” Inú Charissa ti dùn dẹ́yìn. Ó ṣe àwọn ìwádìí gbígbádùn mọ́ni kan lórí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà. “Àwọn ilà ara wọn kì í jẹ́ kí ènìyàn rí bí wọ́n ṣe rí gan-an, ó sì máa ń dojú bí ìlà náà ti rí rú mọ́ ènìyàn lójú gan-an débi pé, àní àwọn ọmọ ìbílẹ̀ tí ojú wọn tètè máa ń rí nǹkan pàápàá kì í fura lọ́pọ̀ ìgbà pé wọ́n wà níbẹ̀ nígbà tí wọ́n bá wà ní kìkì nǹkan bí 40 sí 50 mítà sí wọn. Agbára ìríran àti ìgbóòórùn mímúná àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà, pa pọ̀ pẹ̀lú agbára àtilè sàré geerege wọn—wọ́n tilẹ̀ lè sáre ju 60 kìlómítà lọ ní wákàtí kan—jẹ́ ààbò fún wọn kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹranko apẹranjẹ. Gẹ́gẹ́ bí Orin Dafidi 104:11 tí sọ, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà ‘ń pa òùngbẹ wọn déédéé.’ Ìdí nìyẹn tí ó fi jẹ́ pé agbára káká ni ènìyàn fi lè rí wọn ní ibi tí ó jìnnà jù kìlómítà mẹ́jọ lọ sí omi.” Lẹ́yìn ìyẹn ni ó fi kún un pé: “Àwa náà gbọ́dọ̀ máa pa òùngbẹ wa nípa tẹ̀mí déédéé nípa sísún mọ́ ìjọ, kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, àti lílọ sí àwọn ìpàdé.”
A fi pápá ilẹ̀ Áfíríkà sílẹ̀, a sì rìn gba ìhà ibi tí ọ̀kan nínú àwọn adọdẹ-ẹran tí ó tóbi jù lọ lórí ilẹ̀ ayé, beari kodiak, wà. Èyí tí ó tóbi jù lọ nínú gbogbo àwọn beari yìí lè gùn tó nǹkan bíi mítà mẹ́ta, kí ó sì wọ̀n to kìlógíráàmù 780. Kí àwọn ibi tí wọ́n wà yìí baà lè jọ ibi àdánidá gan-an bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó, a ti fi àwọn odò àti àwọn àpáta ràbàtà-ràbàtà ṣe wọ́n lọ́ṣọ̀ọ́. Beari kodiak jẹ́ ọmọ ìyá beari aláwọ̀ ilẹ̀ ti Syria, èyí tí ń gbé ní Israeli ní àwọn àkókò tí a kọ Bibeli. Gẹ́gẹ́ bí Mari-Claire ti ṣàwárí, àwọn beari máa ń gbẹ́mìí wọn ró pẹ̀lú onírúurú oúnjẹ. Wọ́n máa ń jẹ ewé àti àwọn ẹkàn àwọn ewéko pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn èso, berry, ẹ̀pà, ẹyin, kòkòrò, ẹja, èkúté, àti àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀, wọ́n sì kúndùn oyin ìgàn lọ́pọ̀lọpọ̀. Ní Israeli ìgbàanì, nígbà tí àwọn nǹkan ewéko tí àwọn beari máa ń jẹ́ di ọ̀wọ́n gógó, àwọn olùṣọ́ àgùntàn máa ń ṣọ́ra kí àwọn beari má baà máa jà wọ́n lólè. Nígbà tí Dafidi wà ní kékeré, ó di dandan pé kí ó fi tìgboyàtìgboyà kojú beari kan tí ó kò ó lójú, kí ó baà lè dáàbò bo agbo ẹran baba rẹ̀.—1 Samueli 17:34-37.
“Láti Ihò Imú Rẹ̀ Ni Èéfín Ti Í Jáde Wá”
Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn ẹranko ló tún kù tí a fẹ́ láti rí ní ti gidi. Ní ọjọ́ kan tí à ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli wa, a kà nípa “Lefiatani,” ọ̀ni. Lákọ̀ọ́kọ́, Pepijn ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ‘irú ẹja kan, àmọ́ tí ó tóbi ràgàjì-ragaji!’ Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé àwọn ọ̀ni tètè máà ń mọ ìyípadà nínú ojú ọjọ́ lára, wọ́n kó wọn sí Ilé Ilẹ̀ Áfíríkà, níbi tí ojú ọjọ́ tí máa ń jẹ́ ti ilẹ̀ olóoru. Nígbà tí a wọlé, pẹ̀kí ni a ṣe pẹ̀lú ooru àti ọ̀rinrin tí ó mú kí ooru bo awò ojú wa. Ní àfikún sí ìyẹn, ó tún ku kí a jẹ́ kí ara wa mọlé pẹ̀lú òkùnkùn náà. Bí a ti ń rìn gba orí afárá alágbèérọ̀ kọjá, pẹ̀kí ní a ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀ni gbàǹgbà-gbàǹgbà méjì kan tí ó dà bíi pé wọ́n ń ṣọ́ àwọn ibi àbàtà tí ó wà ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ afárá náà. Ńṣe ni wọ́n kàn nà síbẹ̀ gbalaja débi tí Pepijn fi sọ pé: “Wọn kì í ṣe ààyè ọ̀ni.”
Ọ̀ni jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀dá afàyàfà tí ó tóbi jù lọ tí ó ṣì wà láàyè. Àwọn kan lè gùn tó mítà mẹ́fa, wọ́n sì lè wọ̀n tó 900 kìlógíráàmù. Agbára àgbọndò wọn fa kíki—ọ̀ni tí ó tilẹ̀ jẹ́ kékeré tí ó wọn 50 kìlógíráàmù pàápàá lè lo agbára tí ó tó ohun tí ó ju 700 kìlógíráàmù lọ. Nígbà tí ọ̀ni bá yọrí jáde lẹ́yìn tí ó ti torí bọmi fún ìgbà díẹ̀, afẹ́fẹ́ tí ń jáde láti ihò imú rẹ̀, ní ìgbà tí oòrùn òwúrọ̀ bá mú hanhan lè jẹ́ ìbùjáde ooru ‘ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀’ àti ‘ẹ̀ẹ́fín tí ń jáde wá láti ihò imú rẹ̀’ tí ìwé Jobu ṣàpèjúwe.—Jobu 41:1, 18-21.
“Oníṣọ̀ọ́ra Gẹ́gẹ́ Bí Ejò”
Kò pẹ́ tí a kúrò níbi àwọn ọ̀ni náà tí a fi ń gbúròó àwọn irú ìṣẹ̀dá kan tí a lò nínú Bibeli gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ àwọn ànímọ́ tí ó dára àti èyí tí kò dára, nínú òkùnkùn—Ọlọrun bá wa ṣe é pé wọ́n wà lẹ́yìn ẹ̀là dígí kan. Ejo ni à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀, ẹranko tí a kọ́kọ́ dárúkọ nínú Bibeli. (Genesisi 3:1) Jesu lo ìṣọ́ra tí ejò máa ń lò gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ nígbà tí ò ń fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ìṣítí nípa ìwà wọn láàárín àwọn alátakò tí wọ́n dà bí ìkookò. (Matteu 10:16) Àmọ́, ó dájú pé àwọn ènìyàn máa ń so ejò pọ̀ mọ “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ naa,” Satani Èṣù, tí a ṣàpèjúwe nínú 2 Korinti 11:3 gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó máa ń súnni dẹ́ṣẹ̀, tí ó sì jẹ́ alálùmọ̀kọ́rọ́yí bí ejò.—Ìṣípayá 12:9.
“Tọ Èèrùn Lọ, . . . Kí O Sì Gbọ́n”
Ohun kan tí a kò retí láti rí ní ọgbà àwọn ẹranko ni òkìtì àwọn èèrùn ńlá tí a rí, èyí tí agbo àwọn èèrùn jewéjewé mẹta ń gbé inú rẹ̀. Àwọn wọ̀nyí jẹ́ àwọn aṣọ́gbà láàárín àwọn èèrùn. A lè rí agbo wọn lẹ́yìn ẹ̀là dígí kan; èyí ń mú kí a lè ṣàyẹ̀wò ìṣesí àwọn ẹ̀dá kéékèèké wọ̀nyí. A fẹ́ láti mọ̀ nípa àwọn èèrùn nítorí pé wọ́n lò wọ́n nínú Bibeli gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ìṣiṣẹ́ takuntakun àti ọgbọ́n àtinúdá.—Owe 6:6.
Wijbren Landman jẹ́ ògbógi nípa àwọn kòkòrò. Ó ṣàlàyé pé: “Àwọn èèrùn tí a fojú díwọ̀n sí àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà bílíọ̀nù ń ṣiṣẹ́ fitafita lórí ilẹ̀ẹ́lẹ̀ ayé, èyí tí ó túmọ̀ sí pé fún ènìyàn kọ̀ọ̀kan, èèrùn tí ó tó 200,000 ló wà! Nínú gbogbo 15,000 irú ẹ̀yà àwọn èèrùn tí a rí tí wọ́n fọ́n káàkiri gbogbo àwọn àgbáálá ilẹ̀, yàtọ̀ sí àwọn agbègbè salalu ilẹ̀ ayé, kò sí àwọn méjì tí ó jọra. Wọ́n máa ń kọ́ àwọn òkìtì oríṣiríṣi, wọ́n sì máa ń jẹ oríṣiríṣi oúnjẹ, àmọ́, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé bákan náà ni wọ́n máa ń wà létòlétò.
Àwọn èèrùn jewéjewé máa ń ṣọ̀gbìn àwọn olú tí ó ṣeé jẹ, gẹ́lẹ́ bí àwọn ènìyàn ṣe máa ń ṣọ̀gbìn olú. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i, wọ́n máa ń ṣe ọ̀gbìn yìí lábẹ́ ilẹ̀, àmọ́, oúnjẹ tí àwọn olù náà ń jẹ́ ń wá láti òkè ilẹ̀. Láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀, ọwọ́ àwọn èèrùn òṣìṣẹ́ máa ń dí ní kíkó ewé lọ sí ibi ìtẹ́ wọn. Wọn yóò gun igi tàbí ewéko kan, wọn yóò sì yan ewé kan. Lẹ́yìn rẹ̀, wọn yóò ló àgbọndò wọn gẹ́gẹ́ bí àlùmọ́gàjí, wọ́n yóò sì yára gé àwọn ègé tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣe roboto tán lára ewé náà, wọn yóò sì máa kó ìwọ̀nyí lọ́ sí ìtẹ́ wọn ní ìtòtẹ̀léra, wọn yóò gbé wọn bí ìgbà tí wọ́n gbé agbòòrùn lórí. Ìdí sì nìyí tí a fi ń pè wọ́n ní orúkọ wọn kejì, èèrùn alágbòòrùn. Ewé gígé náà máa ń yára kánkán tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé ní Gúúsù àti Àárín Gbùngbùn America, wọ́n máa ń jẹ gbogbo ewé orí igi tàbí ewéko kan ní kìkì wákàtí bíi mélòó kan. Abájọ tí àwọn ènìyàn kò fi fẹ́ràn wọn níbẹ̀! Nínú ìtẹ́, àwọn òṣìṣẹ́ mìíràn máa ń mú kí àwọn ègé ewé náà wà ní mímọ́ tìṣọ́ra-tìṣọ́ra kí wọ́n tó jẹ wọ́n wómúwómú. Lẹ́yìn ìyẹn, wọn yóò po pọ̀tọ̀pọ́tọ̀ tí wọ́n ti jẹ lẹ́nu náà pẹ̀lú èròjà enzyme àti amino acid tí àwọn èèrùn náà yà jáde. Kìkì lẹ́yìn ìgbà yẹn ni wọ́n tó lè lo pọ̀tọ̀pọ́tọ̀ tí wọ́n jẹ lẹ́nu náà gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ fún àwọn olú náà, tí wọn yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ máa rí ìpèsè olú déédéé fún gbogbo agbo náà.”
Lẹ́yìn tí ọgbọ́n àti àtinúdá tí ó hàn gbangba nínú àwọn àílòǹkà onírúurú ìṣẹ̀dá ti wọ̀ wá lọ́kàn tán, a kúrò níbi agbo àwọn èèrùn. Ọ̀sán ti pọ́n, a sì ní láti darí sílé. Ṣùgbọ́n, ohun púpọ̀ ló ṣì kù fún wa láti rí. A kò tí ì lọ wo àwọn òwìwí (Isaiah 13:21), àwọn ẹranko seali (Eksodu 35:23), àwọn erinmi (“Behemotu,” Jobu 40:15), àwọn ògòǹgò (Jeremiah 50:39), tàbí ọ̀pọ̀ àwọn ẹranko mìíràn tí ó wà níhìn-ín tí a mẹ́nu kàn nínú Bibeli. Gbogbo wọn ló yẹ kí a yẹ̀ wò. Ó dájú pé a óò tún padà wá sí Ọgbà Ẹranko Emmen!—A kọ ọ́ ránṣẹ́.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 16]
Ògòǹgò: Yotvatah Nature Reserve