Máa Fi Ìmoore Hàn Kó O sì Máa Fúnni Tọkàntọkàn
Ọ̀RỌ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa jẹ Jèhófà Baba wa ọ̀run lógún gan-an ni. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi dá wa lójú pé Ọlọ́run bìkítà fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. (1 Pét. 5:7) Ọ̀nà kan tí Jèhófà gbà ń bójú tó wa ni pé ó ń ràn wá lọ́wọ́ lónírúurú ọ̀nà ká lè máa fi ìṣòtítọ́ sìn ín. (Aísá. 48:17) Jèhófà ń fẹ́ ká jàǹfààní ìrànlọ́wọ́ tó ń pèsè fún wa, ní pàtàkì tá a bá wà nínú ìṣòro tó ń kó àárẹ̀ ọkàn bá wa. Òfin Mósè fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí.
Lábẹ́ Òfin Mósè, tìfẹ́tìfẹ́ ni Jèhófà fi rí sí i pé ìrànwọ́ wà “fún ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́,” àwọn bí, ọmọ òrukàn, opó, àtàwọn àtìpó. (Léf. 9:9, 10; Diu. 14:29) Ó mọ̀ pé àwọn ìránṣẹ́ òun kan lè nílò ìrànlọ́wọ́ ara wọn. (Ják. 1:27) Torí náà, ìránṣẹ́ Ọlọ́run kankan ò gbọ́dọ̀ lọ́ tìkọ̀ láti gba ìrànwọ́ látọ̀dọ̀ àwọn tí Jèhófà bá fọwọ́ tọ́ ọkàn wọn láti pèsè irú ìrànwọ́ bẹ́ẹ̀. Bá a bá sì rí irú ìrànwọ́ bẹ́ẹ̀ gbà, a gbọ́dọ̀ gbà á pẹ̀lú èrò tó tọ́.
Bákan náà, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún fi hàn pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run làǹfààní láti fúnni. Rántí “opó aláìní” tí Jésù kíyè sí nínú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù. (Lúùkù 21:1-4) Ó ṣeé ṣe kóun náà ti jàǹfààní àwọn ìpèsè onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà ṣe fáwọn opó gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Òfin. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìní ni opó yìí, à ń rántí ẹ̀ lónìí gẹ́gẹ́ bí ẹni tó fúnni, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹni tó gbà. Ẹ̀mí ọ̀làwọ́ tí opó yẹn ní ti ní láti fún un láyọ̀, torí pé Jésù ní: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Jésù tó jẹ́ òtítọ́ yìí lọ́kàn rẹ, báwo lo ṣe lè “sọ fífúnni dàṣà” kó o sì rí ayọ̀ tó máa tibẹ̀ wá?—Lúùkù 6:38.
“Kí Ni Èmi Yóò San Padà fún Jèhófà?”
Ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Sáàmù sọ pé: “Kí ni èmi yóò san padà fún Jèhófà nítorí gbogbo àǹfààní tí mo rí gbà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀?” (Sm. 116:12) Àwọn àǹfààní wo ni onísáàmù yìí ti rí gbà? Jèhófà dúró tì í nígbà tó wà nínú “wàhálà àti ẹ̀dùn-ọkàn.” Bákan náà, Jèhófà “gba ọkàn [rẹ̀] sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú.” Ó wá ń wá ọ̀nà tó máa gbà ‘san án pa dà’ fún Jèhófà. Kí wá ni onísáàmù yẹn máa ṣe? Ó ní: “Àwọn ẹ̀jẹ́ mi ni èmi yóò san fún Jèhófà.” (Sm. 116:3, 4, 8, 10-14) Ó pinnu pé òun á mú gbogbo ẹ̀jẹ́ tóun ti jẹ́ fún Jèhófà ṣẹ, òun á sì máa ṣàwọn ojúṣe òun.
Ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀. Lọ́nà wo? Nípa gbígbé ìgbé ayé rẹ lọ́nà tó bá àwọn òfin àti ìlànà Ọlọ́run mu nígbà gbogbo. Torí náà, jẹ́ kí jíjọ́sìn Jèhófà jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé ẹ, kó o sì jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí ẹ nínú gbogbo nǹkan tó o bá ń ṣe. (Oníw. 12:13; Gál. 5:16-18) Ká sòótọ́, kò sí bó o ṣe lè san gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún ẹ pa dà. Síbẹ̀, ó máa ń ‘mú ọkàn Jèhófà yọ̀’ tó bá rí i pé ò ń fi tọkàn tara ṣe iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. (Òwe 27:11) Ẹ ò rí i pé àǹfààní àgbàyanu ló jẹ́ láti múnú Jèhófà dùn lọ́nà yìí!
Mú Kí Ìjọ Tura
Kò sí àní-àní pé ọ̀pọ̀ ọ̀nà lo ti gbà jàǹfààní nínú ìjọ Kristẹni. Jèhófà ti tipasẹ̀ ìjọ pèsè ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ tẹ̀mí. O kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó tú ẹ sílẹ̀ lọ́wọ́ ìgbàgbọ́ èké àti kúrò nínú òkùnkùn nípa tẹ̀mí. (Jòh. 8:32) Láwọn ìpàdé ìjọ, àpéjọ àkànṣe, àyíká àti àgbègbè tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ṣètò, o ti gba ìmọ̀ tó máa sìn ẹ́ lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé, níbi tí kò ti ní sí ìrora àti ìjìyà. (Mát. 24:45-47) Ṣó o tiẹ̀ lè ka àwọn àǹfààní tó o ti jẹ àtèyí tó o ṣì máa jẹ nípasẹ̀ ìjọ? Kí lo lè san pa dà fún ìjọ?
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Gbogbo ara náà, nípa síso wọ́n pọ̀ ní ìṣọ̀kan àti mímú kí wọ́n fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nípasẹ̀ gbogbo oríkèé tí ń pèsè ohun tí a nílò, ní ìbámu pẹ̀lú ìṣiṣẹ́ olúkúlùkù ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan ní ìwọ̀n yíyẹ, ń mú kí ara náà dàgbà fún gbígbé ara rẹ̀ ró nínú ìfẹ́.” (Éfé. 4:15, 16) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa wọn, àmọ́ gbogbo Kristẹni lóde òní làwọn ìlànà yẹn kàn. Bẹ́ẹ̀ ni, ẹnì kọ̀ọ̀kan lè mú kí ìjọ túbọ̀ túra, kó sì máa dàgbà. Láwọn ọ̀nà wo?
Ara ọ̀nà tá a lè gbà máa ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa sapá láti máa fún àwọn ará níṣìírí nígbà gbogbo, ká sì máa gbé wọn ró. (Róòmù 14:19) A tún lè mú kí “ara náà dàgbà” nípa mímú èso ẹ̀mí Ọlọ́run dàgbà nínú ìbálò wa pẹ̀lú àwọn ará wa. (Gál. 5:22, 23) Bákan náà, a lè wá ọ̀nà tá a lè gbà máa “ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.” (Gál. 6:10; Héb. 13:16) Gbogbo ará ìjọ pátá, tọkùnrin-tobìnrin, tọmọdé-tàgbà, ló lè kópa nínú ‘gbígbé ara ró nínú ìfẹ́.’
A tún lè lo àwọn ẹ̀bùn, okun àtàwọn ohun ìní wa láti kópa nínú iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà tí ìjọ ń ṣe. Jésù Kristi sọ pé, “ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà.” Kí làwa náà gbọ́dọ̀ ṣe? Jésù sọ pé, “ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.” (Mát. 10:8) Torí náà, máa kópa kíkún nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 24:14; 28:19, 20) Ǹjẹ́ àwọn nǹkan kan wà tó lè mú kó o má ṣe tó bó ṣe yẹ? Rántí opó aláìní tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Nǹkan bíńtín báyìí ló fi ṣètọrẹ. Àmọ́, Jésù sọ pé ohun tó fi sílẹ̀ ju táwọn tó kù lọ. Gbogbo ohun tágbára ẹ̀ gbé ló ṣe yẹn.—2 Kọ́r. 8:1-5, 12.
Gba Ìrànwọ́ Pẹ̀lú Èrò tó Dáa
Àmọ́ ṣá o, àwọn ìgbà míì lè wà tó o máa ní láti gba ìrànwọ́ látọ̀dọ̀ ìjọ. Má ṣe lọ́ tìkọ̀ láti gba ìrànwọ́ èyíkéyìí tí ìjọ lè fún ẹ nígbà tí pákáǹleke tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé bá mú kó o sorí kọ́. Jèhófà ti fún wa láwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n, tí wọ́n sì bìkítà láti máa “ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ,” kí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a bá wà nínú àdánwò àti ìpọ́njú. (Ìṣe 20:28) Àwọn alàgbà àtàwọn mìíràn nínú ìjọ á fẹ́ láti tù ẹ́ nínú, kí wọ́n tì ẹ́ lẹ́yìn, kí wọ́n sì dáàbò bò ẹ́ nígbà ìṣòro.—Gál. 6:2; 1 Tẹs. 5:14.
Àmọ́, rí i pé o ní èrò tó tọ́ nígbà tó o bá rí ìrànwọ́ gbà. Máa fi ìmoore hàn nígbà tó o bá rí ìrànwọ́ gbà. Ńṣe ni kó o máa wo ìrànwọ́ tó o bá rí gbà látọ̀dọ̀ àwọn ará gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí ẹ. (1 Pét. 4:10) Kí nìdí tíyẹn fi ṣe pàtàkì? Ìdí ni pé a ò fẹ́ jẹ́ abaraámóorejẹ bíi ti ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ayé.
Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì Kó O sì Lo Òye
Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí ìjọ tó wà nílùú Fílípì nípa Tímótì, ó sọ pé: “Nítorí èmi kò ní ẹlòmíràn tí ó ní ìtẹ̀sí-ọkàn bí tirẹ̀ tí yóò fi òótọ́ inú bójú tó àwọn ohun tí ó jẹmọ́ yín.” Àmọ́, Pọ́ọ̀lù wá fi kún un pé: “Nítorí gbogbo àwọn yòókù ń wá ire ara wọn, kì í ṣe ti Kristi Jésù.” (Fílí. 2:20, 21) Pẹ̀lú àkíyèsí pàtàkì tí Pọ́ọ̀lù ṣe yẹn lọ́kàn wa, báwo làwa náà ṣe lè yẹra fún gbígbájúmọ́ ‘ire ara wa’ nìkan ju bó ṣe yẹ lọ?
A ò gbọ́dọ̀ máa sọ̀rọ̀ bíi pé à ń pàṣẹ tá a bá fẹ́ káwọn ará lo àkókò wọn láti fi gbọ́ ìṣòro wa. Kí nìdí? Rò ó wò ná: Kò sí àní-àní pé a máa mọrírì ẹ̀ gan-an tí arákùnrin kan bá ràn wá lọ́wọ́ láti yanjú ìṣòro pàjáwìrì kan. Àmọ́, ṣé a lè máa sọ̀rọ̀ bíi pé à ń pàṣẹ tá a bá fẹ́ gba irú ìrànwọ́ bẹ́ẹ̀? Kò yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìgbà gbogbo ni inú àwọn ará wa máa ń dùn láti ràn wá lọ́wọ́ tìfẹ́tìfẹ́, ó yẹ ká wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì ká sì lo òye tó bá dọ̀rọ̀ iye àkókò tá à ń retí pé kí wọ́n lò láti fi ràn wá lọ́wọ́. Ó ṣe tán, ohun tá a fẹ́ ni pé káwọn ará ṣe ohun yòówù tí wọ́n bá lè ṣe láti ràn wá lọ́wọ́ tọkàntọkàn nígbà ìṣòro.
Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ìgbà gbogbo làwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ múra tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́. Àmọ́, ìgbà míì lè wà tí wọ́n lè má lágbára láti gbọ́ gbogbo ìṣòro ẹ. Bọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà á dúró tì ẹ́ nínú ìṣòro yòówù kó o ní, bó ṣe dúró ti onísáàmù náà.—Sm. 116:1, 2; Fílí. 4:10-13.
Torí náà, má ṣe lọ́ tìkọ̀ láti gba ohunkóhun tí Jèhófà bá pèsè fún ẹ pẹ̀lú ẹ̀mí ìmoore, ní pàtàkì nígbà wàhálà àti ìdààmú. (Sm. 55:22) Ohun tó fẹ́ kó o ṣe nìyẹn. Àmọ́, ó tún fẹ́ kó o jẹ́ “olùfúnni ọlọ́yàyà.” Torí náà, ‘pinnu nínú ọkàn-àyà rẹ’ láti máa fi ohunkóhun tí agbára ẹ gbé ṣètìlẹ́yìn fún ìjọsìn tòótọ́. (2 Kọ́r. 9:6, 7) Bó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá lè máa fi ìmoore gba ìrànwọ́ tí wọ́n bá fún ẹ, wàá sì máa fúnni tọkàntọkàn.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
“Kí ni èmi yóò san padà fún Jèhófà nítorí gbogbo àǹfààní tí mo rí gbà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀?”—Sm. 116:12
▪ Wá ọ̀nà láti máa “ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn”
▪ Máa fún àwọn ará níṣìírí nígbà gbogbo, kó o sì máa gbé wọn ró nípa tẹ̀mí
▪ Máa kópa tó jọjú nínú iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn débi tágbára ẹ bá gbé e dé