O Lè Jẹ́ Oníwà Mímọ́ Nínú Ayé Oníṣekúṣe
ADÚMÁADÁN ni, ó sì rẹwà lọ́kùnrin. Orí èyí obìnrin náà pé, òrékelẹ́wà sì ni. Iléeṣẹ́ kan náà ni wọ́n ti jọ ń ṣiṣẹ́. Ojú obìnrin yìí kì í kúrò lára rẹ̀. Òun náà sì fi hàn pé òun gba tobìnrin náà. Wọ́n máa ń ra ẹ̀bùn fún ara wọn. Kíá, wọ́n ti di olólùfẹ́. Èyí ọkùnrin wá tìtorí obìnrin yìí fi ìyàwó tiẹ̀ sílẹ̀. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, obìnrin yìí pinnu pé òun ò ní fi ọkọ tòun sílẹ̀, ó sì fòpin sí ìṣekúṣe tó ń lọ láàárín wọn. Èyí ọkùnrin gbìyànjú láti padà lọ bá ìyàwó rẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò fi gbogbo ọkàn ṣe é. Ṣùgbọ́n nítorí pé ọkùnrin yìí kò ronú pìwà dà ní tòótọ́, lòun àtìyàwó rẹ̀ bá pín gaàrí, tí okùn ìgbéyàwó rẹ̀ sì já láìṣeé so padà. Ni olúkúlùkù wọn bá tún ń bá ìgbésí ayé yí, ó kàn jẹ́ pé nǹkan ò ṣẹnuure mọ́ ni.
Nínú ayé tí a wà yìí, àwọn èèyàn ò ka ìwà rere takọtabo sí ìwà funfun mọ́. Lílépa fàájì àti ìgbádùn láìsí ìkóra-ẹni-níjàánu ló jọ pé ó gbòde kan báyìí. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ pé: “Ó jọ pé panṣágà ń ṣẹlẹ̀ níbi gbogbo, ó sì tilẹ̀ jọ pé ní àwọn ibì kan, bí ìgbéyàwó ṣe wọ́pọ̀ náà ni panṣágà ṣe wọ́pọ̀.”
Ṣùgbọ́n, ìfẹ́ Jèhófà Ọlọ́run ni pé kí ìgbéyàwó “ní ọlá láàárín gbogbo ènìyàn,” kí ibùsùn ìgbéyàwó sì wà “láìní ẹ̀gbin.” (Hébérù 13:4) Ìwé Mímọ́ polongo pé: “Kí a má ṣì yín lọ́nà. Kì í ṣe àwọn àgbèrè, tàbí àwọn abọ̀rìṣà, tàbí àwọn panṣágà, tàbí àwọn ọkùnrin tí a pa mọ́ fún àwọn ète tí ó lòdì sí ti ẹ̀dá, tàbí àwọn ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin dà pọ̀ . . . ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10) Nítorí náà, láti lè rí ojú rere Ọlọ́run, a ní láti jẹ́ oníwà mímọ́ nínú ayé oníṣekúṣe yìí.
Báwo la ṣe lè dáàbò bo ara wa lọ́wọ́ àwọn ohun tí ń sọni dìbàjẹ́ tó yí wa ká? Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì pèsè ìdáhùn ní orí karùn-ún ìwé Òwe inú Bíbélì. Ẹ jẹ́ ká gbọ́ ohun tó ní í sọ.
Agbára Láti Ronú Yóò Máa Ṣọ́ Ọ
Ọba Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ọmọ mi, fetí sí ọgbọ́n mi.” Ó wá fi kún un pé: “Dẹ etí rẹ sí ìfòyemọ̀ mi, kí o bàa lè ṣọ́ agbára láti ronú; kí ètè tìrẹ sì fi ìṣọ́ ṣọ́ ìmọ̀.”—Òwe 5:1, 2.
Láti lè dènà ìdẹwò ṣíṣe ìṣekúṣe, a gbọ́dọ̀ ní ọgbọ́n—ìyẹn, agbára láti lo ìmọ̀ tó wà nínú Ìwé Mímọ́—àti ìfòyemọ̀, ìyẹn, agbára láti mọ ohun tí ó tọ́ yàtọ̀ sí ohun tí kò tọ́ àti láti yan ipa ọ̀nà tó tọ̀nà. A rọ̀ wá pé kí a fetí sí ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀ kí a bàa lè ṣọ́ agbára láti ronú. Báwo la ṣe lè ṣe èyí? Nígbà tí a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó yẹ kí a máa kíyè sí ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń ṣe nǹkan, kí a sì dẹ etí wa sí ìfẹ́ àti ète rẹ̀. Nípa ṣíṣe èyí, a óò máa darí ọ̀nà tí a gbà ń ronú sí ọ̀nà títọ́. Agbára láti ronú tí a bá tipa báyìí jèrè yóò bá ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run mu. Tí a bá lo agbára yìí lọ́nà tí ó tọ́, kò ní jẹ́ ká kó sínú páńpẹ́ ìṣekúṣe.
Ṣọ́ra fún Ẹnu Dídùn Mọ̀nràn-ìn Mọnran-in
Ìdí tí agbára láti ronú fi ṣe kókó nínú jíjẹ́ oníwà mímọ́ nínú ayé aláìmọ́ ni pé ọ̀nà àwọn oníṣekúṣe kún fún ẹ̀tàn. Sólómọ́nì kìlọ̀ pé: “Ètè àjèjì obìnrin ń kán tótó bí afárá oyin, òkè ẹnu rẹ̀ sì dùn mọ̀nràn-ìn mọnran-in ju òróró lọ. Ṣùgbọ́n ohun tí ó máa ń yọrí sí nígbẹ̀yìn láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ korò bí iwọ; ó mú bí idà olójú méjì.”—Òwe 5:3, 4.
Nínú òwe yìí, oníwàkiwà èèyàn ni a fi wé “àjèjì obìnrin”—ìyẹn aṣẹ́wó.a Àwọn ọ̀rọ̀ tó fi ń sún àwọn èèyàn dẹ́ṣẹ̀ dùn bí afárá oyin, ó sì jọ̀lọ̀ ju òróró ólífì lọ. Ǹjẹ́ báyìí kọ́ ni wọ́n ṣe sábà máa ń bẹ̀rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá fẹ́ fi ìṣekúṣe lọni? Fún àpẹẹrẹ, gbọ́ ìrírí obìnrin akọ̀wé kan, tó jẹ́ ẹlẹ́yinjú ẹgẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Amy. Ó ròyìn pé: “Ojú ọkùnrin kan tó wà níbi iṣẹ́ wa kì í kúrò lára mi, ńṣe ló máa ń pọ́n mi ṣáá. Ó máa ń jẹ́ ìwúrí láti gba àfiyèsí àwọn èèyàn. Ṣùgbọ́n mo rí i kedere pé ìfẹ́ tó ní sí mi kò kọjá ìfẹ́ ìbálòpọ̀ takọtabo. Mi ò ní jẹ́ kó fi ẹ̀tàn fà mí lọ.” Ọ̀rọ̀ àpọ́nlé ẹlẹ́tàn, ì báà jẹ́ látẹnu ọkùnrin tàbí obìnrin, sábà máa ń dùn-ún gbọ́ létí, àfi téèyàn bá tètè fura pé ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ni. Ìdí nìyẹn tó fi gba ọgbọ́n ìrònú.
Ohun tí ìṣekúṣe máa ń yọrí sí nígbẹ̀yìn korò bí iwọ, ó sì mú bí idà olójú méjì—ó kún fún ìrora ó sì ń ṣekú pani. Ẹ̀rí ọkàn tí ń dani láàmú, oyún tí a kò fẹ́, tàbí àrùn téèyàn ń kó nípasẹ̀ ìbálòpọ̀, ló sábà máa ń jẹ́ àbájáde burúkú irú ìwà bẹ́ẹ̀. Sì tún ronú nípa ẹ̀dùn ọkàn ńláǹlà tó máa ń dé bá ọkọ tàbí aya aláìṣòótọ́ náà. Ìwà àìṣòótọ́ kan ṣoṣo ti tó láti fa ìròbìnújẹ́ tó lè báni dọjọ́ alẹ́. Dájúdájú, ìṣekúṣe ń ṣeni léṣe.
Ọlọgbọ́n ọba náà ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó sọ nípa ọ̀nà ìgbésí ayé oníwàkiwà obìnrin pé: “Ẹsẹ̀ rẹ̀ ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú ikú. Àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ gan-an fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin nínú Ṣìọ́ọ̀lù. Ipa ọ̀nà ìyè ni òun kò ṣàgbéyẹ̀wò. Àwọn òpó ọ̀nà rẹ̀ ṣe kọ́lọkọ̀lọ, kò mọ ibi tí wọ́n lọ.” (Òwe 5:5, 6) Ọ̀nà ikú ni obìnrin oníṣekúṣe ń tọ̀—àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ sì forí lé Ṣìọ́ọ̀lù, ìyẹn, isà òkú gbogbo aráyé. Pẹ̀lú bí àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń tàtaré rẹ̀ ti ń tàn kálẹ̀ báyìí, àgàgà àrùn éèdì, ẹ ò rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ wọ̀nyí! Ohun tó yọrí sí fún un ló máa yọrí sí fún àwọn tó ń bá a rin àwọn ọ̀nà wíwọ́ rẹ̀.
Ọba yìí wá fi àníyàn àtọkànwá rọ̀ wá pé: “Ǹjẹ́ nísinsìnyí, ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin ọmọ, ẹ má sì yà kúrò nínú àwọn àsọjáde ẹnu mi. Jẹ́ kí ọ̀nà rẹ jìnnà réré sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, má sì sún mọ́ ẹnu ọ̀nà ilé rẹ̀.”—Òwe 5:7, 8.
Ó yẹ ká rìn jìnnà réré sí ọ̀nà àwọn oníṣekúṣe. Èé ṣe tí a ó fi rìn nítòsí ọ̀nà wọn nípa gbígbọ́ àwọn orinkórin, nípa wíwo àwọn eré oníwà ìbàjẹ́, tàbí nípa wíwo àwọn nǹkan tó ń ru ìfẹ́ ìbálòpọ̀ sókè? (Òwe 6:27; 1 Kọ́ríńtì 15:33; Éfésù 5:3-5) Ẹ sì wo bó ti jẹ́ ìwà òmùgọ̀ tó láti máa fa ojú wọn mọ́ra nípa bíbá wọn tage tàbí nípa wíwọṣọ àti mímúra lọ́nà tí kò bójú mu!—1 Tímótì 4:8; 1 Pétérù 3:3, 4.
Aburú Tó Ń Fà Ti Pọ̀ Jù
Kí tún ni ìdí mìíràn tó fi yẹ ká ta kété sí ọ̀nà oníwàkiwà? Sólómọ́nì dáhùn pé: “Kí ìwọ má bàa fi iyì rẹ fún àwọn ẹlòmíràn, tàbí kí o fi àwọn ọdún rẹ fún ohun tí ó níkà; kí àwọn àjèjì má bàa fi agbára rẹ tẹ́ ara wọn lọ́rùn, tàbí kí àwọn nǹkan tí ìwọ fi ìrora rí gbà wà ní ilé ọmọ ilẹ̀ òkèèrè, tàbí kí o wá máa kérora ní ọjọ́ ọ̀la rẹ nígbà tí ẹran ara rẹ àti ẹ̀yà ara rẹ bá wá sí òpin.”—Òwe 5:9-11.
Ọ̀rọ̀ òkè yìí tí Sólómọ́nì sọ fi hàn kedere pé aburú tó máa ń tẹ̀yìn ìṣekúṣe yọ kò kéré rárá. Ẹni tó bá ṣe panṣágà kì í jìnnà sí àbùkù tàbí ẹ̀tẹ́. Ǹjẹ́ kì í ṣe òótọ́ ni pé ó ń tẹ́ni lógo láti wulẹ̀ sọ ara wa di ohun èlò tí a fi ń tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wa tàbí ti ẹlòmíràn lọ́rùn? Kì í ha í ṣe ìfara-ẹni-wọ́lẹ̀ láti lọ́wọ́ nínú ìbálòpọ̀ takọtabo pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya wa?
Ṣùgbọ́n kí ni ‘fífi àwọn ọdún wa, agbára wa, àti èso làálàá wa fún àwọn àjèjì, tàbí ọmọ ilẹ̀ òkèèrè’ wé mọ́? Ìwé kan tí a ṣèwádìí nínú rẹ̀ ṣàlàyé pé: “Ohun tí ẹsẹ wọ̀nyí ń sọ ṣe kedere: Aburú tí àìṣòótọ́ nínú ìgbéyàwó ń fà kò kéré; nítorí pé ohun téèyàn fi gbogbo ọjọ́ ayé ẹ̀ ṣiṣẹ́ fún—bí ipò, agbára, aásìkí—lè pòórá yálà nípasẹ̀ àwọn nǹkan tí obìnrin náà ń fi ìwà ọ̀kánjúà gbà tàbí nípasẹ̀ ohun tí àwọn ará àdúgbò ní kí onítọ̀hún wá san nítorí ìwà ìbàjẹ́ tó hù.” Ẹ ò rí i pé apá kì í sábàá ká ohun tí ìṣekúṣe ń dá sílẹ̀!
Nígbà tí òmùgọ̀ náà bá pàdánù iyì rẹ̀ tán, tí gbogbo dúkìá rẹ̀ sì ti run, á wá máa kérora, pé: “Ẹ wo bí mo ti kórìíra ìbáwí tó, ẹ sì wo bí ọkàn-àyà mi ti ṣàìbọ̀wọ̀ àní fún ìbáwí àfitọ́nisọ́nà tó! Èmi kò sì fetí sí ohùn àwọn olùkọ́ni mi, èmi kò sì dẹ etí mi sí àwọn olùkọ́ mi. Tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn ni mo wá fi wà nínú gbogbo onírúurú ìwà búburú ní àárín ìjọ àti àpéjọ.”—Òwe 5:12-14.
Tó bá yá, ẹlẹ́ṣẹ̀ náà á bẹ̀rẹ̀ sí ké igbe ohun tí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan pè ní “ọ̀kan-kò-jọ̀kan ‘ǹ bá mọ̀,’ bíi: ǹ bá mọ̀ kí n fetí sí bàbá mi; ǹ bá mọ̀ kí n má ṣorí kunkun; ǹ bá mọ̀ kí n gba ìmọ̀ràn àwọn èèyàn.” Ṣùgbọ́n àbámọ̀ ní í gbẹ̀yìn ọ̀rọ̀. Ní báyìí, ìgbésí ayé ẹni tó ti di oníwà àìmọ́ náà ti bà jẹ́, ó sì ti gba orúkọ burúkú. Ẹ ò rí i bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé ká ronú lórí wàhálà ńlá tó máa ń gbẹ̀yìn ìṣekúṣe kí ó tó kó sí wa lórí!
“Mu Omi Láti Inú Ìkùdu Tìrẹ”
Ṣé Bíbélì ò fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ọ̀ràn ìbálòpọ̀ takọtabo ni? Rárá o. Ìrusókè ìfẹ́ àti ìgbádùn tí ń wáyé láàárín ọkùnrin àti obìnrin jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Àmọ́ o, àárín tọkọtaya nìkan ni ìgbádùn yìí gbọ́dọ̀ mọ. Ìdí nìyẹn tí Sólómọ́nì fi gba ọkùnrin tó ti gbéyàwó nímọ̀ràn pé: “Mu omi láti inú ìkùdu tìrẹ, àti omi tí ń sun láti inú kànga tìrẹ. Ó ha yẹ kí àwọn ìsun rẹ tú ká sí ìta, àwọn ìṣàn omi rẹ ní àwọn ojúde ìlú? Jẹ́ kí wọ́n wà fún ìwọ nìkan ṣoṣo, kí ó má sì jẹ́ ti àwọn àjèjì pẹ̀lú rẹ.”—Òwe 5:15-17.
“Ìkùdu tìrẹ” àti “kànga tìrẹ” jẹ́ àkànlò èdè tó tọ́ka sí aya àtàtà. Gbígbádùn ìbálòpọ̀ takọtabo pẹ̀lú rẹ̀ dà bí mímu omi títuni lára. Láìdàbí àwọn omi tí ń ṣàn ní ojúde, ìkùdu tàbí kànga jẹ́ àdáni. A sì gba ọkùnrin nímọ̀ràn pé aya tó fẹ́ sílé ni kó máa bímọ fún un, kì í ṣe pé kí ó máa bímọ kiri ìgboro, èyíinì ni, láàárín àwọn obìnrin mìíràn. Ní kedere, ìmọ̀ràn tí ibí yìí ń gba ọkùnrin ni pé kí ó ṣe olóòótọ́ sí aya rẹ̀.
Ọkùnrin ọlọgbọ́n náà ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Jẹ́ kí orísun omi rẹ jẹ́ èyí tí ó ní ìbùkún, kí o sì máa yọ̀ pẹ̀lú aya ìgbà èwe rẹ, egbin dídára lẹ́wà àti ewúrẹ́ olóòfà ẹwà ti orí òkè ńlá. Jẹ́ kí ọmú tirẹ̀ máa pa ọ́ bí ọtí ní gbogbo ìgbà. Kí o máa yọ ayọ̀ púpọ̀ jọjọ nínú ìfẹ́ rẹ̀ nígbà gbogbo.”—Òwe 5:18, 19.
“Orísun omi,” tàbí ojúsun, tọ́ka sí orísun ìgbádùn ìbálòpọ̀ takọtabo. Gbígbádùn ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkọ tàbí aya ẹni “ní ìbùkún”—ìyẹn ni pé ìṣètò Ọlọ́run ni. Fún ìdí yìí, a gba ọkùnrin níyànjú pé kí ó máa yọ̀ pẹ̀lú aya ìgbà èwe rẹ̀. Lójú rẹ̀, aya rẹ̀ dára ó sì lẹ́wà bí egbin, ojú rẹ̀ fani mọ́ra, ó sì rí rèǹtèrente bí ewúrẹ́ orí òkè ńlá.
Lẹ́yìn èyí ni Sólómọ́nì wá béèrè ìbéèrè mọ̀-ọ́n-nú méjì, ó ní: “Nítorí náà, ọmọ mi, èé ṣe tí ìwọ yóò fi máa yọ ayọ̀ púpọ̀ jọjọ nínú àjèjì obìnrin tàbí tí ìwọ yóò fi gbá oókan àyà obìnrin ilẹ̀ òkèèrè mọ́ra?” (Òwe 5:20) Àní sẹ́, kí ló lè sún ẹni tó ti ṣègbéyàwó dédìí níní ìbálòpọ̀ takọtabo lẹ́yìn òde ìgbéyàwó pẹ̀lú àwọn tó ń bá pàdé níbi iṣẹ́, níléèwé, tàbí níbòmíràn?
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni tó ti ṣègbéyàwó ní ìmọ̀ràn yìí: “Èyí ni mo sọ, ẹ̀yin ará, pé àkókò tí ó ṣẹ́ kù ti dín kù. Láti ìsinsìnyí lọ, kí àwọn tí wọ́n ní aya dà bí ẹni pé wọn kò ní.” (1 Kọ́ríńtì 7:29) Kí ni èyí wé mọ́? Ohun tí èyí wé mọ́ ni pé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi ní láti ‘máa bá a nìṣó ní wíwá ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́.’ (Mátíù 6:33) Nítorí náà, kò yẹ kí ọ̀ràn lọ́kọláya wá gba tọkọtaya lọ́kàn tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí wọn yóò fi wá fi ire Ìjọba náà sípò kejì nínú ìgbésí ayé wọn.
Ìkóra-Ẹni-Níjàánu Ṣe Kókó
Ìfẹ́ ìbálòpọ̀ takọtabo ṣeé ṣàkóso. Gbogbo àwọn tó bá sì fẹ́ rí ojú rere Jèhófà gbọ́dọ̀ ṣàkóso rẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣí wa létí pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́, sísọ yín di mímọ́, pé kí ẹ ta kété sí àgbèrè; pé kí olúkúlùkù yín mọ bí yóò ti ṣèkáwọ́ ohun èlò [ìyẹn, ara] tirẹ̀ nínú ìsọdimímọ́ àti ọlá.”—1 Tẹsalóníkà 4:3, 4.
Nítorí náà, kò yẹ kí àwọn ọ̀dọ́ fi ìwàǹwára kó wọnú ìgbéyàwó, ní gbàrà tí òòfà ìbálòpọ̀ bá bẹ̀rẹ̀ sí ru sókè nínú wọn. Ìgbéyàwó ń béèrè pé ká wọnú ẹ̀jẹ́, èèyàn sì gbọ́dọ̀ dàgbà dénú kí ó bàa lè pa ẹ̀jẹ́ yẹn mọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Ó sàn kéèyàn dúró, kí ó “ré kọjá ìgbà ìtànná òdòdó èwe”—èyíinì ni ìgbà tí òòfà ìbálòpọ̀ máa ń lágbára gan-an, tí ó sì lè tètè kó síni lórí. (1 Kọ́ríńtì 7:36) Ẹ sì wo bó ti jẹ́ ìwà òmùgọ̀ àti ìwà ẹ̀ṣẹ̀ tó, kí ẹni tó ti tójúúbọ́, tí ọ̀ràn ìgbéyàwó ń jẹ lọ́kàn, lọ ṣe ìṣekúṣe, kìkì nítorí pé kò tíì rí ẹni tó máa fẹ́!
“Àwọn Ìṣìnà Ẹni Burúkú Yóò Mú Òun Fúnra Rẹ̀”
Ìdí pàtàkì tí ìṣekúṣe fi lòdì ni pé Jèhófà—Olùfúnni ní ìyè àti Ẹni tó fún ẹ̀dá ènìyàn ní agbára ìbálòpọ̀—kórìíra ìwà yìí. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé nígbà tí Sólómọ́nì Ọba ń fúnni ní ìwúrí láti fọwọ́ dan-in dan-in mú ọ̀ràn ìwà mímọ́, ó sọ pé: “Nítorí àwọn ọ̀nà ènìyàn ń bẹ ní iwájú Jèhófà, ó sì ń ṣàgbéyẹ̀wò gbogbo òpó ọ̀nà rẹ̀.” (Òwe 5:21) Dájúdájú, kò sí ohun tó pa mọ́ lójú Ọlọ́run, “ẹni tí a óò jíhìn fún.” (Hébérù 4:13) Bó ti wù kéèyàn dọ́gbọ́n bo ìwà àìmọ́ takọtabo èyíkéyìí mọ́lẹ̀ tó, ohun tó sì wù kí ó jẹ́ àbájáde rẹ̀ ní ti ara àti láwùjọ, kò sí bí kò ṣe ní ba àárín àwa àti Jèhófà jẹ́. Ẹ ò rí i pé ìwà òmùgọ̀ gbáà ló jẹ́, kéèyàn tìtorí fàájì ìranù tí kò ju ìṣẹ́jú díẹ̀ lọ pàdánù àlàáfíà tó ti ní pẹ̀lú Ọlọ́run!
Lójú àwọn kan tó ń fi ìwà àìnítìjú ṣe ìṣekúṣe kiri, ó lè dà bí ẹni pé àṣegbé ni—àmọ́ àṣegbé kan ò sí. Sólómọ́nì kéde pé: “Àwọn ìṣìnà ẹni burúkú yóò mú òun fúnra rẹ̀, inú àwọn ìjàrá ẹ̀ṣẹ̀ òun fúnra rẹ̀ sì ni a ó ti gbá a mú. Òun ni ẹni tí yóò kú nítorí pé kò sí ìbáwí, àti nítorí pé nínú ọ̀pọ̀ yanturu ìwà òmùgọ̀ rẹ̀, ó ṣáko lọ.”—Òwe 5:22, 23.
Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ yẹ rárá kí ẹnikẹ́ni nínú wa ṣáko lọ? Ó ṣe tán, ìwé Òwe ti kìlọ̀ fún wa ṣáájú nípa àwọn ọ̀nà ẹ̀tàn ayé. Ṣebí ó tún sọ fún wa nípa àkóbá tí ìṣekúṣe máa ń ṣe—fún ìlera wa, dúkìá wa, okun wa, àti iyì wa. Pẹ̀lú gbogbo ìkìlọ̀ àgbọ́tẹ́lẹ̀ wọ̀nyí, kò tiẹ̀ yẹ rárá kí á bá ara wa nínú ipò tí a ó ti máa ké ọ̀kan-kò-jọ̀kan igbe “ǹ bá mọ̀.” Ó dájú pé bí a bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Jèhófà fi fún wa nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ onímìísí, a lè jẹ́ oníwà mímọ́ nínú ayé oníṣekúṣe.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀rọ̀ náà “àjèjì” tọ́ka sí àwọn tó yà kúrò nínú ohun tó bá Òfin mu, tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ kẹ̀yìn sí Jèhófà. Ìdí nìyẹn tí a fi pe aṣẹ́wó ní “àjèjì obìnrin.”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Ohun tí ìṣekúṣe máa ń yọrí sí nígbẹ̀yìn korò bí iwọ
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
“Máa yọ̀ pẹ̀lú aya ìgbà èwe rẹ”