Ìwà Títọ́ Ń ṣamọ̀nà Àwọn Adúróṣánṣán
BÍBÉLÌ sọ pé: “Ènìyàn, tí obìnrin bí, ọlọ́jọ́ kúkúrú ni, ó sì kún fún ṣìbáṣìbo.” (Jóòbù 14:1) Ìrora àti ìjìyà pọ̀ rẹpẹtẹ nínú ayé tí à ń gbé yìí. Họ́wù, àní ìgbésí ayé ojoojúmọ́ pàápàá lè kún fún hílàhílo àti pákáǹleke! Kí ni yóò ṣamọ̀nà wa la àwọn ipò líle koko yìí já, tí yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run?
Gbé àpẹẹrẹ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jóòbù yẹ̀ wò, ẹni tó gbé ayé ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ [3,500] sẹ́yìn, níbi tá a wá mọ̀ sí Arébíà lóde òní. Àjálù tí Sátánì mú bá ọkùnrin tó bẹ̀rù Ọlọ́run yìí mà pọ̀ o! Ó pàdánù gbogbo ohun ọ̀sìn rẹ̀, gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n pátá ló kú. Kété lẹ́yìn ìyẹn ni Sátánì wá fi oówo afòòró-ẹ̀mí kọlu Jóòbù láti orí títí dé àtẹ́lẹsẹ̀. (Jóòbù, orí kìíní àti ìkejì) Jóòbù ò mọ̀dí táwọn ohun búburú fi ń ṣẹlẹ̀ sóun. Síbẹ̀, “Jóòbù kò fi ètè rẹ̀ dẹ́ṣẹ̀.” (Jóòbù 2:10) Ó sọ pé: “Títí èmi yóò fi gbẹ́mìí mì, èmi kì yóò mú ìwà títọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi.” (Jóòbù 27:5) Bẹ́ẹ̀ ni o, ìwà títọ́ Jóòbù ló ṣamọ̀nà rẹ̀ ní gbogbo àkókò àdánwò rẹ̀.
Ìwà títọ́ túmọ̀ sí ìwà rere, tàbí ìwà tó dára délẹ̀délẹ̀, ó sì kan jíjẹ́ aláìlẹ́bi tàbí jíjẹ́ aláìní-àléébù lójú Ọlọ́run. Àmọ́ ṣá o, kò wá túmọ̀ sí ìjẹ́pípé nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe àwọn ẹ̀dá aláìpé, tí kò sí bí wọ́n ṣe lè kúnjú ìwọ̀n ìlànà Ọlọ́run délẹ̀délẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìwà títọ́ ẹ̀dá ènìyàn dúró fún ìfọkànsìn tí kò lábùlà tàbí tó pé pérépéré sí Jèhófà, sí ṣíṣe ìfẹ́ rẹ̀ àti mímú ète rẹ̀ ṣẹ. Irú ìfọkànsìn bẹ́ẹ̀ ló ń ṣamọ̀nà tàbí tó ń darí àwọn adúróṣánṣán lábẹ́ gbogbo ipò tí wọ́n bá wà àti ní gbogbo ìgbà. Apá àkọ́kọ́ nínú orí kọkànlá ìwé Òwe inú Bíbélì ṣàlàyé bí ìwà títọ́ ṣe lè ṣamọ̀nà wa nínú onírúurú ọ̀ràn ìgbésí ayé, ó sì mú un dá wa lójú pé yóò yọrí sí ọ̀pọ̀ ìbùkún. Pẹ̀lú ìfẹ́ jíjinlẹ̀ nígbà náà, ẹ jẹ́ ká yíjú sí ohun tá a kọ síbẹ̀.
Ìwà Títọ́ Ń Sọni Di Olóòótọ́ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ajé
Nígbà tí Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì ń sọ̀rọ̀ nípa ìlànà jíjẹ́ aláìlábòsí, ó lo èdè ewì dípò èdè òfin, ó ní: “Òṣùwọ̀n aláwẹ́ méjì tí a fi ń rẹ́ni jẹ jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà, ṣùgbọ́n òkúta àfiwọn-ìwúwo tí ó pé pérépéré jẹ́ ìdùnnú rẹ̀.” (Òwe 11:1) Àkọ́kọ́ nínú ọ̀nà mẹ́rin tí ọ̀rọ̀ yìí ti fara hàn nínú ìwé Òwe nìyí, níbi tá a ti lo òṣùwọ̀n àti òkúta àfiwọn-ìwúwo láti fi hàn pé Jèhófà fẹ́ kí àwọn olùjọ́sìn òun jẹ́ aláìlábòsí lẹ́nu iṣẹ́ ajé wọn.—Òwe 16:11; 20:10, 23.
Aásìkí àwọn tó ń lo òṣùwọ̀n aláwẹ́ méjì tí a fi ń rẹni jẹ—tàbí ti àwọn tó ń ṣàbòsí—lè wọni lójú. Àmọ́, ṣé a ó dìídì fẹ́ kọ ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọ́run fún rere àti búburú sílẹ̀ nípa ṣíṣe màgòmágó ni? A ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ bí ìwà títọ́ bá ń ṣamọ̀nà wa. À ń sá fún ṣíṣe àbòsí nítorí pé òkúta àfiwọn-ìwúwo pípé, ìyẹn ìwọ̀n tí ó ṣe rẹ́gí túmọ̀ sí àìlábòsí, ó sì ń múnú Jèhófà dùn.
“Ọgbọ́n Wà Pẹ̀lú Àwọn Amẹ̀tọ́mọ̀wà”
Sólómọ́nì Ọba ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Ìkùgbù ha ti dé bí? Nígbà náà, àbùkù yóò dé; ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.” (Òwe 11:2) Ìkùgbù—ì báà jẹ́ ìgbéraga, ṣíṣe àìgbọràn, tàbí ìlara—ń mú ẹ̀tẹ́ wá. Ṣùgbọ́n, mímọ̀wọ̀n ara wa jẹ́ ipa ọ̀nà ọgbọ́n. Ẹ wo bí àwọn àpẹẹrẹ inú Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn pé òótọ́ ni òwe yìí!
Kórà ọmọ Léfì tó jẹ́ onílara kó àwọn ọlọ̀tẹ̀ sòdí lòdì sí ọlá àṣẹ Mósè àti Áárónì, tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ tí Jèhófà yàn sípò. Kí ló tẹ̀yìn ìwà ìkùgbù yẹn jáde? ‘Ilẹ̀ la ẹnu, ó sì gbé’ àwọn kan lára àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà mì, nígbà tí iná jó àwọn tó kù run, títí kan Kórà. (Númérì 16:1-3, 16-35; 26:10; Diutarónómì 11:6) Àbùkù gbáà ni! Tún ronú nípa Úsà, ẹni tó fi ìkùgbù na ọwọ́ rẹ̀ jáde, tó sì gbá àpótí májẹ̀mú mú kí ó má bàa ṣubú. Ojú ẹsẹ̀ ni Ọlọ́run fi ikú pa á. (2 Sámúẹ́lì 6:3-8) Ẹ ò rí i pé ó yẹ kéèyàn máa sá fún ìkùgbù!
Ẹni tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tó sì mẹ̀tọ́mọ̀wà kì í kàbùkù kódà bó tiẹ̀ ṣàṣìṣe. Bí Jóòbù tiẹ̀ jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ ní ọ̀pọ̀ ọ̀nà, síbẹ̀ aláìpé ni. Àwọn àdánwò tó bá a fi hàn pé àwọn kan lára ohun tó ń rò jẹ́ èrò òdì pátápátá. Nígbà tí Jóòbù ń gbìyànjú àtigbèjà ara rẹ̀ lójú àwọn tó ń fẹ̀sùn èké kàn án, ó dà bíi pé ó kọjá àyè rẹ̀. Ó tiẹ̀ sọ̀rọ̀ bí ẹni pé òun jẹ́ olódodo ju Ọlọ́run lọ. (Jóòbù 35:2, 3) Báwo ni Jèhófà ṣe tún èrò Jóòbù ṣe?
Nípa títọ́ka sí ilẹ̀ ayé, òkun, ojú ọ̀run tó kún fún ìràwọ̀, àwọn ẹranko kan, àti àwọn ohun àgbàyanu ìṣẹ̀dá mìíràn, Jèhófà kọ́ Jóòbù lẹ́kọ̀ọ́ kan. Ó jẹ́ kó mọ bí ènìyàn ṣe kéré tó ní ìfiwéra pẹ̀lú bí Ọlọ́run ṣe tóbi lọ́lá tó. (Jóòbù, orí 38 sí 41) Nínú gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ, kò síbi tó ti mẹ́nu kan ìdí tí Jóòbù fi ń jìyà. Kò sì pọn dandan pé kó ṣe bẹ́ẹ̀. Jóòbù jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Ó fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ gbà pé ìyàtọ̀ ńlá ló wa láàárín òun àti Ọlọ́run, láàárín àìpé àti àìlera tòun àti òdodo àti agbára Jèhófà. Ó sọ pé: “Mo . . . yíhùn padà, mo sì ronú pìwà dà nínú ekuru àti eérú.” (Jóòbù 42:6) Ìwà títọ́ Jóòbù sún un láti tẹ́wọ́ gba ìbáwí láìjanpata. Àwa náà ńkọ́? Ǹjẹ́ ìwà títọ́ máa ń sún wa múra tán láti tẹ́wọ́ gba ìbáwí àti ìtọ́ni tó yẹ ká gbà?
Mósè náà mẹ̀tọ́mọ̀wà, ó sì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Nígbà tó ń ṣe àṣekúdórógbó iṣẹ́ níbi tó ti ń bójú tó ìṣòro àwọn ẹlòmíràn, Jẹ́tírò, tó jẹ́ baba ìyàwó rẹ̀, fún un nímọ̀ràn kan tó gbéṣẹ́ pé: Yan àwọn ẹrù iṣẹ́ kan fún àwọn ọkùnrin mìíràn tí ó tóótun. Mósè mọ ibi tí agbára òun mọ, ó si fi ọgbọ́n tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn náà. (Ẹ́kísódù 18:17-26; Númérì 12:3) Ẹni tó bá mẹ̀tọ́mọ̀wà kì í lọ́ tìkọ̀ láti gbé ẹrù iṣẹ́ lé àwọn ẹlòmíràn tó bá tóótun lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì í bẹ̀rù pé gbígbé ẹrù iṣẹ́ lé àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ lè mú kí ọ̀pá àṣẹ bọ́ lọ́wọ́ òun. (Númérì 11:16, 17, 26-29) Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa ń hára gàgà láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. (1 Tímótì 4:15) Ǹjẹ́ kò yẹ kí àwa náà rí bẹ́ẹ̀?
‘Ọ̀nà Ẹni Tí Kò Lẹ́bi Tọ́’
Nítorí tí Sólómọ́nì mọ̀ pé ìwà títọ́ kì í fi gbogbo ìgbà yọ adúróṣánṣán nínú ewu tàbí àjálù, ó sọ pé: “Ìwà títọ́ àwọn adúróṣánṣán ni ohun tí ń ṣamọ̀nà wọn, ṣùgbọ́n ìfèrúyípo àwọn tí ń ṣe àdàkàdekè ni yóò fi wọ́n ṣe ìjẹ.” (Òwe 11:3) Láìsí àní-àní, ìwà títọ́ máa ń ṣamọ̀nà àwọn adúróṣánṣán láti ṣe ohun tí ó tọ́ lójú Ọlọ́run, kódà lábẹ́ ipò líle koko, ó sì ń ṣe wọ́n láǹfààní ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀. Jóòbù rọ̀ mọ́ ìwà títọ́ rẹ̀, Jèhófà sì “bù kún ìgbẹ̀yìn Jóòbù ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ ju ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ rẹ̀ lọ.” (Jóòbù 42:12) Àwọn tó ń ṣe àdàkàdekè lè máa rò pé àwọn ń rí àwọn ẹlòmíràn kó nífà, ó sì lè dà bí ẹni pé nǹkan ṣẹnuure fún wọn fúngbà díẹ̀. Àmọ́, bópẹ́ bóyá ẹ̀tàn wọn ni yóò pa wọ́n run.
Ọlọgbọ́n ọba náà sọ pé: “Àwọn ohun tí ó níye lórí kì yóò ṣàǹfààní rárá ní ọjọ́ ìbínú kíkan, ṣùgbọ́n òdodo ni yóò dáni nídè lọ́wọ́ ikú.” (Òwe 11:4) Ìwà òmùgọ̀ gbáà ni kéèyàn máa ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó nítorí àtijèrè ọrọ̀ àlùmọ́nì, láìní àyè fún ìdákẹ́kọ̀ọ́, àdúrà, lílọ sípàdé, àti òde ẹ̀rí—ìyẹn àwọn ìgbòkègbodò tó ń mú kífẹ̀ẹ́ wa fún Ọlọ́run jinlẹ̀ sí i, tó sì ń fún ìfọkànsìn wa lókun! Kò sí bí ọrọ̀ ṣe lè pọ̀ tó tí yóò gbani lọ́wọ́ ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀. (Mátíù 24:21) Kìkì òdodo ẹni dídúróṣánṣán nìkan ló lè gbani. (Ìṣípayá 7:9, 14) Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti fi ọ̀rọ̀ Sefanáyà sọ́kàn, pé: “Kí ọjọ́ ìbínú Jèhófà tó wá sórí yín, ẹ wá Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́kàn tútù ilẹ̀ ayé, tí ń fi ìpinnu ìdájọ́ Tirẹ̀ ṣe ìwà hù. Ẹ wá òdodo, ẹ wá ọkàn-tútù.” (Sefanáyà 2:2, 3) Ní báyìí ná, ẹ jẹ́ kó jẹ́ ohun tá à ń lépa pé a óò máa ‘fi àwọn ohun ìní wa tí ó níye lórí bọlá fún Jèhófà.’—Òwe 3:9.
Bí Sólómọ́nì ṣe túbọ̀ ń sọ̀rọ̀ nípa ìjẹ́pàtàkì lílépa òdodo, ó jẹ́ ká rí ohun tí jíjẹ́ aláìlẹ́bi ń yọrí sí àti ohun tí jíjẹ́ ẹni burúkú ń yọrí sí. Ó sọ pé: “Òdodo ẹni tí kò lẹ́bi ni yóò mú ọ̀nà rẹ̀ tọ́, ṣùgbọ́n ẹni burúkú yóò ṣubú sínú ìwà burúkú òun fúnra rẹ̀. Òdodo àwọn adúróṣánṣán ni yóò dá wọn nídè, ṣùgbọ́n ìfàsí-ọkàn àwọn tí ń ṣe àdàkàdekè ni a ó fi mú àwọn fúnra wọn. Nígbà tí ènìyàn burúkú bá kú, ìrètí rẹ̀ a ṣègbé; àní ìfojúsọ́nà tí a gbé ka orí agbára níní ti ṣègbé. Olódodo ni a gbà sílẹ̀ àní lọ́wọ́ wàhálà, ẹni burúkú sì wọlé dípò rẹ̀.” (Òwe 11:5-8) Ẹni tí kò lẹ́bi kì í ṣubú ni ọ̀nà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì í kó sí pańpẹ́ nínú àwọn ìṣe rẹ̀. Ọ̀nà rẹ̀ tọ́. Níkẹyìn, adúróṣánṣán yóò rí ìdáǹdè kúrò nínú wàhálà. Ó lè dà bíi pé ẹni burúkú ní agbára, àmọ́ kò lè rí irú ìdáǹdè bẹ́ẹ̀.
“Ìlú A Kún fún Ayọ̀”
Ìwà títọ́ àwọn adúróṣánṣán àti ìwà ibi àwọn aṣebi tún máa ń nípa lórí àwọn ẹlòmíràn. Ọba Ísírẹ́lì náà sọ pé: “Ẹnu ara rẹ̀ ni apẹ̀yìndà fi ń run ọmọnìkejì rẹ̀, ṣùgbọ́n ìmọ̀ ni a fi ń gba olódodo sílẹ̀.” (Òwe 11:9) Ta ló lè sẹ́ pé ìbanilórúkọjẹ́, òfófó, ọ̀rọ̀ rírùn, àti ẹjọ́ wẹ́wẹ́ kì í pa àwọn ẹlòmíràn lára? Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, ńṣe ni ọ̀rọ̀ ẹnu olódodo máa ń mọ́ gaara, tó máa ń jẹ́ èyí tó ronú sí dáadáa kó tó sọ, tó sì máa ń gba ti àwọn ẹlòmíràn rò. Ìmọ̀ ni a fi ń gbà á sílẹ̀ nítorí pé ìwà títọ́ rẹ̀ á jẹ́ kó ní ẹ̀rí púpọ̀ láti fi hàn pé irọ́ ni àwọn tó ń fẹ̀sùn kàn án ń pa.
Ọba náà ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Nítorí ìwà rere àwọn olódodo, ìlú a kún fún ayọ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ẹni burúkú bá ṣègbé, igbe ìdùnnú a ta.” (Òwe 11:10) Ṣàṣà lẹni tí kì í nífẹ̀ẹ́ àwọn olódodo, wọ́n sì máa ń jẹ́ kí àwọn aládùúgbò wọn kún fáyọ̀. Kò sẹ́ni tó máa ń fẹ́ràn “àwọn ẹni burúkú” dénú. Nígbà tí ẹni burúkú bá kú, àwọn èèyàn lápapọ̀ kì í sábà ṣọ̀fọ̀ wọn. Ó dájú pé kò sẹ́ni tó máa banú jẹ́ nígbà tí Jèhófà bá ‘ké àwọn ẹni burúkú kúrò lórí ilẹ̀ ayé, tó sì fa àwọn aládàkàdekè tu kúrò lórí rẹ̀.’ (Òwe 2:21, 22) Dípò ìyẹn, ayọ̀ ló máa wà nítorí pé wọn kò sí mọ́. Ṣùgbọ́n àwa ńkọ́? Á dáa ká yẹ ara wa wò láti mọ̀ bóyá ọ̀nà tá a gbà ń hùwà ń fi kún ayọ̀ àwọn ẹlòmíràn.
“Ìlú A Ní Ìgbéga”
Sólómọ́nì tún sọ̀rọ̀ síwájú sí i nípa ipa tí adúróṣánṣán àti ẹni ibi ń ní lórí àwọn ará àdúgbò wọn, ó ní: “Nítorí ìbùkún àwọn adúróṣánṣán, ìlú a ní ìgbéga, ṣùgbọ́n nítorí ẹnu àwọn ẹni burúkú, a di èyí tí a ya lulẹ̀.”—Òwe 11:11.
Àwọn aráàlú tó tẹ̀ lé ipa ọ̀nà ìdúróṣánṣán máa ń fi kún àlàáfíà àti ìlera, wọ́n sì máa ń gbé àwọn ẹlòmíràn ró láwùjọ. Nípa bẹ́ẹ̀, ìlú á ní ìgbéga—ìyẹn ni pé á láásìkí. Àwọn tó máa ń sọ ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́, tí wọ́n máa ń sọ ọ̀rọ̀ tí ń pani lára, tí wọ́n sì máa ń fi dúdú pe funfun máa ń fa àìbalẹ̀ ọkàn, àìláyọ̀, ìyapa àti wàhálà. Èyí máa ń rí bẹ́ẹ̀, àgàgà bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá lọ wà nípò àṣẹ. Irú ìlú bẹ́ẹ̀ máa ń di rúdurùdu, ó máa ń kún fún ìwà ìbàjẹ́, ìwà rere àti ọrọ̀ ajé rẹ̀ sì máa ń jó àjórẹ̀yìn.
Ìlànà tó wà nínú Òwe 11:11 kan àwọn ènìyàn Jèhófà gan-an, bí wọ́n ti ń bá ara wọn kẹ́gbẹ́ pọ̀ láwọn ìjọ wọn tó dà bí ìlú. Ìjọ tí àwọn ẹni tẹ̀mí—ìyẹn àwọn adúróṣánṣán tí ìwà títọ́ ń darí—bá pọ̀ sí máa ń jẹ́ àwùjọ àwọn aláyọ̀, tí wọ́n jẹ́ aláápọn, tí wọ́n ń ran ara wọn lọ́wọ́, tí wọ́n sì ń bọlá fún Ọlọ́run. Jèhófà máa ń bù kún ìjọ náà, ó sì máa ń láásìkí nípa tẹ̀mí. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn díẹ̀ tí wọ́n jẹ́ aláìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn, tí wọ́n máa ń ṣe lámèyítọ́, tí wọ́n sì máa ń fi ìkorò ọkàn sọ̀rọ̀ nípa bí nǹkan ṣe ń lọ, dà bí “gbòǹgbò onímájèlé” tó lè tàn kálẹ̀, kí ó sì ṣèpalára fáwọn ẹlòmíràn tí kò mọ́wọ́ mẹsẹ̀ tẹ́lẹ̀. (Hébérù 12:15) Irú àwọn bẹ́ẹ̀ sábà máa ń wá ipò ọlá àti òkìkí. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń tan àhesọ kálẹ̀ pé ìwà ìrẹ́nijẹ, ìwà ẹlẹ́yàmẹ̀yà, tàbí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ tàbí látọ̀dọ̀ àwọn alàgbà. Láìsí àní-àní, ẹnu wọn lè fa ìyapa nínú ìjọ. Ǹjẹ́ kò yẹ ká di etí wa sí ọ̀rọ̀ wọn, ká sì gbìyànjú láti jẹ́ ẹni tẹ̀mí tó ń fi kún àlàáfíà àti ìṣọ̀kan ìjọ?
Sólómọ́nì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Ẹni tí ọkàn-àyà kù fún ti tẹ́ńbẹ́lú ọmọnìkejì rẹ̀, ṣùgbọ́n ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀ gbígbòòrò ni ẹni tí ó dákẹ́. Ẹni tí ń rìn káàkiri gẹ́gẹ́ bí afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́ a máa tú ọ̀rọ̀ àṣírí síta, ṣùgbọ́n ẹni tí ó jẹ́ olùṣòtítọ́ ní ẹ̀mí a máa bo ọ̀ràn mọ́lẹ̀.”—Òwe 11:12, 13.
Ẹ ò rí i pé wàhálà ńlá ni ẹni tí kò ní òye, tàbí ẹni tí “ọkàn-àyà kù fún” ń dá sílẹ̀! Ó tiẹ̀ lè bá bórobòro rẹ̀ dórí fífọ̀rọ̀ èké bani jẹ́ tàbí kíkẹ́gàn. Àwọn alàgbà tí a yàn sípò gbọ́dọ̀ tètè fi òpin sí irú ipa búburú bẹ́ẹ̀. Láìdàbí “ẹni tí ọkàn-àyà kù fún,” ẹni tó ní òye mọ ìgbà tó yẹ kí òun dákẹ́. Dípò kí ó tú ọ̀rọ̀ àṣírí síta, á kúkú yàn láti panu mọ́. Ẹni tó ní ìfòyemọ̀ jẹ́ “olùṣòtítọ́ ní ẹ̀mí,” nítorí ó mọ̀ pé ahọ́n tí a kò bá kó níjàánu lè fa ọ̀pọ̀ jàǹbá. Ó jẹ́ adúróṣinṣin sí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, kì í sọ ọ̀rọ̀ àṣírí tó lè pa wọ́n lára síta. Ẹ ò rí i pé ìbùkún ńlá ni irú àwọn olùpa ìwà títọ́ mọ́ bẹ́ẹ̀ jẹ́ fún ìjọ!
Jèhófà ń fún wa ní ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ tẹ̀mí tá à ń pèsè lábẹ́ ìdarí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” ká lè máa rìn lọ́nà àwọn aláìlẹ́bi. (Mátíù 24:45) A tún ń rí ọ̀pọ̀ ìrànlọ́wọ́ gbà nípasẹ̀ àwọn Kristẹni alàgbà nínú àwọn ìjọ wa tó dà bí ìlú. (Éfésù 4:11-13) A dúpẹ́ gan-an fún nǹkan wọ̀nyí, nítorí pé “Nígbà tí kò bá sí ìdarí jíjáfáfá, àwọn ènìyàn a ṣubú; ṣùgbọ́n ìgbàlà wà nínú ògìdìgbó àwọn agbani-nímọ̀ràn.” (Òwe 11:14) Ohun yòówù tí ì báà ṣẹlẹ̀, ẹ jẹ́ ká fi tọkàntọkàn pinnu pé a óò máa ‘rìn nínú ìwà títọ́ wa.’—Sáàmù 26:1.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 26]
Ìwà òmùgọ̀ gbáà ni kéèyàn máa ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó nítorí àtijèrè ọrọ̀ àlùmọ́nì, kó sì wá pa ìgbòkègbodò Ìjọba Ọlọ́run tì!
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ìwà títọ́ Jóòbù ṣamọ̀nà rẹ̀, Jèhófà sì bù kún un
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ìkùgbù Úsà ló ṣekú pa á