Jẹ́ Kí Ìlọsíwájú Rẹ Fara Hàn Kedere
“Máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá, kí ìlọsíwájú rẹ lè fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn.”—1 TÍMÓTÌ 4:15.
1. Báwo lo ṣe lè mọ ìgbà tí èso kan pọ́n, tó sì tóó jẹ?
FOJÚ inú wo èso tóo fẹ́ràn jù lọ—ó lè jẹ́ ìbẹ́pẹ, òroǹbó, máńgòrò, tàbí èso mìíràn. Ǹjẹ́ o máa ń mọ ìgbà tó bá pọ́n, tó sì tóó jẹ? Bẹ́ẹ̀ ni. Òórùn rẹ̀, àwọ̀ rẹ̀, àti bó ṣe rí lọ́wọ́ ló ń sọ fún ọ pé nǹkan aládùn kan ń dúró dè ọ́. Nígbà tóo bá gé díẹ̀ jẹ lára rẹ̀, ó ṣeé ṣe kóo sọ pé ún-ùn, ó mà dùn o! Ẹ wo bó ṣe rọ̀ tó! O gbádùn rẹ̀ gan-an ni, àjẹpọ́nnulá ni.
2. Báwo ni ìdàgbàdénú ṣe máa ń fara hàn kedere, ipa wo ló sì máa ń ní lórí àjọṣe ẹni?
2 Ìrírí kékeré tó sì tún gbádùn mọ́ni yìí ní ohun táa lè fi wé ní àwọn apá ibòmíràn nínú ìgbésí ayé. Fún àpẹẹrẹ, bó ṣe máa ń rọrùn láti rí èso tó pọ́n, bẹ́ẹ̀ náà ni bí ẹnì kan ṣe dàgbà dénú nípa tẹ̀mí máa ń fara hàn lónírúurú ọ̀nà. A máa ń mọ̀ pé ẹnì kan ti dàgbà dénú, nígbà táa bá rí i pé ó ní ìfòyemọ̀, ìjìnlẹ̀ òye, ọgbọ́n, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. (Jóòbù 32:7-9) Ó dájú pé ó máa ń múnú ẹni dùn láti bá àwọn èèyàn tó ń fi irú àwọn ànímọ́ wọ̀nyẹn hàn nínú ìwà àti ìṣe wọn kẹ́gbẹ́, ká sì bá wọn daṣẹ́ pọ̀.—Òwe 13:20.
3. Kí ni àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa àwọn èèyàn ọjọ́ ayé rẹ̀ ní í ṣe pẹ̀lú ìdàgbàdénú?
3 Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, ẹnì kan lè dàgbà lọ́jọ́ orí, àmọ́ kí ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀ fi hàn pé kò dàgbà dénú nípa ti ìmọ̀lára àti nípa tẹ̀mí. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí Jésù Kristi ń sọ̀rọ̀ nípa ìran oníwàkiwà ọjọ́ ayé rẹ̀, ó ní: “Jòhánù wá, kò jẹ bẹ́ẹ̀ ni kò mu, síbẹ̀ àwọn ènìyàn sọ pé, ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù’; Ọmọ ènìyàn sì wá, ó ń jẹ, ó sì ń mu, síbẹ̀ àwọn ènìyàn sọ pé, ‘Wò ó! Ọkùnrin kan tí ó jẹ́ alájẹkì, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún mímu wáìnì.’” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn wọ̀nyẹn dàgbà lọ́jọ́ orí, Jésù sọ pé wọ́n ń ṣe bí “àwọn ọmọ kéékèèké”—tó túmọ̀ sí pé wọn ò dàgbà dénú rárá. Nípa bẹ́ẹ̀, ó fi kún un pé: “Síbẹ̀ náà, a fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.”—Mátíù 11:16-19.
4. Ní àwọn ọ̀nà wo ni ìlọsíwájú àti ìdàgbàdénú ti ń fara hàn kedere?
4 Látinú ọ̀rọ̀ Jésù, a lè mọ̀ bóyá ẹnì kan ní ọgbọ́n tòótọ́—tí í ṣe àmì tó ń fi ìdàgbàdénú hàn kedere—nípa irú iṣẹ́ tónítọ̀hún ń ṣe àti irú èso tí iṣẹ́ ọwọ́ ẹni náà ń so. Látàrí èyí, kíyè sí ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún Tímótì. Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù to ohun tó yẹ kí Tímótì máa lépa lẹ́sẹẹsẹ, ó sọ pé: “Máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá, kí ìlọsíwájú rẹ lè fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn.” (1 Tímótì 4:15) Bẹ́ẹ̀ ni o, bí Kristẹni kan ṣe ń tẹ̀ síwájú dé ìdàgbàdénú máa ń “fara hàn kedere,” tàbí ká kúkú sọ pé ó ṣeé rí kedere. Ìdàgbàdénú Kristẹni, tó dà bí iná tó mọ́lẹ̀ yòò, kì í ṣe ànímọ́ tó mù tàbí tó fara sin. (Mátíù 5:14-16) Nítorí ìdí èyí, a óò wá gbé àwọn ọ̀nà pàtàkì méjì yẹ̀ wò, tí ìlọsíwájú àti ìdàgbàdénú ti lè fara hàn kedere: (1) dídàgbà nínú ìmọ̀, òye, àti ọgbọ́n; (2) fífi àwọn èso ti ẹ̀mí hàn kedere.
Ìṣọ̀kanṣoṣo Nínú Ìgbàgbọ́ àti Ìmọ̀
5. Kí ni ìdàgbàdénú lè túmọ̀ sí?
5 Ọ̀pọ̀ jù lọ ìwé atúmọ̀ èdè ló ṣàpèjúwe ìdàgbàdénú gẹ́gẹ́ bíi dídé ipò àgbà, dídi géńdé, àti dídé òpin ipò kan tàbí góńgó kan táa ń lépa. Báa ti mẹ́nu kàn án níṣàájú, a máa ń sọ pé èso kan ti pọ́n tàbí pé ó ti gbó nígbà tó bá ti dàgbà dé ibi tó yẹ kó dàgbà dé, tí ìrísí rẹ̀, àwọ̀ rẹ̀, òórùn rẹ̀, àti bó ṣe rí lẹ́nu bá rí bó ṣe yẹ kó rí. Nítorí náà ìdàgbàdénú jẹ́ ọ̀rọ̀ mìíràn táa ń lò fún dídára dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, kíkúnjú ìwọ̀n láìkù síbì kan, kódà ìjẹ́pípé pàápàá.—Aísáyà 18:5; Mátíù 5:45-48; Jákọ́bù 1:4.
6, 7. (a) Kí ló fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ tó jinlẹ̀ pé kí gbogbo àwọn tó ń sin òun tẹ̀ síwájú dé ìdàgbàdénú nípa tẹ̀mí? (b) Kí ni ìdàgbàdénú nípa tẹ̀mí tan mọ́?
6 Jèhófà Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ tó jinlẹ̀ pé kí gbogbo àwọn tó ń sin òun tẹ̀ síwájú dé ìdàgbàdénú nípa tẹ̀mí. Kí èyí lè ṣeé ṣe, ó ti pèsè àwọn nǹkan àgbàyanu nínú ìjọ Kristẹni. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù pé: “Ó . . . fúnni ní àwọn kan gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì, àwọn kan gẹ́gẹ́ bí wòlíì, àwọn kan gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere, àwọn kan gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn àti olùkọ́, láti lè ṣe ìtọ́sọ́nàpadà àwọn ẹni mímọ́, fún iṣẹ́ òjíṣẹ́, fún gbígbé ara Kristi ró, títí gbogbo wa yóò fi dé ìṣọ̀kanṣoṣo nínú ìgbàgbọ́ àti nínú ìmọ̀ pípéye nípa Ọmọ Ọlọ́run, tí a ó fi di géńdé ọkùnrin, tí a ó fi dé orí ìwọ̀n ìdàgbàsókè tí ó jẹ́ ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Kristi; kí a má bàa tún jẹ́ ìkókó mọ́, tí a ń bì kiri gẹ́gẹ́ bí nípasẹ̀ àwọn ìgbì òkun, tí a sì ń gbé síhìn-ín sọ́hùn-ún nípasẹ̀ gbogbo ẹ̀fúùfù ẹ̀kọ́ nípasẹ̀ ìwà àgálámàṣà àwọn ènìyàn, nípasẹ̀ àlùmọ̀kọ́rọ́yí nínú dídọ́gbọ́n hùmọ̀ ìṣìnà.”—Éfésù 4:11-14.
7 Nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí, Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé lára àwọn ohun tó mú kí Ọlọ́run pèsè ọ̀pọ̀ yanturu nǹkan tẹ̀mí bẹ́ẹ̀ nínú ìjọ ni pé kí gbogbo wa lè “dé ìṣọ̀kanṣoṣo nínú ìgbàgbọ́ àti nínú ìmọ̀ pípéye,” ká di “géńdé ọkùnrin,” àti pé ká dé orí “ìwọ̀n ìdàgbàsókè tí ó jẹ́ ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Kristi.” Kìkì ìgbà yẹn la lè bọ́ lọ́wọ́ dídi ẹni tí a ń fi àwọn èròǹgbà àti ẹ̀kọ́ èké bì kiri bí ìkókó nípa tẹ̀mí. Nípa bẹ́ẹ̀, a rí bí títẹ̀ síwájú dé ìdàgbàdénú Kristẹni ṣe tan mọ́ jíjèrè “ìṣọ̀kanṣoṣo nínú ìgbàgbọ́ àti nínú ìmọ̀ pípéye nípa Ọmọ Ọlọ́run.” Àwọn kókó bíi mélòó kan wà nínú ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù tí ì bá dára ká kọbi ara sí.
8. Kí ni dídé orí “ìṣọ̀kanṣoṣo” nínú ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀ pípéye ń béèrè?
8 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, níwọ̀n bí a ti gbọ́dọ̀ wà ní “ìṣọ̀kanṣoṣo,” Kristẹni kan tó dàgbà dénú gbọ́dọ̀ wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nínú ọ̀ràn ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀. Kì í ṣalágbàwí èrò ara rẹ̀ tàbí kó rin kinkin mọ́ ọn, bẹ́ẹ̀ ní kì í fara mọ́ èrò ti ara ẹni nípa òye Bíbélì. Dípò ìyẹn, ó ní ìgbàgbọ́ kíkún nínú òtítọ́ gẹ́gẹ́ bí Jèhófà Ọlọ́run ṣe fi hàn nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi, àti “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” Nípa fífi gbogbo ìgbà jẹ àwọn oúnjẹ tẹ̀mí táa ń pèsè “ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu”—nípasẹ̀ àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni, àwọn ìpàdé, àwọn àpéjọ, àtàwọn àpéjọpọ̀—ó dájú pé a ó wà ní “ìṣọ̀kanṣoṣo” pẹ̀lú àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa nínú ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀.—Mátíù 24:45.
9. Ṣàlàyé gbólóhùn náà, “ìgbàgbọ́” gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe lò ó nínú lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn ará Éfésù.
9 Lọ́nà kejì, ohun tí gbólóhùn náà, “ìgbàgbọ́” ń tọ́ka sí kì í ṣe ìdánilójú tí Kristẹni kọ̀ọ̀kan sọ pé òun ní, bí kò ṣe gbogbo ohun táa gbà gbọ́ látòkè délẹ̀, ìyẹn ni “ìbú àti gígùn àti gíga àti jíjìn” rẹ̀. (Éfésù 3:18; 4:5; Kólósè 1:23; 2:7) Ní ti gidi, báwo ni Kristẹni kan ṣe lè wà ní ìṣọ̀kanṣoṣo pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tó bá jẹ́ pé kìkì apá ibì kan nínú “ìgbàgbọ́” náà ló gbà gbọ́ tàbí tó fara mọ́? Èyí túmọ̀ sí pé a ò ní fi mọ sórí mímọ kìkì àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì tàbí níní ìmọ̀ òtítọ́ lóréfèé tàbí lápá kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí lílo gbogbo ohun tí Jèhófà ń pèsè nípasẹ̀ ètò àjọ rẹ̀ láti walẹ̀ jìn sínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. A gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wa láti jèrè òye pípéye, tó sì kún rẹ́rẹ́ nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ àti ète rẹ̀. Èyí kan wíwá àkókò láti ka Bíbélì àtàwọn ìwé táa gbé karí Bíbélì, ká sì máa kẹ́kọ̀ọ́ wọn, ká máa gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ràn wá lọ́wọ́ kó sì tọ́ wa sọ́nà, ká máa lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé, ká sì máa nípìn-ín kíkún nínú iṣẹ́ wíwàásù Ìjọba náà àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn.—Òwe 2:1-5.
10. Kí ni ìjẹ́pàtàkì ọ̀rọ̀ náà “títí gbogbo wa yóò fi dé,” báa ṣe lò ó nínú Éfésù 4:13?
10 Lọ́nà kẹta, ohun tí Pọ́ọ̀lù fi bẹ̀rẹ̀ ṣíṣàpèjúwe góńgó alápá mẹ́ta náà ni ọ̀rọ̀ tó sọ pé “títí gbogbo wa yóò fi dé.” Ní ti gbólóhùn náà, “gbogbo wa,” ìwé ìléwọ́ kan tí ń ṣàlàyé Bíbélì túmọ̀ rẹ̀ pé “kì í ṣe olúkúlùkù, lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, àmọ́ gbogbo wa lápapọ̀.” Lọ́rọ̀ mìíràn, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá rẹ̀ láti lépa ìdàgbàdénú Kristẹni pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará. The Interpreter’s Bible sọ pé: “Ṣíṣe àṣeyọrí ní kíkún nípa tẹ̀mí kì í ṣe ohun tí ọwọ́ wa lè tẹ̀ nígbà táa bá ya ara wa sọ́tọ̀, bó ṣe jẹ́ pé ẹ̀yà ara kan kò lè dá nìkan dàgbà dé ibi tó yẹ kó dàgbà dé láìjẹ́ pé gbogbo ara jọ ń dàgbà pa pọ̀.” Pọ́ọ̀lù rán àwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù létí pé “pẹ̀lú gbogbo ẹni mímọ́” ni kí wọ́n máa làkàkà láti fi èrò orí mòye ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ìgbàgbọ́ náà.—Éfésù 3:18a.
11. (a) Kí ni níní ìlọsíwájú nípa tẹ̀mí kò túmọ̀ sí? (b) Kí ló yẹ ká ṣe táa bá fẹ́ ní ìlọsíwájú?
11 Ó hàn gbangba nínú ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù pé títẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí kò túmọ̀ sí wíwulẹ̀ kó ìmọ̀ àti ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ kún agbárí wa. Kristẹni tó dàgbà dénú kì í ṣe ẹni tó ń fi ìmọ̀ tó ní ṣe fọ́rífọ́rí fún àwọn ẹlòmíràn. Dípò ìyẹn, Bíbélì sọ pé: “Ipa ọ̀nà àwọn olódodo dà bí ìmọ́lẹ̀ mímọ́lẹ̀ yòò, tí ń mọ́lẹ̀ síwájú àti síwájú sí i, títí di ọ̀sán gangan.” (Òwe 4:18) Bẹ́ẹ̀ ni o, “ipa ọ̀nà” la sọ pé ó “ń mọ́lẹ̀ síwájú àti síwájú sí i,” kì í ṣe onítọ̀hún fúnra rẹ̀. Táa bá túbọ̀ ń sapá láti ní òye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ń mọ́lẹ̀ yòò, èyí tí Jèhófà ń fún àwọn ènìyàn rẹ̀, a óò máa ní ìlọsíwájú nípa tẹ̀mí. Nínú ọ̀ràn yìí, láti máa bá a lọ túmọ̀ sí láti máa tẹ̀ síwájú, ohun tí gbogbo wa sì lè ṣe ni.—Sáàmù 97:11; 119:105.
Fi “Èso Ti Ẹ̀mí” Hàn Kedere
12. Èé ṣe tí fífi èso ti ẹ̀mí hàn fi ṣe pàtàkì nínú wíwá tí a ń wá ìlọsíwájú nípa tẹ̀mí?
12 Bó ṣe jẹ́ pé ó ṣe pàtàkì láti dé “ìṣọ̀kanṣoṣo nínú ìgbàgbọ́ àti nínú ìmọ̀ pípéye,” bẹ́ẹ̀ náà ló tún ṣe pàtàkì pé ká máa fi èso tẹ̀mí Ọlọ́run hàn nínú gbogbo apá ìgbésí ayé wa. Kí nìdí? Èyí jẹ́ nítorí pé ìdàgbàdénú, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàlàyé rẹ̀, kì í ṣe ohun tó wà nínú tàbí tó fara sin, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ànímọ́ tó ṣeé rí kedere, èyí tó lè ṣe àwọn ẹlòmíràn láǹfààní, tó sì lè gbé wọn ró. Ní ti tòótọ́, wíwá tí a ń wá ìlọsíwájú nípa tẹ̀mí kì í ṣe ká kàn máa sapá láti mú àwọn ìwà ṣekárími kan dàgbà. Kàkà bẹ́ẹ̀, báa ṣe ń dàgbà nípa tẹ̀mí, táa ń tẹ̀ lé ìdarí ẹ̀mí Ọlọ́run, ìyípadà àgbàyanu kan yóò fara hàn nínú ìwà àti ìṣe wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ máa rìn nípa ẹ̀mí, ẹ kì yóò sì ṣe ìfẹ́-ọkàn ti ẹran ara rárá.”—Gálátíà 5:16.
13. Ìyípadà wo ló jẹ́ ẹ̀rí tó fi ìlọsíwájú hàn kedere?
13 Pọ́ọ̀lù wá to “àwọn iṣẹ́ ti ara” lẹ́sẹẹsẹ, èyí tí ó pọ̀ rẹpẹtẹ, tó sì “fara hàn kedere.” Kó tó di pé ẹnì kan wá lóye àwọn ohun tí Ọlọ́run béèrè, ó ti lè máa gbé ìgbésí ayé rẹ̀ lọ́nà ti ayé, kí ó sì máa ṣe àwọn kan lára ohun tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn wọ̀nyí: “àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìwà àìníjàánu, ìbọ̀rìṣà, bíbá ẹ̀mí lò, ìṣọ̀tá, gbọ́nmi-si omi-ò-to, owú, ìrufùfù ìbínú, asọ̀, ìpínyà, ẹ̀ya ìsìn, ìlara, mímu àmuyíràá, àwọn àríyá aláriwo, àti nǹkan báwọ̀nyí.” (Gálátíà 5:19-21) Àmọ́, bí ẹni náà ti ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, díẹ̀díẹ̀ ni yóò máa gba ara rẹ̀ lọ́wọ́ “àwọn iṣẹ́ ti ara” tí kò dára wọ̀nyí, tí yóò sì máa fi “èso ti ẹ̀mí” rọ́pò wọn. Àwọn ìyípadà tó hàn síta wọ̀nyí ni ẹ̀rí tí ó hàn kedere pé ẹni náà ń tẹ̀ síwájú síhà ìdàgbàdénú Kristẹni.—Gálátíà 5:22.
14. Ṣàlàyé gbólóhùn méjèèjì náà, “àwọn iṣẹ́ ti ara” àti “èso ti ẹ̀mí.”
14 Ó yẹ ká kíyè sí àwọn gbólóhùn méjì náà, “àwọn iṣẹ́ ti ara” àti “èso ti ẹ̀mí.” “Iṣẹ́” ni àbájáde ohun tí ẹnì kan ṣe, ìyẹn ni èrè ohun tí ẹnì kan ṣe. Ní ọ̀rọ̀ mìíràn, àwọn ohun tí Pọ́ọ̀lù tò lẹ́sẹẹsẹ gẹ́gẹ́ bí àwọn iṣẹ́ ti ara wọ̀nyẹn jẹ́ àbájáde ohun tí ẹnì kan mọ̀ọ́mọ̀ ṣe tàbí ohun tí àìpé ẹ̀dá sún un ṣe. (Róòmù 1:24, 28; 7:21-25) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, gbólóhùn náà, “èso ti ẹ̀mí” fi hàn pé àwọn ànímọ́ táa tò lẹ́sẹẹsẹ wọ̀nyẹn kì í ṣe ohun táa lè mú jáde kìkì nípasẹ̀ ìmọ̀wàáhù tàbí nípasẹ̀ títún ìwà ẹni ṣe, àmọ́ ó jẹ́ àbájáde bí ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe ń ṣiṣẹ́ lára ẹnì kan. Bí igi kan ṣe máa mú èso jáde nígbà táa bá tọ́jú rẹ̀ dáadáa, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹnì kan ṣe máa fi èso ti ẹ̀mí hàn kedere nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá ń ṣiṣẹ́ fàlàlà nínú ìgbésí ayé rẹ̀.—Sáàmù 1:1-3.
15. Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì láti fún gbogbo apá tí “èso ti ẹ̀mí” ní láfiyèsí?
15 Kókó mìíràn tó tún yẹ ká gbé yẹ̀ wò ni bí Pọ́ọ̀lù ṣe lo ọ̀rọ̀ náà “èso” láti kó gbogbo ànímọ́ rere tó mẹ́nu kàn pọ̀. Kì í ṣe pé ẹ̀mí náà ń pèsè onírúurú èso, tí a ó fi wá máa ṣa èyí tó bá wù wá níbẹ̀. Gbogbo ànímọ́ tí Pọ́ọ̀lù tò lẹ́sẹẹsẹ—ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, àti ìkóra-ẹni-níjàánu—ló ṣe pàtàkì, tí àpapọ̀ wọn sì ń mú kí àkópọ̀ ìwà Kristẹni tuntun ṣeé ṣe. (Éfésù 4:24; Kólósè 3:10) Nítorí náà, báa ṣe ń rí i pé àwọn kan lára ànímọ́ wọ̀nyí ń fara hàn gan-an nínú ìgbésí ayé wa nítorí irú èèyàn táa jẹ́ àti ìtẹ̀sí ọkàn wa, ó ṣe pàtàkì pé ká fún gbogbo ànímọ́ yòókù tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn láfiyèsí. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a lè túbọ̀ fi àkópọ̀ ìwà bíi Kristi hàn nínú ìgbésí ayé wa.—1 Pétérù 2:12, 21.
16. Kí ni ète táa fi ń lépa àtidi Kristẹni tó dàgbà dénú, báwo ni ọwọ́ wa sì ṣe lè tẹ̀ ẹ́?
16 Ẹ̀kọ́ pàtàkì táa lè kọ́ nínú ìjíròrò Pọ́ọ̀lù ni pé báa ti ń lépa ìdàgbàdénú Kristẹni, ète táa fi ń ṣe é kì í ṣe láti kó ọ̀pọ̀ ìmọ̀ àti ẹ̀kọ́ jọ, tàbí láti túbọ̀ tún àwọn ìwà àbímọ́ni ṣe. Ó jẹ́ láti mú kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa ṣiṣẹ́ fàlàlà nínú ìgbésí ayé wa. Bí a bá ṣe ń jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí èrò àti ìṣe wa tó, bẹ́ẹ̀ náà ni a óò túbọ̀ dàgbà dénú nípa tẹ̀mí tó. Báwo la ṣe lè lé góńgó yìí bá? A gbọ́dọ̀ ṣí ọkàn-àyà àti èrò inú wa payá, kí a sì jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí rẹ̀. Èyí kan lílọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé àti kíkópa nínú wọn. Ó tún yẹ ká máa kẹ́kọ̀ọ́, ká sì máa ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, ká jẹ́ kí àwọn ìlànà rẹ̀ máa darí bí a ṣe ń bá àwọn ẹlòmíràn lò, kó sì máa darí àwọn yíyàn àti ìpinnu tí a ń ṣe. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé ìlọsíwájú wa yóò hàn gbangba.
Tẹ̀ Síwájú fún Ògo Ọlọ́run
17. Báwo ni títẹ̀ síwájú ṣe tan mọ́ yíyin Baba wa ọ̀run lógo?
17 Lékè gbogbo rẹ̀, kì í ṣe àwa ni mímú kí ìlọsíwájú wa fara hàn kedere ń fi ògo àti ìyìn fún bí kò ṣe Baba wa ọ̀run, Jèhófà, tó mú kó ṣeé ṣe fún wa láti dàgbà dénú nípa tẹ̀mí. Ní alẹ́ ọjọ́ tí wọ́n pa Jésù, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “A yin Baba mi lógo nínú èyí, pé ẹ ń bá a nìṣó ní síso èso púpọ̀, tí ẹ sì fi ara yín hàn ní ọmọ ẹ̀yìn mi.” (Jòhánù 15:8) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà ń fi ògo fún Jèhófà nípasẹ̀ èso tí ẹ̀mí tí wọ́n ń fi hàn àti nípasẹ̀ èso Ìjọba Ọlọ́run tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn ń mú jáde.—Ìṣe 11:4, 18; 13:48.
18. (a) Irú ìkórè aláyọ̀ wo ló ń lọ lọ́wọ́ lónìí? (b) Kí sì ni ìpèníjà tí ìkórè yìí ní nínú?
18 Lónìí, ìbùkún Jèhófà wà lórí àwọn èèyàn rẹ̀, bí wọ́n ṣe ń kópa nínú iṣẹ́ ìkórè tẹ̀mí kárí ayé. Fún ọdún bíi mélòó kan báyìí ni nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [300,000] àwọn ẹni tuntun ti ń ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà lọ́dọọdún, tí wọ́n sì ń fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wọn hàn nípasẹ̀ batisí. Èyí ń mú wa láyọ̀, ó sì dájú pé ó tún ń mú ọkàn-àyà Jèhófà yọ̀ pẹ̀lú. (Òwe 27:11) Àmọ́, kí èyí tó lè máa jẹ́ orísun ayọ̀ àti ìyìn fún Jèhófà nìṣó, gbogbo irú ẹ̀yin ẹni tuntun bẹ́ẹ̀ ní láti “máa bá a lọ ní rírìn ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú [Kristi], kí ẹ ta gbòǹgbò, kí a sì máa gbé yín ró nínú rẹ̀, kí ẹ sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́.” (Kólósè 2:6, 7) Èyí gbé ìpèníjà alápá méjì dìde fún àwọn èèyàn Ọlọ́run. Lọ́nà kan, tóo bá jẹ́ ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe batisí, ṣé wàá kojú ìpèníjà sísapá gidigidi kí “ìlọsíwájú rẹ lè fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn”? Lọ́nà kejì, tó bá ti pẹ́ tóo ti wà nínú òtítọ́, ṣé wàá kojú ìpèníjà gbígba ẹrù iṣẹ́ bíbójútó ire tẹ̀mí àwọn ẹni tuntun? Nínú ọ̀nà méjèèjì, ìjẹ́pàtàkì títẹ̀ síwájú dórí ìdàgbàdénú hàn kedere.—Fílípì 3:16; Hébérù 6:1.
19. Àǹfààní àti àwọn ìbùkún wo ló lè jẹ́ tìrẹ bí o bá jẹ́ kí ìlọsíwájú rẹ hàn kedere?
19 Àgbàyanu ìbùkún ń dúró de gbogbo àwọn tó bá ṣe iṣẹ́ àṣekára láti mú kí ìlọsíwájú wọn hàn kedere. Rántí ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Pọ́ọ̀lù sọ lẹ́yìn tó rọ Tímótì láti tẹ̀ síwájú, ó ní: “Máa fiyè sí ara rẹ nígbà gbogbo àti sí ẹ̀kọ́ rẹ. Dúró nínú nǹkan wọ̀nyí, nítorí nípa ṣíṣe èyí, ìwọ yóò gba ara rẹ àti àwọn tí ń fetí sí ọ là.” (1 Tímótì 4:16) Nípa fífi taápọntaápọn sapá kí ìlọsíwájú rẹ lè hàn kedere, ìwọ náà lè nípìn-ín nínú àǹfààní yíyin orúkọ Ọlọ́run lógo àti gbígbádùn àwọn ìbùkún rẹ̀.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Ní àwọn ọ̀nà wo ni ìdàgbàdénú nípa tẹ̀mí ti lè hàn kedere?
• Irú ìmọ̀ àti òye wo ló ń fi ìdàgbàdénú hàn?
• Báwo ni fífi “èso ti ẹ̀mí” hàn ṣe túmọ̀ sí ìlọsíwájú nípa tẹ̀mí?
• Àwọn ìpèníjà wo la gbọ́dọ̀ kojú wọ́n báa ṣe ń tẹ̀ síwájú sí ìdàgbàdénú?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Pípọ́n, tàbí ìdàgbàdénú, máa ń hàn kedere
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
A ń ní ìlọsíwájú tẹ̀mí nípa ṣíṣàì jẹ́ kí òtítọ́ yà wá sílẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Àdúrà ń ràn wá lọ́wọ́ láti fi “èso ti ẹ̀mí” hàn kedere