Àkọsílẹ̀ Jòhánù
1 Ní ìbẹ̀rẹ̀, Ọ̀rọ̀ náà+ wà, Ọ̀rọ̀ náà sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run,+ Ọ̀rọ̀ náà sì jẹ́ ọlọ́run kan.*+ 2 Ẹni yìí wà pẹ̀lú Ọlọ́run ní ìbẹ̀rẹ̀. 3 Ohun gbogbo wà nípasẹ̀ rẹ̀+ àti pé láìsí i, kò sí nǹkan kan tó wà.
Ohun tó wà 4 nípasẹ̀ rẹ̀ ni ìyè, ìyè náà sì ni ìmọ́lẹ̀ àwọn èèyàn.+ 5 Ìmọ́lẹ̀ náà ń tàn nínú òkùnkùn,+ àmọ́ òkùnkùn náà ò borí rẹ̀.
6 Ọkùnrin kan wà tí a rán láti jẹ́ aṣojú Ọlọ́run; Jòhánù+ ni orúkọ rẹ̀. 7 Ọkùnrin yìí wá gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí, kó lè jẹ́rìí nípa ìmọ́lẹ̀ náà,+ kí onírúurú èèyàn lè gbà gbọ́ nípasẹ̀ rẹ̀. 8 Òun kọ́ ni ìmọ́lẹ̀ yẹn,+ àmọ́ a ṣètò pé kó jẹ́rìí nípa ìmọ́lẹ̀ yẹn.
9 Ìmọ́lẹ̀ tòótọ́ tó ń fún onírúurú èèyàn ní ìmọ́lẹ̀ máa tó wá sí ayé.+ 10 Ó ti wà ní ayé,+ ayé sì wà nípasẹ̀ rẹ̀,+ àmọ́ ayé ò mọ̀ ọ́n. 11 Ó wá sí ilé òun fúnra rẹ̀, àmọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ ò gbà á. 12 Ṣùgbọ́n ó fún gbogbo àwọn tó gbà á ní àṣẹ láti di ọmọ Ọlọ́run,+ torí pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀.+ 13 A ò bí wọn látinú ẹ̀jẹ̀ tàbí látinú ìfẹ́ ti ara tàbí látinú ìfẹ́ èèyàn, àmọ́ a bí wọn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.+
14 Torí náà, Ọ̀rọ̀ náà di ẹlẹ́ran ara,+ ó gbé láàárín wa, a sì rí ògo rẹ̀, irú ògo tó jẹ́ ti ọmọ bíbí kan ṣoṣo+ ti bàbá kan; ó sì kún fún oore Ọlọ́run* àti òtítọ́. 15 (Jòhánù jẹ́rìí nípa rẹ̀, àní, ó ké jáde pé: “Ẹni yìí ni mo sọ nípa rẹ̀ pé, ‘Ẹni tó ń bọ̀ lẹ́yìn mi ti lọ níwájú mi, torí ó ti wà ṣáájú mi.’”)+ 16 Torí látinú ẹ̀kún rẹ̀, àní gbogbo wa gba inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí lórí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí. 17 Torí a fúnni ní Òfin nípasẹ̀ Mósè,+ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí+ àti òtítọ́ wà nípasẹ̀ Jésù Kristi.+ 18 Kò sí èèyàn tó rí Ọlọ́run rí;+ ọlọ́run bíbí kan ṣoṣo+ tó wà ní ẹ̀gbẹ́ Baba*+ ni ẹni tó ṣàlàyé Rẹ̀.+
19 Ẹ̀rí tí Jòhánù jẹ́ nìyí nígbà tí àwọn Júù rán àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì láti Jerúsálẹ́mù kí wọ́n lọ bi í pé: “Ta ni ọ́?”+ 20 Ó sọ òótọ́, kò sì sẹ́, ó ní: “Èmi kọ́ ni Kristi.” 21 Wọ́n bi í pé: “Ta wá ni ọ́? Ṣé ìwọ ni Èlíjà?”+ Ó dáhùn pé: “Èmi kọ́.” “Ṣé ìwọ ni Wòlíì náà?”+ Ó dáhùn pé: “Rárá!” 22 Wọ́n wá sọ fún un pé: “Ta ni ọ́? Sọ fún wa ká lè mọ ohun tí a máa sọ fún àwọn tó rán wa níṣẹ́. Kí lo sọ nípa ara rẹ?” 23 Ó sọ pé: “Èmi ni ohùn ẹni tó ń ké nínú aginjù pé, ‘Ẹ mú ọ̀nà Jèhófà* tọ́,’+ bí wòlíì Àìsáyà ṣe sọ.”+ 24 Àwọn Farisí ló rán àwọn èèyàn yìí. 25 Torí náà, wọ́n bi í pé: “Kí ló dé tí o fi ń ṣe ìrìbọmi fún àwọn èèyàn tí kì í bá ṣe ìwọ ni Kristi tàbí Èlíjà tàbí Wòlíì náà?” 26 Jòhánù dá wọn lóhùn pé: “Omi ni mo fi ń batisí. Ẹnì kan wà láàárín yín tí ẹ kò mọ̀, 27 ẹni tó ń bọ̀ lẹ́yìn mi, ẹni tí mi ò tó tú okùn bàtà rẹ̀.”+ 28 Àwọn nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ ní Bẹ́tánì ní òdìkejì Jọ́dánì, níbi tí Jòhánù ti ń ṣèrìbọmi fún àwọn èèyàn.+
29 Lọ́jọ́ kejì, ó rí i tí Jésù ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀, ó wá sọ pé: “Wò ó, Ọ̀dọ́ Àgùntàn+ Ọlọ́run tó kó ẹ̀ṣẹ̀+ ayé lọ!+ 30 Ẹni yìí ni mo sọ nípa rẹ̀ pé: ‘Ọkùnrin kan ń bọ̀ lẹ́yìn mi, ó ti lọ níwájú mi, torí ó wà ṣáájú mi.’+ 31 Èmi gan-an ò mọ̀ ọ́n, àmọ́ ìdí tí mo fi wá, tí mò ń fi omi batisí ni pé ká lè fi í hàn kedere fún Ísírẹ́lì.”+ 32 Jòhánù náà jẹ́rìí sí i, ó ní: “Mo rí i tí ẹ̀mí ń sọ̀ kalẹ̀ bí àdàbà láti ọ̀run, ó sì bà lé e.+ 33 Èmi gan-an ò mọ̀ ọ́n, àmọ́ Ẹni tó rán mi láti fi omi batisí sọ fún mi pé: ‘Ẹnikẹ́ni tí o bá rí tí ẹ̀mí ń sọ̀ kalẹ̀, tó sì bà lé,+ òun ni ẹni tó ń fi ẹ̀mí mímọ́ batisí.’+ 34 Mo ti rí i, mo sì ti jẹ́rìí pé ẹni yìí ni Ọmọ Ọlọ́run.”+
35 Nígbà tó tún di ọjọ́ kejì, Jòhánù dúró pẹ̀lú méjì lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, 36 bó sì ṣe rí Jésù tó ń rìn lọ, ó sọ pé: “Ẹ wò ó, Ọ̀dọ́ Àgùntàn+ Ọlọ́run!” 37 Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjèèjì gbọ́ ohun tó sọ yìí, wọ́n tẹ̀ lé Jésù. 38 Jésù wá yíjú pa dà, bó sì ṣe rí i pé wọ́n ń tẹ̀ lé òun, ó bi wọ́n pé: “Kí lẹ̀ ń wá?” Wọ́n sọ fún un pé: “Rábì (tó túmọ̀ sí “Olùkọ́”), ibo lò ń gbé?” 39 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bọ̀, kí ẹ wá wò ó.” Wọ́n wá lọ wo ibi tó ń gbé, wọ́n sì dúró sọ́dọ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ yẹn; nǹkan bíi wákàtí kẹwàá ni.* 40 Áńdérù+ arákùnrin Símónì Pétérù wà lára àwọn méjì tó gbọ́ ohun tí Jòhánù sọ, tí wọ́n sì tẹ̀ lé Jésù. 41 Ó kọ́kọ́ wá Símónì arákùnrin rẹ̀, ó sì sọ fún un pé: “A ti rí Mèsáyà náà”+ (tó túmọ̀ sí “Kristi”), 42 ó sì mú un lọ sọ́dọ̀ Jésù. Nígbà tí Jésù wò ó, ó sọ pé: “Ìwọ ni Símónì,+ ọmọ Jòhánù; a ó máa pè ọ́ ní Kéfà” (tó túmọ̀ sí “Pétérù”).+
43 Lọ́jọ́ kejì, ó fẹ́ lọ sí Gálílì. Jésù wá rí Fílípì,+ ó sì sọ fún un pé: “Máa tẹ̀ lé mi.” 44 Bẹtisáídà, ìlú Áńdérù àti Pétérù, ni Fílípì ti wá. 45 Fílípì rí Nàtáníẹ́lì,+ ó sì sọ fún un pé: “A ti rí ẹni tí Mósè, nínú Òfin àti àwọn Wòlíì kọ̀wé nípa rẹ̀ pé: Jésù, ọmọ Jósẹ́fù,+ láti Násárẹ́tì.” 46 Àmọ́ Nàtáníẹ́lì sọ fún un pé: “Ṣé ohun rere kankan lè wá láti Násárẹ́tì?” Fílípì sọ fún un pé: “Wá wò ó.” 47 Jésù rí i tí Nàtáníẹ́lì ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì sọ nípa rẹ̀ pé: “Wò ó, ní tòótọ́, ọmọ Ísírẹ́lì tí ẹ̀tàn kankan ò sí nínú rẹ̀.”+ 48 Nàtáníẹ́lì bi í pé: “Báwo lo ṣe mọ̀ mí?” Jésù dá a lóhùn pé: “Kí Fílípì tó pè ọ́, nígbà tí o wà lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́, ni mo ti rí ọ.” 49 Nàtáníẹ́lì dá a lóhùn pé: “Rábì, ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run, ìwọ ni Ọba Ísírẹ́lì.”+ 50 Jésù sọ fún un pé: “Ṣé torí pé mo sọ fún ọ pé mo rí ọ lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ lo ṣe gbà gbọ́? O máa rí àwọn nǹkan tó tóbi ju ìwọ̀nyí lọ.” 51 Ó wá sọ fún un pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹ máa rí i tí ọ̀run ṣí sílẹ̀, tí àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run ń gòkè, tí wọ́n sì ń sọ̀ kalẹ̀ sọ́dọ̀ Ọmọ èèyàn.”+