“Ta Ni O Dabii Jehofa Ọlọrun Wa?”
“Ta ni o dabii Jehofa Ọlọrun wa, oun ẹni ti o fi ibugbe rẹ̀ si ibi giga?” —ORIN DAFIDI 113:5, NW.
1, 2. (a) Oju wo ni awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi ń wo Ọlọrun ati Bibeli? (b) Awọn ibeere wo ni o yẹ fun igbeyẹwo?
AWỌN oluyin Jehofa jẹ alabukun-fun nitootọ. Ẹ wo iru anfaani ti ó jẹ́ lati wà lara ọpọ eniyan alayọ yii! Gẹgẹ bi awọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀, a tẹwọgba imọran, ofin, ikọni, ileri, ati awọn asọtẹlẹ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli. A layọ lati kẹkọọ lati inu Iwe Mimọ ati lati jẹ́ ẹni ti a ‘ń kọ́ lati ọdọ Ọlọrun.’—Johannu 6:45.
2 Nitori ọ̀wọ̀ wọn jijinlẹ fun Ọlọrun, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa le beere pe: “Ta ni o dabii Jehofa Ọlọrun wa?” (Orin Dafidi 113:5, NW) Awọn ọ̀rọ̀ wọnyẹn tí olorin naa sọ dọgbọn fi igbagbọ hàn. Ṣugbọn eeṣe ti awọn Ẹlẹ́rìí fi ni iru igbagbọ bẹẹ ninu Ọlọrun? Ki si ni idi ti wọn ni fun fifi iyin fun Jehofa?
Igbagbọ ati Iyin Yẹ
3. Ki ni awọn Psalmu Hallel jẹ́, ki si ni idi rẹ̀ ti a fi pe wọn bẹẹ?
3 Igbagbọ ninu Jehofa ni a beere fun nitori pe oun jẹ Ọlọrun alailẹgbẹ. Eyi ni a tẹnumọ ninu Orin Dafidi 113, 114, ati 115, apakan lara awọn Psalmu Hallel mẹfa. Ni ibamu pẹlu Ile-ẹkọ rabbi ti Hillel, Orin Dafidi 113 ati 114 ni a kọ lakooko ounjẹ Irekọja awọn Ju lẹhin ti a bá ti bu ife waini keji ti a si ti ṣalaye ijẹpataki aato akiyesi naa. Orin Dafidi 115 si 118 ni a ń kọ lẹhin ife waini kẹrin. (Fiwe Matteu 26:30.) Awọn ni a ń pe ni “Psalmu Hallel” nitori pe leralera ni wọn lo ọ̀rọ̀ ikede naa Hallelujah!—“Ẹ yin Jah!”
4. Ki ni itumọ èdè-ìsọ̀rọ̀ naa “Hallelujah,” bawo ni o si ṣe farahan leralera tó ninu Bibeli?
4 “Hallelujah!” jẹ ìpalẹ́tà ọ̀rọ̀ Heberu kan ti o farahan ni ìgbà 24 ninu Orin Dafidi dà si omiran. Nibomiran ninu Bibeli, oriṣi rẹ̀ ti o jẹ́ Griki farahan ni ìgbà mẹrin ni isopọ pẹlu ayọ ti a ni iriri rẹ̀ lori iparun Babiloni Nla, ilẹ-ọba isin èké agbaye, ati idunnu ti o sopọ mọ́ ibẹrẹ iṣakoso Jehofa Ọlọrun gẹgẹ bi Ọba. (Ìfihàn 19:1-6) Bi a o ti ṣayẹwo mẹta lara awọn Psalmu Hallel naa nisinsinyi, a tun lè ṣe daradara lati foju-inu wo araawa ti a ń kọ awọn orin wọnyi si iyin Jehofa.
Ẹ Yin Jah!
5. Ibeere wo ni Orin Dafidi 113 dahun, awọn wo ni pataki sì ni àṣẹ ti o wà ni Orin Dafidi 113:1, 2 ṣeefisilo fun?
5 Orin Dafidi 113 dahun ibeere naa, Eeṣe ti a fi nilati yin Jehofa? O bẹrẹ pẹlu àṣẹ naa: “Ẹ yin Jah, ẹyin eniyan! Ẹ fi iyin fun un, Oo ẹyin iranṣẹ Jehofa, ẹ yin orukọ Jehofa. Ǹjẹ́ ki orukọ Jehofa di alabukun-fun lati isinsinyi lọ àní titilọ gbére.” (Orin Dafidi 113:1, 2, NW) “Hallelujah!” Bẹẹni, “Ẹ yin Jah!” Àṣẹ yẹn ni pataki ṣeefisilo fun awọn eniyan Ọlọrun ni “ìgbà ikẹhin” yii. (Danieli 12:4) Lati isinsinyi lọ ati titilae, orukọ Jehofa ni a gbega kari-aye. Awọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ ń pokiki nisinsinyi pe Jehofa ni Ọlọrun, Kristi ni Ọba, ati pe a ti fidi Ijọba naa mulẹ ni ọrun. Satani Eṣu ati eto-ajọ rẹ̀ ko le dí fifi iyin fun Jehofa yii lọwọ.
6. Bawo ni a ṣe ń yin Jehofa ‘lati ila-oorun si iwọ-oorun’?
6 Orin iyin naa yoo maa baa lọ titi ti Jehofa yoo fi mu ki o kari ilẹ̀-ayé. “Lati ila-oorun titi o fi de ìwọ̀ rẹ̀ orukọ Jehofa ni a nilati yìn.” (Orin Dafidi 113:3, NW) Eyi tumọsi ohun ti o ju ijọsin ojoojumọ nipasẹ awọn iṣẹda kan lori ilẹ̀-ayé lọ. Oòrùn ń yọ lati ila-oorun o sì ń wọ̀ ni iwọ-oorun, ni kikari gbogbo ilẹ̀-ayé. Nibigbogbo ni oòrùn ti ń ràn, laipẹ orukọ Jehofa ni a o yin nipasẹ gbogbo eniyan ti a tusilẹ lominira kuro lọwọ isinru si isin èké ati eto-ajọ Satani. Niti tootọ, orin yii tí kì yoo dopin lae ni a ń kọ nisinsinyi lati ẹnu awọn ẹni-ami-ororo Ẹlẹ́rìí Jehofa ati awọn ti yoo di ọmọ ori ilẹ̀-ayé fun Ọba rẹ̀, Jesu Kristi. Ẹ wo iru anfaani ti wọn ni gẹgẹ bi awọn olùkọ orin iyin Jehofa!
Jehofa Jẹ Alailafiwe
7. Awọn apa meji wo ninu ipo-ajulọ ti Jehofa ni a mẹnukan ni pataki ni Orin Dafidi 113:4?
7 Olorin naa fikun un pe: “Jehofa ti ga bori gbogbo awọn orilẹ-ede; ògo rẹ̀ ga ju awọn ọrun lọ.” (Orin Dafidi 113:4, NW) Eyi fun apa meji ninu ipo-ajulọ Ọlọrun ni afiyesi: (1) Si Jehofa, Ẹni Onipo-ajulọ, ti o “ga bori gbogbo awọn orilẹ-ede,” wọn dabi ẹ̀kán omi kan lati inu ládugbó ati bii ekuru lasan lori ìwọ̀n; (Isaiah 40:15; Danieli 7:18) (2) ògo rẹ̀ ga rekọja ti awọn ọrun ti o ṣeefojuri, nitori awọn angẹli ń ṣe ifẹ-inu rẹ ti ó ga julọ.—Orin Dafidi 19:1, 2; 103:20, 21.
8. Eeṣe ati bawo ni Jehofa ṣe ń rẹ araarẹ̀ silẹ lati ṣakiyesi awọn ọ̀ràn ni ọrun ati lori ilẹ̀-ayé?
8 Bi a ti sun un nipasẹ ìgafíofío Ọlọrun, olorin naa sọ pe: “Ta ni o dabii Jehofa Ọlọrun wa, oun ẹni ti o fi ibugbe rẹ̀ si ibi giga? O ń rẹ araarẹ̀ silẹ lati wò ọrun ati ilẹ̀-ayé.” (Orin Dafidi 113:5, 6, NW) Ọlọrun gasoke tobẹẹ ti o fi jẹ pe oun nilati rẹ araarẹ̀ silẹ lati ṣe akiyesi awọn ọ̀ràn ni ọrun ati lori ilẹ̀-ayé. Bi o tilẹ jẹ pe Jehofa ko rẹlẹ ju ẹnikẹni tabi wa ni itẹriba fun awọn ẹlomiran, oun fi irẹlẹ hàn nipa lilo aanu ati ìyọ́nú fun awọn ẹni rirẹlẹ ti wọn jẹ́ ẹlẹṣẹ. Pipese Ọmọkunrin rẹ̀, Jesu Kristi, gẹgẹ bi “etutu” fun awọn Kristian ẹni-ami-ororo ati fun ayé araye jẹ ifihanjade irẹlẹ Jehofa.—1 Johannu 2:1, 2.
Jehofa Jẹ Oníyọ̀ọ́nú
9, 10. Bawo ni Ọlọrun ṣe ‘ń gbe talaka soke, lati jẹ ki o jokoo pẹlu awọn ọ̀tọ̀kùlú’?
9 Ni titẹnumọ ìyọ́nú Ọlọrun, olorin naa fikun un pe Jehofa “ń gbé òtòṣì ga lati inu kòtò-eérú fúnraarẹ̀, lati jẹ ki ó jokoo pẹlu awọn ọ̀tọ̀kùlú, pẹlu awọn ọ̀tọ̀kùlú ninu awọn eniyan rẹ̀. Ó ń mú ki àgàn obinrin gbé ninu ilé gẹgẹ bi ìyá alayọ ti awọn ọmọkunrin. Ẹ yin Jah. ẹyin eniyan!” (Orin Dafidi 113:7-9, NW) Awọn eniyan Jehofa ní igbagbọ pe o le gba awọn aduroṣanṣan ti wọn nilo iranlọwọ là, ki o yí ipo wọn pada, ki o si tẹ́ awọn aini ati ìfẹ́-ọkàn wọn titọna lọ́rùn. ‘Ẹni Giga ati ẹni ti a gbega soke naa ń mu ẹmi awọn onirẹlẹ ati ọkàn awọn onirobinujẹ sọji.’—Isaiah 57:15.
10 Bawo ni Jehofa ṣe ‘ń gbé òtòṣì ga lati jẹ ki o jokoo pẹlu awọn ọ̀tọ̀kùlú’? Nigba ti o ba jẹ ifẹ-inu Ọlọrun, o ń gbé awọn iranṣẹ rẹ̀ si ipo ògo ti o jẹ ọgbọọgba pẹlu ti awọn ọ̀tọ̀kùlú. O ṣe bẹẹ ninu ọ̀ràn ti Josefu, ẹni ti o di oluṣabojuto ounjẹ ni Egipti. (Genesisi 41:37-49) Ni Israeli, jijokoo pẹlu awọn ọ̀tọ̀kùlú, tabi awọn alaṣẹ laaarin awọn eniyan Jehofa, jẹ́ anfaani kan ti o yẹ ki a ṣìkẹ́ rẹ̀. Bii awọn Kristian alagba lonii, iru awọn ọkunrin bẹẹ ní aranṣe ati ibukun Ọlọrun.
11. Eeṣe ti a fi le sọ pe Orin Dafidi 113:7-9 paapaa ni pataki ṣeefisilo fun awọn eniyan Jehofa ni akoko ode-oni?
11 Ki ni nipa ti ‘mimu ki àgàn obinrin di ìyá alayọ awọn ọmọkunrin’? Ọlọrun fun Hanna àgàn ni ọmọkunrin kan—Samueli, ẹni ti o yasọtọ patapata fun iṣẹ-isin Rẹ̀. (1 Samueli 1:20-28) Lọna ti o tubọ jamọ pataki, bẹrẹ pẹlu Jesu ati titu ẹmi mimọ jade sori awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ni Pentekosti 33 C.E., obinrin iṣapẹẹrẹ Ọlọrun, Sioni ti ọrun, bẹrẹsii bi awọn ọmọ ti ẹmi. (Isaiah 54:1-10, 13; Iṣe 2:1-4) Ati gan-an gẹgẹ bi Ọlọrun ti mu awọn Ju padabọsipo si ilẹ ibilẹ wọn lẹhin igbekun ni Babiloni, ni 1919 ó tú awọn aṣẹku ẹni-ami-ororo ti “Israeli Ọlọrun” silẹ lominira kuro ninu oko-onde Babiloni o si ti bukun wọn lọpọlọpọ nipa tẹmi ti o fi jẹ pe awọn ọ̀rọ̀ Orin Dafidi 113:7-9 ṣeefisilo fun wọn. (Galatia 6:16) Gẹgẹ bi awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa aduroṣinṣin, awọn aṣẹku ti Israeli tẹmi ati awọn alabaakẹgbẹpọ wọn ti wọ́n ni ireti ori ilẹ̀-ayé ń dahunpada tọkantọkan si awọn ọ̀rọ̀ ti o pari Orin Dafidi 113 (NW): “Ẹ yin Jah, ẹyin eniyan!”
Ẹ̀rí Àìlẹ́gbẹ́ Jehofa
12. Bawo ni Orin Dafidi 114 ṣe fi àìlẹ́gbẹ́ Jehofa hàn?
12 Orin Dafidi 114 fi àìlẹ́gbẹ́ Jehofa hàn nipa titọkasi awọn iṣẹlẹ aláìlẹ́gbẹ́ ti o nii ṣe pẹlu awọn ọmọ Israeli. Olorin naa kọrin pe: “Nigba ti Israeli jade kuro ni Egipti, ti ara-ile Jakobu kuro ninu ajeji ede eniyan; Juda ni ibi mimọ rẹ̀, Israeli ni ijọba rẹ̀.” (Orin Dafidi 114:1, 2) Ọlọrun da Israeli nide kuro ninu oko-ẹrú awọn ara Egipti, awọn ti èdè wọn ṣajeji si etí wọn. Idande awọn eniyan Jehofa, ti a pe ni Juda ati Israeli ní ọ̀nà ìfọ̀rọ̀-ewì wéra, fihàn pe Ọlọrun le dá gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ nide lonii.
13. Bawo ni Orin Dafidi 114:3-6 ṣe fi ipo ajulọ Jehofa hàn ti o si mú un bá awọn iriri Israeli igbaani mu?
13 Ipo ọba-alaṣẹ Jehofa lori gbogbo iṣẹda ni a mú ṣe kedere ninu awọn ọ̀rọ̀ naa: “Okun ri i, o si sá: Jordani pada sẹhin. Awọn oke nla ń fò bi àgbò, ati awọn oke keekeeke bi ọdọ-agutan. Ki ni o ṣe ọ, iwọ okun, ti iwọ fi sá? iwọ Jordani ti iwọ fi pada sẹhin? Ẹyin oke nla, ti ẹ fi ń fò bi àgbò; ati ẹyin oke keekeeke bi ọdọ-agutan?” (Orin Dafidi 114:3-6) Okun Pupa “sá” nigba ti Ọlọrun la ipa-ọna gba inu rẹ̀ fun awọn eniyan rẹ̀. Nigba naa ni Israeli rí ọwọ́ titobi Jehofa lẹnu iṣẹ lodisi awọn ọmọ Egipti ti wọn kú ninu omi ti ń padabọ naa. (Eksodu 14:21-31) Ninu ìfihàn agbara atọrunwa ti o farajọ ọ́, Odo Jordani “pada sẹhin,” ni yiyọnda fun awọn ọmọ Israeli lati kọja lọ sinu Kenaani. (Joṣua 3:14-16) ‘Awọn oke nla fò bi àgbò’ bi Oke Sinai ti ń yeefin ti o sì ń mì tìtì nigba ti a gbé majẹmu Ofin kalẹ. (Eksodu 19:7-18) Pẹlu otente orin rẹ̀ nitosi, olorin naa gbé awọn ọ̀ràn kalẹ ni ọ̀nà ibeere, boya ni didamọran pe okun, odò, awọn oke nla, ati awọn oke keekeeke alailẹmii ni ibẹru jinnijinni bá nipasẹ awọn ìfihàn agbara Jehofa wọnyi.
14. Ki ni ohun ti agbara Jehofa ṣe ni Meriba ati Kadeṣi, bawo si ni eyi ṣe le nipa lori awọn iranṣẹ rẹ̀ ọjọ oni?
14 Ni sisọrọ bá agbara Jehofa sibẹ, olorin naa kọrin pe: “Wárìrì, iwọ ilẹ, niwaju Oluwa, niwaju Ọlọrun Jakobu. Ẹni ti o sọ apata di adagun omi, ati okuta-ibọn di orisun omi.” (Orin Dafidi 114:7, 8) Ni ọ̀nà iṣapẹẹrẹ kan, olorin naa tipa bayii fihàn pe araye gbọdọ wà ni ibẹru-ọlọwọ fun Jehofa, Oluwa ati Oluṣakoso Gbogbogboo fun gbogbo ilẹ̀-ayé. Oun ni “Ọlọrun Jakobu,” tabi Israeli, gẹgẹ bi ó ṣe jẹ́ Ọlọrun Israeli tẹmi ati awọn alabaakẹgbẹpọ wọn ori ilẹ̀-ayé. Ni Meriba ati Kadeṣi ninu aginju, Jehofa fi agbara rẹ̀ hàn nipa pipese omi fun Israeli lọna iyanu, ni ‘sisọ apata di adagun omi, ati okuta-ibọn di orisun omi.’ (Eksodu 17:1-7; Numeri 20:1-11) Irufẹ awọn irannileti agbara tí ń muni ni ibẹru-ọlọwọ ati itọju onijẹlẹnkẹ ti Jehofa bẹẹ, fun awọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ ni idi yiyekooro fun nini igbagbọ ti ko ṣeé gbe ibeere dide sí ninu rẹ̀.
Laidabi Awọn Ọlọrun Oriṣa
15. Ọ̀nà wo ni o ti ṣeeṣe ki a gba kọ Orin Dafidi 115?
15 Orin Dafidi 115 rọ̀ wá lati yin ki a si gbẹkẹle Jehofa. O tọkasi i gẹgẹ bi orisun ibukun ati aranṣe ó si fẹri hàn pe awọn oriṣa jẹ alaiwulo. Orin Dafidi yii ni a ti nilati kọ ni àkọgbà. Iyẹn ni pe, ohùn kan le kọrin pe: “Ẹyin ti o bẹru Oluwa, gbẹkẹle Oluwa.” Awujọ naa ti le dahunpada pe: “Oun ni iranlọwọ wọn ati asà wọn.”—Orin Dafidi 115:11.
16. Iyatọ ifiwera wo ni a le fayọ laaarin Jehofa ati oriṣa awọn orilẹ-ede?
16 Ògo ko gbọdọ wá sọdọ wa ṣugbọn sori orukọ Jehofa, Ọlọrun iṣeun-ifẹ, tabi ifẹ aduroṣinṣin, ati otitọ. (Orin Dafidi 115:1) Awọn ọ̀tá le sọ pẹlu ẹ̀gàn pe: “Nibo ni Ọlọrun wọn wà?” Ṣugbọn awọn eniyan Jehofa le dahunpada pe: “Ọlọrun wa ń bẹ ni ọrun: o ń ṣe ohunkohun ti o wù ú.” (Ẹsẹ 2, 3) Bi o ti wu ki o ri, awọn oriṣa orilẹ-ede ko lè ṣe ohunkohun, nitori wọn wulẹ jẹ awọn ère fadaka ati wura ti a ti ọwọ́ eniyan ṣe. Laika ẹnu, oju, ati etí wọn sí, wọn jẹ alaileesọrọ, afọju, ati aditi. Wọn ni imu ṣugbọn wọn kò lè gbóòórùn, ẹsẹ ṣugbọn wọn kò lè rìn, ati ọ̀nà ọ̀fun ṣugbọn wọn kò le mú ohùn kankan jade. Awọn ti wọn ń ṣe awọn oriṣa aláìlètapútú ati awọn wọnni ti wọn ń gbẹkẹle wọn yoo di alailẹmii bakan naa.—Ẹsẹ 4-8.
17. Niwọn bi awọn òkú ko ti le yin Jehofa, ki ni o yẹ ki a ṣe, pẹlu ifojusọna wo sì ni?
17 Igbaniniyanju ni a pese tẹle e lati gbẹkẹle Jehofa gẹgẹ bi Oluranlọwọ ati Asà aabo Israeli, ti ile alufaa Aaroni, ati ti gbogbo awọn ti o bẹru Ọlọrun. (Orin Dafidi 115:9-11) Gẹgẹ bi awọn ti ń bẹru Jehofa, a ni ọ̀wọ̀-ńlá jijinlẹ fun Ọlọrun ati ifoya pipeye lati maṣe mú un binu. A tun ni igbagbọ pe “Oluṣẹda ọrun oun aye” ń bukun awọn olujọsin rẹ̀ aduroṣinṣin. (Ẹsẹ 12-15) Awọn ọrun jẹ ibi-aye ìtẹ́ rẹ̀, ṣugbọn Ọlọrun ṣe ilẹ̀-ayé bii ile ayeraye fun araye aduroṣinṣin ati onigbọran. Niwọn bi òkú didakẹjẹẹ, alaimọ ohunkohun kò ti le yin Jehofa, awa, ti a walaaye, gbọdọ ṣe bẹẹ ninu ifọkansin ati iduroṣinṣin patapata. (Oniwasu 9:5) Kiki awọn wọnni ti wọn bá yin Jehofa ni yoo gbadun ìyè ayeraye ti wọn yoo si le “bukun Jah” titilae, ni sisọrọ daradara nipa rẹ̀ “titilọgbere.” Nipa bayii ẹ jẹ ki a fi iduroṣinṣin darapọ mọ́ awọn wọnni ti wọn ń fiyesi igbaniniyanju naa: “Ẹ yin Jah, ẹyin eniyan!”—Orin Dafidi 115:16-18, NW.
Awọn Agbayanu Animọ Jehofa
18, 19. Ni awọn ọ̀nà wo ni awọn animọ Jehofa gbà mú ki ó yatọ si awọn ọlọrun èké?
18 Laidabi awọn oriṣa aláìlẹ́mìí, Jehofa ni Ọlọrun alaaye, ti ń fi awọn animọ agbayanu hàn. Oun ni ẹ̀dàyà-àpẹẹrẹ ifẹ o si jẹ “alaaanu ati oloore-ọfẹ, onipamọra, ati ẹni ti o pọ̀ ni oore ati otitọ.” (Eksodu 34:6; 1 Johannu 4:8) Ẹ wo bi o ti yatọ tó si ọlọrun Kenaani onika naa Moleki, eyi ti wọn ń fi awọn ọmọ rubọ sí! Wọn ti damọran rẹ̀ pe ère ọlọrun yii ní irisi eniyan ati ori akọ-maluu. Oriṣa yii ni a rohin pe wọn ń dá iná pípọ́ndẹ̀dẹ̀ mọ́, ti wọn yoo si ju awọn ọmọ si awọn ọwọ́ rẹ̀ ti o nà jade, ni jijabọ sinu ìléru tí ń jófòfò ti o wà nisalẹ naa. Ṣugbọn Jehofa jẹ onifẹẹ ati alaaanu ti o fi jẹ pe èrò iru fifi eniyan rubọ bẹẹ ko tilẹ fi ìgbà kankan “wá si inu [rẹ̀].”—Jeremiah 7:31.
19 Awọn animọ pataki ti Jehofa tun ni ninu idajọ-ododo pipe, ọgbọ́n alailopin, ati agbara aláìláàlà. (Deuteronomi 32:4; Jobu 12:13; Isaiah 40:26) Ki ni nipa awọn ọlọrun ajọsinfun arosọ atọwọdọwọ? Kaka ki wọn fi idajọ-ododo ṣèwàhù, awọn ọlọrun ati abo ọlọrun Babiloni lẹmii igbẹsan. Awọn ọlọrun ajọsinfun Egipti kìí ṣe apẹẹrẹ pipe ti ọgbọ́n ṣugbọn a fi wọn hàn pe wọn ni awọn ailera ẹda eniyan. Iyẹn ko yanilẹnu, niwọn bi awọn oriṣa èké ati awọn abo ọlọrun ti jẹ imujade “ìdasán ni ironu” awọn ẹda-eniyan ti wọn jẹwọ pe awọn jẹ ọlọgbọn. (Romu 1:21-23) Awọn ọlọrun ajọsinfun Griki ni a tànmọ́ọ̀ pe wọn di tẹmbẹlẹkun si araawọn. Fun apẹẹrẹ, ninu arosọ atọwọdọwọ, Zeus ṣi agbara rẹ̀ lo nipa mimu baba rẹ̀, Cronus, ẹni ti o ti rọ baba tirẹ̀ fúnraarẹ̀, Uranus loye, kuro lori ìtẹ́. Ẹ wo iru ibukun ti o jẹ lati ṣiṣẹsin ki a si yin Jehofa, Ọlọrun alaaye ati otitọ, ẹni ti o fi ifẹ, idajọ-ododo, ọgbọ́n, ati agbara pipe hàn!
Jehofa Yẹ fun Iyin Ayeraye
20. Awọn idi wo ni Ọba Dafidi fifunni fun yíyin orukọ Jehofa?
20 Gẹgẹ bi Psalmu Hallel ti fihàn, Jehofa lẹtọọsi iyin ayeraye. Bakan naa, nigba ti Dafidi ati awọn ọmọ Israeli ẹlẹgbẹ rẹ̀ ṣetilẹhin fun kíkọ́ tẹmpili, o sọ niwaju ijọ naa pe: “Olubukun ni Iwọ Oluwa Ọlọrun Israeli baba wa lae ati laelae! Tìrẹ Oluwa ni titobi, ati agbara, ati ogo, ati iṣẹgun, ati ọla-nla: nitori ohun gbogbo ní ọrun ati ní aye tìrẹ ni; ijọba ni tìrẹ, Oluwa, a si gbe ọ leke ní ori fun ohun gbogbo. Ọrọ̀ pẹlu ati ọlá ọ̀dọ̀ rẹ ní tií wá, iwọ sì jọba lori ohun gbogbo; ni ọwọ́ rẹ ni agbara ati ipá wà; ati ni ọwọ rẹ ni sisọni di nla wà, ati fifi agbara fun ohun gbogbo. Ǹjẹ́ nisinsinyi, Ọlọrun wa, awa dupẹ lọwọ rẹ, a si yin orukọ ògo rẹ.”—1 Kronika 29:10-13.
21. Ìfihàn 19:1-6 funni ni ẹ̀rí wo nipa yíyin ti ẹgbẹ́ awọn ọmọ ogun ọrun ń yin Jehofa?
21 Jehofa ni a o tun bukun ti a o sì yin titi ayeraye ninu awọn ọrun. Aposteli Johannu gbọ́ ti “ọpọlọpọ eniyan ni ọrun” wi pe: “Hallelujah ti Oluwa Ọlọrun wa ni igbala, ati ọlá agbara. Nitori otitọ ati ododo ni idajọ rẹ̀: nitori o ti ṣe idajọ àgbèrè nla nì [Babiloni Nla], ti o fi àgbèrè rẹ̀ ba ilẹ̀-ayé jẹ, o si ti gbẹsan ẹ̀jẹ̀ awọn iranṣẹ rẹ̀ lọwọ rẹ̀.” Lẹẹkan sii wọn wi pe: “[Ẹ yin Jah, ẹyin eniyan, NW].” Bakan naa sì ni “awọn àgbà mẹrinlelogun nì, ati awọn ẹ̀dá alaaye mẹrin nì.” Ohùn kan lati ori ìtẹ́ wi pe: “Ẹ maa yin Ọlọrun wa, ẹyin iranṣẹ rẹ̀ gbogbo, ẹyin ti o bẹru rẹ̀, ati èwe ati àgbà.” Lẹhin naa Johannu fikun un pe: “Mo si gbọ́ bi ẹni pe ohùn ọpọlọpọ eniyan, ati bi ìro omi pupọ, ati bi ìro àrá ńláǹlà, ń wi pe [Ẹ yin Jah, ẹyin eniyan, NW]: nitori Oluwa Ọlọrun wa, Olodumare, ń jọba.”—Ìfihàn 19:1-6.
22. Bawo ni a o ṣe yin Jehofa ninu ayé titun ti a ṣeleri rẹ̀?
22 Ẹ wo bi o ti ṣerẹ́gí tó pe awọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọrun ń yin Jehofa! Ninu ayé titun rẹ̀ ti o sunmọle nisinsinyi, awọn ẹni aduroṣinṣin ti yoo ji dide yoo darapọ mọ́ awọn olula opin eto-igbekalẹ yii ja ni yíyin Jah. Awọn oke-nla giga yoo gbe ori wọn soke ninu awọn orin iyin si Ọlọrun. Awọn oke eleweko tutu ati awọn igi eleso yoo kọ orin iyin rẹ̀. Họwu, gbogbo iṣẹda ti o walaaye ti o sì ń mí yoo yin orukọ Jehofa ninu ègbè Hallelujah titobi naa! (Orin Dafidi 148) A o ha gbọ́ ohùn rẹ ninu idunnu ayọ ọlọpọ eniyan naa bi? Yoo ri bẹẹ bi iwọ ba fi iduroṣinṣin ṣiṣẹsin Jah pẹlu awọn eniyan rẹ̀. Iyẹn gbọdọ jẹ ète rẹ ninu igbesi-aye, nitori ta ni o dabii Jehofa Ọlọrun wa?
Bawo Ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?
◻ Eeṣe ti a fi nilati yin Jehofa Ọlọrun?
◻ Ni awọn ọ̀nà wo ni Jehofa gbà jẹ́ alailafiwe?
◻ Awọn ẹ̀rí wo ni ó wà pe Jehofa jẹ́ oníyọ̀ọ́nú?
◻ Bawo ni Jehofa ṣe yatọ si awọn oriṣa alailẹmii ati awọn èké ọlọrun ajọsinfun?
◻ Eeṣe ti a fi le sọ pe Jehofa yoo gba iyin ayeraye ni ọrun ati lori ilẹ̀-ayé?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Awọn Psalmu ti Hallel ni a kọ lakooko ounjẹ Irekọja