“Àgọ́ Àwọn Adúróṣánṣán Yóò Gbilẹ̀”
NÍGBÀ tí ìjì Amágẹ́dọ́nì bá bẹ̀rẹ̀ sí í jà tó sì pa ayé búburú Sátánì run, “a ó pa ilé àwọn ènìyàn burúkú rẹ́ ráúráú.” Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí “àgọ́ àwọn adúróṣánṣán?” Ní tiwọn o, àgọ́ wọn “yóò gbilẹ̀” nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ń mú bọ̀.—Òwe 14:11.
Àmọ́, kó tó dìgbà tí Ọlọ́run yóò ‘ké àwọn ẹni burúkú kúrò lórí ilẹ̀ ayé tí yóò sì fa àwọn aládàkàdekè tu kúrò lórí rẹ̀,’ àwọn olóòótọ́ yóò ṣì máa gbé pẹ̀lú wọn. (Òwe 2:21, 22) Ǹjẹ́ nǹkan lè dára fáwọn olóòótọ́ nínú irú ipò yìí? Ìwé Òwe orí 14 ẹsẹ 1 sí ẹsẹ 11 fi hàn pé tá a bá ń lo ọgbọ́n nínú ọ̀nà tá à ń gbà sọ̀rọ̀ àti nínú ìṣe wa, lákòókò yìí pàápàá, ayé wa lè dára dé àyè kan, a ò sì ní fi bẹ́ẹ̀ níṣòro.
Bí Ọgbọ́n Ṣe Ń Gbé Ilé Ró
Nígbà tí Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì ń sọ̀rọ̀ lórí ipa tí ìwà ìyàwó máa ń ní lórí ire ìdílé, ó sọ pé: “Obìnrin tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ti tòótọ́ ti kọ́ ilé rẹ̀, ṣùgbọ́n èyí tí ó jẹ́ òmùgọ̀ a fi ọwọ́ ara rẹ̀ ya á lulẹ̀.” (Òwe 14:1) Báwo lobìnrin tó gbọ́n ṣe ń gbé ilé rẹ̀ ró? Obìnrin tó gbọ́n máa ń bọ̀wọ̀ fún ètò ipò orí tí Ọlọ́run ṣe. (1 Kọ́ríńtì 11:3) Kì í jẹ́ kí ẹ̀mí jẹ́-n-ṣe-tèmi tó gba ayé Sátánì kan nípa lórí òun. (Éfésù 2:2) Ó máa ń tẹrí ba fún ọkọ rẹ̀ ó sì máa ń sọ̀rọ̀ ọkọ̀ rẹ̀ dáadáa, èyí sì ń jẹ́ kí ọ̀wọ̀ táwọn mìíràn ní fún ọkọ rẹ̀ pọ̀ sí i. Obìnrin tó gbọ́n kì í fi ẹ̀kọ́ ilé àti ẹ̀kọ́ tẹ̀mí àwọn ọmọ rẹ̀ ṣeré rárá. Tọkàntara ló fi ń ṣiṣẹ́ fún àǹfààní ìdílé rẹ̀, ó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ mú kí ayọ̀ wà nínú ìdílé kí ara sì tù wọ́n. Ọ̀nà tó ń gbà ṣètò ilé rẹ̀ àti ṣíṣọ́ tó máa ń ṣọ́wó ná fi hàn pé olóye èèyàn ni. Obìnrin tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n lóòótọ́ máa ń ṣe ipa tirẹ̀ láti mú kí ìgbésí ayé àwọn ará ilé rẹ̀ dára sí i kí wọ́n má sì fi bẹ́ẹ̀ níṣòro.
Òmùgọ̀ obìnrin ní tiẹ̀ kì í bọ̀wọ̀ fún ètò ipò orí tí Ọlọ́run ṣe. Ẹnu kì í fì í láti sọ̀rọ̀ ọkọ rẹ̀ láìdáa. Nítorí pé kò mowó ṣọ́ ná, ìnákúnàá ló máa ń ná owó ìdílé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé owó náà kò rọrùn láti rí. Ó tún máa ń fi àkókò ṣòfò. Nítorí èyí, ńṣe ni gbogbo ilé rẹ̀ máa ń dọ̀tí tá sì rí wúruwùru, àwọn ọmọ rẹ̀ ò sì ní gbádùn nípa tara àti nípa tẹ̀mí. Ká sòótọ́, ńṣe ni òmùgọ̀ obìnrin ń fọwọ́ ara rẹ̀ ya ilé rẹ̀ lulẹ̀.
Kí la fi ń mọ ọlọ́gbọ́n yàtọ̀ sí òmùgọ̀? Òwe 14:2 sọ pé: “Ẹni tí ń rìn nínú ìdúróṣánṣán rẹ̀ ń bẹ̀rù Jèhófà, ṣùgbọ́n ẹni tí ó jẹ́ oníwà wíwọ́ ní àwọn ọ̀nà rẹ̀ ń tẹ́ńbẹ́lú Rẹ̀.” Adúróṣánṣán èèyàn máa ń bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, “ìbẹ̀rù Jèhófà [sì] ni ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ọgbọ́n.” (Sáàmù 111:10) Ẹni tó gbọ́n lóòótọ́ mọ̀ pé ojúṣe òun ni láti “bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí [òun] sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.” (Oníwàásù 12:13) Àmọ́ ti òmùgọ̀ èèyàn ò rí bẹ́ẹ̀, torí pé ìwà tí kò bá àwọn ìlànà rere Ọlọ́run mu ló ń hù. Ìwàkíwà kún ọwọ́ rẹ̀. Ńṣe nirú ẹni bẹ́ẹ̀ ń tẹ́ńbẹ́lú Ọlọ́run, tó sì ń sọ nínú ọkàn rẹ̀ pé: “Jèhófà kò sí.”—Sáàmù 14:1.
Bí A Ṣe Lè Fi Ọgbọ́n Ṣọ́ Ètè Wa
Irú ọ̀rọ̀ wo ló máa ń jáde lẹ́nu ẹni tó bẹ̀rù Jèhófà àtẹni tó ń tẹ́ńbẹ́lú Rẹ̀? Sólómọ́nì Ọba sọ pé:“Ọ̀pá ìrera ń bẹ ní ẹnu òmùgọ̀, ṣùgbọ́n ètè àwọn ọlọ́gbọ́n yóò máa ṣọ́ wọn.” (Òwe 14:3) Nítorí pé òmùgọ̀ èèyàn kò ní ọgbọ́n tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, kì í wá àlàáfíà bẹ́ẹ̀ ni kì í fòye báni lò. Ọgbọ́n ayé yìí, ọgbọ́n ẹranko, àti ti ẹ̀mí èṣù ló ń darí rẹ̀. Ọ̀rọ̀ tó lè fa asọ̀ àtọ̀rọ̀ ìgbéraga ló máa ń sọ jáde lẹ́nu. Ọ̀rọ̀ ìgbéraga ẹnu rẹ̀ yìí sì máa ń kó òun àtàwọn mìíràn sí yọ́ọ́yọ́ọ́.—Jákọ́bù 3:13-18.
Ńṣe ni ètè ọlọ́gbọ́n èèyàn máa ń ṣọ́ ọ, ó sì ń jẹ́ kó ní ìfọ̀kànbalẹ̀. Lọ́nà wo? Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Ẹnì kan wà tí ń sọ̀rọ̀ láìronú bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà, ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìmúniláradá.” (Òwe 12:18) Ọlọ́gbọ́n èèyàn kì í fi ìwàǹwára sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ni kì í sọ ọ̀rọ̀ tó máa dun àwọn èèyàn. Ó kọ́kọ́ máa ń ṣàṣàrò nínú ọkàn rẹ̀ kó tó fèsì ọ̀rọ̀. (Òwe 15:28) Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó máa ń ronú sí kó tó sọ máa ń mára tuni, ìṣírí ló sì máa ń jẹ́ fáwọn tó ní ìdààmú ọkàn ó sì ń mú kára tu àwọn tó wà nínú ìpọ́njú. Dípò kí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ máa múnú bí èèyàn, ńṣe ló ń mú kí àlàáfíà pọ̀ sí i, ó sì ń mú kára àwọn èèyàn túbọ̀ balẹ̀.
Bí A Ṣe Lè Máa Lo Ọgbọ́n Nínú Gbogbo Ìdáwọ́lé Wa
Lẹ́yìn èyí, Sólómọ́nì sọ àgbà òwe kan tó dà bíi pé ó ń sọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì ká máa gbé àwọn àǹfààní àti ìpalára tó wà nínú ohun tá a fẹ́ dáwọ́ lé yẹ̀ wò. Ó ní: “Níbi tí àwọn ẹran ọ̀sìn kò sí, ibùjẹ ẹran a mọ́, ṣùgbọ́n irè oko pọ̀ yanturu nítorí agbára akọ màlúù.”—Òwe 14:4.
Nígbà tí ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ ìtumọ̀ òwe yìí, ó sọ pé: “Ibùjẹ ẹran tó ṣófo túmọ̀ sí pé kò sí màlúù láti fún lóúnjẹ, nípa bẹ́ẹ̀, èèyàn ò ní ṣe wàhálà láti máa palẹ̀ ìdọ̀tí ẹran mọ́ tàbí bójú tó ẹran, ìnáwó á sì dín kù. Àmọ́, apá kejì ẹsẹ kẹrin sọ àléébù tó wà nínú ‘àǹfààní’ yìí, ìyẹn ni pé, láìlo màlúù, ìkórè ò ní pọ̀ yanturu.” Àgbẹ̀ gbọ́dọ̀ fọgbọ́n yan èyí tó bá dára jù fún un.
Ǹjẹ́ ìlànà inú òwe yìí ò ní wúlò nígbà tá a bá ń ronú láti pààrọ̀ iṣẹ́, tá à ń ronú irú ilé tá a fẹ́ máa gbé, bóyá ká ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, ká ní ohun ọ̀sìn nínú ilé, àtàwọn nǹkan mìíràn bẹ́ẹ̀? Ọlọ́gbọ́n èèyàn á kọ́kọ́ gbé àǹfààní àti ìpalára tó wà nínú ohun tó fẹ́ dáwọ́ lé yẹ̀ wò dáadáa, bóyá ó tó ohun téèyàn ń ṣe wàhálà tàbí náwó lé lórí.
Ẹlẹ́rìí Tó Jẹ́ Ọlọgbọ́n
Sólómọ́nì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ẹlẹ́rìí tí ó jẹ́ olùṣòtítọ́ kì yóò purọ́, ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké ń gbé irọ́ pátápátá yọ.” (Òwe 14:5) Aburú kékeré kọ́ ni irọ́ ẹlẹ́rìí èké máa ń fà. Torí pé àwọn ọkùnrin tí kò dára fún ohunkóhun parọ́ mọ́ Nábótì ará Jésíréélì ló jẹ́ kí wọ́n sọ ọ́ lókùúta pa. (1 Àwọn Ọba 21:7-13) Àbí kì í ṣe àwọn ẹlẹ́rìí èké ló jáde wá parọ́ mọ́ Jésù, tí èyí sì wá yọrí sí pípa tí wọ́n pa á? (Mátíù 26:59-61) Bákan náà làwọn ẹlẹ́rìí èké parọ́ mọ́ Sítéfánù, ẹni àkọ́kọ́ lára àwọn ọmọ ẹ̀yin Jésù tí wọ́n pa nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀.—Ìṣe 6:10, 11.
Àṣírí òpùrọ́ èèyàn lè má tètè tú, àmọ́ ìwọ wo ohun tó máa gbẹ̀yìn ayé rẹ̀. Bíbélì sọ pé Jèhófà kórìíra “ẹlẹ́rìí èké tí ń gbé irọ́ yọ.” (Òwe 6:16-19) Adágún tí ń fi iná àti imí ọjọ́ jó, ìyẹn ikú kejì, ni yóò jẹ́ ìpín irú ẹni bẹ́ẹ̀ àtàwọn oníwà ibi mìíràn bí apààyàn, alágbèrè àti abọ̀rìṣà.—Ìṣípayá 21:8.
Ẹlẹ́rìí òdodo kì í parọ́ tó bá ń jẹ́rìí ọ̀rọ̀ tó ti búra lé ṣáájú. Kò tiẹ̀ ní fi irọ́ gbe ẹ̀rí tó máa jẹ́ lẹ́sẹ̀. Àmọ́ o, èyí ò túmọ̀ sí pé ó gbọ́dọ̀ sọ gbogbo ohun tó mọ̀ nípa ọ̀ràn kan fáwọn tó lè fẹ́ ṣàìdáa sáwọn èèyàn Jèhófà. Àwọn baba ńlá ìgbàanì, Ábúráhámù àti Ísákì, fi àwọn ọ̀rọ̀ kan pa mọ́ fáwọn kan tí kì í ṣe olùjọ́sìn Jèhófà. (Jẹ́nẹ́sísì 12:10-19; 20:1-18; 26:1-10) Ráhábù ará Jẹ́ríkò darí àwọn ìránṣẹ́ ọba gba ọ̀nà mìíràn. (Jóṣúà 2:1-7) Jésù fúnra ẹ̀ ṣẹ́ ọ̀rọ̀ kù nígbà tó rí i pé tóun bá sọ gbogbo ẹ̀ tán yóò kó òun sí wàhálà tí ò yẹ. (Jòhánù 7:1-10) Ó sọ pé: “Ẹ má ṣe fi ohun tí ó jẹ́ mímọ́ fún àwọn ajá.” Kí nídìí? Ìdí ni pé “kí wọ́n má bàa . . . yíjú padà, kí wọ́n sì fà yín ya.”—Mátíù 7:6.
Bí “Ìmọ̀ [Ṣe] Jẹ́ Ohun Rírọrùn”
Ṣé gbogbo èèyàn ló ní ọgbọ́n? Òwe 14:6 sọ pé: “Olùyọṣùtì ti wá ọ̀nà àtirí ọgbọ́n, kò sì sí; ṣùgbọ́n sí olóye, ìmọ̀ jẹ́ ohun rírọrùn.” Olùyọṣùtì lè máa wá ọgbọ́n, àmọ́ ọwọ́ rẹ̀ kò lè tẹ ọgbọ́n tòótọ́. Níwọ̀n bí ìgbéraga olùyọṣùtì ti ń mú kó kẹ́gàn àwọn ohun tó jẹ́ ti Ọlọ́run, kò ṣeé ṣe fún un láti ní ohun tó ń mú kéèyàn ní ọgbọ́n, ìyẹn ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run tòótọ́ náà. Ìgbéraga àti ìjọra-ẹni-lójú kò jẹ́ kó lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run kó sì ní ọgbọ́n. (Òwe 11:2) Kí ló tiẹ̀ ń wá ọgbọ́n fún pàápàá? Òwe yìí ò sọ, àmọ́ ó ṣeé ṣe kó jẹ́ tìtorí káwọn èèyàn lè máa rò pé òun gbọ́n ló ṣe ń wá ọgbọ́n kiri.
Ní ti olóye èèyàn, “ohun rírọrùn” ni “ìmọ̀ jẹ́.” Ìtumọ̀ tí wọ́n fún òye ni “kéèyàn lè fi ọpọlọ gbé nǹkan: ìyẹn kí òye nǹkan yéni,” “kó ṣeé ṣe fúnni láti rí bí àwọn kókó ọ̀rọ̀ ṣe bára wọn tan.” Òye ló máa jẹ́ kéèyàn lè so èrò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nípa ọ̀ràn kan mọ́ra wọn kéèyàn sì wá rí bí gbogbo ọ̀ràn ọ̀hún ṣe rí gan-an, kò kàn ní jẹ́ apá kan ọ̀ràn náà lèèyàn á rí. Ohun tí òwe yìí ń sọ ni pé ó máa ń rọrùn fún olóye èèyàn láti ní ìmọ̀.
Níbi tá a dé yìí, gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ìwọ fúnra rẹ yẹ̀ wò nípa bó o ṣe dẹni tó ní ìmọ̀ òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́. Nígbà tó o bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ẹ̀kọ́ ìbẹ̀rẹ̀ nípa Ọlọ́run, àwọn ìlérí rẹ̀, àti Ọmọ rẹ̀ làwọn òtítọ́ tó o kọ́kọ́ kọ́. Níbẹ̀rẹ̀, wọn ò bára wọn tan lọ́kàn rẹ. Àmọ́ bó o ti ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ nìṣó, àwọn ẹ̀kọ́ yìí wá bẹ̀rẹ̀ sí í nítumọ̀ sí ọ, ó sì ṣeé ṣe fún ọ láti rí bí onírúurú ẹ̀kọ́ náà ṣe tan mọ́ ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn láti ṣe fún èèyàn àti sí ilẹ̀ ayé. Òtítọ́ inú Bíbélì bẹ̀rẹ̀ sí í bọ́gbọ́n mu lọ́kàn rẹ, wọ́n sì bára wọn mu. Kò wá nira fún ọ mọ́ láti kọ́ àwọn nǹkan tuntun kó o sì máa rántí wọn nítorí pé o lè rí bí àwọn ẹ̀kọ́ náà ṣe bá ìmọ̀ òtítọ́ inú Bíbélì mu.
Ọlọ́gbọ́n ọba náà sọ ọ̀dọ̀ ẹni tá ò ti lè rí ìmọ̀ fún wa. Ó ní:“Kúrò ní iwájú arìndìn, nítorí ó dájú pé ìwọ kì yóò ṣàkíyèsí ètè ìmọ̀.” (Òwe 14:7) Arìndìn èèyàn ò ní ìmọ̀ gidi. Ètè rẹ̀ kì í sọ ìmọ̀ jáde. Ìmọ̀ràn tí ọba náà fún wa ni pé ká kúrò lọ́dọ̀ irú èèyàn bẹ́ẹ̀, ó sì bọ́gbọ́n mu ká jìnnà sí i. Ẹnikẹ́ni “tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.”—Òwe 13:20.
Sólómọ́nì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Ọgbọ́n afọgbọ́nhùwà ni láti lóye ọ̀nà ara rẹ̀, ṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ àwọn arìndìn ni ẹ̀tàn.” (Òwe 14:8) Kí ọlọ́gbọ́n èèyàn tó ṣe nǹkan, á kọ́kọ́ ronú lé e lórí. Yóò wo onírúurú ọ̀nà tóun tún lè gbé nǹkan náà gbà, á sì ronú dáadáa lórí ohun tí yóò jẹ́ àbájáde ọ̀kọ̀ọ̀kan. Nǹkan tó mọ́gbọ́n dání ló máa ń ṣe. Àmọ́ arìndìn èèyàn ńkọ́? Ọ̀nà òpònú lòun máa ń tọ̀, á sì gbà pé òun mọ ohun tóun ń ṣe àti pé kò sí ìpinnu tó dáa tó èyí tí òun ṣe. Ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ máa ń tàn án jẹ.
Bí A Ṣe Lè Máa Fi Ọgbọ́n Bá Àwọn Èèyàn Lò
Ẹni tó lọ́gbọ́n máa ń wà lálàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ọba Ísírẹ́lì sọ pé: “Òmùgọ̀ ni àwọn tí ń fi ẹ̀bi ṣẹ̀sín, ṣùgbọ́n ìfohùnṣọ̀kan wà láàárín àwọn adúróṣánṣán.” (Òwe 14:9) Nǹkan yẹ̀yẹ́ ni òpònú èèyàn máa ń ka ọ̀ràn kí ẹ̀rí ọkàn máa dáni lẹ́bi sí. Ó ti dọ̀tá aráalé ó ti dọ̀tá ará oko nítorí pé “ìgbéraga kì í jẹ́ [kó] ṣe àtúnṣe ọ̀rọ̀” kì í sì í wá àlàáfíà. (The New English Bible) Adúróṣánṣán èèyàn ní tiẹ̀ máa ń múra tán láti fara da kùdìẹ̀-kudiẹ àwọn ẹlòmíràn. Kì í nira fún un láti tọrọ àforíjì kó sì ṣàtúnṣe tó bá jẹ́ òun ló ṣẹ ẹlòmíràn. Nítorí pé bí àlàáfíà á ṣe jọba ló máa ń wá, ayọ̀ àti ìrẹ́pọ̀ wà láàárín òun àtàwọn èèyàn.—Hébérù 12:14.
Sólómọ́nì wá mẹ́nu kan ohun kan tí kì í jẹ́ kí ẹ̀dá èèyàn gbádùn àjọṣe wọn lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Ó ní: “Ọkàn-àyà mọ ìkorò ọkàn ẹni, kò sì sí àjèjì tí yóò tojú bọ ayọ̀ yíyọ̀ rẹ̀.” (Òwe 14:10) Ṣé gbogbo ìgbà la máa ń sọ ohun tó wà lọ́kàn wa fáwọn ẹlòmíràn, bóyá ohun tó ń bà wá lọ́kàn jẹ́ tàbí ohun tó ń múnú wa dùn, ká sì sọ bí nǹkan náà ṣe rí lára wa gẹ́lẹ́? Ṣé gbogbo ìgbà sì lẹnì kan lè mọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹlòmíràn? Bẹ́ẹ̀ kọ́ ni ìdáhùn àwọn ìbéèrè méjèèjì yìí.
Bí àpẹẹrẹ, wo èrò gbígbẹ̀mí ara ẹni tó máa ń wá sí àwọn kan lọ́kàn. Kì í ṣeé ṣe fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ láti sọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn gan-an fún ẹnì kan nínú ìdílé wọn tàbí fún ọ̀rẹ́ wọn kan. Àwọn èèyàn kì í sì í mọ̀ pé àwọn èèyàn wọn ń ro irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lọ́kàn. Kò yẹ ká máa dára wa lẹ́bi tá ò bá rí àwọn àmì wọ̀nyí ká sì ṣe nǹkan kan láti ran irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́. Òwe yìí tún kọ́ wa pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè rí ìtùnú tá a bá sọ ohun tó ń dà wá lọ́kàn rú fún ọ̀rẹ́ wa kan tí ọ̀rọ̀ wa máa ń ká lára, ó níbi tí ẹ̀dá èèyàn lè tù wá nínú mọ. Jèhófà nìkan ṣoṣo la ní láti gbára lé nígbà tá a bá ní àwọn ìṣòro kan tó ń bá wa fínra.
“Àwọn Ohun Tí Ó Níye Lórí àti Ọrọ̀ Wà Nínú Ilé Rẹ̀”
Ọba Ísírẹ́lì sọ pé: “A ó pa ilé àwọn ènìyàn burúkú rẹ́ ráúráú, ṣùgbọ́n àgọ́ àwọn adúróṣánṣán yóò gbilẹ̀.” (Òwe 14:11) Nǹkan lè ṣẹnuure fún ẹni burúkú nínú ètò àwọn nǹkan yìí, ó sì lè máa gbénú ilé olówó iyebíye. Àmọ́ àǹfààní wo nìyẹn máa ṣe fún un tóun alára bá dẹni ìgbàgbé? (Sáàmù 37:10) Ní ìdàkejì, olóòótọ́ èèyàn lè máa gbénú ilé olówó pọ́ọ́kú. Síbẹ̀, Sáàmù 112:3 sọ pé: “Àwọn ohun tí ó níye lórí àti ọrọ̀ wà nínú ilé rẹ̀.” Kí làwọn nǹkan wọ̀nyẹn?
Bá a bá ń lo ọgbọ́n nínú ọ̀nà tá à ń gbà sọ̀rọ̀ àti nínú ìṣe wa, a óò ní “ọrọ̀ àti ògo” tó ń bá ọgbọ́n rìn. (Òwe 8:18) Lára rẹ̀ ni pé àárín àwa àti Ọlọ́run àti ọmọnìkejì wa á gún régé, ọkàn wa á sì balẹ̀ dé àyè kan. Bẹ́ẹ̀ ni o, “àgọ́ àwọn adúróṣánṣán” lè gbilẹ̀, àní lákòókò tá a wà yìí pàápàá.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Ọlọ́gbọ́n obìnrin ń kọ́ ilé rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
“Ahọ́n ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìmúniláradá”