Ní Ojúlówó Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀
“Àwọn onírẹ̀lẹ̀ ni ìwọ yóò . . . gbà là.”—2 SÁMÚẸ́LÌ 22:28.
1, 2. Kí lohun tí ọ̀pọ̀ àwọn alákòóso ayé fi jọra?
ÀWỌN òkìtì aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ tó wà nílẹ̀ Íjíbítì jẹ́ káwọn èèyàn mọ àwọn tó ṣàkóso ilẹ̀ náà láyé àtijọ́. Àwọn mìíràn tí wọ́n ti ṣe ohun mánigbàgbé nínú ìtàn làwọn bíi Senakéríbù ọba Ásíríà, Alẹkisáńdà Ńlá alákòóso ilẹ̀ Gíríìsì àti Júlíọ́sì Késárì alákòóso ilẹ̀ Róòmù. Ohun kan wà tí gbogbo àwọn alákòóso wọ̀nyí fi jọra. Ohun náà ni pé wọn kò ní ojúlówó ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀.—Mátíù 20:25, 26.
2 Ǹjẹ́ o rò pé èyíkéyìí lára àwọn alákòóso tá a dárúkọ yìí lè máa wá àwọn aráàlú tó ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ kiri láti tù wọ́n nínú? Rárá o! Bẹ́ẹ̀ ni wọn ò ní lọ sílé àwọn tálákà láti lọ fún wọn níṣìírí. Ẹ ò rí i pé ìwà tí wọ́n ń hù sáwọn gbáàtúù èèyàn yàtọ̀ pátápátá sí ti Jèhófà Ọlọ́run, Alákòóso Tó Ga Jù Lọ láyé àti lọ́run!
Ẹni Tí Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Rẹ̀ Ga Jù Lọ
3. Báwo ni Alákòóso Tó Ga Jù Lọ ṣe ń ṣe sáwọn èèyàn tó ń sìn ín?
3 Atóbilọ́lá àti ọ̀gá ògo ni Jèhófà, síbẹ̀ “ojú rẹ̀ ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” (2 Kíróníkà 16:9) Kí ni Jèhófà máa ń ṣe nígbà tó bá rí i tí àwọn olùjọsìn rẹ̀ táwọn èèyàn kò fi bẹ́ẹ̀ kà sí bá rẹ̀wẹ̀sì nítorí onírúurú ìṣòro? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà “ń gbé” pẹ̀lú irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, èyí tó túmọ̀ sí pé ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ wà pẹ̀lú wọn nígbà gbogbo “láti mú ẹ̀mí àwọn ẹni rírẹlẹ̀ sọ jí àti láti mú ọkàn-àyà àwọn tí a tẹ̀ rẹ́ sọ jí.” (Aísáyà 57:15) Ìyẹn ló máa jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fáwọn olùjọsìn rẹ̀ tó ti fún lókun láti tún bẹ̀rẹ̀ sí fi ìdùnnú sìn ín. Ọlọ́run mà ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ o!
4, 5. (a) Kí lèrò onísáàmù nípa ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń ṣàkóso? (b) Kí ló túmọ̀ sí tá a bá sọ pé Ọlọ́run “ń rẹ ara rẹ̀ wálẹ̀” kó lè ran “àwọn ẹni rírẹlẹ̀” lọ́wọ́?
4 Kò tún sẹ́lòmíì láyé àti lọ́run tó tíì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ nítorí àtiran aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́ bíi ti Olúwa Ọba Aláṣẹ. Abájọ tí onísáàmù fi kọ̀wé pé: “Jèhófà ga lékè gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; ògo rẹ̀ lékè ọ̀run. Ta ní dà bí Jèhófà Ọlọ́run wa, ẹni tí ó fi ibi gíga lókè ṣe ibùgbé rẹ̀? Ó ń rẹ ara rẹ̀ wálẹ̀ láti wo ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, ó ń gbé ẹni rírẹlẹ̀ dìde àní láti inú ekuru; ó ń gbé òtòṣì ga àní láti inú kòtò eérú.”—Sáàmù 113:4-7.
5 Jèhófà Ọlọ́run ò lè ní ẹ̀mí ìgbéraga nítorí pé ẹni mímọ́ ni kò sì lẹ́mìí “ìrera” rárá. (Máàkù 7:22, 23) Gbólóhùn náà ‘rẹ ara ẹni wálẹ̀’ lè túmọ̀ sí pé ẹnì kan tó wà ní ipò gíga rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ kó lè bá ẹnì kan tó rẹlẹ̀ sí i ní àjọṣe. Ó mà dára o bí Sáàmù 113:6 ṣe jẹ́ kó ṣe kedere pé Ọlọ́run wa onírẹ̀lẹ̀ ń fi ìfẹ́ gbọ́ tàwọn ẹ̀dá aláìpé tí wọ́n ń sìn ín!—2 Sámúẹ́lì 22:36.
Ìdí Tí Jésù Fi Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀
6. Kí ni ọ̀nà tó ga jù lọ tí Jèhófà gbà fi ìrẹ̀lẹ̀ hàn?
6 Ọ̀nà tó ga jù lọ tí Ọlọ́run gbà fi ìrẹ̀lẹ̀ àti ìfẹ́ hàn ni pé ó rán Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n wá sáyé káwọn òbí tó jẹ́ ẹ̀dá èèyàn lè bí i kí wọ́n sì tọ́ ọ dàgbà láti gba aráyé là. (Jòhánù 3:16) Jésù kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ òtítọ́ nípa Baba rẹ̀ ọ̀run, òun tó jẹ́ ẹni pípé sì fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ kó bàa lè “kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ.” (Jòhánù 1:29; 18:37) Jésù fìwà jọ Baba rẹ̀ láìkù síbì kan, àní ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ bíi ti Jèhófà, ìyẹn ló ṣe fi tinútinú ṣe ohun tí Ọlọ́run ní kó ṣe. Èyí ni ọ̀nà tó ga jù lọ tí ìṣẹ̀dá Ọlọ́run èyíkéyìí tíì gbà fi ìrẹ̀lẹ̀ àti ìfẹ́ hàn. Kì í ṣe gbogbo èèyàn ló mọyì ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ Jésù, kódà “ẹni rírẹlẹ̀ jù lọ nínú aráyé” làwọn ọ̀tá rẹ̀ kà á sí, tó túmọ̀ sí pé kò já mọ́ nǹkan kan lójú wọn. (Dáníẹ́lì 4:17) Síbẹ̀, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé ó yẹ káwọn onígbàgbọ́ bíi tòun tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù kí wọ́n lè máa hùwà ìrẹ̀lẹ̀ sáwọn ẹlòmíràn.— 1 Kọ́ríńtì 11:1; Fílípì 2:3, 4.
7, 8. (a) Báwo ni Jésù ṣe dẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀? (b) Kí ni Jésù sọ fáwọn tó rí pé wọ́n lè di ọmọ ẹ̀yìn òun?
7 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń ṣàpèjúwe ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ Jésù tó ta ti ẹnikẹ́ni yọ, ó kọ̀wé pé: “Ẹ pa ẹ̀mí ìrònú yìí mọ́ nínú yín, èyí tí ó wà nínú Kristi Jésù pẹ̀lú, ẹni tí ó jẹ́ pé, bí ó tilẹ̀ wà ní ìrísí Ọlọ́run, kò ronú rárá nípa ìjá-nǹkan-gbà, èyíinì ni, pé kí òun bá Ọlọ́run dọ́gba. Ó tì o, ṣùgbọ́n ó sọ ara rẹ̀ di òfìfo, ó sì gbé ìrísí ẹrú wọ̀, ó sì wá wà ní ìrí ènìyàn. Ju èyíinì lọ, nígbà tí ó rí ara rẹ̀ ní àwọ̀ ènìyàn, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di onígbọràn títí dé ikú, bẹ́ẹ̀ ni, ikú lórí òpó igi oró.”—Fílípì 2:5-8.
8 Àwọn kan lè máa béèrè pé, ‘Báwo ni Jésù ṣe dẹni tó ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀?’ Ohun tó jẹ́ kó láǹfààní gíga lọ́lá yẹn ni pé àìlóǹkà ọdún ló fi wà lọ́dọ̀ọ́ Baba rẹ̀ ọ̀run, òun sì ni “àgbà òṣìṣẹ́” lákòókò tí Ọlọ́run ń dá gbogbo nǹkan. (Òwe 8:30) Nígbà táwọn òbí wa àkọ́kọ́ ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run ní ọgbà Édẹ́nì, Àkọ́bí Ọlọ́run yìí rí bí Baba rẹ̀ ṣe ń fi ìrẹ̀lẹ̀ bá àwọn ẹ̀dá èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ lò. Abájọ tó fi jẹ́ pé nígbà tó wà láyé, ó ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ bíi ti Baba rẹ̀. Jésù sọ pé: “Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín.”—Mátíù 11:29; Jòhánù 14:9.
9. (a) Kí nìdí tí Jésù fi fẹ́ràn àwọn ọmọdé? (b) Ẹ̀kọ́ wo ni Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nígbà tó mú ọmọdé kan wá síwájú wọn?
9 Àwọn ọmọdé kì í bẹ̀rù àtisúnmọ́ Jésù torí pé ojúlówó ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ni Jésù ní. Ńṣe ni wọ́n máa ń rọ̀gbà yí i ká. Òun náà nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọdé gan-an, kì í sì í fi ọ̀rọ̀ wọn ṣeré rárá. (Máàkù 10:13-16) Kí nìdí tí Jésù fi fẹ́ràn àwọn ọmọdé gan-an? Ìdí tó fi fẹ́ràn wọn ni pé wọ́n máa ń hu àwọn ìwà àtàtà táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó ti dàgbà kì í hù lọ́pọ̀ ìgbà. Kò sẹ́ni tí kò mọ̀ pé àwọn ọmọdé gbà pé àwọn àgbàlagbà mọ nǹkan ju àwọn lọ. Ọ̀pọ̀ ìbéèrè tí wọ́n máa ń béèrè jẹ́ ká mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí. Ká sòótọ́, ó rọrùn gan-an láti kọ́ àwọn ọmọdé lẹ́kọ̀ọ́ ju ọ̀pọ̀lọpọ̀ àgbàlagbà lọ, wọ́n kì í sì í gbéra ga bíi tàwọn àgbàlagbà. Nígbà kan, Jésù mú ọmọ kékeré kan wá síwájú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ó wá sọ fún wọn pé: “Láìjẹ́ pé ẹ yí padà, kí ẹ sì dà bí àwọn ọmọ kéékèèké, ẹ kì yóò wọ ìjọba ọ̀run lọ́nàkọnà.” Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ bí ọmọ kékeré yìí ni ẹni tí ó tóbi jù lọ nínú ìjọba ọ̀run.” (Mátíù 18:3, 4) Jésù wá sọ ọ̀rọ̀ pàtàkì kan tó yẹ ká máa fi sọ́kàn, ó ní: “Nítorí olúkúlùkù ẹni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a ó rẹ̀ sílẹ̀ àti ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óò gbé ga.”—Lúùkù 14:11; 18:14; Mátíù 23:12.
10. Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò?
10 Ọ̀rọ̀ pàtàkì tí Jésù sọ yìí lè gbé àwọn ìbéèrè kan wá sọ́kàn wa. Níwọ̀n bí ojúlówó ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ti wà lára ohun tó yẹ ká ní ká tó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun, kí wá nìdí tí kì í fi í rọrùn fáwa Kristẹni láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ nígbà míì? Kí nìdí tó fi máa ń nira fún wa láti rẹ ara wa sílẹ̀ ká lè fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ yanjú ìṣòro wa? Kí ló sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ojúlówó ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀?—Jákọ́bù 4:6, 10.
Ìdí Tí Kò Fi Rọrùn Láti Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀
11. Kí nìdí tí kì í fi ṣe ohun ìyàlẹ́nu pé kì í rọrùn fún wa láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?
11 Tó bá ṣòro fún ọ láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, má ṣe rò pé ìwọ nìkan lo níṣòro yẹn. Lọ́dún 1920, ìyẹn nǹkan bí ọgọ́rin ọdún sẹ́yìn, Ilé Ìṣọ́ [Gẹ̀ẹ́sì] sọ̀rọ̀ lórí ìmọ̀ràn tí Bíbélì gba àwa Kristẹni pé ó yẹ ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Ó ṣàlàyé pé: “Ní báyìí tá a ti wá rí i pé ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ṣe pàtàkì gan-an lójú Olúwa, ó yẹ kí gbogbo àwa ọmọ ẹ̀yìn tòótọ́ sapá láti máa fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn lójoojúmọ́.” Ìwé ìròyìn náà wá sọ òkodoro òtítọ́ kan, ó ní: “Pẹ̀lú gbogbo ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ yìí, àìpé ẹ̀dá lágbára débi pé àwọn tó ti di ìránṣẹ́ Olúwa tí wọ́n sì ti jẹ́jẹ̀ẹ́ pé àwọn fẹ́ máa tẹ̀ lé Olúwa máa ń ní ìṣòro tó bá dọ̀rọ̀ jíjẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Àní, àfàìmọ̀ ni ò jẹ́ pé ìwà ìrẹ̀lẹ̀ nira fún wọn láti ní ju gbogbo àwọn ìwà mìíràn lọ.” Èyí jẹ́ ká rí ìdí kan táwa Kristẹni tòótọ́ fi ní láti máa sapá ká lè jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Ìdí náà sì ni pé àwa ẹ̀dá èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ máa ń fẹ́ ògo fún ara wa. Ohun tó fa èyí ni pé a jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà, tọkọtaya ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n hùwà ìmọtara-ẹni-nìkan.—Róòmù 5:12.
12, 13. (a) Báwo ni ayé yìí ṣe ń mú kó ṣòro fún àwa Kristẹni láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀? (b) Ta ni kò jẹ́ kó rọrùn fún wa láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?
12 Ìdí mìíràn tí kò fi rọrùn láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ni pé ẹ̀mí tí ayé yìí ń gbìn sọ́kàn àwọn èèyàn ni pé kí wọ́n làkàkà láti ta àwọn mìíràn yọ, ìwà yìí sì lè ràn wá. Ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn èèyàn máa ń fojoojúmọ́ ayé lépa, lára nǹkan ọ̀hún sì ni “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara [ẹlẹ́ṣẹ̀] àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími.” (1 Jòhánù 2:16) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ táráyé ń lé gbà wọ́n lọ́kàn, kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n ní láti jẹ́ kí ojú wọn mú ọ̀nà kan kí wọ́n sì rí i pé ìfẹ́ Ọlọ́run làwọn ń ṣe nígbà gbogbo.—Mátíù 6:22-24, 31-33; 1 Jòhánù 2:17.
13 Ìdí kẹta tí kò fi rọrùn láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ni pé Sátánì Èṣù tó jẹ́ pé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìrera ti bẹ̀rẹ̀ ló ń ṣàkóso ayé. (2 Kọ́ríńtì 4:4; 1 Tímótì 3:6) Sátánì máa ń lo onírúurú ọ̀nà láti gbin ìwà búburú sọ́kàn àwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, ó fẹ́ kí Jésù jọ́sìn òun kí òun sì fún un ní “gbogbo ìjọba ayé àti ògo wọn.” Ṣùgbọ́n nítorí pé onírẹ̀lẹ̀ ni Jésù, ńṣe ló kọ̀ jálẹ̀, kò sì gbà fún Èṣù rárá. (Mátíù 4:8, 10) Bákan náà lónìí, Sátánì máa ń fẹ́ mú káwa Kristẹni wá ògo fún ara wa. Àmọ́, àpẹẹrẹ Jésù Kristi làwọn Kristẹni tí wọ́n lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ máa ń gbìyànjú láti tẹ̀ lé, wọ́n máa ń fi ìyìn àti ògo fún Ọlọ́run.—Máàkù 10:17, 18.
Bí A Ṣe Lè Ní Ojúlówó Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀
14. Kí ni “ìrẹ̀lẹ̀ ẹlẹ́yà”?
14 Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Kólósè, ó kìlọ̀ fún wọn pé wọn kò gbọ́dọ̀ máa ṣojú ayé, kí wọ́n máa ṣe bíi pé àwọn ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ torí káwọn èèyàn lè máa yìn wọ́n. Pọ́ọ̀lù pe irú ìwà yìí ní “ìrẹ̀lẹ̀ ẹlẹ́yà.” Àwọn tó bá ń hùwà ìrẹ̀lẹ̀ ojú ayé kì í ṣe ẹni tẹ̀mí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí ìwà wọn ń fi hàn gan-an ni pé ìgbéraga ló ń mú wọn “wú fùkẹ̀.” (Kólósè 2:18, 23) Jésù fún wa ní àpẹẹrẹ irú ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tí kò dénú bẹ́ẹ̀. Ó bẹnu àtẹ́ lu àwọn Farisí nítorí àdúrà ṣekárími tí wọ́n máa ń gbà àti nítorí bí wọ́n ṣe máa ń bojú jẹ́ tí wọ́n bá ń gbààwẹ̀ káwọn èèyàn lè rí wọn. Nítorí náà, kí àdúrà wa tó lè gbà a gbọ́dọ̀ fi ìrẹ̀lẹ̀ gbà á.—Mátíù 6:5, 6, 16.
15. (a) Kí la lè ṣe tá a bá fẹ́ ní ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú? (b) Àwọn àpẹẹrẹ rere wo la lè tẹ̀ lé tá a bá fẹ́ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?
15 Bí àwa Kristẹni bá ń ronú jinlẹ̀ lórí àpẹẹrẹ Jèhófà Ọlọ́run àti ti Jésù Kristi, àwọn ẹni tí àpẹẹrẹ ìrẹ̀lẹ̀ wọn ga jù lọ, èyí lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ojúlówó ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Ká bàa lè fìwà jọ wọ́n, a ní láti máa kẹ́kọ̀ọ́ déédéé nínú Bíbélì àtàwọn ìwé tó ń jẹ́ ká lóye Bíbélì tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń tẹ̀ jáde. (Mátíù 24:45) Irú ẹ̀kọ́ báyìí ṣe pàtàkì gan-an fáwọn alábòójútó nínú ìjọ, “kí ọkàn-àyà [wọn] má bàa gbé ara rẹ̀ ga lórí àwọn arákùnrin [wọn].” (Diutarónómì 17:19, 20; 1 Pétérù 5:1-3) Ronú nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí Ọlọ́run bù kún nítorí pé wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, irú bíi Rúùtù, Hánà, Èlísábẹ́tì àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn. (Rúùtù 1:16, 17; 1 Sámúẹ́lì 1:11, 20; Lúùkù 1:41-43) Tún ronú nípa ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àpẹẹrẹ àwọn tó ṣe ohun ribiribi nínú iṣẹ́ Jèhófà ṣùgbọ́n tí wọ́n ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, irú bíi Dáfídì, Jòsáyà, Jòhánù Olùbatisí àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. (2 Kíróníkà 34:1, 2, 19, 26-28; Sáàmù 131:1; Jòhánù 1:26, 27; 3:26-30; Ìṣe 21:20-26; 1 Kọ́ríńtì 15:9) Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tá à ń rí nínú ìjọ Kristẹni lónìí ńkọ́? Tí àwa Kristẹni tòótọ́ bá ń ronú nípa àwọn àpẹẹrẹ rere wọ̀nyí, a ó lè máa fi ‘ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú bá ara wa lò.’—1 Pétérù 5:5.
16. Báwo ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ àwa Kristẹni ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?
16 Ohun mìíràn tó lè jẹ́ ká ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ni pé ká máa jáde òde ẹ̀rí déédéé. Nígbà tá a bá bá àwọn àjèjì pàdé nínú iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé tàbí láwọn ibòmíràn, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ lè jẹ́ ká bá wọn sọ̀rọ̀ bó ṣe yẹ. Èyí ṣe pàtàkì gan-an nígbà táwọn tá a fẹ́ wàásù fún ò bá fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa nígbà tá a kọ́kọ́ dé ọ̀dọ̀ wọn tàbí tí wọ́n fìwọ̀sí lọ̀ wá. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn èèyàn máa ń fẹ́ mọ ìdí tá a fi gba àwọn ohun kan gbọ́, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ló sì lè ran àwa Kristẹni lọ́wọ́ láti máa fi “inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀” dáhùn ìbéèrè wọn. (1 Pétérù 3:15) Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ti mú káwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan ṣí lọ sáwọn àgbègbè mìíràn láti lọ máa wàásù fáwọn èèyàn tí àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ sí tiwọn, àtolówó àti tálákà. Káwọn oníwàásù yìí lè túbọ̀ ṣèrànwọ́ fáwọn tí wọ́n ń wàásù fún, àwọn kan ti sa gbogbo ipá wọn láti kọ́ èdè wọn. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ló sì ń jẹ́ kí wọn lè ṣe èyí. Ohun tí wọ́n ṣe yìí mà dára o!—Mátíù 28:19, 20.
17. Àwọn nǹkan wo làwa Kristẹni ń ṣe tó gba pé ká ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ká tó lè ṣe wọ́n?
17 Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tún ń jẹ́ kí ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ṣe àwọn ojúṣe mìíràn torí kí wọ́n lè fi ire tàwọn ẹlòmíì ṣáájú. Bí àpẹẹrẹ, Kristẹni kan tó jẹ́ bàbá gbọ́dọ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ kó tó lè máa ya díẹ̀ lára àkókò tí ì bá fi gbọ́ ti ara rẹ̀ sọ́tọ̀ láti fi múra ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó máa bá àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe sílẹ̀, kó sì rí i pé òun ń ṣe é dáadáa. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ yóò tún jẹ́ káwọn ọmọ máa bọ̀wọ̀ fáwọn òbí wọn kí wọ́n sì máa gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu bí wọ́n tiẹ̀ jẹ́ aláìpé. (Éfésù 6:1-4) Ọ̀pọ̀ nǹkan ló máa ń ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé àwọn aya tí ọkọ wọn jẹ́ aláìgbàgbọ́ tó gba pé kí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ bí irú àwọn aya bẹ́ẹ̀ ṣe ń sapá láti fi “ìwà mímọ́ [wọn] pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀” ran ọkọ wọn lọ́wọ́ láti mọ òtítọ́. (1 Pétérù 3:1, 2) Síwájú sí i, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ ṣe pàtàkì gan-an tá a bá ń fi ìfẹ́ bójú tó àwọn òbí wa tí wọ́n ń ṣàìsàn tàbí tí wọ́n ti ń darúgbó.—1 Tímótì 5:4.
Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Máa Ń Yanjú Ìṣòro
18. Báwo lẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti yanjú ìṣòro?
18 Aláìpé ni gbogbo àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó wà lórí ilẹ̀ ayé. (Jákọ́bù 3:2) Nígbà míì, èdèkòyédè tàbí aáwọ̀ lè wáyé láàárín àwọn Kristẹni méjì. Ó lè jẹ́ pé lóòótọ́ ni ọ̀kan lára wọn ṣẹ ẹnì kejì. Síbẹ̀, irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ lè yanjú lọ́pọ̀ ìgbà tá a bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe.” (Kólósè 3:13) Òótọ́ ni pé kò rọrùn láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí, àmọ́ ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ á jẹ́ ká fi í sílò.
19. Kí ló yẹ ká máa fi sọ́kàn tá a bá ń bá ẹni tó ṣẹ̀ wá sọ̀rọ̀?
19 Nígbà míì, Kristẹni kan lè rò pé ẹ̀ṣẹ̀ tẹ́nì kan ṣẹ òun ju ohun tí òun lè gbójú fò lọ. Síbẹ̀, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ yóò jẹ́ kó lọ bá ẹni tó sọ pé ó ṣẹ òun náà kí wọ́n lè yanjú ọ̀rọ̀ ọ̀hún. (Mátíù 18:15) Ọ̀kan lára ohun tó lè máà jẹ́ kí aáwọ̀ tètè yanjú láàárín Kristẹni méjì ni pé nígbà míì, ọ̀kan lára wọn tàbí àwọn méjèèjì lè jọ ara wọn lójú débi pé wọn kò ní gbà pé àwọn làwọn jẹ̀bi. Tàbí kẹ̀, ẹni tó lọ bá ẹnì kejì nítorí àtiparí ìjà náà lè jẹ́ olódodo lójú ara rẹ̀, kó máa wá fẹ̀sùn kan ẹnì kejì. Àmọ́ tá a bá ní ojúlówó ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, yóò ràn wá lọ́wọ́ láti yanjú ọ̀pọ̀ ìṣòro.
20, 21. Kí ni ọ̀kan lára àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀?
20 Ohun pàtàkì kan tá a lè ṣe tá a bá fẹ́ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ni pé ká gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́ kó sì fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Àmọ́, má ṣe gbàgbé pé “Ọlọ́run . . . [máa ń] fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí [títí kan ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀] fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.” (Jákọ́bù 4:6) Nítorí náà, bí ìṣòro kan bá wà láàárín ìwọ àti Kristẹni mìíràn, gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè fi ìrẹ̀lẹ̀ gba àṣìṣe èyíkéyìí tó o ṣe, ó kéré ni ó pọ̀ ni. Bó bá jẹ́ pé ìwọ ni wọ́n ṣẹ̀ tí onítọ̀hún sì fi tọkàntọkàn bẹ̀ ọ́, tó ní kó o forí ji òun, jẹ́ kí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ sún ọ láti dárí jì í. Bó bá ṣòro fún ọ láti dárí jì í, gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran ọ́ lọ́wọ́ kó o lè mú ẹ̀mí ìgbéraga èyíkéyìí tó bá ṣì wà lọ́kàn rẹ kúrò.
21 Nígbà tá a ti mọ ọ̀pọ̀ àǹfààní tó wà nínú jíjẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó yẹ kí èyí mú ká ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀. Nítorí náà, á dára gan-an ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà Ọlọ́run àti ti Jésù Kristi ká lè ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀! Ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé ohun tí Ọlọ́run mú dá wa lójú yìí pé: “Ìyọrísí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Jèhófà ni ọrọ̀ àti ògo àti ìyè.”—Òwe 22:4.
Àwọn Kókó Tó Yẹ Ká Ṣàṣàrò Lé Lórí
• Àwọn wo ni àpẹẹrẹ ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ wọn ga jù lọ?
• Kí ló mú kó ṣòro láti ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀?
• Kí làwọn ohun tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?
• Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì gan-an pé ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ojúlówó ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ni Jésù ní
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Ẹ̀mí tí ayé yìí ń gbìn sọ́kàn àwọn èèyàn ni pé kí wọ́n làkàkà láti ta àwọn mìíràn yọ
[Credit Line]
Fọ́tò WHO látọwọ́ L. Almasi/K. Hemzǒ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ń jẹ́ ká lè bá àwọn àjèjì sọ̀rọ̀ lóde ẹ̀rí
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Ọ̀pọ̀ ìṣòro ló máa yanjú bá a bá ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tá a sì fi ìfẹ́ bò wọ́n mọ́lẹ̀
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Onírúurú ọ̀nà làwa Kristẹni lè gbà fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn