Orí 5
Agbára Ìṣẹ̀dá—“Olùṣẹ̀dá Ọ̀run àti Ilẹ̀ Ayé”
1, 2. Báwo ni oòrùn ṣe fi agbára ìṣẹ̀dá tí Jèhófà ní hàn?
ǸJẸ́ o tíì yáná nínú otútù, lóru rí? Bóyá ńṣe lo rọra ń fọwọ́ ra iná náà kó lè ta sí ọ bó o ṣe fẹ́. Bó o bá sún mọ́ iná yẹn jù, á máa ta ọ́ lára. Bó o bá tún tàdí mẹ́yìn jù, atẹ́gùn tútù á máa fẹ́ lù ọ́, otútù á sì mú ọ.
2 “Iná” kan wà tó máa ń ta sí wa lára lójúmọmọ. Nǹkan bí àádọ́jọ [150] mílíọ̀nù kìlómítà lọ́hùn-ún ni “iná” yìí wà tó ti ń jó!a Áà, agbára oòrùn mà kúkú pọ̀ jọjọ o, tó fi lè máa rà wá lára bá a ṣe jìnnà sí i tó yìí! Síbẹ̀, ìwọ̀n tó tọ́ gẹ́lẹ́, láìjìnnà jù láìsúnmọ́ jù, ni ayé wà tó ti ń yípo oòrùn, tí í ṣe àgbáàràgbá iná ìléru tó ń kẹ̀ rìrì yẹn. Bí ayé bá sún mọ́ ọn jù bẹ́ẹ̀, ooru rẹ̀ á fa gbogbo omi ayé gbẹ; bó bá sì jìnnà jù bẹ́ẹ̀, omi inú ayé yóò di yìnyín gbagidi. Bí èyíkéyìí nínú méjèèjì bá ṣẹlẹ̀ pẹ́nrẹ́n, ayé ò ní ṣeé gbé fún ohun alààyè rara. Bẹ́ẹ̀, kòṣeémáàní ni ìmọ́lẹ̀ oòrùn jẹ́ fún ohun alààyè ayé yìí. Ó mọ́ lóló bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ségesège, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti pé ó máa ń dùn mọ́ni.—Oníwàásù 11:7.
Jèhófà “pèsè orísun ìmọ́lẹ̀ sílẹ̀, àní oòrùn”
3. Òtítọ́ pàtàkì wo ni oòrùn jẹ́rìí sí?
3 Síbẹ̀, àwọn èèyàn ò ka oòrùn sí rárá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ló gbé ẹ̀mí wọn ró. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n pàdánù ẹ̀kọ́ tó yẹ kí wọ́n rí kọ́ lára oòrùn. Bíbélì sọ nípa Jèhófà pé: “Ìwọ . . . ni ó pèsè orísun ìmọ́lẹ̀ sílẹ̀, àní oòrùn.” (Sáàmù 74:16) Dájúdájú, oòrùn ń ṣe Jèhófà “Olùṣẹ̀dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé” lógo. (Sáàmù 19:1; 146:6) Ó jẹ́ ọkàn lára ọ̀kẹ́ àìmọye ìṣẹ̀dá ojú ọ̀run tó ń kọ́ wa nípa agbára kíkàmàmà tí Jèhófà ní láti fi dá àwọn nǹkan. Jẹ́ ká túbọ̀ gbé díẹ̀ lára ìṣẹ̀dá ojú ọ̀run wọ̀nyí yẹ̀ wò dáadáa, kí á tó wá yíjú sí orí ilẹ̀ ayé àti àwọn ẹ̀dá alààyè inú rẹ̀.
“Ẹ Gbé Ojú Yín Sókè Réré, Kí Ẹ sì Wò”
4, 5. Báwo ni oòrùn ṣe lágbára tó, báwo ló sì ṣe gbòòrò tó, síbẹ̀ báwo ló ṣe jẹ́ sí àwọn ìràwọ̀ yòókù?
4 Ó ṣeé ṣe kí o mọ̀ pé ọ̀kan lára àwọn ìràwọ̀ ni oòrùn tí à ń rí jẹ́. Ohun tó jẹ́ kó dà bíi pé ó tóbi ju àwọn ìràwọ̀ tí à ń rí lálẹ́ ni pé ó sún mọ́ wa jù wọ́n lọ. Báwo ló ṣe lágbára tó? Bí a bá fi ohun tí a fi ń díwọ̀n ìgbóná nǹkan wọn àárín gbùngbùn oòrùn lọ́hùn-ún wò, ìwọ̀n ìgbóná rẹ̀ á dé orí ipele mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lórí òṣùwọ̀n ọ̀hún. Ká sọ pé o ṣeé ṣe fún ọ láti mú èyí tí kò ju orí abẹ́rẹ́ lọ lára oòrùn wá sí ayé yìí, gbígbóná tí ìwọ̀nba bíńtín yẹn máa gbóná yóò pọ̀ débi pé o kò ní lè dúró ní nǹkan bí ogóje kìlómítà sí ibi tó bá wà! Ńṣe ni agbára tó ń ti ara oòrùn jáde ní ìṣẹ́jú àáyá kọ̀ọ̀kan dà bí ìgbà tí ọ̀kẹ́ àìmọye àgbá bọ́ǹbù átọ́míìkì bá bú gbàù pa pọ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.
5 Oòrùn tóbi fàkìà fakia débi pé bí wọ́n bá kó mílíọ̀nù kan àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [1,300,000] irú ayé wa yìí sínú rẹ̀ yóò gbé e mì. Ṣé ìràwọ̀ tó tóbi lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ wá ni oòrùn tí à ń rí yìí ni? Ó tì o, nítorí àwọn onímọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀dá inú sánmà sọ pé oòrùn ṣì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìràwọ̀ kóńkóló tí iná rẹ̀ ò fi bẹ́ẹ̀ lágbára. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé “ìràwọ̀ yàtọ̀ sí ìràwọ̀ ní ògo.” (1 Kọ́ríńtì 15:41) Òun fúnra rẹ̀ ò lè mọ bí ọ̀rọ̀ onímìísí tó sọ yìí ṣe jóòótọ́ tó. Ìràwọ̀ kan wà tó tóbi fàkìà fakia débi pé tí wọ́n bá gbé e sí ọ̀gangan ibi tí oòrùn wà, ó fẹ̀ débi pé ayé wa yìí gan-an á bọ́ sí inú rẹ̀. Ìràwọ̀ ńlá mìíràn sì tún wà tó jẹ́ pé bí a bá gbé òun náà síbi tí oòrùn wà yìí yóò dé ibi tí pílánẹ́ẹ̀tì tí à ń pè ní Sátọ̀n wà. Bẹ́ẹ̀ kẹ̀, Sátọ̀n yìí jìnnà sí ayé gan-an débi pé ìrìn ọdún mẹ́rin gbáko láìdúró ni ọkọ̀ tá a fi ń rìnrìn àjò ojú sánmà yóò rìn kó tó débẹ̀. Ọkọ̀ yìí sì máa ń yára sáré ní ìlọ́po ogójì ju bí ọta ìbọn alágbára kan ṣe máa jáde fòì lẹ́nu ìbọn nígbà tá a bá yìn ín!
6. Báwo ni Bíbélì ṣe fi hàn pé ńṣe ni iye ìràwọ̀ pọ̀ salalu lójú ọmọ ènìyàn?
6 Tá a bá tiẹ̀ ṣì gbé bí àwọn ìràwọ̀ ṣe tóbi tó tì ná ká tún wá wo bí wọ́n ṣe pọ̀ tó, ìyẹn gan-an tún túbọ̀ mú kí ẹ̀rù Ọlọ́run bani. Kódà Bíbélì sọ ohun tó fi hàn pé bóyá la lè ka iye ìràwọ̀ tán, ó ló dà bí “iyanrìn òkun,” èyí tí kì í ṣe ohun tó rọrùn láti kà. (Jeremáyà 33:22) Gbólóhùn yẹn fi hàn pé àwọn ìràwọ̀ pọ̀ gan-an ju ìwọ̀nba téèyàn lè fojú rí lọ. Ó ṣe tán, bí òǹkọ̀wé Bíbélì kan bíi Jeremáyà bá wo ojú ọ̀run lálẹ́, tó sì gbìyànjú láti ka iye ìràwọ̀ tó rí, kò ní lè kà ju nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta lọ. Iye ìràwọ̀ téèyàn lè fojú kà láìlo awò nígbà tójú ọ̀run bá mọ́ kedere lálẹ́ kò jù bẹ́ẹ̀ náà lọ. Iye yìí ṣeé fi wé iye egunrín inú ẹ̀kúnwọ́ iyanrìn lóòótọ́. Àmọ́ ká sòótọ́, ńṣe ni iye ìràwọ̀ pọ̀ yanturu bí iyanrìn òkun.b Ta ló wá lè ka iye wọn tán?
7. (a) Nǹkan bí iye ìràwọ̀ mélòó ló wà nínú ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Onírìísí Wàrà tí ayé wà nínú rẹ̀, báwo sì ni iye tí a wí yìí ṣe pọ̀ tó? (b) Kí nìdí tó fi gba àfiyèsí pé ó ṣòro fún àwọn onímọ̀ nípa ìṣẹ̀dá inú sánmà láti lè sọ iye ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tó wà, kí sì nìyẹn kọ́ wa nípa agbára ìṣẹ̀dá tí Jèhófà ní?
7 Aísáyà 40:26 dáhùn pé: “Ẹ gbé ojú yín sókè réré, kí ẹ sì wò. Ta ni ó dá nǹkan wọ̀nyí? Ẹni tí ń mú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn jáde wá ni, àní ní iye-iye, àwọn tí ó jẹ́ pé àní orúkọ ni ó fi ń pe gbogbo wọn.” Sáàmù 147:4 sọ pé: “Ó ka iye àwọn ìràwọ̀.” Kí wá ni “iye àwọn ìràwọ̀” tó wà? Ìdáhùn rẹ̀ kò rọrùn o. Àwọn onímọ̀ nípa ìṣẹ̀dá inú sánmà fojú díwọ̀n rẹ̀ pé ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Onírìísí Wàrà (Milky Way galaxy) tí ayé yìí wà nínú rẹ̀ ní ohun tó ju ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù ìràwọ̀ lọ.c Bẹ́ẹ̀, ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tí à ń wí yìí kàn jẹ́ ẹyọ kan lásán ni lára ọ̀pọ̀ irú rẹ̀ tí ìràwọ̀ wọn tún pọ̀ ju ìyẹn lọ pàápàá. Iye ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ mélòó ló wá wà? Àwọn kan tí wọ́n jẹ́ onímọ̀ nípa ìṣẹ̀dá inú sánmà sọ pé wọ́n pọ̀ tó àádọ́ta bílíọ̀nù. Àwọn kan sọ pé wọ́n tó bílíọ̀nù márùnlélọ́gọ́fà [125] pàápàá. Tó fi hàn pé àwa èèyàn ò tiẹ̀ mọ iye ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tó wà, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti mímọ àròpọ̀ iye bílíọ̀nù ìràwọ̀ tó wà nínú gbogbo wọn. Síbẹ̀ Jèhófà mọ àròpọ̀ iye wọn pátá. Ẹ̀wẹ̀, àní ó tún fún ìràwọ̀ kọ̀ọ̀kan lórúkọ tirẹ̀ pàápàá!
8. (a) Báwo lo ṣe máa ṣàlàyé bí ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Onírìísí Wàrà ṣe tóbi tó? (b) Kí ni Jèhófà lò láti mú kí àwọn ìṣẹ̀dá inú gbangba òfuurufú wọ̀nyí máa yí po?
8 Tá a bá tún wá wo bí àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ ṣe máa ń gbòòrò tó ẹ̀rù Ọlọ́run á túbọ̀ bà wá. Ìmọ́lẹ̀ máa ń rìn jìnnà tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta kìlómítà ní ìṣẹ́jú àáyá kan ṣoṣo. Ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Onírìísí Wàrà, tí ayé yìí wà nínú rẹ̀, tóbi débi pé pẹ̀lú ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta kìlómítà láàárín ìṣẹ́jú àáyá kan tí ìmọ́lẹ̀ fi ń rìn, bí ìmọ́lẹ̀ bá wà ní ìkángun kan ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ yìí, kí ìmọ́lẹ̀ yìí tó lè dé ìkángun kejì á tó ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] ọdún! Bẹ́ẹ̀ kẹ̀, àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ kan tún ju tiwa yìí lọ ní ìlọ́po-ìlọ́po. Bíbélì sọ pé ńṣe ni Jèhófà “na ọ̀run” bí ìgbà téèyàn ń ta aṣọ lásán. (Sáàmù 104:2) Òun ló sì tún pàṣẹ pé kí gbogbo ìṣùpọ̀ yìí máa yí bí wọ́n ṣe ń yí. Gbogbo ìṣẹ̀dá inú gbangba òfuurufú wọ̀nyí, látorí èyí tó kéré jù lọ títí dórí èyí tó tóbi fàkìà fakia jù lọ, ló ń yí po níbàámu pẹ̀lú àwọn òfin tí Ọlọ́run là sílẹ̀ pé kí wọ́n máa tẹ̀ lé. (Jóòbù 38:31-33) Ìyẹn làwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ fi sọ pé ọ̀nà tí àwọn ìṣẹ̀dá inú gbangba òfuurufú wọ̀nyí gbà fi ń yí po kò yàtọ̀ sí bí ìgbà tí àwọn afijódárà bá pagbo ijó! Nígbà náà, wá ronú nípa Ẹni tó dá gbogbo nǹkan wọ̀nyí. Ǹjẹ́ o kò gbà pé Ọlọ́run tó lágbára kíkàmàmà tó fi dá àwọn ìṣẹ̀dá inú gbangba òfuurufú wọ̀nyí tóbi lọ́ba?
“Olùṣẹ̀dá Ilẹ̀ Ayé Nípasẹ̀ Agbára Rẹ̀”
9, 10. Báwo ni ibi tí Jèhófà gbé oòrùn àti àwọn ọ̀wọ́ rẹ̀, àti Júpítà àti ayé àti òṣùpá sí, ṣe fi agbára Jèhófà hàn kedere?
9 Agbára ìṣẹ̀dá tí Jèhófà ní tún hàn kedere lára ilé ayé wa yìí. Ńṣe ló fara balẹ̀ gbé ayé síbi tó yẹ gẹ́lẹ́ láàárín òfuurufú gbalasa. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan gbà pé ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ púpọ̀ wà tó jẹ́ pé ká níbẹ̀ layé wà ni, ẹ̀dá alààyè ò ní lè gbébẹ̀. Ó sì jọ pé ibi tó pọ̀ jù nínú ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Onírìísí Wàrà tí ayé wà nínú rẹ̀ ní kò ṣeé gbé fún ẹ̀dá alààyè. Ṣe ni ìràwọ̀ kún àárín gbùngbùn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ yìí fọ́fọ́. Ìtànṣán olóró tó wà níbẹ̀ pọ̀ jù, àti pé àwọn ìràwọ̀ ibẹ̀ máa ń fẹ́rẹ̀ẹ́ fara gbára lọ́pọ̀ ìgbà. Eteetí ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ yìí kò ní ọ̀pọ̀ àwọn ohun tó jẹ́ kòṣeémánìí fún ẹ̀dá alààyè. Ṣùgbọ́n ibi tó yẹ gẹ́lẹ́ láàárín gbogbo ìwọ̀nyí ni Ọlọ́run gbé oòrùn àti àwọn ọ̀wọ́ rẹ̀ tí ayé wà nínú rẹ̀ sí.
10 Pílánẹ́ẹ̀tì ńlá kan tó ń jẹ́ Júpítà, tó wà lọ́nà jíjìn sí ayé náà tún ń ṣe ayé láǹfààní, ó ń dáàbò bò ó. Júpítà yìí tóbi ju Ayé lọ ní ìlọ́po ẹgbẹ̀rún, nípa bẹ́ẹ̀, agbára òòfà tirẹ̀ kọyọyọ. Kí nìyẹn wá yọrí sí? Òòfà rẹ̀ máa ń bá wa fa àwọn nǹkan eléwu tó bá ń já ṣòòròṣò bọ̀ láti gbangba òfuurufú mọ́ra tàbí kí ó tì í dà nù. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣírò rẹ̀ pé, bí kì í bá a ṣe ti Júpítà yìí ni, àwọn òkúta ràbàtà-ràbàtà tí ì bá máa rọ́ lu ayé wa yìí á kọjá wẹ́rẹwẹ̀rẹ. Jèhófà tún wá fi òṣùpá àrà ọ̀tọ̀ tó ń yípo ayé yìí jíǹkí wa. Yàtọ̀ sí pé òṣùpá wà fún ẹwà àti fún “ìmọ́lẹ̀ òru,” ó tún ń mú kí ayé rọra dagun díẹ̀. Dídagun tí ayé dagun yìí ló mú ká lè máa ní onírúurú ìgbà tí kì í yẹ̀ lọ́dún, kí a sì lè máa fi ìdánilójú sọ àkókò tí wọ́n máa wáyé. Èyí tún jẹ́ àǹfààní pàtàkì mìíràn táwọn ẹ̀dá alààyè orí ilẹ̀ ayé níhìn-ín ń jẹ.
11. Báwo ni ọ̀nà tí a gbà ṣe òfuurufú ayé yìí ṣe mú kó dà bí gọgọwú tá a fi dáàbò bò ó?
11 Agbára ìṣẹ̀dá tí Jèhófà ní hàn kedere nínú gbogbo ọ̀nà tó gbà gbé ayé kalẹ̀. Wo òfuurufú ayé wa yìí tó dà bí gọgọwú tá a fi dáàbò bò ó. Àti ìtànṣán tó ń ṣeni lóore àti èyí tó léwu ni oòrùn máa ń mú jáde. Nígbà tí èyí tó léwu bá ràn dé apá òkè òfuurufú ayé, ó máa ń mú kí afẹ́fẹ́ ọ́síjìn yí padà di afẹ́fẹ́ tó ń fínni nímú tí wọ́n ń pè ní afẹ́fẹ́ òsóònù (ozone). Afẹ́fẹ́ òsóònù yìí á wá bo apá òkè òfuurufú ayé, òun ló sì máa ń gba ìtànṣán eléwu náà sára. Ẹ ẹ̀ rí nǹkan bí, ilé ayé wa yìí náà ní agboòrùn tiẹ̀!
12. Báwo ni ìyípoyípo omi òfuurufú ṣe fi àpẹẹrẹ agbára ìṣẹ̀dá tí Jèhófà ní hàn?
12 Apá kan lásán lèyí jẹ́ nínú iṣẹ́ òfuurufú wa, èyí tó kún fún onírúurú afẹ́fẹ́ tó jẹ́ kòṣeémánìí fún ẹ̀dá alààyè tó ń fò lófuurufú tàbí èyí tó ń gbé lórí ilẹ̀ ayé. Lára ohun ìyanu tó ń ṣẹlẹ̀ nínú afẹ́fẹ́ àyíká wa ni ìyípoyípo omi. Ìwọ̀n omi tí oòrùn máa ń fà sókè gẹ́gẹ́ bí oruku láti ojú àwọn òkun ayé yìí lọ́dọọdún á kún inú ládugbó tó fẹ̀, tó gùn, tó sì ga tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [400,000] kìlómítà. Oruku yìí á wá di ìkuukùu tí afẹ́fẹ́ máa ń tì káàkiri. Omi rẹ̀ tó mọ́ nigín á wá rọ̀ bí òjò tàbí yìnyín wuluwulu tàbí yìnyín dídì, èyí tó máa ń pèsè omi fún wa. Gẹ́lẹ́ bí Oníwàásù 1:7 ṣe sọ ọ́ ló ṣe jẹ́, ó ní: “Gbogbo ọ̀gbàrá ìgbà òtútù ń ṣàn lọ sínú òkun, síbẹ̀síbẹ̀ òkun kò kún. Ibi tí àwọn ọ̀gbàrá ìgbà òtútù ti ń ṣàn jáde lọ, ibẹ̀ ni wọ́n ń padà sí, kí wọ́n bàa lè ṣàn jáde lọ.” Jèhófà nìkan ṣoṣo ló lè ṣẹ̀dá ìyípoyípo omi yẹn.
13. Ẹ̀rí wo ni a rí látinú àwọn ewéko àti ilẹ̀ ayé nípa bí agbára Ẹlẹ́dàá ṣe tó?
13 Kò síbi tí a bá ti rí ohun alààyè tá ò ní rí agbára Ẹlẹ́dàá níbẹ̀. Agbára ìṣẹ̀dá tí Jèhófà ní máa ń hàn kedere lára ohun tó ń pèsè ọ̀pọ̀ jù lọ afẹ́fẹ́ ọ́síjìn tí à ń mí sínú, èyí sì bẹ̀rẹ̀ látorí àwọn igi pupa tí à ń pè ní sẹ̀kóà tó máa ń ga ju ilé tó ní ọgbọ̀n àjà lọ títí dórí ewéko tín-tìn-tín tó kún inú òkun. Ilẹ̀yílẹ̀ gan-an kún fún ohun alààyè irú bí àwọn kòkòrò, olú àti àwọn nǹkan tín-tìn-tín mìíràn, gbogbo wọn sì jùmọ̀ ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ lọ́nà tó díjú láti mú kí àwọn ewéko máa hù. Ìdí nìyẹn tí ohun tí Bíbélì sọ, pé ilẹ̀ ní agbára, ṣe bá a mu.—Jẹ́nẹ́sísì 4:12.
14. Yaágbó-yaájù agbára wo ní ń bẹ nínú átọ́ọ̀mù bíńtín kan?
14 Láìsí àní-àní, Jèhófà ni “Olùṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé nípasẹ̀ agbára rẹ̀.” (Jeremáyà 10:12) Agbára Ọlọ́run hàn kedere nínú àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ tó kéré jù lọ pàápàá. Bí àpẹẹrẹ, bí wọ́n bá to àádọ́ta ọ̀kẹ́ kinní kan bíńtín tí à ń pè ní átọ́ọ̀mù jọ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́, gbogbo rẹ̀ ò lè tó fọ́nrán irun orí wa kan ṣoṣo. Àní bí a bá tiẹ̀ fi awò tó lè mú kí átọ́ọ̀mù kan ga tó ilé alájà mẹ́rìnlá wò ó, ilé agbára inú átọ́ọ̀mù yìí kò lè ju egunrín iyọ̀ lásán lọ láàárín rẹ̀. Síbẹ̀, ilé agbára rẹ̀ bíńtín yìí ló máa ń mú agbára bọ́ǹbù átọ́míìkì ọ̀gbálẹ̀gbáràwé jáde!
“Gbogbo Ohun Eléèémí”
15. Bí Jèhófà ṣe sọ̀rọ̀ nípa onírúurú ẹranko ìgbẹ́, ẹ̀kọ́ wo ló fi kọ́ Jóòbù?
15 Ẹ̀rí mìíràn tó tún fi agbára ìṣẹ̀dá tí Jèhófà ní hàn kedere ni bí ohun alààyè ṣe kún orí ilẹ̀ ayé yìí pìtìmù. Sáàmù 148 mẹ́nu kan ọ̀pọ̀ nǹkan tó ń yin Jèhófà, ẹsẹ ìkẹwàá sì fi ‘àwọn ẹranko ìgbẹ́ àti gbogbo àwọn ẹran agbéléjẹ̀’ kún wọn. Jèhófà fìgbà kan sọ fún Jóòbù nípa irú ẹranko bíi kìnnìún, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà, akọ màlúù ìgbẹ́, Béhémótì (tàbí, erinmi) àti Léfíátánì (ìyẹn ọ̀nì) láti jẹ́ kó rí ìdí tó fi yẹ kéèyàn bẹ̀rù Ẹlẹ́dàá. Kí ni Jèhófà fẹ́ tipa bẹ́ẹ̀ fà yọ? Òun ni pé, béèyàn bá ń bẹ̀rù àwọn ẹ̀dá alágbára tó bani lẹ́rù tí kò sì ṣeé mú sìn wọ̀nyí, irú ojú wo ló yẹ ká máa fi wo Ẹlẹ́dàá wọn?—Jóòbù orí 38 sí 41.
16. Kí ló wù ọ́ nípa àwọn kan nínú ẹyẹ tí Jèhófà dá?
16 Sáàmù 148:10 tún mẹ́nu kan ‘àwọn ẹyẹ’ pẹ̀lú. Ìwọ wò ó bí wọ́n ṣe pọ̀ lóríṣiríṣi tó! Jèhófà sọ̀rọ̀ ògòǹgò fún Jóòbù pé “ó ń fi ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún rẹ́rìn-ín.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹyẹ yìí ga tó ilé, tí kò sì lè fò, ó máa ń sá eré kìlómítà márùnlélọ́gọ́ta ní wákàtí kan, kódà ìṣísẹ̀ rẹ̀ kan ṣoṣo lásán tó mítà mẹ́rin ààbọ̀! (Jóòbù 39:13, 18) Ní ti ẹyẹ albatross, inú afẹ́fẹ́ ojú òkun ló ti ń lo èyí tó pọ̀ jù nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Ẹyẹ aràbàbà lòun ní tiẹ̀, ìyẹ́ apá rẹ̀ sí gùn tó mítà mẹ́ta. Ó lè máa fi ọ̀pọ̀ wákàtí rà bàbà láìju ìyẹ́ apá rẹ̀ rárá. Ẹyẹ akùnyùnmù yàtọ̀ sí èyí ní tiẹ̀. Kò ju béńbé báyìí lọ, òun sì ni ẹyẹ tó kéré jù lọ láyé yìí. Ó lè ju ìyẹ́ apá rẹ̀ ní ìwọ̀n ọgọ́rin ìgbà ní ìṣẹ́jú àáyá kan ṣoṣo! Àwọn ẹyẹ akùnyùnmù tó máa ń dán gbinrin bí òkúta olówó iyebíye yìí, lè dúró sójú kan nínú afẹ́fẹ́ gẹ́lẹ́ bí hẹlikóbítà ṣe máa ń ṣe, kódà ó tiẹ̀ lè fo àfòsẹ́yìn pàápàá.
17. Báwo ni ẹranmi àbùùbùtán títóbi ṣe tóbi tó, kí ló sì yẹ kó tinú ọkàn wa wá tá a bá ronú nípa àwọn ẹranko tí Jèhófà dá?
17 Sáàmù 148:7 sọ pé “ẹran ńlá abàmì inú òkun” pàápàá ń yin Jèhófà. Tiẹ̀ wo ẹranmi àbùùbùtán títóbi ná, èyí tí àwọn kan gbà pé ó tóbi jù lọ nínú gbogbo ẹran ńlá tó tíì gbé ilé ayé yìí rí. Ẹran ńlá fàkìà-fakia tó ń gbé inú òkun yìí máa ń gùn tó ọgbọ̀n mítà tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó lè wọ̀n tó àpapọ̀ ìwọ̀n ọgbọ̀n erin. Ìwọ̀n ahọ́n rẹ̀ lásán tó ìwọ̀n odindi erin kan. Ohun tó fi ṣe ọkàn tóbi tó ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kékeré kan. Ọkàn rẹ̀ yìí kì í lù kìkì ju ẹ̀ẹ̀mẹsàn-án lọ ní ìṣẹ́jú kan, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọkàn ẹyẹ akùnyùnmù máa ń lù kìkì tó ẹgbẹ̀fà [1,200] ìgbà ní ìṣẹ́jú kan ní tirẹ̀. Ó kéré tán, ọ̀kan nínú iṣan ẹ̀jẹ̀ ẹranmi àbùùbùtán títóbi yìí fẹ̀ tó èyí tí ọmọ kékeré fi lè rá kòrò gba inú rẹ̀ kọjá. Nítorí náà, ó dájú pé tinútinú la ó fi tún ọ̀rọ̀ ìgbaniníyànjú tó parí ìwé Sáàmù sọ, èyí tó sọ pé: “Gbogbo ohun eléèémí—kí ó yin Jáà.”—Sáàmù 150:6.
Kíkẹ́kọ̀ọ́ Látinú Agbára Ìṣẹ̀dá Tí Jèhófà Ní
18, 19. Báwo ni oríṣiríṣi ohun alààyè tí Jèhófà dá sórí ilẹ̀ ayé yìí ṣe pọ̀ tó, kí sì ni ìṣẹ̀dá kọ́ wa nípa ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run?
18 Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú agbára ìṣẹ̀dá tí Jèhófà ní? Bí onírúurú nǹkan tí Ọlọ́run dá ṣe pọ̀ yanturu mú kí ẹ̀rù Ọlọ́run bani. Onísáàmù sọ̀rọ̀ tìyanutìyanu pé: “Àwọn iṣẹ́ rẹ mà pọ̀ o, Jèhófà! . . . Ilẹ̀ ayé kún fún àmújáde rẹ.” (Sáàmù 104:24) Òdodo ọ̀rọ̀ gan-an nìyẹn! Àwọn onímọ̀ nípa ohun alààyè sọ pé ó ju mílíọ̀nù kan oríṣiríṣi ọ̀wọ́ àwọn ohun alààyè tí àwọn mọ̀ pé ó ń bẹ nínú ayé yìí; àmọ́, ẹnu wọn kò tíì kò lórí èyí pàápàá, nítorí àwọn kan sọ pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n tó mílíọ̀nù mẹ́wàá, òmíràn ní ọgbọ̀n mílíọ̀nù tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni. Nígbà mìíràn ọmọ aráyé oníṣẹ́ ọnà máa ń rí i pé òun ti pa gbogbo itú tóun mọ̀ pé wọ́n ń fi ọnà pa tán pátá, òun ò tún rí nǹkan tuntun ṣe mọ́. Àmọ́ ní ti Jèhófà, agbára tirẹ̀ láti ronú kí ó sì ṣẹ̀dá onírúurú nǹkan yàtọ̀, kò lè pa itú ọwọ́ rẹ̀ tán láé ní tirẹ̀.
19 Agbára ìṣẹ̀dá tí Jèhófà ní kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ nípa ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run. Jíjẹ́ tí Jèhófà jẹ́ “Ẹlẹ́dàá” mú kó yàtọ̀ pátápátá sí gbogbo nǹkan yòókù tí ń bẹ láyé àtọ̀run nítorí pé òun ló “ṣẹ̀dá” wọn. Kódà Bíbélì kò pe Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Jèhófà, tó jẹ́ pé ó jẹ́ “àgbà òṣìṣẹ́” fún Ọlọ́run nígbà ìṣẹ̀dá, ní Ẹlẹ́dàá tàbí alájọjẹ́-Ẹlẹ́dàá rárá. (Òwe 8:30; Mátíù 19:4) Kàkà bẹ́ẹ̀, òun ló jẹ́ “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá.” (Kólósè 1:15) Jíjẹ́ tí Jèhófà jẹ́ Ẹlẹ́dàá mú kó ní gbogbo ẹ̀tọ́ pátápátá láti máa nìkan lo ipò ọba aláṣẹ lórí ayé àtọ̀run.—Róòmù 1:20; Ìṣípayá 4:11.
20. Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń sinmi láti ìgbà tó ti parí iṣẹ́ ìṣẹ̀dá rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé?
20 Ṣé Jèhófà ti wá ṣíwọ́ lílo agbára rẹ̀ láti ṣẹ̀dá àwọn nǹkan? Òótọ́ ni pé Bíbélì sọ pé nígbà tí Jèhófà parí iṣẹ́ ìṣẹ̀dá rẹ̀ ní ọjọ́ ìṣẹ̀dá kẹfà, ó “bẹ̀rẹ̀ sí sinmi ní ọjọ́ keje kúrò nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ti ṣe.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:2) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi hàn pé “ọjọ́” keje yìí gùn tó ẹgbẹẹgbẹ̀r bún ọdún, nítorí ó ní ó ṣì ń bá a lọ láyé ìgbà tòun. (Hébérù 4:3-6) Ṣùgbọ́n ṣé sísinmi tó “sinmi” yìí wá túmọ̀ sí pé Jèhófà kúkú dáwọ́ iṣẹ́ dúró pátápátá ni? Rárá o, Jèhófà kò dáwọ́ iṣẹ́ dúró o. (Sáàmù 92:4; Jòhánù 5:17) Èyí fi hàn pé sísinmi tó sinmi ni pé ó ṣíwọ́ dídá àwọn nǹkan sórí ilẹ̀ ayé yìí. Àmọ́ kò dáwọ́ iṣẹ́ lórí rírí i pé àwọn ète òun ní ìmúṣẹ dúró rárá. Ara iṣẹ́ yẹn ni mímí tó mí sí Ìwé Mímọ́. Iṣẹ́ rẹ̀ tiẹ̀ kan iṣẹ́ pípèsè “ìṣẹ̀dá tuntun” èyí tí a máa ṣàlàyé nípa rẹ̀ ní Orí 19.—2 Kọ́ríńtì 5:17.
21. Ipa wo ni agbára ìṣẹ̀dá tí Jèhófà ní yóò máa ní lórí àwọn olóòótọ́ èèyàn títí ayé?
21 Tí ọjọ́ ìsinmi Jèhófà bá wá parí níkẹyìn, yóò lè wá sọ pé gbogbo iṣẹ́ tí òun ti ń ṣe lórí ilẹ̀ ayé “dára gan-an ni,” gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe nígbà ìparí ọjọ́ mẹ́fà tó fi ṣe iṣẹ́ ìṣẹ̀dá. (Jẹ́nẹ́sísì 1:31) A ò tíì mọ ọ̀nà tí yóò gbà máa lo agbára rẹ̀ tí kò lópin láti fi ṣẹ̀dá nǹkan nígbà yẹn. Àmọ́ ṣá, kí ó dá wa lójú pé ọ̀nà tí Jèhófà yóò máa gbà lo agbára ìṣẹ̀dá tí ó ní kò ní ṣàì máa bá a lọ láti wú wa lórí. Títí ayérayé ni àwọn ohun tí Jèhófà dá yóò máa kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́. (Oníwàásù 3:11) Bí ẹ̀kọ́ wa nípa Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá bá ṣe ń jinlẹ̀ sí i tó bẹ́ẹ̀ la óò ṣe túbọ̀ gbà pé ó tóbi lọ́ba tó, èyí á sì mú ká túbọ̀ sún mọ́ ọn.
a Láti mọ bí iye kìlómítà tá a wí yìí ṣe jìnnà tó, gba èyí yẹ̀ wò: Tó bá jẹ́ pé ọkọ̀ lèèyàn fẹ́ gbé lọ sọ́hùn, bó bá tiẹ̀ ń sáré níwọ̀n ọgọ́jọ kìlómítà ní wákàtí kan fún odindi wákàtí mẹ́rìnlélógún lójúmọ́ láìdúró rárá, yóò lò ju ọgọ́rùn-ún ọdún lọ lórí ìrìn kó tó lè dé ọ̀hún!
b Àwọn kan rò pè ó ṣeé ṣe kí àwọn tó ń gbé láyé ìgbà tí à ń kọ Bíbélì ní awò àtijọ́ kan tí wọ́n ń lò. Wọ́n ní láìjẹ́ bẹ́ẹ̀, báwo ni irú àwọn èèyàn ìgbà yẹn ṣe wá mọ̀ pé ọ̀kẹ́ àìmọye ìràwọ̀ ló wà? Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé àwọn tó ń sọ irú ọ̀rọ̀ tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ bẹ́ẹ̀ kì í ro ti Jèhófà mọ́ ọn, wọn kì í rántí pé òun ni Orísun ọ̀rọ̀ inú Bíbélì.—2 Tímótì 3:16.
c Ronú nípa bó ṣe máa pẹ́ tó kó o tó ka iye ìràwọ̀ tó jẹ́ ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù tán. Jẹ́ ká sọ pé ó ṣeé ṣe fún ọ láti máa ka ìràwọ̀ kan ní ìṣẹ́jú àáyá kọ̀ọ̀kan, kó o sì máa kà á lọ bẹ́ẹ̀ fún wákàtí mẹ́rìnlélógún láìdánudúró, yóò gbà ọ́ ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé mọ́kànléláàádọ́sàn-án [3,171] ọdún kó o tó kà á tán!