Ẹwà Ìṣẹ̀dá Jèhófà
‘Ìwọ Ní Ọlá Ńlá Ju Àwọn Òkè Ńlá Lọ’
ÌRÍRÍ mánigbàgbé ló jẹ́ láti wo bí oòrùn ṣe ń yọ láti orí Òkè Fújì. Oòrùn aláwọ iná tàn yòò sórí ibi tí ó jọ pé ilẹ̀ òun òfuurufú ti pàdé, ó sì tan ìmọ́lẹ̀ sórí ìrì dídì funfun àti àpáta yíyòrò aláwọ̀ eérú. Bí ojú ọjọ́ kejì tún ṣe mọ́ báyìí, òjìji òkè ńlá náà yára bo ọ̀pọ̀ kìlómítà lára àwọn òkè àtàwọn àfonífojì náà.
Kò sígbà tí àwọn òkè ńláńlá kò ní máa jọ wa lójú bíi ti Òkè Fújì, tí orúkọ rẹ̀ tí wọ́n fi lẹ́tà aláwòrán kọ nígbà kan túmọ̀ sí “aláìlẹ́gbẹ́.” Ká sòótọ́, títóbi wọn nìkan tó ohun tó ń mú kí á rẹ ara wa sílẹ̀! Títóbi àwọn òkè ńláńlá wọ̀nyí ga lọ́lá tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi gbà gbọ́ pé àwọn téńté òkè ńláńlá, tí ìrì àti ìkùukùu sábà máa ń bò jẹ́ ibi tàwọn ọlọ́run ń gbé.
Ọlọ́run kan ṣoṣo tí ṣóńṣó àwọn òkè wọ̀nyí ń fi ìyìn fún ni Jèhófà, Ẹlẹ́dàá wọn tí kò láfiwé. Òun nìkan ṣoṣo ni “Aṣẹ̀dá àwọn òkè ńlá.” (Ámósì 4:13) Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ìdámẹ́rin ayé ló jẹ́ ibi olókè ńláńlá, nígbà tí Ọlọ́run sì dá ayé wa yìí, ó mú kí àwọn ipá alágbára kan wà tó ń mú káwọn téńté òkè ńlá àti ọ̀wọ́ àwọn òkè jáde wá. (Sáàmù 95:4) Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn gbà gbọ́ pé àwọn ìmìtìtì lílágbára tó ṣẹlẹ̀ nínú ayé àti bí ilẹ̀ ṣe ń rọ́ láti ibi kan sí ibòmíràn ló mú ọ̀wọ́ àwọn òkè Himalayas àti ti Andes jáde.
Àwa èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ mọ bí àwọn òkè ńlá ṣe wáyé, a ò sì mọ ìdí tí wọ́n fi wà. Ká sòótọ́, a ò le dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí tí Ọlọ́run béèrè lọ́wọ́ Jóòbù olódodo nì, pé: “Ibo ni ìwọ wà nígbà tí mo [ìyẹn Jèhófà] fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀? . . . Inú kí ni a ri ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀ sí?”—Jóòbù 38:4-6.
Àmọ́ ṣá o, a mọ̀ pé a kò lè wà láàyè láìsí àwọn òkè ńláńlá. Nítorí èyí làwọn èèyàn ṣe pè wọ́n ní àgbá omi tó wà níbi gíga, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé inú àwọn òkè ńláńlá wọ̀nyí ni omi gbogbo àwọn odò ńláńlá ti máa ń ṣàn wá, inú àwọn òkè ńlá wọ̀nyí sì ni ìdajì èèyàn tó wà láyé ti ń rí omi tí wọ́n ń lò. (Sáàmù 104:13) Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé, “mẹ́fà lára ogún igi eléso tó ń pèsè oúnjẹ jù lọ lágbàáyé wá látinú àwọn òkè ńlá.” Nígbà tí àwọn ohun alààyè àti ti àyíká bá wà lábẹ́ ipò tó dára nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí, “ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.”—Sáàmù 72:16; 2 Pétérù 3:13.
Nígbà tá a bá sọ̀rọ̀ nípa àwọn òkè ńlá, Òkè Ńlá Yúróòpù ló máa ń wá sí ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́kàn. Àwọn òkè gíga wọ̀nyí, títí kan Òkè Civetta tá a fi hàn níhìn-ín, ń fi ẹ̀rí tó lágbára hàn pé Ẹlẹ́dàá kan wà. (Sáàmù 98:8) Wọ́n ń fi ìyìn fún Jèhófà, ẹni tí ó “fi àwọn òkè ńláńlá múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in nípasẹ̀ agbára rẹ̀.”—Sáàmù 65:6.a
Àgbàyanu ni títóbi àwọn Òkè Alps tó ga fíofío yìí, pẹ̀lú ipele-ipele àti poro wọn tí yìnyín bò, àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ wọn tí òjò dídì bò, àfonífojì àti adágún wọn títí kan ilẹ̀ eléwéko tútù wọn. Dáfídì Ọba sọ pé Jèhófà ni “Ẹni tí ń mú kí àwọn òkè ńláńlá rú koríko tútù jáde.”—Sáàmù 147:8.
Àwọn òkè gíga—bí àwọn òkè tó wà ní Guilin, ní orílẹ̀-èdè Ṣáínà—lè dà bí ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ jọni lójú bíi ti àwọn Òkè Alps, síbẹ̀ ẹwà wọn ṣàrà ọ̀tọ̀. Ẹwà àwọn òkúta funfun tí wọ́n tò tẹ̀ lé ara wọn létí Odò Li, máa ń jọ àwọn tó bá ṣèbẹ̀wò síbẹ̀ lójú gan-an ni. Wíwo àwọn omi mímọ́ lóló tó ń dà yàà látorí àwọn òkè tí kùrukùru bò wọ̀nyí lè mú kéèyàn rántí ọ̀rọ̀ onísáàmù tó sọ pé: “[Jèhófà] ń fi àwọn ìsun ránṣẹ́ sí àwọn àfonífojì olójú ọ̀gbàrá; wọ́n ń lọ láàárín àwọn òkè ńláńlá.”—Sáàmù 104:10.
Àwọn òkè ńlá wọ̀nyí máa ń jọ wá lójú gan-an nítorí pé a kà wọn sí ara àwọn ohun ọlọ́lá ńlá tí Ẹlẹ́dàá fìfẹ́ pèsè fún ire àti ìgbádùn àwa ẹ̀dá ènìyàn. Bó ti wù kí wọ́n jẹ́ àgbàyanu tó, síbẹ̀ bíńtín ni àwọn òkè ńlá wọ̀nyí lára ọlá ńlá Jèhófà. Láìsí àní-àní, ó ‘ní ọlá ńlá ju àwọn òkè ńlá lọ.’—Sáàmù 76:4.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo 2004 Calendar of Jehovah’s Witnesses, oṣù March àti April.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ìpín mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún èèyàn tó wà láyé ló ń gbé láwọn àgbègbè olókè ńláńlá. Àmọ́, ìyẹn kì í ṣe ìdènà tí kò ṣeé borí fún àwọn tó ń kéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ọwọ́ àwọn Kristẹni òjíṣẹ́ wọ̀nyí ń dí gan-an ní ọ̀pọ̀ àgbègbè tó ga fíofío wọ̀nyí. Àá, “ẹsẹ̀ ẹni tí ń mú ìhìn rere wá mà dára rèǹtè-rente lórí àwọn òkè ńlá o, ẹni tí ń kéde àlàáfíà fáyé gbọ́, ẹni tí ń mú ìhìn rere ohun tí ó dára jù wá, ẹni tí ń kéde ìgbàlà fáyé gbọ́!”—Aísáyà 52:7.
Onísáàmù náà kọ ọ́ lórin pé: “Àwọn òkè ńlá gíga wà fún àwọn ewúrẹ́ orí òkè ńlá.” (Sáàmù 104:18) Àwọn ewúrẹ́ òkè ńlá bíi àwọn ewúrẹ́ orí òkè Nubia tí ìwo wọn lẹ́wà gan-an, wà lára àwọn ẹ̀dá tí ẹsẹ̀ wọn le gírígírí ju gbogbo ẹ̀dá tó ń gbé orí àwọn òkè ńlá lọ. Wọ́n máa ń rìn kọjá láàárín àwọn ihò tóóró tó dà bí èyí tí kò ṣeé gbà. Ara ewúrẹ́ orí òkè ńlá gba ìyà débi pé ò lè gbé àwọn ibi tí kò ṣeé dé. Ara ohun tó mú kí èyí ṣeé ṣe ni bí Ọlọ́run ṣe dá pátákò ẹsẹ̀ rẹ̀. Bí ewúrẹ́ náà ṣe lọ́ọ̀rìn tó lè mú kí ẹ̀là tí ń bẹ láàárín ọmọ ìkasẹ̀ rẹ̀ fẹ̀ sí i, kó mú kí ẹsẹ̀ ẹranko yìí lókun nígbà tó bá dúró tàbí nígbà tó bá ń rín lórí àwọn ibi tó yọ gọnbu lára àwọn òkè ńlá. Ní ti tòótọ́, ewúrẹ́ orí òkè jẹ́ àgbàyanu iṣẹ́ ọnà!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Òkè Ńlá Fújì, Honshu, Japan